Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Àtọkànwá Wa Gbogbo
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2022


14:16

Àtọkànwá Wa Gbogbo

Bí a bá fẹ́ kí Olùgbàlà gbé wa sókè sí ọ̀run, nígbànáà ìfọkànsìn wa sí I àti ìhìnrere Rẹ̀ kò gbọ́dọ̀ jẹ́ àìnípọn tàbí ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan.

Ẹbọ kan Sí I

Kété ní àwọn ọjọ́ ṣíwájú kí Ó tó fi ayé Rẹ̀ fún wa, Jésù Krístì wà ní tẹ́mpìlì ní Jérúsálẹ́mù, Ó nwo àwọn ènìyàn tí wọ́n ndáwó sínú ìsura tẹ́mpìlì. “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí wọ́n jẹ́ ọlọ́rọ̀ sì sọ púpọ̀ síi,” ṣùgbọ́n nígbànáà, tálákà opó kan sì wá, “ó si fi idẹ wẹ́wẹ́ méjì síi.” Ó jẹ́ irú oye kekeré kan, ó tilẹ̀ má lè yẹ ní kíkọsílẹ̀.

Opó kan tí ó nfúnni ní owó idẹ wẹ́wẹ́ méjì.

Àtì síbẹ̀síbẹ̀ ìdáwó tí kò níyì yí dàbí ó gba ìdojúkọ Olùgbàlà. Nítoótọ́, ó wọ̀ Ọ́ lọ́kàn jinlẹ̀-jìnlẹ̀ gan tí “ó pè àwọn ọmọẹ̀hìn rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì wí fún wọn pé, Lootọ ni mo wí fún yín, Pé tálákà opó yí sọ sínú àpótí ìṣura, ju gbogbo àwọn tí ó sọ sínú rẹ̀ lọ:

“Nítorí gbogbo wọn sọ sínú rẹ̀ nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìnì wọn; ṣùgbọ́n òun nínú àìní rẹ̀ ó sọ ohun gbogbo tí ó ní síi, àní gbogbo ìní rẹ̀.”1

Pẹ̀lú àfiyèsí ìrọ̀rùn yí, Olùgbàlà kọ́ wa bí a ṣe nwọn àwọn ọ̀rẹ nínú ìjọba Rẹ̀—ó sì yàtọ̀ gidigidi sí ọ́ná tí à fi nwọn àwọn nkan. Sí Olúwa, iyì ìdáwó ni a kò wọ̀n nípa abájáde tí ó ní lóri àpótí ìṣúra ṣùgbọ́n nípa àbájáde tí ó ní lórí ọkàn olùfisílẹ̀.

Ní yínyin opó onígbàgbọ́ yí, Olùgbàlà fún wa ní òṣùwọn kan láti wọn jíjẹ́-ọmọẹ̀hìn wa nínú gbogbo ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìfihàn rẹ̀. Jésù kọ́ni pé ọrẹ wa lè tóbi tàbí ó lè kéré, ṣùgbọ́n ní ọ̀nàkọnà, gbogbo rẹ̀ gbọ́dọ̀ jẹ́ àtọkànwá wa.

Ẹ̀kọ́ ìpìnlẹ̀ yí ni a túnsọ nínú ẹ̀bẹ̀ wòlíì Ámálékì ti Ìwé ti Mọ́mọ́nì: “Wá sọ́dọ̀ Krístì, ẹni tí íṣe Ẹni Mímọ́ Ísráẹ́lì, kí ẹ sì ṣe àbápín ígbàlà rẹ̀, àti agbára ti ìràpadà rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ni, ẹ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, kí ẹ si fi gbogbo ọkàn yín fun bí ọrẹ sí i.”2

Ṣùgbọ́n báwo ni ó ti ṣeéṣe? Sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ lára wa, irú òṣùwọn ìfọkànsìn gbogbo-ọkàn dàbí àìsí ní àrọ́wọ́tó. A ti nà tán gan tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. Báwo ni a ṣe lè mú àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbèèrè ti ayé dọ́gba pẹ̀lú àwọn ìfẹ́ wa láti fi gbogbo ọkàn wa fún Olúwa?

Bóyá ìpènijà wa ni pé a rópé dídọ́gba túmọ̀ sí pípín àkókò wa déédé ní àárín àwọn ìfẹ́ tó ndíje. Ẹ wòó ní ọ̀nà yí, ìfarajìn wa sí Jésù Krístì yíò jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun tí a níláti ṣe ní ìbámu sí ètò iṣẹ́ ṣíṣe wa jùlọ. Ṣùgbọ́n bóyá ọ̀nà míràn wà láti wò ó.

Ìbádọ́gba: Bíi ti Yíyí Kẹ̀kẹ́ kan

Ìyàwó mi, Harriet, àti èmi fẹ́ràn láti lọ yí kẹ̀kẹ́ papọ̀. Ó jẹ́ ọ̀nà ìyanu kan láti ṣe ìdárayá díẹ̀ nígbàtí à nlo àkokò papọ̀. Nígbàtí à nyí-kẹ̀kẹ́, tí èmi kò bá sì mí gule-gule púpọ̀ jù, à ngbádùn ayé rírẹ̀wà ní àyíká wa àní àti gbígbá ìbánisọ̀rọ̀ aládùn kan. Ó ṣọ̀wọ́n kí a tó fi ojúsí pípa ìbádọ́gba wa mọ́ lórí àwọn kẹ̀kẹ́ wa. A ti nyí-kẹ̀kẹ́ ti pẹ́ tó nísisìyí àní tí a kò tilẹ̀ rònú nípa ìyẹn—ó ti di déédé àti ìwà-ẹ̀dá fún wa.

Ṣùgbọ́n nígbàkugbà tí mo bá nwo ẹnìkan tí ó nyí kẹ̀kẹ́ fún ìgbà àkọ́kọ́, mo nrántí pé kò rọrùn láti mú ara wa dọ́gbà lórí àwọn wíìlì tínrín méjì. Ó ngba àkokò. Ó ngba ìṣe. Ó ngba sùúrù. Àní ó ngba ṣíṣubú sílẹ̀ ní ìgbà kan tàbí méjì.

Ju gbogbo rẹ̀ lọ, àwọn ẹni tí ó yege ní dídọ́gba lórí kẹ̀kẹ́ kọ́ àmọ̀ràn pàtàkì yí:

Ẹ máṣe wo àtẹ́lẹsẹ̀ yín.

Wo iwájú.

Ẹ pa ojú yín mọ́ sí ojú ọ̀nà ní iwájú yín. Ẹ dojúkọ òpin ìrìnàjò yín. Kí ẹ sì tẹ̀ pẹ́dálì. Dídúró ní ìbádọ́gba wà nípa títẹ̀síwájú

Irú àwọn ẹ̀kọ́-ìpìlẹ̀ kannáà wúlò nígbàtí ó bá di rírí ìbádọ́gba nínú ayé wa bí àwọn ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì. Láti pín àkokò àti okun yín ní àárín ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn iṣẹ́ pàtàkì yín yíò jẹ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láti ẹnìkan sí ẹnìkan àti láti àkokò ayé kan sí òmíràn. Ṣùgbọ́n, kókári àfojúsùn wa, ni láti tẹ̀lé Ọ̀nà ti Olùkọ́ wa, Jésù Krístì, àti láti padà sí ọ̀dọ̀ olùfẹ́ Baba wa ní Ọ̀run. Àfojúsùn yí gbọ́dọ̀ dúró-títí àti léraléra, ẹnikẹ́ni yíówù kí a jẹ àti ohunkóhun míràn tí ó nṣẹlẹ̀ nínú ayé wa.3

Gbésókè: Bí Ọkọ̀ Òfúrufú Fífò kan.

Nísisìyí, fún àwọn ẹnití wọ́n jẹ́ olùyíkẹ̀kẹ́ mímọṣẹ́, ní ìfiwé jíjẹ́-ọmọẹ̀hìn sí yíyí kẹ̀kẹ́ kan lè jẹ́ ìjúwe ìrànlọ́wọ́. Fún àwọn ẹnití kò rí bẹ́ẹ̀, ẹ máṣe dàmú. Mo ní àfiwé míràn tí ó dá mi lójú pé, gbogbo ọkùnrin, obìnrin, àti ọmọdé yíò lè wà ní ìbámu pẹ̀lú.

Jíjẹ́-ọmọẹ̀hìn, bìiti púpọ̀jùlọ àwọn nkan nínú ayé, bákannáà ni a lè fi júwe sí ọkọ̀-òfúrufú kan ti ó nfò.

Ṣe ẹ ti dùró láti ronú bí ó ti jẹ́ ìyanu kí jẹ́ẹ̀tì nlá akérò lè kúrò lórí ilẹ̀ gan an kí ó sì fò. Kíni ohun tí ó npa àwọn ẹ̀rọ fífò wọ̀nyí mọ́ ní yíyangàn bí wọ́n ti nfò lójú òfúrufú, ní sísọdá òkun àti àwọn àgbáyé?

Kí a kàn sọ jẹ́jẹ́ pé, ọkọ̀-òfúrufú kan nfò nìkan nígbàtí atẹ́gùn nfẹ́ lórí àwọn apá rẹ̀. Rínrìn yí dá ìyàtọ̀ nínú agbára atẹ́gùn tí ó nfún ọkọ̀-òfúrufú ní ìgbéra sílẹ̀. Àti pé báwo ni ẹ ṣe rí atẹ́gùn tó tó láti rìn lórí àwọn apá kí ó lè dá ìgbéra sílẹ̀? Ìdáhùn náà ni títì síwájú.

Ọkọ̀-òfúrufú náà kò jèrè gíga ní jíjókó ní ọ̀nà-ìsáré. Àní ní ọjọ́ ìjì kan, ìgbéra kìí ṣẹlẹ̀ àyàfi tí ọkọ̀-òfúrufú bá nrìn sí iwájú, pẹ̀lú títì tí ó tako àwọn agbára tí ó ndi í mú padà.

Gẹ́gẹ́ bí ìyára síwájú ṣe npa kẹ̀kẹ́ mọ́ ní ìdọ́gba àti ìdúró, rínrìn síwájú nran ọkọ̀-òfúrufú kan lọ́wọ́ láti borí gbígbé agbára àti fífàá.

Kíni ohun tí èyí túmọ̀sí fún wa bí ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì? Ó túmọ̀sí pé a fẹ́ láti rí ìdọ́gba nínú ayé, àti bí a bá fẹ́ kí Olùgbàlà gbé wa sókè sí ọ̀run, nígbànáà ìfọkànsìn wa sí I àti ìhìnrere Rẹ̀ kò gbọ́dọ̀ jẹ́ àìnípọn tàbí ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan Bíi opó ní Jérúsálẹ́mù, a gbọ́dọ̀ fún Un ní gbogbo ọkàn wa. Ọrẹ wa lè kéré, ṣùgbọ́n ó gbọ́dọ̀ wá látinú ọkàn àti ẹ̀mí wa.

Jíjẹ́ ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì kìí ṣe ọ̀kan lásán lára àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun tí à nṣe. Olùgbàlà ni agbára ìwúrí lẹ́hìn gbogbo ohun tí à nṣe. Òun kìí ṣe ìdúró ìsinmi nínú ìrìnàjò wa. Òun kìí ṣe ihò kan nípa ọ̀nà àní tàbí kókó àmì. Òun “ni ọ̀nà, òtítọ́, ati ìyè: kò sí ẹnikẹ́ni tí ó le wá sí ọ̀dọ̀ Baba bíkòṣe nípasẹ̀ [Jésù Krístì].”4 Ìyẹn ni Ọ̀nà àti ibùdó ìgbẹ̀hìn wa.

Ìdọ́gba àti ìgbéra nwá bí a ṣe “ntẹ̀síwájú pẹ̀lú ìdúróṣinṣin nínú Krístì, níní ìrètí dídán, àti ìfẹ́ ti Ọlọ́run àti ti gbogbo ènìyàn.”5

Ìrúbọ àti Ìyàsọ́tọ̀

Àti pé kíni ó ṣẹlẹ̀ sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn iṣẹ́ àti ojúṣe tí ó nmú ayé wa kún fún iṣẹ́? Lílo àkokò pẹ̀lú àwọn àyànfẹ́, lílọ sí ilé-ìwé tàbí mímúrasílẹ̀ fún iṣẹ́ kan, gbígba ìgbé-ayé, ìtọ́jú fún ẹbí, sísìn nínú ìletò—níbo ní gbogbo èyí ti ní ìbamu? Olùgbàlà ti tún mu dáwalójú pé:

“Bàbá yín Ọ̀run mọ̀ pé ẹ̀yin nílò gbogbo ohun wọ̀nyí.

“Ṣùgbọ́n ẹ tètè máa wá ìjọba Ọlọ́run ná, àti òdodo rẹ̀, gbogbo àwọn ohun wọ̀nyí ni a ó sì fi kun fún yín.”6

Ṣùgbọ́n ìyẹn kò túmọ̀sí pé ó rọrùn.7 Ó gba méjèèjì ìrúbọ àti ìyàsọ́tọ̀.

Ó gba jíjẹ́ kí àwọn ohunkan lọ àti jíjẹ́ kí àwọn ohun míràn dàgbà.

Ìrúbọ àti Ìyàsọ́tọ̀ jẹ́ àwọn òfin méjì tọ̀run tí a dá májẹ̀mú láti gbọ́ran sí nínú tẹ́mpìlì mímọ́. Àwọn òfin méjì wọ̀nyí rí bákánnáà ṣùgbọ́n ko jọra. Láti rúbọ túmọ̀sí láti fi ohunkan sílẹ̀ fún ojúrere ohunkan tí ó níyì jù síi. Ní àtijọ́, àwọn ènìyàn Ọlọ́run rúbọ àkọ́bí àwọn agbo-ẹ̀ràn wọn nínú ọlá ti Mèsíàh tí ó nbọ̀. Nínú gbogbo àkọọ́lẹ̀-ìtàn, àwọn onígbàgbọ́ Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ti rúbọ àwọn ìfẹ́ araẹni, ìtùnú, àní àti ìgbé-ayé wọn fún Olùgbàlà.

Gbogbo wa ní àwọn ohun, nlá àti kékeré, tí a nílò láti rúbọ ní èrò láti tẹ̀lé Jésù Krístì síi pátápátá.8 Àwọn ìrúbọ wa nfi ohun tí a mọyì rẹ̀ hàn nítòótọ́. Àwọn ẹbọ jẹ́ mímọ́ wọ́n sì lọlá nípasẹ̀ Olúwa.9

Yíyàsọ́tọ̀ yàtọ̀ sí ẹbọ ní ọ̀nà pàtàkì kan ó kéréjù. Nígbàtí a bá ya ohunkan sọ́tọ̀, a kò ní fi sílẹ̀ láti parẹ́ lórí pẹpẹ. Ṣùgbọ́n, a ó fi sí ìlò nínú iṣẹ́-ìsìn Olúwa. A yàá sí mímọ́ fún èrèdí mímọ́ Rẹ̀.10 À ngba àwọn tálẹ́ntì tí Olúwa ti fún wa a sì nmú wọn pọ̀si, lọ́pọ̀lọpọ̀, àní láti di olùrànlọ́wọ́ síi ní gbígbé ìjọba Olúwa ga.11

Díẹ̀ lára wa ni a kò ní ní kí a fi ayé wa rúbọ̀ fún Olùgbàlà láéláé. Ṣùgbọ́n a pe gbogbo wa láti ya ayé wa sí mímọ́ sí I.

Iṣẹ́ kan, Ayọ̀ kan, Èrèdí kan

Bí a ṣe nwá láti ya ayé wa sí mímọ́ kí a sì wo Krísti ní gbogbo èrò,12 gbogbo ohun míràn yíò bẹ̀rẹ̀sí wà ní ìbámu. Ìgbé-ayé kó ní dàbí ìtò gígùn ti yíyàsọ́tọ̀ ìtiraka tí a dìmú nínú ìbádọ́gba líle.

Ní àkokò, gbogbo rẹ̀ yíò di iṣẹ́ kan.

Ayọ̀ kan.

Èrèdí mímọ́ kan.

Ó jẹ́ iṣẹ́ fífẹ́ni àti sísin Ọlọ́run. Ó jẹ́ fífẹ́ àti sísin àwọn ọmọ Ọlọ́run.13

Nígbàtí a bá wo ìgbé-ayé wa tí a sì wo àwọn ohun ọgọrun kan láti ṣe, à nní ìmọ̀lára ìbòmọ́lẹ̀. Nígbàtí a bá wo ohun kan—fífẹ́ àti sísin Ọlọ́run àti àwọn ọmọ Rẹ̀, ní àwọn ọ̀nà yíyàtọ̀ ọgọrun kan—nígbànáà a lè dojúkọ àwọn ohun wọnnì pẹ̀lú ayọ̀.

Èyí jẹ́ bí a ṣe nfúnni ní gbogbo ọkàn wa—nípa rírúbọ ohunkóhun tí ó ndìwá mú kí a sì ya ìyókù sọ́tọ̀ sí Olúwa àti àwọn èrèdì Rẹ̀.

Ọ̀rọ̀ Ìgbà-ni-níyànjú àti Ẹ̀rí kan

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n àti ẹ̀yin ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n, àwọn ìgbà kan yíò wà nígbàtí ẹ̀yí ó ní ìfẹ́ pé kí ẹ lè ṣe púpọ̀ si. Olùfẹ́ Baba yín ní Ọ̀run mọ ọkàn yín. Ó mọ pé ẹ kò lè ṣe ohungbogbo tí ọkàn yín nfẹ́ láti ṣe. Ṣùgbọ́n ẹ lè nifẹ́ kí ẹ sì sìn Ọlọ́run. Ẹ lè ṣe dídárajùlọ láti pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́. Ẹ lè nifẹ kí ẹ sì sin àwọn ọmọ Rẹ̀. Àti pé àwọn ìtiraka yín nya ọkàn yín sí mímọ́ ó sì nmúra yín sílẹ̀ fún ọjọ́-ọ̀la ológo kan.

Èyí ni ohun tí ó dàbì opó níbi àpótí-ìsura tẹ́mpìlì ní ìmọ̀. Dájúdájú òun mọ̀ pé ọ̀rẹ rẹ̀ kò ní yí ire Ísráẹ́lì padà, ṣùgbọ́n ó lè yí òun padà—nítorí, bíótilẹ̀ kéré, ó jẹ́ gbogbo ohun tí ó ní.

Nítorínáà, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n àti olùfẹ́ ọmọnìkejì ọmọẹ̀hìn ti Jésù Krístì, ẹ jẹ́ kí a máṣe “rẹ̀wẹ̀sì nínú rere-ṣíṣe, nítorí a ngbé ìpìlẹ̀ iṣẹ́ nlá kalẹ̀.” Àti pé nínú àwọn ohun kékeré ni “èyí tí ó tóbí yíò ti jáde.”14

Mo jẹri pé èyí jẹ́ òtítọ́, bákannáà mo tún jẹri pé Jésù Krístì ni Olùkọ wa, Olùràpadà wa, àti Ọ̀na kan àti nìkàn láti padà sí ọ̀dọ̀ olùfẹ́ Baba wa ní Ọ̀run. Ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Márkù 12:41–44.

  2. Omni 1:26.

  3. Àwọn ọmọde àti ọ̀dọ́ ni a pè láti gbèrú nínú ọ̀nà ìbádọ́gba bí a ṣe ntẹ̀lé Jésù Krístì, ẹnití ó “npọ̀ ní ọgbọ́n ó sì ndàgbà, ó sì wà ní ojúrere ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run àti ènìyàn” (Lúkù 2:52

  4. Jòhánnù14:6.

  5. 2 Nefì 31:20.

  6. 3 Néfì 13 32-33; bákannáà wo Matteu 6:32-33. Ìyírọ̀padà-èdè Joseph Smith, Máttéù 6:38pèsè àfikún òye: “Ẹ máṣe wá àwọn ohun ayé yí ṣùgbọ́n ẹ kọ́kọ́ wá láti gbé ìjọba Ọlọ́run ga, àti láti gbé òdodo rẹ̀ kalẹ̀” (in Matthew 6:33, footnote a).

  7. Àpẹrẹ kan nwá láti ọ̀dọ̀ wòlíì wa, Ààrẹ Russell M. Nelson. Nígbàtí ó wà ní òkè mímòye iṣẹ́ rẹ̀ bí alábẹ ọkàn, a pè é bí ààrẹ èèkàn. Àwọn Alàgbà Spencer W. Kimball àti LeGrand Richards nawọ́ ipè náà. Dídá ìbèèrè ti mímòye ìgbé-ayé rẹ̀ mọ̀, wọ̀n wí fun pé, “Bí ìwọ bá ní ìmọ̀lára pé iṣẹ́ ti pọ̀ jù tí o kò sì gbọ́dọ̀ tẹ́wọ́gba ìpè, nígbànáà ìyẹn jẹ́ ànfàní rẹ.” Ó dáhùn pé ìpinnu rẹ̀ nípa bóyá tàbí kí òun máṣe sìn nígbàtí a pè é ní pípẹ́ sẹ́hìn, nígbàtí òun àti aya rẹ̀ dá àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Olúwa. “A ṣe ìfọkànsìn nígbànáà,”ó wípé, “láti kọ́kọ́ ‘wá … ìjọba Ọlọ́run, àti òdodo rẹ̀’ [Máttéù 6:33], níní ìmọ̀lára ìgbẹ́kẹ̀lé pé ohun gbogbo míràn ni a ó fikun fún wa, bí Olúwa ti ṣe ìlérí” (Russell Marion Nelson, Látinú Ọkàn sí Ọkàn Ìtàn-ìgbésí-ayé araẹni kan [1979], 114).

  8. Ààrẹ Nelson láìpẹ́ sọ̀rọ̀ nípa “ìnílò fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wa láti mú, àwọn àbàwọ́n àtijọ́ inú ayé wa kúrò, nípa ìrànlọ́wọ́ Olùgbàlà. … Ó wípé, mo pe yín láti gbàdúrà,” “láti dá àwọn àbàwọ́n tí ẹ níláti múkúrò nínú ayé yín mọ̀ kí ẹ lè di yíyẹ” (“Ọ̀rọ̀ Ìkíni-káàbọ̀,” Liahona, Oṣù karun 2021, 7).

  9. Ìwé-mímọ́ wí pé, sí Ọlọ́run, àwọn ìrúbọ wa jẹ́ mímọ́ ju àwọn àṣeyọrí wa (wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 117:13). Èyí lè jẹ́ èrèdí kan tí Olúwa fi mọyì àwọn máìtì ti opó púpọ̀ ju ìdáwó ti ọlọ́rọ̀. Titẹ́lẹ̀ jẹ́ ìrúbọ kan, èyí tí ó ní èrè ìyàsímímọ́ lórí olùfúnni. Ti ìgbẹ̀hìn nígbàtí ó lè ní àṣeyọrí ju ti owó, kìí ṣe ìrúbọ kan, ó sì fi olùfúnni sílẹ̀ láìyípadà.

  10. Díẹ̀ lára wa ni a kò ní níláti fi ayé wa rúbọ̀ fún Olùgbàlà láéláé. Ṣùgbọ́n a pe gbogbo wa láti ya ayé wa sí mímọ́ sí I.

  11. Wo Máttéù 25:14–30.

  12. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 6:36.

  13. Ní ọ̀nà yí, a rí ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ ti Àpóstélì Páùlù nínú ayé wa: “Ní àwọn àkokò ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ iṣẹ́-ìríjú [Ọlọ́run yíò] kó àwọn ohun gbogbo jọ nínú Krístì, méjèèjì èyí tí ó wà ní ọ̀run, àti èyí tí ó wà ní ayé: àní nínú rẹ̀” (Éfésù 1:10).

  14. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 64:33.