Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Wá sínú Agbo Ọlọ́run
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2022


10:20

Wá sínú Agbo Ọlọ́run

Ní ààrin agbo Ọlọ́run, a nní ìrírí ìṣọ́ Olùṣọ́-àgùtàn Rere, ìtọ́jú ìkẹ́ Rẹ̀ a sì jẹ́ alábùkúnfún láti ní ìmọ̀lára ìfẹ́ ìràpàdà Rẹ̀.

Bí àwọn ọ̀dọ́ òbí, Arákùnrin àti Arábìnrin Samad kọ́ ẹ̀kọ́ ìhìnrere ti Jésù Krístì nínú ibùgbé wọn oní yàrá-méjì ní Semarang, Indonesia.1 Ní jijoko yí tábìlì kékeré kan ká, pẹ̀lú àtùpà elépo kẹrosínì tí ó dàbí pé ó pèsè ẹ̀fọn ju ìmọ́lẹ̀ lọ, àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere méjì kọ́ wọn ní àwọn òtítọ́ ayérayé. Nípasẹ̀ àdúrà tòótọ́ àti ìtọ́ni ti Ẹ̀mí Mímọ́, wọ́n gba ohun tí a kọ́ wọn gbọ́ wọ́n si yàn láti di rírìbọmi kí wọn sì di ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn. Ìpinnu náà, àti àwòrán ìgbé ayé wọn láti ìgbà náà, ti bùkún Arákùnrin àti Arábìnrin Samad àti ẹbí wọn ní gbogbo abala ìgbésí ayé wọn.2

Wọ́n wà lára àwọn Ènìyàn Mímọ́ olùlàna ìṣaájú ní Indonesia. Lẹ́hìnnáà wọ́n gba àwọn ìlànà ti tẹ́mpìlì, Arákùnrin Samad sì sìn bíi ààrẹ ẹ̀ka àti lẹ́hìnnáà ààrẹ ẹkùn, ní wíwakọ̀ jákèjádò àringbùngbùn Java láti mú àwọn ojúṣe rẹ̀ ṣe. Fún ọdún mẹ́wa sẹ́hìn, ó ti sìn bíi babanlá àkọ́kọ́ ti Èèkàn Surakarta Indonesia.

Alàgbà Funk pẹ̀lú Arábìnrin àti Arákùnrin Samad

Bíi ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere nínú ilé ìrẹ̀lẹ̀ àti kíkún fún ìgbàgbọ́ ní ọdún mọ́kàndínláàdọ́ta sẹ́hìn, mo ti rí ẹ̀rí rẹ̀ nínú wọn ohun tí Ọba Benjamin kọ́ni nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì pé: “Èmi yío fẹ́ kí ẹ ro ti ipò alábùkún-fún àti ìdùnnú ti àwọn wọnnì tí wọ́n pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́. Nítorí ẹ kíyèsíi, wọ́n jẹ́ alábùkúnfún nínú ohun gbogbo, méjèèjì ní ti ara àti ti ẹ̀mí.”3 Àwọn ìbùkún tí ó nṣàn sínú ìgbé ayé àwọn tí wọ́n tẹ̀lé àpẹrẹ àti àwọn ìkọ́ni Jésù Krístì, tí wọ́n yàn lati jẹ́ kíkà mọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Rẹ̀, jẹ́ àìníye, aláyọ̀, àti ayérayé.4

Agbo ti Ọlọ́run

Ìfipè májẹ̀mu ìribọmi ti Álmà sí àwọn tí wọ́n péjọpọ̀ ní ibi Àwọn Omi Mọ́mọ́nì bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú gbólóhùn ọ̀rọ̀ yí: “Nísisìyí, bí ẹ̀yin ti ní ìfẹ́ inú láti wá sínú agbo Ọlọ́run.”5

Flock of sheep in the country side standing next to a rock fence.

Agbo, tàbí agbo-ẹran kan, jẹ́ ibi àkámọ́ títóbi kan, nígbàgbogbo a máa nkọ́ ọ pẹ̀lú àwọn ògiri òkúta, níbití àwọn àgùtàn ti njẹ́ dídá ààbò bò ní òru. Ó máa nní ibi kanṣoṣo tí a lè ṣí. Ní òpin ọjọ́, olùṣọ́ àgùtàn npe àwọn àgùtàn náà. Wọ́n mọ ohùn rẹ̀, àti pé láti ibi ẹnu ọ̀nà náà wọn wọlé sí ibi ààbò agbo náà.

Àwọn ènìyàn Ǎlmà ìbá ti mọ̀ pé àwọn olùṣọ́ àgùtàn máa ndúró ní ibi ẹnu ọ̀nà tóóró agbo náà kí ó le jẹ́ pé nígbàtí àwọn àgùtàn bá nwọlé, wọn á jẹ́ kíkà6 àti pé àwọn ọgbẹ́ àti àwọn àìlera wọn yíó di fífi iyè sí àti ṣíṣe ìtọ́jú-fún ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan. Ààbò àti wíwà lálàáfíà àwọn àgùtàn dá lórí ṣíṣetán wọn láti wá sínú agbo kí wọn ó sì dúró nínú agbo náà.

Ní ààrin wa àwọn kan le wà tí wọ́n ní ìmọ̀lára pé wọ́n wà ní etí bèbè agbo, bóyá tí wọ́n nrò pé a kò nílò tàbí buyì fún wọn tó tàbí pé wọn kìí ṣe ara inú agbo náà. Àti pé, bí ti inú agbo-àgùtàn, nínú agbo Ọlọ́run nígbà míràn a ntẹ̀ ara wa ní ẹsẹ̀ mọ́lẹ̀ a sì nílò láti ronúpìwàdà tàbí dáríjì.

Ṣùgbọ́n Olùṣọ́-Àgùtàn Rere7—olùṣọ́ àgùtàn wa tòótọ́—jẹ́ dídára ní gbogbo ìgbà. Ní ààrin agbo Ọlọ́run, a nní ìrírí ìṣọ́, ìtọ́jú ìkẹ́ Rẹ̀ a sì jẹ́ alábùkúnfún láti ní ìmọ̀lára ìfẹ́ ìràpàdà Rẹ̀. Ó wípé, “Èmi ti kọ ọ́ sí orí àtẹ́lẹwọ́ ọwọ́ mi; àwọn odi rẹ nbe títílọ níwájú mi.”8 Olùgbàlà wa ti kọ àwọn ẹ̀ṣẹ̀, àwọn ìrora, àwọn ìpọ́njú wa sí orí àtẹ́lẹwọ́ Rẹ̀,9 àti gbogbo ohun tí kò dára tó nínú ayé.10 Gbogbo ènìyàn káàbọ̀ láti gba àwọn ìbùkún wọ̀nyí, bi wọ́n “ti nfẹ́ láti wá”11 kí wọn ó sì yàn láti wà nínú agbo náà. Ẹ̀bùn iṣojú araẹni kìí ṣe ẹ̀tọ́ láti yàn nìkan, pàtàkì jùlọ ó jẹ́ ànfààní láti yan èyí tó tọ́. Àti pé àwọn odi agbo náà kìí ṣe ìdíwọ́ ṣùgbọ́n orísun ààbò ní ti ẹ̀mí.

Jésù kọ́ni pé “agbo kan, àti olùṣọ́-àgùtàn kan” ni ó wà.12 Ó wí pé:

“Ẹni náà tí ó bá wọlé nípa ẹnu ọ̀nà ni olùṣọ́ ti àwọn àgùtàn náà. …

“Ǎwọn àgùtàn náà sì gbọ́ ohùn rẹ̀ … ,

“… , àwọn àgùtàn náà sì tẹ̀lé e: nítorítí wọ́n mọ ohùn rẹ̀.”13

Nígbànáà Jésù wípé, “Èmi ni ẹnu ọ̀nà: bí ẹnikẹ́ni bá wọlé nípasẹ̀ mi, òun yio di gbígbàlà,”14 kíkọ́ni kedere pé ọ̀nà kanṣoṣo ni ó wà sí inú agbo Ọlọ́run àti ọ̀nà kanṣoṣo láti jẹ́ gbígbàlà. Ó jẹ́ láti ọwọ́ àti nípasẹ̀ Jésù Krístì.15

Àwọn Ìbùkún Nwá sọ́dọ̀ Àwọn tí wọ́n wà nínú Agbo Ọlọ́run

A nkọ́ bí a ṣe lè wá sínú agbo náà láti inú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyítí ó jẹ́ ẹ̀kọ́ tí a kọ́ni láti ọwọ́ Jésù Krístì àti àwọn wòlíì Rẹ̀.16 Nígbàtí a bá tẹ̀lé ẹ̀kọ́ Krístì tí a sì wá sínú agbo náà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì, ìrònúpìwàdà, ìrìbọmi àti ìfẹsẹ̀múlẹ̀, àti ìṣòdodo títílọ,17 Álmà ṣe ìlérí àwọn ìbùkún mẹ́rin pàtó, ti araẹni. Ẹ̀yin le (1) “di ríràpadà nípa Ọlọ́run,” (2) “di kíkà pẹ̀lú àwọn ti àjínde àkọ́kọ́,” (3) “ní ìyè ayérayé,” àti pé (4) Olúwa yío “tú Ẹmí rẹ̀ jáde lé yín lórí ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ síi.”18

Lẹ́hìn tí Ǎlmà kọ́ni nípa àwọn ìbùkún wọ̀nyí, àwọn ènìyàn náà pàtẹ́wọ́ wọn fún ayọ̀. Ìdí nìyí:

Ìkínní: Láti ràpadà túmọ̀ sí láti san gbèsè tábí ojúṣe kan kúrò, tàbí láti sọ di òmìnira kúrò lọ́wọ́ ohun tó ndani láàmú tàbí ṣeni léṣe.19 Kò sí iye gbígbèrú ti araẹni ní ọ̀dọ̀ tiwa tí ó le sọ wá di mímọ́ kúrò nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí a ti dá, tàbí sọ wá di pípé kúrò nínú àwọn ọgbẹ́ tí a ti jìyà láìsí Ètùtù ti Jésù Krístì Òun ni Olùràpadà wa.20

Ìkejì: Nítorí Àjínde Krístì, gbogbo ènìyàn yío jínde.21 Lẹ́hìn tí àwọn ẹ̀mí wa bá ti kúrò ní àwọn ara kíkú wa, láìṣiyèméjì a ó fojúsọ́nà sí ìgbà tí a ó le gba àwọn tí a fẹ́ràn mọ́ra lẹ́ẹ̀kansíi pẹ̀lú ara tó ti jínde. A o fi ìtara fi ojú sọ́nà láti wà láàrin àwọn wọnnì ti Àjínde Àkọ́kọ́.

Ìkẹta: Ìyè ayérayé túmọ̀ sí láti gbé pẹ̀lú Ọlọ́run àti bí Òun ti ngbé. Ó jẹ́ “títóbijùlọ nínú gbogbo àwọn ẹ̀bùn Ọlọ́run”22 yíò sì mú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ayọ̀ wa.23 Ó jẹ́ èrèdí ìgbẹ̀hìn àti kókó ti ìgbé ayé wa.

Ìkẹrin: Ìbákẹ́gbẹ́ ìkan lára àwọn ọmọ àjọ ti Ọlọ́run-Olórí, Ẹ̀mí Mímọ́, npèsè ìtọ́ni àti ìtùnú tí a nílò púpọ̀ ní àkókò ayé kíkú yi.24

Yẹ díẹ̀ lára àwọn okùnfà àìní ìdùnnú wò: òṣì nwá láti ara ẹ̀ṣẹ̀,25 ìbánújẹ́ àti ìdánìkanwà láti ara ikú olùfẹ́ kan, àti ẹ̀rù láti ara àìní-ìdánilójú ohun tí yío ṣẹlẹ̀ nígbàtí a bá kú. Ṣùgbọ́n nígbàtí a bá wọ inú agbo Ọlọ́run tí a sì pa àwọn májẹ̀mú wa pẹ̀lú Rẹ̀ mọ́, a nní ìmọ̀lára àlàáfíà ti mímọ̀ àti níní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Krístì yío rà wá padà kúrò nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, pé ìyapa ti ara àti ẹ̀mí wa yío dópin kíákíá, àti pé a ó gbé ní ayérayé pẹ̀lú Ọlọ́run ní ọ̀nà tó lógó jùlọ.

Ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run sì Gbé Ìgbésẹ̀ nínú Ìgbàgbọ́

Ẹ̀yín arákùnrin àti ẹ̀yin arábìnrin, àwọn ìwé mímọ́ kún fún àwọn àpẹrẹ ọlánlá agbára ti Olùgbàlà àti ìyọ́nú àánú àti oore ọ̀fẹ́ Rẹ̀. Ní ìgbà iṣẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, àwọn ìbùkún ìwòsàn Rẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ àwọn tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé E tí wọ́n sì gbé ìgbésẹ̀ nínú ìgbàgbọ́. Fún àpẹrẹ, ọkùnrin abirùn náà ní ibi adágún omi Bethesda rìn nígbàtí, pẹ̀lú ìgbàgbọ́, ó tẹ̀lé àṣẹ Olùgbàlà láti “dìde, gbé àkete rẹ, kí o sì máa rìn.”26 Àwọn tí wọ́n ní àìlera tàbí tí a pọ́n lójú ní èyíkéyi ọ̀nà nínú ilẹ̀ Ibi Ọpọ̀ ni a wòsàn nígbàtí wọ́n “jáde lọ” “pẹ̀lú ìfìmọ̀ṣọkan.”27

Bákannáà, láti gba àwọn ìbùkún yíyanilẹ́nu tí a ṣelèrí fún awọn tí ó wá sínú agbo Ọlọ́run a nílò wa láti ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́—a níláti yàn láti wá. Álmà Kékeré kọ́ni pé, “Àti nísisìyí mo wí fún yín pé olùṣọ́ àgùtàn rere npè yín; bí ẹ̀yin bá sì fétísí ohùn rẹ̀ òun yío mú yín wá sínú agbo rẹ̀.”28

Ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́hìn, olùfẹ́ ọ̀rẹ́ kan kọja lọ láti ọwọ́ àrùn jẹjẹrẹ. Nígbàtí ìyàwó rẹ̀, Sharon, kọ́kọ́ kọ̀wé nípa àyẹ̀wò rẹ̀, ó wí pé, “A Yan Ìgbàgbọ́. Ìgbàgbọ́ nínú Olùgbàlà wa, Jésù Krístì. Ìgbàgbọ́ nínú ètò Baba wa Ọrun, àti ìgbàgbọ́ pé Ó mọ ìnílò wa ó sì nmú àwọn ìlérí Rẹ̀ ṣẹ.”29

Mo ti pàdé púpọ̀ Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn bíi Sharon ẹnití ó ní ìmọ̀lára àlàáfíà àtinúwá ti wíwà pẹ̀lú ààbò láàrin agbo Ọlọ́run, pàápàá nígbàtí ìdánwò, àtakò, tàbí ìdojúkọ bá wá.30 Wọ́n ti yàn láti ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì àti láti tẹ̀lé wòlíì Rẹ̀. Wòlíì wa ọ̀wọ́n, Ààrẹ Russell M. Nelson, ti kọ́ni pé, “Ohun gbogbo tí ó dára ní ìgbésí ayé—gbogbo ìbùkún tí a lè ní tí ó ṣe pàtàkì sí ayérayé—bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́.”31

Wá Ní Kíkún sí inú Agbo Ọlọ́run

Babanlá baba-baba mi James Sawyer Holman wá sí Utah ní 1847, ṣùgbọ́n kò sí láàrin àwọn tí wọ́n dé nínú Oṣù Keje pẹ̀lú Brigham Young. Ó dé ní ìkẹhìn nínú ọdún àti pé, ní ìbámu sí àwọn àkọsílẹ̀ ẹbí, ó ní ojúṣe láti kó àwọn àgùtàn wá. Kò dé sí Àfonífojì Salt Lake títí di Oṣù Kẹwàá, ṣùgbọ́n òun àti àwọn àgùtàn náà dé ibẹ̀.32

Ní sísọ̀rọ̀ bíi àfiwé, àwọn kan lára wa ṣì wà ní orí pẹ̀tẹ́lẹ̀ síbẹ̀. Kìí ṣe gbogbo ènìyàn ló dé nínú ẹgbẹ́ ti àkọ́kọ́. Ẹyin ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, ẹ jọ̀wọ́ ẹ tẹ̀síwájú nínú ìrìnàjò náà—kí ẹ sì ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́—láti wá ní kíkún sí inú agbo Ọlọ́run. Àwọn ìbùkún ti Ìhinrere Jésù Krísti jẹ́ àìní òdiwọ̀n nítorípé wọ́n jẹ́ ti ayérayé.

Mo ní ìmoore láti jẹ́ ọmọ-ijọ ti Ìjọ Jésù Krístì tí Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-Ìkẹhìn. Mó jẹ́ ẹ̀rí nípa ìfẹ́ Baba wa Ọ̀run àti Olùràpadà wa, Jésù Krístì, àti àlàáfíà tí ó nwá láti ọ̀dọ̀ Wọn nìkan—àlàáfíà àtinúwá àti àwọn ìbùkún tí a nrí nínú agbo Ọlọ́run. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Bíi ti púpọ̀ àwọn ara Indonesia ti àkókò ìran rẹ̀, Arákùnrin Samad ní orúkọ kan péré. Ìyàwó rẹ̀, Sri Katoningsih, àti àwọn ọmọ wọn nlo Samad bíi orúkọ ẹbí wọn.

  2. Arákùnrin àti Arábìnrin Samad ròhìn pé ó kéré jù 44 (mẹ́rìnlélógójì) nínú àwọn mọlẹ́bí wọn jẹ́ ọmọ Ìjọ nísisìyí. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹlòmíràn bákannáà ngbádùn àwọn ìbùkún ìhìnrere nítorí àpẹrẹ àti iṣẹ́ ìsìn wọn.

  3. Mòsíàh 2:41

  4. Wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 59:23

  5. Mòsíàh 18:8

  6. Wo Moroni 6:4

  7. Wo Jòhánnù 10:14; bákannáà wo Gerrit W. Gong, “Olùṣọ́ Àgùtàn Rere, Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run,” LàìhónàOṣù Karũn 2019, 97.

  8. Ìsàíàh 49:16

  9. Wo Álmà 7:11–13

  10. Wo Dale G. Renlund, “Infuriating Unfairness,” LiahonaMay 2021, 41–44.

  11. Mòsíàh 18:8

  12. Jòhánnù10:16

  13. Jòhánnù 10:2–4

  14. Jóhánnù 10:9

  15. Wo 2 Néfì 31:21; Hẹ́llámánì 5:9.

  16. Wo Henry B. Eyring, “Agbara Kíkọ́ni Ní Ẹ̀kọ́,” LiahonaOṣù Keje 1999, Nígbàtí a bá lépa láti wá sí ọ̀dọ̀ Krístì, a gbọ́dọ̀ wá ní ìbámu sí àwọn ọ̀rọ̀ Krístì, “nítorí Ọlọ́run kan ni ó wà àti Olùṣọ́ Àgùtàn kan lórí gbogbo ilẹ̀ ayé” (wo 1 Néfì 13:40–41).

  17. Ẹ̀kọ́ ti Krístì, ti a sọ nírọ̀rùn, ni pé gbogbo ènìyàn níbi gbogbo gbọ́dọ̀ lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì àti Ètùtù Rẹ̀, ronúpíwàdà, ṣe ìrìbọmi, gba Ẹ̀mí Mímọ́, àti forítì de òpin, tàbí, gẹ́gẹ́bí Olùgbàlà ti kọ́ni ní 3 Néfì 11:38, “Ẹ̀yin kò lè jogún ìjọba Ọlọrun bíótiwù kíórí.”

  18. Mòsíàh 18:8–11

  19. Wo Merriam Webster.com Dictionary, “ràpadà”; bákannáà wo D. Todd Christofferson, “Ìràpadà,” Lìàhónà, May 2013, 109.

  20. Wo Álmà 11:37

  21. Wo 2 Néfì 2:8; 9:12.

  22. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 109:7

  23. Wo 1 Néfì 16:29

  24. Wo 1 Nephi 3:7Moroni 7:33

  25. Wo Mòsíàh 5: 2Álmà 5:7

  26. Jòhánnù14:2

  27. 3 Néfì 17:7

  28. Álmà 32:27 In Mósè 7:53, Mèssíàh náà tún sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá wọlé ní ẹnubodè, tí ó sì gòkè nípasẹ̀ mi, kì yóò ṣubú láé.”

  29. Sharon Jones, “Diagnosis,” wechoosefaith.blogspot.com, Mar. 18, 2012.

  30. Wàásù Ìhìnrere Mi túmọ̀ “ìforítìí títí dé opìn” bí ìwọ̀nyí: “Láti duro ṣinṣin sí àwọn òfin ti Ọlọ́run àti láti jẹ́ olótítọ́ sí ẹ̀bun àti àwọn ìlànà ìsopọ̀ ti tẹ́mpìlì láìbìkítà ìdánwò, alátakò, àti ìpọ́njú ní gbogbo ìgbésí ayé” ([2019], 73). Èyí fi hàn pé a óò nírìírí ìdẹwò, àtakò, àti ìpọ́njú jálẹ̀ ìgbésí ayé wa.

  31. Russell M. Nelson, “Krístì Jínde; Ìgbàgbọ́ nínú Rẹ̀ Yíò Ṣí àwọn Òkè,” Liahona, May 2021, 102.

  32. See brief biographies of James Sawyer Holman and Naomi Roxina LeBaron Holman by their granddaughter Grace H. Sainsbury in the possession of the speaker (Charles C. Rich diary, Sept. 28, 1847, Church History Library, Salt Lake City; Journal History of The Church of Jesus Christ of Latter-day Saints, June 21, 1847, 49, Church History Library). Holman jẹ́ olórí nínú àwọn 1847 Charles C. Rich Company.