Ipa Ọ̀nà Májẹ̀mú: Ọ̀nà sí Ìyè Ayérayé
Ipá-ọ̀nà sí àṣepé ni ipá-ọ̀nà májẹ̀mú, àti pé Krístì ní gbùngbùn gbogbo àwọn ìlànà àti májẹ̀mú.
Ọba alágbára kan fẹ́ kí ọmọkùnrin rẹ̀ jọba lórí ọ̀kan lára àwọn ìjọba rẹ̀. Ọmọ-ọba náà ní láti kẹkọ kí ó sì dàgbà nínú ọgbọ́n láti joko lórí ìtẹ́. Ní ọjọ́ kan, ọba náà pàdé pẹ̀lú ọmọ-ọba náà ó sì ṣe àbápín ètò rẹ̀. Wọ́n gbà pé ọmọ-ọba yíò lọ sí ìlú ọ̀tọ̀ láti ní àwọn ìrírí. Òun yíò dojúkọ àwọn ipènijà bákannáà yíò sì gbádùn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun rere níbẹ̀. Nìgbànáà Ọba rán an lọ sí ìlú náà, níbití a ti nretí pé ọmọ-ọba ní lati dán òdodo rẹ̀ wò sí ọba kí ó sì fihàn pé òun dára tó láti gba àwọn ànfàní àti ojúṣe tí ọba ní ní-ìṣura fún un. Ọmọ-ọba ni a fún ní ààyè láti yàn láti gba àwọn ànfàní àti ojúṣe wọ̀nyí tàbí bẹ́ẹ̀kọ́, ní dídálórí ìfẹ́ rẹ̀ àti òdodo rẹ̀. Ó dá mi lójú pé ẹ fẹ́ láti mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí ọmọ-ọba náà. Njẹ́ ó padà láti jogún ìjọba náà?
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa jẹ́ ọmọ-ọba ọkùnrin tàbí ọmọ-ọba obìnrin. A ti rán wa wá sí ayé-ikú nípasẹ̀ olùfẹ́ni Baba Ọ̀run láti gbádùn ìbùkún ti ara tí yíò di àìkú nípasẹ̀ Ètùtù àti Àjínde Jésù Krístì. À nretí láti múrasílẹ̀ láti padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nípa dídánwò pé a ó “ṣe gbogbo ohunkóhun tí Olúwa Ọlọ́run [wa] yíò pàṣẹ fún [wa]” (Ábráhámù 3:25).
Láti rànwálọ́wọ́, Olùgbàlà wá láti ràwàpadà àti láti fi ipá-ọ̀nà tó padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run hàn. Àwọn ọmọ Ọlọ́run ni a pè láti wá sí ọ̀dọ̀ Olùgbàlà kí a sì ṣe àṣepé nínú Rẹ̀. Nínú ìwé-mímọ́, a rí ìfipè fún wa láti wá sí ọ̀dọ̀ Olúwa léraléra ju bíi ìgbà Àádọ́ọ̀wá, àti jíju ìlàjì ìwọ̀nyí ni àwọn ìfipè araẹni láti ọ̀dọ̀ Olúwa Fúnrarẹ̀. Títẹ́wọ́gba ìfipè Olùgbàlà túmọ̀sí ṣíṣe àbápín àwọn ìlànà Rẹ̀ àti pípa àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Rẹ̀ mọ́. Jésù Krístì ni ọ̀nà, òtítọ́, àti ìyè” (Jòhánnù 14:6), Ó sì pè gbogbo wá “láti wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ kí a sì pín nínú oore rẹ̀; kò sì kọ̀ fún ẹnìkẹ́ni láti wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀” (2 Néfì 26:33
Ìkọ́ni àti ikẹkọ ìhìnrere wa nmú íyípadà wa sí Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì jinlẹ̀ ó sì nrànwálọ́wọ́ láti dàbíi Tiwọn. Àní bíótilẹ̀jẹ́pẹ́ kìí ṣe gbogbo ohun tí a ti fihàn nípa “déédé àkokò àti irú-ọ̀nà èyí tí [a ó] fi gba àwọn ìbùkún ìgbéga,” bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀ tí a kò nì ìdánilójú nípa wọn (M. Russell Ballard, “Ìrètí nínú Krístì,” Liahona, May 2021, 55).
Álmà àlùfáà gíga, nkọ́ni ní ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, ó tún ìfipè ìjìnlẹ̀ kan látẹnu Jésù Krístì sọ pé:
“Ẹ kíyèsĩ, ó rán ìfipè sí gbogbo ènìyàn, nítorípé ó na ọwọ́ ãnú rẹ̀ sí nwọn, òun sì wípé: Ẹ ronúpìwàdà, èmi yíò sì gbà yín.
“Bẹ̃ni, ó wípé: Ẹ wá sí ọ̀dọ̀ mi, ẹ̀yin yíò sì pín nínú èso igi ìyè nã” (Álmà 5:33–34).
Olùgbàlà Fúnrarẹ̀ pè wá láti wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ kí a sì gbé àjàgà Rẹ̀ lé orí wa kí a lè ní ìsinmi nínú ìrúkèrúdò aye (see Máttéù 11:28–29). A nwá sí ọ̀dọ̀ Krístì nípa “lílo ìgbàgbọ́ nínú [Rẹ̀], ríronúpìwàdà lójojúmọ́, dídá àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run bí a ti ngba àwọn ìlànà ìgbàlà àti ìgbéga, tí a sì nforítìí dé òpin nípa pípa àwọn májẹ̀mú wọnnì mọ́” (Ìwé-ìléwọ́ Gbogbogbò: Sísìn nínú Ìjọ Jésù Krístì ti a`wọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, 1.2.1, ChurchofJesusChrist.org). Ipá-ọ̀nà sí àṣepé ni ipá-ọ̀nà májẹ̀mú, àti pé Krístì ní gbùngbùn gbogbo àwọn ìlànà àti májẹ̀mú.
Ọba Benjamin kọ́ni pé nítorí àwọn májẹ̀mú tí a dá, a di ọmọlókùnrin àti ọmọlóbìnrin Krístì, ẹnití ó bí wa nínú ẹ̀mí, àti ní abẹ́ orí Rẹ̀ ni àwa di òmìnira, nítorí “kò sí orúkọ̀ míràn tí a fúnni nípasẹ̀ èyítí ìgbàla yíò wá” (wo Mòsíàh 5:7–8). A ó ní ìgbàlà bí a ṣe nforítìí dé òpin nípa, “títẹ̀lé àpẹrẹ Ọmọ Ọlọ́run alààyè” (2 Néfì 31:16). Néfì dámọ̀ràn pé kò tán síbẹ̀ lẹ́hìn tí a bá ti bọ́ sí ọ̀nà híhá àti tóóró yí; a gbọ́dọ̀ “tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìdúróṣinṣin nínú Krístì, kí ẹ ní ìrètí dídán, àti ìfẹ́ Ọlọ́run àti gbogbo ènìyàn” (wo 2 Néfì 31:19–20).
Ẹ̀kọ́ Krístì nrànwálọ́wọ́ láti wá kí a sì dúró ní ọ̀nà májẹ̀mú, ìhìnrere ni a sì tò kí a lè gbà àwọn ìbùkún ìlérí Olúwa nípasẹ̀ àwọn ìlànà àti májẹ̀mú mímọ́. Wòlíì Ọlọ́run, Ààrẹ Russell M. Nelson kìlọ̀ fún wa nínú ìgbóhùnká rẹ ní ọjọ̀ kẹrindinlogun, Oṣù Kínní, 2018, láti “tẹramọ́ ọ̀nà májẹ̀mú. Ìfarasìn yín láti tẹ̀lé Olùgbàlà nípa dídá májẹ̀mú pẹ̀lú Rẹ̀ àti pípa àwọn májẹ̀mú wọ̃nnì mọ́ yíò ṣí ilẹ̀kùn sí gbogbo ìbùkún ti ẹ̀mí àti ànfàní tí ó wà fùn àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin, àti àwọn ọmọdé níbigbogbo. … Òpin fún èyí tí ọ̀kọ̀ọ̀kan lára wa ntiraka ni láti gba ẹ̀bùn agbára nínú ilé Olúwa, so àwọn ẹbí pọ̀, jẹ́ olóòtọ́ sí àwọn májẹ̀mú tí a ṣe nínú tẹ́mpìlì tí ó mú wa yege fún ẹ̀bùn nlá ti Ọlọ́run—ti ìyè ayérayé” (“Bí A Ti Ntẹ̀síwájú Papọ̀,” Liahona, Apr. 2018, 7).
Ọlọ́run kò ní pa ìbáṣepọ̀ Rẹ̀ pèlú wa ti, tàbí dá ìlérí àwọn ìbùkún Rẹ̀ ti ìyè ayérayé dùrò kùrò lọ́dọ̀, olùpamọ́ májẹ̀mú òtítọ́ kankan. Bi a sì ṣe nbu-ọlá fún àwọn májẹ̀mú mímọ́, à nfá súnmọ́ ọ̀dọ̀ Olùgbàlà. Alàgbà David A. Bednar kọ́ni ní ànà pé àwọn májẹ̀mú àti ìlànà ìhìnrere nṣiṣẹ́ nínú ayé wa bíiti atọ́nà kan láti fún wa ní kókó ìdarí láti wá sí ọ̀dọ̀ Krístì àti láti dà bíi Tirẹ̀ si.
Àwọn májẹ̀mú sàmì sí ipá-ọ̀nà padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Àwọn ìlànà ìrìbọmi àti gbígba ẹ̀bùn ti Ẹ̀mí Mímọ́, ìyàsọ́tọ̀ oyèàlùfáà, àti oúnjẹ Olúwa ndarí wa lọ sí tẹ́mpìlì Olúwa láti ṣe àbápín àwọn ìlànà ìgbéga Rẹ̀.
Èmì yíò fẹ́ láti dárúkọ àwọn ohun méjì tí Olùgbàlà wa tẹnumọ́ láti rànwálọ́wọ́ láti pa àwọn májẹ̀mú wa mọ́ pẹ̀lú òdodo.
-
Ẹ̀mí Mímọ́ lè kọ́ wa, ránwa létí nípa àwọn ìkọ́ni Olùgbàlà, kí ó sì bá wa gbé títíláé (wo Jòhánnù 14:16, 26). Ó lè jẹ́ ẹnìkejì wa lemọ́lemọ́ láti tọ́wásọ́nà lórí ipá-ọ̀nà májẹ̀mú. Ààrẹ Russell M. Nelson kọ́ni pé “ní àwọn ọjọ́ tó nbọ̀, kò ní ṣeéṣè láti yege nípa ti ẹ̀mí láìsí títọ́ni, dídarí, títuni-nínú, àti ipá ti Ẹ̀mí Mímọ́ ní ìgbà gbogbo” (“Ìfihàn fún Ìjọ, Ìfihàn fún Ìgbé Aye Wa,” Liahona, May 2018, 96).
-
Olùgbàlà fi ìlànà oúnjẹ Olúwa lélẹ̀ kí a lè máa rántí Rẹ̀ kí a sì ní Ẹ̀mí Rẹ̀ pẹ̀lú wa nígbàgbogbo. Ìrìbọmi nṣí ọ̀nà sí ìyè Ayérayé, oúnjẹ Olúwà sì nrànwálọ́wọ́ láti tẹ̀síwajú pẹ̀lú ìdúróṣinṣin ní ipá-ọ̀nà májẹ̀mú. Bí a ti njẹ́ oúnjẹ Olúwa, yíò jẹ́ ẹ̀rí sí Bàbá pé à nrántí Ọmọ Rẹ̀ nígbàgbogbo. Bí a sì ti nrántí Rẹ̀ tí a sì npa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́, a ó ní Ẹ̀mí Rẹ̀ láti wà pẹ̀lú wa. Àfikún sí ìlérí yí, Olúwa ṣe àtunṣe ìlérí ìwẹ̀numọ́ ẹ̀ṣẹ̀ bí a ti nronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ wa pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀.
Ní dídúró lódodo sí àwọn májẹ̀mú wa, a níláti gbìyànjú láti ní Ẹ̀mí náà nígbàgbogbo láti múra wa sílẹ̀ láti jẹ oúnjẹ Olúwa ní yíyẹ, àti bákannáà, ki a sì jẹ́ oúnjẹ Olúwa déédé kí a lè ní Ẹ̀mí náà pẹ̀lú wa nígbàgbogbo.
Nígbàtí ọmọbìnrin wa jẹ́ ọdún marun, ó ní ọkọ̀ oní-bátirì kan ó sì fẹ́ràn láti yi káàkiri ilé. Ní ìrọ̀lẹ́ kan, ó wá sọ́dọ̀ mi ó wípé, “Baba, ọkọ̀ mi kò yí mọ́. Ṣe a lè gba epo díẹ̀ látinú ọkọ̀ rẹ si kì ò lè yíká lẹ́ẹ̀kansi? Bóyá ó nílò epò bíiti ọkọ̀ rẹ̀ láti yíká.”
Léhìnnáà mo ṣe àkíyèsí pé bátìrì náà tí tán, nítorínáà mo wípé èmi yíò mú u ṣiṣẹ́ ní bíi wákàtí kan. Pẹ̀lú inúdidùn gidi, ó wípé, “Bẹ́ẹ̀ni! A ó mu lọ sí ibùdó epo.” Mo kàn so bátìrì náà papọ̀ sí orísun iná láti fun-lágbára, lẹ́hìn wákàtí kan ó sì lè yí ọkọ̀ náà ká, pẹ̀lú okun nípasẹ̀ bátìrì tí ó ti lágbára. Lẹ́hìnnáà ó kẹkọ pé ó ṣe pàtàkì láti máa fún bátìrì náà lágbára nígbàgbogbo nípa síso ó mọ́ orísun iná.
Bí ọmọbìnrin mi ti kọ́ ìbáṣepọ̀ ní àárín bátìrì àti agbára láti yí ọkọ̀ ìṣeré rẹ̀, bẹ́ẹ̀ni à nkọ́ nípa Jésù Krístì, oúnjẹ Olúwa, àti Ẹ̀mí. A nílò Ẹ̀mí láti rànwálọ́wọ́ láti yíká nínú ayé-ikú bí a ti npa àwọn májẹ̀mú wa mọ́ lódodo, a sì nílò oúnjẹ́ Olúwa láti fún jíjẹ́ ti-èmí wa lókun. Títún májẹ̀mú ìrìbọmi wa ṣe àti jíjẹ́ oúnjẹ Olúwa ndarí ìṣòdodo sí gbogbo àwọn májẹ̀mú míràn. Ìparí aláyọ̀ ni ó dájú bí a ti nfi àdúrà ṣe àṣàrò tí a sì nbu-ọlá fún ìpè Olùgbàlà kí a sì gbádùn àwọn ìlérí ìbùkún Rẹ̀. Ó wípé, “Àti kí ìwọ ó lè pa ara rẹ mọ́ ní kíkún síi láìsí àbàwọ́n kúrò nínú ayé, ìwọ yíò lọ sí ilé àdúrà kí o sì rúbọ oúnjẹ Olúwa ní ọjọ́ mímọ́ mi” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 59:9).
Mo jẹ́ ẹ̀rí pé àwọn olùpamọ́ májẹ̀mú ni a ṣe ìlérí àláfíà fún ní ayé yí àti ìyè ayérayé ní ayé tó nbọ̀” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 59:23). Mo jẹ́ ẹ̀rí pé bí ẹ ti nṣe àbápín ara Olùgbàlà nípasẹ̀ oúnjẹ Olúwa, ẹ̀yin yíò ní Ẹ̀mí Rẹ̀ láti tọ́ yín sọ́nà ní ipa-ọ̀nà májẹ̀mú kí ẹ sì dúró lódodo sí àwọn májẹ̀mú yín. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.