Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ṣe Ohun Tó Ṣe Pàtàkì Jùlọ
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2022


10:46

Ṣe Ohun Tó Ṣe Pàtàkì Jùlọ

Bí a ṣe gbé ìgbésí ayé wa lé oókan Jésù Krístì, a ó di alábùkún pẹ̀lú okun ti-ẹ̀mí, ìtẹ́lọ́rùn, àti ayọ̀.

Ní àìpẹ́ sẹ́hìn, ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n kan ní ìtẹ̀mọ́ra láti bẹ obìnrin kan ní wọ́ọ̀dù rẹ̀ wò. O gbọn ìṣílétí náà nù nitori pe ko mọ ọ dáradára—ko mú ọgbọ́n wá rárá. Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí ọ̀rọ̀ náà ti nwá léraléra sọ́dọ̀ rẹ̀, ó pinnu láti gbé ìgbésẹ̀ lórí ìṣílétí náà. Nítorípé ó ti nní ìmọ̀lára àìbalẹ̀ ọkàn nípa ìbẹ̀wò tó nbọ̀ náà, ó pinnu pé gbígbé ohunkan lọ sọ́dọ̀ arábìnrin náà yíò ṣèrànwọ́ láti dín àníyàn rẹ̀ kù. Dájúdájú kò le lọ ní ọwọ́ òfo! Nítorínàà ó ra àpótí wàrà-dídì, àti pé ó lọ láti bẹ̀rẹ̀ ohun tí ó ní àníyàn pé ó lè jẹ́ ìbẹ̀wò wúruwùru.

Ó kan ilẹ̀kùn obìnrin náà, kò sì pẹ́ tí arábìnrin náà fi dáhùn. Ọ̀rẹ́ mi fi wàrà-dídì náà fún un nínú àpò ìwé rúṣúrúṣú kan, ìbáraẹnisọ̀rọ̀ naa sì bẹrẹ. Kò gba àsìkò pípẹ́ fún ọ̀rẹ́ mi láti mọ ìdí tí a fi nílò ìbẹ̀wò náà. Bí wọ́n ti jọ jókòó ní àbáwọlé iwájú, obìnrin náà ṣí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìpèníjà tí òun ndojúkọ. Lẹ́hìn wákàtí kan ti sisọrọ̀ ni ìyárí ojú ọjọ́ ìgbà-ẹ̀rùn náà, ọ̀rẹ́ mi ṣe àkíyèsí pé wàrà-dídì ti nyọ́ nínú àpò ìwé rúsúrúsú náà.

Ó kígbe pé, “Mo kaanu gan pé wàrà-dídì rẹ ti yọ́!”

Arábìnrin náà dáhùn pẹ̀lú ìdùnnú pé, “Ó dára! Èmi kò ní ìfaradà fún ohun dídùn!”

Nínú àlá kan, Olúwa sọ fún wòlíì Léhì pé, “Ìbùkún ni fún ìwọ Léhì, nítorí àwọn ohun tí ìwọ ti ṣe..”1

Jíjẹ́ ọmọẹ̀hìn Jésù Kristi ju kí a kàn níretí tàbí nígbàgbọ́ lọ. Ó pè fún akitiyan, ìgbésẹ̀, ati ìfaramọ́. Ó béèrè fún pé kí a ṣe ohun kan, ní jíjẹ́ “olùṣe ọ̀rọ̀ náà, kìí sìí ṣe olùgbọ́ nìkan.”2

Nínú ọ̀ràn ti wàrà-dídi tí ó yọ́, kíni ó ṣe pàtàkì jùlọ? Wàrà dídì náà? Tàbí pé ọ̀rẹ́ mi kàn ṣe ohunkan?

Mo ní ìrírí alárinrin pẹ̀lú ọ̀dọ́mọbìnrin olólùfẹ́ kan tí ó béèrè ìbéèrè àtinúwá gidi kan pé: “Arábìnrin Craven, báwo ni o ṣe mọ̀ pé ohunkóhun nípa Ìjọ jẹ́ òtítọ́? Nítorí Èmi kò nímọ̀lára kankan.”

Ṣáájú fífò sí ìdáhùn, mo kọ́kọ́ bèèrè àwọn ìbéèrè díẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀. “Sọ fún mi nípa àṣàrò ìwé-mímọ́ ti araẹni rẹ.”

Ó fèsì pé, “Èmi kìí ka àwọn ìwé mímọ́.”

Mo béèrè pé, “Báwo ni ẹbi rẹ pẹlu? Ṣé ẹ nṣe àṣàrò Wá, Tẹ̀lé Mi papọ̀?”

Ó sọ pé, “Rárá.”

Mo béèrè nípa àwọn àdúrà rẹ̀, “Ìmọ̀lára wo ni o nní nígbàtí o bá gbàdúrà?”

Ìdáhùn rẹ̀, “Èmi kìí gbàdúrà.”

Ìdáhùn mi sí I sì rọrùn, “Tí o bá fẹ́ mọ ohunkóhun, ìwọ yíò ní láti ṣe ohunkan.”

Njẹ́ èyí kìí ṣe òtítọ́ pẹ̀lú ohunkóhun tí a fẹ́ láti kọ́ tàbí mọ̀? Mo pe ọ̀rẹ́ mi titun láti bẹ̀rẹ̀ sí ṣíṣe ìhìnrere ti Jésù Krístì: gbígbàdúrà, ṣíṣe àṣàrò, sínsin àwọn ẹlòmíràn, àti níní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa. Ìyípadà kii wá nígbàtí a kò ṣe ohunkòhun. Ó nwá nípasẹ̀ agbára Ẹ̀mí Mímọ́ bí a ṣe nmọ̀ọ́mọ̀ tiraka láti mọ̀ nípa bíbéèrè, ṣíṣe àwárí, àti kíkanlẹ̀kùn. Ó nwá nípa ṣíṣe.3

Nínú Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú, Olúwa sọ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan pé, “Kò pọndandan.”4 Ó jẹ́ kí nronú pé tí àwọn ohun kan kò bá pọndandanì, tàbí dínkù ní pípọndandan, àwọn nkàn gbọ́dọ̀ wà tí ó pọndandan jùlọ. Nínú àwọn aápọn wa láti ṣe ohun kan tàbí ṣe ohunkóhun, a lè bi ara wa léèrè, “Kí ó ṣe pàtàkì jùlọ?”

Àwọn tó npolówó ọjà sábà máa nlo àwọn ọ̀rọ̀ àsọyé bíi “Pàtàkì” tàbí “Ó gbọ́dọ̀ ní” ní ìrètí mímú wa gbàgbọ́ pé ohun tí wọ́n ntà ṣe pàtàkì fún ìdúnnú tàbí wíwà ní àlàáfíà wa. Ṣugbọn njẹ́ ohun ti wọn nta ṣe pataki lóotọ́ ? Njẹ́ a gbọdọ̀ ní in lõtọ́ ? Ṣe ó pọndandan lóotọ́ ?

Níhín ni àwọn èrò-inú díẹ̀ kan láti yẹ̀wò. Ohun Tó Pọndandan Jùlọ?

  • Àwọn “fífẹ́ràn” mélo ni a gbà lórí àwọn ìfìwéránṣẹ́ àwùjọ wa? Tabi báwo ni Baba wa Ọ̀run ti fẹ́ràn tí Ó sì mọ iyì wa tó?

  • Wíwọ aṣọ titun nínú ìwọṣọ? Tàbí fífi ọ̀wọ̀ hàn fún arawa nípa wíwọ asọ ní ìwọ̀ntún-wọ̀nsì?

  • Wíwá àwọn ìdàhùn nípasẹ̀ wíwá inú íntánẹ́ẹ̀tì kàn? Tàbí gbígba àwọn ìdáhùn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́?

  • Ní fífẹ sii? Tàbí kí a ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ohun tí a fifún wa?

Ààrẹ Russell M. Nelson kọ́ni:

“Pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́ bí ojúgbà yín, ẹ lè rí tààràtà nípasẹ̀ ọ̀làjú olókìkí tí ó ti kọlu àwùjọ wa. O le jẹ́ jíjáfáfá ju bí àwọn ìran ìṣáájú ti wà tẹ́lẹ̀ rí. …

Gbé òdiwọ̀n kan kalẹ̀ fún ìyókù aráyé!”5

Ó gba aápọn láti dúró pẹ̀lú ìdojúkọ sórí ohun tó ṣe kókó lõtọ́ fún ayọ̀ pípẹ́ títí. Sátánì kì yíò fẹ́ràn ohunkóhun ju pé kí a ṣi àwọn iyì ayérayé wa lò lọ, ní dídarí wa sí pípàdánù àkokò iyebíye, àwọn ẹ̀bùn, tàbí okun ti ẹ̀mí lórí àwọn ohun tí kò pọndandan. Mo pe ẹnìkọ̀ọ̀kan wa láti fi tàdúràtàdúrà yẹ̀ àwọn ohun tó npín ọkàn wa níyà kúrò nínú ṣíṣe ohun tó pọndandan jùlọ wò.

Olùkọ́ kíláàsì ipele-kẹta ọmọ wa àgbà kọ́ kíláàsì rẹ̀ láti “jẹ́ ọ̀gá ọpọlọ wọn.” O jẹ ìrannileti kan fún àwọn ọ̀dọ́ akẹkọ rẹ pé wọ́n wà ní ìṣàkóso àwọn èrò wọn àti nítorínáà wọ́n lè ṣe àkóso ohun tí wọ́n nṣe. Mo rán ára mi létí láti “jẹ́ ọ̀gá ọpọlọ mi” nígbàtí mo ríi pé mò nsún lọ sí ìhà àwọn nkan tí kò fi bẹ́ẹ̀ pọndandan.

Akẹkọ ilé-ìwé gíga kan láìpẹ́ sọ fún mi láìpẹ́ pé ó ti wọ́pọ̀ láarín àwọn ọ̀dọ́ kan nínú Ìjọ láti ṣe àìkàsí àwọn òfin pẹ̀lú ètò ṣíṣirò láti ronúpíwàdà lẹ́hìnnáà. “Ó jẹ́ irú àmì ọlá kan,” ni a sọ fún mi. Dájúdájú Olúwa yíò máa tẹ̀síwájú láti dáríji àwọn tí wọ́n fi ìrẹ̀lẹ̀ ronúpìwàdà “pẹ̀lú èrò inú tòótọ́.”6 Ṣùgbọ́n Ètùtù Olùgbàlà tó kún fún àánú kò gbọdọ̀ jẹ́ lílò láé ní irú ọ̀nà ẹ̀gàn bẹ́ẹ̀. A mọ òwe àgùntàn kan tí ó sọnù. Dájúdájú, olùṣọ́ àgùntàn yíò fi àgùntàn mọ́kàndínlọ́gọ́rùn yìókù sílẹ̀ láti wá èyítí ó ti ṣáko lọ. Ṣùgbọ́n njẹ́ o lè fojú inú wo ayọ̀ tí àwọn tí ó yàn láti jẹ́ mọ́kàndínlọ́gọ́run mú wá fún Olùṣọ́ Àgùntàn Rere náà? Àwọn tí wọ́n dúró papọ̀ tí wọ́n sì ran ara wọn lọ́wọ́ láti gbé ìgbé-ayé àwọn májẹ̀mú wọn? Ǹjẹ́ ẹ lè fojú inú ya àwòrán ohun tí ayé, tàbí ilé ẹ̀kọ́ rẹ, tàbí iṣẹ́ rẹ, tàbí ilé rẹ yíò ti rí tó bá jẹ́ pé ìgbọràn ni ohun tó wọ́pọ̀ láti ṣe? Kìí ṣe nípa ṣíṣe ìgbésí-ayé ní pípé—ó jẹ́ nípa wíwá ayọ̀ nígbàtí à nsa ipá wa dídárajùlọ láti gbé ìgbé-ayé àwọn májẹ̀mú tí a ti ṣe pẹ̀lú Olúwa.

Pẹ̀lú bí àgbáyé tí nṣe àfihàn iyèméjì díẹ̀ síi nípa Ọlọ́run, àti tí ìdàrúdàpọ̀ ati àwọn pákánleke npọ̀ síi, àsìkò yíi ni a gbọ́dọ̀ súnmọ́ wòlíì náà jù lọ. Gẹ́gẹ́ bí agbẹnusọ Olúwa, a lè ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé ohun tí ó nrọ̀ wá, ngbani nímọ̀ràn, ó sì nbẹ̀ wá láti ṣe àwọn ohun tí ó pọndandanì jùlọ.

Bótilẹ̀jẹ́ pé ó lè má rọrùn, ọ̀nà kan máa nwà nígbà gbogbo láti ṣe ohun tó tọ́. Nígbàtí wọ́n nbá ẹgbẹ́ àwọn ọ̀rẹ́ kan sọ̀rọ̀ ní ilé-ìwé, ọkàn ọ̀dọ́mọbìnrin kan lọ sílẹ̀ nígbàtí ìjíròrò náà yà sí ṣíṣe àtakò àwọn odiwọ̀n ti Ìjọ. Ó sì rí i pé òun kò lè dákẹ́ mọ́—ó ní láti ṣe ohun kan. Pẹ̀lú ọ̀wọ̀, ó sọ̀rọ̀ nípa ìfẹ́ Baba Ọ̀run àti bí àwọn òfin tí Ó fi lélẹ̀ ṣe jẹ́ láti bùkún àti dáàbòbo àwọn ọmọ Rẹ̀. Ìbá ti rọrùn púpọ̀ fún un láti máṣe ohunkóhun. Ṣùgbọ̀n kíni ohun tó pọndandan jùlọ? Ní pípapọ̀ pẹ̀lú ogunlọ́gọ̀ náà? Tàbí dídúró jáde bí ẹlẹri kan ti Ọlọ́run ní “gbogbo ìgbà àti nínú ohun gbogbo àti níbi gbogbo”?7

Bí Ìjọ Jésù Krístì tí a múpadàbọ̀sípò yíò bá jáde kúrò nínú òkùnkùn, a gbọ́dọ̀ jáde kúrò nínú òkùnkùn. Gẹ́gẹ́bí àwọn obìnrin tí npa májẹ̀mú mọ́, a gbọ́dọ̀ tan ìmọ́lẹ̀ ihinrere wa káàkiri àgbáyé nípa gbígbéra sókè àti dídúró yàtọ̀. A nṣe èyí papọ̀ bí ọmọbìnrin Ọlọ́run—agbára kan tí ó jẹ́ mílíọ̀nù mẹ́jọ ólé méjì àwọn obìnrin ẹni ọjọ́ orí ọdún mọ́kànlá àti jù bẹ́ẹ̀ lọ, tí iṣẹ́ wọn jẹ́ bákannáà gẹ́gẹ́. A nkó Ísráẹ́lì jọ bí a ṣe nkópa nínú iṣẹ́ ìgbàlà àti ìgbéga: ní ìlàkàkà láti gbé ìgbé-ayé ìhìnrere Jésù Krístì, ntọ́jú àwọn ẹlòmíràn tí wọ́n wà nínú àìní, npe gbogbo ènìyàn láti gba ihinrere, àti bí ti ìṣọ̀kan àwọn ẹbí títí ayérayé.8 Ìhìnrere Jésu Krístì tí a múpadàbọ̀sípò jé ìhìnrere ti ìṣe àti ìhìnrere ti ayọ̀! Ẹ máṣe jẹ́kí a ro ara wa pin nínú ipa wa láti ṣe àwọn ohun wọ̀nnì tó pọndandan. Ogún àtọ̀runwá wa fún wa ní ìgboyà àti ìgbẹ́kẹ̀lé láti ṣe àti láti jẹ́ gbogbo ohun tí olùfẹ́ni Baba wa Ọ̀run mọ̀ pé a lè jẹ́.

Àkòrí ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀dọ́ fún ọdún yìí wá láti inú Òwe 3:5–6:

“Fi gbogbo àyà rẹ gbẹ́kẹ̀lé Olúwa; másì ṣe tẹ̀ sí ìmọ̀ ara rẹ.

“Mọ̀ọ́ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun ó sì máa tọ ipa-ọ̀nà rẹ.”

Kókó ẹ̀yà kan ti níní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa ni gbígbé ìgbésẹ̀ síwájú, ní gbígbàgbọ́ pé Òun yíò ṣe amọ̀nà wa paapaa nígbàtí a kò ní gbogbo àwọn ìdáhùn.

Ẹ̀yin Arábìnrin, kíí ṣe nípa wàrà-dídì. Àti pe kìí ṣe nípa ṣíṣe díẹ̀ síi. Ó jẹ́ nípa ṣíṣe ohun tó pọndandan. Ó jẹ́ síṣe àmúlò ẹ̀kọ́ Kristi nínú àwọn ìgbésí-ayé wa bí a ṣe nlàkàkà láti dàbí Rẹ̀ síi.

Bí a ti nṣe díẹ̀ síi láti dúró ṣinṣin lórí ipa ọ̀nà májẹ̀mú, bẹ́ẹ̀ ni ìgbàgbọ́ wa yíò maa dagba si. Bí ìgbàgbọ́ wa bá ṣe ndàgbà sí, bẹ́ẹ̀ ni a ó máa ní ìfẹ́ inú láti ronúpìwàdà. Bí a bá sì ṣe nronúpìwàdà sí, bẹ́ẹ̀ a ó ṣe mú kí ìbáṣepọ̀ májẹ̀mú wa pẹ̀lú Ọlọ́run ní okun si. Ìbáṣepọ̀ májẹ̀mú náà nfà wá lọ sí tẹ́mpìlì nítorípé pípa àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì mọ́ ni bí a ṣe nní ìfaradà dé òpin.

Bí a ṣe ngbé ìgbésí ayé wa lé Jésù Kristi, a ó tọ́ wa sọ́nà láti ṣe ohun tó pọndandan jùlọ. A ó sì bùkún wa pẹ̀lú okun ti-ẹ̀mí, ìtẹ́lọ́rùn, àti ayọ̀ Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. 1 Néfì 2:1àfikún àtẹnumọ́.

  2. Jákọ́bù 1:22

  3. Wo Alma 5:45–46; Russell M. Nelson, “Fífa Agbára Krístì Sínú Ayé Wa,” Liahona, May 2017, 39–42.

  4. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 45:26; 88:91

  5. Russell M. Nelson, “Hope of Israelworldwide youth devotional, June 3, 2018), HopeofIsrael.ChurchofJesusChrist.org.

  6. Mórónì 6:5

  7. Mòsíàh 18:9; wo pẹ̀lú “Àkòrí Àwọn Ọ̀dọ́mọbìrin,” ChurchofJesusChrist.org.

  8. Wo Ìwé-ìléwọ́ Gbogbogbò: Sísìn nínú Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn1.2ChurchofJesusChrist.org.