Îbínú Àìṣòdodo
Jésù Krístì ní òye àìdára àti agbára láti pèsè àtúnṣe bákannáà.
Ní 1994, ìpaẹ̀yàrun kan ṣẹlẹ̀ ní ìlà-oòrùn oriílẹ̀-èdè Áfríkà ti Rwanda tí ó jẹ́ apákan nítorí ìfíngun ẹlẹ́yà-mẹ̀yà ọjọ́ pípẹ́. Ìṣirò ni pé ju ìlàjì míllíọ̀nù ni wọ́n pa.1 Pẹ̀lú ìyanu, àwọn ènìyàn Rwandan ní àpákan títóbi làjà,2 ṣùgbọ̀n àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí tẹ̀síwájú láti dún padà.
Ní ọdún mẹ́wa sẹ́hìn, nígbà ìbẹ̀wò sí Rwanda, ìyàwó mi àti èmi bẹ̀rẹ̀ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ pẹ̀lú èrò ọkọ̀ míràn ní pápá ọkọ̀ òfúrufú Kígálì. Ó pohùnréré àìṣòdodo ti ìpaẹ̀yàrun ó sì fi àánú bèèrè, “Bí Ọlọ́run bá wà, ṣé Òun kò ti ní ṣe ohunkan nípa rẹ̀?” Fún ọkùnrin yí—àti fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ lára wa—ìjìyà àti àìdára lè dàbí àìbàrámu pẹ̀lú àrídájú ti onínúrere, olùfẹ́ni Baba Ọ̀run. Síbẹ̀ Ó jẹ́ òdodo, Ó ní inúrere, àti pé Ó nifẹ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ Rẹ ní pípé. Ìyàtọ̀ èyí jẹ́ pípẹ́ bíiti gbogbo ènìyàn a kò sì lè ṣe àlàyé rẹ̀ nínú ìro-díẹ̀ jẹ́jẹ́ tàbí àlẹ̀mọ́ bọ́mpà kan.
Láti bẹ̀rẹ láti mú ọgbọ́n wá nípa rẹ̀, ẹ jẹ́ kí a yẹ gbogbo onírurú ẹ̀yà ti àìdára wò. Ẹ ronú ẹbí kan nínú èyí tí ọmọ kọ̀ọ̀kan gba owó ìtọ́jú ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ fún ṣíṣe àwọn iṣẹ́ ilé tó wọ́pọ̀. Ọmọkùnrin kan, Jòhánù, ra cándy; ọ̀kan ọmọbìnrin, Anná, fi owó rẹ̀ pamọ́. Ní ìgbẹ̀hìn, Anna ra kẹ̀kẹ́ kan fún ararẹ̀. Jòhánù ro pé kò dára rárá pé Anná ní kẹ̀kẹ́ nígbàtí òun kò ní. Ṣùgbọ́n àwọn àṣàyàn Jòhánù ní ó dá àìdọ́gba sílẹ̀, kìí ṣe àwọn ìṣe òbí. Ìpinnu ti Anná láti fojúfo ìgbádùn lọ́wọ́lọ́wọ́ ti jíjẹ candy kò fi àìdára kankan sí orí Jòhánù, nítorí òun ti ní irú ànfàní biiti arábìnrin rẹ̀.
Àwọn ìpinnu wa bákannáà lè mú àwọn ànfàní pípẹ́ tàbí àìní-ànfàní wá. Bí Olúwa ti fihàn, “Bí ẹnikan bá sì jèrè ìmọ̀ àti òye púpọ̀ nínú ayé yí nípasẹ̀ aápọn àti ìgbọràn rẹ̀ ju ẹlòmíràn, òun ó ní ànfàní náà ní ayé tí ó nbọ̀.”3 Nígbàtí àwọn ẹlòmíràn bá gba èrè nítorí aápọn yíyàn wọn, a kò lè parí rẹ̀ ní òtítọ́ pé a ti ṣe àìṣòdodo nígbàtí a ti ní irú ànfàní bẹ́ẹ̀.
Àpẹrẹ míràn ti àìdára wá látinú ipò kan tí ìyàwó mi, Ruth, bá pàdé bí ọmọdé. Ní ọjọ́ kan Ruth kọ́ pé ìyá rẹ̀ nmú arábìnrin rẹ̀ kékeré, Merla, láti lọ ra bàtà titun. Ruth ṣàròyé pé, “Ìyá, kò dára rárá! Merla gba bàtà titun tó kẹ́hìn .”
Ìyá Ruth bèèrè , “Ruth, ṣe bàtà rẹ ba ọ mu?”
Ruth Fèsì, “Ódára, bẹ́ẹ̀ni.”
Nígbànáà ìyá Ruth wípé, “Bàtà Merla ko bamu mọ́”
Ruth faramọ pé ọmọ kọ̀ọ̀kàn nínú ẹbí níláti ní àwọn bàtà tó bá wọn mu. Bíótilẹ̀jẹ́pé Ruth yíò fẹ́ láti ní àwọn bàtà titun, ìrò rẹ̀ nípa ṣíṣe àìdára si kúrò nígbàtí ó rí àwọn ipò nípa ìwo ìyá rẹ̀.
Díẹ̀ nínú àìdára kò ṣe ṣe àlàyé; àìdára tí kò ṣeé ṣe àlàyé jẹ́ ìbínú. Ìwà àìṣòdodo wá láti inú gbigbè pẹ̀lú àwọn ara tí kò pé, ti o farapa, tàbí ṣe àìsàn. Ìgbé ayé ikú jẹ́ àbímọ́ àìdára. A bí àwọn ènìyàn kan pẹ̀lú ọlá; àwọn míràn kò rí bẹ́ẹ̀. Àwọn kan ní òbí olùfẹ́ni, àwọn míràn kò ní. Àwọn kan gbé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún láyé, àwọn míràn, gbé díẹ̀. Àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn olúkúlùkù nṣe àṣìṣe pípanilára àní nígbàtí wọ́n ntiraka láti ṣe rere. Àwọn kan kò yàn láti mú àìdára kúrò nígbàtí wọ́n lè ṣe. Nínú ìrẹ̀wẹ̀sì, olúkúlùkù nlo agbára tí Ọlọ́run fún wọn láti pa àwọn ẹlòmíràn lára nígbàtí kò yẹ kí wọn ṣe bẹ́ẹ̀ rárá.
Àwọn onírurú ìyàtọ̀ àìdára lè dàpọ̀, láti ṣẹ̀dá ìjì líle àìdára nla. Fún àpẹrẹ, àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19 lápapọ̀ ní ipá lórí àwọn ẹni tí wọ́n jẹ́ kókó ohun ìṣẹ̀lẹ̀ tẹ́lẹ̀, àwọn àìní-ànfàní abẹ́lẹ̀. Mo ní ìrora ọkàn fún àwọn ẹni tí wọ́n dojúkọ irú àìdára náà, ṣùgbọ́n mo kéde pẹ̀lú gbogbo ìrora ọkàn pé Jésù Krístì ní ìmọ̀ àìṣòdodo tí ó sì ní agbára láti pèsè àtúnṣe bákannáà. Kò sí ohun tí a lè fi wé àìdára tí Ó faradà. Kò dára pé kí Òun ní gbogbo ìrírí àwọn ìrora àti ìpọ́njú ti ẹ̀dá ènìyàn. Ko dára pé kí Òun jìyà fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àti àṣìṣe mi àti fún ẹ̀yin. Ṣùgbọ́n Ó yàn láti ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí ti ifẹ́ Rẹ̀ fún wa àti fún Baba Ọ̀run. Ó ní òye ohun tí a nní ìrírí rẹ̀ ní pípé.4
Ìwé mímọ́ ṣe àkọsílẹ̀ pé àwọn ará Ísráẹ́lì àtijọ́ ráùn pé Ọlọ́run ko tọ́jú wọ́n dáadáá. Ní ìfèsì, Jèhófà bèèrè, “Obìnrin ha lè gbàgbé ọmọ ọmú rẹ̀ bí, tí kì yíò fi ṣe ìyọ́nú sí ọmọ inú rẹ̀?” Bí o ti le ṣe aláìríbẹ́ẹ̀ tó pé ìyá olùfẹ́ni kan yíò gbàgbé ọmọ ọwọ́ rẹ̀, Jèhófà kéde pé àní ìfọkànsìn Rẹ̀ jẹ́ dídúróṣinṣin si. Ó tẹnumọ pé: “Bẹ́ẹ̀ni, wọ́n lè gbàgbé, ṣùgbọ́n èmi kì yíò gbàgbé rẹ̀. … Kíyèsĩ i, èmi ti kọ ọ́ sí àtẹ́lẹwọ́ mi; àwọn odi rẹ ńbe títílọ níwájú mi.”5 Nítorí Jésù Krístì farada ìrúbọ ètùtù àìlópin, Ó nṣe ìyọ́nú ní pípé pẹ̀lú wa.6 Ó nfi ìgbàgbogbo ní ìfura nípa wa àti àwọn ipò wa.
Nínú ayé ikú, a lè “wá pẹ̀lú ìgboyà” sí ọ̀dọ̀ Olùgbàlà ki a sì gba àánú, ìwòsàn, àti ìrànlọ́wọ́.7 Àní nígbàtí a bá jìyà àìlèṣe-àlàyé, Ọlọ́run lè bùkún wa ní àwọn ọ̀nà jẹ́jẹ́, lásán, àti alámì. Bí a ti kọ́ láti dá àwọn ìbùkún wọ̀nyí mọ̀, ìgbẹ́kẹ̀lé wa nínú Ọlọ́run yíò pọ̀ si. Nínú àwọn ayérayé, Bàbá Ọ̀run àti Jésù Krístì yíò tún gbogbo àìdára ṣe. Níní òye a fẹ́ mọ̀, báwo àti nígbàwo. Báwo ni Wọn ó ti ṣe yẹn? Ìgbàwo ni Wọn ó ṣe é? Ní ìmọ̀ mi, Wọn kò tíì fihàn báwo tàbí ìgbàtí.8 Ohun tí mo mọ̀ ni pé Wọn ó ṣe.
Nínu àwọn ipò àìdára, ọ̀kan lára àwọn iṣẹ́ wa ni láti nígbẹ́kẹ̀lé pé “gbogbo èyí tí ko dára nípa ìgbé ayé ni a lè ṣé dáradára nípasẹ̀ Ètùtù Jésù Krístì.”9 Jésù Krístì borí ayé Ó sì “gba gbogbo àìdára mọ́ra”. Nítorí Rẹ̀, a lè ní àláfíà nínú ayé yí kí a sì tújúká.10 Bí a bá jẹ́ kí Ó Ṣee, Jésù Krístì yíò ya àìdára sọ́tọ̀ fún èrè wa.11 Òun ko ní tùwánínú kí Ó mú ohun tí a ti sọnù padàbọ̀sípò lásán;12 Òun yíò lo àìdára náà fún ànfàní wa. Nígbàtí ó bá di báwo àti nígbàwo, a nílò láti dámọ̀ kí a sì tẹ́wọ́gbàá, bi Álmà ti ṣe, “kò já mọ́ nkankan; nítorípé Ọlọ́run mọ àwọn ohun wọ̀nyí gbogbo; ó sì tọ́ fún mi láti mọ̀ pé ohun tí yíò ṣẹlẹ̀ ni èyí.”13
A lè gbìyànjú láti di ìbèèrè wa mú nípa báwo àti nígbàwo fún ìgbà-tóbáyá àti ìdojúkọ lórí gbígbèrú ìgbágbọ́ nínú Jésù Krístì, pé Òun ní agbára láti mú ohun gbogbo tọ́ ó sì nyára láti ṣe bẹ́ẹ̀.14 Fún wa láti tẹnumọ mímọ báwo tàbí nígbàwo kò ní àbájáde àti, lẹ́hìn gbogbo rẹ̀, ó jẹ́ inú-kan.15
Bí a ti nmú ìgbàgbọ́ wa nínú Jésù gbèrú si, bákannáà a níláti tiraka láti dà bíi Rẹ̀. Nígbànáà kí a dé ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú àánú kí a sì gbìyànjú láti mú àìdára kúrò níbití a ti ri;16 a lè gbìyànjú láti mú àwọn ohun tọ́ ní àárín àyíká agbára wa. Nítòótọ́, Olùgbàlà darí wa pé “kí a fi taratara ṣiṣẹ́ nínú èrò rere, kí a ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun fún ìfẹ́ ara [wa] , kí a mú òdodo púpọ́ wá sí ìmúṣẹ.”17
Ẹnìkan ti ó fi taratara ṣiṣẹ́ ní bíba àìdára jà ni Agbẹjọ́rò Bryan Stevenson. Ìṣe ti òfin rẹ̀ ní United States ni a ya sọ́tọ́ fún dídáààbò bo àwọn tí a pè lẹ́jọ́ ní àìtọ́, fífi òpin sí ìjiyà púpọ̀jù, àti dídáààbò bo ẹ̀tọ̀ ènìyàn ní pàtó. Ọdún díẹ̀ sẹ́hìn, Arákùnrin Stevenson dáààbò bo ọkùnrin kan ẹnití wọ́n ti fẹ̀sùn ìpànìyàn kan láìtọ́ tí wọ́n sì dá lẹ̀bi ikú. Arákùnrin Stevenson bèèrè àtìlẹhìn lọ́wọ́ ìjọ krístẹ́ni ìbílẹ̀ ọkùnrin náà, àní bíotilẹ̀jẹ́pé ọkùnrin náà ko wá déédé sí ìjọ rẹ̀ tí wọ̀n sì ti paátì nínú ìletò nítorí mímọ ìwa àgbèrè rẹ̀ káàkiri.
Láti dojúkọ gbogbo ìjọ lórí ohun tí ó ṣe kókó, Arákùnrin Stevenson bá wọn sọ̀rọ̀ nípa àkọsílẹ̀ bíbélì nípa obìnrin tí a fẹ̀sùn àgbèrè kan ẹnití a mú wá sọ́dọ̀ Jésù. Àwọn olùfisùn fẹ́ láti sọ ọ́ ni òkúta pa, ṣùgbọ́n Jésù wípé, “Ẹnikẹ́ni tí kò bá ní ẹṣẹ̀ ní áárín yín, ẹ jẹ́ kí ó kọ́kọ́ sọ òkúta lùú.”18 Àwọn olùfisun obìnrin náà kúrò. Jésù kò dá obìnrin náà lẹ́bi ṣùgbọ́n ó bawí láti máṣe dẹ́ṣẹ̀ mọ́.19
Lẹ́hìn títùn ìtàn yí sọ, Arákùnrin Stevenson ṣe àkíyèsí pé òdodo-araẹni, ẹ̀rù, àti ìbínú ti mú kí àwọn krístẹ́nì ju òkúta sí àwọn ènìyàn tí wọ́n tasẹàgèrè. Nígbànáà ó wípé “A kò lè wo ìyẹn tí ó nṣẹlẹ̀ jẹ́jẹ́,” ó sì gbà àwọn ìjọ ní ìyànjú láti di “àwọn olùdìmú òkúta.”20 Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, ki a máṣe ju òkúta ni ìgbẹ́sẹ̀ àkọ́kọ́ ní títọ́jú àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú àánú. Ìgbésẹ̀ kejì ni láti tiraka láti mú òkúta tí àwọn ẹlòmíràn jù.
Bí a ti nlò pẹ̀lú àwọn ànfàní àti àìní-ànfàní jẹ́ apákan àdánwò ayé. A ó gba ìdájọ́ kìí ṣe púpọ̀ nìpa ohun tí a sọ ṣùgbọ́n bí a ṣe tọ́jú awọn olùpalára àti aláìni-ànfàní.21 Gẹ́gẹ́bí àwọn Ènìyàn Mimọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, à nwá láti tẹ̀lé àpẹrẹ Olùgbàlà, láti lọ nìpa ṣíṣe rere.22 A nfi ìfẹ́ wa hàn fún aladugbo wa nípa ṣíṣe iṣẹ́ láti mu iyì gbogbo àwọn ọmọ Baba Ọ̀run dájú.
Pẹ̀lú àwọn ànfàní ti ara wa àwọn aláìlánfàní wa lọ́kàn, ríronú jẹ́ ìlera. Fún Jòhánù láti ní ìmọ̀ ìdí tí Anná fi ní Kẹ̀kẹ́ jẹ́ olùfihàn. Fún Ruth láti wo ìnílò Merla fún àwọn bàtà nípasẹ̀ ìwò ìyá rẹ̀ lanilọ́yẹ̀. Láti gbìyànjú láti rí àwọn ohun pẹ̀lú ìwò ayérayé lè jẹ́ yíyẹ̀wò. Bi a ti ndà biiti Olùgbàlà si, a ngbèrú si ní ìyọ́nú, níní ìmọ̀, àti ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́.
Mo padà sí ìbèèrè tí èrò-ọkọ̀ ẹlẹgbẹ́ wa gbé wá ní Kigali tí ó ràùn àìdára ti ìpaẹ̀yàrun Rwanda ó sì bèèrè, “Bí Ọlọ́run kan bá wá, ṣé Òun ìbá má ti ṣe ohun kan nípa rẹ̀?”
Láì ke ìjìyà tí ìpaẹ̀yàrun náà fa kúrú, àti lẹ́hìn jíjẹ́wọ́ àìní agbára wa láti ní òye irú ìjìyà bẹ́ẹ̀, a fèsì pé Jésù Krístì ti ṣe ohunkan nípa ìmúbínú àìdára.23 A ṣe àlàyé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀kọ́ ìhìnrere nípa Jésù Krístì àti Ìmúpadàbọ̀sípò Ìjọ Rẹ̀.24
Lẹ́hìnnáà, olùbárìn wa bèèrè, pẹ̀lú omijé ní ojú rẹ̀, “O túmọ̀ sí pé ó ní ohun tí mo lè ṣe fún àwọn òbí mi àti ẹ̀gbọ́n tó ti kú?”
A wípé, “Aà bẹ́ẹ̀ni!” Lẹ́hìnnáà a jẹ́ ẹ̀rí pé gbogbo ohun tí kò dára nípa ìgbé ayé ni ó lè di dídára nípasẹ̀ Ètùtù Jésù Krístì àti pé nípa àṣẹ Rẹ̀ àwọn ẹbí lè dara papọ̀ títíláé.
Nígbàtí a bá ní ìdojúkọ àìdára, a le ti arawa kúrò ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run tàbí a lè yí síwájú Rẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ àti àtilẹhìn. Fún àpẹrẹ, Mọ́mọ́nì ṣe àkọsìlẹ̀ pé ogun gígùn ní àárín àwọn ara Néfì àti ará Lámánì pa àwọn ènìyàn lára lọ́tọ̀ọ̀tọ̀. Mọ́mọ́nì ṣe àkíyèsí pé “ọkàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti le” àti pé àwọn ẹlòmíràn “rọ̀ nítorí ti àwọn ìpọ́njú wọn, dé bi pé wọ́n rẹ arawọn sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run.”25
Ẹ máṣe jẹ́ kí àìdára mú yín lọ́kan le tàbí bo ìgbàgbọ́ yín nínú Ọlọ́run mọ́lẹ̀. Dípò bẹ́ẹ̀, ẹ bèèrè fún ìrànlọ́wọ́. Ẹ mú ìmoore yín fún àtì ìgbẹ́kẹ̀lé lórí Olùgbàlà pọ̀si. Sànju dídà oníkorò, ẹ jẹ́ kí Ó ràn yín lọ́wọ́ láti dára si.26 Ẹ fi ààyè gbà Á láti ràn yín lọ́wọ́ láti ní àmúmọ́ra, láti jẹ́ kí “ayọ̀ ti Krísti gbé àwọn ìpọ́njú yín mi.”27 Darapọ̀ mọ Ọ nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀ “láti wo oníròbìnújẹ́ ọkàn sàn,”28 tiraka láti ṣe ìdádúró àìdára, àti láti di olùdìmú òkútà.29
Mo jẹ́ ẹ̀rí pé Olùgbàlà wà láàyè. Ó ní òye àìdára. Àwọn àmì ní àtẹ́lẹwọ́ ti ọwọ́ Rẹ̀ ntẹ̀síwájú láti rán An létí nípa yín àti áwọn ipò yín. Ó nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí yín ní gbogbo ìdàmú yín. Fún àwọn ẹni tí ó wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀, adé ti ẹ̀wà kan ni yíò rọ́pò eérú ọ̀fọ̀; ayọ̀ àti ìdùnnú yíò rọ́pò ìbànújẹ́ àti ìkorò; ìmọyì àti àjọyọ̀ yíò rọ́pò ìrẹ̀wẹ̀sì àti àìnírètí.30 Ìgbàgbọ́ yín nínú Bàbá Ọ̀run àti Jésù Krístì yíò gba èrè ju bí ẹ ti lérò lọ. Gbogbo àìdára—ní pàtàkì ìbínú àìṣòdodo—yíò di ìyàsímímọ́ fún èrè yín. Mo jẹ́ ẹ̀rí bẹ́ẹ̀ ní orúkọ ti Jésù Krístì, àmín.