Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ìmọ́lẹ̀ Ìhìnrere ti Òtítọ́ àti Ìfẹ́
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2021


Ìmọ́lẹ̀ Ìhìnrere ti Òtítọ́ àti Ìfẹ́

Mo jẹri pé ìmọ́lẹ̀ ìhìnrere ti òtítọ́ àti ìfẹ́ ntàn ìmọ́lẹ̀ ní dídán jákèjádò ilẹ̀ ayé loni.

Orin alárinrin Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn “Fetísílẹ̀, Gbogbo Ẹ̀yin Orílẹ̀ Èdè!” láìṣe àṣìṣe kó gbogbo ìtara àti ìgbádùn ti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere tí o nlọ sí gbogbo ayé jọ. Nínú orin yi a kọ:

Fetísílẹ̀, Gbogbo Ẹ̀yin Orílẹ̀ Èdè! Gbọ́ ohùn ọ̀run

La gbogbo ilẹ̀ já kí gbogbo ènìyàn lè yọ̀!

Ẹyin Ángẹ́lì ògo ẹ kígbe ègbè orin:

A mú òtítọ́ padàbọ̀sípò lẹ́kàn si!1

Louis F. Mönch, olùkọ ọ̀rọ̀ ayọ̀ yí, jẹ ará Germani tí a yí padà ẹnití o kọ àwọn ọ̀rọ̀ ìmísí fún orin náà nígbà ti ó ngbé ní Switzerland ní àkokò iṣẹ́-ìsìn ìránṣẹ́ ìhìnrere kíkún rẹ̀ ní Europe.2 Ayọ̀ tí o nwáyé láti inú jíjẹ́ri ipa ti Ìmúpadàbọ̀sípò náà di sísọ kedere nínú àwọn ọ̀rọ̀ orin wọ̀nyí:

Ní ìwákiri nínu òkùnkùn, àwọn orílẹ̀-èdè ti sọkùn;

Ní ṣíṣọ́nà fún òwúrọ̀, wọ́n ti ṣe ìṣọ́ òru wọn.

Gbogbo wọn nyọ̀ nísisìyí; òru gígùn ti tán.

Òtítọ́ wà nílẹ̀-ayé lẹ́ẹ̀kan síi!3

Ọpẹ́ fún bíbẹ̀rẹ̀ Ìmúpadàbọ̀sípò tí o nlọ lọ́wọ́ tí ó lé díẹ̀ ní igba ọdún sẹ́hìn, “ìmọ́lẹ̀ ìhìnrere náà ti òtítọ́ àti ìfẹ́”4 ntàn nísisìyí jákéjádò ilẹ̀ ayé. Wòlíì Joseph kẹ́kọ̀ọ́ ní 1820, àwọn ẹgbẹgbẹ̀rún síi ni wọ́n sì ti kẹ́kọ̀ọ́ láti ìgbà náà, pé Ọlọ́run “nfifún gbogbo ènìyàn lọ́pọ̀lọpọ̀, tí kìí sì bániwí.”5

Ní kété lẹ́hìn ìṣètò ti Ìjọ ní ìgbà ìkẹhìn yi, Olúwa bá Joseph Smith sọ̀rọ̀ ó sì fi ìfẹ́ púpọ̀ Rẹ fún wa hàn nígbà ti o wípé:

“Nítorínáà, Èmi Olúwa, ní mímọ àwọn ewu tí yíò wá sí órí àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé, ké pe ìránṣẹ́ mi Joseph Smith Kékeré, mo sì sọ̀rọ̀ sí i láti ọ̀run, mo sì fún un ní àwọn òfin; …

“Kí májẹ̀mú mi ti ayérayé lè fi ẹsẹ̀ múlẹ̀;

“Kí a lè kéde ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere mi láti ẹnu aláìlágbára àti òpè sí àwọn òpin ayé.”6

Láìpẹ́ lẹ́hìn tí a gba ìfíhàn yí, a bẹ̀rẹ̀ síí pe àwọn ìránṣẹ ìhìnrere a sì nrán wọn lọ sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè ayé. Gẹ́gẹ́ bí wòlíì Néfì ṣe fojúsọ́nà, ọ̀rọ̀ ìhinrere tí a múpadàbọ̀sípò bẹ̀rẹ̀ síí di wíwàásù “ní ààrin àwọn orílẹ̀-èdè, àwọn ìbátan, ahọ́n, àti àwọn ènìyàn.”7

“Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-Ìkẹhìn di dídásílẹ̀ ní ilé pákó kékeré kan ní ìhà àríwá New York ní ọdún 1830.

Ó gba ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́fà—títí di ọdún 1947—kí ìjọ náà to dàgbà láti ọmọ ìjọ mẹ́fà ní ìbẹ̀rẹ̀ sí mílíọ̀nù kan. Àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere jẹ́ ẹ̀yà Ìjọ láti ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọjọ́ rẹ̀, tí ó n jáde sí àwọn ilẹ̀ Abínibí America, sí Canada àti, ní ọdún 1837, kọjá ìpínlẹ̀ Àríwá Amerika si England. Kò pẹ́ lẹ́hìnnáà, àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere nṣiṣẹ́ lórí ìpínlẹ̀ ti European àti jìnnà réré bíi sí India àti àwọn Erékùsù Pacific.

“Ojú àmì míllíọ̀nù-méjì ọmọ ìjọ ni a dé ni ọdún mẹ́rìndínlógún péré lẹ́hìnnáà, ní ọdún 1963, àti ojú àmì míllíọ̀nù-mẹ́ta ní ọdún mẹjọ si.”8

Ní sísọ nípa yíyára dàgbàsokè Ìjọ, Ààrẹ Russell M. Nelson sọ láìpẹ́ yí pé: “Loni, iṣẹ́ Olúwa nínú Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ntẹ̀síwájú ni ìgbésẹ̀ yíyá kíákíá. Ìjọ yíò ní ọjọ́ iwájú ti kò sí irú rẹ̀ rí, tí kò lẹ́gbẹ́.”9

Ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Jésù Krístì ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, ìṣètò ìjọ alààyè ti Olúwa ní orí ilẹ̀ ayé lẹ́ẹ̀kan síi, àti ìdàgbàsókè títayọ rẹ̀ láti ìgbà náà ti jẹ́ kí àwọn ìbùkún oyè àlúfàà ó wà ní àrọ́wọ́tó jákèjádò ilẹ̀ ayé. Àwọn ìlànà mímọ́ àti àwọn májẹ̀mú tí ó so wa pọ̀ mọ́ Ọlọ́run tí ó sì gbé wa sí ipa ọ̀nà májẹ̀mú fi “agbára ìwà-bí-Ọlọ́run” hàn.10 Bí a ṣe nkópa nínú àwọn ìlànà mímọ́ wọ̀nyí fún alààyè àti fún àwọn òkú, a nkó Ísráẹ́lì jọ ni ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ti ìbòjú a sì npèsè ayé sílẹ̀ fún Bíbọ̀ Ẹẹ̀kejì Olùgbàlà.

Ní Oṣù kẹ́rin ọdún 1973, àwọn òbí mi àti èmi rin ìrìnàjò làti abínibí Argentina wa láti ṣe èdìdí ní tẹ́mpìlì. Níwọ̀n ìgbà ti kò sí tẹ́mpìlì ní gbogbo Latin America nígbà náà, a fò ju ẹgbẹ̀rún mẹfa máìlì lọ (9,700 km) ní ọ̀nà kọ̀ọ̀kan láti ṣe èdìdí ní Tẹ́mpìlì Salt Lake. Bíótilẹ̀jẹ́pé mo jẹ́ ọmọ ọdún méjì péré nígbà náà tí èmi kò sì rántí gbogbo ìrírí pàtàkì náà, àwọn àwòrán mẹ́ta ọ̀tọ̀ọtọ̀ láti ibi ìrìn àjò náà lẹ̀ mọ́ ọkàn mi wọ́n sì dúró síbẹ̀ láti ìgbà náà.

Ìwò láti ojú fèrèsé ọkọ-òfúrufú

Àkọ́kọ́, mo rántí bi a ṣe gbé mí si tòsí fèrèsé bàálù tí mo sì nwo àwọ̀sánmọ̀ funfun ní ìsàlẹ̀.

Àwọn àwọ̀sánmọ̀ rírẹwà, dídán wọnnì dúró nínú ọkàn mi bi ẹni pé wọ́n jẹ́ ẹ̀gbọ̀n òwú nla.

Àwòrán míràn tí o wà nínú ọkàn mi ni ti díẹ̀ nínú àwọn ohun ìṣeré tí wíwò wọn panilẹ́rìn ní ọgbà ìṣeré ní agbègbè Los Angeles. Àwọn ohun ìṣeré náà ṣòro láti gbàgbé.

Ṣùgbọ́n ti pàtàkì púpọ̀ jùlọ ni àwòrán dídán àti mánigbàgbé yii:

Yàrá èdidì Tẹ́mpìlì Salt Lake

Kedere ni mo rántí wíwà nínú yàrá mímọ́ kan ní Tẹ́mpìlì Salt Lake níbití èdìdí àwọn tọkọtaya ti njẹ́ síṣe fún àkókò àti fún gbogbo ayérayé. Mo rántí pẹpẹ rírẹwà ti tẹ́mpìlì mo sì rántí ìmọ́lẹ̀ ìtànsán òòrùn bí ó ti mọ́lẹ̀ láti ara fèrèsé ìta ti yàrá náà. Mo ní ìmọ̀lara nígbànáà, mo si ntẹ̀síwájú láti máa ni ìmọ̀lára láti ìgbà náà lọ, ti ara yíyá, ààbò, àti ìtùnú ti ìmọ́lẹ̀ Ìhìnrere ti òtítọ́ àti ìfẹ́.

Irú àwọn ìmọ̀lára kanna ni a fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ nínú ọkàn mi ní ogún ọdún lẹ́hìn naa, nígbà ti mo wọ tẹ́mpìlì láti ṣe èdìdí lẹ́ẹ̀kan síi—ni àkókò yi bí ìyàwó àfẹ́sọ́nà mi àti èmi ti ṣe èdìdí fún àkokò àti fún gbogbo ayérayé. Bákannáà, ní àkókò yi, a ko nílò lati rìn ìrìnàjò ẹgbẹgbẹ̀rún máìlì, nítorí a ti kọ́ Tẹ́mpìlì Buenos Aires Argentina a si ti yàá si mímọ́ láti ìgbà náà, ó sì jẹ́ ọkọ̀ wíwà kúkurú láti ilé wa.

Ẹbí Walker

Ọdún méjìlélógún lẹ́hìn ìgbeyàwó àti èdìdí wa, a ní ìbùkùn láti padà sí tẹ́mpìlì, ṣùgbọ́n ni àkokò yí pẹ̀lu arẹwà ọmọbìnrin wa, a si ṣe èdìdí gẹ́gẹ́bí ẹbí fún àkókò àti fún gbogbo àyerayè.

Bí mo ti nṣe àṣàrò lórí àwọn àkokò mímọ́ jùlọ ti ìgbésí ayé mi, mo ti kún fún ìjìnlẹ̀ ayọ̀ àtọkànwá, ayọ̀ pípẹ́. Mo ti ní ìmọ̀lara mo sì ntẹ̀síwájú làti ni ìmọ̀lara ìfẹ́ Bàbá ní Ọ̀run alãnú jùlọ, ẹniti o mọ àwọn àìní ẹnìkọ̀ọ̀kan wa àti àwọn ìfẹ́ inú àtọkànwá wa.

Ní sísọ̀rọ̀ lórí ìkójọ Ísráẹ́lì ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn, Olúwa Jèhófà sọ pé; “Èmi ó fi òfin mi sí inú wọn, èmi ó sì kọọ́ sí oókàn àyà wọn; èmi ó sì jẹ́ Ọlọ́run wọn, àwọn ó sì jẹ́ ènìyàn mi.”11 Mo ní ìmọ̀lára ìdúpẹ́ ayérayé pé láti ọjọ́ orí ọ̀dọ́ mi, ni òfin Olúwa ti bẹ̀rẹ̀ síí gbilẹ̀ jíjinlẹ̀ ní ọkàn mi nípasẹ̀ àwọn ìlànà mímọ́ nínú ilé mímọ́ Rẹ̀. Báwo ni o ti ṣe pàtàkì tó láti mọ̀ pé Òun ni Ọlọ́run wa, pé àwa ni ènìyàn Rẹ̀, àti pé èyíkéyìí àwọn ipò tí ó yí wa ká, bí a bá jẹ olõtọ́ tí a sì ṣe ìgbọràn sí àwọn májẹ̀mú ti a tì dá, a lè “yí wa ká títí ayérayé nínú apá ìfẹ́ rẹ.”12

Lakoko ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò abala ti àwọn obìnrin ní Oṣù kẹwa ọdún 2019, Ààrẹ Nelson sọ pé, “Gbogbo ìtiraka wa láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí ara wa, láti kéde ìhìnrere, láti ṣe àwọn Ènìyàn Mímọ́ ní pípé, àti láti ra àwọn okù padà wà papọ̀ nínú tẹ́mpìlì mímọ́.”13

“Bákannáà, ní àkókò ìpàdé àpapọ gbogbogbò kannáà, Ààrẹ Nelson kọ́ni pé: “Bẹ́ẹ̀ni, ohun iyebíye tí ó parí Ìmúpadàbọ̀sípò ni tẹ́mpìlì mímọ́. Àwọn ìlànà mímọ́ àti àwọn májẹ̀mù rẹ̀ ṣe kókó sí ìmúrasílẹ̀ àwọn ènìyàn kan tí wọ́n ṣetán láti kí Olùgbàlà káàbọ̀ ní Bíbọ Ẹ̀ẹ̀kẹjì Rẹ̀.”14

Ìmúpadàbọ̀sípò tí o nlọ lọ́wọ́ ni a ti ṣe àmì rẹ̀ nípa kíkọ́ àti yíyà àwọn tẹ́mpìlì sí mímọ́ ní ìgbésẹ̀ ìyára. Bí a ti kórajọ ní ẹ̀gbẹ́ méjéèjì ìbòjú, bí a ti nṣe ìrúbọ láti sìn àti láti mú tẹ́mpìlì jẹ́ pàtàkì nínú ayé wa, Olúwa nkọ́ wa nítòótọ́—Ó nkọ́ àwọn ènìyàn májẹ̀mú Rẹ.

Áà, bí ògo rẹ̀ ti tó láti orí ìtẹ́ lókè

Ni ìmọ́lẹ̀ ìhìnrere òtítọ́ àti ìfẹ́ ntàn!

Dídán bí òòrùn, ìtànṣán ti ọ̀run yí

Tàn ìmọ́lẹ̀ sí gbogbo ilẹ̀ loni.15

Mo jẹri pé ìmọ́lẹ̀ ìhìnrere ti òtítọ́ àti ìfẹ́ ntàn ìmọ́lẹ̀ ní dídán jákèjádò ilẹ̀ ayé loni. “Iṣẹ́ ìyanu àti yíyanilẹ́nu náà” tí a sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu wòlíì Isaiah16 tí Néfì si rí17 ó nṣẹlẹ̀ ní ìgbésẹ̀ tí a mú yára kánkán, àní ní àwọn àkókò ìpèníjà wọ̀nyí. Bí Joseph Smith ti kéde pẹ̀lú àsọtẹ́lẹ̀: “A ti gbé Ọ̀págun Òtítọ́ dúró; kò sí ọwọ́ tí a kò yà sí mímọ́ kan tí yío lè dá iṣẹ́ náà dúró ní lílọsíwájú … títí tí àwọn èrò Ọlọ́run yíò fi wá sí ìmúṣẹ, àti tí Jehofa Nla yíò sọ pé iṣẹ́ náà ti ṣe.”18

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, njẹ́ kí a nifẹ kí a sì pinnu loni láti fi ara wa àti àwọn ẹbí wa sílẹ̀ nínú gbígbọ́ ohùn ọ̀run, àní ohùn Olùgbàlà wa. Njẹ́ kí á le ṣe kí a sì le pa àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run mọ́, èyí tí yio fúnwa ní ààbò dídúróṣinṣin ní ipa-ọ̀nà tí ó ndarí padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀, àti kí á lè yọ̀ nínú àwọn ìbùkún ìmọ́lẹ̀ ológo àti òtítọ́ ti ìhìnrere Rẹ. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.