Krístì Jínde; Ìgbàgbọ́ nínú Rẹ̀ Yíò Ṣí àwọn Òkè
Ìgbàgbọ́ nínu Jésù Krístì ni agbára títóbijùlọ tí ó wà fún wa ní ayé yí Ohun gbogbo ṣeéṣe fún àwọn tí ó gbàgbọ́.
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, mo dúpẹ́ fún ànfàní láti bá yín sọ̀rọ̀ ní Ọjọ́-ìsinmi Ọdún-àjínde yí.1 Ètùtù ìrúbọ àti Àjínde Jésù Krístì yí ọ̀kọ̀ọ̀kan ìgbésí ayé wa padà. A nifẹ Rẹ̀ à sì jọ́sìn pẹ̀lú Rẹ̀ pẹ̀lú ìmoore àti Bàbá wa Ọ̀run.
Ní oṣù mẹfà tó kọjá, a ti tẹ̀síwájú láti ní ìdojúkọ pẹ̀lú àjàkálẹ̀ àrùn àgbáyé. Ìfaradà yín àti okun ti-ẹ̀mí yà mí lẹ́nu ní ojú àìsàn, àdánù, àti ìpatì. Mo gbàdúrà léraléra pé, nínú gbogbo rẹ̀, ẹ ó ní ìmọ̀lára ìfẹ́ àìkùnà Olúwa fún yín. Bí ẹ bá dáhùn sí àwọn àdánwò yín pẹ̀lú ipò-ọmọẹ̀hìn alágbára si, ọ̀dún tó lọ yí kì bá ti jẹ́ òfò.
Ní òwúrọ̀ yí, a ti gbọ́ ní ẹnu àwọn olórí Ìjọ tí wọ́n wá láti gbogbo ìgbé orílẹ̀-èdè ilẹ̀-ayé. Nítòótọ́, àwọn ìbùkún ìhìnrere wa fún gbogbo ẹ̀yà, èdè, àti ènìyàn. Ìjọ Jésù Krístì ni ìjọ àgbáyé kan. Jésù Krístì ni olórí wa.
A dúpẹ́, àní àjàkálẹ̀-àrùn kan tí kò ní ànfàní láti fa lílọ síwájú òtítọ́ Rẹ̀ sílẹ̀. Ìhìnrere Jésù Krístì ni ohun tí a nílò rẹ́gí nínú ayé rúdurùdu, ìjà, àti ẹ̀rù yí.
Ọ̀kọ̀ọ̀kan lára àwọn ọmọ Ọlọ́run lẹtọ ànfàní láti gbọ́ àti láti gba ọ̀rọ̀ ìwòsàn, ìràpadà ti Jésù Krístì. Kò sí ọ̀rọ̀ míràn tí ó ṣe kókó sí ìdùnnú wa—nísisìyí àti títíláé.2 Kò sí ọ̀rọ̀ míràn tí ó kún fún ìrètí si. Kò sí ọ̀rọ̀ míràn tí ó lè mú ìjà kúrò ní àwùjọ wa.
Ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì ni ìpìlẹ̀ gbogbo ìgbàgbọ́ àti ọ̀nà sí agbára tọ̀run. Gẹ́gẹ́bí Àpóstélì Paulu, “Áìsí ígbàgbọ́ ó ṣòrò láti dun [Ọlọ́run] nínú: nítorí ẹni ti ó bá wá sọ́dọ̀ Ọlọ́run níláti gbàgbọ́ pé ó wà, ó sì jẹ́ afúnni lére àwọn tí ó fi ìtara wá a.”3
Gbogbo ohun rere nínú ayé—gbogbo agbára ìbùkún ti pàtàkì ayérayé—bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́. Fífi àyè gba Ọlọ́run láti borí nínú ayé wa bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́ pé Ó nfẹ́ láti tọ́ wa sọ́nà. Ìrònúpìwàdà òtítọ́ bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́ pé Jésù Krístì ní agbára lati wẹ̀nùmọ́, wosàn, àti láti fún wa lókun.4
“Máṣe sẹ agbára Ọlọ́run,” wòlíì Mọ́mọ́nì kede, “nítorí ó nṣiṣẹ́ nípa agbára, gẹ́gẹ́bí ìgbàgbọ́ àwọn ọmọ ènìyàn.”5 Ìgbàgbọ́ wa ni yíò ṣí agbára Ọlọ́run nínu ayé wa.
Àti pé síbẹ̀síbẹ̀, lílo ìgbàgbọ́ lè dàbí ìbonimọ́lẹ̀. Ní ìgbàmíràn a lè rò bí tí a bá lè ní ìgbàgbọ́ tó ṣeéṣe tó láti gba àwọn ìbùkún tí a nílò taratara gan. Bákannáà, Olúwa fi ẹ̀rù wọnnì dúró lé àwọn ọ̀rọ̀ wòlíì Álmà nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì.
Alma ni kí a ṣe àyẹ̀wò jẹ́jẹ́ lórí ọ̀rọ̀ náà kí a sì “lo èérún ìgbàgbọ́ kan, bẹ́ẹ̀ni, àní bí [a] kò bá lè ní ìfẹ́ si láti gbàgbọ́.”6 Gbólóhùn ọ̀rọ̀ “èérún ìgbàgbọ́” rán mi létí nípa ìlérí ti bíbélì pé bí a bá “ní ìgbàgbọ́ bí wóró irúgbìn mústádì,” a ó lè “wí fún òkè yí, pé Ṣí nihin lọ sí ọ̀hún; yio sì ṣí kúrò; kò sì sí ohunkankan tí kò ní ṣeéṣe fún [wa].”7
Olúwa ní òye àìlera ayé ikú wa. Gbogbo wa nkọsẹ̀ nígbàmíràn. Ṣùgbọ̀n bákannáà Ó mọ agbára nlá wa. Wóró mústádì bẹ̀rẹ̀ kékeré ṣùgbọ́n ndàgbà sí igi títóbi tó fún àwọn ẹyẹ láti bà lé àwọn ẹ̀ka rẹ̀. Wóró mústádì rọ́pò ìgbàgbọ́ kékeré tí ó tí ó ndàgbà.8
Olúwa kò bèère fún ìgbàgbọ́ pípé fún wa láti ní àyè sí agbára pípé rẹ̀. Ṣùgbọ́n Ó ní kí a gbàgbọ́.
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, ìpè mi sí yín ní òwúrọ̀ Ọdún-àjínde yí ni láti bẹ̀rẹ̀ loni láti mú ìgbàgbọ́ yín pọ̀ si. Nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ yín, Jésù Krístì yíò mú okun yín láti ṣí òkè pọ̀si nínú ayé yín,9 àní bí ó tilẹ̀jẹ́ pé àwọn ìpènijà araẹni yín lè wà ní títóbi bí Òke Everest.
Àwọn òkè yín lè jẹ́ àdáwà, iyèméjì, àìsàn, tàbí àwọn wàhálà araẹni míràn. Àwọn òkè yín yíò yàtọ̀, àti pé síbẹ̀ ìdáhùn sí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìpènijà yín ni láti mu ìgbàgbọ́ yín pọ̀ si. Ìyẹn gba iṣẹ́. Ọlẹ̀ olukẹkọ àti àwọn ọmọẹ̀hìn dídẹrasílẹ̀ yíò fi ìgbàgbogbo làkàkà àní láti ní èérún ìgbàgbọ́ kan.
Láti ṣe ohunkóhun dáradára gba ìtiraka. Dída ọmọẹ̀hìn òtítọ́ ti Jésù Krístì kìí ṣe ìyàtọ̀ rárá. Mímú ìgbàgbọ́ yín pọ sì àti níní ìgbẹ́kẹ̀lé nínu Rẹ̀ gba ìtiraka. Njẹ́ kí n fúnni ní àwọn àbá mẹfa láti ràn yín lọ́wọ́ láti gbèrú ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé náà.
Àkọ́kọ́, ṣe àṣàrò. Di olùṣiṣẹ́ akẹkọ kan. Ẹ ri ara yín sínú àwọn ìwé-mímọ́ láti ní òye dáradára si nípa iṣẹ́ ìránṣẹ́ Krístì àti ìhìnrere. Ẹ mọ ẹ̀kọ́ Krístì kí ẹ lè ní òye agbára rẹ̀ fún ayé yín. Ẹ fi òtítọ́ tí Ètùtù Jésù Krístì lo fún yín sínú. Ó gbé ìbànújẹ́ yín, àṣìṣe yín, àìlera yín, àti ẹ̀ṣẹ̀ yín lé orí Ararẹ̀. Ó san ìdíyelé ẹ̀sàn ó sì pèsè agbára fún yín láti ṣí gbogbo òkè tí ẹ ó dojúkọ láéláé. Ẹ gba agbára pẹ̀lú ìgbàgbọ́ yín, ìgbẹ́kẹ̀lé, àti ìfẹ́ láti tẹ̀lé E.
Ṣíṣí àwọn òkè yín lè nílò iṣẹ́ ìyànu. Kọ́ nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu. Àwọn iṣẹ́ ìyanu nwá gẹ́gẹ́bí ìgbàgbọ́ yín nínú Olúwa. Àringbùngbun sí ìgbàgbọ́ náà ni gbígbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ Rẹ̀ àti aago-àkokò bí—àti ìgbàtí Òun yíò bùkún yín pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ìyanu tí ẹ fẹ́. Àìgbàgbọ́ yín nìkanni yíò pa Ọlọ́run mọ́ ní bíbùkún yín pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ ìyanu láti ṣí òkè inú ayé yín nidi.10
Bí ẹ ti nkọ́ nípa Olùgbàlà si, ní yíò rọrùn láti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àánú Rẹ̀, ìfẹ́ àìlópin Rẹ̀, àti ìfúnnilókun Rẹ̀, ìwósán, àti agbára ìràpadà. Olùgbàlà ko súnmọ́ yín jùlọ sí ìgbà tí ẹ bá ndojúkọ tàbí gun òkè pẹ̀lú ìgbàgbọ́.
Ìkejì, yan láti gbàgbọ́ nínú Jésù Krístì. Bí ẹ bá ní iyèméjì nípa Ọlọ́run Baba àti Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀, tàbí òdodo Àjínde tàbí dídájú ìpè tọ̀run Joseph Smith bí wòlíì, yàn láti gbàgbọ́11 kí ẹ dúro nínú òtítọ́. Ẹ mú ìbèèrè yín tọ Ọlọ́run lọ àti àwọn orísun òtítọ́ míràn. Ṣe àṣàrò pẹ̀lú ìfẹ́ láti gbàgbọ́ sànju pẹ̀lú ìrètí pé ẹ lè rí àṣìṣe nínú híhàn ìgbé ayé wòlíì tàbí àìdáa inú iwé mímọ́. Ẹ dáwọ́ mímú ìyèmejì yín pọ̀ sí nípa títún wọn sọ pẹ̀lú àwọn oníyèméjì. Ẹ fi àyè gba Olúwa láti darí yín lórí ìrìnàjò yín nípa ìwárí.
Ìkẹ́ta, ṣe ìṣe nínú ìgbàgbọ́. Kíni ẹ̀yin yíò ṣe bí ẹ bá ní ìgbàgbọ́ si? Ronú nípa rẹ̀! Kọ nípa rẹ̀. Lẹ́hìnnáà gba ìgbàgbọ́ si nípa ṣíṣe ohunkan tí ìgbàgbọ́ bèèrè fún ìgbàgbọ́ si.
Ikẹrin, ẹ ṣe àbápín àwọn ìlànà mímọ́ ní yíyẹ. Àwọn ìlànà nṣí agbára Ọlọ́run fún ìgbé ayé yín.12
Àti Ikarun, bèèrè lọ́wọ́ Baba Ọ̀run, ní orúkọ Jésù Krístì, fún ìrànlọ́wọ́.
Ìgbàgbọ́ gba iṣẹ́. Gbígba ìfihàn ngba iṣẹ́. Ṣùgbọ́n “ẹnikẹ́ni tí ó bá bẽrè nrí gbà; ẹnití ó bá sì wá kiri nrí; ẹnití ó bá sì kànkùn ni a ò síi sílẹ̀ fún.”13 Ọlọ́run mọ ohun tí yíò mú ìgbàgbọ́ yín dàgbà. Ẹ bèèrè, lẹ́hìnnáà kí ẹ bèèrè lẹ́ẹ̀kansi.
Aláìgbàgbọ́ kan lè wípé ìgbàgbọ́ wà fún aláìlera. Ṣùgbọ́n ìtẹnumọ́ yí fojú fo agbára ti ìgbàgbọ́. Ṣé àwọn Àpóstélì Olùgbàlà ìbá ti tẹ̀síwájú láti kọ́ni ní ẹ̀kọ́ rẹ̀ lẹ́hìn ikú Rẹ̀, nínú ewu ayé wọn, bí wọ́n bá ti ṣe iyèméjì sí I?23 Ṣé Joseph àti Hyrum Smith ìbá ti jìyà ikú apani láti dá ààbò bo Ìmúpadàbọ̀sípò Ìjọ Olúwa àyàfi tí wọ́n bá ní ẹ̀rí ìdánilójú pé ó jẹ́ òótọ́? Ṣé bí ẹgbẹ̀rún méjì àwọn Ènìyàn Mímọ́ ìbá ti kú lẹgbẹ olùlànà nínú ìrìnàjò24 bí wọ́n bá ní iyèméjì kankan pé ìhìnrere Jésù Krístì ti padabọ̀sípò? Nítòótọ́, ìgbàgbọ́ ni agbára tí ó nmú ẹni tí kò yẹ kó ṣe àṣeyege le ri ṣe.
Ẹ máṣe dín ìgbàgbọ́ tí ẹ ti ní tẹ́lẹ̀ kù. Ó gba ìgbàgbọ́ láti darapọ̀ mọ́ Ìjọ àti láti dúró nínú òtítọ́. Ó gba ìgbàgbọ́ láti tẹ̀lé àwọn wòlíì sànju ìròhìn àti èrò olókìkí. Ó gba ìgbàgbọ́ láti sin míṣọ̀n kan ní ìgbà àjàkálẹ̀ àrùn kan. Ó gba ìgbàgbọ́ láti gbé ìgbé ayé mímọ́ nígbàtí ayé nké pé ìwà mímọ́ Ọlọ́run jẹ́ ti àtijọ́ nísisìyí. Ó gba ìgbàgbọ́ láti kọ́ ìhìnrere sí àwọn ọmọ ní ayé àìlèsìn kan. Ó gba ìgbàgbọ́ láti bẹ̀bẹ̀ fún ìyè olólùfẹ́ kan, àní àti ìgbàgbọ́ jùlọ láti tẹ́wọ́gba ìjákulẹ̀ ìdáhùn.
Ọdún méjì sẹ́hìn, Arábìnrin Nelson àti pé èmi bẹ Samoa, Fiji, àti Tahiti wò. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn orílẹ̀-èdè erékùṣù náà ní ìrírí òjò líle fún ọ̀pọ̀ ọjọ́. Àwọn ọmọ ìjọ gbàwẹ̀ àti àdúrà pé kí àwọn ìpàdé ìta wọn le ní ààbò kúrò lọ́wọ́ òjò.
Ní Samoa, Fiji, àti Tahiti, ní kété tí àwọn ìpàdé bẹ̀rẹ̀, òjò dáwọ́dúró. Ṣùgbọ́n ní Tonga, òjò kò dáwọ́dúró. Síbẹ̀ àwọn Ènìyàn Mímọ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlá wá ní wákàtí díẹ̀ ṣíwájú kí wọ́n lè ní ijoko, wọ́n sì dúró pẹ̀lú sùúrù nínú ìṣàn tí kò dáwọ́dúró, wọn sì joko nínú ìpàdé wákàkí-méji rírẹ gan.
A rí ìgbàgbọ́ akọni níbi iṣẹ́ laarin ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ti erékùṣù—ìgbàgbọ́ tító láti dá òjò dúró, àti ìgbàgbọ́ láti faradà nígbàtí òjò kò dáwọ́dúró.
Àwọn òkè nínú ayé wa kò ní ṣí nígbàgbogbo bí àti nígbàtí a bá fẹ́. Ṣùgbọ́n ìgbàgbọ́ wa nígbàgbogbo yíò mú wa tẹ̀ síwájú. Ìgbàgbọ́ nmú àyè wa sí agbára tọ̀run pọ̀ si nígbàgbogbo.
Jọ̀wọ́ mọ èyí pé: bí ohun gbogbo àti ẹni gbogbo ní àgbáyé tí ẹ gbẹ́kẹ̀lé bá lè kùnà, Jésù Krístì àti Ìjọ Rẹ̀ kò ní já yín kulẹ̀ láéláé. Olùwa kìí tògbé, bẹ́ẹ̀ni kìí sùn.16 Òun ni ọ̀kannáà lana, loni, àti [lọ́la].”17 Òun kò ní pa àwọn májẹ̀mú Rẹ̀ ti,18 ìlérí Rẹ̀, tàbí ìfẹ́ Rẹ̀ fún gbogbo ènìyàn. Ó nṣe iṣẹ́ ìyanu ní òní yíò si ṣe iṣẹ́ ìyanu lọ́la.19
Ìgbàgbọ́ nínu Jésù Krístì ni agbára títóbijùlọ tí ó wà fún wa ní ayé yí. Ohun gbogbo ṣeéṣe fún àwọn tí ó gbàgbọ́.20
Dídàgbà ìgbàgbọ́ yín nínú Rẹ̀ yíò ṣí àwọn òkè—kìí ṣe àwọn òkè òkúta tí ó nfún ilẹ̀ ayé lẹ́wà ṣùgbọ́n àwọn òkè ìbànújẹ́ nínú ayé yín. Ìgbèrú ìgbàgbọ́ yín yíò ràn yín lọ́wọ́ láti yí àwọn ìpènijà padà sínú ìdàgbà àìlẹ́gbẹ́ àti ànfàní.
Ní Ọjọ́-ìsinmi Ọdún-àjínde yí, pẹ̀lú ìmọ̀lára jíjinlẹ̀ nípa ìfẹ́ àti ìdúpẹ́, lẹ́ẹ̀kansi mo kíi yín: “Krìstì Jínde.” Ó jínde láti darí Ìjọ Rẹ̀. Ó jínde láti bùkún ayé gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run, níbikíbi tí ẹ̀ ngbé. Pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú Rẹ̀, a lè ṣí àwọn ókè. Ní mo jẹ́ ẹ̀rí bẹ́ẹ̀ ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.