Àwọn Ìbáraẹnisọ̀rọ̀ Pàtàkì
A kò lè dúró de ìyípadà ọkàn láti ṣẹlẹ̀ ní ìrọ̀rùn sí àwọn ọmọ wa. Ìyípadà ọkàn àìròtẹ́lẹ̀ kìí ṣe ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ ìhìnrere ti Jésú Krìstì.
Njẹ́ ó ti ṣe ọ́ ní kàyéfì rí ìdí tí a fi pe Àkọ́bẹ̀rẹ̀ ní “Alákọ́bẹ̀rẹ̀”? Nígbàtí orúkọ náà tọ́ka sí ìkẹ́kọ ti ẹ̀mí tí àwọn ọmọdé gbà ní àwọn ọdún àkọ́kọ́ wọn, sí mi ó tún jẹ́ ìránnilétí ti òtítọ́ alágbára kan. Sí Bàbá wa Ọ̀run, àwọn ọmọdé kò tíì wà ní ipò èkejì rí láe —wọ́n máa nfi ìgbà gbogbo jẹ́ “àkọ́kọ́.”1
Ò gbẹ́kẹ̀lé wa láti mọ iyì wọn, láti bọ̀wọ̀ fún wọn, ati láti dá ààbo bò wọ́n bí ọmọ Ọlọ́run. Tí ó túmọ̀ sí pé a kò ṣe ìpalára fún wọn ní ti ara, ní ọ̀rọ̀ sísọ, tàbí ti ẹ̀dùn-ọkàn ní èyíkéyi ọ̀nà, àní nígbàtí àwọn àìfọ̀kànbalẹ̀ àti àwọn ìfipá ṣe bá bá ga sókè. Dípò bẹ́ẹ̀ kí a mọ iyì àwọn ọmọdé kí a sì ṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe láti dojúko àwọn ìwà ibiti ìlòkulò. Ìtọ́jú wọn jẹ́ àkọ́kọ́ sí wa-bí ó ti jẹ́ sí Òun.2
Ọdọ́ ìyá àti bàbá kan jóko ní ibi tábìlì yàrá ìdáná wọn, ní ṣíṣe àgbéyẹ̀wò ìṣe wọn fún ọjọ́ náà. Láti ìsàlẹ̀ gbọ̀ngàn náà, wọ́n gbọ́ ariwo ìṣubú kan. Ìyá náà béèrè, “Kínnì yẹn?”
Lẹ́hìnnáà wọ́n gbọ́ ẹkún jẹ́jẹ́ kan tí nbọ láti yàrá ìyẹ̀wù ọmọkùnrin ọdún mẹ́rin wọn. Wọ́n sáré sísàlẹ̀ gbọ̀ngàn náà. Níbẹ̀ ni ó wà, ó dùbúlẹ̀ lórí ilẹ̀ lẹ́gbẹ ibùsùn rẹ̀. Ìyá náà gbé ọmọ kékeré náà ó sì bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé kí ló ṣẹlẹ̀.
Ò sọ pé, “Mo ṣubú kúrò lórí ibùsùn mi.”
Ó wípé, “èéṣe tí o fi ṣubú kúrò lórí ibùsùn?”
Ó sọ èjìká sókè ó sì sọ pé, “Èmi kò mọ̀. Mo rò pé èmi kò kàn wọlé jìnnà sínú tó ni.”
Ó jẹ́ nípa “wíwọlé jìnnà tó sínú” yí ni èmi yíò sọ̀rọ̀ ní òwúrọ̀ yí. Ó jẹ́ ànfàní àti ojúṣe wa láti ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ “láti wọlé jìnnà tó sí“ inú ìhìnrere Jésù Krístì. Àti pé kò lè yá jù láti bẹ̀rẹ̀.
Àkókò pàtàkì kan tí ó jẹ́ àìláfiwé wà ní àyè àwọn ọmọdé nígbàtí wọ́n ní ìdáàbòbò lati kúrò ní ipa Satani. Ó jẹ́ àkókò kan nígbàtí wọ́n jẹ́ aláìṣẹ̀ àti òmìnira-sí-ẹ̀ṣẹ̀.3 Ó jẹ́ àkókò mímọ́ fún òbí àti ọmọ. A gbọ́dọ̀ kọ́ àwọn ọmọdé, nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ àti àpẹrẹ, ṣáájú àti lẹ́hìn tí wọ́n bá “dé àwọn ọdún ti ìjiyìn níwájú Ọlọ́run.”4
Ààrẹ Henry B. Eyring kọ́ni pé: “A ní ànfàní tí ó tóbi jùlọ pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́ Àkókò tí ó dára jùlọ láti kẹ́kọ ni kùtùkùtù, ni àkókò tí àwọn ọmọdé ṣì ní ààbò sí àwọn ìdánwò ti ọ̀tá ayé ikú, àti ní pípẹ́ ṣáájú kí àwọn ọ̀rọ̀ òtítọ́ to lè nira fún wọn láti gbọ́ nínú ariwo àwọn ìtiraka ti ara-ẹni wọn.”5 Irú ìkọ́ni bẹ́ẹ̀ yíò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ ìdánimọ̀ àtọ̀runwá wọn, èrèdí wọn, àti àwọn ìbùkún lọ́pọ̀lọpọ̀ tí ó ndúró dè wọ́n bí wọ́n ti nṣe àwọn májẹ̀mú mímọ́ tí wọ́n sì ngba àwọn ìlànà ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú náà.
A kò lè dúró de ìyípadà ọkàn láti ṣẹlẹ̀ ní ìrọ̀rùn sí àwọn ọmọ wa. Ìyípadà àìròtẹ́lẹ̀ kìí ṣe ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ ìhìnrere ti Jésú Krìstì. Dída bí Olùgbàlà wa kì yíò ṣẹlẹ̀ láìletò. Jíjẹ́ àtinúwá nínú fífẹ́ràn, kíkọ́ni, àti jíjẹ́ ẹ̀ri lè ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́-orí kékeré láti ní ìmọ̀lára ipa Ẹ̀mí Mímọ́. Ẹmí Mímọ́ jẹ́ pàtàkì sí ẹ̀rí àwọn ọmọ wa nípa àti ìyípadà ọkàn sí Jésù Krístì; a fẹ́ wọn láti máa “rántí rẹ̀ nígbà gbogbo, pé kí wọn ó lè ní Ẹ̀mí rẹ̀ láti wà pẹ̀lú wọn.”6
Ro iyì ti àwọn ìbárasọ̀rọ̀ ẹbí nípa ìhìnrere ti Jésù Krístì, àwọn ìbárasọ̀rọ̀ pàtàkì , tí ó lè jẹ́ ohun èlò tí yío ṣe ànfàní láti pe Ẹmí. Nígbàtí a bá ní irú àwọn ìbárasọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ wa, a nràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe ẹ̀dá ìpìlẹ̀ kan, “èyítí ó jẹ́ ìpìlẹ̀ tó dájú, ìpìlẹ̀ lórì èyí tí wọn bá gbélé tí wọn kò lè ṣubú.”7 Nígbàtí a bá fún ọmọ kan lókun, a fún ẹbí lókun.
Àwọn ìjíròrò pàtàkì wọ̀nyí lé darí àwọn ọmọdé láti:
-
Ní òye ẹ̀kọ́ ti ìrònúpíwàdà.
-
Ní ìgbàgbọ́ nínú Krístì, Ọmọ Ọlọ́run alãyè.
-
Yan ìrìbọmi àti ẹ̀bùn Ẹmí Mímọ́ nígbàtí wọn bá jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́jọ.8
-
Gbàdúrà kí wọn ó sì rìn ní títọ́ níwájú Olúwa.9
Olùgbàlà gbà wá níyànjú pé, “Nítorínáà, mo fi àṣẹ kan fún yín, láti fi àwọn nkàn wọ̀nyí kọ́ àwọn ọmọ yín ní ọfẹ́ sí àwọn ọmọ yín.”10 Àti pé Kíni Ó fẹ́ kí a kọ́ni ní òmìnira bẹ́ẹ̀?
-
Ìsubú ti Ádámù
-
Ètùtù ti Jésù Krístì
-
Pàtàkì jíjẹ́ àtúnbí11
Alàgbà D. Todd Christofferson sọ pé, “Dájúdájú inú ọ̀tá a máa dùn nígbàtí àwọn òbí bá kọ̀ láti kọ́ àti láti tọ́ àwọn ọmọ wọn láti ní ìgbàgbọ́ nínú Kírísítì kí a sì tún wọn bí ní ti ẹ̀mí.”11
Ní ìfiwéra, Olùgbàlà fẹ́ kí a ran àwọn ọmọdé lọ́wọ́ “fi ìgbẹ́kẹ̀lé [wọn] sínú Ẹmí náà tí ó ndarí ẹni sí ṣíṣe rere.”12 Láti ṣe bẹ́ẹ̀, a lè ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ọmọdé ní mímọ̀ ìgbàtí wọ́n bá ní ìmọ̀lára Ẹmí àti níní òye àwọn ìṣe tí ó nfa kí Ẹ̀mí lọ kúrò. Báyìí wọ́n nkọ́ láti ronúpìwàda àti láti padà nípasẹ̀ Ètùtù Jésù Krístì. Èyí nṣèrànlọ́wọ́ láti gbani-níyàjú ìfaradà ti ẹ̀mí.
A lè ní ìgbádùn ní ríran àwọn ọmọ wa lọ́wọ́ láti kọ́ ìfarada ti ẹ̀mí ní èyíkéyi ọjọ́-orí. Kò ní láti jẹ́ ìnira tàbi àkókò líle. Àwọn ìbáraẹnisọ̀rọ̀ ìkẹ́ tí ó rọrùn, lè darí àwọn ọmọdé láti mọ̀ kìí ṣe ohun tí wọ́n gbàgbọ́ nìkan, ṣùgbọ́n pàtàkì jùlọ, ìdí tí wọ́n fi gbà á gbọ́. Àwọn ìbáraẹnisọ̀rọ̀ ìkẹ́, tí ó nṣẹlẹ̀ ní àdánidá àti léraléra, le darí sí òye tí ó dára jùlọ àti àwọn ìdáhùn. Ẹ máṣe jẹ́kí á gba ìrọ̀rùn ti àwọn ohun èlò ẹ̀rọ oníná láti pa wá mọ́ kúrò ní kíkọ́ àti fífeẹ́tísí àwọn ọmọ wa àti ní wíwo inú ojú wọn.
Àwọn ànfàní àfikún fún àwọn ìbáraẹnisọ̀rọ̀ tó ṣe pàtàkì lè wáyé nípasẹ̀ ṣiṣe-ojúṣe. Àwọn ọmọ ẹbí lè ṣeré ní àwọn ipò bíi dídánwò tàbí fífi ipá mú láti yan ohun ti ko dara. Irú ìdárayá bẹ́ẹ̀ lè ró àwọn ọmọdé lágbára láti wà ní ìmúra sílẹ̀ ní ipò ìpènijà kan. Fún àpẹẹrẹ, a le ṣe é bí eré àti lẹ́hìnnáà kí a sọ ọ́ lọ́rọ̀ bí a ṣe nbèèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọdé ohun tí wọn yíò ṣe:
-
Bí a bá dán wọn wò láti ṣe lòdì sí Ọ̀rọ̀ Ọgbọ́n?
-
Bí a bá fi wọ́n hàn sí àwòrán ìwòkuwò.
-
Bí a bá dán wọn wò láti parọ́, jalè, tàbí ṣe ìyànjẹ.
-
Tí wọ́n bá gbọ́ ohun kan láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ tàbi olùkọ́ kan ní ilé-ìwé tí ó tako àwọn ìgbàgbọ́ tàbi àwọn iyì wọn.
Bí wọn ti nṣeé léré jáde àti lẹ́hìnnáà tí wọ́n nsọ ọ́ jáde lọ́rọ̀, dípò kí a mú wọn ní àìmúrasílẹ̀ nínú ipò àkójọpọ̀ ẹgbẹ́ oníwà-ipá, àwọn ọmọdé lè di ìhámọ́ra pẹ̀lú “àsà ìgbàgbọ́ èyítí [wọ́n] yíò fi lè pa gbogbo àwọn ọfà iná tí àwọn ènìyàn búburú.”14
Ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ti ara ẹni kan kọ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì yi ní ìbẹ̀rẹ̀. Ó fi orúkọ sílẹ̀ nínú iṣẹ́ ológun United States lákoko rògbòdìyàn láarín Àmẹ́ríkà àti Vietnam. Ó rí ara rẹ̀ ní yíyàn sí ìkẹ́kọ ìpílẹ̀ nínú ọmọ-ogun làti di ọmọ ogun ẹlẹ́sẹ̀. Ó ṣàlàyé pé ìkẹ́kọ̀ náà burú. Ó ṣe àpèjúwe olùkọ́ amúniṣiṣẹ́ rẹ̀ bí ìkà àti ọ̀dájú.
Ní ọjọ́ kan pàtó àwọn ọmọ ẹgbẹ́ rẹ̀ wà ní ìwọṣọ ohun èlò ìjà ní kíkún, ní gígun òkè gígá nínú ooru gbígbóná. Olùkọ́ ìgbaradì pariwo lójijì pẹ̀lú àwọn àṣẹ láti lọ sílẹ̀ láì mira. Olùkọ́ni náà nwò fún àní iṣípòpadà tí ó kéré jùlọ. Èyíkéyi ara mímì yíò yọrí sí àwọn àbájáde tó wúwo lẹ́hìnwa. Ẹgbẹ́ náà jìyà fún wákàtí méjì ó lé nínú ooru pẹ̀lú ìbínú tó nru àti ìkórira sí olórí wọn.
Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn oṣù lẹ́hìnnáà ọ̀rẹ́ wa ríi ara rẹ̀ ní síṣe àkóso ẹgbẹ́ rẹ̀ la àwọn igbó dídí Vietnam já. Èyí jẹ́ tòótọ́ gidi, kìí ṣe ìkẹ́kọ lásán. Àwọn ìbọn bẹ̀rẹ̀ síí dún láti òkè nínú àwọn igi àyíká. Gbogbo ẹgbẹ́ náà bẹ̀rẹ̀ lọ sílẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.
Kíni nkan tí ọ̀tá nwá? Ìṣípòpadà. Èyíkéyi ìṣípòpadà rárá yíò fa iná. Ọ̀rẹ́ wa sọ pé bí òun ti dùbúlẹ̀ tí ó nláàgún àti láìmira lórí ilẹ̀ igbó dídí náà, tó ndúró kí ilẹ̀ ṣú fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn wákàtí pípẹ́, àwọn èrò inú rẹ̀ padà sẹ́hìn sórí kókó ìdánilẹ́kọ. Ó rántí ìkórira líle fún olùkọ́ ìgbaradì rẹ̀. Nísinsìnyí, ó ní ìmọlára ìmoore jíjinlẹ̀—fún ohun tí ó ti kọ́ ọ, àti bí ó ti múra rẹ̀ sílẹ̀ fún ipò tó léwu yíi. Olùkọ́ni ìgbaradì náà ti fi ọgbọ́n ró ọ̀rẹ́ wa àti àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú agbára láti mọ ohun ṣíṣe nígbàtí ogun bá ngbóná. Òun ti, gba ayé ọ̀rẹ́ wa là, ní àyọrísí.
Báwo ni a ṣe lè ṣe bákannáà fún àwọn ọmọdé níti ẹ̀mí? Ní ìgbà pípẹ́ ṣáájú kí wọn tó wọ ojú-ogun ti ìgbésí ayé, báwo ni a ṣe lè gbìyànjú ní kíkún síi láti kọ́ wọn, ró wọn lágbára àti múra wọn sílẹ̀?15 Báwo la ṣe lè pè wọn láti “wọlé jìnnà sínú tó?” Njẹ́ a kò ní jẹ́ kí wọn ó kúkú “làágùn” ní ààbò ìkẹ́kọ̀ọ́ àìléwu ti ilé ju kí wọn ṣẹ̀jẹ̀ ní ojú-ogun ìgbésí ayé lọ?
Bí mo ṣe bojúwò ẹ̀hìn, àwọn àkókò kan wà nígbàtí èmi àti ọkọ mì ní ìmọ̀lára dídàbí àwọn olùkọ́ni ìgbaradì nínù ìtara wa láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ọmọ wa láti gbé ìgbé ayé ìhìnrere ti Jésù Krísti. Wòlíì Jákọ́bù dàbí ẹni pé ó sọ àwọn ìmọ̀lára kannáà nígbàtí ó sọ pé: “Emi nfẹ̀ àlàáfíà ẹ̀mí yin. Bẹ́ẹ̀ni, àníyàn mi pọ̀ fún yín; ẹ̀yin tìkarãyín sì mọ̀ pé bẹ́ẹ̀ ni ó ti wà nígbà-gbogbo.”16
Bí àwọn ọmọdé ṣe nkẹ́kọ tí wọ́n sì ntẹ̀síwájú, àwọn ìgbàgbọ́ wọn yíò ní ìpenijà. Ṣùgbọ́n bí wọ́n ti jẹ́ ríró lágbára dáradára, wọ́n lè dàgbà nínú ìgbàgbọ́, ìgboyà, àti ìdánilójú, àní láarín àtakò líle.
Álmà kọ́ wa láti “múra ọkàn àwọn ọmọ [náá] sílẹ̀.”17 À npèsè ìran tí ó ndìde sílẹ̀ láti jẹ́ àwọn olùgbèjà ìgbàgbọ́ ti ọjọ́ iwájú, láti ní òye “pé [àwọn] ní òmìnira láti ṣe fún [ara wọn]—láti yan ọ̀nà ikú àìnípẹ̀kun tàbí ọ̀nà tí ìyè ayérayé.”18 Àwọn ọmọdé yẹ láti ní òye òtítọ́ nlá yi: ayérayé jẹ́ ohun àṣìṣe tí kò tọ́ láti ṣe àṣìṣe nípa rẹ̀.
Njẹ́ kí àwọn ìbárasọ̀rọ̀ wa tí ó ṣe pàtàkì síbẹ̀síbẹ̀ tí ó rọrùn pẹ̀lú àwọn ọmọ wa ràn wọn lọ́wọ́ láti “gbádùn àwọn ọ̀rọ̀ ti ìyè ayérayé” nísisìyi, ki wọn ó le gbadun “ìyè ayérayé ní ayé tó nbọ̀, àní ògo àìkú.”18
Bí a ṣe ntọ́jú tí a sì npèsè àwọn ọmọ wa sílẹ̀, a nfi ààye gbà ìṣojú ara ẹni wọn, a fẹ́ràn wọn pẹ̀lú gbogbo ọkàn wa, a kọ́ wọn ní àwọn òfin Ọlọ́run àti ẹ̀bùn ìrònúpíwàdà Rẹ̀, àti pé a kò gbọdọ̀, juwọ́lẹ̀,, láéláé lóri wọn. Lẹ́hìn gbogbo rẹ̀, njẹ́ èyí kìí ṣe ọ̀nà Olúwa pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan wa?
Ẹ jẹ́ kí a tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìdúróṣinṣin nínú Krístì, ní mímọ̀ pé a lè ní “ímọ́lẹ̀ ìrètí pípé”19 nípasẹ̀ olùfẹ́ni Olùgbàlà wa.
Mo jẹ́rí pé Òun ni ìdáhùn náà nígbàgbogbo. Ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.