Dídáàbò Bo Òfin-Orílẹ̀èdè Onímísí Àtọ̀runwá
Ìgbàgbọ́ wa ninú ìmísí tọ̀run fún àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ní ojúṣe àìláfiwé láti dìmú àti láti dá ààbò bo Òfin-Orílẹ̀ èdè United States àti àwọn ẹ̀kọ́-ìpìlẹ̀ ti òfin-ìlú.
Ní ìgbà wàhálà yí, mo ní ìmọ̀lára láti sọ̀rọ̀ nípa Òfin-ìlú onimisi ti United States. Òfin-ilú yí ṣe pàtàkì gidi sí àwọn ọmọ United States, ṣùgbọ́n bàkannáà ó jẹ́ ogun tó wọpọ̀ ti àwọn òfin-ìlú káàkiri ayé.
1.
Òfin-Orílẹ̀ èdè kan ni ìpìlẹ̀ ìjọba. Ó npèsè ọ̀nà àti ààlà fún lílo àwọn agbàra ìjọba. Òfin-Orílẹ̀ èdè United States ni òfin-ìlú tí a kọ tí ó dàgbà jùlọ tí ó ṣì wà loni. Bíotilẹ̀jẹ́pé ní àtilẹ̀wá a gbàá látọwọ́ àwọn ìletò kékeré ní iye, ó di àwòṣe fún àgbáyé láìpẹ́. Loni, gbogbo orílẹ̀-èdè yàtọ̀ sí mẹta ti gba àwọn òfin-ìlú kíkọsílẹ̀.1
Nínú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí èmi kò sọ̀rọ̀ fún ẹgbẹ́ òṣèlú kankan tàbí ẹgbẹ́ míràn. Mo nsọ̀rọ̀ fún Òfin-Orílẹ̀ èdè United States, èyí tí mo ti ṣe àṣàrò fún ọgọ́ta ọdún ó lé. Mo nsọ̀rọ̀ látinú ìrírí iṣẹ́ òfin mi bí akọ̀wé òfin sí Adájọ́ Àgbà ti Ilé Ẹjọ́ Gíga Jùlọ ní United States. Mo nsọ̀rọ̀ látinú ọdún mẹẹdogun bii amoye òfin kan àti ọdún mẹ́ta ààbọ̀ bí adájọ́ ní Ilé Ẹjọ́ Gíga Jùlọ ní Utah. Nípàtàkì jùlọ, mo nsọ̀rọ̀ látinú ọdún mẹ́tàdínlógójì bí Àpóstélì Jésù Krístì, tí ó ní ojúṣe láti ṣe àṣàrò ìtumọ̀ Òfin-Orílẹ̀ èdè onimisi àtọ̀runwá ti United States bí ó ti wúlò sí iṣẹ́ Ìjọ Rẹ̀ tí a múpadàbọ̀sípò.
Òfin-Orílẹ̀ èdè United States jẹ́ àìláfiwé nítorí Ọlọ́run fihàn pé Òun “gbée kalẹ̀” “fún àwọn ẹ̀tọ́ àti ààbò gbogbo ẹlẹ́ran ara” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 101:77; bákannáà wo ẹsẹ 80). Ìyẹn ni ìdí tí òfin-orílẹ̀ èdè yí fi jẹ́ àníyàn pàtàkì fún Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn káàkiri àgbáyé. Bóyá tàbí bí àwọn ẹ̀kọ́-ìpìlẹ̀ rẹ̀ ṣe níláti wúlò ní àwọn orílẹ̀-èdè ti ayé míràn jẹ́ ọ̀ràn fún wọn láti pinnu.
Kíni èrèdí tí Ọlọ́run fi gbé Òfin-Orílẹ̀ èdè United States kalẹ̀? A lè rí i nínú ẹ̀kọ́ ti ìwà ìṣojú araẹni. Ní dẹ́kédì àkọ́kọ́ ti ìmúpadàbọ̀sípò Ìjọ, àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ní ìṣíwájú ìwọ-oòrùn n jìyà inúnibíni ìkọ̀kọ̀ àti gbangba. Ní apákan èyí jẹ́ nítorí àtakò sí ìkónilẹ́rú ènìyàn tí ó wà ní United States nígbànáà. Nínú àwọn ipò wọ̀nyí, Ọlọ́run fi àwọn òtítọ́ ayérayé hàn nípa ẹ̀kọ́ Rẹ̀ nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith.
Ọlọ́run ti fún àwọn ọmọ Rẹ̀ ní ìwà ìṣojú araẹni—agbára láti pinnu àti láti ṣe ìṣe. Ipò tí ó wuni jùlọ fún lílò ìṣojú araẹni náà ni òmìnira àìdẹ́kun fún ẹnìkan láti pinnu àti láti ṣe ìṣe gẹ́gẹ́bí àwọn àṣàyàn olúkúlùkù ọkùnrin tàbí obìnrin wọn. Àyọrísí tí òmìnira yí bá wá ni ìjíyìn, ìfihàn náà ṣàlàyé, nítorí kí “gbogbo ènìyàn lè jíyìn fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ararẹ ní ọjọ́ ìdájọ́” (Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 101:78. “Nítorináà,” Olúwa fihàn pé, “kò tọ́ kí ẹnikẹ́ni wà ní ìgbèkùn ọ̀kan sí ẹlòmíràn” (Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 101:79). Èyí túmọ̀ sí pé ó hàn gbàngba pé ìkónilẹ́rú ènìyàn jẹ́ àṣìṣe. Àti pé gẹ́gẹ́bí irú ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ kannáà, kò bójúmu fún ọmọ ìlú láti máṣe ní ohùn ní yíyan àwọn olórí wọn tàbí ṣíṣe àwọn òfin wọn.
ll.
Ìgbàgbọ́ wa pé Òfin-orílẹ̀ èdè United States jẹ́ onimisi àtọ̀runwá kò túmọ̀ sí pé ìfihàn àtọ̀runwa ni ó ṣe àpekọ gbogbo ọ̀rọ̀ àti gbólóhùn-ọ̀rọ̀, bí irú ìpèsè tí ó fúnni ní oye àwọn aṣojú láti ìpínlẹ́ kọ̀ọ̀kan tàbí ọjọ́-orí tó kéréjù.2 Òfin-orílẹ̀ èdè kìí ṣe “ìwé tó tidàgbà ní kíkún,” ni Ààrẹ J. Reuben Clark sọ. “Ní ìlòdi,” ó ṣàlàyé, “a gbàgbọ́ pé ó gbọ́dọ̀ dàgbà kí ó sì gbèrú láti bá àwọn íníló tó nyípadà ti ayé ti ó nlọsíwájú pàdé.”3 Fún àpẹrẹ, àwọn àtúnṣe onímísí mú ìkónilẹ́rú kúrò ó sì fún àwọn obìnrin ní ẹ̀tọ́ láti dìbò. Bákannáà, a kò rí ìmísí ní gbogbo ìpinnu Ilé Ẹjọ́ Gíga Jùlọ tí ó ntúmọ̀ Òfin-orílẹ̀ èdè.
Mo gbàgbọ́ pé Òfin-orílẹ̀ èdè United States ní ó kéré jù àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ àtọrunwá onímísí marun.4
Àkọ́kọ́ ni ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ pé àwọn ènìyàn ni orísun agbára ìjọba. Ní àkókò kan nígbàtí gbogbo àgbáyé rò pé agbára ọba wá látinú ẹ̀tọ́ àtọ̀runwá àwọn ọba tàbí agbára ológun, o jẹ́ ìṣọ̀tẹ̀ ka agbára ọba sí àwọn ènìyàn. Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ti ṣe àgbàwí èyí, ṣùgbọ́n Òfin-ìlú United State ni àkọ́kọ́ láti lò ó. Agbára ọba nínú àwọn ènìyàn kò túmọ̀ sí pé àwọn àgbájọ ẹ̀nìyàn búburú tàbí àwọn ẹgbẹ́ ènìyàn míràn lè dásí tàbí mú ìjọba nípá láti ṣe ìṣe. . Òfin-orílẹ̀ èdè gbé òfin olómìnira tiwantiwa kalẹ̀, níbití àwọn ènìyàn ti nlo agbára wọn nípasẹ̀ àwọn aṣojú tí wọ́n yàn.
Ìkejì ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ onimisi ni pípín agbára fífúnni ní àárín orílẹ̀-èdè àti àwọn ìpínlẹ̀ olùrànlọ́wọ́ rẹ̀. Nínú ètò àpapọ̀ wa, ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ tí kò sí irú rẹ̀ rí yí ni a ti fìgbàmíràn yíkúrò nípasẹ̀ àwọn àtúnṣe onimisi, bí irú àwọn tí ó mú ikónilẹ́rú kúrò àti nínawọ́ ìbò sí àwọn obìnrin, bí a ti sọ tẹ́lẹ̀. Nípàtàkì, Òfin-Orílẹ̀ èdè United States dẹ́kun ìjọba ti orìlẹ̀-ède láti lo àwọn agbára tí a fúnni kíákíá tàbí nípa lílọ́wọ́ nínu nkan, ó sì fi gbogbo àwọn agbára ìjọba míràn pamọ́ “sí àwọn ìpìnlẹ̀ níkọ̀ọ̀kan tàbí sí àwọn ènìyàn.”5
Ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ onimisi míràn ni yíyapa agbára. Ní sẹ́ntúrì kan ó lé ṣíwájú Àpèjọ ti Òfin-ìlú 1787, Òyìnbó Ìgbìmọ̀-ìjọba lànà ìyapa àṣẹ ti aṣòfin àti aláṣẹ nígbàtí wọ́n bá jìjàkadì àwọn agbára kan pàtó látọ̀dọ̀ ọbá. Ìmísí inú àpèjọ Amẹ́ríkà ni láti fúnni ní òmìnira aláṣẹ, aṣòfin, àti àwọn agbára onídájọ́ kí àwọn ẹ̀ka mẹ́ta wọ̀nyí lè lo àyẹ̀wò lórí arawọn.
Ìkẹ́rin ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ onímisí wà nínú àkópọ̀ ìṣedúró pàtàkì ti ẹ̀tọ́ olúkúlùkù àti ìdẹ́kun lórí àṣẹ ìjọba nínú Ìwé ti àwọn Ẹ̀tọ́, tí a gbà ní ọdún mẹ́ta péré lẹ́hìn tí Òfin-orílẹ̀ èdè bẹ̀rẹ̀. Ìwé ti àwọn Ẹ̀tọ́ kan kò jẹ́ titun. Nihin ìmísí wà nínú ṣíṣe ìmúṣe àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ tí a lànà ní England, bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Magna Carta. Àwọn olùkọ̀wé Òfin-Orílẹ̀ èdè ní ìfaramọ́ pẹ̀lú ìwọ̀nyí nítorí àwọn kan lára ìṣàkóso ìletò ní irú ìṣedúró bẹ́ẹ̀.
Láìsí Ìwé ti àwọn Ẹ̀tọ́ kan, Amẹ́ríkà kò lè ti sìn bí orílẹ̀-èdè agbàlejò fún ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere, èyí tí ó bẹ̀rẹ̀ ní dẹkédì mẹ́ta péré lẹ́hìnnáà. Ìmísí àtọ̀runwá wa nínú ìpèsè àtilẹ̀wá pé kò gbọ́dọ̀ sí ìdánwò ẹ̀sìn fún ibi-iṣẹ́ gbangba,6 ṣùgbọ́n àfikún ominira ẹ̀sìn àti àìgbẹ́kalẹ̀ ìṣedùró nínú Àtúnṣe Àkọ́kọ́ ṣe kókó. Bákannáà a rí ìmísí tọ̀run nínú Àtúnṣe Àkọ́kọ́ ominira ọ̀rọ̀ àti ìgbéròhìnjáde àti nínú àwọn ààbò araẹni tí ó wà nínú àwọn àtúnṣe miràn, bíiti irú ìbániṣẹjọ́ ọ̀daràn.
Ikarun àti ìgbẹ̀hìn, mo rí ìmísí tọ̀run nínú kókó èrèdí gbogbo Òfin-orílẹ̀ èdè. Wọ́n njọba lórí wa nípa òfin kìí ṣe nípa olúkúlúkù, àti ìṣòdodo wa sí Òfin-orílẹ̀ èdè náà àti àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ rẹ̀ àti ìṣètò, kìí ṣe sí eyikeyi olùdìmú ibi-iṣẹ́. Ní ọ̀nà yí, gbogbo ẹni níláti baradọ́gba níwájú òfin. Ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ wọ̀nyí tako àwọn ìlépa agbára tó nṣe tinu ararẹ̀ tí ó ti ba ìjọba tiwantiwa jẹ́ ní àwọn orílẹ̀-èdè kan. Bákannáà wọ́n túmọ̀ sí pé kò sí ọ̀kankan lára àwọn ẹ̀ka mẹ́ta ìjọba tí ó níláti jẹ́ olùdarí lórí àwọn míràn tàbí dènà àwọn míràn nínú ṣíṣe àwọn ìṣe títọ́ òfin-ìlú wọn láti ṣe àyẹ̀wo ẹlòmíràn.
lll.
Bí ó tilẹ̀jẹ́pé àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ onimisi àtọ̀runwá ni Òfin-Orílẹ̀ èdè United States, bí a ti lòó nípasẹ̀ àwọn aláìpé ènìyàn kíkú wọn kò tíì gbé èrò àtilẹ̀wá jáde nígbàgbogbo. Àwọn Àkórí pàtàkì òfin-ṣíṣe, bíiti àwọn òfin tí ó ndarí ìbáṣepọ̀ ẹbí, ni ìjọba àpapọ̀ ti gbà lọ́wọ́ àwọn ìpínlẹ̀. Àtúnṣe Àkọ́kọ́ gba ìṣedúró òmìnira sísọ̀rọ̀ tí ó fi ìgbàmíràn jẹ́ ìdàrúdàpọ̀ nípasẹ̀ ìbonimọ́lẹ̀ àìlókìkí ìsọ̀rọ̀. Ẹkọ́-ìpìlẹ̀ ìyapa àwọn agbára ti wà lábẹ́ ìtẹ̀mọ́lẹ̀ pẹ̀lú ìṣá àti ìṣàn ẹ̀ka ìjọba kan ní lílo tàbí dídádúró àwọn agbára tí a fún ẹlòmíràn.
Àwọn ìdẹ́rùbani míràn tí ó tàbùkù àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ Òfin-ìlú United States wà. Ìdàgbà Òfin-ìlú ndínkù nípasẹ̀ ìtiraka láti rọ́pò àwọn ìtẹ́sí àwùjọ bí èrèdí fún ìdásílẹ̀, dípò ominira àti ìjọba-araẹni. Àṣẹ Òfin-orílẹ̀ èdè ni a mú yẹpẹrẹ láti ọwọ́ àwọn tí ó wọnú ẹgbẹ́ tàbí òṣìṣẹ́ tí wọ́n pa àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ti. Iyì àti agbára Òfin-orílẹ̀ ède ndínkù láti ọ̀dọ̀ àwọn tí ó tọ́ka si bíiti ìdánwò ìṣòdodo tàbí àsọgbè òṣèlú, dípò ipò gíga rẹ̀ bí orísun pípàṣẹ àti ìdẹ́kun fún àṣẹ ìjọba.
IV.
Ìgbàgbọ́ wa ninú ìmísí tọ̀run fún àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ní ojúṣe àìláfiwé láti dìmú àti láti dá ààbò bo Òfin-Orílẹ̀ èdè United States àti àwọn ẹ̀kọ́-ìpìlẹ̀ ti òfin-orílẹ̀ èdè níbikíbi tí a bá ngbé. A gbọ́dọ̀ ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa ki a sì ní ìgbàgbọ́ nínú àti kí a jẹ́ dídára nípa ọjọ́ ọ̀la orílẹ̀-èdè.
Kíni àwọn olotitọ Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn tún níláti ṣe? Bákannáà a gbọ́dọ̀ gbàdúrà kí Olúwa bùkún kí ó sì tọ́ gbogbo orílẹ̀-èdè àti olórí wọn sọ́nà. Èyí ni ara nkan ìgbàgbọ́ wa. Wíwà lábẹ́ àwọn ààrẹ tàbí olórí7 bẹ́ẹ̀náà kò dúró bí ìdènà sí àtakò àṣẹ tàbí ìṣètò olúkúlùkù. Ó túmọ̀ sí pé a níláti lo okun wa ni ìmòye àti àláfíà, ní àárín ìlànà àwọn òfin-orílẹ̀ èdè wa àti lílo àwọn àṣẹ. Lórí ìjàdù àwọn ọ̀ràn, a níláti lépa láti ní ìrẹ́pọ̀ àti ìwọ̀ntún-wọ̀nsì.
Àwọn ojúṣe míràn tí ó jẹ́ ara dídi Òfin-orílẹ̀ èdè onimisi mú. A níláti kọ́ kí a sì ṣe àgbàwí ìmísí àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ti Òfin-orílẹ̀ èdè. A níláti wá láti ti àwọn ènìyàn rere àti ọlọgbọn lẹ́hìn tí yíò ti àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ lẹ́hìn nínú àwọn ìṣe gbangba.8 Àwọn ojúṣe wọ̀nyí fi wá sí níní ìmọ̀ àwọn ọmọ-ìlú tí ó láápọn ní mímú okun wa sí ìmọ̀ara nínú àwọn ètò ìmoye.
Ní United State àti àwọn ìjọba tiwantiwa míran, okun òṣèlú ni à nlò nípa lílọ fún ipò-iṣẹ́ (èyí tí a gbàníyànjú), nípa dídìbò, nípa ìtìlẹhìn ìṣúná-owó, nípa jíjẹ́-ọmọ ẹgbẹ́ àti iṣẹ́-ìsìn nínú àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú, àti nípa ìbánisọ̀rọ̀ tó nlọ lọ́wọ́ sí àwọn òṣìṣẹ́, ẹgbẹ́, àti olùwọgbẹ́. Láti ṣiṣẹ́ dáradára, ìjọba tiwantiwa nílò gbogbo ìwọ̀nyí, ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ ọmọ-ìlú tí ó ní ẹ̀rí-ọkàn kò nìlò láti pèsè gbogbo wọn.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀ràn òṣèlú, àti àìsí ẹgbẹ́ kankan, pẹpẹ, tàbí olúkúlùkù olùwọgbẹ́ tí ó lè tẹ́ gbogbo ààyò araẹni lọ́run. Nítorínáà ọmọ-ìlú kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ pinnu ọ̀ràn èyí tí ó ṣe pàtàkì jùlọ. Nígbànáà àwọn ọmọ-ẹgbẹ́ níláti wá ìmísí lórí bí wọn ó ti lo okun wọn gẹ́gẹ́bí ààyò olúkúlùkù. Ètò yí kò ní rọrùn. Ó lè fẹ́ ìyípadà ìtìlẹhìn ẹgbẹ́ tàbí àwọn àṣàyàn olùwọgbẹ́, àní láti ìdìbò sí ìdìbò.
Irú àwọn òmìnira ìṣe bẹ́ẹ̀ nígbàmíràn yíò fẹ́ àwọn olùdìbò láti ti olùwọgbẹ́ lẹ́hìn tàbí àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú tàbí pẹpẹ wọnnì tí àwọn ipò míràn kò lè fọwọ́sí.8 Ìyẹn ni èrèdí kan tí a fi ngba àwọn ọmọ-ìjọ níyànjú láti mú dídá arawa lẹ́jọ́ ní àwọn ọ̀ràn ìṣẹ̀lú kúrò. A kò gbọ́dọ̀ tẹnumọ rárá pé àwọn olótítọ́ Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ko lè wa ní ẹgbẹ́ kan pàtó tàbí dìbò fún olùwọgbẹ́ kan pàtó. À nkọ́ àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ títọ́ àti fífi àwọn ọmọ ìjọ wa sílẹ̀ láti yan ohun tó ṣe kókó sí wọn jùlọ àti lílo àwọn ẹ̀kọ́ ípìlẹ̀ wọnnì lórí àwọn ọ̀ràn láti ìgbà sí ìgbà. Bákannáà a tẹnumọ, a sì ní kí àwọn olórí ìbílẹ̀ tẹnumọ, pé kí àwọn àṣàyàn àtí ìsopọ̀mọ́ máṣe jẹ́ àkórí àwọn ìkọ́ni tàbí àgbàwí ní èyíkéyí àwọn ìpàdé Ìjọ.
Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn yíò, bẹ́ẹ̀ni, lo ẹ̀tọ́ rẹ̀ láti bọwọ́lù tàbí tako àwọn kókó àbá òfin tí a rò pé ó tako lílo òmìnira ẹ̀sìn tàbí ìfẹ́ pàtàkì ti àwọn ìṣètò Ìjọ.
Mo jẹri nípa Òfin-Orílẹ̀ èdè onimisi àtọ̀runwá tì Amẹ́ríkà mo sì gbàdúrà pé kí àwa tí a da Jíjẹ́ Àtọ̀runwá ẹni tí ó mísii mọ̀ yíò gbéniga nígbàgbogbo yíò sì dá ààbò bo àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ nlá rẹ̀. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.