Àwọn Tálákà Kékeré
Ninu wọ́ọ̀dù ati ẹ̀ka kọ̀ọ̀kan a nílò gbogbo ènìyàn—àwọn tí ó lè jẹ́ alágbára àti àwọn tí ntiraka. Gbogbo wọn ṣeéṣe
Bí ọmọdékùnrin kan, mo rántí wíwakọ̀ nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ pẹ̀lú bàbá mi tí a sì rí àwọn ènìyàn kọ̀ọ̀kan ní òpópónà tí wọ́n ti bá ara wọn ní àwọn ipò tí ó nira tàbí tí wọn nílò ìrànlọ́wọ́. Bàbá mi máa nfi ìgbàgbogbo sọ pé “Pobrecítò,” èyítí ó túmọ̀ sí “tálákà kékeré kan.”
Lẹ́ẹ̀kọ̀kan, mo máa nwò pẹ̀lú ìfẹ́ bí bàbá mi yíò ṣe ran ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn ènìyàn wọ̀nyí lọ́wọ́, ní pàtàkì nígbàtí a bá rin ìrìn-àjò lọ sí Mexico láti wo àwọn òbí mi àgbà. Òun máa nsábà wá ẹnìkan tí ó wà ní ipò àìní àti lẹ́hìnnáà yío lọ ní àṣírí yío sì pèsè ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n nílò. Mo mọ̀ lẹ́hìnáà pé ó nṣe ìrànlọ́wọ́ fún wọn láti fi orúkọ sílẹ̀ ní ilé-ìwé, ra oúnjẹ díẹ̀, tàbí pèsè ní ọ̀nà kan tàbí òmíràn fún ìlera wọn. Ó nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún “tálákà kékeré” kan tí ó bá kọjá ní ọ̀nà rẹ̀. Ní òtítọ́, ní àwọn ọdún ìdàgbà mi èmi kò lè rántí àkókò kan nígbàtí a kò ní ẹnìkan tí ó ngbé pẹ̀lú wa tí ó nílò ibìkan láti gbé bí wọ́n ṣe ndi ẹnití ó le gbẹ́kẹ̀lé ara wọn. Wíwo àwọn ìrírí wọ̀nyí ṣẹ̀dá ẹ̀mí àánú nínú mi sí ènìyàn ẹlẹgbẹ́ mi àti fún àwọn tí ó ṣe aláìní.
Nínú Wàásù Ìhìnrere Mi ó sọ pé: “Àwọn ènìyàn yíi yín ká. Ẹ nkọjá wọn ní òpópó ọ̀nà, ẹ nṣe àbẹ̀wò sí wọn ní ilé wọn, ẹ sì nrin ìrìn-àjò larin wọn. Gbogbo wọn jẹ́ àwọn ọmọ Ọlọ́run, àwọn arákùnrin àti arábìnrin yín. … Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn wọ̀nyí nwa ìdí ní ìgbésí ayé. Wọ́n jẹ́ àníyàn fún ọjọ́ iwájú wọn àti àwọn ìdílé wọn” (Wàásù Ìhìnrere Mi: Atọ́nà kan sí Iṣẹ́ Ìsìn Ìránṣẹ́ Ìhìnrere [2018], 1).
Jákèjádò àwọn ọdun nígbà sísìn ninú Ìjọ, mo ti gbìyànjú láti wá àwọn tí ó nílò ìrànlọ́wọ́ nínú ìgbésí ayé wọn, níti ara àti ti ẹ̀mí. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà mo gbọ́ ohùn bàbá mi wípé, “Pobrecito,” tálákà kékeré kan.
Nínú Bíbélì a rí àpẹrẹ àgbàyanu ti ìtọ́jú fún tálákà kékeré kan:
“Njẹ́ Pétérù òun Jòhánnù jùmọ̀ ngòkè lọ sí tẹ́mpìlì ní wákàtí àdúrà, tí íṣe wákàtí kẹsan ọjọ́.
“Nwọ́n sì gbé ọkùnrin kan tí ó yarọ láti inú ìyá rẹ̀ wá, tí nwọ́n ímá gbé kalẹ̀ ní ojoójumọ́ ní ẹnu-ọ̀nà tẹ́mpìlì tí à npè ní Dáradára, láti máa ṣagbe lọ́wọ́ àwọn tí nwọ inú tẹ́mpìlì lọ;
“Nígbàtí ó rí Pétérù òun Jòhánnù bí nwọ́n ti fẹ́ wọ inú tẹ́mpìlì, ó ṣagbe.
“Pétérù, sì tẹjúmọ́ ọ pẹ̀lú Jòhánnù, ó ní, Wò wá.
“Ó sì fiyèsí wọn, ó nretí àti rí nkan gbà lọ́wọ́ wọn.
“Nígbà náà Pétérù wípé, Fàdákà àti wúrà èmi kò ní; ṣùgbọ́n ohun tí mo ní èyínì ni mo fifún ọ: Ní orúkọ Jésù Krístì ti Násárẹ́tì dìde kí o sì máa rìn.
“Ó sì fà á lí ọwọ́ ọ̀tún, ó sì gbé e dìde: lí ojúkannà ẹsẹ̀ rẹ̀ àti egungun kókósẹ́ rẹ̀ sì mókun” ( (Iṣe Awọn Aposteli 3: 1-7; a fi àtẹnumọ́ kun).
Ní kíka ìwé àkọọ́lẹ̀ yi, mo ní ìdìtẹ̀ nipa lilo ọrọ náà tẹjúmọ́. Ọrọ̀ náà tẹjúmọ́ túmọ̀ sí láti darí ojú, ìrònù ẹni, tàbí láti wò tààrà fún ìdí kan (wo “tẹjúmọ́,” Dictionary.com). Bí Pétérù ti wo ọkùnrin yi, ó rí i yàtọ̀ rẹ̀ sí àwọn miràn. Ó wò kọjá àìlágbára láti rìn àti àwọn àìlera rẹ̀ ó sì lè lo òye rẹ̀ pé ìgbàgbọ́ rẹ̀ tó láti mú un láradá kí ó sì wọ inú tẹ́mpìlì láti gba àwọn ìbùkún tí ó nwá.
Mo ṣe àkíyèsí pé ó mú u ní ọwọ́ ọ̀tún ó sì gbé e dìde. Bí ó ti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọkùnrin náà ní ọ̀nà yí, Olúwa gba ọ̀nà ìyanu wò ó sàn, àti pé “àwọn ẹsẹ̀ àti egungun kókósẹ̀ rẹ̀ mókun” (Ìṣe Àwọn Àpóstélì 3:7). Ìfẹ́ rẹ̀ fún ọkùnrin yi àti ìfẹ́ inú láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún u fa àlékún agbára àti ipá nínú ọkùnrin tí ó jẹ́ aláìlera.
Lakoko ti mo nsìn bi Adọrin Agbegbe, mo fi alẹ́ Ọjọ́rú kọ̀ọ̀kan sílẹ̀ láti ṣe àwọn àbẹ̀wò iṣẹ́-ìránṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ààrẹ èèkàn ní agbègbè iṣẹ́ ìríjú mi. Mo pè wọ́n láti pinnu ìpàdé pẹ̀lú àwọn wọ̀nni tí wọ́n nílò ìlànà ìhìnrere ti Jésù Kristi tàbí àwọn tí wọn kò pa àwọn májẹ̀mú tí wọn ti ṣe mọ́ lọ́wọ́lọ́wọ́. Nípasẹ̀ ṣíṣe iṣẹ́-ìránṣẹ́ wa léraléraati pẹ̀lú èrò inú, Olúwa ṣe àmútóbi awọn ìgbìyànjú wa, àti pé a ní ànfàní láti ṣe àwárí àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan àti àwọn ẹbí tí wọ́n ṣe aláìní. Ìwọ̀nyí ni “àwọn tálákà kékeré” tí wọ́n ngbé ní àwọn oriṣiriṣi èèkàn níbití a ti sìn.
Ní àkókò kan, mo tẹ̀lé Ààrẹ Bill Whitworth, ààrẹ ti Èèkàn Sandy Canyon View, láti ṣe àwọn àbẹ̀wò iṣẹ́-ìránṣẹ́. Ò gba àdúrà nípa ẹnití ó yẹ kí a bẹ̀wò, ní ìgbìyànjú láti ni ìrírí kanná bíi ti Néfì, ẹnití “a darí nípa Ẹ̀mí, láìmọ tẹ́lẹ̀ àwọn ohun ti [ó] lè ṣe” (1 Néfì 4:6). Ó ṣe àfihàn pé bí a ti nṣe ìránṣẹ́, ó yẹ kí a lè dari wa nípa ìfihàn sí àwọn tí wọ́n wà nínú àìní jùlọ, ní ìlòdì sí mímú orúkọ kan ṣá tabi síṣe àbẹwo awọn enikọọkan lọ́nà tí a ti ṣètò. Ó yẹ kí a darí wa nípasẹ̀ agbára ìmísí.
Mo rántí lílọ sí ilé ọ̀dọ́ tọkọtaya kan, Jeff àti Heather, àti ọmọkùnrin wọn kékeré, Kai. Jeff dàgbà sókè bí aláapọn ọmọ ìjọ. O jẹ eléré-ìdárayá ti ó ní ẹ̀bùn púpọ̀ ó sì ní iṣẹ́ ti ó ṣeé gbẹ́kẹ̀lé. Ó bẹ̀rẹ̀ sí yẹ̀ kúrò nínú ijọ ni awọn ọdún ọdọ rẹ. Lẹ́hìnnáà, ó wà nínú ìjàmbá ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan, èyítí ó yí ọ̀nà ìgbésí ayé rẹ̀ padà. Bí a ṣe wọ ilé wọn tí a mọ ara wa, Jeff bèèrè lọ́wọ́ wa ìdí tí a fi wá láti wo ẹbí òun. A dáhùn pé ó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta àwọn ọmọ ijọ 3,000 tí wọ́n ngbé láarin àwọn ààlà èèkàn náà. Nígbànáà ni mo bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀, “Jeff, nínú gbogbo àwọn ilé tí a lè ti ṣèbẹ̀wò ní alẹ́ yi, sọ fún wa ìdí tí Olúwa fi ránwa wá sí ibí yi.”
Pẹ̀lú èyí, Jeff di ẹnití ó ní ẹ̀dùn-ọkàn ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àjọpín díẹ̀ nínú àwọn ìṣòro rẹ̀ pẹ̀lú wa àti díẹ̀ nínú àwọn ọ̀ràn tí wọ́n ntiraka pẹlu bíi ẹbi. A bẹ̀rẹ̀ láti ṣe àjọpín oríṣiríṣi àwọn ìlànà ìhìnrere ti Jésù Krístì. A pè wọ́n láti ṣe àwọn ohun díẹ̀ kan pàtó tí ó lè dàbí ẹni pé ó jẹ́ ìpènijà ní àkọ́kọ́ ṣùgbọ́n ni àìpẹ́ tí yíò mú ayọ̀ àti ìdùnnú nlá wá fún wọn. Lẹ́hìnnáà Ààrẹ Whitworth fún Jeff ní ìbùkún oyè àlùfáà láti ràn án lọ́wọ́ láti borí àwọn ìpènijà rẹ. Jeff àti Heather gbà láti ṣe ohun tí a pè wọ́n láti ṣe.
Ní ìwọ̀n ọdún kan lẹ́hìnnáà, ó jẹ́ ànfàní mi láti wo Jeff bí ó ti ri ìyàwó rẹ̀, Heather, bọmi bí ọmọ Ìjo Jésù Krístì ti Àwọn Èniyan Mímọ́ Ọjọ́-Ìkẹhìn. Wọ́n ti npèsè ara wọn sílẹ̀ báyi láti wọ inú tẹ́mpìlì láti fi èdìdí dì bíi ẹbí fún àkókò àti fún gbogbo ayérayé. Ìbẹ̀wò wa yí ọ̀nà ìgbésí ayé wọn padà níti ara àti ti ẹ̀mí.
Olúwa ti wípé:
“Nítorínáà, jẹ́ olõtọ́; dúró ní ipò iṣẹ́ èyítí mo ti yàn fún ọ; ran àwọn aláìlágbára lọ́wọ́, fa ọwọ́ tí ó rọ sókè, kí ẹ sì fi okun fún eékún àìlera.” (Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 81:5).
“Àti ní ṣíṣe àwọn nkan wọ̀nyí ìwọ yíò ṣe rere títóbi jùlọ fún àwọn ẹ̀dá bíi tìrẹ, ìwọ yíò sì mú ìgbéga bá ògo rẹ̀ ẹni tí íṣe Olúwa rẹ” (Ẹ̀kọ ati Awọn Majẹmu 81:4).
Arákùnrin àti arábìnrin, Àpóstélì Páùlù kọ́ni ní ohun pàtàkì kan nínú síṣe iṣẹ́-ìránṣẹ́ wa. Ò kọ́wa pé àwa jẹ́ “ara Krístì, àti àwọn ẹ̀yà ni pàtó” (1 Kọrinti 12:27àti pé a nílò ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan nínú ara láti ríi dáju pé gbogbo ara wà ní ìgbéga. Lẹhinna o kọ otitọ ti o lagbara ti o wọ inu ọkan mi lọkan nigbati mo ka. Ó wípé, “Ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀yà ara wọ̀nnì, tí ó dàbí ẹnipé nwọ́n ṣe àìlera jù, àwọn ni a kò lè ṣe aláìní jù: àti àwọn ẹ̀yà ara wọ̀nnì tí àwa rò pé nwọ̀n ṣe àìlọ́lá jù,, lórí wọ̀nyí li àwa sì , nfi ọlá sí jù” (1 Kọ́ríntì 12:22–23; àtẹnumọ́ àfikún).
Níbí, ní wọ́ọ̀dù àti ẹ̀ka kọ̀ọ̀kan a nílò gbogbo ènìyàn—àwọn tí ó lè jẹ́ alágbára àti àwọn tí ntiraka. Gbogbo wọn jẹ́ dandan wọ́n sì ṣe pàtàkì fún gbígbé gbogbo “ara Krístì” ga. Mo sábà máa nronú nípa tani ẹnití a sọnú nínú onírúurú àpéjọpọ̀ wa tí yóò fún wa lókun àti tí yío sọ wá di odidi.
Alàgbà D. Todd Christofferson kọ́ni: “Nínú Ìjọ a kò ní kọ́ ẹ̀kọ́ tọ̀run nìkan; bákannáà à nní ìrírí ìlò rẹ̀. Bí ara Krístì, àwọn ọmọ Ìjọ nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí ara wọn ní òdodo ìgbé ayé ọjọ́-sí-ọjọ́. Gbogbo wa kó pé. … Nínú ara Krístì, a níláti lọ kọjá àwọn ẹ̀kọ́ àti ọ̀rọ̀ ìgbéga àti kí a ní ‘ọwọ́-lórí’ ìrírí bí a ti nkọ́ láti ‘gbé papọ̀ nínú ìfẹ́’ [Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 42:45]” (“Kínìdí Ìjọ,” Liahona, Nov. 2015, 108–9).
Ní ọdún 1849, Brigham Young lá àlá níbití ó ti rí Wòlí Joseph Smith tí ó nwakọ̀ agbo nlá ti àwọn àgùtàn àti ewúrẹ́. Díẹ̀ nínú àwọn ẹranko wọ̀nyí tóbi wọ́n sì rẹwà; àwọn míràn jẹ́ kékeré àti ẹlẹ́gbin. Brigham Young ràntí pé òun wojú Wòlí Joseph Smith òun sọ pé, “Josefu, ìwọ ti ní agbo ẹran dídárajùlọ… tí èmi ti rí rí ní ìgbésí ayé mi; kí ni ìwọ yóò fi wọ́n ṣe?” Wòlí náà, tí ó dàbí ẹnipé kò bìkítà pẹ̀lú agbo ẹran alaigbọran yi, dáhùn jẹ́jẹ́, “[Brigham,] gbogbo wọn dára ní àwọn ààyè wọn.”
Nígbàtí Ààrẹ Young jí, ó ní òye pé nígbà tí Ìjọ yoo bá ko onírûrú “àwọn àgùtàn àti ewúrẹ́” jọ, ó jẹ́ ojúṣe rẹ̀ láti mú gbogbo wọn wọlé kí ó sì gba ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn láàyè láti mọ agbára wọn ní kíkún bí nwọ́n ti ndi àwọn ipò wọn mú nínú Ijọ. (Adapted from Ronald W. Walker, “Brigham Young: Olùkọ́ ti Wòlíì,” Ensign, Feb. 1998, 56–57.)
Arákùnrin ati arábìnrin, ìpilẹ̀ṣẹ̀ ọ̀rọ̀ mi wá bí mo ṣe ronú jinlẹ̀ nípa ẹnìkan tí kò ṣiṣẹ́ lọ́wọ́lọ́wọ́ nínú Ìjọ ti Jésù Krístì. Ni ìṣẹ́jú kan Èmi yóò fẹ́ láti bá ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn sọ̀rọ̀. Alàgbà Neal A. Maxwell ti kọ́ni pé “irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ máa nfi ìgbà gbogbo wà nítòsí—ṣùgbọ́n wọn kìí kópa ní kíkún ninu—Ìjọ naa. Wọn kì yóò wá sí inú ilé-ìjọsìn, ṣùgbọ́n bẹ́ẹ̀ni wọn kò ní fi ìloro rẹ̀ sílẹ̀. Ìwọ̀nyí ni àwọn tí wọ́n nílò Ìjọ àti tí Ìjọ nílò wọn, ṣùgbọ́n tí wọn, ní apákan, ‘ngbé láìsí Ọlọ́run ní àgbáyé’ [Mosiah 27:31]” (“Kíni Ìdí tí Kò fi Jẹ́ Ìsisìyí?,” Ensign, Nov. 1974, 12).
Emi yíò ṣe àtúnsọ ìfìpè ti olùfẹ́ wa Ààrẹ Russell M. Nelson bí ó ti kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ sí àwọn ọmọ Ìjọ bíi wòlíì wa titun. O wípé: “Nísisìnyí, sí ọ̀kọ̀ọ̀kan ọmọ Ìjọ mo wípé: tẹramọ́ ipa ọ̀nà májẹ̀mú. Ìfaramọ́ yín láti tẹ̀lé Olùgbàlà nípa dídá májẹ̀mú pẹ̀lú Rẹ̀ àti pípa àwọn májẹ̀mú wọ̃nnì mọ́ yíò ṣí ilẹ̀kùn sí gbogbo ìbùkún ti ẹ̀mí àti ànfàní tí ó wà fùn àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin, àti àwọn ọmọdé níbigbogbo.
Lẹ́hìnnáà ó bẹ̀bẹ̀: “Nísisìnyí, tí ẹ bá ti yẹ̀ kúrò ní ipa ọ̀nà náà, njẹ́ kí npè yín pẹ̀lú gbogbo ìrètí tí ó wà ní ọ̀kàn mi láti jọ̀wọ́ padà wá. Ohunkóhun tí àwọn àníyàn yín jẹ́, ohunkóhun tí àwọn ìpènijà yín jẹ́, ìbì kan wà fún yín nínú Ìjọ Olúwa yí. Ìwọ àti àwọn ìran tí a kò tíì bí yíò di alábùkún fún nípa àwọn ìṣe yín nísisìyí láti padà sí ipá ọ̀nà májẹ̀mú” (“Bí A Ti Nlọsíwájú Papọ̀,” or Liahona, Apr. 2018, 7; emphasis added).
Mo jẹ́ ẹ̀ri Rẹ̀, àní Jésù Krístì, Olùkọ́ni oníṣẹ́ ìránṣẹ́ àti Olùgbàlà gbogbo wa. Mo pe ẹnìkọ̀ọ̀kan wa láti wá àwọn “pobrecitojáde,” àwọn “òtòṣì kékèké” ní àárín wa nínú àìní. Èyí ni àdúrà àti ìbùkún mi ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.