Rántí Ọ̀nà Rẹ Padà Sílé
A ní àpẹrẹ pípé láti tẹ̀lé nípa Jésù Krístì, ati pé ìrìn-àjò sí ilé ayérayé wa ṣeé ṣe nìkan nítorí àwọn ẹ̀kọ́ Rẹ, ìgbésí ayé Rẹ, àti ẹbọ ètùtù Rẹ.
Ní 1946, ọ̀dọ́ oluwadi Arthur Hasler n rin ìrìn-àjò lẹgbẹẹ omi-ṣíṣàn òkè kan nítòsí ilé tó ti ṣọmọdékùnrin rẹ̀ nígbàtí ó ní ìrírí tí ó darí sí àwárí pàtàkì nípa bí ẹja ṣe wa ọ̀nà wọn padà sí àwọn odò-ṣíṣàn àbímọ́ wọn.
Rírìn ìrìn-àjò lórí òkè kan, síbẹ̀síbẹ̀ kúrò ní ojú ìṣubú-omi ìṣọmọdé rẹ̀ ti o fẹ́ràn jùlọ, Hasler ni a mú padà lójijì si ìrántí ti o ti gbàgbé. Ó wípé, “Bí afẹ́fẹ́ tútù, tí ó ní òórùn ti mosses ati columbine ṣe gbá àyíká àpáta abúttúmẹ́ntì, àwọn àlàyé ìṣubú-omi yìí àti àgbékalẹ̀ rẹ ní ojú òkè lójijì lọ sí ojú inú mi.”1
Awọn òórùn wọ̀nyí tún sọ àwọn ìrántí àwọn ìgbà èwe rẹ o si ràn an létí ilé.
Bí àwọn òórùn bá lè fa irú àwọn ìrántí bẹ́ẹ̀ fún un, ó ronú pé bóyá àwọn òórùn lè jẹ́ ìtanijí fún irú ẹja nlá kan tí, ó padà si ṣíṣàn gangan ti bíbí wọn, lẹ́hìn àwọn ọdún tí ó ti wa ni ṣíṣísílẹ̀ òkun nla.
Ní ìbámu sí ìrírí yi, Hasler, papọ̀ pẹ̀lú àwọn oluwadi míràn, lọ síwájú láti ṣe àfihàn pé irú ẹja nla kan rántí àwọn òórùn ti yio ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lọ kiri ní ẹgbẹgbẹ̀rún máìlì láti wa ọ̀nà wọn padà sí ilé láti òkun.
Àkọsílẹ̀ yí jẹ́ kí n ronú pé ọ̀kan nínú àwọn ohun pàtàkì jùlọ tí a lè ṣe ní ayé yi ní láti mọ̀ àti láti rántí ipa ọ̀nà padà sí ọ̀dọ̀ Bàbá wa Ọ̀run àti láti fi ìṣòtítọ́ àti yọ̀ farada ìrìn-àjò naa jákèjádò.
Mo ronú àwọn ìránnilétí mẹ́rin pé, nígbàtí a bá lòó tí a sì ṣeé léraléra ninu ayé wa, wọ́n lè sọ àwọn ìmọ̀lára ti ilé wa ọ̀run jí.
Ni àkọ́kọ́, A Lè Rántí Pé A Jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run
A ní ogún ti ọ̀run kan. Mímọ̀ pé àwa jẹ́ ọmọ Ọlọ́run àti pé Ó fẹ́ kí a padà sí iwájú Rẹ jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ lórí ìrìn àjò padà sí ilé wa ọ̀run.
Rán ara rẹ létí nípa ogún yi. Wá àkókò nígbàgbogbo láti ṣe àlékún ètò ìgbéga ẹ̀mí rẹ nípa rírántí àwọn ìbùkún tí o ti gbà látọ̀dọ̀ Olúwa. Gbẹ́kẹ̀lé àwọn ìtọ́sọ́nà ti a ti fún ọ látọ̀dọ̀ Rẹ, dípò kí o yípadà sí ayé nìkan láti wọn ìwúlò ti araẹni rẹ ki o sì wá ọ̀nà rẹ.
Láìpẹ́ mo ṣàbẹ̀wò sí àyànfẹ́ kan lẹ́hìn tí ó ti wà ní ilé-ìwòsàn. Ó sọ fún mi pẹ̀lú ẹ̀dùn ọkàn pé lakoko ti òun dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn ilé-ìwòsàn, gbogbo ohun tí òun fẹ́ ni kí ẹnìkan kọ orin “Ọmọ Ọlọ́run ni mí” fún òun. Ó wípé èrò yẹn nìkan, fún òun ní àlááfíà tí òun nílò ní wákàtí ìpọ́njú náà.
Mímọ ẹni tí ìwọ jẹ́ nyí ohun ti ìwọ ní ìmọ̀lára rẹ àti ohun tí o nṣe padà.
Lílóye ẹni tí ẹ jẹ lotitọ nmúra yín sílẹ̀ ní dídára si láti damọ̀ àti lati rántí ọ̀nà yín padà si ilé yín ọ̀run kí ẹ si yọ́nú láti wà níbẹ̀.
Ìkejì, A Lè Rántí Ìpìlẹ̀ Tí Ó NṢe Ààbò Fún Wa
Okun wa fún wa nígbàtí a bá dúró ní òdodo, òtítọ́, ati olóòtítọ́ sí Bàbá Ọ̀run àti Jésù Krístì, pàápàá nígbàtí àwọn míràn bá fi ìbòmọ́lẹ̀ ṣe àìkàsí sí àwọn òfin àti àwọn ẹ̀kọ̀ ìpìlẹ̀ ìgbàlà2
Nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì, Hẹ́lámánì kọ́ àwọn ọmọ rẹ láti rántí pé wọ́n gbọ́dọ̀ kọ́ àwọn ìpìlẹ̀ wọ́n lè orí Jésù Krístì láti ní agbára láti kojú àwọn ìdánwò ti ọ̀tá. Àwọn ẹ̀fúùfù nlá ati àwọn ìjì Sàtánì n nà wá, ṣùgbọ́n wọn ki yio ní agbára láti fà wá lulẹ̀ tí a bá fi ìgbẹ́kẹ̀lé wa sí ibi ti o ni ààbò jùlọ—nínú Olùràpadà wa.3
Mo mọ́ láti inú ìrírí ti araẹni pé bí a ṣe yàn láti gbọ́ ohun Rẹ àti láti tẹle E, àwa yio gba ìrànlọ́wọ́ Rẹ. Àwa yio gba ìwòye gbígbòòrò ti awọn ipò wa ati òye ti o jinlẹ̀ nípa èrèdí aye. Àwa yio ní ìrírí sísọkutu ẹ̀mi ti yio tọ́wa sọ́nà sílé wa ọ̀run.
Kẹta, A Lè Rántí láti Gbàdúrà Gidi
À n gbé ní àkókò kan pẹ̀lú ìfọwọ́kàn kan tábi pípàṣẹ ohùn, a lè bẹ̀rẹ̀ wíwá àwọn ìdáhùn lórí èyíkeyi kókó-ọ̀rọ̀ nínú àìlópin dátà pípamọ́ láti ìṣètò ní ìyára àti nẹ́tíwọ́ọ̀kì líle ati ẹ̀ka àwọn ayárabíàṣá.
Ní apá keji, a ní ìrọ̀rùn ìfipè láti bẹ̀rẹ̀ wíwá àwọn ìdáhùn láti ọ̀run. “Ẹ gbàdúrà nígbàgbogbo, èmi ó sì dà Ẹ̀mí mi lé yín lórí.” Nígbànáà Olúwa ṣèlérí, “Àti pé títóbi ni ìbùkún yín—bẹ́ẹ̀ni, ju bí ẹ ti ṣe lè gbá ìṣura ní ilẹ̀ ayé.”4
Ọlọ́run mọ ìfura ẹnikọ̀ọ̀kan wa níkíkún Ó sì ṣetán láti fetísí sí àwọn àdúrà wa. Nígbàtí a bá rántí láti gbàdúrà, a ó rí ìfẹ́ Rẹ tó ngbéni dúró, àti bí a ṣe ngbàdúrà si sí Bàbá wa ní Ọ̀run ní orúkọ Krístì, bẹ́ẹ̀ ni a ó ṣe mú Olùgbàlà wá sí ìgbésí ayé wa si àti pé a ó dá ipá-ọ̀nà tí Ó ti sàmì sí sí ile wa ọ̀run mọ̀ dídára jùlọ.
Ẹ̀kẹ́rin, A Lè Rántí lati Sin Àwọn Míràn
Bí a ṣe n gbìyànjú láti tẹ̀lé Jésù Krístì nípa sísìn àti fífi inúrere hàn sí àwọn ẹlòmíràn, a ó sọ ayé di ibi tí ó dára síi.
Àwọn ìṣe wa lè bùkún ayé àwọn ti wọ́n wà ní àyíká wa dáradára ati àwọn ìgbésí ayé tiwa bákannáà. Iṣẹ́-ìsìn ìfẹ́ nṣe àfikún onítumọ̀ sí ìgbésí ayé olùfúnni àti olùgbà.
Máṣe fojú yẹpẹrẹ wo agbára tí o ní láti ní ipa lórí àwọn míràn fún rere, méjèèjí nípasẹ̀ ìsìn àwọn ìṣe rẹ ati nípasẹ̀ iṣẹ́-ìsìn àpẹrẹ rẹ.
Iṣẹ́-ìsìn ìfẹ́ni sí àwọn ẹlòmíràn n ṣe ìtọ́sọ́nà wa ní ọ̀nà sí ilé wa ọ̀run—ọ̀nà lati dà bíi Olùgbàlà wa.
Ní ọdun 1975, nítorí àbájáde ogun abẹ́lé kan, Arnaldo àti Eugenia Teles Grilo àti àwọn ọmọ wọn ní láti fi ilé wọn sílẹ̀ àti gbogbo ohun tí wọ́n ti kójọ nípasẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún iṣẹ́ takuntakun. Ní orílẹ-èdè abínibí wọn ti Portugal, Arákùnrin ati Arábìnrin Teles Grilo dojúkọ ìpèníjà bíbẹ̀rẹ̀ padà lẹ́ẹ̀kansi. Ṣùgbọ́n àwọn ọdún lẹ́hìnnáà, lẹ́hìn ti wọ́n ti darapọ̀ mọ́ Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-Ìkẹhìn, wọn wípé, “A pàdánù ohun gbogbo tí a ní, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ohun tí ó dára nítorí ó fi ipá mú wa láti ronú pàtàkì àwọn ìbùkùn ayérayé.”5
Wọ́n pàdánù ilé wọ́n ní ilé-ayé, ṣùgbọ́n wọ́n wá ọ̀nà láti padà sí ilé wọn ọ̀run.
Ohunkóhun ti ẹ gbọ́dọ̀ fi sílẹ̀ láti tẹ̀lé ipa-ọ̀nà sí ilé yín ọ̀run yíò fi ọjọ́ kan dàbí ẹnipé kò sí ìfarajìn kankan rárá.
A ní àpẹrẹ pípé láti tẹ̀lé nípa Jésù Krístì, ati pé ìrìn-àjò sí ilé ayérayé wa ṣeé ṣe nìkan nítorí àwọn ẹ̀kọ́ Rẹ, ìgbésí ayé Rẹ, àti ẹbọ ètùtù Rẹ—pẹ̀lú ikú Rẹ ati Àjínde ológo Rẹ.
Mo pè yín láti ní ìrírí ayọ̀ ti rírántí pé àwa jẹ́ ọmọ Ọlọ́run àti pé Ó fẹ́ aráyé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí ó rán Ọmọ Rẹ̀6 láti fi ipa-ọ̀nà hàn wá. Mo pè yín láti rántí láti jẹ́ olótítọ́, láti yí ayé yín padà sí ọ̀dọ̀ Olùgbàlà ki ẹ sì kọ́ ìpìlẹ̀ yín lé E. Ẹ rántí láti gbàdúrà gidi nínú ìrìn-àjò yín ati lati sin àwọn míràn lẹgbẹ ọ̀nà.
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin ọ̀wọ́n, ní Ọjọ́ Ìsìn Àjíǹde yí, mo jẹ́rìí pé Jésù Krístì ni Olùràpadà àti Olùgbàlà ayé. Òun ní ẹni ti o le mú wa wá sí tábìlì ìgbésí ayé aláyọ̀ kí ó sì darí wa ní ìrìn-àjò wa. Njẹ́ kí á rántí ki a sì tẹ̀le E délé. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.