Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Kínni Olùgbàlà Wa Ti Ṣe fún Wa?
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2021


Kínni Olùgbàlà Wa Ti Ṣe fún Wa?

Jésù Krístì ti ṣe ohun gbogbo tó ṣe kókó fún ìrìnàjò wa nínú ayé kíkú yi já sí ọ̀nà àyànmọ́ tí a ti là sílẹ̀ nínú ètò ti Baba wa Ọrun.

Nínú ìpàdé ìrọ̀lẹ́ Sátidé kan ní ìpàdé àpapọ̀ èèkàn kan ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́hìn, mo pàdé obìnrin kan tí ó sọ fúnmi pé àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ pè é láti padà wá sínú ìjọ lẹ́hìn ọ̀pọ̀ ọdún ti àìdúró déédé, ṣùgbọ́n kò le ronú ìdí kankan tí òun yío fi ṣe bẹ́ẹ̀. Láti gbà á níyànjú mo sọ pé, “Nígbàtí o bá gbé gbogbo ohun tí Olùgbàlà ti ṣe fún ọ yẹ̀wò, ìwọ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ èrèdí láti padà wá láti jọ́sìn àti láti sìn Ín.” Ó yàmí lẹ́nu nigbàtí ó dáhùn pé, “Kínni Ó ti ṣe fún mi?”

Ìpadabọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì

Kínni Jésù Krístì ti ṣe fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wa? Ó ti ṣe ohun gbogbo tó ṣe kókó fún ìrìnàjò wa nínú ayé kíkú yi já sí ọ̀nà àyànmọ́ tí a ti là sílẹ̀ nínú ètò ti Baba wa Ọrun. Èmi ó sọ̀rọ̀ nípa mẹ́rin nínú àwọn ẹ̀yà patàkì ti ètò náà. Nínú ìkọ̀ọ̀kan àwọn wọ̀nyí, Ọmọ Bíbí Rẹ̀ Kanṣoṣo, Jésù Krístì, jẹ́ kókó àwòrán. Ní síṣe ìwúrí fún gbogbo èyí ni “ìfẹ́ Ọlọ́run, èyítí ó tan ara rẹ̀ ká lóde nínú ọkàn àwọn ọmọ ènìyàn; nítorínã, ó jẹ́ ohun ti o wuni ju gbogbo ohun lọ” (1 Nephi 11:22).

1.

Ní kété ṣaájú Ọjọ́ Ìsinmi Ọdún Àjínde, ó jẹ́ ohun tí ó bá ìgbà mu láti kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa àjínde Jésù Krístì. Àjínde kúrò nínú òkú ni òpó ti ara ẹni ìmudánilójú ti ìgbàgbọ́ wa. Ó nṣe àfikún ìtumọ̀ sí ẹ̀kọ́ wa, ìwúrí sí ìhùwàsí wa, àti ìrètí fún ọjọ́ iwájú wa.

Nítorípé a gba àwọn àpèjúwe inú Bíbélì àti Ìwé ti Mọ́mọ́nì gbọ́ nípa bí àjínde Jésù Krístì ti rí gan, bákannáà a gba onírúurú àwọn ìkọ́ni ti awọn ìwé mímọ́ pé irú àjínde kannáà yío wá sí ọ̀dọ̀ gbogbo ara kíkú tí ó ti gbé rí ní orí ilẹ̀ ayé yi.1 Bí Jésù ti kọ́ni, “Nítorípé èmi yè, ẹ̀yin yío yè bákannáà” (Johanu 14:19 Àpóstélì Rẹ̀ sì kọ́ni pé “a ó jí àwọn òkú dìde ní àìdíbàjẹ́” àti pé “kíkú yi ìbá sì ti gbé àìkú wọ̀” (1 Corinthians 15:52, 54).

Àjínde

Ṣùgbọ́n ajínde nfún wa ju ìdánilójú ti àìkú yi lọ. Ó nṣe àyípadà ọ̀nà tí a fi nwo ayé kíkú.

Àjínde náà nfún wa ní ìgbìrò àti okun láti farada àwọn ìpènijà ayé ikú tí ó dojúkọ ẹnìkọ̀ọkan wa àti àwọn wọnnì tí a fẹ́ràn. Ó nfún wa ní ọ̀nà titun láti wo àwọn àìpé ti ara, ti ọpọlọ, tàbí ti ẹ̀dùn ọkàn tí a ní ní ìgbà ìbí tàbí tí a gbà ní àkókò ayé kíkú. Ó nfún wa ní okun láti fi ara da àwọn ìbànújẹ́, àwọn ìjákulẹ̀, àti àwọn ìrẹ̀wẹ̀sì. Nítorípé ọ̀kọ̀ọ̀kan wa ní ìdánilójú àjínde, a mọ̀ pé àwọn aìpé àti àtakò ayé ikú wọ̀nyí wa fún ìgbà díẹ̀.

Àjínde bákannáà nfún wa ní ìwúrí alágbára kan láti pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́ ní àkókò ìgbé ayé kíkú wa. Nígbàtí a bá dìde kúrò nínú òkú tí a sì tẹ̀síwájú sí ibi ìdájọ́ ìkẹhìn tí a ti sọtẹ́lẹ̀, a fẹ́ kí a ti yege fún àwọn ìbùkún dídára jùlọ tí a ti ṣèlérí fún àwọn ẹ̀dá tó bá jínde.2

A lè gbé bí ẹbí títíláé.

Ní àfikún, ìlérí pé àjínde ná lè ní ànfàní láti wà pẹ̀lú àwọn ọmọlẹ́bí—ọkọ, ìyàwó, àwọn ọmọ, àwọn òbí, àti àwọn ìran tó nbọ̀—jẹ́ ìyànjú tó lágbára kan láti mú àwọn ojúṣe ẹbí wa ṣẹ nínú ayé kíkú. Ó nrànwá lọ́wọ́ bákannáà láti gbé papọ̀ nínú ìfẹ́ ní ayé yi, ó sì ntù wá nínú ní àkókò ikú àwọn olólùfẹ́ wa. A mọ̀ pé àwọn ìyapa ayé kíkú wọ̀nyí jẹ́ fún ìgbà díẹ̀, a sì nfojú sọ́nà fún àwọn ìdàpọ̀ àti àwọn ìbáṣepọ̀ aláyọ̀ ọjọ́ iwájú. Àjínde npèsè ìrètí àti okun fúnwa láti ní sùúrù bí a ti ndúró. Ó tún nmura wa sílẹ̀ pẹ̀lú ìgboyà àti ọ̀wọ̀ láti kojú ikú tiwa—àní ikú kan tí ó ṣeéṣe kí a pè ní àìtọ́jọ́.

Gbogbo àwọn àbájáde wọ̀nyí ti àjínde jẹ́ apákan ìdáhùn àkọ́kọ́ sí ìbéèrè “Kíni Jésù Krístì ti ṣe fún mi?”

ll.

Fún púpọ̀jù nínú wa, ànfàní láti jẹ́ dídáríjì fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa ni ìtumọ̀ títóbijù sí Ètùtù ti Jésù Krístì. Nínú ìjọsìn, a máa nfi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ kọrin:

Ẹ̀jẹ̀ Rẹ̀ iyebíye ni ó dà sílẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́

Ayé rẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́ ló fúnni,

Ìrúbọ àìlẹ́ṣẹ̀ kan fún ẹ̀bi,

Ayé tó nkú lọ láti gbàlà.3

Olùgbàlà àti Olùrapadà wa fi ara da ìjìyà àìní-òye láti di ìrúbọ kan fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ti gbogbo ara kíkú tí ó bá ronúpìwàdà. Ètùtù ìrúbọ yi fúnni ní òpin rere, ọ̀dọ́ àgùtàn mímọ́ láìsí àbàwọ́n, fún òpin ìwọ̀n ti ibi, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ti gbogbo aráyé. Ó ṣí ìlẹ̀kùn náà fún ìkọ̀ọ̀kan wa láti di wíwẹ̀nù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ti ara ẹni wa, kí a le gbà wá padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, Baba wa Ayérayé. Ìlẹ̀kùn ṣíṣí yi wà fún gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run. Nínú ìjọsìn, a nkọrin:

Mo ní ìyàlẹ́nu pé yío sọ̀kalẹ̀ láti orí ìtẹ́ rẹ̀ ti ọ̀run

Láti gba ọkàn ọlọ́tẹ̀ àti agbéraga bíi tèmi,

Pé yio nawọ́ ìfẹ́ nlá rẹ̀ sí irú ẹni bíi èmi.4

Àyọrísí títóbi àti àìní-òye ti Ètùtù Jésù Krístì dá lórí ìfẹ́ Ọlọ́run fún ìkọ̀ọ̀kan wa. Ó fi ìdí ìkéde Rẹ̀ múlẹ̀ pé “iye ti àwọn ọkàn”—ti olukúlùkù gbogbo ẹ̀dá kíkú—”jẹ́ títóbi ní ojú Ọlọ́run” (Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 18:10). Nínú Bíbélì, Jésù Krístì ṣàlàyé èyí nínú ọ̀ràn ìfẹ́ Baba wa Ọ̀run: “Nítorí Ọlọ́run fẹ́ aráiyé tóbẹ́ẹ́ gẹ́, tí ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kanṣoṣo fúnni, pé ẹnikẹ́ni tí ó bá gbàá gbọ́ má bàá ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”(Johanu 3:16). Nínú ìfihàn ti òde òní, Olùrapadà wa, Jésù Krístì kéde pé Òun “fẹ́ràn aráyé tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi ayé tirẹ̀ sílẹ̀, pé kí iye àwọn tí wọ́n bá gbàgbọ́ le di ọmọ Ọlọ́run” (Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 34:3).

Njẹ́ ó ha jẹ́ ìyàlẹ́nu, nígbànáà, pé Ìwé ti Mọ́mọ́nì, “Ẹrí Miràn ti Krístì,” parí pẹ̀lú ìkọ́ni pé láti jẹ́ “pípé” àti “mímọ́ nínú Krístì,” a gbọdọ̀ “fẹ́ Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo agbára, inú àti okun” [wa]”? (Mómónì 7:27–28). Èrò Rẹ̀ tí a fún ní ìwúrí nípa ìfẹ́ gbọdọ̀ jẹ́ gbígbà pẹ̀lú ìfẹ́.

lll.

Kí tún ni Olùgbàlà wa, Jésù Krístì, ti ṣe fún wa? Nípasẹ̀ àwọn ìkọ́ni ti àwọn wòlíì Rẹ̀ àti nípasẹ̀ iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti ara ẹni Rẹ̀, Jésù kọ́ wa ní ètò ìgbàlà. Nínú ètò yi ni Ìṣẹ̀dá, èrèdí ìgbé ayé, jíjẹ́ dandan ti àtakò, àti ẹ̀bùn ti ìṣojú ara ẹni. Ó tún kọ́wa ní àwọn òfin àti àwọn májẹ̀mú tí a gbọdọ̀ gbọ́ràn sí àti àwọn ìlànà tí a gbọdọ̀ ní ìrírí láti mú wa padà sí ọ̀dọ̀ àwọn òbí wa Ọrun.

Ìwàásùn lórí Òkè

Nínú Bíbélì a ka ìkọ́ni Rẹ̀ pé, “Èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé: ẹni tí ó bá tẹ̀lé mi kò ní rìn nínú òkùnkùn, ṣùgbọ́n yíò ní ìmọ́lẹ̀ ìyè” (Johanu 8:12). Àti nínú ìfihàn ti òde òní a kà pé, “Kyèsíi, èmi ni Jésù Krístì, … ìmọ́lẹ̀ kan tí a ko le fi pamọ́ nínú òkùnkùn” (Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 14:9). Bí a bá tẹ̀lé àwọn ìkọ́ni Rẹ̀, Òun nfi ìmọ́lẹ̀ sí ipa ọ̀nà wa ní ayé yi àti ìdánilójú àyànmọ́ wa ní èyí tí nbọ̀.

Nítorípé Ó fẹ́ràn wa, Ó npè wá níjà láti fojú sùn sí Òun dípò sí àwọn ohun ti ayé kíkú yi. Nínú ìwàásù nlá Rẹ̀ lórí oúnjẹ ìyè, Jésù kọ́ni pé kí a máṣe wà láàrin àwọn wọnnì tí nfà púpọ̀ jùlọ sí àwọn ohun tí ayé—àwọn ohun tí nṣe àtilẹhìn fún ìyè lórí ilẹ̀ ayé ṣùgbọ́n tí kò fúnni ní ìtọ́jú sí ìhà ìyè ayérayé.5 Bí Jésù ti npè wá lẹ́ẹ̀kan àti lẹ́ẹ̀kan àti lẹ́ẹ̀kansíi, “Tẹ̀lé mi.”5

IV.

Ní ìparí, Ìwé ti Mọ́mọ́nì nkọ́ni pé bíi apákan Ètùtù Rẹ̀ Jésù Krístì “jìy[à] ìrora àti àwọn ìpọ́njú àti àdánwò onírurú; èyítí ó rí bẹ̃ kí ọ̀rọ̀ nã lè ṣẹ, èyítí ó wípé yíò gbé ìrora àti àìsàn àwọn ènìyàn rẹ̀ lé ara rẹ̀” (Alma 7:11).

Kínni ṣe tí Olùgbàlà wa jìyà àwọn ìpèníjà “onírúurú” ti ayé kíkú wọ̀nyí? Álmà ṣàlàyé, “Òun yíò sì gbé gbogbo àìlera wọn lé ara rẹ̀, kí inú rẹ̀ lè kún fún ãnú, nípa ti ara, kí òun kí ó lè mọ̀ nípa ti ara bí òun yíò ṣe ran àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ́wọ́ [èyítí ó túmọ̀ sí láti tù lára tàbí fún ní àtìlẹ́hìn] nínú gbogbo àìlera wọn” (Alma 7:12).

Krísti ní Gẹ́tsémánì

Olùgbàlà wa ní ìmọ̀lára Ó sì mọ àwọn àdánwò wa, àwọn ìtiraka wa, àwọn ìrora ọkàn wa, àti ìjìyà wa, nítorí Ó fi tìfẹ́tìfẹ́ ní ìrírí gbogbo wọn bíi apákan Ètùtù Rẹ̀. Àwọn ìwé mímọ́ miràn tẹnumọ́ èyí. Májẹ̀mú titun kéde pé, “Nítorí níwọ̀nbí òun tìkararẹ̀ ti jìyà nípa ìdánwò, Ó le ran àwọn tí a ndánwò lọ́wọ́” (Hebérù 2:18). Isaiah kọ́ni pé, “Má bẹ̀rù; nítorí èmi wà pẹ̀lú rẹ: … èmi yio fún ọ lókun; bẹ́ẹ̀ni, èmi yio ràn ọ́ lọ́wọ́” (Isaiah 41:10). Gbogbo ẹnití njìyà èyíkeyi irú àwọn àìpé kan níláti rántí pé Olùgbàlà wa ní ìrírí irú ìrora bẹ́ẹ̀ bákannáà, àti pé nípasẹ̀ Ètùtù Rẹ̀, Ó nfún ẹ̀nìkọ̀ọ̀kan wa ní okun láti gbé e.

Wòlíì Joseph Smith ṣe àkópọ̀ gbogbo èyí nínú ìkẹ́ta nkan ìgbàgbọ́wa: “A gbàgbọ́ pé nípasẹ̀ Ètùtù Krístì, gbogbo ènìyàn lè ní ìgbàlà, nípasẹ̀ ìgbọràn sí àwọn òfin àti ìlànà Ìhìnrere.”

“Kíni Jésù Krístì ti ṣe fúnmi?” arábìnrin náà bèèrè. Ní abẹ́ ètò Baba wa Ọrun, Ó “dá àwọn ọ̀run àti ilẹ̀ ayé” (Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 14:9) kí ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ó le ní ìrírí ayé kíkú tí ó ṣe dandan láti lépa àyànmọ́ wa ti ọ̀run, Bíi apákan ètò ti Baba, Àjíìnde ti Jésù Krístì borí ikú láti fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ní ìdánilójú àìkú. Ètùtù ìrúbọ ti Jésù Krístì nfún ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ní ànfààní láti ronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa kí a sì padà ní mímọ́ sí ilé wa ọ̀run. Àwọn àṣẹ àti àwọn ìlànà Rẹ̀ nfi ọ̀nà hàn wá, àti pé oyè àlùfáà Rẹ̀ nfúnni ní àṣẹ láti ṣe àwọn ìlànà tí wọ́n ṣe kókó láti dé ibi àyànmọ́ náà. Olùgbàlà wa fi tìfẹ́tifẹ́ ní ìrírí gbogbo àwọn ìrora àti àwọn àìpé ti ayé kíkú kí Òun ó le mọ bí yío ti rànwá lọ́wọ́ tàbí fúnwa lókun nínú àwọn ìpọ́njú wa.

Jésù Krístì

Jésù Krístì ṣe gbogbo èyí nítorípé Ó fẹ́ràn gbogbo àwa ọmọ Ọlọ́run. Ìfẹ́ ni ìwúrí fún gbogbo rẹ̀, ó sì ti wà bẹ́ẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ gan. Ọlọ́run ti sọ fúnwa nínú ìfihàn ti òde oní pé “ó dá … ọkùnrin àti obìnrin, ní àwòrán ara rẹ̀ … ; ó sì fi àwọn àṣẹ fún wọn pé kí wọn ó máa fẹ́ràn kí wọn ó sì máa sìn òun” (Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 20:18–19).

Mo jẹ́ri nípa gbogbo èyí mo sì gbàdúrà pé kí gbogbo wa ó le rántí ohun tí Olùgbàlà wa ti ṣe fún ìkọ̀ọ̀kan wa àti pé kí gbogbo wa ó le fẹ́ràn Rẹ̀ kí a sì sìn Í, ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.