Ìmọ́lẹ̀ Fi Ara Mọ́ Ìmọ́lẹ̀
Bí a ṣe nmú ìgbàgbọ́ wa nínú Krístì pọ̀ si, a ngba ìmọ́lẹ̀ ní ìwọ̀n púpọ̀ síi títí di ìgbà tí yio tú gbogbo òkùnkùn tí o lè yí wa ka dànù.
Ẹyin Arákùnrin àti Arábìnrin mi, mo báa yìn yọ̀ ní Ọjọ́ Ìsinmi Ọdún Àjínde oníbùnkún yi ní ṣíṣe ìgbèrò ìmọ́lẹ̀ ológo tí ó wá sáyé pẹ̀lú Àjínde ti Olúwa àti Olùgbàlà wa Jésù Krístì.
Ní àkókò iṣẹ́-ìránṣẹ ayé-ikú Rẹ, Jésù kéde pé: “Èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé: ẹni tí ó bá tẹ̀lé mi kì yio rìn nínú òkùnkùn, ṣùgbọ́n yíò ní ìmọ́lẹ̀ ìyè.”1 Ẹ̀mí Krístì “wà nínú oun gbogbo, [Ó sì] fi ẹ̀mí fún ohun gbogbo.”2 Ó ṣẹ́gun òkùnkùn tí ìbá yíwa ká.
Ní àwọn ọdún sẹ́hìn, ní wíwá ìrírí tó lápẹrẹ, àwọn ọmọkùnrin mi méjì àti émi darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin kan lọ sí ihò-ìráhun, tí a fún lórúkọ bẹ́ẹ̀ nítorí ìró tí ó ndún jáde ní àkokò kan láti ẹnu rẹ̀. Ihò náà jẹ́ ihò èéfín èyítí ó ṣí sínú ìyẹ̀wù ìnàró bíi ọgọ́sãn (180) ẹsẹ̀ bàtà ní jíjìn, ìyẹ̀wù-ihò ẹlẹ́yọkan tí ó tóbi jùlọ ní California.
Àwọn ọ̀nà méjì nìkan ló sọ̀kalẹ̀: àtẹ̀gùn yíyípo àìléwu tàbí sísọ̀kalẹ̀ sí ilẹ̀ ihò pẹ̀lú okùn; èmi àti àwọn ọmọkùnrin mi yàn lati sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú okùn. Ọmọ mì àgbà kọ́kọ́ lọ nígbà tí ọmọkùnrin mi kékeré àti èmi pinnu láti lọ kẹ́hìn kí a lè sọ̀kalẹ̀ papọ̀.
Lẹ́hìn tí àwọn atọ́nà wa ti kọ́wa tí wọ́n sì ṣe ààbò wa pẹ̀lú ìjánu àti sí okùn tí ó lágbára, ti a tẹ sẹ́hìn títí ti a fi dúró lori pẹpẹ kékeré kan ti a sì ṣe àkójọpọ̀ ìgboyà wa, nítorí èyí ni ààyè to kẹ́hìn láti yíra padà àti ààyè tí a le rí èyikeyi ìtànṣán oòrùn láti ẹnu ihò náà.
Ìgbésẹ̀ ti o tẹ̀le wá sẹ́hìn fi wa sínú ihò cathedral kan tí o ga tí ó sì fẹ̀ tóbẹ́ẹ̀ ti o le gbe gbogbo Ère Òmìnira mì. Níbẹ̀ ni a ti rọ ní ìyípo ti ó lọ́ra bí àwọn ojú wa ṣe túnṣe sí òkùnkùn díẹ̀. Bí a ṣé ntẹ̀síwájú sísọ̀kalẹ̀ wa, dídán ti àwọn iná ẹ̀lẹ́tírìkì tan ìmọ́lẹ̀ sí ògiri ìyanu ti sítálágáìtì ati àwọn sítálátì dídán.
Láìsí ìkìlọ̀, àwọn iná náà lọ lójijì pátápátá. Ní dídádúró lókè ọ̀gbun náà, a rì sínú òkùnkùn tó jinlẹ̀ débi pé a kò lè rí ọwọ́ wa pàápàá lórí àwọn okùn tí ó wà níwájú wa. Ohùn kan pè lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, “Bàbá, Bàbá, ṣé o wà níbẹ̀?”
“M’o wà níbí, ọmọ, mo wà níbí yi,” mo dáhùn.
Ìpàdánù àìròtẹ́lẹ̀ tí ìmọ́lẹ̀ ni a ṣe láti fihàn pé láìsì iná, okunkun ihò náà kò ṣèe wọ̀. Ó ṣe àṣeyọrí; a ní “ìmọ̀lára” òkùnkùn náà. Nígbàtí àwọn ìmọ́lẹ̀ padà, òkùnkùn náà jọ̀wọ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, bi òkùnkùn ṣe gbọdọ tẹríba nígbàgbogbo, si àní ìmọ́lẹ̀ tí kò lágbára jùlọ. Àwọn ọmọkùnrin mi ati èmi ti wà pẹ̀lú ìrántí ti òkùnkùn kan tí a kò mọ̀ tẹ́lẹ̀ rí, ìmoore púpọ̀ síi jfún ìmọ́lẹ̀ tí a kì yíò gbàgbé, ati ìdánilójú pé kìi ṣe àwa nìkan ni ó wà nínú òkùnkùn.
Ìsọ̀kalẹ̀ wa sínú ihò yẹn ni àwọn ọ̀nà kan tí ó jọra ní ìrìnàjò wa nínú ayé ikú. A kúrò nínú ìmọ́lẹ̀ ológo ti ọ̀run a sì sọ̀kalẹ̀ nípasẹ̀ ìbòjú ti ìgbàgbé sí ayé ti o ṣókùnkùn. Bàbá wa Ọ̀run kò fi wá sílẹ̀ sínú òkùnkùn ṣùgbọ́n Ó ṣe ìlérí imọlẹ fun wa fún ìrìnàjò wa nípasẹ̀ olùfẹ́ Ọmọ Rẹ, Jésù Krístì.
A mọ̀ pé oòrùn jẹ́ kókó fún gbogbo ẹ̀mí ni orí ilẹ̀ ayé . Síṣe pàtàkì bákannáà sí ìgbésí ayé ti ẹ̀mí wa ni ìmọ́lẹ̀ ti o njáde láti ọ̀dọ̀ Olùgbàlà wa. Nínú ìfẹ́ pípé Rẹ̀, Ọlọ́run fi ìmọ́lẹ̀ ti Krístì fún gbogbo ènìyàn “ti´ó wá sí ayé”3 pé kí wọ́n lè “mọ rere kúrò nínú ibi”4 kí a sì ṣí wọn létí láti “ṣe rere nígbàgbogbo.”5 Ìmọ́lẹ̀ náà, nfi ara rẹ̀ hàn nípasẹ̀ ohun tí a ma npè ni ẹ̀rí-ọkàn wa, ó npe wá nígbàgbogbo láti ṣe kí a sì dára síi, láti jẹ́ ara wa tí ó dára jùlọ.
Bí a ṣe nmú ìgbàgbọ́ wa nínú Krístì pọ̀ si, a ngba ìmọ́lẹ̀ ní ìwọ̀n púpọ̀ síi títí di ìgbà tí yio ba gbogbo òkùnkùn tí o lè yí wa ka jẹ́. “Èyí nì tí íṣe ti Ọlọ́run jẹ́ ìmọ́lẹ̀; ẹni tí ó bá sì gbà ìmọ́lẹ̀, tí ó sì ntẹ̀síwájú nínú Ọlọ́run, ngba ìmọ́lẹ̀ sí; àti pé ìmọ́lẹ̀ náà ńdàgbà síwájú àti síwájú sí i títí di ọjọ́ pípé.”6
Ìmọ́lẹ̀ ti Krístì múra wa sílẹ̀ láti gba ipa iṣẹ́-ìránṣẹ́ ti Ẹ̀mí Mímọ́, èyítí o jẹ “agbára ìdánilójú Ọlọ́run … ti òtítọ́ Ìhìnrere náà”7 Ẹ̀ni kẹ́ta ti Ọlọ́run-Olórí, Ẹ̀mí Mímọ́ “jẹ́ ẹ̀yà ti Ẹ̀mí.”8 Orísun ìmọ́lẹ̀ tí ó tóbi jùlọ tí Bàbá Ọrun fún ọ ní ayé ikú ni ó wá nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́, tí ipa rẹ̀ “yio tan ìmọ́lẹ̀ sí inú rẹ yio[sì] kún ẹ̀m rẹ fún ayọ.”9
Nínú Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, nípasẹ̀ àṣẹ oyèàlúfà tí a mú padàbọ̀sípò, a ti rì ọ́ bọmi nípasẹ̀ ìrìbomi fún ìmúkúrò àwọn ẹ̀ṣẹ̀. Lẹ́hìnnáà, a gbé ọwọ́ le orí rẹ ati pé ẹ̀bùn ìyanu, “tí a kò lè fẹnu sọ” yi”10 nípa Ẹ̀mí Mímọ́ ni a fi fun ọ.
Lẹ́hìnnáà, nígbàtí àwọn ìfẹ́ inú ati àwọn ìṣe rẹ bá dojúkọ ipa ọ̀nà májẹ̀mú, Ẹ̀mí Mímọ́, bí ìmọ́lẹ̀ ninú rẹ, yio fihàn yío sì jẹri ti òtítọ́,11 kìlọ̀ nípa ewu, ṣe ìtùnú12 yío sì ṣe ìwẹnúmọ́,13 àti pé yío pèsè alafia14 sí ẹ̀mí re.
Nítorí “ìmọ́lẹ̀ fi ara mọ́ ìmọ́lẹ̀,”15 ìbákẹ́gbẹ́ ìgbàgbogbo tí Ẹ̀mí Mímọ́ yio darí rẹ láti ṣe àwọn yíyàn tí yio jẹ́ kí o wà nínú ìmọ́lẹ̀ náà; ní ìlòdìsí, àwọn yíyàn tí a ṣe láìsí ipa ti Ẹ̀mí Mímọ́ yio ṣọ́ láti mú ọ lọ sínú àwọn òjìjí àti òkùnkùn. Bí Alàgbà Robert D. Hales ti kọ́ni: “Nígbàtí ìmọ́lẹ̀ bá wá, a ṣẹ́gun òkùnkùn ati pé ó gbọ́dọ̀ kúrò. … Nígbàtí ìmọ́lẹ̀ ẹ̀mí ti Ẹ̀mí Mímọ́ bá wá, òkùnkùn ti Èṣù a lọ kúrò.”16
Njẹ́ mo lè daba pé, bóyá, àkókò nì yí láti béèrè lọ́wọ́ araàrẹ: Njẹ mo ní “ìmọ́lẹ̀” náà nínú ayé mi? Tí kìí bá ṣe bẹ́ẹ̀, nígbàwo ni àkókò ìkẹhìn tí mo ṣé?
Gẹ́gẹ́bí ìtànṣán ojojúmọ́ ti nwẹ́ fún ilẹ̀-ayé láti tunṣe àti láti ṣe ìmudúró ayé, o lè tàn ìmọ́lẹ̀ nínú yín nígbàtí ẹ bá yàn láti tẹ̀le É.
Àfikún ìtànṣán ni a fikun ní gbogbo ìgbà tí ẹ bá nwá Ọlọ́run nínú àdúrà; ṣe àṣàrò àwọn ìwé mímọ́ láti “gbọ Tirẹ”;17 tàbí ṣe iṣe lórí ìtọ́nisọ́nà àti látẹnu wòlíì alãye wa; àti láti gbọ́ran kí a sì pa àwọn òfin mọ́ láti “rìn nínú gbogbo àwọn ìlànà Olúwa.”18
Ẹ ó pe ìmọ́lẹ̀ ti ẹ̀mí sínú ẹ̀mí yín àti àláfíà sínú ayé yín ní gbogbo ìgbà tí ẹ bá ronúpìwàdà. Bí o ṣe ngba oúnjẹ Olúwa ni lọ́sọ̀sẹ̀, bí o ṣe ngbé orúkọ Olùgbàlà sí orí rẹ, bí o ṣe nrántí Rẹ̀ nígbàgbogbo tí o sì npa àwọn òfin Rẹ̀ mọ, ìmọ́lẹ̀ Rẹ yio máa tàn nínú rẹ.
Oòrùn wa nínú ẹ̀mí yín ní gbogbo ìgbà ti ẹ bá pín ìhìnrere tí ẹ sì jẹ́ ẹ̀rí rẹ. Ní gbogbo ìgbà tí ẹ ba nsin ara yin bi Olùgbàlà ti ṣe, ẹ o ní ìmọ̀lára ìwúrí Rẹ nínú ọkàn yín. Ìmọ́lẹ̀ Baba Ọ̀run nfi ìgbàgbogbo dúró nínú tẹ́mpìlì mímọ́ Rẹ̀ àti lórí gbogbo ẹni tí ó bá gbé arawọn sílẹ̀ nínú ilé Olúwa. Ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀ nínú yín ngbòòrò si pẹ̀lú àwọn ìṣe inúrere yín, sùúrù, ìdáríjì, ifẹ́-àìlẹ́gbẹ́, ó sì nfi ararẹ̀ hàn nínú ìwò ayọ̀ yín. Ní apá kejì, à nrín nínú àwọn òjijì nígbàtí a bá yára jù láti bínú tàbí lọ́ra jù lati ìdáríjì. “Bí o ṣe fi ojú rẹ sí ìhà ìtànsán oòrùn, àwọn òjijì kò lè ran ara wọn lọ́wọ́ ṣùgbọ́n ṣubú sẹ́hìn rẹ.”19
Bí ẹ ṣe ngbé ìgbé ayé làti yẹ fún ìbákẹ́gbẹ́ ti Ẹ̀mí Mímọ́, ní òtítọ́ ẹ̀yin “mú kí agbára ẹ̀mí yín pọ si lati gba ìfihàn.”20
Ìgbésí ayé nfi awọn ìpèníjà ati àwọn ìfàsẹ́yìn sí iwájú ẹni, ati pé gbogbo wa gbọdọ̀ dojúko díẹ̀ nínú àwọn ọjọ́ dúdú àti àwọn ìjì. Nínú gbogbo rẹ̀, tí a bá “jẹ́ kí Ọlọ́run borí nínú àwọn ayé wa,”21 ìmọ́lẹ̀ ti Ẹ̀mí Mímọ́ yio fi hàn pé ìdí àti ìtumọ̀ wa nínú àwọn ìdánwò wa, àti pé wọn yio yí wa padà nígbẹ̀hìn si àwọn ènìyàn dídára síi, àwọn ènìyàn pípé síi pẹ̀lú ìgbàgbọ́ dídúró ṣinṣin síi ati ìrètí dídán síi nínú Krístì, ni mímọ̀ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa ní gbogbo ìgbà. Bí Ààrẹ Nelson ti gbani nímọ̀ràn, “Òkùnkùn púpọ̀ si tí ó nbá ìpọ́njú wá nmú ìmọ́lẹ̀ Jésù Krístì tàn ní dídán síi láé.”22
Àwọn àkókò ti ìgbésí ayé wa lè mú wa lọ sí àwọn ibi àìròtẹ́lẹ̀ ati àìfẹ́. Bí ẹ̀ṣẹ̀ bá ti dar rẹ síbẹ̀, fa aṣọ-ìkèlè òkùnkùn sẹ́hìn ki o sì bẹ̀rẹ̀ nísisìyí lati fi ìrẹ̀lẹ̀ súnmọ́ ọ̀dọ̀ Bàbá rẹ Ọ̀run pẹ̀lú ìròbìnújẹ́ ati ìrora ọkàn kí o si ronúpìwàdà. Yio gbọ́ àdúrà ìtara rẹ. Pẹ̀lú ìgboyà loni, “sún mọ́ [Ọ] àti pé [Òun] yíò sún mọ́ ọ.”23 Ẹ ko kọjá agbára ìwòsàn ti Ètùtù Jésù Krístì.
Mo wá lati ọ̀dọ̀ àwọn òbí tí ó dára ati lati ọ̀dọ̀ àwọn bàbá nlá olótítọ́ tí ó dáhùn sí ìmọ́lẹ̀ ti Jésù Krístì ati ìhìnrere Rẹ, àti pé ó bùkún àwọn ìgbésí ayé wọn àti àwọn ìran ti o tẹ̀lé e pẹ̀lú ìfaradà ti ẹ̀mí. Bàbá mi ma nsọ̀rọ̀ nípa bàbá rẹ nígbàgbogbo, Milo T Dyches, ó sì pín bí ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú Ọlọ́run ṣe jẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún un lọsan àti lóru. Bàbá àgbà jẹ olùṣọ́ igbó kan ó sì nfi ígbàgbogbo gun awọn oke-nla ní òun nìkan, ní fífi ẹ̀mí rẹ lé ìtọ́sọ́nà ati ìtọ́jú ti Ọlọ́run láìsí ìbéèrè. .
Ní òpin ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn kan, Bàbá àgbà nìkan wà ní àwọn òkè giga. Ìgbà òtútù ti ṣe àfihàn ojú rẹ tẹ́lẹ̀ nígbàtí ó gun ọ̀kan nínú àwọn ẹṣin àyànfẹ́ rẹ, Prince àtijọ́, o si lọ sílé igi kan láti ṣe ìwọ̀n igi nlá ṣaájú ki wọ́n tó lè gé síwẹ́wẹ́.
Ní aṣálẹ́, o parí iṣẹ́ rẹ o sì gun un padà sínú gààrì. Ní àkókò náà, ìwọ̀n òtútù ti lọ sílẹ̀ àti pé ìjì yìnyín líle ti ìgbà òtútù tí gba òkè náà. Pẹ̀lú àìsí ìmọ́lẹ̀ tàbí ipa ọ̀nà láti tọ́ ọ, ó yí Prince padà sí ìtọ́sọ́nà kan ti ó rò pé yio mu wọ́n padà sí ibùdó olùṣọ́.
Lẹ́hìn tí ó rin ìrìn-àjò àwọn máìlì ní òkùnkùn, Prince lọ́ra, lẹ́hìnnáà ó dúró. Bàbá àgbà rọ Prince síwájú léraléra, ṣùgbọ́n ẹṣín kọ̀. Pẹ̀lú yìnyín dídì tí ó le fọ́jú ní àyíká wọ́n, Bàbá àgbà mọ̀ pé oun nílò ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run. Bí ó ti ṣe ní gbogbo ayé rẹ, ó fi ìrẹ̀lẹ̀ “[bèèrè] nínú ìgbàgbọ́, láìṣe iyèméjì.”24 Ohùn kan, kékeré, dáhùn, “Milo, fun Prince ni orí rẹ.” Bàbá àgbà gbọ́ran, àti pé bi o ti mú ọwọ́ rẹ fúyẹ́ lórí awọn okùn ìdáró, Prince yipo yíká o si lọ kúrò ní ìtọ́sọ́nà míràn. Àwọn wákàtí lẹ́hìnnáà, Prince tún dúró ó sì rẹ orí rẹ̀ sílẹ̀. Nínú wíwakọ̀ òjò-dídì náà, Bàbá àgbà rí pé wọ́n ti gúnlẹ̀ láyọ̀ lẹ́nu ibùdó ranger.
Pẹ̀lú oòrùn òwúrọ̀, Bàbá àgbà tọ ipa ẹsẹ̀ Prince nínú òjò-dídì náà. Ó fa èémi jíjìnlẹ̀ nígbàtí ó rí ibití ó ti fún Prince ní orí rẹ: ó jẹ́ etí òkè gíga kan, níbití ìgbésẹ̀ kan síwájú ìbá tí fi àwọn méjèèjì ẹṣin àti ẹlẹ́ṣin ikú wọn nínú àwọn àpáta rírú ní ìsàlẹ̀.
Ní ìbámu si ìrírí náà ati ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn míràn, Bàbá àgbà dámọ̀ràn pé, “alabaṣiṣẹpọ tí ó dára jùlọ àti tí ó tóbi jùlọ tí ìwọ yio ní láéláé ni Bàbá rẹ ní Ọ̀run.” Nígbàtí bàbá mi yíò sọ ìtàn Bàbánlá, mo rántí pé òun yíò ṣe àyọsọ látinú ìwé mímọ́:
Fi gbogbo àyà rẹ gbẹ́kẹ̀lé Olúwa; másì ṣe tẹ̀ sí ìmọ̀ ara rẹ.
“Mọ̀ọ́ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun ó sì máa tọ ipa-ọ̀nà rẹ.”25
Mo jẹri pé Jésù Krístì ni Ìmọ́lẹ̀ ayérayé ti ó ṣì “ntàn nínú òkùnkùn.”26 Kò sí òkùnkùn tí ó lè rẹ̀ẹ́ sílẹ̀, pa rẹ́, borí rẹ, tàbí ṣẹ́gun Ìmọ́lẹ̀ náà. Bàbá wa Ọ̀run fún wa ní Ìmọ́lẹ̀ náà lọfẹ. Ẹ kò dá nìkan wà. Ó ngbọ́ Ó sì ndáhùn gbogbo àdúrà. Ó ti “pe ọ́ kúrò nínú òkùnkùn sínú ìmọ́lẹ̀ ìyanu Rẹ,”27 Nígbàtí ẹ bá bèèrè lọ́wọ́ “Baba, Baba, ṣe O wà níbẹ̀?” Òun yíò dáhùn nígbàgbogbo,, “M’o wà níbí, ọmọ tèmi; m’o wà nibí.”
Mo jẹri pé Jésù Krístì mú ètò Bàbá Ọ̀run ṣẹ gẹ́gẹ́ bi Olùgbàlà wa àti Olùràpadà wa;28 Òun ni ìmọ́lẹ̀ wa, ayé wa, àti ọ̀nà wa. Ìmọ́lẹ̀ Rẹ ki yio ṣókùnkùn láé,29 ògo Rẹ̀ kò ní dúró láéláé, ìfẹ́ Rẹ fún yín jẹ́ ayérayé—lana, loni, ati títíláé. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.