Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ẹ Le Kó Ísráẹ́li Jọ!
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2021


Ẹ Le Kó Ísráẹ́li Jọ.

Mo mọ̀ dájú pátápátá pé ẹ̀yin ọ̀dọ́ le ṣe èyí nítori ohunkan nípa ìdánimọ̀ yín àti agbára nlá kan tí ó wà nínú yín.

Bí ọdún mẹ́ta sẹ́hìn, Ààrẹ Russel M. Nelson pe gbogbo àwọn ọ̀dọ́ Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn láti forúkọ sílẹ̀ nínú “ẹgbẹ́ ọ̀dọ́ àwọn ọmọ ogun Olúwa láti kó Ísráẹ́lì jọ” ní àwọn ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ìbòjú. Ó wípé, “Kíkójọpọ̀ náá ni ohun pàtàkì jùlọ tí ó nṣẹlẹ̀ ní orí ilẹ̀ ayé lóni.”2 Mo mọ̀ dájú pátápátá pé ẹ̀yin ọ̀dọ́ le ṣe èyí—kí ẹ sì ṣe é dáradára gan—nítori ti (1) ohun kan nípa ìdánimọ̀ yín àti (2) agbára nlá kan tí ó wà nínú yín.

Arákùnrin àti Arábìnrin Corbitt

Ní ọdún mọ́kànlélógójì sẹ́hìn, àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere méjì láti Ìjọ wa ní ìmọ̀lára dídarí sí ilé kan ní New Jersey United States. Láìpẹ́, pẹ̀lú ìyanu, àwọn òbí méjèjì àti gbogbo àwọn ọmọ mẹ́wã ṣe ìrìbọmi. Ní àwọn ọ̀rọ̀ wòlíì, wọn “jẹ́kí Ọlọ́run borí”3 nínú ayé wọn. Ó yẹ kí nsọ pé “ayé wa.” Èmi ni ọmọ kẹ́ta. Mo jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàdínlógún nígbàtí mo pinnu láti dá májẹ̀mú pípẹ́ títí kan láti tẹ̀lé Jésù Krístì. Ṣùgbọ́n ẹ ro kínni ohun míràn tí mo pinnu? Èmi kò ní sìn ní míṣọ̀n ní ìgbà-kíkún. Èyínnì ti pọ̀ jù. Àti pé a kò níi retí èyí láti ọ̀dọ̀ mi, ṣebí? Èmi jẹ́ ọmọ Ìjọ titun nini. Èmi kò ní owó. Bákannáà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ṣẹ̀ṣẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ jáde ní ilé ìwé gíga tí ó le jù ní Ìwọ̀ oorun Philadelphia tí kò jìnnà púpọ̀, tí mo sì dojúkọ àwọn ìpèníjà líléwu díẹ̀, ní ìkọ̀kọ̀ mo nbẹ̀rù fífi ilé sílẹ̀ fún odidi ọdún méjì.

Ẹbí Corbitt

Ìdánimọ̀ Yín Tòótọ́

Ṣùgbọ́n mo ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ ẹ̀kọ́ pé èmi àti gbogbo ẹ̀dá ènìyàn ti gbé rí pẹ̀lú Baba wa Ọrun bíi ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin ẹ̀mí Rẹ̀ ṣaájú ìbí wa. Àwọn ẹlòmíràn nílò láti mọ̀, bí èmi ti mọ̀, pé Ó nwọ̀nà fún gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀ láti gbádùn ìyè ayérayé pẹ̀lú Rẹ̀. Nítorínáà, Ó gbé ètò pípé ti ìgbàlà àti ìdùnnú Rẹ̀ kalẹ̀ síwájú gbogbo ènìyàn ní ilẹ̀ ayé, pẹ̀lú Jésù Krístì bíi Olùgbalà wa. Pẹ̀lú ẹ̀dùn, Sátánì tako èrò Ọlọ́run.4 Gẹ́gẹ́bí ìwé ti Ìfihàn, “ogun wà ní ọ̀run”!5 Sátánì fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ tan ìdá mẹ́ta àwọn ọmọ ẹ̀mí ti Baba Ọrun sí jíjẹ́kí ó borí dípò Ọlọ́run.6 Ṣùgbọ́n kìí ṣe ẹ̀yin! Apóstélì Jòhánù rí pé ẹ borí Sátánì “nípa ọ̀rọ̀ ti ẹ̀rí [yín].”7

Mímọ ìdánimọ̀ mi tòótọ́, rírànlọ́wọ́ nípasẹ̀ ìbùkún baba-nlá mi, fúnmi ní ìgboyà àti ìgbàgbọ́ láti gba ìfipè ti Ààrẹ Spencer W. Kimball láti kó Israẹ́lì jọ.7 Yíò jẹ́ ọjọ́ ìrú kannáà fún yín, ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n. Mímọ̀ pé ẹ borí Sátánì nípa ọ̀rọ̀ ti ẹ̀rí yín ṣíwájú yío ràn yín lọ́wọ́ láti fẹ́ràn, láti pín, àti láti pè8 nísisìyí àti nígbà gbogbo—láti pe àwọn ẹlòmíràn láti wá wò, wá ṣe ìrànlọ́wọ́, àti láti wà pẹ̀lú, bí ogun kannáà fún ẹ̀mí àwọn ọmọ Ọlọ́run ṣe ntẹ̀síwájú.

Alàgbà Corbitt

Ìgbágbọ́ Alágbára nínú Yín

Agbára púpọ̀ tí ó wà nínú yín nkọ́? Ẹ ronú nípa èyí: ẹ kígbe fun ayọ̀9 láti wá sí ayé síṣubú níbití gbogbo ènìyàn yío ti dojúkọ ikú ti ara àti ti ẹ̀mí. Kò le ṣeéṣe fúnwa láti borí ìkankan fúnra ara wa. A kò níi jìyà láti inú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tiwa nìkan ṣùgbọ́n ẹ̀ṣẹ̀ ti àwọn ẹ̀lòmíràn pẹ̀lú. Ẹdá ènìyàn yío ní ìrírí ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ gbogbo oríṣi àìpé àti ìjákulẹ̀ tí a le rò nípa10—gbogbo rẹ̀ pẹ̀lú ìbòjú ìgbàgbé lóri ẹ̀mí wa, àti pé ọ̀tá búburú jùlọ ti ayé nnì yío tẹ̀síwájú láti máa dọdẹ kí ó sì máa dán wa wò. Gbogbo ìrètí fún pípadà bíi ẹnití ó ti jínde àti tí ó mọ́ sí ibi mímọ́ ti Ọlọ́run dá pátápátá lé orí Ẹ̀dá kan ní pípa ìlérí Rẹ̀ mọ́.11

Kínni ó róo yín lágbára láti lọ síwájú? Ààrẹ Henry B. Eyring kọ́ni pé, “O gba ìgbàgbọ́ nínú Jésù láti mú ètò ìdùnnú àti ipò Jésù Krístì nínú rẹ̀ dúró nígbàtí ẹ mọ díẹ̀ tí ó kéré tó bẹ́ẹ̀ nínú àwọn ìpènijà tí ẹ ó dojúkọ nínú ayé ikú.”12 Nígbàtí Jésù Krístì ṣe ìlérí pé Òun yío wá sínú ayé ikú yío sì fi ayé Rẹ̀ sílẹ̀ láti kó wa jọ13 kí Ó sì gbà wá là, kìí ṣe pé ẹ kàn gbà Á gbọ́ lásán. Ẹ̀yin “ọlọ́lá ẹ̀mí”14 ní irú “ìgbàgbọ́ nlá gidigidi” bẹ́ẹ̀ tí ẹ rí ìlérí Rẹ̀ bíi dídájú.15 Kò le parọ́, nítorínáà ẹ rí I bí ẹnipé Ó ti ta ẹ̀jẹ̀ Rẹ̀ sílẹ̀ fún yín tán tẹ́lẹ̀, ti pẹ́ ṣaájú kí a tó bí I.16

Nínú àwọn ọ̀rọ̀ alápẹ̀rẹ̀ ti Jòhánù, ẹ̀yin “borí [Sátánì] nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ ti Ọdọ́ Àgùtàn náà.”17 Ààrẹ Dallin H. Oaks kọ́ni pé nínú ayé náà “[ẹ̀yin] rí òpin láti ìbẹ̀rẹ̀.”18

Ní ọjọ́ kan ṣíwájú kí ẹ tó lọ sí ilé ìwé, ọ̀kan nínú àwọn òbí yín ṣe ìlérí òtítọ́ kan pé ẹ le ní oúnjẹ tí ẹ fẹ́ràn jùlọ nígbàtí ẹ bá padà dé ilé! Ara yín yá gágá! Nígbàtí ẹ wà ní ilé ìwé ẹ nfi ojú inú jẹ oúnjẹ náà ẹ sì le tọ́ ọ wò gan báyi. Ní ìwà-ẹ̀dá, ẹ tilẹ̀ pín ìròhìn rere náà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Wíwò síwájú sí lílọ sí ilé mú inú yín dùn tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ìdánwò àti àwọn ìpèníjà ti ilé ìwé dàbíi pé ó fúyẹ́. Ohunkóhun kò le mú ayọ̀ yín kúrò tàbí mú un yín ṣe iyèméjì nítorí bí ìlérí náà ṣe dájú sí! Ní àfijọ, kí a tó bí ẹ̀yin ọlọ́lá ẹ̀mí, ẹ ti kọ́ láti rí àwọn ìlérí ti Krístì ní ọ̀nà dídájú yi, ẹ sì ṣe ìtọ́wò nínú ìgbàlà Rẹ̀.19 Ìgbàgbọ́ títóbi yín dàbí àwọn iṣan tí ó ndi líle àti lílágbára síi bí ẹ ti nlò wọ́n sí, ṣùgbọ́n tí wọ́n ti wà tẹ́lẹ̀ nínú yín.

Báwo ni ẹ ṣe le ta ìgbàgbọ́ nlá yín nínú Krístì jí kí ẹ sì lò ó láti kó Isráẹ́lì jọ nísisìyí kí ẹ sì ṣẹ́gun lórí Sátánì lẹ́ẹ̀kansíi? Nípa títún ẹ̀kọ́ kọ́ láti fojúsọ́nà kí ẹ sì rí ìlérí Olúwa pẹ̀lú ìdánilójú kannáà láti kójọ àti láti gbàlà lóni. Ó nlo Ìwé ti Mọ́mọ́nì àti àwọn wòlíì Rẹ̀ láti kọ́wa bí a ó ti ṣeé. Ní ọjọ́ pípẹ́ ṣaájú Krístì, “àwọn wòlíì, àti … àwọn àlùfáà, àti … àwọn olùkọ́ni … [rọ àwọn ènìyàn] láti fojúsọ́nà sí Messia náà, kí wọ́n ó sì gbàgbọ́ nínú rẹ̀ pé ó nbọ̀ bí èyítí ó ti wá.”20 Wòlíì Ábínádì kọ́ni “Àti nísisìyí, tí kò bá jẹ́ pé Krístì wá sínú ayé, tí ó nsọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun èyítí mbọ̀ bí èyítí ó ti dé, kì bá ti sí ìràpadà.”21 Bii ti Almà, Abínádì “[fi] ojú sọ́nà pẹ̀lú ojú ìgbàgbọ́”22 ó sì rí ìlérí Ọlọ́run dídájú nípa ìgbàlà bíi pé ó ti wá sí ìmúṣẹ. Wọ́n “borí [Sátánì] nípa ẹ̀jẹ̀ Ọdọ́ Àgùtàn, àti … ọ̀rọ̀ ẹ̀rí wọn” ní ọjọ́ pípẹ́ ṣaájú kí a tó bí Krístì, gẹ́gẹ́bí ẹ̀yin náà ti ṣe. Olúwa sì fi agbára fún wọn láti pè àti láti kó Israẹ́lì jọ. Òun ó ṣe bákannáà fún yín bí ẹ ti nfojú sọ́nà nínú ìgbàgbọ́, tí ẹ nrí Isráẹ́lì ní kíkójọ—ní àgbáyé àti nínú àwọn “agbo” tiyín23—tí ẹ sì npe gbogbo ènìyàn!

Àwọn ọgọ́gọ́rũn àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere kọ́ lé orí alágbára ìgbágbọ́ wọn nínú Krístì ṣaájú ayé ikú nípa fífi ojú inú wo àwọn wọnnì tí wọ́n bá pàdé tàbí kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ní wíwọ aṣọ ìrìbọmi tàbí ti tẹ́mpìlì. Nínú ọ̀rọ̀ kan tí a pe àkòrí rẹ̀ ní “Ẹ Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Òpin ní Inú Yín,”24 Ààrẹ Nelson pín àpẹrẹ ti ara ẹni kan ti síṣe èyí àti kíkọ́ àwọn adárí iṣẹ́ ìránṣẹ́ láti kọ́ àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere láti ṣe bákannáà. Mímọ̀ pé àwọn lo ìgbàgbọ́ nlá yi nínú Krístì ní ìṣíwáju ayé ràn àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere wa ọ̀wọ́n lọ́wọ́ lọ́pọ̀lọpọ̀ láti “gbọ́ Tirẹ̀”25 ó sì mú ìgbàgbọ́ wọn ṣiṣẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀ láti kó Israẹ́lì jọ bí Olúwa ti ṣe ìlérí.

Ní tòótọ́, fífi ojú inú wo àwọn irọ́ máa nkóbá ìgbàgbọ́.26 Ẹyin ọ̀rẹ́ mi, láti mọ̀ọ́mọ̀ wòó pẹ̀lú ojú inú tàbí wíwòran àwọn ohun tí ó tako ẹnití ẹ jẹ́ gan, nípàtàkì àwọn àwòrán tí kò tọ́, yío mú kí ó rẹ ìgbàgbọ́ yín nínú Krístì àti pé, láìsí ìrònúpìwàdà, ó le pa á run. Ẹ jọ̀wọ́ lo àwọn ìfinúrò yín láti mú ìgbàgbọ́ yín nínú Krístì gbèrú, kìí ṣe láti pa á run.

Ètò àwọn Ọmọdé àti Ọ̀dọ́

Ètò àwọn Ọmọdé àti Ọ̀dọ́ jẹ́ irinṣẹ́ kan ti wòlíì láti ràn ẹ̀yín ọ̀dọ́ lọ́wọ́ fi agbára fún ìgbàgbọ́ nlá yín. Ààrẹ Oaks kọ́ni pé, “Ètò náà ni a gbé kalẹ̀ láti ràn yín lọ́wọ́ dàbí Olùgbàlà wa síi ní àwọn ọ̀nà mẹ́rin: ti ẹ̀mí, ti àwùjọ, ti ara, àti ti ọgbọ́n orí.”27 Bí ẹ̀yin ọ̀dọ́ ti ndarí—darí—ní gbígbé ìgbé ayé ìhìnrere, títọ́jú àwọn ẹlòmíràn, pípe gbogbo ènìyàn láti gba ìhìnrere, dída àwọn ẹbí pọ̀ fún ayérayé, àti síṣe ètò àwọn ìṣe,28 ìgbàgbọ́ nlá nínú Krístì tí ẹ ní nínú ìṣíwájú ayé yío tún yọjú jáde yío sì róo yín lágbára láti ṣe iṣẹ́ Olúwa nínú ayé yi!

Bákannáà, àwọn àfojúsùn ti ara ẹni, “nípàtàkì àwọn àfojúsùn ti àkókò kúkúrú,”29 yío ràn yín lọ́wọ́ láti tún ìgbàgbọ́ lílágbára yín ṣe. Nígbàtí ẹ bá gbé àwọn àfojúsùn rere kalẹ̀ ẹ nfojú sọ́nà, bí ẹ ti ṣe ṣaájú, ẹ sì nrí ohun tí Baba yín Ọrun fẹ́ kí ẹ̀yin tàbí ẹlòmíràn dà.30 Nígbànáà ẹ ṣètò ẹ sì ṣiṣẹ́ kára láti ṣe àṣeyege rẹ̀. Alàgbà Quentin L. Cook kọ́ni pé, “Ẹ máṣe dágunlá jíjẹ́ pàtàki síṣe ètò, gbígbé àwọn àfojúsùn kalẹ̀… àti [pípe àwọn ẹlòmíràn]—gbogbo rẹ̀ pẹ̀lú ojú ìgbàgbọ́.”31

Yíyàn náà jẹ́ tiyín! Olúwa wí pé, “Agbára [láti yàn] wà nínú wọn.”32 Alàgbà Neil L. Andersen ṣe àlàyé pé, ìgbàgbọ́ yín yío dàgbà kìí ṣe nípa àìròtẹ́lẹ̀ ṣùgbọ́n nípa yíyàn.”33 Ó fi kún pé, “[Èyíkéyi] àwọn ìbéèrè tõtọ́ [tí ẹ lè ní] … yío jẹ́ yíyanjú pẹ̀lú sùúrù àti ojú ìgbàgbọ́.”33

Mo jẹ́ ẹ̀rí pé (1) ìdánimọ̀ tòótọ́ yín àti (2) agbára púpọ̀ ti ìgbàgbọ́ nínú Krístì tí ó wà nínú yín yío mú kí ó ṣeéṣe fún yín láti “ṣèrànwọ́ pèsè ayé sílẹ̀ fún ìpadàbọ̀ Olùgbàlà nípa pípe gbogbo ènìyàn láti wá sí ọ̀dọ̀ Krístì kí wọn ó sì gba àwọn ìbùkún ti Ètùtù Rẹ̀.”34 Njẹ́ kí gbogbo wa le pín ayọ̀ ìlérí dídájú Ìwé ti Mọ́mọ́nì’:

“Àwọn olódodo tí wọ́n fetísílẹ̀ sí àwọn wòlĩ, àti … tí wọ́n wo iwájú sọ́dọ̀ Krístì pẹ̀lú ìdúróṣinṣin … láìka inúnibíni gbogbo sí … kò ní parun.

“Ṣùgbọ́n [Krístì] … yío wò wọ́n sàn, wọn ó sì ní àlàáfíà pẹ̀lú rẹ̀.”35

Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Russell M. Nelson, “Hope of Israel” (worldwide youth devotional, June 3, 2018), HopeofIsrael.ChurchofJesusChrist.org.

  2. Wo Russell M. Nelson, “Let God Prevail,” Liahona, Nov. 2020, 92–95.

  3. Wo Àwọn Àkòrí Ìhìnrere,“Ètò Ìgbàlà,” topics.ChurchofJesusChrist.org; Henry B. Eyring, “Agbára Ìmúdúró Ìgbàgbọ́,” Liahona, May 2019, 58.

  4. Wo Ìfihàn 12:7–8.

  5. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 29:36–37.

  6. Revelation 12:11.

  7. Wo Spencer W. Kimball, “It Becometh Every Man,” Ensign, Oct. 1977, 2–7.

  8. Pínpín Ìhìnrere,” ChurchofJesusChrist.org/share.

  9. Wo Jobù 38:4–7.

  10. Wo àwọn Àkórí Ìhìnrere, “Èto Ìgbàlà”; bákannáà wo “Be Still, My Soul,” àwọn orin, no. 124, verse 3.

  11. Wo Àwọn Àkòrí Ìhìnrere, “Plan of Salvation”; bákannáà wo Dallin H. Oaks, “The Great Plan,” Liahona, May 2020, 93–94, 96.

  12. Henry B. Eyring, “Agbára Imúdúró Ìgbàgbọ́,” 58.

  13. Wo 3 Néfì 27:14.

  14. Russell M. Nelson, “Ìrètí Isráẹ́lì,” HopeofIsrael.ChurchofJesusChrist.org; bákannáà wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 138:55–56.

  15. Wo Alma 13:2–4; bákannáà wo Revelation 12:11; Articles of Faith 1:5. Ìwé ti Mọ́mọ́nì sọ kedere pé “ìgbàgbọ́ nlá gidigidi” nrí àwọn ìlérí Ọlọ́run bíi pé ó ti wá sí ìmúṣẹ gan. Wo 1 Nephi 5:5; Mosiah 3:11–13; 4:1–3; Alma 27:28; 28:12 (“they are raised” in 77–76 BC; emphasis added); see also Exodus 3:13; Isaiah 53; Doctrine and Covenants 130:7; Moses 7:47.

  16. Wo 2 Nefì 31:15; Ether 3:11–13, 6–9. Ìgbàgbọ́ láti rí ìlérí ìgbàlà ti Krístì bíi pé ó ti wá sí ìmúṣẹ gbọdọ̀ nílò mímọ̀ pé Krístì kò le parọ́. Irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ jé ìhùwàsí kan tí ó nṣe àlàyé àwọn olódodo ṣaájú ayé ikú, àwọn ọ̀dọ́ wa ní pàtó. “Baba Wa Ọrun ti ṣe ìpamọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀mí Rẹ̀ tí wọ́n ní ọlá jùlọ—bóyá, mo le sọ pé, àwọn ẹgbẹ́ Rẹ̀ tí ó dára jùlọ—fún ìgbésẹ̀ ìparí yi. Àwọn ọlọ́lá ẹ̀mí wọnnì—àwọn òṣèré tí wọ́n dára jùlọ wọnnì, àwọn akíkanjú wọnnì—ni ẹ̀yin!” Russell M. Nelson, “Ìrètí ti Israelì,” HopeofIsrael.ChurchofJesusChrist.org. Bákannáà wo John 1:1; 14:6, 17.

  17. Ìfihàn 12:11; bákannáà wo Ether 3: 6–9.

  18. Dallin H. Oaks, “The Great Plan,” 93.

  19. Wo Alma 36:24–26; see also Orin Dáfidì 34:8; Jacob 3:2; Mosiah 4:11.

  20. Jarom 1:11.

  21. Mosiah 16:6.

  22. Álmà 5:15

  23. Wo “Agbo: Ìgbé Ayé Ìhìnrere,” New Era, Oct. 2020.

  24. Russell M. Nelson, “Ẹ Bẹ̀rẹ̀ Pẹ̀lú Opin Ní Inú Yín” (ọ̀rọ̀ tí a fúnni níbi ìdanilẹkọ fún àwọn ààrẹ tuntun míṣọ̀n, June 22, 2014).

  25. Russell M. Nelson, “Gbọ́ Tirẹ̀,” Liahona,, Oṣù Kárún 2020, 88-92.

  26. Fún àpẹrẹ, Almà bá àwọn ènìyàn rẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa wíwo iwájú pẹ̀lú ojú ìgbàgbọ́ sí ìgbà tí wọn ó dúró níwájú Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ó kìlọ̀ pé wọn kò le rò síṣe bẹ́ẹ̀ pèlú ìgbẹ́kẹ̀lé àti àlàáfíà bíkòṣepé wọ́n bá ti ronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn (wo Alma 5:15–17).

  27. Ojúkojú pẹ̀lú Ààrẹ àti Arábìnrin Oaks (worldwide youth broadcast, Feb. 23, 2020), facetoface.ChurchofJesusChrist.org.

  28. Wo General Handbook: Serving in The Church of Jesus Christ of Latter-day Saints, 1.2; 10.2.1.3; 11.2.1.3, ChurchofJesusChrist.org.

  29. Ojúkojú pẹ̀lú Ààrẹ àti Arábìnrin Oaks, facetoface.ChurchofJesusChrist.org.

  30. Wo Preach My Gospel: A Guide to Missionary Service (2018), 156, ChurchofJesusChrist.org; see also Alma 5:15–17.

  31. Quentin L. Cook, “Èrèdí àti Ìgbèrò” (ọ̀rọ̀ tí a fúnni níbi ìdanilẹkọ fún àwọn ààrẹ tuntun míṣọ̀n, June 2019).

  32. Ẹkọ àti Àwọn Májẹmú 58:28

  33. Neil L. Andersen, “Faith Is Not by Chance, but by Choice,” Liahona, Nov. 2015, 66.

  34. Neil L. Andersen, “Oju Ìgbàgbọ́,” Liahona, May 2019.

  35. Àkórí Iyejú Oyè-àlùfáà Árọ́ni,” ChurchofJesusChrist.org.

  36. 3 Néfì 27:7–8.