Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ìlépa Dé Òpin Iré-ìje
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2021


Ìlépa Dé Òpin Iré-ìje

Kìí ṣe púpọ̀ nípa ohun tí à nlà kọjá ní ayé ṣùgbọ́n ohun ti à ndà.

Bí mo ti ka ìwé Ìṣe àwọn Àpóstélì àti àwọn lẹ́tà Páùlù, ó yà mí lẹ́nu bí ìfẹ́ àti ìmoore nínú iṣẹ́ ìsìn Páùlù, kíkọ́ni, àti jíjẹ́ ẹ̀rí Jésù Krístì ṣe ntìí ká. Báwo ni irú ẹni bẹ́ẹ̀ ṣe lè sìn pẹ̀lú irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ àti ọpẹ́, nípàtàkì ní ríro àwọn ìjìyà nlá rẹ̀? Kíni ó fún Páùlù ní ìwúrí láti sìn? “Mo lépa dé òpin iré-ìje fún oye ìpè gíga Ọlọ́run nínú Krístì Jésù.”1

Láti lépa dé òpin iré-ìje ni láti fi òtítọ́ tẹ̀ramọ́ “ọ̀nà híhá ati tóóró èyí tí ó darí sí ìyè ayérayé”2 pẹ̀lú Olùgbàlà wa àti Bàbá wa ní Ọ̀run. Páùlù yẹ àwọn ìjìyà rẹ̀ wò bí “àìyẹ láti fiwé pẹ̀lú ògo èyí tí a fi hàn wá.”3 Lẹ́tà Páùlù sí àwọn Ará Fílíppì, èyí tí ó kọ nígbàtí wọ́n dèé sínú ẹ̀wọ̀n ni lẹ́tà ayọ̀ àti yíyayọ̀ tó bonimọ́lẹ̀, àti ìgbani-níyànjú sí gbogbo wa, nípàtàkì ní ìgbà ìṣòro àti àìnírètí yí. Gbogbo wa ni a nílò ìgboyà láti ọ̀dọ̀ Páùlù: “Mo ṣírò gbogbo nkan ṣùgbọ́n àdánù fún títayọ ìmọ̀ Krístì Jésù Olúwa mi: nítorí ẹni tí mo jìyà àdánù gbogbo nkan, mo sì ṣírò rẹ̀ sí asán, kí nlè jèrè Krístì.”4

Nígbàtí a bá wo iṣẹ́-ìsìn Páùlù, a ó ni ìmísí àti ìgbéga nípa “àwọn Paul” ti ọjọ́ wa, ẹni tí ó sìn bákannáà, kọ́ni, àti jíjẹ́ ẹ̀rí pẹ̀lú ìfẹ́ àti ìmoore ní àárín àwọn ìpenijà tí wọ́n dojúkọ nínú ayé wọn àti nínú ayé àwọn olólùfẹ́ wọn. Ìrírí kan tí mo ní ní ọdún mẹsan sẹ́hìn ràn mí lọ́wọ́ láti mọ pàtàkì lílépa dé òpin iré-ìje.

Ní 2012, bí mo ti rìn fún ìgbà àkọ́kọ́ ní ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò olórí, èmi kò lè ran ara mi lọ́wọ́ nínú ìbòmọ́lẹ̀ àti àìpé. Nínú mi ohùn kan wà tí ó ndún léraléra, “Ìwọ ko yẹ nihin! Àṣìṣe líle kan ti ṣẹlẹ̀!” Gẹ́gẹ́ bí mo ti nrìn tí mo ngbìyànjú lati wá ibì kan láti joko, Alàgbà Jeffrey R. Holland rí mi. Ó wá bá mi ó sì wípé, “Edward, ó dára láti rí ọ nihin,” ó sì fọwọ́kàn mí lójú jẹ́jẹ́. Mo ní ìmọ̀lára bí ọmọ-ọwọ́! Ìfẹ́ rẹ̀ àti dídìmọ́ fún mi ní ọ̀yàyà ó sì ràn mí lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀lára ẹ̀mí wíwà pẹ̀lú, ẹ̀mí jíjẹ́ arákùnrin. Ní ọjọ́ keji, mo ṣe àkíyèsí Alàgbà Holland tí ó nṣe ohun kannáà tí ó ṣe sí mi ní àná, ó fi òyàyà fọwọ́kan ojú Alàgbà Dallin H. Oaks jẹ́jẹ́, ẹni tí ó jẹ́ àgbà si!

Ní àkokò náà mo ni ìmọ̀lára ìfẹ́ Olúwa nípasẹ̀ àwọn ọkùnrin wọ̀nyí tí a ṣe ìmúdúró fún bí àwọn wòlíì, aríran, àti olùfihàn. Alàgbà Holland, nípasẹ̀ inúrere rẹ̀, ìṣe àbínibí, ràn mí lọ́wọ́ láti borí ìmọtaraẹni-nìkan mi àti ìmọ̀lára ti àìpé mi. Ó ràn mí lọ́wọ́ láti dojúkọ iṣẹ́ mímọ́ àti àláyọ̀ sí èyí tí a ti pè mí—láti mú àwọn ọkàn wá sọ́dọ̀ Krístì. Òun, bíiti Páùlù àtijọ́, nawọ́ sí mi láti tẹ̀síwájú dé òpin iré-ìje.

Ní dídùn-mọ́ni, Páùlù gbà wá níyànjú láti tẹ̀síwájú nígbàtí à npè wá láti gbàgbé èyí tí ó wà lẹ́hìn—àwọn ẹ̀rù wa tó kọjá, ìdojúkọ wa tó kọjá, ìkùnà wa to kọjá, àti ìbànújẹ́ wa tó kọjá. Ó npè wá, bíiti wòlíì wa ọ̀wọ́n, Ààrẹ Russell M. Nelson, “sí ọ̀nà titun si, mímọ́ si.”5 Ìlérí Olùgbàlà jẹ́ òtítọ́: “Nítorí ẹnìkẹ́ni tí ó bá fẹ́ gba ẹ̀mí rẹ̀ là yíò sọọ́ nù: ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ sọ ẹ̀mí rẹ̀ nù nitorì mi yíò ri”6

Ní ọ̀rọ̀ mi àkọ́kọ́ ti ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò, mo pín ìrírí kan nípa ìyá mi tí ó nkọ́ mi láti ṣiṣẹ́ ní pápá wa. “Máṣe wẹ̀hìn wò,” ni ó sọ. “Wo iwájú ohun tí a ṣì níláti ṣe!”7

Ní lílọ sí òpin ayé rẹ̀, nígbàtí iyá bá àrùn jẹjẹrẹ jagun, ó gbé pẹ̀lú Naume àti èmi. Ní alẹ́ kan mo gbọ́ tí ó nsunkún nínú yàrá-ibùsùn rẹ̀. Ìrora rẹ le gidi, àní lẹ́hìn lílo egbòogi ojúmọ́ to gbẹ̀hìn ti morphine ní wákàtí méjì ṣíwájú.

Mo wọ yàrá rẹ̀ mo sì sunkún pẹ̀lú rẹ̀. Mo gbàdúrà síta fún un láti gba ìrọ̀rùn kíákíá látinú ìrora rẹ̀. Lẹ́hìnnáà ó ṣe ohun kannáà tí ó ṣe nínú pápá ní ọdún díẹ̀ sẹ́hìn: ó dúró ó sì kọ́ mi ní ẹ̀kọ́ kan. Èmi kò ní gbàgbé ojú rẹ̀ ní àkokò náà: àìlera, ìpalára, àti níuń ìrora kíkún, ó wò pẹ̀lú àánú lórí ìkorò ọmọkùnrin rẹ̀. Ó rẹrin nínú omije rẹ̀, ó wo ojú mi tààrà, ó wípé, “Kìí ṣe ìwọ tàbí ẹlòmíràn, ṣùgbọ́n ó wà lọ́wọ́ Ọlọ́run bóyá ìrora yí yíò kúrò tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́.”

Mo joko sóke jẹ́jẹ́. Òun náà joko jẹ́jẹ́. Ìran náà dúró ní híhàn yékéyéké nínú ọkàn mi. Ní alẹ́ náà, nípasẹ̀ ìyá mi, Olúwa kọ́ mi ní ẹ̀kọ́ kan tí yíò dúró pẹ̀lú mi títíláé. Bi ìyá mi ti fi ìtẹ́wọ́gbà ìfẹ́ Ọlọ́run hàn, mo rántí èrèdí tí Jésù Krístì fi jìyà nínú Ọgbà Gẹ́thsémánì àti ní orí àgbélèbú ní Golgotha. Ó wípé: “Kíyèsĩ èmi ti fi ìhìnrere mi fún yín, èyí sì ni ìhìnrere [mi] èyítí èmi ti fi fún yín---pé mo wá sínú ayé láti ṣe ìfẹ́ Bàbá mi, nítorípé Bàbá mi ni ó rán mi.”8

Krístì ní Gẹ́tsémánì

Bí mo ti ronú lórí wòlíì wa ọ̀wọ́n àwọn ìbèèrè ti-wòlíì Ààrẹ Nelson sí wa ní ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò tó kọjá. Ààrẹ Nelson bèèrè pé: “Ṣe ẹ̀ nfẹ́ láti jẹ́kí Ọlọ́run Borí nínú ayé yín? Ṣe ẹ̀ nfẹ́ láti jẹ́kí Ọlọ́run jẹ́ agbára pàtàkì jùlọ nínú ayé yín?… Njẹ ẹ ó fàyè gba ohùn Rẹ̀ láti jẹ́ … ìṣíwájú lórí gbogbo ọ̀kánjúwà míràn? Ṣé ẹ̀ nfẹ́ láti jẹ́ kí ìfẹ́ Rẹ̀ ó gbé tiyín mì?9 Ìyá mi ìbá ti fèsì pẹ̀lú ẹ̀dùn-ọkàn ṣùgbọ́n gbọingbọin “bẹ́ẹ̀ni,” àti àwọn ọmọ Ìjọ olotitọ míràn káàkiri gbogbo-ayé yíò fèsì pẹ̀lú ẹ̀dùn ọkàn gbọingbọin “bẹ́ẹ̀ni.” Ààrẹ Nelson, a dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ fún ìmísí àti ìgbéga wa pẹ̀lú àwọn ìbèèrè ti wòlíì wọ̀nyí.

Láìpẹ́, mo ní ìjíròrò ní Pretoria, Gúsù Áfríkà, pẹ̀lú bíṣọ́ọ̀pù tí ó sìn ìyàwó rẹ̀ àti ọmọbìnrin rẹ̀ àgbà ní ọjọ́ kannáà. Ìgbé ayé wọn ni a gbà nípasẹ̀ àjàkálẹ̀ àrùn yí. Mo bèèrè bí ó ti nṣe. Èsì Bíṣọ́ọ̀pù Teddy Thabete fún ipinnu mi lókun láti tẹ̀lé àwọn ọ̀rọ̀ àti àmọ̀ràn láti ọ̀dọ̀ wòlíì, aríran, àti olùfihàn Olúwa. Bíṣọ́ọ̀pù Thabete fèsì pé ìrètí àti ìtùnú wà nígbàgbogbo ní mímọ̀ pé Olùgbàlà ti gbé ìrora àwọn ènìyàn Rẹ̀ lé orí Ararẹ̀, kí Ó lè mọ àti tìwá lẹ́hìn.10 Pẹ̀lú ìgbàgbọ́ ìjìnlẹ̀ ó jẹ́ ẹ̀rí pé, “Mo ṣọpẹ́ fún ètò ìgbàlà, ètò ìdùnnú.” Nígbànáà ó bí mi ní ìbèèrè kan, “Njẹ́ èyí kìí ṣe ohun tí wòlíì wa ngbìyànjú láti kọ́ wá ní ìpàdé àpapọ̀ tó kọjá?”

Nígbà tí àwọn ìpènijà ti ayé ikú yíò wá sọ́dọ̀ gbogbo wa ní ọ̀nà kan tàbí òmíràn, ẹ jẹ́ kí a dojúkọ àfojúsùn wa “títẹ̀[síwájú] dé òpin iré-ìje,” èyí ni “oye ìpè gíga Ọlọ́run.”10

Ìpè ìrẹ̀lẹ̀ mi sí gbogbo wa ni láti máṣe juwọ́lẹ̀! A ti pè wá láti “pa ohun ìdíwọ́ gbogbo ti sí apákan, àti ẹ̀ṣẹ̀ tí ó rọrùn láti dì mọ́ wa, kí a sì máa fi suúrù súré ìje tí a gbé ka iwájú wa, kí a máa wo Jésù olùpilẹṣẹ àti aláṣepé wa.”11

Kìí ṣe púpọ̀ nípa ohun tí à nlà kọjá ní ayé ṣùgbọ́n ohun ti à ndà. Ayọ̀ wà nínú ìtẹ̀síwájú dé òpin iré-ìje. Mo jẹ́ ẹ̀rí pé Ẹni tí ó borí ohun gbogbo yíò ràn wá lọ́wọ́ bí a ti nwo Ó lókè. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.