Olùgbàlà ti Araẹni Wa
Nítorí ìrúbọ ètùtù Rẹ̀, Olùgbàlà ní agbára láti wẹnimọ́, wòsàn, àti fún wá lókun ní ọ̀kọ̀ọ̀kàn.
Mo dúpẹ́ láti wà pẹ̀lú yín ní òwúrọ̀ Ọdún-àjínde oníyanu yí. Nígbàtí mo nronú nípa Ọdún-àjínde, mo nifẹ láti tún àwọn ọ̀rọ̀ tí a sọ nípasẹ̀ àwọn ángẹ́lì sí àwọn tí wọ́n wà ní Ọgbà Ibojì sọ: “Èéṣe tí ẹ̀ fi nwá alààyè ní àárìn òkú? Kò si níhĩn , ṣùgbọ́n ó ti jíìnde.”1 Mo jẹ́ ẹ̀rí pé Jésù ti Násárẹ́tì jíìnde àti pé Ó wà láàyè.
Kíni Èrò Yín Nípa Krístì?
Ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n sẹ́hìn, ẹnìkejì ìránṣẹ́ ìhìnrere mi àti èmi pàdé a sì kọ́ ọkùnrin olóye kan ẹnití ó jẹ́ olùkọ̀wé ìdásí níbi ìwé-ìròhìn ìbílẹ̀ kan ní Davao, Philippines. A gbádùn kíkọ́ ọ nítorí òun ní àwọn ìbèèrè púpọ̀ ó sì ní ọ̀wọ̀ gidigidi fún àwọn ìgbàgbọ́ wa. Ìbèèrè ìrántí jùlọ tí ó bèèrè lọ́wọ́ wa ni “Kíni èrò yín nípa Krístì?”2 Àwa bákanáà fi ìdùnnú pín ìmọ̀lára wa a sì jẹ́ ẹ̀rí nípa Jésù Krístì. Lẹ́hìnnáà ó tẹ nkan jáde lórí àkọlé kannáà tí ó ní àwọn ọ̀rọ̀ ìyanu àti gbólóhùn ọ̀rọ̀ nípa Olùgbàlà. Mo rántí níní ìtẹ̀mọ́ra ṣùgbọ́n kìí ṣe gbígbé ga. Ó ní àlàyé dídára ṣùgbọ́n ní ìmọ̀lára òfo àti agbára ti àìní ẹ̀mí.
Wíwá láti Mọ̀ Ọ́ Si Dáradára.
“Kíni Èrò Yín Nípa Krístì?” Mò ndamọ̀ pé bí mo ṣe mọ Olùgbàlà sí nfún okun mi lágbára láti gbọ́ Tirẹ̀ àti bí mo ṣe ndáhùn bákannáà. Ní ọdún díẹ̀ sẹ́hìn, Alàgbà David A. Bednar bèèrè àwọn ìbèèrè wọ̀nyí bí ara ọ̀rọ̀ rẹ̀: “Ṣé a mọ nípa Olùgbàlà nìkan, tàbí ṣé a nwá láti mọ̀ Ọ́ púpọ̀ si? Báwo ni a ṣe nwá láti mọ Olúwa?”3
Bí mo ṣe nṣe àṣàrò àti ìjíròrò, mo wá sí ìdámọ̀ kedere pé ohun tí mo mọ̀ nípa Olùgbàlà ju bí mo ṣe mọ́ Ọ́ dájúdájú lọ. Lẹ́hìnnáà mo pinnu láti fi ìtiraka si láti mọ̀ Ọ́. Mo dúpẹ́ fún àwọn ìwé mímọ́ àti ẹ̀rí àwọn olotitọ ọmọẹ̀hìn ọkùnrin àti obìnrin Jésù Krístì. Ìrìnàjò ti ara mi ní àwọn ọdún díẹ̀ sẹ́hìn ti mú mi lọ sí ọnírurú àwọn òpópónà ti àṣàrò àti ìwákiri. Mo gbàdúrà pé Ẹ̀mí Mímọ́ yíò fún yín ní ọ̀rọ̀ kan tí ó tóbi gidi ju àwọn ọ̀rọ̀ àìpé tí mo ti kọ.
Àkọ́kọ́, a nílò láti damọ̀ pé mímọ Olùgbàlà ni ìlépa pàtàkì jùlọ ìgbé ayé wa. Ó níláti gba ìṣíwájú lórí ohunkóhun míràn.
“Ìyè àìnípẹ̀kun náà sì ni èyí, kí wọn kí ó lè mọ̀ ọ, ìwọ nìkan Ọlọ́run òtítọ́, àti Jésù Krístì, ẹnití ìwọ rán.”4
“Jésù wí fun pé, èmi ni ọ̀nà, ati òtítọ́ ati ìyè: kò sí ẹnikẹ́ni tí ó le wá sí ọ̀dọ̀ Bàbá, bíkòṣe nípasẹ̀ mi.”5
“Èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé: ẹni tí ó bá tẹ̀lé mi kò ní rìn nínú òkùnkùn, ṣùgbọ́n yíò ní ìmọ́lẹ̀ ìyè.”6
Èkejì, bí a ti nwá láti mọ̀ Olùgbàlà púpọ̀ si, àwọn ẹsẹ ti ìwé mímọ́ àti ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì di onítumọ̀ típẹ́típẹ́ sí wa gan tí wọ́n fi di àwọn ọ̀rọ̀ ti arawa. Kìí ṣe nípa ṣíṣe ẹ̀dà àwọn ọ̀rọ̀, níní ìmọ̀lára, àti ìrírí àwọn ẹlòmíràn bí ọ̀pọ̀ ti nwá láti mọ̀ ọ́ fúnrawa, ní ọ̀nà yíyàtọ̀ arawa, nípa ìyẹ̀wò lórí ọ̀rọ̀ náà7 àti gbìgba ẹ̀rí kan láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́. Bí wòlíì Álmà ti kéde:
“Njẹ́ ẹ̀yin kò mọ̀ pé èmi mọ̀ nípa àwọn ohun wọ̀nyí fúnra mi? Kíyèsi, mo jẹ́ ẹ̀rí sí yín pé èmi mọ̀ pé àwọn ohun èyí tí mo sọ wọ̀nyí jẹ́ òtítọ́. Àti pé báwo ni ẹ ṣe rò pé mo mọ̀ òdodo wọn?
“Ẹ kíyèsĩ, èmi wí fún un yín pé Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọ́run ni ó fi wọ́n hàn mí. Kíyèsi, èmi ti gba ãwẹ̀ mo sì ti gbàdúrà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ kí èmi kí ó lè mọ́ ohun wọ̀nyí fúnra mi. Àti nísisìyí èmi sì mọ̀ ọ́ fúnra mi pé òtítọ́ ni nwọ́n; nítorítí Olúwa Ọlọ́run ti fi nwọ́n hàn mí nípa Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀; èyí sì ni ẹ̀mí ìfihàn èyítí ó wà nínú mi.”8
Ẹ̀kẹ́ta, ìmọ̀ púpọ̀si pé Ètùtù Jésù Krístì wa fúnrawa àti olúkúlùkù yíò ràn wá lọ́wọ́ láti mọ̀ Ọ́. Nígbàkugbà ó rọrùn fún wa láti rónú àti láti sọ̀rọ̀ nípa Ètùtù Krístì ní ọ̀ràn gbangba ju kí a dá pàtàkì araẹni rẹ̀ nínú ìgbé ayé wa mọ̀. Ètùtù Jésù Krístì ni àìlópin àti ayérayé àti wíwàní gbogbo ìbú àti ìjìnlẹ̀ rẹ ṣùgbọ́n ti araẹni pátápátá àti olúkúlùkù nínú àbájáde rẹ̀. Nítorí ìrúbọ ètùtù Rẹ̀, Olùgbàlà ní agbára láti wẹnimọ́, wòsàn, àti fún wá lókun ní ọ̀kọ̀ọ̀kàn.
Ìfẹ́ Olùgbàlà nìkan, èrèdí Rẹ̀ nìkan làti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, ni láti ṣe ìfẹ́ ti Bàbá. Ìfẹ́ Bàbá ni fun Un láti ṣe àtìlẹhìn ní “[mímú] ìyè ayérayé ènìyàn wá sí ìmúṣẹ”9 nípa dída “alágbàwí wa pẹ̀lú Bàbá.”10 Nítorínáà, “bíótilẹ̀jẹ́ pé Ọmọ ni, síbẹ̀ ó kọ́ ìgbọràn nípa àwọn ohun èyí tí ó jìyà; a ṣe ní pípé, ó sì di olùpìlẹ̀ṣẹ̀ ìgbálà ayèrayé sí gbogbo àwọn tó gbọ̀ràn si.”11
“Òun yíò sì jáde lọ, ní ìjìyà ìrora àti ìpọ́njú àti àdánwò onírurú. …
Òun yíò sì gbé ikú lé ara rẹ̀, kí òun kí ó lè já ìdè ikú èyítí ó de àwọn ènìyàn rẹ̀; òun yíò sì gbé gbogbo àìlera wọn lé ara rẹ̀, kí inú rẹ̀ lè kún fún ãnú, … kí òun kí ó lè mọ̀ nípa ti ara bí òun yíò ṣe ran àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ́wọ́ nínú gbogbo àìlera wọn.
“… Ọmọ Ọlọ́run jìyà nípa ti ara, kí ó lè gbé ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ ka orí ara rẹ̀, kí ó lè pa gbogbo ìwà ìrékọjá nwọn rẹ́ nípa agbára ìdásílẹ̀ rẹ̀”12
Èmi yíò fẹ́ láti pín ìrírí jẹ́jẹ́ kan tí ó júwe ìlàkàkà tí à nní nígbàmíràn láti dìmọ́ àbínibí araẹni ti Ètutù Olúwa.
Àwọn ọdún sẹ́hìn, ní ìfipè olórí tí mo tẹ̀lé, mo ka Ìwé ti Mọ́mọ́nì láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin mo sì sàmì sí àwọn ẹsẹ tí ó tọ́ka sí Ètùtù Olúwa. Olórí mi bákannáà pè mi láti múra àkópọ̀ ojú ewé kan nípa ohun tí mo kọ́ sílẹ̀. Mo wí fúnra mi pé, ojú ewé kan? Dájúdájú, ìyẹn rọrùn.” Sí ìyàlẹ́nu mi, bákannáà, mo rí tí iṣẹ́ náà le gan an, mo sì kùnà.
Látìgbà náà mo ti damọ̀ pé mo kùnà nítorí mo fo àmì náà mo sì ní àwọn àròsínú àìtọ́. Àkọ́kọ́, mo lérò kí àkópọ̀ náà jẹ́ ìmísí sí gbogbo ènìyàn. Àkópọ̀ náà yẹ fún mi kìí ṣe fún ẹlòmíràn. Ó yẹ kí ó di ìmọ̀lára àti ẹ̀dùn ọkàn mi mú nípa Olùgbàlà àti ohun tí Ó ti ṣe fún mi nítorínáà kí ó lè mú àwọn ìrírí ìyanu, pàtàkì, àti ti ẹ̀mí araẹni wá sókè ní gbogbo ìgbà tí mo bá kàá.
Èkejì, mo lérò kí àkópọ̀ náà jẹ́ ọlọ́lá àti fífẹ̀ kí ó sì ní àwọn ọ̀rọ̀ nlá àti gbólóhùn nínú. Kìí ṣe nípa títóbi rárá. Ó yẹ kí ó jẹ́ ìkéde jẹ́jẹ́ ìdánilójú àti híhàn kedere. “Nítorí ọkàn mi yọ̀ ní kedere; nítorí irú ọ̀nà báyĩ ni Olúwa Ọlọ́run gbà nṣiṣẹ́ lãrín àwọn ọmọ ènìyàn. Nítorí Olúwa Ọlọ́run fi ìmọ́lẹ̀ fún lílóye.”13
Ẹ̀kẹ́ta, mo lérò kí ó jẹ́ pípé, àkópọ̀ kan láti parí gbogbo àkọ́pọ̀—àkópọ́ tó gbẹ̀hìn tí ẹnìkan kò lè àti tí kò sì gbọ́dọ fikún—dípò iṣẹ́ tó nlọ lọ́wọ́ tí mo lè fi ọ̀rọ̀ kan kún nihin tàbí gbólóhùn kan níbẹ̀ bí lílóye mi nípa Ètùtù Jésù Krístì ti ndàgbà si.
Ẹ̀rí àti Ìfipè
Bí ọ̀dọ́mọkùnrin kan, mo kọ́ púpọ̀ látinú àwọn ìbárasọ̀rọ̀ mi pẹ̀lú bíṣọ́ọ̀pù mi. Ní àwọn ọdún rírọ̀ wọnnì, mo kọ́ láti fẹ́ràn àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí látinú orin alárinrin kan:
Mo dúró ní gbogbo ìyanu fún ìfẹ́ tí Jésù fi fún mi,
Dààmú ní oore-ọ̀fẹ́ tí ó fifún mi ní kíkún.
Mo wárìrì láti mọ̀ pé a kàn án mọ́gi nítorí mi,
Nítorí fún mi, ẹlẹ́ṣẹ̀, ó jìyà, ó ṣẹ̀jẹ̀ ó sì kú.
Wòlíì Mórónì pè wá: “Àti nísisìyí, èmi ó kìn yín láti wá Jésù yí nìpa ẹnití àwọn wòlíì àti àpóstélì ti kọ.”15
Ààrẹ Russell M. Nelson ṣèlérí pé “Bí [a] bá tẹ̀síwájú láti kọ́ gbogbo ohun tí [a] lè kọ́ nípa Jésù Krístì, … ipá [wa] láti yí kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ yíò pọ̀ si. [Ìfẹ́ wa] láti pa àwọn òfin mọ́ yíò gbilẹ̀.”16
Ní Ọjọ́-ìsinmi Ọdún-àjínde yí, gẹ́gẹ́bí Olùgbàlà ṣe jáde wá látinú òkúta iboji, njẹ́ kí a jí látinú oorun ti ẹ̀mí kí a dìde kọjá ìkuùkù iyèmejì, àwọn ìdìmú ẹ̀rù, ìgbéraga ìpani, àti ìmúdákẹ́ ìtẹ́lọ́rùn. Jésù Krístì àti Baba Ọ̀run wà láàyè. Mo jẹri nípa ìfẹ́ pípé Wọn fún wa. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.