Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Kíkọ́ni ní Ọ̀nà ti Olùgbàlà
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2021


Kíkọ́ni ní Ọ̀nà ti Olùgbàlà

Ojúṣe nàá dá lórí ọ̀kọ̀ọ̀kan wa gan an láti tẹ̀lé àpẹrẹ ti Olùkọ́ni àti láti kọ́ni bíi Tirẹ̀.

Àwọn Olùkọ́ni Títayọ

Ní oṣù díẹ̀ sẹ́hìn, ọmọ-kílásì mi tẹ́lẹ̀ láti ilú tí a ti bí mi ní Overton, Nevada, daba kì a kó ẹ̀bùn Kérésìmesì kan papọ̀ fún àyànfẹ́ olùkọ́ wa ìgbà ọmọ-ọwọ́, tí ó ṣe ayẹyẹ ọjọ́-ìbí ọdún kejìdínlọ́gọ́ọ̀rún láìpẹ́. Ó kọ́ wa láti jẹ́ onínúrere, síṣe pàtàkì oorun ránpẹ́, ayọ̀ mílíkì àti kírákà gíráhámù, àti láti ní ìfẹ́ ara wa. Ẹ ṣé, Arábìnrin Davis, fún jíjẹ́ irú oníyanu olùkọ́ kan bẹ́ẹ̀.

Arábìnrin Davis

Mo ní olùkọ́ míràn tí ó tayọ nígbàtí mò nlọ sí Kọ́lẹ́jì Ricks ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́hìn. Mo nmúrasílẹ̀ láti sìn ní míṣọ̀n mo sì rò pé yíò jẹ́ ìrànlọ́wọ́ láti lọ sí kílásì ìmúrasílẹ̀ fún iṣẹ́ ìhìnrere. Ìrírí ohun tí mo ní yí ìgbé ayé mi padà.

Láti ọjọ́ ìkínní kílásì, mò damọ̀ pé mo wà ní iwájú ọ̀gá olùkọ́ kan. Olùkọ́ náà ni Arákùnrin F. Melvin Hammond. Mo mọ pé Arákùnrin Hammond nifẹ Olúwa ó sì ní ìfẹ́ mi. Mo lè rí i ní ìwò ojú rẹ̀ kí nsì gbọ́ ọ nínú ohùn rẹ̀. Nígbàtí ó nkọ́ni, Ẹ̀mí nfi òye sí inú mi. Ó kọ́ni ní ẹ̀kọ́, ṣùgbọ́n bákannáà ó pè mí láti kọ́ ọ fúnra mi. Ìpè náà ràn mí lọ́wọ́ láti rí ojúṣe mi kedere láti kọ́ ẹ̀kọ́ Olúwa fúnra mi. Ìrírí náà yí mi padà títíláé. Ẹ ṣe, Arákùnrin Hammond, fún kíkọ́ni ní ọ̀nà ti Olùgbàlà.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, gbogbo ènìyàn lẹtọ láti ní irú ìrírí ìkọ́ni bẹ́ẹ̀ nínú ilé àti ní ilé ìjọsìn bákannáà.

Ọ̀rọ̀ ìṣaájú sí Wá, Tẹ̀lé Mi fún wa ní ìran ohun tí ìkọ́ni bíi ti Krístì le ṣeyọrí. Ó wípé “Àbájáde gbogbo ìkọ́ni àti ikẹkọ ìhìnrere, ni láti mú ìyípadà-ọkàn wa sí Jésù Krístì jinlẹ̀ kí ó sì ràn wá lọ́wọ́ láti dà bíi Tirẹ̀ si. … Irú ìkọ́ni ìhìnrere tí ó nfún ìgbàgbọ́ wa lókun tí ó sì ndarí sí iṣẹ́ ìyanu ti ìyípadà ọkàn, gbogbo rẹ̀ kìí ṣẹ̀lẹ̀ lẹ́ẹ̀kannáà. Ó kọjá yàrá-ìkàwé [náà] sí inú ọkàn olúkúlùkù àti ibùgbé.”1

Àwọn ìwé mímọ́ fihàn pé iṣẹ́ ìránṣẹ́ Olùgbàlà ní Amẹ́ríkà àtijọ́ ní ipa gidigidi ó sì tànká tí “gbogbo àwọn ènìyàn náà ni a sì yí lọ́kàn padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa, ní gbogbo ori ilẹ̀ náà, àti àwọn ara Néfì àti àwọn ara Lámánì, kò sì sí ìjà àti àríyàn-jiyàn kankan ní ãrín wọn, wọ́n sì nfi òdodo bá ara wọn lò.”2

Báwo ni ìkọ́ni wa ṣe lè ní irú ipa kannáà ní orí àwọn tí a nifẹ? Báwo ni a ṣe lè kọ́ni bíi ti Olùgbàlà síi kí a sì ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti jinlẹ̀ síi ní yíyí ọkàn padà jí? Ẹ fi ààyè gbà mí láti fún yín ní àwọn àbá díẹ̀.

Farawé Olùgbàlà

Akọ́kọ́ tí ó ṣíwájú jùlọ, ẹ gbà á lé orí ara yín láti kọ́ gbogbo ohun tí ẹ lè kọ́ nípa Ọ̀gá Olùkọ́ni Fùnrarẹ̀. Báwo ni Ó ti fi ìfẹ́ hàn fún àwọn ẹlòmíràn? Kíni wọ́n ní ìmọ̀lára rẹ̀ nígbàtí Ó kọ́ wọn? Kíni Ó Kọ́ni? Kíni àwọn ìrètí Rẹ̀ nípa àwọn tí Ó kọ́? Lẹ́hìn tí ẹ bá jíròrò àwọn ìbèèrè bí ìwọ̀nyí, ẹ yẹ̀ẹ́ wò kí ẹ sì tún ọ̀nà ìkọ́ni yín ṣe láti dàbíi Tirẹ̀.

Ìjọ pèsè ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun èlò ìkọ́ni nínú áàpù Ibi-ìkàwé Ìhìnrere àti lórí ChurchofJesusChrist.org. Irú ohun èlò bẹ́ẹ̀ ní àkọlé Kíkọ́ni ní Ọ̀nà Olùgbàlà. Mo pè yín láti kà àti láti ṣe àṣàrò gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀. Àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ wọ̀nyí yíò ràn yín lọ́wọ́ nínú ìlàkàkà yín láti dà bii ti Krístì si nínú ìkọ́ni yín.

Ẹ Ṣí Agbára àwọn Ẹbí Sílẹ̀

Àbá mi tó kàn ni a lè júwe pẹ̀lú ìrírí kan tí mo ní ní oṣù díẹ̀ sẹ́hìn nígbàtí mo dúró láti bẹ ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n kan wò. Mo lè gbọ́ tí ìyàwó rẹ̀ nsọ̀rọ̀ lábẹ́nú pẹ̀lú ẹnìkan nítorínáà mo tètè ṣe gáfárà fúnra mi kí ó lè padà sí ọ̀dọ̀ ẹbí rẹ̀.

Wákàtí kan tàbí bẹ́ẹ̀ lẹ́hìnnáà mo gba ọ̀rọ̀ àtẹ̀jíṣẹ́ yí láti ọ̀dọ́ ìyàwó rẹ̀ dídára: “Arákùnrin Newman, ó ṣe pé o wá. Awa ìba ti pè ọ́ wọlé, ṣùgbọ́n mo fẹ́ pín ohun tí à nṣe pẹ̀lú rẹ. Láti ìgbà àjàkálẹ̀ àrùn ti a ti njíròrò Wá, Tẹ̀lé Mi pẹ̀lú àwọn ọmọ wa àgbà lọ́jọọjọ́ Ìsinmi lórí Súùmù. Ó ti nṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu gan an. Mo rò pé ó jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ tí ọmọbìnrin wa ti ka Ìwé ti Mọ́mọ́nì fúnrarẹ̀. Òní ni ẹ̀kọ́ ìgbẹ̀hìn lórí Ìwé ti Mọ́mọ́nì, àti pé a ṣẹ̀ṣẹ̀ nparí ni nígbàtí o dé bí. … Mo rò pé yíò wù yín láti gbọ́ bí Wá, Tẹ̀lé Mi, Súùmù, àti àjàkálẹ̀ àrùn kan ti pèsè ànfàní ní ìgbà tó yẹ láti yí ọkàn kan padà. … Ó mú mi ronú bí iye àwọn iṣẹ́ ìyanu kékèké ti pọ̀ tó tí ó ti nṣẹlẹ̀ ní ìgbà òdì yí.”

Èyí dún sí mi bí ìmúṣẹ kan ti ìlérí tí Ààrẹ Russell M. Nelson ṣe ní Oṣù Kẹwa 2018. Ó wípé kíkọ́ ẹ̀kọ́ ìhìnrere ní ààrin-gbùngbun ilé, àti tí ó ní àtìlẹhìn-Ìjọ “ní agbára ìṣe láti ṣí agbára awọn ẹbí sílẹ̀, bí ẹbí kọ̀ọ̀kan ti ntẹ̀lé e tọkàntọkàn àti pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ láti yí ilé wọn padà sí ibi mímọ́ ígbàgbọ́. Mo ṣe ìlérí pé bí ẹ ṣe nfi aápọn ṣiṣẹ́ láti tún ilé yín ṣe sí gbùngbun ikẹkọ ìhìnrere kan, bí ìgbà ti nlọ àwọn ọjọ́ Ìsinmi yín yíò ládùn nítoọ́tọ́. Inú àwọn ọmọ yín yíò dùn láti kẹkọ àti láti gbé ìgbé ayé àwọn ìkọ́ni ti Olùgbàlà. … Ìyípadà nínú ẹbí yín yíò jẹ̀ kíakíá àti ìmúdúró.”3 Ìlérí dídára kan ni èyí!

Láti jẹ́ ìgbé ayé-yíyípadà nítòótọ́, ìyípadà ọkàn sí Jésù Krístì a gbọ́dọ̀ wé mọ́ gbogbo ẹ̀mí wa kí ó sì wọnú gbogbo abala ìgbé ayé wa. Èyí ni ìdí tí ó fi gbọ́dọ̀ fojúsùn sí ààrin gbùngbun ìgbé ayé wa—àwọn ẹbí àti ilé wa.

Ẹ Rántí Pé Ìyípadà-ọkàn Jẹ́ Ti Araẹni

Àbá mi tó kẹ́hìn ni láti rántí pé ìyípadà-ọkàn gbọ́dọ̀ wá láti inú. Bí a ti júwe nínú òwé àwọn wúndíá mẹwa, a kò lè fún ẹ̀lòmíràn ní òróró ti ìyípadà ọkàn wa, bí ó ti wú kí a lè fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ tó. Bí Alàgbà David A. Bednar ti kọ́ni: “Òróró iyebíyé yí ni a gbà ọ̀kán lkan ní ìgbà kan … pẹ̀lú sùúrù àti ìtẹramọ́. Kò sí ọ̀nà àbùjá kankan ní àrọ́wọ́tó; ko sí ìrusókè ìmúrasílẹ̀ ìṣẹ́jú ìgbẹ̀hìn tí ó ṣeéṣe.”4

Wá, Tẹ̀lé Mi dá lé orí òtítọ́ náà. Mo fi wé ángẹ́lì tí ó ran Néfì lọ́wọ́ láti kọ́ nípa Jésù Krístì tí ó wípé, “Wòó!”5 Bíi ti ángẹ́lì náà, Wá, Tẹ̀lé Mi pè wá láti wo inú àwọn ìwé mímọ́ àti ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì òde-òní ní èrò láti rí Olùgbàlà kí a sì gbọ́ Ọ. Bíi ti Néfì, a ó gba ìkọ́ni ti-araẹni láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí nígbàtí a bá nkà á tí a sì njíròrò ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Wá, Tẹ̀lé Mi ni amúṣẹyá tí ó nran ẹnìkọ̀ọ̀kan wá lọ́wọ́ láti wọ inú àwọn omi alàà ìyè ti ẹ̀kọ́ Krístì jinlẹ̀jinlẹ̀.

Ojúṣe òbí jọ ara wọn ní àwọn ọ̀nà púpọ̀. Àwọn ọmọ njogún ohun púpọ̀ láti ọwọ́ àwọn òbí wọn, ṣùgbọ́n ẹ̀rí kìí ṣe ọ̀kan lára wọn. A kò lè fún àwọn ọmọ wa ní ẹ̀rí kan ju bí a ṣe lè mú kí irúgbìn dàgbà. Ṣùgbọ́n a lè pèsè àyíká tí ó ní ìkẹ́, pẹ̀lú ilẹ̀ rere, tí kò ní àwọn ẹ̀gún tí yíò “gún ọ̀rọ̀ náà pa.” A lè tiraka láti ṣe ẹ̀dá àwọn ipò dídára nítorí kí àwọn ọmọ wa—àti àwọn míràn tí a fẹ́ràn—lè rí àyè fún irúgbìn láti, “[gbọ́] ọ̀rọ̀ náà, kí wọn ó sì ní [ìmọ̀] rẹ̀”6 kí wọn ó sì ṣe àwárí fún ara wọn “pé irúgbìn náà dára.”7

Arákùnrin Newman àti ọmọkùnrin rẹ̀ Jack.

Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́hìn, ọmọkùnrin mi Jack àti èmi ní ànfàní láti ṣe eré-ìje Àtijọ́ ní St. Andrews ní Scotland, níbití eré gọ́lfù ti bẹ̀rẹ̀. Ó kàn jẹ́ oníyanu! Ní ìpadàbọ̀ mi mo gbìyànjú láti mú títóbi ìrírí náà wá sí ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn. Ṣùgbọ́n èmi kò lè ṣéé. Àwọn fọ́tò, fídíò, àti àwọn àpèjúwe mi dídárajùlọ kò kún ojú òsùnwọ̀n rárá. Ní òpin mo dáa mọ̀ pé ọ̀nà kanṣoṣo fún ẹnìkẹ́ni láti mọ ọlánlá St. Andrews ni láti ní ìrírí rẹ̀—láti rí títóbi àwọn ọ̀nà dídára, mí àfẹ́fẹ́ náà símú, ní ìmọ̀lára àtẹ́gùn ní ojú wọn, àti kí wọn gbá yínyín àṣìṣe díẹ̀ sínú àwọn ihò gbígbòòrò àti àwọn igbó òdòdó líle títóbi, èyí tí a ṣe pẹ̀lú ìjáfefe nlá.

Bẹ́ẹ̀ ni ó wà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. A lè kọ́ni lẹkọ rẹ̀, a lè wàásù rẹ̀, a lè ṣe àlàyé rẹ̀. A lè sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, a lè ṣe àpèjúwe rẹ̀, àní a lè jẹ́ ẹ̀rí nípa rẹ̀. Ṣùgbọ̀n títí di ìgbà tí ẹnìkan bá ní ìmọ̀lára ọ̀rọ̀ mímọ́ Ọlọ́run tí ó kán sórí ẹ̀mí rẹ̀ lọ́kùnrin tàbí lóbìrnin bí àwọn ìrì láti ọ̀run nípasẹ̀ agbára ti Ẹ̀mí,8 yíò máa dàbí wíwo káàdì kan tàbí àwọn fọ́tò ìgbà ìsinmi ti ẹlòmíràn. Ẹ níláti lọ síbẹ̀ fúnra yín. Ìyípadà ọkan jẹ́ ìrìnàjò araẹni—ìrìnàjò ti ìkórajọ kan.

Gbogbo ẹni tí ó nkọ́ni nínú ilé àti ní ilé ìjọsìn, le fún àwọn míràn ní ànfàní láti ní àwọn ìrírí ẹ̀mí ti ara wọn. Nípasẹ̀ àwọn ìrírí wọ̀nyí, wọn yíò wá “mọ òtítọ́ ohun gbogbo” fún ara wọn.9 Ààrẹ Nelson kọ́ni pé, “Bí ẹ bá ní àwọn ìbèère àtinúwá nípa ìhìnrere tàbí Ìjọ, bí ẹ ti yàn láti jẹ́kí Ọlọ́run borí, a ó darí yín láti rí àti láti ní ìmọ̀ àwọn òtítọ́ pípé àti ti ayérayé, tí yíò tọ́ yín sọ́nà nínú ìgbé ayé yín yío sì ràn yín lọ́wọ́ láti dúró gbọingbọin lórí ipa ọ̀nà májẹ̀mú.”10

Mú Ìkọ́ni Gbèrú Gidigidi

Mo pe àwọn olórí àti àwọn olùkọ́ ní gbogbo ìṣètò Ìjọ láti dámọ̀ràn papọ̀ pẹ̀lú àwọn òbí àti ọ̀dọ́ ní èrò láti mú ìkọ́ni gbèrú gidigidi ní gbogbo ipele—ní àwọn èèkàn, ní wọ́ọ̀dù, àti nínú ilé. A lè ṣe àṣeyọrí rẹ̀ nípa kíkọ́ni ní ẹ̀kọ́ àti pípe ìbáraẹnisọ̀rọ̀ tí ó kún fún Ẹ̀mí nípa àwọn òtítọ́ tí Ẹ̀mí Mímọ́ ti kọ́ wa nínú àwọn àkokò ìdákẹ́ jẹ́jẹ́ ti àṣàrò araẹni wa.

Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n nínú Krístì, ojúṣe nàá dá lórí ọ̀kọ̀ọ̀kan wa gan an láti tẹ̀lé àpẹrẹ ti Olùkọ́ni àti láti kọ́ni bíi Tirẹ̀. Ọ̀nà Rẹ̀ ni ọ̀nà tòótọ́! Bí a ti ntẹ̀lé E “nígbàtí yíò bá farahàn a ó dàbíi rẹ̀, nítorí a ó ri i bí ó ṣe wà; kí a lè ní ìrètí yi; kí a lè di yíyàsímímọ́ àní bí òun ṣe jẹ́ mímọ́.”11 Ní orúkọ Rẹ̀ ẹni tí ó jínde, Ọ̀gá Olùkọ́ni Fúnrarẹ̀, Jésù Krístì, àmín.