Àkókò Wa Nìyí!
Ọlọ́run ti ránwa wá síbí, lọ́wọ́lọ́wọ́, ní àkokò pàtàkì yín nínú àkọọ́lẹ̀ ìtàn.
Ní 1978, mo dúró lórí ààyè bọ́ọ̀lù ní pápá-ìṣeré tí a ṣàjọ pẹ̀lu àwọn olùfẹ́ 65,000. Ní iwájú mi ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn alátakò nlá nlá tí ó dàbí ẹni pé wọ́n fẹ́ mú orí mi kúrò. Ó jẹ́ eré àkọ́kọ́ mi bi ìdábẹ̀rẹ̀ ní Àjùmọ̀ṣe Bọ́ọ̀lù Orílẹ̀-èdè, àti pé a nṣeré ìṣaájú èèkàn nlá tí nṣàkóso. Láti jẹ́ olódodo, mo bèèrè bóyá mo dára tó láti wà lórí pápá. Mo ṣubú sẹ́hìn láti ju ìwé ìrìnnà mi àkọ́kọ́, àti bi mo ṣe fi bọ́ọ̀lù sílẹ̀, a lù mi ju bí a ti lù mí tẹ́lẹ̀ lọ. Ni àkokò yẹn, ti mo dùbúlẹ̀ lábẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí àwọn eléré ìdárayá nla wọ̀nyí, mo ṣe ìyàlẹ́nu kíni mo nṣe níbẹ̀. Mo ní ìpinnu lati ṣe. Èmí ó ha jẹ́ kí iyèméjì mi bọrí mi, tàbí èmi ó rí ìgboyà àti okun láti dìde àti láti tẹ̀síwájú.
Èmi kò mọ̀ ní àkokò náà bíi ìrírí yi yio ṣe múra mi sílẹ̀ fún àwọn ànfàní ní ọjọ iwájú. Mo nílò láti kọ́ ẹ̀kọ́ pé mo lè jẹ́ onígboyà àti alágbára ní ojú àwọn ipò ìṣòro.
Eré bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá lè má fẹ́rẹ̀ ṣe pàtàkì bí àwọn ìpèníjà tí ẹ kojú bí ìránṣẹ́ Olúwa. Ní ìgbà púpọ̀, kò ní sí pápá-ìṣeré tí ó kún fún àwọn ènìyàn to nwòran. Ṣùgbọ́n àwọn ìgboyà ìpinnu yín yio ní ipa ayérayé.
Bóyá a kìí ní ìmọ̀lára pé o ni ìpèníjà. Ṣùgbọ́n Bàbá Ọ̀run rí wa gẹ́gẹ́ bí olùgbéga aláíbẹ̀rù ìjọba Rẹ. Ìdí nì yẹn tí Ó rán wa wá sihin ní ìgbà onípinnu nla yí nínú àkọọ́lẹ̀ ìtàn ayé. Àkókò Wa Nìyí!
Fetísí ohun tí Ààrẹ Russell M. Nelson sọ kété lẹ́hìn tí o di Ààrẹ Ìjọ: “Olùgbàlà àti Olùràpadà, Jésù Krístì, yio ṣe lára àwọn iṣẹ́ alágbára Rẹ̀ laarin ìsisìyí sí ìgbà tí Yìó bá padà wá lẹ́ẹ̀kansi. A ó ri àwọn àmì iṣẹ́ ìyanu pé Ọlọ́run Bàbá àti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, nṣe àkóso Ìjọ yí nínú ọlánlá àti ògo” (“Ìfihàn fún Ìjọ, Ìfihàn fún Ayé Wa,” Liahona, May 2018, 96).
Àwọn iṣẹ́ alágbára jùlọ? Àwọn àmì iṣẹ́ ìyanu? Kíni ni wíwò yẹn ṣe rí? Kíni ipa tí a kó, àti báwo ni a ṣe lè ní òye ohun tí a ó ṣe? Mi ò mọ gbogbo ìdáhùn náà, ṣùgbọ́n mo mọ̀ pé Olúwa nílò wa láti ṣetán! Lílo agbára oyèàlúfà ní yíyẹ kò ì ti ṣe kókó rí.
Ṣe a gbàgbọ́ nínú wòlíì Ọlọ́run? Njẹ́ a lè rí kí á sì gba ìpín wa? Bẹ́ẹ̀ni, a lè ṣe, àti bẹ́ẹ̀ni, a gbọdọ, nítorí àkókò wa nìyí!
Nígbàtí a bá gbọ́ àwọn ìtàn ìrànṣẹ́ Ọlọ́run tó wá níwájú wa—bíi Mósè, Màríà, Mórónì, Álmà, Ẹ́stérì, Jósẹ́fù, àti àwọn míràn—wọn rí bíí títóbi ju ayé. Ṣùgbọ́n wọ́n ko fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sí wa. Wọ́n jẹ́ ènìyàn déédé tí wọ́n dojú kọ àwọn ìpèníjà. Wọ́n ní igbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa. Wọ́n ṣe àwọn yíyàn tí ó tọ́ ní àwọn àkókò pàtàkì. Àti, pẹ̀lú ìgbàgbọ nínú Jésù Krístì, wọ́n ṣiṣẹ́ tó yẹ kí wọ́n ṣe ní àkókò wọn.
Ronú lórí akọni Joshua Májẹ̀mú Láéláé. Ó jẹ́ ọmọlẹ́hìn olùfọkànsìn Mósè, ọ̀kan nínú àwọn adarí nlá jùlọ nínú ìtàn. Lẹ́hìn tí Mósè kúrò, ni àkókò Joshua. Òún ní láti darí àwọn ọmọ Ísráẹ́lì lọ sí ilẹ̀ ìlérí. Báwo ni ó ti ṣe ìyẹn? A bí Joshua o si dàgbà ní oko-ẹrú ní Egypt. Kò ní ìwé àmúdání tàbí àwọn fídíò ìtọ́sọ́nà láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún un. Kò tilẹ̀ ní fóònúìyára kan! Ṣùgbọ́n ó ní ìlérí yí láti ọ̀dọ̀ Olúwa:
“Bí mo ti wà pẹ̀lú Mósè, bẹ́ẹ̀ni Èmi yio wà pẹ̀lú rẹ: Èmi kì yio ja ọ kulẹ̀ tàbí pa ọ́ tì.
“Jẹ́ Alágbára kí o sì ní ìgboyà rere kan” (Joshua 1:5–6).
Nígbàtí mo jẹ Àádọrin titun tí nkò sì ní ìrírí, mo gba ipè lórí aago láti ilé-iṣẹ́ Àjọ Ààrẹ i[kínní, ní ìbèrè bóyá mo lè ṣojú wòlíì ni bíbẹ ọ̀dọ́mọkùnrin kan wò ni ilé-ìwòsàn—lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Orúkọ ọ̀dọ́mọkùnrin nã ni Zach. Ó nmúra láti di ìránṣẹ́ ìhìnrere ṣùgbọ́n ó ni ìjàmbá ọkọ̀ ó sì fi orí ṣèṣe gidi.
Bí mo ṣe nwakọ̀ lọ ilé-ìwòsàn, ọkàn mi lọ sóke. Iṣẹ́ fún wòlíì—ṣé ò nṣeré ni? Kínni èmi yìó dojú kọ́? Báwo ni èmi yio ṣe ran ọ̀dọ́mọkùnrin yí lọ́wọ́? Njẹ́ mo ní ìgbàgbọ́ tí ó tó? Àdúrà kíkan àti òye pé mo ní àṣẹ oyèàlúfà mímọ́ di àwọn ìdákọrò mi.
Nígbàtí mo dé, Zach sùn ní orí-ibùsùn kan nílé ìwòsàn. Ètò kan dúró ní ṣíṣetán lati wọ́ọ lọ si yara iṣẹ́-abẹ ki àwọn dókítà lè ṣèrànwọ́ nípa títẹ̀ lórí ọpọlọ rẹ̀. Mo wo ìyá rẹ tí ó ní omijé àti ọ̀rẹ rẹ̀ tó nbẹ̀rù tí ó dúró nítòsí, mo sì mọ̀ dájú pé Zach nílò ìbùkún oyèàlúfà kan. Ọ̀rẹ́ rẹ̀ gba oyèàlúfà Melchizedek láìpẹ́, nítorí náà mo sọ fun kí ó rànmílọ́wọ́. Mo ní ìmọ̀lára agbára oyèàlúfà bí a ṣe fi ìrẹ̀lẹ̀ fún Zach ní ìbùkún. Lẹ́hìnnáà o yára lọ fún iṣẹ́ abẹ náà, ìmọ̀lára àlááfíà sì fi ìdí rẹ múlẹ̀ pè Olùgbala yio mu àwọn nkan wà ni ìbámu pẹ̀lú ọgbọ́n Rẹ.
Àwọn òṣìṣẹ́ ìlera ṣe X-ray tó kẹ́hìn ṣaájú ṣíṣe sínsín ìbẹ̀rẹ̀. Wọ́n ṣe àwárí, sí ìyàlẹ́nu wọn, pé kò nílò iṣẹ́ abẹ rárá.
Lẹ́hìn ìtọ́jú àìlera púpọ̀, Zach kọ́ lati rìn ati láti sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kansi. Ó sin míṣọ̀n àṣeyọrí ati pé ó ngbé ẹbí ti o ni ẹwà dìde bayi.
Dájúdájú, kìí ṣe ìgbàgbogbo ni irú àbájáde náà. Mo ti fi àwọn ìbùkún oyèàlúfà míràn pẹ̀lú ìgbàgbọ́ déédé fúnni, ati pé Olúwa kò fúnni ní ìwòsàn pípé nínú ayé yi. A gbẹ́kẹ̀le èrèdí Rẹ̀ ati pé a sì fi àwọn àbájáde sílẹ̀ fún Un. A kò lè fi ìgbà gbogbo yan àbájáde ti àwọn ìṣe wa, ṣùgbọ́n a lè yan láti ṣetán láti ṣe ìṣe.
Àjọ Ààrẹ Ìkínní lè má tilẹ̀ ní kí a ṣojú wọn ní irú ipò ìdẹ́rùbà-ẹ̀mí kan láéláé. Ṣùgbọ́n a pè gbogbo wa láti ṣe àwọn ohun ìyípadà-ayé bí àwọn aṣojú Olúwa. Òun kò ní pa wá tì. Àkókò Wa Nìyí!
Pétérù, olóyè Àpóstélì Olùgbàlà, wà nínú ọkọ-ojú omi lórí òkun nígbàtí Jésù rìn lórí omi. Ó fẹ́ darapọ̀ mọ́ Ọ, Olùgbala sì wípé, “Wá.” Ní ìgboyà, àti ní ìyanu, Pétérù fi ààbò ọkọ̀ ojú-omi sílẹ ó bẹ̀rẹ̀ sí nrìn sọ́dọ̀ Olùgbala. Ṣùgbọ́n nígbàtí Pétérù dojúkọ afẹ́fẹ́ nla, ìgbàgbọ́ rẹ̀ dínkù. “Ó bẹ̀rù; nígbàtí ó bẹ̀rẹ̀ síí rì, ó kígbe, ó wípé, Olúwa, gbà mí. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ Jésù sì na ọwọ́ rẹ, ó si dìí mú.” (Wo Máttéù 13:18–2.)
Nígbàtí àwọn afẹ́fẹ́ bá nfẹ́ nínú ayé wa, níbo nì ìdojúkọ wa wà? Rántí, nígbàgbogbo pé orísun kan ti o nígbẹkẹle agbára ati ìgboyà ni ó wà. Apá Jésù nà síwa, gẹ́gẹ́bí wọ́n ti nà sí Pétérù. Bí a ti dé ọ̀dọ̀ rẹ, Yíò fi ìfẹ́ gbàwá. Àwa ni ti Rẹ̀. Ó wípé, “Má bẹ̀rù: nítorí mo ti rà ọ́ padà, mo ti pè ọ́ ní orúkọ rẹ; ti èmi ni ìwọ” (Isaiah 43:1). Òun yíò borí ní ayé rẹ tí o bá gbà Á láyè. Yíyàn náà jẹ́ tiyín! (Wo Russell M. Nelson “Ẹ Jẹ́ Kí Ọlọ́run Borí,” Liahona, Nov. 2020, 92-95.)
Ní ìgbẹ̀hìn ayé rẹ̀, Joshua bẹ̀bẹ̀ fún àwọn ènìyàn rẹ, “ẹ yàn ẹnití ẹ̀yin o ma sìn loni; … ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi àti ilé mi ni, Olúwa ni àwa o ma sìn” (Joshua 24:15). Nítorí àwọn yíyàn tí ó ṣe láti sin Olúwa, Joshua di adarí nlá ní àkókò rẹ. Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, èyí ni àkókò wa! Àti pé àwọn yíyàn wa yio pinnu àyànmọ wa (wo Thomas S. Monson, “Àwọn Ìpinnú Nmú Àyànmọ́ Wá” [Brigham Young University fireside, Nov. 6, 2005], speeches.byu.edu).
Lákokò ti mo nsìn bi Bíṣọ́ọ̀pù, a ní àkòrí-ọ̀rọ̀ ní wọ́ọ̀dù wa: Àwọn yíyàn dídára dọ́gba pẹ̀lú ìdùnnú—ayérayé. Àwọn ọ̀dọ́ yio kọjá mi ní gbọ̀ngán náà ní wí wípé, “Bíṣọ́ọ̀pù, Mò nyan àwọn yíyàn tí ó dára!” Ìyẹn ni àlá ti bíṣọ́ọ̀pù kan!
Kinni “yíyàn tí ó dára” túmọ̀ sí? Ẹnìkan bèrè lọ́wọ́ Jésù lẹ́ẹ̀kan ri, “èwo ni àṣẹ nlá nínú òfin?” Ó dáhùn pe:
“Kí ìwọ kí ó fi gbogbo àyà rẹ, àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo inú rẹ fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ.
“Èyí ni èkínní àti òfin ńlá.
“Èkejì sì dàbíi rẹ̀, Ìwọ fẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.” (Máttéù 22:37–39
Èmi kò mọ̀ nípa rẹ, ṣùgbọ́n nígbàtí mo bá ka àwọn òfin nlá méjì wọ̀nyí, mo ṣe àwárí ẹ̀kẹ́ta, òfin mímọ̀: lati nifẹ ara rẹ.
Njẹ́ ẹ ti ronú rí pé níní ìfẹ́ ara rẹ jẹ́ òfin kan? Njẹ́ a lè nifẹ Ọlọ́run àti àwọn ọmọ Rẹ̀ bí a kò bá nifẹ ara wa?
Gẹ́gẹ́bí adarí ọlọgbọ́n ṣe gba ọkùnrin kan nímọ̀ràn ẹni tí o ngbìyànjú lati borí àwọn ọdún ti àwọn yíyan ìparun. Ó ní ìmọ̀lára ìtìjú, o ṣiyèmejì pé òun kò yẹ fún ìfẹ́ ẹnikẹ́ni.
Olùdarí rẹ̀ wí fun pé, “Olúwa mọ̀ ọ́, nifẹ rẹ, inú Rẹ̀ sì dùn dáradára sí ọ àti àwọn ìgbésẹ̀ ìgboyà ti o ngbé.” Ṣùgbọ́n o fi kun, “[O] nílò láti gbọ́ òfin láti nifẹ ara rẹ ki o lè ni ìmọ̀lara [ìfẹ́] Ọlọ́run àti àwọn míràn.”
Nígbàtí arákùnrin yí gbọ́ àmọ̀ràn náà, ó rí ayé pẹ̀lú ojú titun. Ó sọ lẹ́hìnáà pé, “Mo ti lo gbogbo ayé mi ni ìgbìyànjú láti wa àlááfíà àti ìtẹ́wọ́gbà. Mo ti wá àwọn nkan wọnnì ní ọ̀pọ̀ àwọn ibi tí ko yẹ. Nínú ìfẹ́ Bàbá Ọ̀run àti Olùgbàlà nìkan ni mo tì le rí ìtùnú. Mo mọ̀ pé wọ́n fẹ́ kin nifẹ ara mi; ọ̀nà kanṣoṣo nìyí tí mo lè ni ìmọ̀lára ìfẹ́ wọn fún mi.”
Bàbá wa Ọ̀run fẹ́ kí a fẹ́ràn ara wa—kìí ṣe kí á lè gbéraga tàbí kí á ní ìmọtaraẹni-nìkan, ṣùgbọ́n kí á lè rí ara wa bí Òún ti rí wa: bí ọmọ tí Ó nṣìkẹ́. Nígbàtí òtítọ́ yi bá jinlẹ̀ sínú ọkàn wa, ìfẹ́ wa fún Ọlọ́run yio dàgbà. Nígbàtí a bá wo ararwa pẹ̀lú ọ̀wọ̀, ọkàn wa ṣí sílẹ̀ láti ṣe dáadáa sí àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú. Bí a ti nṣe ìdámọ̀ yíyẹ ti ọ̀run wa si, ni a ó ní òye òtítọ́ ti ọ̀run yi dáradára si: pé Ọlọ́run ti rán wa wá síbí, ní bayi, ní àkokò pàtàkì yii nínú àkọọ́lẹ̀ ìtàn, kí o lè ṣe ohun tí o dára jùlọ tí o ṣeéṣe pẹ̀lú àwọn ọrẹ àti àwọn ẹ̀bùn tí o ní. Àkókò Wa Nìyí! (Wo Russell M. Nelson, “Dída Àwọn Mìllẹ́níà Tòótọ́” [ìfọkànsìn gbogbo ayé fún àwọn ọ̀dọ́ àgbà, Jan. 10, 2016], broadcasts.ChurchofJesusChrist.org.)
Joseph Smith kọ́ pé gbogbo wòlíì, ní gbogbo ọjọ́ orí, “fojú síwájú pẹ̀lú ìfojúsọ́nà ayọ̀ tí a n gbé; … wọ́n ti kọ àti kọ àti sọtẹ́lẹ̀ ti ọjọ́ wa; … a jẹ́ ènìyàn tí o ní ojúrere tí Ọlọ́run ti [yàn] láti mú ògo Ọjọ́-ìkẹhìn ṣẹ” (Àwọn Ìkọ́ni Ààrẹ Ìjọ: Joseph Smith [2007], 186).
Bí o ṣe ndojú kọ ìpèníjà ojoojúmọ́, rántí ìfọ̀kanbalẹ̀ yí tí a ṣe lati ọwọ Alàgbà Jeffrey R. Holland: “púpọ̀ sinmi lórí àwọn èjìká wa, ṣùgbọ́n yìó jẹ́ ìrírí ológo àti àṣeyọrí. … Ìṣẹ́gun ní ìdíje ìparí yíì ni a ti kéde tẹ́lẹ̀. Ìṣẹ́gun ti wà tẹ́lẹ̀ nínú àwọn ìwé àkọsílẹ̀ … , àwọn ìwé-mímọ́!” (“”Má Bẹ̀rù, Gbàgbọ́ Nìkan” [address to Church Educational System religious educators, Feb. 6, 2015], broadcasts.ChurchofJesusChrist.org).
Ní òpin ọ̀sẹ̀ Ọdún-àjínde dídára yí, njẹ́ kí nnawọ́ ìpè pé kí gbogbo wa gbàdúrà láti dámọ̀ kí a sì gba ojúṣe olúkúlùkù wa mọ́ra bí a ṣe nmúrasílẹ̀ fún ọjọ́ ológo nígbàtí Olùgbàlà yíò wá lẹ́ẹ̀kansi. Olúwa nifẹ wa ju bí a ṣe lóye lọ, Òun yíò sì dáhùn àwọn àdúrà wa! Bóyá a wà ní pápá-ìṣeré bọ́ọ̀lù, ní yàrá ilé-ìwòsàn, tàbí ní ilé ara wa, a lè jẹ́ apákan pàtàkì àwọn ìṣẹ̀lẹ olókìkí wọ̀nyí—nítorí àkokò wa nìyí! Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.