Ọkàn Ìṣọ̀kan Làpapọ̀
Bí ẹ ṣe nmú arayín gbòòrò pẹ̀lú inúrere, ìtọ́jú, àti àánú, mo ṣe ìlérí pé ẹ ó gbé ọwọ́ tí ó rẹlẹ̀ ga ẹ ó sì wo ọkàn sàn.
Ìfihàn
Njẹ́’ èyì kò fanimọ́ra bí ìwákiri pàtàkì ti sáyẹ́nsì ṣe nfi ìgbàmíràn gba ìmísí nípasẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ jẹ́jẹ́ bí ápù kan tó njábọ́ láti orí igi?
Loni, ẹ jẹ́ kí npín ìwákiri kan tí ó ṣẹ̀lẹ̀ nítorí ẹgbẹ́ àyẹ̀wò ehoro.
Ní àwọn 1970, àwọn oluwadi gbé àyẹ̀wò kan kalẹ̀ láti yẹ àwọn àbájáde oúnjẹ wò lórí ìlera ọkàn. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn oṣù, wọ́n bọ́ ẹgbẹ́ ìṣàkóso kan ti ehoro ní oúnjẹ ọlọra-púpọ̀ wọ́n sì nbojútó ìfúnpa, mímí ọkàn, àti kolẹstẹrọ̀.
Bí a ti nretí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ lára àwọn ehoro fi dídágbàsókè ọ̀rá sínú orí àwọn iṣọn-àlọ̀ wọn. Gbogbo èyí kò tán síbẹ̀! Àwọn oluwadi ti ṣàwárí ohunkan tí ó mú ọgbọ́n díẹ̀ wá. Bíotilẹ̀jẹ́pé gbogbo ehoro ti dàgbàsókè, pẹ̀lú ìyàlẹnu ẹgbẹ́ kan ní púpọ̀ bí ìdá ọgọta ní ìdínkù ju àwọn míràn. Ó hàn bíi pé wọ́n nwo àwọn ẹgbẹ́ ehoro yíyàtọ̀ méjì.
Sí àwọn amòye-sáyẹ́nsì, èsì bí irú èyí lè fa àìsùn. Báwo ni èyí ṣe jẹ́? Àwọn ehoro jẹ́ obí irúkannáà láti New Zealand, latinú àkójọ ẹ̀jẹ̀ tó fẹ́rẹ̀ barajọ. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ti gba oye ìbámu oúnjẹ kannáà.
Kíni èyí túmọ̀ sí?
Ṣé èsì wọ̀nyí ti sọ àṣàrò di àìpé? Njẹ́ àwọn àṣìṣe wà nínú ṣíṣe àyẹ̀wò náà?
Àwọn amoye-sáyẹ́nsì náà tiraka lásán láti ní ìmọ̀ àbájáde àìròtẹ̀lẹ̀ yí!
Nígbẹ̀hìn, wọn fojú wọn sí òṣìṣẹ́ iwadi. Ṣé ó ṣeéṣe pé àwọn oluwadi ti ṣe ohunkan láti nípá lórí èsì? Bí wọn ṣe nlépa èyí, wọ́n ri pé gbogbo ehoro pẹ̀lú ọ̀rá díẹ̀ nínú ti wà lábẹ́ ìtọ́jú ọkàn lára oluwadi. Ó bọ́ àwọn ehoro rẹ̀ ní oúnjẹ kannáà bíiti gbogbo àwọn míràn. Ṣùgbọ́n, bí amoye sáyẹ́nsì ti ròhìn, “ó jẹ́ ẹ̀nìkan àìwọ́pọ̀ onínúrere àti olùtọ́jú.” Nígbàtí ó bọ́ àwọn ehoro rẹ̀, “ó sọ̀rọ̀ sí wọn, gbéwọnmọ́ra ó sì kẹ́ wọn. … Òun kò lè ṣèrànwọ́ rẹ̀. Bí òun ṣe jẹ́ nìyẹn.”1
Ó ṣe ju fífún àwọn ehoro ní oúnjẹ lásán. Ó fún wọn ní ìfẹ́!
Ní wíwò àkọ́kọ́, ó dàbí kò ṣeéṣe kí èyí jẹ́ èrèdí fún ìyàtọ̀ kíákíá, ṣùgbọ́n ẹgbẹ́ ìwadi kò rí ìṣeéṣe kankan míràn.
Nítorínáà wọn tún àyẹ̀wò náà ṣe—ní àkokò yí pẹ̀lú ìṣàkóso híhá fún gbogbo ìyípadà míràn. Nígbàtí wọ́n tú èsì-ìgbẹ̀hìn ká, ohun kannáà ṣẹlẹ̀! Àwọn ehoro lábẹ́ ìtọ́jú olùfẹ́ni olùwadi ní abájáde ìlera pàtàkì púpọ̀.
Àwọn amòye sáyẹ́nsì tẹ èsì àṣàrò yí jáde nínú iwé-ìròhìn olókìkí Sáyẹ́nsì.2
Àwọn ọdún lẹ́hìnáà àwọn àwárí àyẹ̀wò yí ṣì dàbí alágbára ní àárín ìletò egbòogi. Ní àwọn àìpẹ́ ọdún, Dókítà Kelli Harding tẹ ìwé kan jáde tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ Àbájáde Ehoro tí ó gba orúkọ rẹ̀ látinú àyẹ̀wò. Ìparí Rẹ̀: “Mú ehoro kan pẹ̀lú ìgbé-ayé àìnì-lera. Sọ̀rọ sí i. Dì í mú. Fún ní ìfẹ́ni. … Ìbáṣepọ̀ náà ṣe ìyàtọ̀ kan. Nígbẹ̀hìn,” ó parí, “Oun tí ó npa ìlera wa lára nínú àwọn ọ̀nà onítumọ̀ jùlọ ní púpọ̀ láti ṣe pẹ̀lú bí a ṣe nṣe sí àwọn ẹlòmíràn, bí a ṣe ngbé, àti bí a ṣe nronú nípa ohun tí ó túmọ̀ sí láti jẹ́ ẹlẹ́ran-ara.”3
Nínú ayé àìní-ẹ̀sìn, afárá tí ó so sáyẹ́nsì pẹ̀lú ìhìnrere àwọn òtítọ́ papọ̀ nígbàmíràn dàbí gigùn àti díẹ̀ ní àárín. Síbẹ̀síbẹ̀ bí Krístẹ́ni, ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì, àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn—àwọn èsì àṣàrò sáyẹ́nsì yí lè dàbí àtinúdá si ju ìyanilẹ́nu. Fún mi, èyí gbé bíríkì míràn kalẹ̀ nínú ìpìlẹ̀ inúrere bí ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀, wíwo ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ sàn—ọ̀kan tí ó lè wo ẹ̀dùn ọkàn, níti-ẹmí, àti, bí a ṣe júwe nihin, àní ti ara.
Ọkàn Ìṣọ̀kan Làpapọ̀
Nígbàtí a bèèrè, “Olùkọ́ni, èwo ni òfin tó tóbi jùlọ?” èsì Olùgbàlà láti “fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ̀,” tí, “Ìwọ yíò fẹ́ ẹnìkejì rẹ bí ara rẹ̀ tẹ̀le.”4 Ìfèsí Olùgbàlà fi-agbàra-kún ojúṣe àtọ̀runwá wa. Àwọn wòlíì àtijọ́ pàṣẹ pé “kí a máṣe ní ìjà ní ẹnìkan sí òmíràn, ṣùgbọ́n kí [a] wo iwájú … , níní ọkàn [wa] papọ̀ ní ìṣọ̀kan àti ní ìfẹ́ sí òmíràn.”5 A tún kọ wa síwájúsi pé “agbára tàbí ipá … tó yẹ kí a dìmú … nípasẹ̀ ìrẹ̀lẹ̀ àti ọkàn-pẹ̀lẹ́, … nípasẹ̀ inúrere, … láìsí ẹ̀tàn.”6
Mo gba ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ yí gbọ́ bí ìlò káríayé sí gbogbo àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn: àgbàlagbà, ọ̀dọ́, àti ọmọdé.
Pẹ̀lú iyẹn lọ́kàn, ẹ jẹ́ kí nsọ̀rọ̀ tààra sí yín ẹ̀yin ọmọdé tí ẹ jẹ́ ọjọ́-orí Alakọbẹrẹ ní àkokò kan.
Ẹ ti ní ìmọ̀ tẹ́lẹ̀ bí ó ti ṣe pàtàkì tó láti ní inúrere. Ègbè ọ̀kan lára àwọn orin Alakọbẹrẹ yín, “Mo Ngbìyànjú láti Dà Bíi Jésù,” kọ́ni:
Ẹ fẹ́ ara yín bí Jésù ti fẹ́ẹ yín.
Ẹ gbìyànjú láti fi inúrere han nínú ohungbogbo tí ẹ̀ nṣe.
Ẹ ṣe pẹ̀lẹ́ àti ìfẹ́ni ní iṣe àti ní èrò,
Nítorí ìwọ̀nyí ni àwọn ohun tí Jésù kọ́ni.7
Àní síbẹ̀síbẹ́, nígbàmíràn ẹ lè ní ìgbà ìṣòro. Nihin ni ìtàn kan tí ó lè ràn yín lọ́wọ́ nípa ọkùnrin Alakọbẹrẹ kan tí a pè ní Minchan Kim láti Gúsù Korea. Ẹbí rẹ̀ dárapọ̀ mọ́ Ìjọ ní bí ọdún mẹ́fà sẹ́hìn.
“Níjọ́ kan ní ilé-ìwé, díẹ̀ lára àwọn akẹ́gbẹ́-kílásì mi nfi akẹkọ míràn ṣe yẹ̀yẹ́ nípa pípè e ní àwọn orúkọ. Ó dàbíi yẹ̀yẹ́, nítorí fún àwọn ọ̀sẹ̀ díẹ̀ mo darapọ̀ mọ́ wọn.
“Ọ̀sẹ̀ púpọ̀ lẹ́hìnnáà, ọmọdékùnrin náà sọ fún mi àní bíótilẹ̀jẹ́pé ó díbọ́n pé òun kò mikàn, ó ní ìpalára nípasẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ wa, ó sì nsunkún lálaalẹ́. Mo fẹ́rẹ̀ lè sọkún nígbàtí ó sọ fún mi. Mo ní ìmọ̀lára ìkáàánú gan an mo sì fẹ́ láti ràn án lọ́wọ́. Ní ọjọ́ tó tẹ̀le mo lọ ba mo sì gbé ọwọ́ mi lé èjìká rẹ̀ yíká mo bẹ̀bẹ̀, ní sísọ pé, ‘Mo káàánú gidi pé mo fi ọ́ ṣe yẹ̀yẹ́.’ Ó mi orí sí àwọn ọ̀rọ̀ mi, àti pé ojú rẹ̀ sì kún fún ẹ̀kún.
“Ṣùgbọ́n àwọn ọmọdé míràn ṣì nfi ṣe yẹ̀yẹ́. Nígbànáà mo rántí ohun tí mo kọ́ ní kílásì Alakọbẹrẹ: yan òtítọ́. Nítorínáà mo ni kí àwọn akẹ́gbẹ́ kílásì mi dúró. Púpọ̀ lára wọn pinnu láti má tilẹ̀ yípadà, inú sì bí wọn sí mi. Ṣùgbọ́n ọ̀kan lára àwọn ọmọdékùnrin míràn ní òun káàánú, àwa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sì di ọ̀rẹ́ dáadáa.
“Àní bíótilẹ̀jẹ́pé àwọn ènìyàn díẹ̀ ṣì nfi ṣe yẹ̀yẹ́, ó nímọ̀lára dídára si nítorí ó ní wa.
“Mo yan òtítọ́ nípa ríran ọ̀rẹ́ kan lọ́wọ́ nínú àìní.”8
Èyí ko há jẹ́ àpẹrẹ rere fún yín láti gbìyànjú láti dà bíi ti Jésù bí?
Nìsisìyí, fún àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin, bí ẹ ti ndàgbà si, fífi àwọn míràn ṣe yẹ̀yẹ́ lè mú èwú jáde gidi. Ìjayà, ìrẹ̀wẹ̀sì, àti búburújùlọ ni ojúgba pípániláyà. “Nígbàtí ìpániláyà kìí ṣe èrò titun, ìròhìn àwùjọ àti ẹ̀rọ̀ ìgbàlódé ti mú ìpániláyà wá sí ipele titun. Ó di léraléra si, ìdẹ́rùbani wíwà-lọ́wọ́lọ́wọ́—ìpániláyà sáíbà.”9
Ní kedere, ọ̀tá nlo èyí láti pa ìrán yín lára. Kò sí ibìkankan fún èyí nínú àyè-sáìbà, aladugbo, ilé-ìwé, iyejú, àti kílásì. Ẹ jọ̀wọ́ ẹ ṣe gbogbo ohun tí ẹ bá lè ṣe láti mú ìbí wọ̀nyí ní ààbó àti inúrere si. Bí ẹ bá ṣàkíyèsí tàbí kópa nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan èyí, èmi kò mọ àmọ̀ràn kankan ju èyí tí a fúnni nípasẹ̀ Alàgbà Dieter F. Uchtdorf.
“Nígbàtí ó bá kan ìríra, òfófó, ìpatì, ìrẹnisílẹ̀, dídi ìkùnsínú mú, tàbí fífẹ́ láti ṣe ípalára, ẹ jọ̀wọ́ ẹ lo ìwọ̀nyí:
“Da dúró!”10
Ṣe ẹ gbọ́ ìyẹn? Da dúró! Bí ẹ ṣe nmú ara yín gbòòrò pẹ̀lú inúrere, ìtọ́jú, àti àánú, àní níti díjítà, mo ṣe ìlérí pé ẹ ó gbé ọwọ́ tí ó rẹlẹ̀ ga ẹ ó sì wo ọkàn sàn.
Ní sísọ̀rọ̀ sí àwọn ọmọ Alakọbẹrẹ àti ọ̀dọ́, nísisìyí mo darí ọ̀rọ̀ mi sí àwọn àgbàlagbà Ìjọ. A ní ojúṣe pàtàkì láti gbé àwòṣe kan kalẹ̀ àti bí alápẹrẹ inúrere, wíwà pẹ̀lú, àti ọ̀làjú—láti tẹ̀síwájú ní kíkọ̀ni ìwà bíi ti Krístì sí àwọn ìran tó ndìde nínú ohun tí à nsọ àti tí à nṣe. Nípàtàkì ó ṣe kókó bí a bá fi àkíyèsí sàmì ìyíkúrò ti àwùjọ síwájú ìyapa nínú òṣèlú, kílásì àwùjọ, àti bíi títayọ gbogbo ṣíṣe-ènìyàn míràn.
Ààrẹ M. Russell Ballard bákannáà ti kọ́ni pé àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn kò gbọ́dọ̀ jẹ́ onínúrere sí ara wọn nìkan ṣùgbọ́n bákannáà sí gbogbo ènìyàn ní àyíká wọn. Ó ṣàkíyèsí: “Ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan mo máa ngbọ́ tí àwọn ọmọ ìjọ nṣẹ̀ sí àwọn ìgbàgbọ́ míràn nípa fífojú fò wọ́n àti yíyọ wọ́n kúrò. Èyí lè ṣẹlẹ̀ nípàtàkì nínú àwọn ìletò níbití àwọn ọmọ ìjọ wa tí pọ̀ jùlọ. Mo tí gbọ́ nípa àwọn òbí olóyé-tínrín tí wọ́n wí fún àwọn ọmọ wọn pé wọn kò lè ṣeré pẹ̀lú ọmọ kan pàtó ní àdúgbò nítorí ọkùnrin tàbí obìnrin náà kìí ṣe ọmọ Ìjọ. Irú ìwà yí kìí ṣe pípa àwọn ìkọ́ni Olúwa Jésù Krístì mọ́. Èmi kò lè ní òye ìdí tí ọmọ Ìjọ wa kankan yíò fi àyè gba irú àwọn ohun bẹ́ẹ̀ láti ṣẹlẹ̀. … Èmi ko gbọ́ rí kí àwọn ọmọ Ìjọ rọni láti jẹ́ ohunkóhun ṣùgbọ́n ìfẹ́ni, inúrere, ìfaradà, àti ọlọ́yàyà sí àwọn ọ̀rẹ́ wa àti aladugbo àwọn ìgbàgbọ́ míràn.”11
Olúwa nretí wa láti kọ́ wíwà pẹ̀lú ní àwọn ọ̀nà rere síwájú ìṣọ̀kan àti pé àìsí pẹ̀lú ndarí sí ìyapa.
Bí àwọn àtẹ̀lé Jésù Krístì, ó njá wá láyà nígbàtí a bá gbọ́ bí àwọn ọmọ Ọlọ́run ṣe nhuwa búrúkú lórí ẹ̀yà wọn. Ó ti bà wá lọ́kàn jẹ́ láti gbọ́ ìkọlù àìpẹ́ lórí àwọn tí wọ́n jẹ́ dúdú, Asian, Latino, tàbí ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́ míràn. Ẹ̀tanú, àìbalẹ̀-ọkàn ẹ̀yà, tàbí ìjà kò gbọdọ̀ ní àyè níbikíbi nínú àdúgbò, ìletò, tàbí àárín Ìjọ wa.
Ẹ jẹ́ kí ẹnìkọ̀ọ̀kan wa, èyíówù ọjọ́ orí wa, tiraka láti jẹ́ dídára wa si.
Ẹ Fẹ́ràn Àwọn Ọ̀tá Yín
Àní bí ẹ ṣe ntiraka láti mú ara yín gbòòrò nínú ìfẹ́, ọ̀wọ̀, àti inúrere, ẹ ó gba ìpalára tàbí àìdára nípasẹ̀ àwọn àṣàyàn búburú ti àwọn ẹlòmíràn. Kíni a ó ṣe nígbànáà? A ó tẹ̀lé ìkìlọ Olúwa “ ẹ fẹ́ àwọn ọ̀tá yín … ẹ sì gbàdúrà fún àwọn tó nkẹ́gàn yín.”12
Lẹ́hìnnáà kí a ṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe láti borí ìpọ́njú tí a lè gbé sí ipa ọ̀nà wa À ntiraka láti faradà dé òpin, ní gbígbàdúrà ní gbogbo ìgbà pé ọwọ́ Olúwa yíò yí àwọn ipò wa padà. A fi ìdúpẹ́ fún àwọn wọnnì tí Ó gbé sí ipa ọ̀aǹ wa láti tì wá lẹ́hìn.
Mo ní ìwọ̀lọ́kàn nípasẹ̀ àpẹrẹ èyí nínú àkọọ́lẹ̀-ìtàn ìbẹ̀rẹ̀ Ìjọ. Ní ìgbà-òtútù ti 1838 Joseph Smith àti àwọn olórí Ìjọ míràn ni a tì mọ́lé ní ẹ̀wọ̀n Liberty nígbàtí àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ni wọ́n fipá lé lọ kúrò nílé wọn ní ìpínlẹ̀ Missouri. Àwọn Ènìyàn Mímọ́ di alàìnílé, aláìlọ́rẹ́, àti pé wọ́n jìyà gidi látinú òtútù àti àìsí ohun èlò. Àwọn olùgbé Quincy, Illinois, rí ipò àìnírètí wọn wọ́n sì nawọ́ jáde ní àánú àti ìbáṣọ̀rẹ́ sí wọn.
Wandle Mace, olùgbé Quincy, lẹ́hìnnáà rántí ìgbàtí ó kọ́ rí àwọn Ènìyàn Mímọ́ lẹgbẹ odò Mississippi nínú àwọn àgọ́ yíyípadà: “Àwọn kan ní ìtẹ́bẹ́ẹ̀dì tó nà láti ṣe ààbò díẹ̀ kúrò nínú afẹ́fẹ́, … àwọn ọmọ ngbọ̀n ní àyíká iná èyí tí afẹ́fẹ́ nfẹ́ kiri nítorínáà ó ṣèrànwọ́ kékeré fún wọn. Àwọn òtòṣì Ènìyàn Mímọ́ njìyà gidigidi.”13
Wíwo ipò àwọn Ènìyàn Mímọ́, àwọn olùgbé Quincy kọ́rajọ papọ̀ láti pèsè ìrànlọ́wọ́, àwọn kan tilẹ̀ nṣe àtìlẹhìn láti kó àwọn ọ̀rẹ́ wọn titun sọdá odò. Mace tẹ̀síwájú: “[Wọ́n] dáwó lọ́pọ̀lọpọ̀; àwọn olùṣòwò ndíje pẹ̀lú ara wọn bí wọ́n ti lè di ọ̀pọ̀ … pẹ̀lú … ẹlẹ́dẹ̀, … súgà, … bàtà àti aṣọ, ohun gbogbo tí àwọn òtòṣì olùfọ́nká nílò púpọ̀ gan.”14 Láìpẹ́, àwọn olùkówá pọ̀ju àwọn olùgbé Quincy, tí wọ́n ṣí ilé wọn sílẹ̀ tí wọ́n sì pín ohun èlò kékeré wọn ní ìrúbọ araẹni nlá.15
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn yè nínú òtútù líle nítorí àánú àti ìwàrere àwọn olùgbé Quincy nìkan. Ángẹ́lì ti ilẹ̀ ayé wọ̀nyí ṣí ọkàn wọn àti ilé, tí ó nmú ìṣìkẹ́ ìgbàlà-ìyè wá, ìṣìkẹ́, ọ̀yàyà, àti—bóyá ní pàtàkì jùlọ—ọwọ́ ìbánidọ́rẹ́ kan sí àwọn Ènìyàn Mímọ́ tó njìyà. Bí ó tilẹ̀jẹ́pé ìdúró wọn ní Quincy kúrú gan, àwọn Ènìyàn Mímọ́ kò gbàgbé gbẹ̀sẹ̀ ìmoore wọn sí àwọn olólùfẹ́ aladugbo, àti pé a mọ Quincy bí “ìlú ti ààbò.”16
Nígbàtí ìpọ́njú àtì ìkorò ni ó wá sórí wa nípasẹ̀ àwọn ìṣe, líle, àìdára, àní díẹ̀ ti-ẹ̀mí, a lè yàn láti ní ìrètí nínú Krístì. Ìrètí yí wá latinú ìfipè àti ìlérí láti “tújúká, nítorí èmi yíò darí yín lọ̀”16 àti pé Òun yíò ya ìpọ́njú yín sọ́tọ̀ fún èrè yín.17
Olùṣọ́-àgùtàn Rere
Ẹ jẹ́ kí a parí níbití a ti bẹ̀rẹ̀: olùtọ́jú aláàánú, mú ara rẹ̀ gbòòrò ní inúrere pẹ̀lú ẹ̀mí ìkẹ́ni, àti àyọrísí àìròtẹ́lẹ̀—wíwo ọkàn ẹrànko sàn lórí ẹnití òun ti ní ìríjú Kínìdí? Nítorí ó kàn jẹ́ bí ó jẹ́!
Bí a ṣe nwo nínú jígi ìhìnrere wa, a damọ̀ pé àwa bákanáà wa lábẹ́ ìtọ́jú olùtọ́jú aláàánú, ẹnití ó mú Ararẹ̀ gbòòró ní inúrere àti ẹ̀mí ìṣìkẹ́. Olùṣọ́-àgùtàn Rere mọ ẹnìkọ̀ọ̀kan wa nípa orúkọ àti pé “ó ní ìfẹ́ araẹni nínú wa.”18 Olúwa Jésù Krístì Fúnrarẹ̀ wípé, “Èmi ni olùṣọ́-àgùtàn rere, mo sì mọ àwọn àgùtàn tèmi.… Àti pé èmi [ó] gbé ẹ̀mí mi lélẹ̀ fún àwọn àgùtàn.”20
Ní òpin ọ̀sẹ̀ Ọdún-àjínde yí, mo rí àláfíà pípẹ́ ní mímọ̀ pé “Olúwa ni olùṣọ́-àgùtàn mi”20 áti pé Ó mọ ẹnìkọ̀ọ̀kan wa a sì wà lábẹ́ ìtọ́jú inúrere Rẹ̀. Nígbàtí mo dojúkọ afẹ́fẹ́ àti ìjì-òjò, àìsàn àti ìpalára ayé, Olúwa—Olùṣọ́-àgùtàn wa, Olùtọ́jú wa—yíò ṣìkẹ̀ wa pẹ̀lú ìfẹ́ àti inúrere. Òun yíò wo ọkàn wa sàn yíò sì mú ẹmí wa padàbọ̀sípò.
Nípa èyí ni mo jẹri—àti nípa Jésù Krístì bí Olùgbàlà wa àti Olùràpàdà wa—ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.