Kínìdí Ipá Ọ̀nà Májẹ̀mú
Ìyàtọ̀ ipá ọ̀nà májẹ̀mú jẹ́ àràọ̀tọ̀ àti pàtàkì ayérayé.
Ní gbogbo iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀, Ààrẹ Russell M. Nelson ti ṣe àṣàrò ó sì kọ́ni nípa àwọn májẹ̀mú Ọlọ́run pẹ̀lú àwọn ọmọ Rẹ̀. Òun fúnrarẹ̀ jẹ́ àpẹrẹ dídán ẹnìkan tí ó nrìn ní ipá ọ̀nà Májẹ̀mú. Nínú ọ̀rọ àkọ́kọ́ rẹ bí Ààrẹ Ìjọ, Ààrẹ Nelson wípé:
“Ìfaramọ́ yín láti tẹ̀lé Olùgbàlà nípa dídá májẹ̀mú pẹ̀lú Rẹ̀ àti pípa àwọn májẹ̀mú wọ̃nnì mọ́ yíò ṣí ilẹ̀kùn sí gbogbo ìbùkún ti ẹ̀mí àti ànfàní tí ó wà fùn àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin, àti àwọn ọmọdé níbigbogbo.
“Àwọn ìlànà ti tẹ́mpìlì àti àwọn májẹ̀mú tí ẹ dá níbẹ̀ jẹ́ kókó sí ìfùnlókun ìgbé ayé yín, ìgbéyàwó àti ẹbí yín, àti agbára yín láti tako àwọn àtakò èṣù. Ìjọ́sìn yín nínù tẹ́mpìlì àti iṣẹ́ ìsìn yín níbẹ̀ fún àwọn bàbánlá yín yíò bùkún yín pẹ̀lú ìfihàn araẹni púpọ̀ síi àti àláfíà yíò sì dà ààbò bo ìfẹsẹ̀múlẹ̀ yín láti dúró lórí ipa ọ̀nà májẹ̀mú.”1
Kíni ipa ọ̀nà májẹ̀mú? Ó jẹ́ ipa ọ̀nà tí ó darí sí ìjọba sẹ̀lẹ́stíà Ọlọ́run. A ti bẹ̀rẹ̀ lórí ipa ọ̀nà ní ẹnu-ọ̀nà ìrìbọmi àti lẹ́hìnnáà “tẹ̀ síwájú pẹ̀lú ìdúróṣinṣin nínú Krístì, níní ìrètí dídán pípé, àti ìfẹ́ Ọlọ́run àti gbogbo ènìyàn [àwọn òfin nlá méjì] … títí dé òpin.”2 Ní èrò ipa ọ̀nà (èyí, nípa ọ̀nà, nawọ́ kọjá ayé-ikú), a gba gbogbo àwọn ìlànà àti májẹ̀mú tí ó jẹ mọ́ ìgbàlà àti ìgbéga.
Ìfarajìn májẹ̀mú wa púpọ̀ ni láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run “àti láti gbọ́ran sí àwọn òfin nínú ohun gbogbo tí òun ti pàṣẹ.”3 Títẹ̀lé àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ àti òfin ìhìnrere ti Jésù Krístì ní ọjọ́ sí ọjọ́ ni ìdùnnú jùlọ àti ìgbé ayé ìtẹ́nilọ́rùn jùlọ. Fún ìdí kan, ẹnìkan níláti yẹra fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàhálà nlá àti àbámọ̀. Ẹ jẹ́ kí nlo àpẹrẹ eré-ìdárayá. Ní tẹnísì, kiní kan wà tí a pè ní àwọn àṣìṣe àìmúnípá. Àwọn wọ̀nyí ní irú ohun tí gbígbá bọ́ọ̀lù ìṣere sínú àwọ̀n tàbí àṣìṣe-méjì nígbàtí à nsìn. Àwọn àṣìṣe àìmúnípa ni a rò ní àbájáde ìpalára ti olùṣeré sànju jíjẹ́ ìdí ipasẹ̀ iṣẹ́ alátakò.
Léraléra jùlọ àwọn wàhálà tàbí ìpènija wa jẹ́ àfọwọ́fà, àbájáde àwọn àṣàyàn búburú, tàbí a lè wípé àbàjáde ti “àwọn àṣìṣe àìmúnípá.” Nígbàtí à nfi ìtara lépa ipa ọ̀nà májẹ̀mú, a nfi jẹ́jẹ́ yẹra fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ “àwọn àṣìṣe àìmúnípá” níti-abínibí. A ngbésẹ-sẹgbẹ ní onírurú ọ̀ràn bánbákú. A ko ṣubú sínú ọ̀gbun irọ́ àti ìṣe àìṣòótọ́. A sọdá lórí ọ̀run-àpáàdì ayé-àìkú àti àìṣòdodo. A kọjá àwọn ènìyàn àti àwọn ohunkan, àní ní lókìkí, yíò pa wíwà-dáadáa wa lára níti-ara àti níti-ẹ̀mí. A yẹra fún àwọn àṣàyàn tí ó npanilára tàbí àìdára fún àwọn ẹlòmíràn àti dípò bẹ́ẹ̀ gba àwọn ìhùwa ti ìkora-ẹni-níjánu àti iṣẹ́-ìsìn.4
Alàgbà J. Golden Kimball ni ó ti wípé “Èmi lè má tilẹ̀ rìn ní ọ̀nà híhá àti tóóró [nígbàgbogbo], ṣùgbọ́n èmi [gbìyànjú] láti sọdá rẹ̀ léraléra bí mo ti lè ṣe.”4 Nínú Àkokò líle si, ó dá mi lójú pé Arákùnrin Kimball yíò faramọ pé dídúró pẹ́, kìí ṣe sísọdá, sí ipa ọ̀nà májẹ̀mú ni ìrètí títóbijùlọ wa fún yíyẹra yẹrafún ìbànújẹ́ ní ọwọ́ kan àti fifi yíyege bá àwọn ewu àìlèyẹra ìgbé ayé ní ọ̀nà míràn.
Àwọn kan lè wípé, “Mo lè ṣe àwọn àṣàyàn rere pẹ̀lú tàbí àìsí ìrìbọmi; èmi kò nílò àwọn májẹ̀mú láti jẹ́ ọlọ́lá àti ẹni yíyege.” Nítòọ́tọ́, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wà nígbàtí wọn, kò sí ní ọ̀nà májẹ̀mú fúnrawọn, nṣe ìṣe ní ọ̀nà tí ó fi àwọn àṣàyàn hàn àti ìfọwọ́sí àwọn tí wọ́n wà ní ipa ọ̀nà. Ẹ lè wípé wọ́n kórè àwọn ìbùkún ti rírìn ní “ipa ọ̀nà májẹ̀mú-lémọ́lemọ́”. Lẹ́hìnnáà kíni ìyàtọ̀ ipa ọ̀nà májẹ̀mú?
Dájúdájú, ìyàtọ̀ náà ni àìláfiwe àti pàtàkì ayèráyé. Ó pẹ̀lú ìwà-ẹ̀dá ti ìgbọràn wa, ìwà ìfarajìn Ọlọ́run sí wa, ìrànlọ́wọ́ ti-ọ̀run tí a gbà, àwọn ìbùkún tí ó rọ̀mọ́ ìkójọ bí àwọn ènìyàn májẹ̀mú, àti nípàtàkì jùlọ, ìjogún ayérayé wa.
Ìgbọ́ran Ìfarajìn
Àkọ́kọ́ ni ìgbọ́ran ìwà-ẹ̀dá wa sí Ọlọ́run. Ju níní àwọn èrò rere lásán, a ní ìfarajìn pẹ̀lú ọ̀wọ̀ láti gbé nípa gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó jáde wá látẹnu Ọlọ́run. Nínú èyí, à ntẹ̀lé àpẹrẹ Jésù Krístì, ẹnití, nípa ṣíṣe ìrìbọmi, “fihàn sí àwọn ọmọ ènìyàn pé, nípa ti ara ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Bàbá, ó sì jẹ́rĩ sí Baba pé òun yíò ní ígbọ́ran sí i ní pípa àwọn òfin rẹ̀ mọ́.”6
Pẹ̀lú àwọn májẹ̀mú, a ní èrò lórí yíyẹra fún àṣìṣe lásán tàbí jíjẹ́ amèrò. A ní ìmọ̀lára ìjiyìn sí Ọlọ́run fún àwọn àṣàyàn wa àti ìgbé ayé wa. A gbé orúkọ Krístì lé orí ara wa. A dojúkọ Krístì—lórí jíjẹ́ akọni nínú ẹ̀rí Jésù àti ní gbigbèrú ìwà ti Krístì.
Pẹ̀lú àwọn májẹ̀mú, ìgbọràn sí ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ìhìnrere di gbòngbò nínú ẹ̀mí wa gan. Èmi mọ àwọn lọ́kọláya kan níbití, ní ìgbà ìgbéyàwó wọn, ìyàwó kìí wá déédé sí Ìjọ àti pé ọkọ kìí ṣe ọmọ Ìjọ rárá. Mo máa pè wọ́n ní Màríà àti Jòhannù, kìí ṣe orúkọ òtítọ́ wọn. Bí àwọn ọmọ ṣé ndé, Màríà ní ìmọ̀lára gidi nípa ìnilò láti tọ́ wọ́n, bí ìwé mímọ́ ti sọ, “nínú ìtójú àti ìkìlọ̀ Olúwa.”8 Jòhánnù tì í lẹ́hìn. Màríà ṣe àwọn ìrúbọ pàtàkì láti wà nílé láti kọ́ ìhìnrere léraléra. Ó mu dájú pé ẹbí náà gba ìṣe àti ìjọsìn dídára ti Ijọ ní kíkún. Màríà àti Jòhánnù di àwọn òbí alápẹrẹ, àwọn ọmọ wọn (gbogbo ọmọdékùnrin alágbára) dàgbà nínú ìgbàgbọ́ àti ìfọkànsìn sí àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ àti òṣùwọ̀n ìhìnrere.
Àwọn òbí Jòhánù, inú òbí-baba àwọn ọmọdèkùnrin náà dùn, pẹ̀lú ìgbé ayé dídára wọn àti àṣeyege ti àwọn ọmọ-ọmọ wọn, ṣùgbọ́n nítorí àtakò sí Ìjọ, wọ́n fẹ́ fi àṣeyọrí yí mọ́ iṣẹ́ òbí ti Màríà àti Jòhánnù. Bíótilẹ̀jẹ́pé, Jòhánnù kìí ṣe ọmọ Ìjọ, kò jẹ́ kí àyẹ̀wò ìyẹn lọ láìní-ìpenijà. Ó tẹnumọ pé wọ́n nní ẹ̀rí àwọn èso ìkọ́ni ìhìnrere—ìrírí ohun tí àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ nní nínú Ìjọ àti ohun tí ó nṣẹlẹ̀ bákannáà ní ilé.
Jòhánù fúnrarẹ̀ ni a fún lókun nípasẹ̀ ẹmí, ìfẹ́ àti àpẹrẹ ìyàwó rẹ̀, àti ti àwọn onígbìyànjú ọmọkùnrin rẹ̀. Ní ìgbà díẹ̀ si, ó ṣe ìrìbọmi, púpọ̀ sí ayọ̀ àwọn ọmọ wọ́ọ̀dù àti ọ̀rẹ́.
Nígbàtí ayé kò wà láìsí àwọn ìpènijà fún wọn àti àwọn ọmọkùnrin wọn, Màríà àti Jòhannu fi tọkàntọkàn tẹnumọ pé májẹ̀mú ìhìnrere nítòótọ́ ni ó wà ní gbòngbò àwọn ìbùkún wọn, bí olúkúlùkù àti ẹbí. Wọ́n ti ri tí ọ̀rọ̀ Olúwa sí Jeremíàh tí wá sí ìmúṣẹ nínú ayé àwọn ọmọ wọn àti pẹ̀lú ti arawọn: “Èmi ó fi àṣẹ mi sí inú ara wọn, émi ó sì kọọ́ sí ọkàn wọn; èmi yíò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn, àwọn yíò sì jẹ́ ènìyàn mi.”9
Sopọ̀ mọ́ Ọlọ́run
Ìṣe àìláfiwé ti ipa ọ̀nà májẹ̀mú ni íbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú Ọba kan. Àwọn májẹ̀mú tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Rẹ̀ nṣe ju títọ́ wa sọ́nà lọ. Wọ́n so wá pọ̀ mọ́ Ọ, tí a bá sì, ti sopọ̀ mọ́ Ọ, a lè borí ohun gbogbo.9
Mo ka nkankan nígbàkan nípasẹ̀ oníròhìn tí a sọ ohùn tí kò tọ́ fún tí ó sàlàyé pé ọ̀nà tí a fi nṣe ìrìbọmi fún òkú ni láti ri róòlù fíìmù-kínkín sínú omi. Lẹ́hìnnáà gbogbo àwọn tí orúkọ wọ́n bá jáde lórí fíìmù-kínkín náà ni a kà sí ṣíṣe ìrìbọmi. Ọ̀nà náà yíò jáfefe, ṣùgbọ́n ó pa yíyẹ àìlópin ti ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan tì àti ominú pàtàkì ti májẹ̀mú araẹni pẹ̀lú Ọlọ́run.
“[Jésù] wípé … : Ẹ wọlé ní ẹnu ọ̀nà híhá; nítorí híhá ni ẹnu-ọ̀nà nã, tõró sì ni ojú-ọ̀nà nã èyítí ó lọ síbi ìyè, díẹ̀ sì ni àwọn ẹnití nríi.”10 Ní sísọ̀rọ̀ alámì, ẹnu-ọ̀nà yí jẹ́ tóóró gan tí ó fàyè gba ẹnìkan láti wọlé ní ìgbà kan. Ẹnìkọ̀ọ̀kan nṣe ìfarajìn olúkúlùkù sí Ọlọ́run, Ọlọ́run nṣe májẹ̀mú araẹni sí ẹnìkọ̀ọ̀kan, nípa orúkọ, pé a lè gbélé orí ìgbà àìlèfọwọ́yí àti àìlópin. Pẹ̀lú àwọn ìlànà àti májẹ̀mú, “agbára ìwà-bí-ọlọ́run ni ó nfarahàn” nínú ayé wa.11
Ìrànlọ́wọ́ ti Ọ̀run
Èyí darí wa sí èrò ìbùkún kẹta pàtàkì ti ipa ọ̀na májẹ̀mú. Ọlọ́run pèsè ẹ̀bùn tí ó fẹ́rẹ̀ má ní òye láti ran àwọn olùdá-májẹ̀mú lọ́wọ́ láti jẹ́ olùpamọ́-májẹ̀mú: ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́. Èyí ni ẹ̀tọ́ sí ojúgbà léraléra, ààbò, àti ìtọ́nisọ́nà Ẹ̀mí Mímọ́.11 Ẹ̀mí Mímọ́, tí a mọ̀ sí Olùtùnú bákannáà, “kún fún ìrètí àti ìfẹ́ pípé.”12f Ó “mọ ohun gbogbo, ó sì jẹ ẹ̀ri nípa Baba àti Ọmọ.”13 ẹ̀rí àwọn ẹnití a farajìn láti jẹ́.15
Ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú bákannáà a rí àwọn ìbùkún pàtàkì ti ìdáríjì àti ìwẹ̀nùmọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀. Èyí ni ìrànlọ́wọ́ tí ó lè wá nípasẹ̀ oore-ọ̀fẹ́ ti ọ̀run nìkan, tí a fúnni nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́. “Nísisìyí èyí ni àṣẹ nã,” ni Olúwa wí, “Ẹ ronúpìwàdà, gbogbo ẹ̀yin ìkangun ayé, ẹ sì wá sí ọ̀dọ̀ mi kí ẹ sì ṣe ìrìbọmi ní orúkọ mi, kí ẹ̀yin ó di mímọ́ nípa gbígba Ẹ̀mí Mímọ́, kí ẹ̀yin ó lè dúró ní àìlábàwọ́n níwájú mi ní ọjọ́ ìkẹhìn.”15
Kórajọ pẹ̀lú àwọn Ènìyàn Májẹ̀mú
Ìkẹ́rin, àwọn tí ó nlépa ipa ọ̀nà májẹ̀mú rí àwọn ìbùkún kọ̀ọ̀kan nínú àwọn onírurú ìkórajọ tí a yàn. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ti ọ̀ran kíkórajọ bí ó ti wa nípa àwọn ẹ̀yà Ísráẹ́lì yíyapa-tipẹ́tipẹ́ sí àwọn ilẹ̀ ìjogún wọn ni a rí káàkiri ninú iwé mímọ́.16 Ìmúṣẹ àwọn àṣọtẹ́lẹ̀ àti ìlérí ti wà ní ọjú-ọ̀nà pẹ̀lú ìkórajọ àwọn ènìyàn májẹ̀mú sínu Ìjọ, ìjọba Ọlọ́run ní ayé. Ààrẹ Nelson ṣàlàyé pe, “Nígbàtí a sọ̀rọ̀ nípa ìkórajọ, à nsọ jẹ́jẹ́ nípa ẹ̀kọ́ ìpìnlẹ̀ òtítọ́: gbogbo àwọn ọmọ Baba wa Ọ̀run … lẹtọ́ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere ti Jésù Krístì.”17
Olúwa pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn láti “dìde kí ẹ tàn jáde wá, kí ìmọ́lẹ̀ yín lè jẹ́ òṣùwọ̀n fún àwọn orílẹ̀-èdè; … kí ìkórajọ papọ̀ lórí ilẹ̀ Síónì, àti ní àwọn èèkàn rẹ̀, lè jẹ́ fún ìgbèjà, àti ààbò kúrò nínú ìjì, àti kúrò nínú ìrunú nígbàtí ó bá túu jáde láìsí ìdárúdàpọ̀ lórí gbogbo ayé.”18
Ìkórajọ ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ti àwọn ènìyàn májẹ̀mú wà bákannáà sí ilé àdúrà ní ọjọ́ Olúwa, kí a lè “pa [arawa] mọ́ ní àìlẹ́gbin kúrò nínú ayé.”19 Ó jẹ́ ìkórajọ láti ṣe àbápín búrẹ́dì oúnjẹ Olúwa àti omi ní ìrántí ti Ètùtù Jésù Krístì àti ìgbà kan “láti gbàwẹ̀ àti láti gbàdúrà, àti láti sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ara wa nípa àlàfíà ti ẹ̀mí [wa].”20 Bí ọmọdé, èmi nìkan ni ọmọ Ìjọ ní kílásì mi nílé-ìwé gíga. Mo gbádùn ìbákẹ́gbẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ mi rere ní ilé-ìwé, síbẹ̀ mo ri pé mo gbaralé ìkórajọ Ọjọ́-ìsinmi ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ gidi láti tún mi ṣe níti-ẹ̀mí, àní nìti-ara. Bí a ti ṣe nní ìmọ̀lára gan nípa àdánù ìkórajọ májẹ̀mú déédé nínú àjàkálẹ̀-àrùn lọ́wọ́lọ́wọ́, àti bí a ti nfi ìlọ́ra gbèrò ìgbà tí a lè wá papọ̀ lẹ́ẹ̀kansi bíiti tẹ́lẹ̀.
Àwọn ènìyàn májẹ̀mú kórajọ sí tẹ́mpìlì, ilé Olúwa, láti gba àwọn ìlànà, ìbùkún, àti ìfihàn àìláfiwé tí ó wà níbẹ̀. Wòlíì Joseph Smith kọ́ni: “Kíni kókó ìkórajọ … àwọn ènìyàn Ọlọ́run ní ọjọ́ orí eyikeyi ní ayé? … Kókó àkọ́rí ni láti kọ́ ilé kan fún Olúwa níbití Òun ti lè fi àwọn ìlànà ilé Rẹ̀ àti ògo ìjọba Rẹ̀ hàn sí àwọn ènìyàn Rẹ̀, kí ó sì kọ́ àwọn ènìyàn ní ọ̀nà ìgbàlà; nítorí àwọn ìlànà àti ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ kan pàtó wà, nígbàtí a bá kọ́ wọn tí a sì ṣeé, a gbọ́dọ̀ ṣeé ní ibi tàbí ilé tí a kọ́ fún èrèdí náà.”21
Ẹ Jogún àwọn Ìlérí Májẹ̀mú
Ní òpin, nípa lílépa ipa ọ̀nà májẹ̀mú nìkan ni a ó jogún àwọn ìbùkún Ábráhámù, Ísáákì, àti Jákọ́bù, àwọn ìbùkún ìgbẹ̀hìn ti ìgbàlà àti ìgbéga tí Ọlọ́run lè fúnni.22
Àwọn ìtọ́ka ìwé mímọ́ sí àwọn ènìyàn májẹ̀mú túmọ̀ àwọn àtẹ̀lé léraléra bí ó ti wa tí Ábráhámù mọ̀ bí “ìdílé Ísráẹ́lì.” Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn májẹ̀mú bákannáà pẹ̀lú gbogbo àwọn ẹnití wọ́n gba ìhìnrere Jésù Krístì.23 Paulu ṣàlàyé:
“Nítorí bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí wọ́n ti ṣe ìrìbọmi sínú Krístì ti gbé Krístì lé orí. …
“Bí ẹ bá jẹ́ ti Krístì, nígbànáà ẹ jẹ́ irú-ọmọ Ábráhámù, àti ajogún gẹ́gẹ́bí ìlérí náà.”24
Àwọn tí wọ́n bá jẹ́ olótítọ́ sí májẹ̀mú wọn “yíò jáde wá nínú àjínde olódodo.”25 A ṣe wọ́n “ní pípé nípasẹ̀ Jésù alágbàwí ti májẹ̀mú titun . … Ìwọ̀nyí ni àwọn tí ara wọn jẹ́ sẹ̀lẹ̀stíà, tí ògo wọn jẹ́ ti oòrùn, àní ògo Ọlọ́run, tí ó ga ju gbogbo rẹ̀ lọ.”26 “Nítorínáà, ohun gbogbo jẹ́ ti wọn, bóyá ìyè tàbí ikú, tàbí ohun ìsisìyí, tàbí ohun tí ó nbọ̀, gbogbo rẹ̀ jẹ́ tiwọn wọ́n sì jẹ́ ti Krístì, Krístì sì jẹ́ ti Ọlọ́run.”27
Ẹ jẹ́ kí a gbọ́ ìpè ti wòlíì láti dúró ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú. Néfì rí wa atì ìgbà wa ó sì kọ́sílẹ̀ pé, “Èmi, Néfì, kíyèsí agbára Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run, tí ó sọ̀kalẹ̀ sórí àwọn ènìyàn mímọ́ ti ìjọ onígbàgbọ́ ti Ọ̀dọ́-àgùtàn, àti sórí àwọn ènìyàn májẹ̀mú ti Olúwa, àwọn tí a túká sórí gbogbo ojú àgbáyé; wọ́n sì gbáradì pẹ̀lú òdodo àti pẹ̀lú agbára Ọlọ́run nínú ògo nlá.”28
Pẹ̀lú Néfì, “ọkan mi yọ̀” nínú àwọn májẹ̀mú Olúwa.”30 Ní Ọjọ́-ìsinmi Ọdún-àjínde yí, mo jẹ́ ẹ̀rí mi nípa Jésù Krístì, ẹnití Àjínde rẹ̀ jẹ́ ìrètí àti ìdánilójú nípa gbogbo ìlérí tí ó ṣe lórí àti ní òpin ipa ọ̀nà májẹ̀mú. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.