Ẹ̀yin Yíò Di Òmìnira
Jésù Krístì ni ìmọ́lẹ̀ náà tí o yẹ kí a múdúró pàápàá lákokò àwọn òkùnkùn ti ìgbésí ayé ikú wa.
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, mo dúpẹ́ gidigidi fún ànfàní lati bá yín sọ̀rọ̀ láti Áfríkà. Ó jẹ́ ìbùkún láti ní ìmọ̀ ẹ̀rọ ìgbàlódé loni àti láti lòó ni ọ̀na tí ó mùnà dóko làti dé ọ̀dọ̀ yín níbikíbi tí ẹ wà.
Ní oṣù kẹsan 2019, Arábìnrin Mutombo àti èmi, nígbàtí a nsìn bi olórí Míṣọ̀n Maryland Baltimore, ní ànfàní láti bẹ díẹ̀ nínu àwọn ibi ààyè àkọọ́lẹ̀-ìtàn ìjọ wò ni Palmyra, New York, nígbàtí a wà níbi àpèjọ àwọn olórí míṣọ̀n. A parí àbẹ̀wò wa si Igbó Mímọ́ Ṣúúru. Ìpinnu wa ní lílọ si Igbó Mímọ́ Ṣúúrú kìí ṣe láti ni ìfihàn pàtàkì kan tàbí ìran, ṣùgbọ́n a ní ìmọ̀lára wíwà Ọlọ́run ni ibi mímọ́ yi. Ọkàn wa kún fún ọpẹ́ fún Wòlíì Joseph Smith.
Ní ọ̀nà ìpadàbọ̀, Arábìnrin Mutombo ṣàkíyèsí pé mo rẹrin músẹ́ bi a ṣe nwa ọkọ̀ o sì bèèrè, “Kíni ìdí ìdùnnú rẹ?”
Mo dáhùn, “Nathalie mi ọ̀wọ́n, òtítọ́ ni yíò máa borí àṣìṣe nígbàgbogbo, òkùnkùn kì yiò sì tẹ̀síwájú ni ilẹ̀-ayé nítorí ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere ti Jésù Krístì.”
Ọlọ́run Baba àti Jésù Krístì bẹ ọ̀dọ́ Joseph Smith wò láti mú ohun tí ó fi ara pamọ́ wá sí ìmọ́lẹ̀, kí a lè gba “ìmọ̀ àwọn ohun bí wọ́n ṣe wà, … bí wọ́n ti ṣe wà rí, àti bí wọn yìo [ṣe wà]” (Ẹkọ ati Àwọn Májẹ̀mú 93:24).
Lẹ́hìn bíi igba ọdún ólé, ọ̀pọ̀ ṣì nwá àwọn òtítọ́ tí a nílò láti di òmìnira lọ́wọ́ àwọn àṣà àti irọ́ tí ọ̀tá tànká gbogbo ayé. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti “fọ́jú nípasẹ̀ ète àrekérekè ti ènìyàn” (Ẹkọ ati Àwọn Májẹ̀mú 123:12). Nínú èpístélì rẹ̀ si àwọn ará Éfésù, Páùlù kọ́ni pé: “Jí ìwọ ẹnití ó sùn, sì jínde kúrò nínú òkú, Krístì yio sì fún ọ́ ní ìmọ́lẹ̀” (Éfésù 5:14). Olùgbàlà ṣèlérí pé Òhun yio jẹ́ ìmọ́lẹ̀ sí àwọn tí o bá gbọ́ ọ̀rọ̀ Rẹ̀ (wo 2 Nífáì 10:14).
Ọdún marundinlogoji sẹ́hìn, àwọn òbi mi náà fọ́jú wọ́n sì nfi àínírètí wá láti mọ òtítọ́ naa àti pé wọ́n ṣe àniyàn nípa ibi ti àwọn le yà si láti ri i. A bí awọn òbí mi ní abúlé, níbi tí àwọn àṣà ti gbilẹ̀ nínú ayé ẹnìkọ̀ọ̀kan àti àwọn ẹbí. Àwọn méjèjì fi abúlé wọn sílẹ̀ nígbàtí wọ́n kéré wọ́n sì wá sí ìlú nla, láti wá ìgbé ayé tí ó dára.
Wọ́n fẹ́ra wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ẹbí wọn ni ọ̀nà ìwọ̀ntun-wọ̀nsì gangan. A fẹ́rẹ̀ to ènìyàn mẹ́jọ ni ilé kékeré—àwọn òbí mi, arábìnrin mi méjì àti èmi, àti ìbátan kan ti o bá wa gbe rí. Ó máa nyàmí lẹ́nu bóyá a jẹ́ ẹbí kan ní tòótọ́, bí wọn ko ṣe ngbàwá láàyè láti jẹun alẹ́ ni tábìlì pẹ̀lú àwọn obí wa. Nígbàtí baba wa bá dé láti ibi iṣẹ́, ní kété tí ó bá ti wọlé, wọ́n a sọ fun wa lati kúrò kí a sì bọ́ síta. Alẹ́ wa kúrú gidi, bí a ko ṣe lè sùn nítorí àìsí ìṣọ̀kan àti ìfẹ́ òtítọ́ nínú ìgbéyàwó àwọn obí wa. Ilé wa kò kéré ní ìwọ̀n nìkan, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ibi òkùnkùn. Kí a to pàdé àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere, á máa nlọ sí onírúurú ìjọ ni gbogbo ọjọ́ ìsinmi. Ó hàn gbangba pé àwọn obí wa nwá ohun kan ti ayé kò lè pèsè.
Èyí nlọ́ bẹ́ẹ̀ títí ti a fi pàdé Alàgba àti Arábìnrin Hutchings, tọkọtaya ìránṣẹ ìhìnrere agba àkọ́kọ́ tí a pè láti sìn ni Zaire (tí a mọ̀ sí DR ti Congo tàbí Congo-Kinshasa loni). Nígbàtí a bẹ̀rẹ̀ síí pàdé àwọn ìránṣẹ ìhìnrere oníyanu yi, àwọn tí wọ́n dàbí àwọn ángẹ́lì tí o wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, mo fiyèsi pé ohùn kan bẹ̀rẹ̀ síí yípadà nínú ẹbí wa. Lẹ́hìn ìrìbọmi wa, a bẹ̀rẹ̀ síí nní ilosiwaju ní ìgbésí ayé titun nitòótọ́ nítorí ìhìnrere tí a mú padàbọ̀sípò. Àwọn ọ̀rọ̀ Krístì bẹ̀rẹ̀ síí mú ẹ̀mí wa gbòrò. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí tan ìmọ́lẹ̀ sí òye wa wọ́n sì di dídùn fún wa, bí àwọn òtítọ́ tí a gbà ṣe ni làákàyè ti à si lè rí ìmọ́lẹ̀, àti pé ìmọ́lẹ̀ yí ndi titàn àti títàn si lójojúmọ́.
Òye èrèdí ìhìnrere yí nràn wá lọ́wọ́ láti dà bí Olùgbàlà si. Ìwọ̀n ilé wa ko yípadà; bẹ́ẹ̀ni àwọn ipò wa ní àwùjọ náà. Ṣùgbọ́n mo rí ìyípadà ọkàn àwọn òbí mi bí a ṣe ngbàdúrà lójoojúmọ́, òwúrọ̀ àti àṣálẹ́. A kọ́ ẹ̀kọ́ nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì; a ṣe ìpàdé ẹbí ìrọ̀lẹ́ nílé; a di ẹbí kan ní tòótọ́. Gbogbo ọjọ́ ìsinmi a njí ní agogo mẹ́fà òwúrọ̀ láti múra láti lọ ilé ìjọsìn, a o si rin ìrìnàjò fùn àwọn wákàtí láti kópa nínú àwọn ìpàdé ìjọ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láì ṣàròyé. Ó jẹ́ àkokò rere láti jẹri. Àwa, tí a ti rìn nínú òkùnkùn rí, lé òkùnkùn kúrò laarin wa (wo Ẹkọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 50:25) a sì rí “ìmọ́lẹ̀ nla” (2 Néfì 19:2).
Mo rántí ọjọ́ kan, ti èmi kò fẹ́ tètè ji ní òwúrọ̀ fún àdúrà ẹbí, Mo kùn sí àwọn arábìnrin mi, “Kò sí ohun míràn tí a lèṣe nílé yí mọ́, ju gbàdúrà nìkan, gbàdúrà, gbàdúrà.” Baba mi gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ mi. Mo rántí ìfèsì rẹ, bí ó ti fi tìfẹ́tìfẹ́ ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìdúróṣinṣin kọ́ mi pé, “Níwọ̀n ìgbà ti ìwọ o bá wà nínu ilé yi, ìwọ yio gbàdúrà, gbàdúrà, gbàdúrà.”
Àwọn ọ̀rọ̀ baba mi dún ni etí mi lójoójúmọ́. Kíni ohun tí ẹ rò pé Arábìnrin Mutombo àti Èmi ṣe sí àwọn ọmọ wa loni? A ngbàdúrà, gbàdúrà, ati gbàdúrà. Èyí ni ogún wa.
Ọkùnrin náà ti a bi ni afọ́jú tí Jésù Krístì wòsàn, lẹ́hìn ìnilára láti ọ̀dọ̀ aládugbo ati àwọn Farisí, wípé:
“Ọkùnrin kan ti a npe ní Jésù ni o ṣe amọ̀, ó sì fi kùn mí lóju, ó sì wí fún mi pé, lọ sí adágún Sílóámù, kí o sì wẹ̀: èmí sì lọ, mo sì wẹ̀, mo sì ríran. …
“… Ohùn kan [ti] mo mọ̀ [ni] wi pé … Mo ti fójú ri, nisisiyi mo [le] riran ” (Jòhánnù 9:11, 25).
Àwa bakannáà ti fọ́jú rí a sì ríran nisisiyi. Ìhìnrere tí a mú padàbọ̀sípò ti ní ipa lórí ẹbí wa láti ìgbà náà. Níní òye èrèdí ìhìnrere ti bùkún ìran mẹta ti ẹbí mi yio sì tẹ̀síwájú láti máa bùkún àwọn ìran tí ó mbọ̀wá.
Jésù Krístì ni Ìmọ́lẹ̀ ti ó ntàn nínú òkùnkùn Ẹnití ó bá tẹ̀lé E “kì yiò rìn nínú òkùnkùn, ṣùgbọ́n yíò ní ìmọ́lẹ̀ ayé”(Jòhánnù 8:12).
Fún bí ọdún kan láarín 2016 àti 2017, àwọn ènìyàn ni agbègbè Kasai dojú kọ àjálù kan tí o banilẹ́rù. Ó jẹ́ àkokò òkùnkùn kan fún àwọn ènìyàn naà nítorí ìjà kan láarín àwọn ẹgbẹ́ jagunjagun ìbílẹ̀ àti àwọn ikọ̀ ti ìjọba. Ìwà-ipá náà tàn láti àwọn ìlú ní Àárín-gbùngbùn Kasai sí gbígbòrò agbègbè Kasai náà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sá kúrò ní ilé wọn sí ibi àìléwu wọ́n sì sápamọ́ sí inú igbó. Wọn kò ní oúnjẹ tàbí omi, tàbí ohunkóhun ní pàtó, àti pé láarín wọn ni àwọn ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn kan ní agbègbè Kananga náà wà. Àwọn ọmọ ogun pa àwọn ọmọ Ijọ kan.
Arákùnrin Honoré Mulumba ti Wọ́ọ̀dù Nganza ní Kananga àti ẹbí rẹ̀ jẹ́ díẹ̀ nínú àwọn ìwọ̀nba ènìyàn tí wọ́n fi ara pamọ́ sí ilé wọn, láìmọ̀ ibi tí wọ́n fẹ́ lọ nítorí tí gbogbo àwọń òpópónà ti yípadà si àwọn sákánì ìbọn. Ní ọjọ́ kan díẹ̀ nínú àwọn ọkùnrin jagunjagun àdúgbò ti fiyèsí wíwà arákùnrin Mulumba àti ẹbí rẹ ní ìrọ̀lẹ́ kan wọ́n jáde lọ láti gbìyànju láti wa ẹ̀fọ́ díẹ̀ nínú ọgbà ẹbí láti jẹ. Ẹgbẹ́ àwọn jagunjagun náà wá sí ilé wọn láti fà wọ́n síta wọ́n sì sọ fún wọn lati yàn láti faramọ́ iṣe ogun wọn tàbí kí wọ́n ó pa wọ́n.
Arákùnrin Mulumba fi ìgboyà sọ fún wọn pé, “Mo jẹ́ ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn. Ẹbí mi àti èmi ti gba Jésù Krístì a sì ní ìgbàgbọ́ nínu Rẹ̀. A ó jẹ olótitọ́ sí àwọn májẹ̀mú wa, a o sì gbà láti kú.
Wọ́n sọ fún wọn pé, “Bí ẹ ti yan Jésù Krístì, àwọn ajá ni yíò jẹ ara yín,” wọ́n sì ṣèlérí láti padà wa. Ṣùgbọ́n wọn kò padà wa, àwọn ẹbí náà dúró síbẹ̀ fún oṣù méjì wọn kò sì rí wọn mọ́. Arákùnrin Mùlúmba àti ẹbí rẹ mú ìtànná ìgbàgbọ́ wọn dúró. Wọ́n rántí àwọn májẹ̀mú wọn a sì pa wọ́n mọ́.
Jésù Krístì ni ìmọ́lẹ̀ náà tí o yẹ kí a múdúró pàápàá lákokò àwọn òkùnkùn ti ìgbésí ayé ikú wa (wo 3 Néfì 18:24). Nígbàtí a bá yàn láti tẹ̀lé Krístì, a yàn láti di yíyípadà. Arákùnrin tàbí obìnrin kan ti a yípadà fún Krístì yíò jẹ balógun nípasẹ̀ Krístì, àti pé a o máa bèèrè, bíi Páùlù ti ṣe, “Olúwa, kíni ẹ̀yin fẹ́ kí èmi kí o ṣe?” (Ìṣe Àwọn Àpóstélì 9:6). A ó “tẹ̀lé àwọ́n ìṣísẹ̀ rẹ” (1 Pétérù 2:21). A ó “rìn, àní bi oun ṣe rìn” (1 Jòhánnù 2:6). (Wo Ezra Taft Benson, “Tí Ọlọ́run Bí,” Tambuli, Oct. 1989, 2, 6.)
Mo jẹ́rì Ẹni náà tí o kú, tí a sì sin, tí ó tún jínde ní ọjọ́ kẹ́ta tí ó sì gòkè re ọ̀run nítorí kí ìwọ àti èmi le gba àwọn ìbùkùn ayé àìkú àti ìgbéga. Òun ni “ìmọ́lẹ̀ náà, … ìyè náà, àti òtítọ́ náà” (Ẹ́térì 4:12). Òun ni aporó àti àtúnṣe sí rògbòdìyàn ayé. Òun ni òṣùwọ̀n ti tìtayọ fún ìgbéga, àní Jésù Krístì. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.