Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Jésù Krístì: Olùtọ́jú Ẹ̀mí Wa
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2021


Jésù Krístì: Olùtọ́jú Ẹ̀mí Wa

Bí a ṣe nronúpìwàdà fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa dénúdénú, a nfi ààyè gba ìrúbọ ètùtù Krísti láti ní ipa tán pátápátá nínú ayé wa.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, ní òwúrọ̀ dídán Ọdún-àjinde yí ọkàn mi nyọ̀ ní rírántí ìṣe oníyanu, ọlọ́lá, àti àìníwọ̀n jùlọ tí ó ṣẹlẹ̀ ní gbogbo àkọọlẹ̀-ìtàn ènìyàn—ètùtù ìrúbọ Olúwa wa, Jésù Krístì. Àwọn ọ̀rọ̀ olókìkí ti wòlíì Ísáíàh ṣe àgbéga títóbijùlọ àti àìní-ìmọtaraẹni-nìkan ìgbé ayé ìrelẹ̀ Olùgbàlà àti ìrúbọ ní ìtìlẹhìn gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run.

“Lõótọ́ ó ti ru ìbànújẹ́ wa, ó sì gbé ìkàánú wa lọ; ṣùgbọ́n àwa kà á sí bí ẹnití a nà, tí a lù láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, tí a sì pọ́n lójú.

“Ṣùgbọ́n a ṣáa lọ́gbẹ́ nítorí ìrékọjá wa, a pã lára nítorí àìṣedẽdé wa; ìnà àlãfíà wa wà lára rẹ̀, àti nípa nínà a rẹ̀ ni a fi mú wa láradá.”1

Nípa fífi ìyọ̀ọ̀da gbé ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo ènìyàn lé orí Ararẹ̀, jíjẹ́ kíkàn mọ́ àgbélèbú ní àìṣòdodo, àti fífi ìṣẹ́gun borí ikú ní ọjọ́ kẹta,2 Jésù fúnni ní ìtumọ̀ mímọ́ jùlọ sí ìlànà Ìrékọjá tí a ti fi lé orí Israẹ́lì ní àwọn ìgbà àtijọ́.3 Nínú ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀, Ó fira Rẹ̀ sílẹ̀ bí ẹbọ nlá àti ìgbẹ̀hìn,4 ní mímú àwọn àmì àṣà di òfin tí a lò nínú àyẹyẹ Ìrékọja Olúwa .5 Ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, Krístì ní ìrírí ìjìyà ti-ara àti ti-ẹ̀mí tí ó jẹ́ àìlóyé sí ọkàn ènìyàn. Olùgbàlà Funrarẹ̀ wípé:

“Nítorínáà kíyèsi, èmi, Ọlọ́run, ti jìyà àwọn ohun wọ̀nyí fún gbogbo ènìyàn, …

“Ìjìyà èyí tí ó mú èmi tikara mi, àní Ọlọ́run, tí ó tóbi ju ohun gbogbo lọ, láti gbọn-rìrì nítorí ìrora, àti láti ṣẹ̀jẹ̀ nínú gbogbo ihò ara, àti láti jìyà ní ara àti ẹ̀mí—àti láti fẹ́ pé kí èmi máṣe mu nínú ago kíkorò náà, kí èmi sì fàsẹ́hìn—

“Bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀, ògo ni fún Baba, àti pé èmi kópa mo sì ṣe àṣepari àwọn ìmúrasílẹ̀ mi fún àwọn ọmọ ènìyàn.”6

Krísti fi oore-ọ̀fẹ́ mú ìfẹ́ Baba ṣẹ7 nípasẹ̀ ìrúbọ àìlópin àti àánú Rẹ. Ó ṣẹ́gun oró ikú ti ara àti ti ẹ̀mí,8 tí a fihàn sí ayé nípasẹ̀ Ìṣubú,9 tí ó fún wa ní ìṣeéṣe ìgbàlà ayérayé.10

Jésù nìkan ni Ẹni tí ó lágbára láti dá ìrúbọ ayérayé àti pípé yí fún gbogbo wa mọ̀.11 A yàn Án tẹ́lẹ̀ àti ṣíwájú nínú Ìgbìmọ̀ Nlá ní Ọ̀run, àní kí a tó dá ayé.12 Síwájú si, a bi nípasẹ̀ ìyá ayé ikú, Ó jogún ikú ti-ara, ṣùgbọ́n látọ̀dọ Ọlọ́run, Ọmọ Bíbí Nìkanṣoṣo Baba, Ó jogún agbára láti fi ẹ̀mí ara Rẹ̀ lélẹ̀ àti lẹ́hìnáà ó tún mú padà lẹ́ẹ̀kansi.13 Ní àfikún, Krístì gbé ìgbé ayé pípé tí ó wà láìsí ẹ̀gbìn, àti pé, nítorínáà, a yọ́ kúrò nínú àwọn ìbèèrè fún ìdáláre ti ọ̀run.13 Ní àwọn ọ̀ràn kan Wòlíì Joseph Smith kọ́ni:

Ìgbàlà Kò lè wá sí ayé láìsí ìlàjà Jésù Krístì.

“Ọlọ́run … pèsè ìrúbọ kan nínú ẹ̀bùn Ọmọ Tirẹ̀, tí a ó rán wá ní àkokò tó nbọ̀ láti … ṣí ilẹ̀kùn kan nípa èyí tí ènìyàn lè wọlé sí ọ̀dọ̀ Olúwa.”14v-p10

Bíótilẹ̀jẹ́pé Olùgbàlà mú ikú ti ara kúrò pátápátá nípasẹ̀ ìrúbọ Rẹ̀,15 Òun kò mú ojúṣe araẹni wa kúrò láti ronúpìwàdà fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí a ti dá.16 Ṣùgbọ́n, Ó ti nawọ́ ìfipè pàtàkì sí wa láti làjà pẹ̀lú Baba wa Ayérayé. Nípasẹ̀ Jésù Krístì àti ìrúbọ ètùtù Rẹ̀, a lè ní ìrírí ìyípadà nlá ti inú àti ọkàn, tí ó nmú ìhùwàsí titun wá, sí Ọlọ́run àti sí ìgbé ayé lápapọ̀. Nígbàtí a ba ronúpìwàdà dénúdénú kúrò nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, ní yíyí ọkàn àti ìfẹ́ inú wa sí Ọlọ́run àti sí àwọn òfin Rẹ̀, a lè gba ìdáríjì Rẹ̀ kí a sì ní ìmọ̀lára agbára Ẹ̀mí Mímọ́ Rẹ̀ ní tìtóbi síi lọ́pọ̀lọpọ̀. Pẹ̀lú àánú, a ó yẹra fún níní ìrírí irú ìjìnlẹ̀ ìjìyà tí Olùgbàlà ti faradà.18

Ẹ̀bùn ìrònúpìwàdà jẹ́ ìfihàn inúrere Ọlọ́run sí àwọn ọmọ Rẹ̀, àti pé ó jẹ́ ìjúwe agbára àìláfiwé Rẹ̀ láti rànwálọ́wọ́ láti borí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí a ndá. Bákannáà ó jẹ́ ẹ̀rí kan ti sùúrù àti ìpamọ́ra ti Baba wa Ayérayé fún àwọn àìlera àti àìlókun ayé ikú wa. Ààrẹ Russell M. Nelson, àyànfẹ́ wòlíì wa, tọ́ka sí ẹ̀bùn yí bí “kọ́kọ́rọ́ sí ìdùnnú àti àláfíà ọkàn.”19

Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, mo jẹ́ ẹ̀rí pé bí a ṣe nronúpìwàdà fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa dénúdénú,20 a nfi ààyè gba ìrúbọ ètùtù Krísti láti ní ipa tán pátápátá nínú ayé wa.21 A ó di òmìnira kúrò nínú ìgbèkùn ẹ̀ṣẹ̀, a ó rí ayọ̀ nínú ìrìnàjò ti ilẹ-ayé wa, a ó sì di yíyẹ láti gba ìgbàlà ayérayè, èyí tí a ti múrasílẹ̀ láti ìpìlẹ̀ ayé fún gbogbo ẹnití ó gbàgbọ́ nínú Jésù Krístì tí ó sì wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.22

Ní àfikún sí ẹ̀bún ọlọ́lá ìgbàlà yí, Olùgbàlà bákannáà fún wá ní ìrànlọ́wọ́ àti ìtùnú bí a ṣe ndojúkọ àwọn ìpọ́njú, àdánwò, àti àwọn àìlera wa ti ayé ikú, pẹ̀lú àwọn ipò tí a ní ìrírí wọn láìpẹ́ yi nínú àjàkálẹ̀-àrùn tó nlọ lọ́wọ́. Mo lè fi dáa yín lójú pé Krístì fi ìgba gbogbo mọ̀ nípa àwọn ìpọ́njú tí à nní ìrírí rẹ̀ nínú ayé ikú. Ó ní ìmọ̀ gbogbo ìkorò, ẹ̀dùn, àti ìrora ti-ara àti bákannáà àwọn ìpènijà ti ẹ̀dùn-ọkàn àti ti ẹ̀mí tí a ndojúkọ. Inú Olùgbàlà kún fún àánú, àti pé Ó ṣetán láti tù wá nínú. Èyí ṣeéṣe nítorí Òun ní ìrírí ti araẹni ó sì gbé ẹran ara ìrora àìlera àti àìlókún wa lé Ararẹ̀.24

Pẹ̀lú inútútù àti ìrẹ̀lẹ̀ ọ̀kan, Ó sọ̀kalẹ̀ ju ohun gbogbo lọ ó sì tẹ́wọ́gba ìkẹgàn, ìpatì, àti ìdójútì láti ọwọ́ àwọn ènìyàn, ní pípalára fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àti ìrékọjá wa. Ó jìyà àwọn ohun wọ̀nyí fún gbogbo ènìyàn, ó gbé gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ aráyé lé orí Ara rẹ̀,24 Ó sì di olùtọ́jú ìgbẹ̀hìn ti-ẹ̀mí wa.

Bí a ti nsúnmọ Ọ si, tí à njọ̀wọ́ ara wa sílẹ̀ níti-ẹ̀mí sí ìtọ́jú Rẹ̀, a ó lè gbé àjàgà Rẹ̀ lé orí ara wa, èyí tí ó rọrùn, àti ẹrù Rẹ̀, èyí tí ó fúyẹ́, nípa báyìí kí a rí ìtùnú àti ìsinmi tí a ṣe ìlérí rẹ̀. Síwájú si, a ó gba okun tí gbogbo wá nílò láti borí àwọn ìnira, aìlera, àti ìkorò ayé, èyí tí yíò ṣòrò gan an láti faradà láìsí ìrànlọ́wọ́ àti agbára ìwòsàn Rẹ̀.25 Àwọn ìwé mímọ́ kọ́ wá láti “gbé ẹrù rẹ lé Olúwa, Òun ó sì ràn wá lọ́wọ́.”26 “Nígbànáà njẹ́ kí Ọlọ́run gbà fún [wa] kí ẹrù [wa] lè fúyẹ́, nípasẹ ayọ̀ Ọmọ [Rẹ̀].”27

Àwòrán
Regina àti Mario Emerick

Ní ìsúnmọ́ òpin ọdún tó kọjá, mo gbọ́ nípa ikú lọ́kọ-láya ọ̀wọ́n kan, Mario àti Regina Emerick, àwọn tí wọ́n jẹ́ olotitọ gidi sí Olúwa tí wọ́n sì kú ní ọjọ́ mẹ́rin síra wọn, nítorí ìlọ́lù láti inú COVID-19.

Ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin wọn, tí ó nsìn lọ́wọ́lọ́wọ́ bí Bíṣọ́ọ̀pù kan ní Brazil, sọ ìwọ̀nyí fún mi: “Ó ṣòrò gidi láti ri tí àwọn òbí mi kúrò nínú ayé yí nínú ipò náà, ṣùgbọ́n mo lè ní ìmọ̀lára kedere ti ọwọ́ Olúwa nínú ayé mi ní àárín àjálù náà, nìtorí mo gba okun àti àláfíà tí ó tayọ ìmọ̀ mi. Nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ mi nínú Jésù Krístì àti Ètùtù Rẹ̀, mo gba ìrànlọ́wọ́ ti-ọ̀run láti fún mi lókun àti láti tù àwọn ọmọ ẹbí mi nínú àti gbogbo àwọn tí wọ́n ràn wá lọ́wọ́ ní ìgbà ìyànjú ìrírí yí. Àní bíótilẹ̀jẹ́pé iṣẹ́-ìyanu tí gbogbo ènìyàn nretí kò ṣẹlẹ̀, níti-araẹni mo jẹ́ ẹlẹ́rìi ìyípadà tí ó ṣẹlẹ̀ nínú ayé tèmi àti nínú ayé àwọn ọmọ ẹbí mi. Mo ní ìmọ̀lára àláfíà àìlèjúwe tí ó wọnú ìjìnlẹ̀ ọkàn mi, tí ó fún mi ní ìrètí àti ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìfẹ́ Olùgbàlà fún mi àti nínú ètò ìdúnnú ti Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Rẹ̀. Mo kọ́ pé ní àwọn ọjọ́ kíkún fún ọ̀fọ̀ jùlọ gan an, ọwọ́ ìfẹ́ni tí Olùgbàlà nnà nígbà gbogbo nígbàtí a bá wá A pẹ̀lú gbogbo ọkàn, agbára, inú, àti okun wa.”

Àwòrán
Ẹ̀bí Emerick

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, ní òwúrọ̀ Ọjọ́-ìsinmi Ọdún-àjínde yí, mo jẹ́ ẹ̀rí ọ̀wọ̀ mi pé Jésù dìde kúrò nínú òkú àti pé Ó wà láàyè. Mo jẹ́ ẹ̀rí sí yín pé nípasẹ̀ Rẹ̀ àti irúbọ ètùtù Rẹ̀, Olùgbàlà pèsè ọ̀nà fún wa láti borí ikú, níti-ara àti níti-ẹ̀mí bákannáà. Ní àfikún sí àwọn ìbùkún nlá wọ̀nyí, bákannáà Ó fún wa ní ìtùnú àti ìdánilójú ní àwọn ìgbà ìṣòrò. Mo mu dáa yín lójú pé bí a ti nfi ìgbẹ́kẹ̀lé wa sínú Jésù Krístì àti Ètùtù Rẹ̀ títayọ, tí a nfaradà nínú ìgbàgbọ́ wa dé òpin, a ó gbàdùn àwọn ìlérí àyànfẹ́ Baba wa Ọ̀run, ẹnití ó nfẹ́ láti ṣe ohun gbogbo nínú agbára Rẹ̀ láti ràn wá lọ́wọ́ láti padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ní ọjọ́ kan. Èyí ni iṣẹ́ Rẹ̀ àti Ìjọ Rẹ̀!29 Mo jẹ́ ẹ̀rí sí yín pé Jésù ni Krístì, Olùràpadà aráyé, Messiah tí a ṣèlérí, àjínde àti ìyè náà.28 Mo pín àwọn òtítọ́ yí pẹ̀lú yín ní orúkọ mímọ́ Rẹ̀, Ọmọ Bíbí Nìkanṣoṣo ti Baba, Olúwa wa, Jésù Krístì, àmín.

Tẹ̀