Ìbànújẹ́ Wa Yìo Yípadà sí Ayọ̀
Mo pe gbogbo ẹni tí ó ní ìmọ̀lára ìbànújẹ́, gbogbo àwọn ti o nyàlẹ́nu ohun to nṣẹlẹ̀ lẹ́hìn tí a bá kú, láti fi ìgbàgbọ́ rẹ sínú Krístì.
Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́hìn, nígbàtí a lọ sí àwọn ìpàdé ni Ìlú Nla Salt Lake, olùfẹ́ wòlíì wa, Russell M. Nelson kí mi. Ní ọ̀nà ọ̀yàyà àti ìṣe ara ẹni rẹ̀, o bèrè pé, “Mark, báwo ni ìyá rẹ?”
Mo sọ fun pé mo ti wà pẹ̀lú rẹ ni ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀sẹ̀ náà ní ilé rẹ̀ ni New Zealand àti pé ó ti ndàgbà ṣùgbọ́n ó kún fún ìgbàgbọ́ àti ìmísí fún àwọn tí o mọ̀ ọ́.
Ó sọ pé, “Jọ̀wọ́ fun ní ìfẹ́ mi … kí o sọ fun pé mo nírètí láti ri i lẹ́ẹ̀kan si.”
Ó jẹ́ ìyàlẹ́nu fún mi mo sì bèrè pé, “Njẹ́ o ngbèrò láti rin ìrìnàjò lọ New Zealand láìpẹ́?”
Pẹ̀lú àròjinlẹ̀ òtítọ́ ó dáhùn pé, “Ah rárá, èmi ó ri ní ayé tó nbọ̀.”
Kò sí ohun àwàdà kankan nínú ìdáhùn rẹ. O jẹ́ ọ̀rọ̀ sísọ ti òtítọ́ kan ní pípé àdánidá. Ní àkókó ìkọ̀kọ̀, tí kò ni ààbò náà, mo gbọ́ mo sì ní ìmọ̀lára ẹ̀rí àìlẽrí láti ẹnu wòlíì alàyè pé ayé ntẹ̀síwájú lẹ́hìn ikú.
Ní òpin ọ̀sẹ̀ ti ìpàdé àpapọ̀ yí ẹ ó gbọ àwọn àpóstélì àti wòlíì alààyè tí wọn ó jẹri nípa Àjínde Jésù Krístì. “Àwọn ìpìlẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ti ẹ̀sìn wa ni ẹ̀rí àwọn Àpóstélì àti àwọn Wòlíì, nípa Jésù Krístì, pé Ó kú, a sín I, Ó sì tún jí ní ọjọ́ kẹ́ta, … gbogbo àwọn nkan míràn tí ó jẹmọ́ ẹ̀sìn wa jẹ́ àwọn àfikún nìkan sí [òtítọ́ yí].”1 Mo ṣèlérí pé bí ẹ bá ṣe fetísílẹ̀ pẹ̀lú èrò-inú gidi, Ẹ̀mí yìó jẹri òtítọ́ àwọn ẹ̀rí wọ̀nyí ní inú àti ọkàn yín.2
Àwọn Àpòstélì àtíjọ ti Jésù di yíyípadà láéláé lẹ́hìn tí Ó farahàn wọ́n lẹ́hìn ikú Rẹ̀. Mẹwa nínú wọn ri fúnrawọn pé Ó ti jínde Thomas, ti kò sí níbẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀, kéde, “Bíkòṣe pé èmi bá ri … , Èmi kì yíò gbàgbọ́.”3 Lẹ́hìnnáà Jésù gbà Thomas nímọ̀ràn: “Máṣe jẹ́ aláìgbàgbọ́, ṣùgbọ́n gbàgbọ́.”4 Nígbànáà Olúwa kọ́ ipa pàtàkì ti ìgbàgbọ́: “Alábùkún fún ni àwọn tí kò rí mi, tí wọ́n sì gbàgbọ́ síbẹ̀.”5
Olúwa tí ó jínde fún àwọn Àpóstélì Rẹ̀ ní àṣẹ láti jẹ́ri Rẹ̀. Bíi ti àwọn Àpóstélì alààyè wa loni, wọ́n fi àwọn iṣẹ́ ti ayé sílẹ̀ wọ́n sì lo ìyókù ayé wọn ní kíkéde pẹ̀lú ìgboyà pé Ọlọ́run ti jí Jésù yí dìde. Àwọn ẹ̀rí alágbára wọn yọrí si ẹgbẹgbẹ̀rún tí ngba ìfipè láti ṣe ìrìbọmi.6
Ọ̀rọ ológo ti òwúrọ̀ Àjínde jẹ́ kókó sí gbogbo Krìstẹ́nì. Jésù Krístì ti jínde nínú òkú, àti nítorí èyí, àwa náà yíò yè lẹ́ẹ̀kansíi lẹ́hìn tí a bá kú. Ìmọ̀ yìí fún wa ní ìtumọ̀ àti ìdí sí ìgbé ayé wa. Tí a bá lọ síwájú nínú ìgbàgbọ́, a ó yípadà láéláé, bí àwọn Àpóstélì ìgbàanì ti ṣe. Àwa, bí àwọn, yìó ni okun láti faradà èyíkèyí ìnira pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì. Ìgbàgbọ́ yí tún fún wa ní ìrètí fún àkókò kan nígbàtí “Ìbànújẹ́ wa yìo yípadà sí ayọ̀.”7
Ìgbàgbọ́ tèmi ní àwọn ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ní títẹ̀lé àkókò ìbànújẹ́ kan.
Bàbá àti ìyá mí jẹ́ àgbẹ̀ àgùtàn ní New Zealand.8 Wọ́n gbádùn ayé wọn. Bí ọ̀dọ́ tọkọtaya tí wọ́n ṣe ìgbéyàwó, a bùkún wọn pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin kékeré mẹ́ta. Èyí tí o kéré jùlọ ni a sọ ní orúkọ Ann. Ní ọjọ́ kan nígbà tí wọ́n wà ní ìsinmi papọ̀, Ann ọmọ oṣù mẹ́tàdínlógún rìn lọ. Lẹ́hìn àwọn ìṣẹ́jú wíwá àìnírètí, wọ́n rí I láì ni ẹ̀mí mọ́ nínú omi.
Àlá burúkú yi fa ìbànújẹ́ tí kò ṣeé sọ. Bàbá kọwé lẹ́hìn ọdún púpọ̀ pé díẹ̀ nínú àwọn ẹ̀rín jáde kúrò ní ìgbé ayé wọn títí láíláí. Bákannáà ó fa ìyọ́nú fún àwọn ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè pàtàkì jùlọ ni ìgbé ayé: “Kíni yìó jẹ́ ti Ann wa iyebíye? Ṣé a ó rí I mọ́ láé? Báwo ni àwọn ẹbí wa ṣe lè dunnú lẹ́ẹ̀kan si?”
Ọdún díẹ̀ lẹ́hìn àjálù yí, ìránṣẹ́ ìhìnrere kékere méjì láti Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn wá sí oko wa. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ síí kọ́ni ní àwọn òtítọ́ tí a rí láti inú Ìwé ti Mọ́mọ́nì àti Bíbélì. Nínú àwọn òtítọ́ wọ̀nyí ni ìdánilójú pé Ann ngbé bayi ní ayé ẹ̀mí. Nítorí Àjíndè ti Jésù Krístì, òun náà yio jínde. Wọ́n kọ́ni pé a ti mú Ìjọ Jésù Krístì padàbọ̀sípò lẹ́ẹ̀kan si ní orí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú alààyè wòlíì kan àti àwọn Àpóstélì méjìlá. Àti pé wọ́n kọ́ni ní ẹ̀kọ́ olókìkí pé àwọn ẹbí lè wà papọ̀ títíláé nípasẹ̀ àṣẹ oyè àlùfáà kannáà ti Jésù Krístì fún olóyè Àpóstélì Rẹ, Pétérù.9
Màmá dá òtítọ́ mọ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ó sì gba ẹ̀rí nípasẹ̀ Ẹ̀mí. Ṣùgbọ́n, bábá, ja ìjàkadì fún ọdùn kan si laarin àwọn iyèméjì àti àwọn ìdaradúró ti ẹ̀mí. Bákannáà, o nlọ́ra láti yí ọ̀nà ìgbé ayé rẹ̀ padà. Ní òwúrọ̀ kan tí o tẹ̀lé òru àìlesùn kan, nígbà ti o nyílẹ̀, ó kọjú sí Màmá o sì wípé, “èmi ó ṣe ìrìbọmi lóni tàbí láíláí.”
Màmá sọ ohun tí o ṣẹlẹ̀ fún àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ wọ́n dá ìtànṣán ìgbàgbọ́ nínú bàbá mi mọ̀ tí yìó jẹ́ bóyá títàn nísisìyí tàbí pípa.
Ní òwúrọ̀ náà gan ẹbí wa rin ìrìnàjò lọ sí etí òkun tí ó súnmọ́ tòsí jùlọ. Láì mọ ohun tí ó nṣẹlẹ̀, àwa ọmọ ní eré aláfẹ́ ni orí erùpẹ̀ gíga nígbà tí àwọn Alàgbà Boyd Green àti Gary Sheffield mú àwọn òbi mi lọ sínú òkun tí wọ́n sì rì wọ́n bọmi. Ní ìṣe ìgbàgbọ́ síwájú, Bàbá ṣe ìlérí àdáni fún Olúwa pé, bí o ti wù kí ó rí, òhun yio ṣe òtítọ́ ní gbogbo ayé rẹ̀ sí àwọn ìlérí tí òun nṣe.
Ní ọdún kan lẹ́hìnwá a ya tẹ́mpìlì kan si mímọ́ ni Hamilton, New Zealand. Láìpẹ́ lẹ́hìnnáà ẹbí wa, pẹ̀lú ẹnìkan tí nṣe aṣojú Ann, kúnlẹ̀ ní àyíká pẹpẹ nínú ilé mímọ́ Olúwa náà. Níbẹ̀, nípa àṣẹ oyè àlúfáà, a sọ wá di ọ̀kan bíi ẹbí ayérayé nínú ìlànà kan tí ó rọrùn tí ó sì rẹwà. Èyí mú àlááfíà àti àyọ nla wá.
Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdùn lẹ́hìnwá Bàbá sọ fún mi pé bí kò ba sí ti àjálù ikú Ann, òun kì bá má ní ìrẹ̀lẹ̀ tó láti gba ìhìnrere tí a mú padàbọ̀ sípò . Síbẹ̀ Ẹ̀mí Olúwa gbin ìrètí pé ohun tí àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere kọ́ jẹ́ òtítọ́. Ìgbàgbọ́ àwọn òbí mi tẹ̀síwájú láti dàgbà títí tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn fi jó fún iná ẹ̀rí èyítí ó fi ìdákẹ́jẹ́ àti ìrẹ̀lẹ̀ darí gbogbo ìpinnu wọn ní ìgbésí ayé.
Èmi yio máa dúpẹ́ nígbàgbogbo fún àpẹrẹ àwọn òbi mi sí àwọn ìran tó nbọ̀. Kò ṣeéṣe láti wọn iye àwọn ìgbésí ayé tí ó yípadà títíláé nítorí àwọn ìṣe ìgbàgbọ́ wọn ní ìdáhùn sí ìbànújẹ́ jíjinlẹ̀.
Mo pe gbogbo ẹni tí ó ní ìmọ̀lára ìbànújẹ́, gbogbo ẹni tí ó njìjàkadì pẹ̀lú iyèméjì, gbogbo àwọn ti o ṣe ìyàlẹ́nu kínni o nṣẹlẹ̀ lẹ́hìn tí a bá kú, láti fi ìgbàgbọ́ wọn sínú Krístì. Mo ṣe ìlérí pé bí ìwọ bá fẹ́ láti gbàgbọ́, nígbànáà gbé ìgbésẹ̀ nínú igbàgbọ̀ kí o sì tẹ̀le àwọn ìsọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ ti Ẹ̀mí, ìwọ yio rí ayọ̀ ní ayé yi àti ní ayé tó nbọ̀.
Mo ti nfi ojúsọ́nà sí ọjọ́ náà tí Èmi yio pàdé arábìnrin mi Ann. Mo nfojúsọ́nà sí ìdàpọ̀ aláyọ̀ kan pẹ̀lú bàbá mi, ẹnití ó kú ní ọgbọ̀n ọdún sẹ́hìn. Mo jẹri ayọ̀ tí a ó rí nínú gbígbé ayé nípa ìgbàgbọ́, gbígbàgbọ́ láì rí, ṣùgbọ́n mímọ̀ nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́ pé Jésù Krístì wà láàyè. Pẹ̀lú gbogbo ọkàn àti ẹ̀mí mi, mo yàn láti tẹ̀lé Jésù Krístì àti ìhìnrere Rẹ̀ tí a mú padàbọ̀ sípò. Èyí nbùkún gbogbo abala ìgbésí ayé mi. Mo mọ̀ pé Jésù ni Krístì, Ọmọ Ọlọ́run, Olùgbàlà wa àti Olùràpadà wa. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.