Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ìrìnàjò Araẹni ti Ọmọ Ọlọ́run
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2021


Ìrìnàjò Araẹni ti Ọmọ Ọlọ́run

Bí àwọn ọmọ májẹ̀mú Ọlọ́run, a ní ìfẹ́, ọlá, ìkẹ́, ààbò, àti kíkí àwọn ẹ̀mí wọnnì káàbọ̀ tí wọ́n nbọ̀ látinú ìṣíwájú ayé.

Àjàkálẹ̀ àrùn gbogbo ayé ti pa ẹnìkọ̀ọ̀kan wa lára, bi ẹbí àti ọ̀rẹ́ ti lọ kọjá àìrótẹ́lẹ̀ ayé-ikú. Ẹ jẹ́ kí a jẹ́wọ́ mẹ́ta tí a dárò dáadáa, ṣíṣojú gbogbo àwọn wọnnì tí a nifẹ púpọ̀ gidi.

Arákùnrin àti Arábìnrin Nsondi

Èyí ni arákùnrin Philippe àti arábìnrin Germaine Nsondi. Èyí ni arákùnrin Nsondi tí ó nsìn bí babanla Èèkàn Brazzaville Congo nígbàtí ó kú. Ó jẹ́ dókítà egbòogi tí ó pín àwọn ẹ̀bùn rẹ̀ pẹ̀lú inúrere sí àwọn ẹlòmíràn.1

Clara Ruano de Villareal

Èyí ni Arábìnrin Clara Ruano de Villareal láti Tulcán, Ecuador. Ó gba ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere mọ́rà ní ọmọ ọjọ́-orí mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n ó sì jẹ́ olórí olólùfẹ́. Ẹbí rẹ̀ sọ ó dàbọ̀ sí i ní kíkọ orin alárinrin rẹ̀, “Mo Mọ̀ Pé Olùràpadà Mi Wà Láàyè.”2

Ray Tuineau àti ẹbí rẹ̀

Èyí ni Arákùnrin Ray Tuineau láti Utah, pẹ̀lú àwọn ẹbí rẹ̀ dídára. Ìyàwó rẹ̀, Juliet, wípé, “Ohun tí mo fẹ́ kí [àwọn ọmọkùnrin mi] [rántí ni pé baba wọn] máa nfi Ọlọ́run síwájú nígbàgbogbo.”3

Olúwa ti wípé, “Ẹ̀yin ó gbé papọ̀ nínú ìfẹ́, tóbẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin yíò sọkún fún àdánù àwọn tí ó kú.”4

Nígbàtí à nsọkún, bákannáà a nyọ̀ nínú Àjínde ológo ti Olùgbàlà wa. Nítorí Rẹ̀, àwọn olólùfẹ́ wa àti ọ̀rẹ́ yíò tẹ̀síwájú nínú ìrìnàjò ayérayé wọn. Bí Ààrẹ Joseph F. Smith ti ṣàlàyé: “A kò lè gbàgbé wọn; a ko dá níní ìfẹ́ wọn dúró. … Wọ́n ti dàgbàsókè; à ndàgbàsókè; à ndàgbà bí wọ́n ti dàgbà.”5 Ààrẹ Russell M. Nelson wípé, “omijé ti ìkorò wa … yípadà sí omijé ìgbèrò.”6

A mọ nípa Ayé àti ṣíwájú Ìbí

Ìwò ayérayé wa kò mú òye wa nípa ti àwọn tí ó tẹ̀síwájú nínú ìrìnàjò wọn kọjá ayé-ikú gbòòrò lásán ṣùgbọ́n bákannáà ó ṣí òye wa nípa àwọn tí wọ́n ṣíwájú nínú ìrìnàjò wọn àti tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ wọnú ayé ikú nísisìyí.

Ẹnìkọ̀ọ̀kan tí ó wá sórí ilẹ̀ ayé jẹ́ ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin àràọ̀tọ̀ Ọlọ́run.7 Ìrìnàjò araẹni wa kò bẹ̀rẹ̀ní ìbí. Ṣíwájú kí a tó bí wa, a wà papọ̀ nínú ayé ìmúrasílẹ̀ kan níbití a ti “gba àwọn ẹ̀kọ́ àkọ́kọ́ [wa] nínú ayé ẹ̀mí.”8 Jehofah wí fún Jeremíàh, “Kí èmi tó dá ọ ní inú èmi ti mọ̀ ọ́; kí ìwọ kí ó sì tó ti inú jáde wá ni èmi ti sọ ọ́ di mímọ́.”9

Àwọn kan lè bèèrè bóyá ayé bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú dídá oyún kan, tàbí nígbàtí ọkàn bẹ̀rẹ̀ sí nmì, tàbí tí ọmọ lè gbé níta ikùn, ṣùgbọ́n fún wa, kò sí ìbèèrè pé àwọn ọmọbìnrin àti ọmọkùnrin Ọlọ́run wà ní ìrìnàjò araẹni tí wọ́n wá sí ilẹ̀ ayé láti gba ara àti ìrírí ayé ikú.

Bí àwọn ọmọ májẹ̀mú Ọlọ́run, a ní ìfẹ́, ọlá, ìkẹ́, ààbò, àti kíkí àwọn ẹ̀mí wọnnì káàbọ̀ tí wọ́n nbọ̀ látinú ìṣíwájú ayé.

Àwọn Ìdásí Ìyanu àwọn Obìnrin

Fún obìnrin kan, níní ọmọ lè jẹ́ ìrúbọ nla ti-ara, ẹ̀dùn ọkàn, àti ìṣúná. A nifẹ a sì bu ọlá fún àwọn obìnrin oníyanu Ìjọ yí. Pẹ̀lú òye àti ọgbọ́n, ẹ ngbe àwọn àjàgà ẹbí yín. Ẹ nifẹ. Ẹ nsìn. Ẹ̀ nfarajìn. Ẹ̀ nfún ìgbàgbọ́ lókun, ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn wọnnì nínú àìní, ẹ sì lè dásí àwùjọ gidigidi.

Ojúṣe Mímọ́ ti Dídá Ààbò Bo Ìgbé Ayé

Àwọn ọdún sẹ́hìn, ní ìmọ̀lára àníyàn jíjinlẹ̀ fún oye ìṣẹ́yún nínú ayé, Ààrẹ Gordon B. Hinckley bá àwọn obìnrin Ìjọ sọ̀rọ̀. Ó wípé: “Ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ ìyàwó àti ìyá ni ìdákòró ẹbí. Ẹ̀ nbí àwọn ọmọ. Irú ojúṣe títóbi àti mímọ́ tí èyí jẹ́. … Kíni ó nṣẹlẹ̀ sí ìmoore wa nípa iyì ayé ẹlẹ́ran-ara? Ìṣẹ́yún jẹ́ oun ibi, pátápátá àti gidi àti ìṣiwèrè, èyí tí ó ngbá lọ lórí ayé. Mo bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú àwọn obìnrin Ìjọ láti pa á ti, láti dúró kọjá rẹ̀, láti kúró nínú àwọn ìpò ìlàjà wọnnì èyí tí ó mu dàbí ìwuni. Àwọn ipò díẹ̀ lábẹ́ èyí tí ó lè ṣẹlẹ̀ wà, ṣùgbọ́n wọn ní òpin gan.10 … Ẹ̀yin ni àwọn ìyá ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin Ọlọ́run, tí ayé wọn jẹ́ mímọ́. of God, whose lives are sacred. Dídá ààbò bó wọ́n ni ojúṣe tọ̀run tí a fúnni èyí tí a kò lè ti sẹgbẹ́ lásán.”1112

Alàgbà Marcus B. Narsh pín ìtàn obìnrin ọmọ ọjọ́ orí mẹrìnlélọ́gọ́rin kan pẹ̀lú mi ẹni tí ó, “jẹ́wọ́ ìṣẹ́yún [lọ́pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́hìn] ní ìgbà ìfọ̀rọ̀wànilẹ́nuwò ìrìbọmi rẹ̀.” Pẹ̀lú ẹ̀dùn ọkàn àtinúwá, ó wípé: “Èmi ti gbé àjàgà ti ṣíṣẹ́ oyún ọmọ kan lójojúmọ́ ayé mi fún ọdún mẹ́rìndínládọ́ta. … Kò sí ohun tí mo ṣe tí ó lè mú ìrora àti ẹ̀rí ọkàn náà kúrò. Èmi kò nírètí títí tí a fi kọ́ mi ní òtítọ́ ìhìnrere Jésù Krístì. Mó kọ́ bí mo ṣe lè ronúpìwàdà … mo sì kún fún ìrètí lọ́gán. Ní ìgbẹ̀hìn mo mọ̀ pé a lè dáríjì mi nítòótọ́ bí mo bá ronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi.”1314

Bí a ṣe dúpẹ́ tó fún àwọn ẹ̀bùn tọ̀run ti ìrònúpìwàdà àti ìdáríjì.

Kíni A Lè Ṣe?

Kíni ojúṣe wa bí ọmọẹ̀hìn àláláfíà ti Jésù Krístì? Ẹ jẹ́ kí a gbé òfin Ọlọ́run, kọ́ wọn sí àwọn ọmọ wa, kí a sì pín wọn pẹ̀lú àwọn míràn tí wọ́n fẹ́ fétísílẹ̀.15 Ẹ jẹ́ kí a pín ìmọ̀lára ìjìnlẹ̀ wa nípa iyi ayé pẹ̀lú àwọn wọnnì tí wọ́n nṣe ìpinnu ní àwùjọ. Wọ́n lè má tilẹ̀ mọyì ohun tí a gbàgbọ́, ṣùgbọ́n a gbàdúrà pé wọn yíò ní òye kíkún si nípa ìdí, fún wa, tí àwọn ìpinnu wọ̀nyí fi lọ dáadáa kọjá ohun tí ẹnìkan nfẹ́ fún ọkùnrin tàbí obìnrin ayé ararẹ̀ lásán.

Bí ọmọ tí a kò retí kan bá mbọ̀, ẹ jẹ́ kí a nawọ́ jáde pẹ̀lú ìfẹ́, ìgbàni-níyànjú, àti nígbàtí wọ́n bá nílò, ṣe ìrànlọ́wọ́ owó, fún iya lókun ní fífi àyè gbà á ní bíbí ọmọ rẹ̀ àti láti tẹ̀síwájú ní ìrìnàjò ayé ikú.14

Ẹwà Ìgbanitọ́

Nínú ẹbí wa, a ti di alábùkúnfún làìniwọ̀n bí díkédì méjì sẹ́hìn, ọ̀dọ́mọbìnrin ọjọ́ orí mẹ́rìndínlógún kọ́ pé òun nretí ọmọ kan. Òun àti baba ọmọ náà kò ṣe ìgbeyàwó, wọn kò rí ọ̀nà kankan síwájú papọ̀. Ọ̀dọ́mọbìnrin náà gbàgbọ́ pé ẹ̀mí tí ó ngbé jẹ́ iyebíye. Ó bí ọmọbìrin ó sì gbà ẹbí olódodo kan láti gbàá tọ́ bí ti ara wọn. Fún Bryce àti Jolinne, ó jẹ́ ìdáhùn sí àwọn àdúrà wọn. Wọn sọọ́ lórúkọ Emily wọ́n sì kọ láti nígbẹ́kẹ̀lé nínú Baba Ọ̀run àti nínú Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì.

Emily àti Christian

Emily dàgbà sókè. Bí a ṣe dúpẹ́ pé Emily àti ọmọ-ọmọ wa ọkùnrin, Christian, yọrí ìfẹ́ wọ́n sì ṣe ìgbeyàwó ní ilé Olúwa. Emily àti Christian nísisìyí ní ọmọdébìnrin ara wọn.

Emily pẹ̀lú ọmọbìnrin

Emily kọ láìpẹ́ pé: “Ní gbogbo oṣù mẹsan ti oyún wọ̀nyí, mo ní àkokò láti ronú lórí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ [ti] ìbí ara mi. Mo ronú nípa ìyá tó bí mi, ẹni tí ó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún péré. Bí mo ṣe ní ìrírí àwọn ìrora àti ìyípadà tí oyún múwá, èmì kò lè ṣèrànwọ́ ṣùgbọ́n ro bí yíò ti le tó ní ọjọ́ orí mẹ́rìndínlógún. … Omijé ṣàn nísisìyí àní bí mo ṣe ronú nípa ìyá òbí mi, ẹni tí ó mọ pé òun lè fún mi ní ayé [tí ó fẹ́ fún mi àti fi àìmọtaraẹni-nìkan gbé] mi sílẹ̀ fún ìtọ́jú. Èmi kò lè mọ ohun tí ó lè ti là kọjá ní àwọn oṣù mẹsan wọnnì; ní wíwòó pẹ̀lú ojú ìdájọ́ bí ara rẹ̀ ti yípadà, àwọn ìrírí èwe tí ó pàdánù, ní mímọ̀ pé ní òpin iṣẹ́ ìfẹ́ ìyá yí, òun yíò gbé ọmọ rẹ̀ sí ọwọ́ ẹlòmíràn. Mo ṣọpẹ̀ gan an fún àṣàyàn àìní-ìmọtaraẹni-nìkan, pé kò yàn láti lo ìṣojúẹni rẹ̀ ní ọ̀nà kan tí yíò mú ti ara mi lọ.” Emily parí pé,“Èmi dúpẹ́ fún ètò àtọ̀runwá Baba Ọ̀run, fún àwọn òbí aláràgbàyídá tí [ó nifẹ tí ó sì ṣe ìtọ́jú fún] mi, àti fún àwọn tẹ́mpìlì níbití a ti lè ṣe èdidì pẹ̀lú àwọn ẹbí wa fún ayérayé.”16

Kíkó fọ́tò papọ̀

Olùgbàlà “gbé ọmọ kan, ó gbe sí àárín wọn: nígbàtí ó gbe sí ọwọ́ rẹ̀, ó wí fún wọn pé, Ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ọ̀kan lára àwọn ọmọ [wọ̀nyí] ní orúkọ mi, gbà mí”17

Nígbàtí Ìfẹ́ Olódodo Kò Wá Sí Ìmúṣẹ

Mo fi ìfẹ́ mi àti àánú mi hàn fún àwọn lọ́kọláya olódodo tí wọ́n ṣe ìgbeyàwó tí wọn kò sì ní ọmọ tí wọ́n nwá taratara àti sí àwọn obìnrin àti ọkùnrin tí wọn kò tíi ní ànfàní láti ṣe ìgbeyàwó gẹ́gẹ́bí àṣẹ Ọlọ́run. Àwọn àlá ayé le láti lóye bí a bá wòó látinú ìwò ayé ikú nìkan. Bí ìránṣẹ́ Olúwa, mo ṣèlérí fún yín bí ẹ ṣe jẹ́ olóòtítọ́ sí Jésù Krístì àti àwọn májẹ̀mú yín, ẹ̀yin yíò gba ìsanpada àwọn ìbùkún nínú ayé yí àti ìfẹ́ òdodo yín nínú ìgbà ìlà ayérayé Olúwa.18 Inú dídùn lè wà nínú ìrìnàjò ayé ikú àní nígbàtí gbogbo àwọn ìrètí wa ko bá ṣẹ.19

Lẹ́hìn ìbí, àwọn ọmọdé tẹ̀síwájú láti nílò ìrànlọ́wọ́ wa. Àwọn kan nílò rẹ̀ kíákíá. Ọdọọ́dún nípasẹ̀ ìtọ́jú àwọn bíṣọ́ọ̀pù àti ìdásí inúrere ti ọrẹ àwẹ yín àti owó ìtọ́júẹni, tí ó bùkún ayé míllíọ́nù àti míllíọ́nù àwọn ọmọdé. Àjọ Ààrẹ Ìkínní kéde àikún ogun míllíọ́nù dọ́là láìpẹ́ sí UNICEF nínú ìtiraka àgbáyé láti ṣe ìpín bíllíọ̀nù méjì ti abẹ́rẹ́ àjẹsára.20 Ọlọ́run nifẹ àwọn ọmọdé.

Ìpinnu Mímọ́ láti Ní Ọmọ Kan

Àní nípa ìyẹn ni a ṣe nbí àwọn ọmọ díẹ̀ ní àwọn orílẹ̀-èdè ayé tó lásìkí jùlọ.21 “Òfin Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Rẹ̀ láti bí si àti láti rẹ̀ si ní ayé ṣì wà nípá.”22 Ìgbàtí a ó bímọ àti iye ọmọ tí a ó bí jẹ́ ìpinnu ìkọ̀kọ̀ láti ṣe ní àárín ọkọ àti ìyàwó àti Olúwa. Pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti àdúrà, ìpinnu mímọ́ wọ̀nyí lè jẹ́ ìrírí dídára, olùfihàn.23

Mo pín ìtàn ẹbí Laing ti Gúsù California. Arábìnrin Rebecca Laing kọ pé:

Ẹbí Laing

“Ní ìgbà ooru ti 2011, ìgbé ayé fún ẹbí wa dàbí ó pé. A wà ní ìgbeyàwó aláyọ̀ pẹ̀lú ọmọ mẹrin—ọjọ́ orí mẹsan, meje, marun, àti mẹta. …

“Àwọn oyún àti ìbímọ mi [ti jẹ́] ewu gidi … [àti pé] a nímọ̀lára ìbùkún [ púpọ̀] láti ní ọmọ mẹrin, ní [ríronú] pé ẹbí wa ti pé. Ní Oṣu Kẹwa nígbàtí mo fetísílẹ̀ sí ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò, mo ní ìmọ̀lára àìláṣìṣe pé a níláti ní ọmọ míràn. Bí LeGrand àti èmi ti jíròrò a sì gbàdúrà, … a mọ̀ pé Ọlọ́run ní ètò tó yàtọ̀ fún wa ju bí a ti ní fúnra wa.

“Lẹ́hìn oyún àti ìbímọ líle míràn, a di alábùkúnfún pẹ̀lú ọmọbìnrin ẹlẹ́wa kan. A sọ ní orúkọ Brielle. Ó jẹ́ ìyanu kan. Ní àkokò lẹ́hìn ìbí rẹ̀, nígbàtí mo ṣì wà ní [yàrá ìbímọ], mo gbọ́ ohùn àìtàsé ti Ẹ̀mí: ‘Ọkan ṣì wà si.’

“Ọdún mẹ́ta lẹ́hìnnáà, ìyanu míràn, Mia. Brielle àti Mia jẹ́ ayọ̀ nlá fún ẹbí wa.” Ó pari pè, “Ṣíṣí sílẹ̀ fún ìdarí Olúwa àti títẹ̀lé ètò Rẹ̀ fún wa nígbàgbogbo yíò mú ìdùnnú títóbi jù … gbígbaralé òye ti ara wa.”24

Brielle àti Mia Laing

Olùgbàlà nifẹ ọmọ kọ̀ọ̀kan.

“Ó sì mú àwọn ọmọdé wọn, ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, ó sì súre fún wọn, …

“Wọ́n … sì gbé ojú wọn síwájú ọ̀run, … wọ́n rí àwọn àngẹ́lì tí wọ́n nsọ̀kalẹ̀ ní ọ̀run … nínú iná; àti [àwọn ángẹ́lì] … tó yí àwọn ọmọ kékeré wọnnì ká, … àti pé àwọn ángẹ́lì ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí wọn.”25

Mo jẹri pé ìrìnàjò araẹni yín bí ọmọ Ọlọ́run kò bẹ̀rẹ̀ fún yín bí ìṣàn àkọ́kọ́ atẹ́gùn ayé ṣe nrọ́ wọnú ọ̀fun yín àti pé kò ní dópin nígbàtí ẹ bá gba èémí ìkẹhìn yín ti ayé ikú.

Njẹ́ kí a rántí nígbàgbogbo pé ọmọ ẹ̀mí Ọlọ́run kọ̀ọ̀kan nwá sí ilẹ̀-ayé nínú ìrìnàjò ọkùnrin tàbí obìnrin ti araẹni rẹ̀.26 Njẹ́ kí a kí wọn káàbọ̀, dáààbòbò wọ́n, kí a sì nifẹ wọn nígbàgbogbo. Bí ẹ ti ngba àwọn ọmọ iyebíye wọ̀nyí ní orúkọ Olùgbàlà tí ẹ sì nràn wọ́n lọ́wọ́ nínú ìrìnàjò ayérayé wọn, mo ṣe ìlérí pé Olúwa yíò bùkún yín yíò sì da ìfẹ́ àti àṣẹ Rẹ̀ lé yín lórí. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Ìfìwéṣọwọ́sí Araẹni.

  2. Ìfìwéṣọwọ́sí Araẹni. Wo “I Know That My Redeemer Lives,” Hymns, no. 136.

  3. Ìfìwéṣọwọ́sí Araẹni.

  4. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 42:45.

  5. Joseph Fielding Smith, nínú Ìròhìn Ìpàdé Àpapọ̀, Apr. 1916, 3.

  6. Nínú “‘Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ayọ̀’: Ààrẹ Nelson pín ọ̀rọ̀ Ìyé Ayérayé ní Ìsìnkú Ọmọbìnrin Rẹ̀,” Ìròhìn Ìjọ, Jan.19, 2019, thechurchnews.com.

  7. Wo “Ẹbí Náà: Ìkéde Kan Sí Àgbáyé,” ChurchofJesusChrist.org.

  8. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 138:56.

  9. Jeremíàh 1:5. Májẹ̀mú Titun sọ nípa Jòhánù onírìbọmi tí a kò tí ì bí tí ọlẹ́ sọ nínú bí Èlísábẹ́tì ṣe bá Màríà pàdé, ẹni tí ó nretí Jésù ọmọ-ọwọ́ (wo Lúkù 1:41).

  10. Ipò gbangba ti Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn

    “Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn gbàgbọ́ nínú ayé ẹ̀dá. Nítorínáà, Ìjọ tako ṣíṣẹ́ oyún fún araẹni tàbí ìrọ̀rùn àwùjọ, ó sì gba àwọn ọmọ Ìjọ ní àmọ̀ràn láti kọ̀ ọ́, má ṣeé, gbìyànjú, sanwó fun, tàbí ṣe ètò fún irú ìṣẹ́yún bẹ́ẹ̀.

    “Ìjọ fi ààye gba àwọn ìmúkúrò tó ṣeéṣe fún àwọn ọmọ ìjọ nígbàtí: members when:

    “Oyún bá wá látinú ìfipa-bánilò tàbí ìbálòpọ̀ ẹbí, tàbí

    “Amòye olùwòsàn pinnu pé ayé tàbí ìlera ìyá wà nínú ewu líle, tàbí

    “Amòye olùwòsàn pinnu pé ọlẹ̀ inú ní àbùkú olóró tí kò ní jẹ́ kí ọmọ náà yè kọ́já ìbí.

    “Ìjọ kọ́ àwọn ọmọ ìjọ rẹ̀ pé àní ìmúkúrò tó ṣọ̀wọ́n wọ̀nyí kò gbà ìṣẹ́yún tààrà láàyè. Ìṣẹ́yún ni ọ̀ràn líle jùlọ tí a níláti ro nìkan lẹ́hìn tí ẹni tí ó ṣẹlẹ̀ sí bá ti filọ àwọn olórí ìjọ ìbílẹ̀ tí wọ́n sì rò nípasẹ̀ àdúrà pé ìpinnu náà tọ́.

    “Ìjọ kò fọwọ́sí tàbí tako ìṣòfin tàbí ìjúwe gbangba nípa ìṣẹ́yún” (“Ìṣẹ́yún,” Newsroom, newsroom.ChurchofJesusChrist.org; see also Ìwé Ìléwọ́: Sísìn nínú Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, 38.6.1, ChurchofJesusChrist.org).

  11. Gordon B. Hinckley, “Rírìn nínú Ìmọ́lẹ̀ Olúwa,” Ensign, Nov. 1998, 99; Liahona, Jan. 1999, 117.

    Ààrẹ Gordon B. Hinckley wípé:

    Ààrẹ Gordon B. Hinckley wípé: “Ìṣẹ́yún jẹ́ ohun ibi, ohun ìrẹnisílẹ̀, ohun èyí tí ó nmú àbámọ̀ àti ìkorò àti àbámọ̀.

    “Nígbàtí a kọ̀ọ́, a fi ààyè gba irú ipò bí ìgbàtí oyún bá jẹ́ àbájáde ìbálòpọ̀ ẹbí tàbí ìfipa-bánilòpọ̀, nígbàtí ayé tàbí ìlera ìyá bá wa nínú ewu lílé tí aláṣẹ egboogi fọwọ́si, tàbí nígbàtí aláṣẹ egbòogi bá mọ̀ pé ọlẹ̀ inú ní àbùkù líle tí kò ní jẹ́ kí ọmọ náà yè kọjá ìbí,.

    “Ṣùgbọ́n irú àpẹrẹ bẹ́ẹ̀ ṣọ̀wọ́n, ó lè ṣèèṣì ṣẹlẹ̀ pẹ̀lú àìfiyèsí. Nínú àwọn ipò wọ̀nyí àwọn tí ó dojúkọ ìbèèrè náà ni a ní kí wọ́n bá àwọn olórí àlùfáà ìbílẹ̀ wọn sọ̀rọ̀ kí wọ́n sì gbàdúrà nínú ìtara nlá, kí wọ́n gba ìfẹsẹ̀múlẹ̀ nípa àdúrà ṣíwájú títẹ̀síwájú” (“Kíni Àwọn Ènìyan Nbèèrè Nípa Wa?,” Ensign, Nov. 1998, 71; Liahona, Jan. 1999, 83–84).

  12. Neil L. Andersen, Ẹ̀bùn Ìdáríjì Tọ̀run (2019), 25.

    Ní ìgbà kan ní France, ní ìgbà ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò ìrìbọmi, obìnrin kan sọ̀rọ̀sí mi nípa ìṣẹ́yún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́hìn. Mo dúpẹ́ fún inúrere rẹ̀. Ó Ṣe Ìrìbọmi. Ni ọdún kan lẹ́hìnnáà, mo gba ìpè fóònù kan. Obìnrin oníyanu yí nínú ọdún látigbà tí ó ti ṣe ìrìbọmi ni a ti kọ́ nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́. Ó pè nínú ẹkùn: “Ṣé ó rántí pé … mo wí fún ọ nípa ìṣẹ́yún kan láti àwọn ọdún sẹ́hìn? Mo ní ìmọ̀lára ìkáàánú fún ohun tí mo ṣe. Ṣùgbọ́n ọdún tó kọjá ti yí mi padà. … Ọkàn mi ti yí padà sí Olùgbàlà. … Mo ní ìrora gan nípasẹ̀ líle gidi ẹ̀ṣẹ̀ mi tí èmi kò ní ọ̀nà láti mupadàbọ̀sípò.”

    Mo ní ìmọ̀lára ìfẹ́ títóbi Olúwa fún obìnrin yí. Ààrẹ Boyd K. Packer wípé: “Mímúpadàbọ̀sípò ohun tí ko lè padàbọ̀sípò, ìwòsàn ọgbẹ́ tí ẹ kò lè wòsàn, àtúnṣe ohun èyí tí ó bàjẹ́ tí ẹ kò lè túnṣe ni èrò gan an nípa ètùtù Krístì. Nígbàtí ìfẹ́ yín bá dúró gbọingbọin tí ẹ sì nfẹ́ láti san ‘oókan tí ó kù’ [wo Matthew 5:25–26], òfin ìdápadà tí a dá dúró. Ojúṣe yín ni a gbé fún Olúwa Wo Boyd K. Packer” (“Òwúrọ̀ Dídán ti Ìdáríjì,” Ensign,, Nov. 1995, 19–20). Mo fi ìfẹ́ Olùgbàlà dá a lójú. Olúwa kò gbé ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ nìkan kúrò; Ó fún ẹmí rẹ̀ lókun ó sì tunṣe. Neil L. Andersen, Ẹ̀bùn Ìdáríjì Tọ̀run, 154–56.)

  13. Wo Dallin H. Oaks, “Dá Ààbò Bo àwọn Ọmọ,” Liahona, Nov. 2012, 43–46.

  14. Dídá ààbò bo ayé ọmọbìnrin àti ọmọkùnrin Ọlọ́run bákannáà ni ojúṣe baba. Gbogbo baba ní ẹ̀dùn-ọkàn, ti-ẹ̀mí, àti ojúṣe owó láti ṣe, ìfẹ́, àti ìtọ́jú fún ọmọ tí ó mbọ̀ wá sí ilẹ̀-ayé.

  15. Ìfìwéṣọwọ́sí Araẹni.

  16. Máttéù 4:36–37.

  17. Wo Neil L. Andersen, “A Compensatory Spiritual Power for the Righteous” (Brigham Young University devotional, Aug. 18, 2015), speeches.byu.edu.

  18. Wo Dallin H. Oaks, “Ètò Ìdùnnú Nlá,” Ensign, Nov. 1993, 75; see also Russell M. Nelson, “Choices,” Ensign, Nov. 1990, 75.

  19. Wo “Bishop Caussé Thanks UNICEF and Church Members for COVID-19 Relief,” Newsroom, Mar. 5, 2021, newsroom.ChurchofJesusChrist.org.

  20. Fún àpẹrẹ, bí United States bá mú ìwọ̀n ìrọyin 2008, ní ọdún mẹ́tàlá sẹ́hìn, bí 5.8 million ó jù bẹ́ẹ̀ àwọn ọmọ ni wọ́ wà láyé loni (wo “5.8 Million Fewer Babies: America’s Lost Decade in Fertility,” Institute for Family Studies, Feb. 3, 2021, ifstudies.org/blog/5–8-million-fewer-babies-americas-lost-decade-in-fertility).

  21. Ẹbí Náà: Ìkéde Kan Sí Àgbáyé,” ChurchofJesusChrist.org. Àwọn ìwé mímọ́ kọ́sílẹ̀ pe “àwọn ọmọ ni ìní Olúwa” (Psalm 127:3). Wo Russell M. Nelson, “Bí Ìpìlẹ Wa Ṣe Dúró Gbọingbọin,” Liahona, July 2002, 83–84; see also Dallin H. Oaks, “Òtítọ́ àti Ètò Náà,” Liahona, Nov. 2018, 27.

  22. Wo Neil L. Andersen, “Children,” Liahona, Nov. 2011, 28.

  23. Ìfìwéṣọwọ́sí Araẹni, Mar. 10, 2021.

  24. 3 Nephi 17:21, 24.

  25. “Ní òdodo, gbogbo wa jẹ́ arìnrìnàjò—àní olùwákiri ayé ikú. A kò ní èrè ìrírí araẹni tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. A gbọ́dọ̀ kọjá iṣẹsẹ̀gbé àti rírú ọmi nínú ìrìnàjò arawa nihin lórí ilẹ̀-ayé” (Thomas S. Monson, “Olùkọ́lé Bíríjì,” Liahona, Nov. 2003, 67).