Àwọn Ẹ̀kọ́ Ìpìlẹ̀ ti Ìhìnrere Mi
(Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 42:12).
Ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ìhìnrere kan jẹ́ ìtọ́ni ti ẹ̀kọ́ tí ó dá lórí fífi òdodo lo ìwà ìṣojúẹni.
Nínú ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò ti Ijọ Jésù Kristì ti Àwọn Ènìyàn Mimọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ní Oṣù Kẹwa 1849, a pe Alàgbà John Taylor ti Iyejú àwọn Àpóstélì Méjìlá lati ṣí orilẹ̀ èdè France fún wíwàásù ìhìnrere ti Jésù Krístì. Nínú iṣẹ́-ìsìn rẹ̀ ni ṣíṣe àtúnkà àkọ́kọ́ ìwé àtìgbàdégbà ti Ijọ ni orilẹ̀ èdè náà. Alàgbà Taylor pèsè ó sì ṣe àtẹ̀jade ọ̀rọ̀ kan ni 1851 ní ìfèsì sí àwọn ìbéèrè léraléra ti wọ́n ti bii nípa Ijọ. Àti pé ní ẹ̀bá òpin ọ̀rọ̀ kíkọ naà, Alàgbà Taylor ṣe ìránti ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó tẹ́lé yi:
“Ní àwọn ọdún díẹ̀ sẹ́hìn, ní Nauvoo, arákùnrin kan ti mo gbọ́ èdè rẹ̀, ọmọ Ìgbìmọ̀ Aṣòfin kan, béèrè lọ́wọ́ Joseph Smith bí ó ti ṣeéṣe fún un láti ṣe àkóso àwọn ènìyàn púpọ̀ bẹ́ẹ̀, àti láti wà ní irú ètò pípé bẹ́ẹ̀; ó sọ ní àkókò kannáà pé kò ṣeéṣe fún wọn láti ṣe bẹ́ẹ̀ ní ibikíbi míràn. Ọgbẹ́ni Smith sọ pé ó rọrùn púpọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. ‘Báwo?’ ni arákùnrin náà fésì; ‘sí wa ó jẹ́ ohun tí ó ṣòro gidigidi.’ Ọgbẹ́ni Smith dáhùn pé, ‘mo kọ́ wọn ní àwọn ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ pípé, wọ́n sì nṣe àkóso ara wọn.’”1
Mo gbàdúrà pé Ẹmí Mímọ́ yío kọ́ wa yío sì gbé ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ga bí mo ti ntẹnumọ́ ojúṣe pàtàkì ti àwọn ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ inú ìhìnrere Jesu Krístì ti a múpadàbọ̀sípò.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Ìpìlẹ̀
Oluwa fi hàn sí Wòlíì Joseph Smith pé “àwọn alàgbà, àwọn àlùfáà àti àwọn olùkọ́ni ti ìjọ yío kọ́ni ni àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ti ìhìnrere mi, àwọn èyítí ó wà nínú Bíbélì àti Ìwé ti Mọ́mọ́nì, nínú èyítí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere wà.”2 Ó kéde bákannáà pé Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn “níláti jẹ́ kíkọ́ dáradára nínú èrò orí, nínú ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́, nínú ẹ̀kọ́, nínú òfin ìhìnrere, nínú ohun gbogbo tí ó ní í ṣe sí ìjọba Ọlọ́run, tí ó ṣe dandan fún yín láti mọ̀.”3
Sísọ ní kúkúrú, ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ìhìnrere kan jẹ́ ìtọ́ni tí ó dá lórí ẹ̀kọ́ fun fífi òdodo lo ìwà ìṣojúaraẹni. Awọn ẹkọ́ ìpìlẹ̀ ni a nrí láti ara àwọn òtítọ́ ìhìnrere gbígbòrò síi, ó sì npèsè ìdarí ati àwọn òsùnwọ̀n bi a ti ntẹ̀síwájú lórí ipa ọ̀nà májẹ̀mú.
Fún àpẹrẹ, àwọn Nkan Ìgbàgbọ́ mẹ́ta àkọ́kọ́ ṣe ìdámọ̀ àwọn abala ìpìlẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ ti ìhìnrere Jésù Krístì tí a mú padàbọ̀ sípò: àdánidá Olórí-ọ̀run nínú nkan ìgbàgbọ́ kinní, àwọn àyọrísí Ìṣubú Adámù àti Éfà nínú nkan ìgbàgbọ́ kejì, àti àwọn ìbùkún tí a mú kí ó ṣeéṣe nípasẹ̀ Ètùtù ti Jésù Krístì nínú nkan ìgbàgbọ́ kẹta.4 Àti nkan ìgbàgbọ́ kẹrin ṣe àgbékalẹ̀ àwọn àwọn ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ àkọ́kọ́—àwọn ìtọ́ni ti lílo ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì àti ríronúpìwàdà—àti àwọn ìlànà àkọ́kọ́ ti oyè àlùfáà tí ó fún Ètùtù ti Jésù Krístì lágbára láti jẹ́ wíwúlò nínú ìgbé ayé wa.5
Ọ̀rọ̀ Ọgbọ́n ni àpẹrẹ míràn ti ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ kan bíi ìtọ́nsọ́nà. Ẹ jọ̀wọ́ ẹ fiyèsí àwọn ẹsẹ tí ó ṣe ìṣaájú nínú ìpín 89 ti Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú.
“Tí a ti fúnni fún ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ kan pẹ̀lú ìlérí, tí a mú bádọ́gba sí ipa ti àwọn aláìlágbára àti àwọn tí wọ́n jẹ́ aláìlágbára jùlọ nínú gbogbo àwọn ẹni mímọ́, àwọn tí wọ́n jẹ́ tàbí tí a le pè ní ẹni mímọ́.
“Kíyèsíi, lõtọ́, báyi ni Oluwa wí fún yín: Ní ìyọrísí àwọn ohun búburú àti ète èyítí ó wà àti tí yío wà nínú ọkàn àwọn ènìyàn tí wọn nditẹ̀ ní àwọn ọjọ́ tí ó kẹ́hìn, èmi ti kìlọ fún yín, mo sì kìlọ̀ fún yín ṣaájú, nípa fífún yín ní ọ̀rọ̀ ọgbọ́n yìí nípa ìfihàn.”6
Ìkọ́ni pẹ̀lú ìmísí tí ó tẹ̀lé ìfihàn yi pèsè àwọn ìtọ́ni tí ó pẹ́ títí fún ànfààní ti ara àti ti ẹ̀mí ó sì njẹ́rìí àwọn ìbùkún pàtó tí ó dá lórí ṣíṣe olódodo wa sí ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ náà.
Ikẹkọ, níní òye, àti gbígbé ìgbé ayé àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ìhìnrere nfún ìgbàgbọ́ wa nínú Olùgbàlà lókun, ó nmú ìfarasìn wa sí I jinlẹ̀ síi, ó sì npe ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ìbùkún àti ẹ̀bùn ti ẹ̀mí wá sínú ayé wa. Àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ti ìṣòdodo bákannáà nràn wá lọ́wọ́ láti wò kọjá àwọn ohun tí ó wuni jùlọ àti àwọn ìfẹ́ ìmọtara ẹni nípa pípèsè èrò orí ti òtítọ́ ayérayé bí a ti nlọ láàrin oríṣiríṣi àwọn ipò, àwọn ìpèníjà, àwọn ìpinnu, àti àwọn ìrírí ti ayé ikú.
Akẹgbẹ́ Àwọn Àpẹrẹ Kíkọ́ni ti Àwọn Ẹkọ́ Ìpìlẹ̀ Pípé
Ìsọ̀rọ̀ náà láti ẹnu Wòlíì Joseph Smith nípa kíkọ́ni ní àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ pípé ni bóyá ọ̀kan lára àwọn ìkọ́ni rẹ̀ tí a nṣe àyọsọ rẹ̀ lemọ́lemọ́ jùlọ. A sì nrí àwọn àwọn àpẹrẹ tó lágbára nípa àwòṣe ìkọ́ni onímĩsí yí nínú àwọn ìkéde ti àwọn ìránṣẹ́ tí Olúwa fún ní àṣẹ lóni.
Ìpìlẹ̀ ti Àìsí Ìdíwọ
Ààrẹ Dallin H. Oaks sọ̀rọ̀ nínú ìpàdé àpapọ gbogbogbò ní 1998 nípa àwọn ojúṣe ti àwọn olùdìmú Oyè Àlùfáà Aárónì tí ó ní í ṣe sí pípèsè àti ṣíṣe ìpínfúnni oúnjẹ Olúwa. Ó ṣe àpèjúwe ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ àìsí ìdíwọ́ ó sì fihàn pé olùdìmú Oyè Àlùfáà Aárónì kan kò ní fẹ́ rárá pé kí ohunkóhun nínú ìfarahàn tàbí ìhùwàsí rẹ̀ ó dí ọmọ Ìjọ kankan lọ́wọ́ nínú ìjọ́sìn rẹ̀ àti ìsọdọ̀tun àwọn májẹ̀mú. Ààrẹ Oaks bákannáà ṣe àtẹnumọ́ àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ti wíwà létò, ìmọ́tótó, ọ̀wọ̀, àti iyì.
Pẹ̀lú ìdùnmọ́ni, Ààrẹ Oaks kò fún àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin náà ní àtòsílẹ̀ gígùn ti àwọn ohun tí wọ́n níláti ṣe tàbí tí wọn kò níláti ṣe. Dípò bẹ́ẹ̀, ó ṣe àlàyé ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ náà pẹ̀lú ìrètí pé àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti àwọn òbí wọn àti àwọn olùkọ́ wọn le lò ìdájọ́ ti arawọn àti ìmísí láti tẹ̀lé ìtọ́nisọ́nà.
Ó ṣe àlàyé pé, “Èmi kò níi dábàá àwọn òfin ní kíníkíní, níwọ̀n ìgbà tí àwọn ipò inú oríṣiríṣi àwọn wọ́ọ̀dù àti àwọn ẹ̀ka Ìjọ àgbáyé wa yàtọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí òfin kan pàtó tí ó dàbí pé wọ́n nílò ní ibìkan le ma dára tó ní ibòmíràn. Dípò bẹ́ẹ̀, èmi ó dábàá ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ kan tí ó dá lórí àwọn ẹ̀kọ́. Bí ẹni gbogbo bá ní òye ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ yí tí wọ́n sì ṣiṣẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú rẹ̀, ìnílò kékeré ni ó yẹ kí ó wà fún àwọn òfin. Bí a bá nílò àwọn òfin tàbí ìdámọ̀ràn tí a nílò nínú olukúlùkù ọ̀ràn, àwọn olórí ibilẹ le pèsè wọn, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ẹ̀kọ́ àti àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ tí ó jẹ mọ́ wọn.”7
Ẹkọ́ Ìpìlẹ̀ ti Ọjọ́ Ìsinmi bí Àmì Kan
Nínú ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2015, Ààrẹ Russell M. Nelson kọ́wa pé “Ọjọ́ Ìsinmi jẹ́ ìgbádùn.”8 Bákannáà ó ṣe àlàyé bí òun fúnrarẹ̀ ṣe ní òye kókó ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ nípa bíbọ̀wọ̀ fún Ọjọ́ Ìsinmi:
“Báwo ni a ṣe le bọ̀wọ̀ fún Ọjọ́ Ìsinmi? Ní àwọn ọdún ti mo ṣì kéré ju báyi lọ, mo ṣe àṣàrò iṣẹ́ àwọn ẹlòmiràn tí wọ́n ti ṣe àkójọ àwọn àtòsílẹ̀ àwọn ohun tí ó le jẹ́ síṣe àti àwọn ohun tí kò le jẹ́ síṣe ní Ọjọ́ Ìsinmi. Ní ìgbẹ̀hìn gbẹ́hín ni mo kọ́ láti inú àwọn ìwé mímọ́ pé ìṣe àti ìwà mi ní Ọjọ́ Ìsinmi njẹ́ àmì kan láàrin èmi àti Baba mi Ọrun. Pẹ̀lú òye náà, èmi kò nílò àwọn àtòsílẹ̀ síi nípa ti àwọn ṣíṣe àti àwọn máṣe mọ́. Nígbàtí mo bá níláti ṣe ìpinnu kan bóyá tàbí kìí ṣe ìṣe kan tó dára tó fún Ọjọ́ Ìsinmi, mo kàn máa nbi ara mi léèrè pé, ‘Irú àmì wo ni mo fẹ́ fún Ọlọ́run?’ Ìbéèrè yi mú àwọn yíyàn mi nípa Ọjọ́ Ìsinmi mọ́lẹ̀ kedere bíi kírístà.”9
Ìbéèrè Ààrẹ Nelson tó rọrùn ṣùgbọ́n tó lágbára ṣe àtẹnumọ́ ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ kan tí ó la èyíkéyìí àìdánilójú já nípa ohun tí ó túmọ̀ sí àti ohun tí a nílati ṣe láti bọ̀wọ̀ fún Ọjọ́ Ìsinmi. Ìbéèrè rẹ̀ ṣe àkópọ̀ ìtọ́nisọ́nà àti òsùnwọ̀n kan tí ó le bùkún gbogbo wa nínú àwọn oríṣiríṣi ipò wa.
Ẹ̀kọ́ Ìpilẹ̀ ti Níní Ìfẹ́ láti Jẹ́kí Ọlọ́run Borí.
Ní oṣù mẹ́fà sẹ́hìn nínú ìpàdé àpapọ gbogbogbò, Ààrẹ Nelson ṣe àpèjúwe gbígbéga ti ara ẹni bí a ṣe darí rẹ̀ sí èrò orí titun nípa ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà Israẹ́lì Ó sọ fún wa pé ọkàn rẹ̀ yá gágá bí ó ti kọ́ pé orúkọ Ísráẹ́lì gan an tọ́ka sí ẹnìkan tì ò ní ìfẹ́ láti jẹ́ kí Ọlọ́run borí nínú ìgbé ayé ọkùnrin tàbí obìnrin.”10 Nígbànáà Ààrẹ Nelson ṣe ìdámọ̀ àwọn àyọrísí pàtàkì bíi mélo kan tí ó jẹyọ láti inú èrò yi.
Ọrọ̀ rẹ̀ nípa níní ìfẹ́ láti jẹ́ kí Ọlọ́run borí jẹ́ àpẹrẹ kan tí ó ní àmì ti kíkọ́ni ní àwọn ẹ̀kọ́ ìpilẹ pípé kí a ba le ṣe àkóso ara wa. Ati pé gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ nípa mímú kí Ọjọ́ Ìsinmi jẹ́ ìgbádùn, Ààrẹ Nelson ju àwọn ìbéèrè kan tí ó dá lórí ẹ̀kọ́ ìpilẹ tí wọ́n le ṣiṣẹ́ bíi ìtọ́ni àti òsùnwọ̀n fún ẹnikọ̀kan wa.
“Njẹ́ ẹ fẹ́ láti jẹ́kí Ọlọ́run borí nínú ayé yín? Njẹ́ ẹ fẹ́ láti jẹ́kí Ọlọ́run jẹ́ agbára pàtàkì jùlọ nínú ayé rẹ?”
Ó tẹ̀síwájú:
“Ẹ ronú bí irú ìfẹ́ náà ti lè bùkún yín. Bí ẹ kò bá tíì ṣe ìgbeyàwó tí ẹ sì nwá ojúgbà ayérayé kan, ìfẹ́-inú yín láti jẹ́ ‘ti Ísráẹ́lì’ yíò ràn yín lọ́wọ́ láti pinnu ẹnití ẹ̀yin ó bá dọrẹ àti báwo.
“Bí ẹ bá ti ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú ojúgbà kan tí ẹ ti já àwọn májẹ̀mú yín lọ́kùnrin tàbí lóbìnrin, ìfẹ́ inú yín láti jẹ́kí Ọlọ́run borí nínú ayé yín yíò fi àyè gbà kí àwọn májẹ̀mú yín pẹ̀lú Ọlọ́run wà ní pípé. Olùgbàlà yíò wo ọkàn ìròbìnújẹ́ yín sàn. Àwọn ọ̀run yíò ṣí bí ẹ ti nwá láti mọ̀ bí ẹ ó ti tẹ̀síwájú. Ẹ kò nílò láti rìnkiri tàbí ní ìyàlẹ́nu.
“Bí ẹ bá ní àwọn ìbèère tõtọ́ nípa ìhìnrere tàbí Ìjọ, bí ẹ ti nyàn láti jẹ́kí Ọlọ́run borí, a ó darí yín láti rí àti láti ní ìmọ̀ àwọn òtítọ́ pípé àti ti ayérayé náà, tí yíò tọ́ ìgbé ayé yin sọ́nà tí yío sì ràn yin lọ́wọ́ láti dúró gbọingbọin ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú.
“Nígbàtí ìdánwò bá ìdojúkọ yín—àní bí ìdánwò náà bá wá nígbàtí ó ti rẹ̀ yín tàbí tí ẹ ní ìmọ̀làra ànìkan wà tàbí àṣìgbọ́—ẹ fi ojú inú wo ìgbòya tí ẹ lè ní bí ẹ ti nyàn láti jẹ́ kí Ọlọ́run borí nínú ayé yín bí ẹ ti mbẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú Rẹ̀ láti fún yín lókun.
“Nígbàtí ìfẹ́ inú yín títóbi jùlọ bá jẹ́ láti jẹ́kí Ọlọ́run borí, láti jẹ́ ara Ísráẹ́lì, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìpinnu á di ìrọrùn síi. Nítorínáà ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀ràn di àìsí-ọ̀ràn! Ẹ mọ̀ bí ẹ ṣe lè tún ara yín ṣe dáradára jùlọ̀. Ẹ mọ ohun tí ẹ ó wò àti tí ẹ ó kà, ibi tí ẹ ó ti lo àkokò, àti pẹ̀lú ẹnití ẹ ó darapọ̀ mọ́. Ẹ mọ ohun tí ẹ fẹ́ láti ṣe àṣeyege. Ẹ ó mọ irú ẹni tí ẹ fẹ́ gan láti dà ní tòótọ́.”11
Ẹ kíyèsí iye àwọn ìpinnu pàtàkì àti àwọn ìrírí ìgbé ayé tí ó le jẹ́ fifọwọ́bà nípa ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ ti níní ifẹ́ láti jẹ́ kí Ọlọ́run boríìbádọ́rẹ àti ìgbeyàwó, àwọn ìbéèrè àti àwọn àníyàn ìhìnrere, àìdánwò, ìtúnraṣe ti ara ẹni, ohun tí a le wò àti tí a le kà, ibi tí a ó ti lo àkokò, pẹ̀lú ẹnití a lè bárìn, àti púpọ̀, púpọ̀ síi. Àwọn ìbéèrè onímisí Ààrẹ Nelson tẹnumọ́ ẹ̀kọ́ ìpilẹ̀ ìrọrùn kan tí ó npèsè ìdarí ní gbogbo abala àwọn ìgbé ayé wa tí ó sì nfúnwa lágbára láti ṣe àkóso ara wa.
“Ìwakọ̀ Kan Kíkéré Gan
Nígbàtí wọ́n fi Joseph Smith sí àhámọ́ ní Ọgbà Ẹwọ̀n Liberty, ó kọ àwọn ìwé ìkọ́ni sí àwọn ọmọ Ìjọ àti àwọn olórí ó sì rán wọn létí pé “ọkọ̀ ojú omi nlá gidigidi kan nrí ànfàní púpọ̀ nípasẹ̀ ìwakọ̀ tí ó kéré gidi ní àkókò ìjì, nípa fífi sí àwọn ojú ọ̀nà pẹ̀lú afẹ́fẹ́ àti àwọn ìgbì omi.”12
“Ìwakọ̀” kan jẹ́ síárìn tàbí tílà àti irinṣẹ́ tí ó jẹmọ́ èyí tí a nlò láti wa ọkọ̀ ojú omi nlá tàbí kékeré. Àti pé “ojú ọ̀nà pẹ̀lú afẹ́fẹ́ àti àwọn ìgbì omi” ntọ́ka sí yíyí ọkọ̀ ojú omi kan kí ó le mú dúró kí ó má bàá dojúdé ní àkókò ìjì.
Àwọn ìpilẹ̀ ẹ̀kọ́ ìhìnrere jẹ́ fún ẹ̀yin àti èmi bí ìwakọ̀ ti jẹ́ sí ọkọ̀ ojú omi kan. Àwọn ẹ̀kọ́ ìpilẹ̀ pípé nfún wa ní agbára láti rí ọ̀nà wa àti láti dúró gbọingbọin, ṣinṣin, àti ní àìyẹsẹ̀ kí a má baà sọ ìdúró wa nù kí a sì ṣubú nínú àwọn ìjì jíjà ọjọ́-ìkẹhìn ti òkùnkùn àti ìdààmú.
A ti bùkún wa lọ́pọ̀lọpọ̀ nínú ìpàdé àpapọ gbogbogbò yi láti kọ́ ẹ̀kọ́ nípa àwọn ẹ̀kọ́ ìpilẹ̀ ayérayé láti ọ̀dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ tí Olúwa fún ní àṣẹ. Nísisìyí, ojúṣe ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ni láti ṣe àkóso ara wa ní ìbámu sí àwọn òtítọ́ nípa èyí tí wọ́n ti jẹ́rí.13
Ẹrí
Ààrẹ Ezra Taft Benson kọ́ni pé, “Fún oṣù mẹ́fà tí ó nbọ̀, ẹ̀dà àpéjọ rẹ ti [Liàhónà] yẹ kí ó dúró tẹ̀lé àwọn òṣùwọ̀n iṣẹ́ rere yín kí ẹ sì máa tọ́ka síi nígbàgbogbo.”14
Pẹ̀lú gbogbo agbára ẹmí mi, mo pe gbogbo wa láti kọ́, gbé ìgbé ayé, kí a sì fẹ́ràn àwọn ẹ̀kọ́ ìpilẹ̀ ti òdodo. Àwọn òtítọ́ ìhìnrere nìkan ní ó le mú kí ó ṣeéṣe fúnwa láti “fi ọ̀yàyà ṣe ohun gbogbo tí ó wà ní agbára wa” láti tẹ̀síwájú ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú àti láti “rí ìgbàlà Ọlọ́run, àti láti mú kí apá rẹ̀ ó di fífihàn.”15
Mo mọ̀ pé àwọn ẹ̀kọ́ àti àwọn ẹ̀kọ́ ìpilẹ̀ ti ìhìnrere ti Jésù Krístì jẹ́ ìgbẹ̀hìn àti orísun ìdarí kanṣoṣo fún ìgbé ayé wa àti ti ayọ̀ pípẹ́ títí ní ayé kíkú àti ayérayé. Àti ní Ọjọ́-ìsinmi Àjínde ológo yí, mo sì fi tayọ̀tayọ̀ jẹ́rìí pé Olùgbàlà wa tí ó wà láàyè ni ìsun ibití àwọn òtítọ́ wọ̀nyí ti nṣàn wá. Ní mo jẹ́ ẹ̀rí bẹ́ẹ̀ ní orúkọ mímọ́ ti Olúwa Jésù Krístì, àmín.