Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
“Kíyèsi! Èmi ni Ọlọ́run Ìyanu
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2021


“Kíyèsi! Èmi ni Ọlọ́run Ìyanu

Àwọn iṣẹ́ ìyanu, àmìn, àti àrà wà káàkiri ní àárín àwọn ọmọlẹ́hìn Jésù Krístì loni, nínú ayé yín àti tèmi.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, o jẹ́ ànfàní láti dúró níwájù yín loni. Ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹni tí wọ́n ti bá wa sọ̀rọ tẹ́lẹ̀ ní ìpàdé àpapọ̀ yí, mo jẹ́ri sí yín pé Jésù wà láàyè. Ó ndarí Ìjọ Rẹ̀, Ó nsọ̀rọ sí wòlíì Rẹ̀, Ààrẹ Russell M. Nelson, ó sì nifẹ gbogbo àwọn ọmọ Baba Ọ̀run.

Ní Ọjọ́-ìsinmi Ọdún-àjínde yí a nṣe àjọyọ̀ Àjínde Jésù Krístì, Olùgbàlà àti Olùràpadà wa,1 Ọlọ́run Alágbára, Ọba-aládé Àláfíà.2 Ètùtù Rẹ̀, tí ó parí pẹ̀lú Àjínde Rẹ̀ lẹ́hìn ọjọ́ mẹ́ta nínú ibojì kan tí a yá, dúró bí iṣẹ́ ìyanu nlá jùlọ nínú ìtàn ènìyàn. “Nítorínáà kíyèsi,” Ó kéde pé, “Èmi ni Ọlọ́run; àti pé èmi ni Ọlọ́run ìyanu.”3

“Njẹ́ iṣẹ́ ìyanu ha dópin nítorí Krísti ti gòkè lọ sí ọ̀run, àti tí ó sì ti joko ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run?”4 wòlíì Mọ́mọ́nì bèèrè nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Ó dáhùn, “Rárá, bẹ̃ni àwọn ángẹ́lì kò dáwọ́dúró nínú iṣẹ ìránṣẹ́ ṣíṣe fún àwọn ọmọ ènìyan.”5

Títẹ̀lé kíkànmọ́-àgbélèbú, ángẹ́lì Olúwa kan farahan sí Màríà àti àwọn obìnrin míràn díẹ̀, ti wọ́n ti lọ sí ibojì láti fi àmì òróró yan ara Jésù. Ángẹ́lì náà wípé:

“Èéṣe tí ẹ̀nyín fi ńwá alààyè láárín àwọn òkú?”6

“Kò si níhĩn, nítorí ó ti jíìnde.”7

Ábínádì wòlíì Ìwé ti Mọ́mọ́nì kéde nípa iṣẹ́-ìyanu náà.

“Tí Krístì ko bá jínde kúrò nínú òkú, … kì bá ti sí àjínde.

“Ṣùgbọ́n àjĩnde wà, nítorínã ìsà-òkú kò ní ìṣẹ́gun, oró ikú sì jẹ́ gbígbémì nínú Krístì.”8

Àwọn ìṣe ìyanilẹ́nu ti Jesù Krístì mú kí àwọn ọmọẹ̀hìn ìṣaájú kígbé: “Irú ọkùnrin wo ni èyí! nítorí ó bá ẹfúùfù àti ríru òmi wí, wọ́n sì gbọ́ tirẹ̀.”9

Bí àwọn Àpóstélì ìsáájú ṣe tẹ̀lé Jesù Krístì tí wọ́n sì gbọ́ Ọ́ tí ó nkọ́ ìhìnrere, wọ́n jẹ́ri ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn iṣẹ́ ìyanu. Wọ́n rí “àwọn afọ́jú nríran, àwọn amukun sì nrìn, à nwẹ àwọn adẹ́tẹ̀ mọ́, awọn adití ngbọ́ran, à njí àwọn òkú dide, a sì nwàásù ìhìnrere sí àwọn otòṣì.”10

Àwọn iṣẹ́ ìyanu, àmìn, àti àrà wà káàkiri ní àárín àwọn ọmọlẹ́hìn Jésù Krístì loni, nínú ayé yín àti tèmi. Àwọn iṣẹ́-ìyanu jẹ́ àwọn ìṣe àtọ̀runwá, àwọn ìfihàn àti àwọn ọ̀rọ̀ ti agbára àìnípẹ̀kun Ọlọ́run àti ìjẹ́risí kan pé Òun wà “bákannáà lana, loni, àti láéláé.”11 Jésù Krístì, ẹnití ó dá òkun, lè mú wọn dákẹ́rọ́rọ́; Ẹnití ó mú afojú ríran lè gbé àwọn ojú wa sí ọ̀run; Ẹnití ó wẹ adẹ́tẹ̀ mọ́ lè tún àwọn àìlera wa ṣe; Ẹnití ó wo ọkùnrin alárùn sàn lè pè wá láti dìde pẹ̀lú “Wá, tẹ̀lé mi.”12

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ lára yín ti jẹ́ri àwọn iṣẹ́ ìyanu, ju bí ẹ ṣe damọ̀. Wọ́n lè dàbí kékeré ní àfiwé sí Jésù tó njí òkú dìde. Ṣùgbọ́n títóbi náà kò mú ìyàtọ̀ iṣẹ́ ìyanu wá, ó wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nìkan ni. Àwọn kan daba pé àwọn iṣẹ́ ìyanu ni àmúwá jẹ́jẹ́ tàbí oríre lásán. Ṣùgbọ́n wòlíì Néfì dá àwọn tí yíò “rẹ agbára àti iṣẹ́ ìyanu Ọlọ́run sílẹ̀ lẹ́bi, tí wọ́n sì wàásù sírawọn nípa ọgbọ́n ara wọn àti ikẹkọ, kí wọ́n le gba èrè .”13

Àwọn iṣẹ́ ìyanu ni à nṣe nípasẹ̀ agbára tọ̀run nípasẹ̀ Rẹ̀ ẹnití ó “tóbi láti gbàlà.”14 Àwọn iṣẹ́ ìyanu ni ìtànká ètò ayérayé Ọlọ́run; iṣẹ́ ìyanu ni ìlà-ìyè láti ọ̀run wá sí ayé.

Ní ìgbà-ọ̀gbẹlẹ̀ tó kọjá Arábìnrin Rasband àti èmi wà ní ọ̀nà wa lọ sí Goshen, Utah, fún ìṣẹ̀lẹ̀ gbogbo ayé Ojú Kojú tí à tan káàkiri sí àwọn ènìyàn tó ju ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ lọ ní èdè oríṣiríṣi mẹ́rìndínlógún mẹ́rìndínlógún.16 Ètò náà ni láti dojúkọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ Ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Jésù Krístì pẹ̀lú àwọn ìbèèrè tí a fi ṣọwọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀dọ́ àgbà káàkiri àgbáyé. Arábìnrin Rasband àti èmi ṣe àyẹ̀wò àwọn ìbèèrè náà fún arawa; wọ́n fún wa ni ànfàní láti jẹ́ri nìpa Joseph Smith bí wolíì Ọlọ́run, agbára ìfìhàn nínú ayé wa, Ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Jésù Krístì tí ó nlọ lọ́wọ́, àti àwọn òtítọ́ àti òfin tí a fẹ́ràn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí wọ́n nfetísílẹ̀ loni jẹ́ ara ìṣẹ̀lẹ̀ oníyanú náà.

Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ ìtànkiri náà yẹ kó bẹ̀rẹ láti Igbó Ṣúúrú Mímọ́ ní ìhà òkè-nlá New York, níbití Joseph Smith ti jẹ́ri pé: “Mo rí àwọn ènìyàn méjì, tí ìmọ́lẹ̀ àti ògo wọn tó kọjá gbogbo ìjúwe, wọ́n dúró lórí mi nínú afẹ́fẹ́. Ọ̀kàn lára wọn sọ̀rọ̀ sí mi, ó pè mí ní orúkọ ó nawọ́ sí ẹnìkejì, ó wípé—Èyí ni Àyànfẹ́ Ọmọ Mi. Gbọ́ Tirẹ̀!16 Ìyẹn, ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi, ni iṣẹ́ ìyanu kan.

Jerusalem ni a gbékalẹ̀ ní Goshen, Utah

Àjàkálẹ̀-àrùn àgbáyé mú wa nípá láti gbé ìtànkiri lọ sí Goshen, Utah, níbití Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹ̀hìn ti tún-dásílẹ̀, fún yíyà fíìmù, ìpín kan lára Jérúsálẹ́mù àtijọ́. Arábìnrin Rasband àti èmi wà ní àárín àwọn máìlì díẹ̀ ti Goshen ní ìrọ̀lẹ́ Ọjọ́-ìsinmi náà nígbàtí a rí eéfín tó nípọn tó nwá láti ibi tí à nlọ. Iná-líle njó ní agbègbè náà, a sì dààmú bóyá ìtàn káàkiri náà lè wà nínú ewu. Dájúdájú tó, ní ogún ìṣẹ́jú sí aago mẹ́fà, ìtànkiri ní àkokò wa, iná ní gbogbo àyíká náà kú. Kò sí iná rárá! Kò sí ìtàn káàkiri. Ẹ̀rọ amúnáwá kan wà tí àwọn kan rò pé a lè fi mú iná jáde, ṣùgbọ́n kò sí ìdánilójú pé ó lè gbé ohun èlò ìgbàlódé tó wà lárọwọ́tó.

Èéfín látinú iná

Gbogbo wa níbi ètò náà, pẹ̀lú olùsọ̀rọ̀, olórin, àti oníṣẹ́ ẹ̀rọ—àní àwọn ogún ọ̀dọ́ àgbà látinú ẹbí gbígbòòrò ara mi—ni wọ́n fọwọ́sí ohun tí a fẹ́ ṣe ní kíkún. Mo jáde kúrò nínú omijé àtì ìdàmú wọn mo sì bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú Olúwa fún iṣẹ́ ìyanu kan. “Baba Ọ̀run,” mo gbàdúrà, “Èmi kìí sáábà bèèrè fún iṣẹ́-ìyanu kan, ṣùgbọ́n mò nbèèrè fún ọ̀kan nísisiyí. Ìpàdé yí gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ fún gbogbo àwọn ọ̀dọ́ àgbà wa káàkiri àgbáyé. A nílò iná láti tẹ̀síwájú tí ó bá jẹ́ ìfẹ́ yín.”

Ìṣẹ́jú méje lẹ́hìn aago mẹ́fà, bí iná ṣe lọ kíákíá, ó padà wá. Ohun gbogbo bẹ̀rẹ̀ sí nṣiṣẹ́, láti orin sí gbohùngbohùn sí àwọn fídíò àti gbogbo ohun èlò àgbéká. A sì nsáré ká. A ní ìrírí iṣẹ́-ìyanu kan.

Ìṣeré orin kíkọ nígbà ìṣẹ̀lẹ̀ Ojúkojú

Bí Arábìnrin Rasband àti èmi ti wà nínú ọkọ̀ tí a npadà sílé lẹ́hìnnáà ní ìrọ̀lẹ́, Ààrẹ àti Arábìnrin Nelson fi àtẹ̀jíṣẹ́ ránṣẹ́ síwa pẹ̀lú ọ̀rọ̀ yí: “Ron, a fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé ní kété tí a gbọ́ nípa iná tó kú, a gbàdúrà fún iṣẹ́-ìyànu kan.”

Nínú ìwé mímọ́ ọjọ́-ìkẹhìn a kọ pé: “Nítorí Èmi, Olúwa, ti na ọwọ́ mi síwájú láti lo àwọn agbára ọ̀run; ẹ̀yin kò lè ri nísisìyí, síbẹ̀ ní àìpẹ́ ẹ̀yin yíò sì ri i, ẹ ó sì mọ̀ pé èmi ni, àti pé èmi yíò wá láti jọba pẹ̀lú àwọn ènìyàn mi.”18

Ìyẹn ni déédé ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Olúwa ti na ọwọ́ rẹ̀ síwájú, iná náà sì wá.

Àwọn iṣẹ́ ìyanu ni à nṣe nípa agbára ìgbàgbọ́, bí Ààrẹ Nelson kọ́ wa pẹ̀lú agbára ní abala tó kẹ́hìn. Wòlíì Mórónì gba àwọn ènìyàn níyànjú, “Bí kò básí ìgbàgbọ́ lãrín àwọn ọmọ ènìyàn Ọlọ́run kò lè ṣe iṣẹ́ ìyanu lãrín wọn; nítorínã, òun kò fi ara rẹ̀ hàn àfi ní ẹ́hìn ìgbàgbọ́ wọn.”

Ó tẹ̀síwájú:

“Ẹ kíyèsĩ, ìgbàgbọ́ Álmà àti Ámúlẹ́kì ní ó mú kí tũbú wo lulẹ̀.

“Ẹ kíyèsĩ, ìgbàgbọ́ Néfì àti Léhì ní ó mú kí ìyípadà wá sórí àwọn ara Lámánì, tí a fi ṣe ìrìbọmi wọn pẹ̀lú iná àti pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́.

“Ẹ kíyèsĩ, ìgbàgbọ́ Ámọ́nì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ ni ó mú kí a ṣe iṣẹ́ ìyanu nla lãrín àwọn ará Lámánì. …

“Kò sì sí ìgbà kan tí ẹnikẹ́ni ti ṣe iṣẹ́ ìyanu àfi ní ẹ́hìn ìgbàgbọ́ wọn; nítorí èyí wọ́n kọ́kọ́ gbàgbọ́ nínú Ọmọ Ọlọ́run.”21

Mo lè fikun pé ẹ̀yà àwọn ìwé mímọ́ náà, “Ìgbàgbọ́ àwọn òṣèré ọ̀dọ́ àgbà onítara, amòye ìtànkiri, olórí Ìjọ àti ọmọ ìjọ, àpóstélì kan, àti wòlíì Ọlọ́run ti wá iṣẹ́ ìyanu nlá gidi tí iná fi dé síbi ọ̀nà-jíjìn ìgbékalẹ̀ fíìmù ní Goshen, Utah.”

Àwọn iṣẹ́ ìyanu lè wá bí ìdáhùn sí àdúrà. Wọn kìí ṣe ohun tí a bèèrè fún tàbí ohun tí a nretí nígbàgbogbo, ṣùgbọ́n nígbàtí a bá ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa, Òun yíò wà níbẹ̀, Òun yíò jẹ́ òtítọ́. Òun yíò ṣe iṣẹ́ ìyanu ní àkoko ìbámu tí a nílò rẹ̀.

Olúwa nṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu láti rán wá létí nípa agbára Rẹ̀, ìfẹ́ Rẹ̀ fún wa, ìnawọ́ Rẹ̀ láti ọ̀run sí ìrírí ayé ikú wa, àti ìfẹ́ Rẹ̀ láti kọ́ nípa èyí ni ohun títọ́ jùlọ. “Ẹnití ó ní ìgbàgbọ́ nínú mi láti rí ìwòsàn,” Ó wí fún àwọn Ènìyàn Mímọ́ ni1831, ìlérí náà tẹ̀síwájú loni, “tí kìí ṣe sí ikú, yíò ní ìwòsàn.”22 A ti ṣe àwọn òfin ní ọ̀run, a sì wà lábẹ́ wọn nígbàgbogbo.

Àwọn ìgbà míràn wà tí a ní ìrètí fún iṣẹ́ ìyanu láti wo àwọn olólùfẹ́ kan sàn, láti yí ìṣe àìdára padà, tàbí mú ọkàn ìkorò tàbí ẹ̀mí yẹpẹrẹ rọ̀. Wíwo àwọn ohun nínú ojú ayé ikú, a fẹ́ kí Olúwa dási, láti de ohun tó já. Nípa ìgbàgbọ́, iṣẹ́ ìyanu yíò wá, bíótilẹ̀jẹ́pé kò ṣe pàtàkì lórí tábìlì-àkokò wa tàbí pẹ̀lú ìpinnu tí a fẹ́. Ṣé ìyẹn túmọ̀ sí pé a kéré sí olótítọ́ tàbí a kò tọ́sí ìdáhùnsí Rẹ̀ bí? Rárá. A jẹ́ olólùfẹ́ ti Olúwa. Ó fi ayé Rẹ̀ fún wa, Ètùtù Rẹ̀ tẹ̀síwájú láti dá wa sílẹ̀ látinú àwọn àjàgà àti ẹ̀ṣẹ̀ bí a ti nronúpìwàdà tí a sì nsúnmọ Ọ si.

Olúwa ti rán wa létí, “Bẹ́ẹ̀ni ọ̀nà yín kìí ṣe ọ̀nà mi.”23 Ó wí fúnni, “Wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí nṣiṣẹ́ tí a di ẹrù wúwo lé, èmi ó sì fi ìsìnmi fún ọkàn yín”21—ìsinmi kúrò nínú ìdàmú, ìjákulẹ̀, ẹ̀rù, àìgbọ́ran, àníyàn fún àwọn olólùfẹ́, fún àwọn àlá jíjá tàbí tó sọnù. Àláfíà ní àárín ìrúkèrúdò tàbí ìkorò ni iṣẹ́ ìyanu kan. Rántí àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa: “Njẹ́ èmi ko ha sọ̀rọ̀ àláfíà sí ọkàn yín nípa ọ̀ràn náà? Irú ẹ̀rí nlá wo ni ẹ lè ní ju látọ̀dọ̀ Ọlọ́run?”25 Iṣẹ́ ìyanu ni pé Jésù Krístì, Jèhófà Nlá, Ọmọ ti Ọ̀gá-ògo, nfèsì pẹ̀lú àláfíà.

Gẹ́gẹ́bí Òun ti farahàn sí Màríà nínú ọgbà, pípè é ní orúkọ rẹ̀, Ó pè wá láti lo ìgbàgbọ́ wa. Màríà nwo láti sìn Í àti láti tọ́jú Rẹ̀. Àjínde Rẹ̀ kìí ṣe ohun tí ó nretí, ṣùgbọ́n ó jẹ́ gẹ́gẹ́bí ti ètò nlá ìdùnnú.

“Ó wá láti orí àgbélèbú,”26 àwọn èrò aláìgbàgbọ́ fi Í ṣe ẹlẹ́yà ní Kálfárì. Ó lè ti ṣe irú ìṣẹ́ ìyanu kan. Ṣùgbọ́n Ó mọ òpin láti ìbẹ̀rẹ̀, ó sì lérò láti jẹ́ olótítọ́ sí ètò Baba Rẹ̀. Àpẹrẹ náà kò gbọ́dọ̀ sọnù lórí wa.

Sí wa ní àwọn ìgbà àdánwò Ó wípé, “Kíyèsí àwọn àpá èyí tí ó wọ̀ ẹ̀gbẹ́ mi, àti bákannáà àwọn ojú ìṣó tí ó wà ní ọwọ́ àti ẹsẹ̀ mi; jẹ́ olõtọ́, pa àwọn òfin mi mọ́, ìwọ ó sì jogún ìjọba ọ̀run”14 Ìyẹn, ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, ni ìlérí iṣẹ́ ìyanu sí gbogbo wa.

Ní Ọjọ́-ìsinmi Ọdún-àjínde yí tí a nṣe àjọyọ̀ iṣẹ́-ìyanu Àjínde Olúwa wa, bí Àpóstélì Jésù Krístì kan mo gbàdúrà pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ pé kí ẹ ó ní ìmọ̀lára agbára Olùràpadà nínú ayé yín, kí ẹ lè gba ìdáhùn sí àwọn ẹ̀bẹ̀ yín sí Baba wa Ọ̀run pẹ̀lú ìfẹ́ àti ìfarajìn tí Jésù Krístì júwe ní gbogbo iṣẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀. Mo gbàdúrà pé kí ẹ lè dúró ṣinṣin àti tòótọ́ nínú gbogbo ohun tí ó nbọ̀. Mo bùkún yín pé ki àwọn iṣẹ́ ìyanu wà pẹ̀lú yín bí a ṣe ní ìrírí ni Goshen—tí ó bá jẹ́ ìfẹ́ Olúwa. Ẹ wá àwọn ìbùkún àránwá-tọ̀run wọ̀nyí nínú ayé yín bí ẹ ti “nwá Jésù yĩ kiri nípa ẹniti àwọn wòlĩ àti àwọn àpóstélì ti kọ, pé kí õre ọ̀fẹ́ Ọlọ́run Baba, àti pẹ̀lú Jésù Krístì Olúwa, àti Ẹ̀mí Mímọ́, èyí ti ó njẹ́rĩ sí wọn, lè bá yín gbé títí láé.”28 Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.