Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Àwọn Bíṣọ́ọ̀pù—Àwọn olùṣọ́-àgùtàn lórí Agbo Olúwa
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2021


Àwọn Bíṣọ́ọ̀pù—Àwọn olùṣọ́-àgùtàn lórí Agbo Olúwa

Bísọ́ọpù ní ojúṣe ìṣaájú ní sìsìn bí olùṣọ́-àgùtàn láti tọ́ ìran tó ndìde sọ́nà sọ́dọ̀ Jésù Krístì.

Ẹ̀yin Arákunrin mi oyè-àlùfáà ọ̀wọ́n, ọ̀kan lára àwọn ìlà olùrántí jùlọ nínú orin kan tí a fẹ́ràn-púpọ̀ bèèrè, “Ṣé àwọn ọ̀dọ́ ti Síónì yíò kọsẹ̀?”1 Ìkéde àtúnsọ àti àtinúwá mi ní ìdáhùn sí ìbèèrè náà ni “Rárá!”

Láti mu dájú pé ìdáhùn náà jẹ́ òtítọ́, mo jẹ́ri loni pé títi àwọn ìran tó ndìde lẹ́hìn ní àkokò àwọn ípènijà àìdájú àti àdánwò ni ojúṣe pàtàkì kan tí a fún àwọn òbí àti bísọ́príkì láti ọ̀dọ̀ Baba Ọ̀run.2 Ẹ jẹ́ kí èmi júwe pàtàkì bíṣọ́príkì pẹ̀lú ìrírí ti araẹni kan.

Nígbàtí mo jẹ́ díákónì, ẹbí mi kó lọ sí ilé titun ní wọ́ọ̀dù ọ̀tọ̀. Mo nbẹ̀rẹ̀ ilé-ìwé gíga kékeré, nítorínáà mo lọ sí ilé-ìwé titun kan. Àwọn ẹgbẹ́ ọ̀dọ́mọkùnrin ìyanu kan wà nínú iyejú àwọn díákónì. Púpọ̀jù lára àwọn òbí wọn jẹ́ ọmọ ìjọ tí ó nwá déédé. Ìyá mi máa nwá déédé gan; baba mi tayọ ní gbogbo ọ̀nà ṣùgbọ́n kìí ṣe ọmọ ìjọ tó nwá déédé.

Olùdámọ̀ràn ìkejì nínú bìṣọ́príkì,3 Arákùnrin Dean Eyre, jẹ́ olùfọkànsìn olórí. Nígbàtí mo ṣì nṣe àtùnṣe sí wọ́ọ̀dù titun, ìṣẹ̀lẹ̀ baba-ọmọ kan ni a kéde fún Òkun Bear—nípa ogójì máìlì (kílómítà 65) jìnnà. Èmi kò rò pé èmi ó lọ láìsí baba mi. Ṣùgbọ́n Arákùnrin Eyre fi ìfipè pàtàkì ṣọ́wọ́ sí mi láti lọ pẹ̀lú rẹ̀. Ó sọ̀rọ̀ dáradára àti pẹ̀lú ọ̀wọ̀ nípa baba mi ó sì tẹnumọ́ lílámì ànfàní mi láti wà pẹ̀lú àwọn ọmọ iyejú ẹgbẹ́ díákónì míràn. Nítorínáà mo pinnu láti lọ pẹ̀lú Arákùnrin Eyre, mo sì ní ìrírí alárà.

Arákùnrin Eyre ni àpẹrẹ ìyanilẹ́nu ti ìfẹ́ bíi Krístì ní mímú ojúṣe bìṣọ́príkì ṣẹ láti ti àwọn òbí lẹ́hìn ní títọ́jú àti ṣíṣe ìkẹ́ àwọn ọ̀dọ́. Ó fún mi ní ìbẹ̀rẹ̀ títayọ nínú wọ́ọ̀dù titun yí ó sì jẹ́ olùtọ́júẹni sí mi.

Àwọn oṣù díẹ̀ ṣíwájú kí ntó kúrò fún míṣọ̀n kan ní 1960, Arákùnrin Eyre kú látinú àrùn jẹ́jẹrẹ ní ọjọ́-orí ọdún mọ́kàndínlógójì. Ó fi ìyàwó kan àti ọmọ marun sílẹ̀, gbogbo wọ́n kéré ju ọjọ́ orí mẹ́rìndínlógún. Àwọn ọmọkùnrin mi tó dàgbà jùlọ, Richard àti Chris Eyre, fi dá mi lójú pé láìsí baba wọn, bìṣọ́príkì ti wọ́n lẹ́hìn wọ́n sì ntọ́jú wọn àti àwọn arákùnrin àti arábìnrin wọn kékeré pẹ̀lú ìfẹ́ bíi ti Krístì, ní èyí tí mo dúpẹ́ fún.

Àwọn òbí yíò ní ojúṣe pàtó fún ẹbí wọn nígbàgbogbo.4 Àwọn àjọ ààrẹ iyejú bákannáà pèsè àtìlẹhìn pàtàkì àti ìtọnisọ́nà sí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ iyejú nípa títì wọ́n lẹ́hìn ní gbígbé àwọn ojúṣe wọn àti agbára ti Oyè-àlùfáà Árónì ga sí gbùngun ìgbé ayé wọn.5

Olùṣọ́-àgùtàn pẹ̀lú àgùtàn

Ní òní èrèdí mi ni láti dojúkọ àwọn bíṣọ́ọ̀pù àti àwọn olùdámọ̀ràn wọn, tí wọ́n lè fì ìbádọ́gba pè ní “olùsọ́-àgùtàn lórí agbo olúwa”—pẹ̀lú àtẹnumọ́ lórí jíjẹ́ olùṣọ́-àgùtàn fún ìran tó ndìde.6 Ó dùnmọ́ni pé Àpostélì Peter tọ́ka sí Jésù Krístì bí “Olùṣọ́-àgùtàn àti Bíṣọ́ọ̀pù ẹ̀mí yín.”7

Bíṣọ́ọ̀pù ní àwọn kókó ojúṣe marun ní ìṣàkóso lórí wọ́ọ̀dù kan:

  1. Òun ni àlùfáà alakoso gíga ní wọ́ọ̀dù.8

  2. Òun ni ààrẹ Oyè-àlùfáà Árọ́nì.9

  3. Òun ni adájọ́ wíwọ́pọ̀.10

  4. Ó nfojúsí iṣẹ́ ìgbàlà àti ìgbéga, pẹ̀lú ìtọ́jú fún àwọn tí ó wà nínú àìní.11

  5. Ó sì nbojútó àwọn àkọsílẹ̀, ìnáwó, àti lílò àwọn ilé-ìjọsìn.12

Nínú ojúṣe rẹ̀ bí àlùfáà alakoso gíga, bíṣọ́ọ̀pù ni “olórí ti-ẹ̀mí wọ́ọ̀dù.”13 Òun ni ọmọẹ̀hìn tòótọ́ Jésù Krístì.”14

Ní àfikún, “bíṣọ́ọ̀pù nfètòsí iṣẹ́ ìgbàlà àti ìgbéga nínú wọ́ọ̀dù.”15 Bíṣọ́ọ̀pù níláti yan ojúṣe ọjọ́ sí ọjọ́ fún pípín ìhìnrere, fífún àwọn ọmọ ìjọ titun àti ìpadàbọ̀ lókun, ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́, àti iṣẹ́ tẹ́mpìlì àti àkọọ̀lẹ̀-ìtàn ẹbí sí àwọn alàgbà iyejú àti Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́.16 Bíṣọ́ọ̀pù nfètòsí iṣẹ́ yí nínú ìgbìmọ̀ wọ́ọ̀dù àti ìgbìmọ̀ ọ̀dọ́.

Bísọ́ọpù ní ojúṣe ìṣaájú ní sìsìn bí olùṣọ́-àgùtàn láti tọ́ ìran tó ndìde sọ́nà, pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́ àgbà àdánìkanwà, sọ́dọ̀ Jésù Krístì.17 Ààrẹ Russell M. Nelson ti tẹnumọ́ ojúṣe àtilẹ̀wá ti bíṣọ́ọ̀pù àti àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀. Ojúṣe rẹ àkọ́kọ́ àti ìṣaájú ni láti tọ́jú àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin ní wọ́ọ̀dù [wọn].”18 Bìsọ́príkì nti àwọn òbí lẹ́hìn ní títọ́jú àti ṣíṣe ìkẹ́ àwọn ọmọdé àti ọ̀dọ́ nínú wọ́ọ̀dù. Bíṣọ́ọ̀pù àti ààrẹ àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin ndámọ̀ràn papọ̀. Wọ́n ntiraka láti ran àwọn ọ̀dọ́ lọ̀wọ́ láti gbé àwọn òdiwọ̀n inú Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́, yege láti gba àwọn ìlànà, àti láti ṣe àti láti pa àwọn májẹ̀mú mímọ́ mọ́.

Ẹ lè bèèrè, “Kínìdí tí a fi darí bíṣọ́ọ̀pù láti lo àkokò púpọ̀ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́?” Olúwa ti ṣètò Ìjọ Rẹ̀ láti ṣe àṣeyọrí àwọn ìsíwájú tó ṣe kókó. Gẹ́gẹ́bí, ìṣètò Ìjọ Rẹ̀ ní ìlàsílẹ̀ nínú èyí tí bíṣọ́ọ̀pù ní ojúṣe méjì. Ó ní ojúṣe ti-ẹ̀kọ́ fún wọ́ọ̀dù bí gbogbo wọn, ṣùgbọ́n bákannáà ó ní kókó ojúṣe ti-ẹ̀kọ́ fún iyejú àwọn àlùfáà.

Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tí wọ́n jẹ́ àlùfáà àti àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin ọjọ́ orí kannáà wà ní ipò pàtàkì gan an àti ìdàgbàsókè nínú ayé wọn. Ní àkokò ìgbà kúkurú kan, wọ́n ṣe ìpinnu tí ó ní àyọrísí pàtàkì ìgbé-ayé pípẹ́. Wọ́n pinnu bóyá wọn yíò yege fún tẹ́mpìlì, sin ní míṣọ̀n kan,20 tiraka láti ṣe ìgbeyàwó ní tẹ́mpìlì, àti ìmúrasílẹ̀ fún iṣẹ́ ayé wọn. Àwọn ìpinnu wọ̀nyí, lẹ́ẹ̀kan tí a bá ṣeé, ní àwọn àyọrísí ìjìnlẹ̀ ti-ẹ̀mí ìfihàn fún ìyókù igbé-ayé wọn. Ẹ̀yin bíṣọ́ọ̀pù, ẹ jọ̀wọ́ ẹ mọ̀ pé àkókò kúkurú tí a bá lò déédé pẹ̀lú ọ̀dọ́ àlùfáà kan, tàbí ọ̀dọ́mọbìnrin lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ní òye agbára tí ó wà fún wọn nípasẹ̀ Ètùtù Jésù Krístì. Ó lè pèsè ìran kan tí yíò ní okun ìjìnlẹ̀ lórí gbogbo ayé wọn.

Bíṣọ́ọ̀pù Moa Mahe àti àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀

Ọ̀kan lára àwọn àpẹrẹ dídárajùlọ tí mo ti rí nípa bíṣọ́ọ̀pù kan ẹnití ó ṣèrànwọ́n láti pèsè irú ìran yí fún àwọn ọ̀dọ́ ni Bíṣọ́ọ̀pù Moa Mahe. A pèé láti jẹ́ bíṣọ́ọ̀pù àkọ́kọ́ ti wọ́ọ̀dù San Francisco Tongan.21 Ó jẹ́ olùkólọ láti Vava’u, Tonga. Wọ́ọ̀dù rẹ̀ wà nítòsí ìdókọ̀-ọkọ̀ òfúrufú San Framcisco, california, níbití ó ti nṣiṣẹ́.22

Wọ́ọ̀dù Tongan

Wọ́ọ̀dù náà ní oyé àwọn ọ̀dọ́ púpọ̀, ọ̀pọ̀ làtinú àwọn ẹbí tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ̀ wá sí United States. Bíṣọ́ọ̀pù Mahe kò kọ́ wọn ní ọ̀rọ̀ àti nípa àpẹrẹ bí wọn ó ti jẹ́ ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì nìkan, ṣùgbọ́n bákannáà ó ṣèrànwọ́ láti fún wọn ní ìran kan nípa ohun tí wọ́n lè dà àti láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti múrasílẹ̀ fún tẹ́mpìlì, míṣọ̀n, ẹ̀kọ́, àti iṣẹ́. Ó sìn fún bíi ọdún mẹ́jọ, àwọn àlá àti ìfẹ́ rẹ̀ fún àwọn ọ̀dọ́ di òdodo.

Bíi ìpín àádọ́run àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin nínú àwọn iyeju Oyè-àlùfáà Árọ́nì sìn ní àwọn míṣọ̀n. Àwọn mẹẹdogun ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin ni ọmọ àwọn ẹbí àkọ́kọ́ láti lọ sí kọ́lẹ́jì.23 Ó pàdé Olórí ilé-ìwé gíga ìbílẹ̀ (kìí ṣe ti ìgbàgbọ́ wa), wọ́n sì jìjọ di ọ̀rẹ́ wọ́n kórajọ́ lórí bí wọn yíò ti ọ̀dọ́ kan lẹ́hìn láti ṣe àṣeyege àwọn ìfojúsùn dídára àti láti borí àwọn wàhálà. Olórí ilé-ìwé náà wí fún mi pé Bíṣọ́ọ̀pù Mahe ti òun lẹ́hìn ní ṣíṣe iṣẹ́ pẹ̀lú àwọn olùkólọ ti gbogbo ìgbàgbọ́ tí wọ́n nlàkàkà. Àwọn ọ̀dọ́ ènìyàn mọ̀ pé bíṣọ́ọ̀pù nifẹ wọn.

Pẹ̀lú ìbànújẹ́, Bíṣọ́ọpù Mahe kọjá lọ nígbàtí mò nsìn bí bíṣọ́ọ̀pù. Èmi kòní gbàgbé ìfọwọ́tọ́ni rẹ̀ àti ìsìnkú onímísí. Àwọn ọgọ̀ọ̀rọ̀ èrò wà níbẹ̀. Àwọn Akọrin wà pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́ ọmọ ìjọ tó ju marundinlogoji tí wọ́n ti sìn ní míṣọ̀n tàbí tí wọ́n nlọ sí kọ́lẹ́jì tí wọ́n ti jẹ́ ọ̀dọ́ ní ìgbà iṣẹ́-ìsìn rẹ̀ bí bíṣọ́ọ̀pù. Olùsọ̀rọ̀ kan fi imọ̀lára rẹ̀ líle hàn nípa ìmoore látọ̀dọ̀ àwọn ọ̀dọ́ àti àgbà ọ̀dọ́ nínú wọ́ọ̀dù rẹ̀. Ó fi oríyìn fún Bíṣọ́ọ̀pù Mahe fún ìran tí ó ti fún wọn ní mímúrasílẹ̀ fún ìgbé ayé iṣẹ́-ìsìn òdodo. Ṣùgbọ́n pàtàkì jùlọ, Bíṣọ́ọ̀pù Mahe ti ti wọ́n lẹ́hìn láti gbé ìgbàgbọ́ nínú Olúwa Jésù Krístì gẹ́gẹbí ìpìlẹ̀ ga nínú ayé wọn.

Nísisìyí, ẹ̀yin bíṣọ́ọ̀pù, níbikíbí tí ẹ ti nsìn, nínu àwọn ìfọ̀rọ̀wánilẹnúwò yín àti àwọn ìbaṣé míràn, ẹ lè pèsè irú ìran náà kí ẹ sì gbé ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krìstì ga. Ẹ lè nawọ́ àwọn ìfipè alágbára sí ìyípadà ìwà, múra wọn sílẹ̀ fún ìgbé ayé, àti ìmísí wọn láti dúró lórí ipa ọ̀nà májẹ̀mú.

Ní àfikún, ẹ lè ran àwọn ọ̀dọ́ kan tí wọ̀n wà nínú rògbòdìyàn pẹ̀lú obí lórí àwọn ohun tí kìí ṣe pàtàkì lọ́wọ́.24 Bí àkokò kan nígbàtí àwọn ọ̀dọ̀ ènìyàn dàbí wọ́n nní rògbòdìyàn kọjá àlà pẹ̀lú àwọn òbí wọn, ẹni tí ó nṣàkóso lórí iyejú wọn àti sí ẹnití wọn ndáhùn sí níti-àlùfáà ẹnitì àwọn òbí wọn nlọ bá fún ìkaniyẹ tẹ́mpìlì. Èyí gbé bíṣọ́ọ̀pù sí ipò ọ̀tọ̀ láti gba ọ̀dọ́ àti ọ̀bí wọn lámọ̀ràn bákannáà nígbàtí ìjà bá dá ìyapa sílẹ̀. Àwọn bíṣọ́ọ̀pù lè ran àwọn méjèèjì lọ́wọ́ láti wo àwọn nkan pẹ̀lú ìwò ayérayé kí awọn sì yanjú àwọn ọ̀ràn tí kò fi bẹ́ẹ̀ jẹ́ pàtàkì. A wí fún àwọn bíṣọ́ọ̀pù pé kí wọ́n máṣe ní àwọn ẹbí tí wọ́n nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí kí wọ́n lè dojú àkokò wọn àti agbára láti kọ àwọn ọ̀dọ́ àti ẹbí wọn nínú irú àwọn ipò wọ̀nyí.25

Mo ní ìfura nípa bíṣọ́ọ̀pù kan tí ó yanjú ìjà líle ní àárín ọmọkùnrin kan àti àwọn òbí rẹ̀, mímú ìṣọ̀kan wá sí ilé àti mímú ìfaramọ́ wọn gbòòrò nínú ìhìnrere. Bíṣọ́ọ̀pù náà ran àwọn òbí lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ pé títiraka láti jẹ́ ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì ṣe pàtàkì ju bí ìdọ́gbà àti nígbàtí wọ́n bá ṣe àṣeyọrí àwọn iṣẹ́-ilé ẹbí.

Ní èrò láti lo àkokò pẹ̀lú ọ̀dọ́, níbikíbi tí wọ́n wà, pẹ̀lú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tàbí ìṣe ní ilé-ìwé, àwọn bìṣọ́príkì ní a gbà nímọ̀ràn láti yan àwọn ìpàdé déédé àti àkokò ìgbàni-nímọ̀ràn pẹ̀lú àwọn àgbà. Nígbàtí àwọn bíṣọ́ọ̀pù lè dámọ̀ràn lórí àwọn ọ̀ràn kíákíá àti líle, a ní kí wọ́n yan ìdámọ̀ràn lílọlọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn ọ̀ràn líle, tí kìí ṣe kíákíá tí kò wà pẹ̀lú àwọn ìdájọ́ bíiti yíyẹ jẹ́ yíyàn sí ọmọ ẹgbẹ́ iyejú àwọn alàgbà tàbí Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́—bí ó ti máa njẹ́ àwọn àjọ ààrẹ tàbí àwọn arákùnrin àti arábìnrin òjíṣẹ́ ìránṣẹ́ Ẹ̀mí yíò tọ́ àwọn olórí sọ́nà26 láti yan àwọn ọmọ ìjọ tótọ́ láti ṣe ìbáni-dámọ̀ràn yí. Àwọn tí ó gba iṣẹ́ yíyàn ìgbàni-nímọ̀ràn yí ní ẹ̀tọ́ sí ìfihàn. Àwọn, bẹ́ẹ̀náà, gbọ́dọ̀ bojútó àṣírí lílé nígbàgbogbo.

Àwọn olórí tó laniyàn ti fi ìgbàgbogbo rúbọ fún ìran tó ndìde. Èyí ni ibití àwọn ọmọ ẹgbẹ́ bíṣọ́príkì nlo púpọ̀jù àkokò iṣẹ́-ìsìn ìjọ wọn sí.

Nísisìyí mo fẹ́ láti sọ àwọn ohun díẹ̀ tààrà sí àwọn ọ̀dọ́ àti lẹ́hìnnáà sí àwọn bíṣọ́ọ̀pù wa.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iyebíye ọ̀dọ́ ènìyàn lára yín lè má ní ìran kedere ti ẹnití ẹ jẹ́ àti ẹnití ẹ lè dà. Síbẹ̀ ẹ wà ní ààlà àwọn ìpinnu pàtàkì jùlọ tí ẹ ó ṣe nínú ayé yín. Ẹ jọ̀wọ́ ẹ bá àwọn òbí àti bíṣọ́ọ̀pù yí dámọ̀ràn nípa àwọn àṣàyàn pàtàkì tí ó wà níwájú yín. Ẹ fi ààyè gba bíṣọ́ọ̀pù láti jẹ́ ọ̀rẹ́ àti olùdámọ̀ràn yín.

A ní ìfura pé àwọn àdánwò àti ìdánwò nbọ̀ láti gbogbo ibi. Gbogbo wa nílò láti ronúpìwàdà lójoojúmọ́, bí Ààrẹ Nelson ti kọ́ni. Ẹ jọ̀wọ́ ẹ bá bíṣọ́ọ̀pù yín sọ̀rọ̀ nípa ọ̀rankọràn nínú èyí tí olùdájọ́ wíwọ́pọ̀ lè tì yín lẹ́hìn ní gbígbé ayé yín sí èrò pẹ̀lú Olúwa ní mímúrasílẹ̀ fún “iṣẹ́ nlá” tí Òun ní fún yín ní òpin àkokò iṣẹ́ ìríjú yí.27 Bí Ààrẹ Nelson ti pè yín, ẹ jọ̀wọ́ ẹ yege fúnra yín láti jẹ́ ara ọmọ-ogun ọ̀dọ́ Olúwa!28

Nísisìyí ọ̀rọ̀ kan fún ẹ̀yin bíṣọ́ọ̀pù iyebíye ní ìtìlẹhìn àwọn olórí àti ọmọ Ìjọ. A fi ìdúpè ìjìnlẹ̀ hàn sí yín. Pẹ̀lú àwọn àtúnṣe pé a ti ní kí ẹ ṣe ní àwọn ọdún àìpẹ́, ẹ̀yin bíṣọ́ọ̀pù ọ̀wọ́n, ẹ jọ̀wọ́ ẹ mọ̀ bí a ṣe nifẹ tí a sì mọyì yín. Ìfọwọ́sí yín nínú ìjọba fẹ́rẹ̀ kọjá ìjúwe. Ìjọ ní ọgbọ̀n-ẹgbẹ̀rún àti ọgọrun mẹsan àwọn bíṣọ́ọ̀pù àti ààrẹ ẹ̀ká tí wọ́n nsìn káàkiri àgbáyé.29 A bú-ọlá fún ẹnìkọ̀ọ̀kan yín.

Àwọn ọ̀rọ̀ díẹ̀ àti àwọn ìpè mímọ́ tí wọ́n júwe fẹ́rẹ̀ wà pẹ̀lú agbára ti ìmọ́lẹ̀, ẹ̀mí, pàtàkì. Ìpè ti bíṣọ́ọ̀pù dájúdájú ni ìsopọ̀ irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀. Láti sin Olúwa nínú agbára jẹ́ alámì ní oríṣiríṣi àwọn ọ̀nà. Ìpè náà, ìmúdúró, àti yíyàsọ́tọ̀ bíṣọ́ọ̀pù kan jẹ́ ìrírí tí a kò lè gbàgbé láé. Fún mi, ó jẹ́ ipò pẹ̀lú oye àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tìtóbi nínú ìgbòòrò sákáni àti ìmọ́lára ìyírapadà ìjìnlẹ̀. Ó joko pẹ̀lú ìtura nínú ipele àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ iyebíye bíiti ìgbeyàwó àti ipò-baba tí a kò lè júwe nínú àwọn ọ̀rọ̀ díẹ̀.30

Ẹ̀yin Bíṣọ́ọ̀pù, a ṣe ìmúdúró yín! Ẹ̀yin Bíṣọ́ọ̀pù, a ní ìfẹ́ yín! Ẹ jẹ́ olùṣọ́-àgùtàn lórí agbo Rẹ̀ nítòọ́tọ́. Olùgbàlà kò ní pa yín tì nínú àwọn ìpè mímọ́ wọ̀nyí. Nípa Èyí ni mo jẹ́ri ní òpin ọ̀sẹ̀ Ọdún-àjínde yí, ni orúkọ Jésù Krístì, Àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. “Òtítọ́ sí Ìgbàgbọ́,” Àwọn orin, no. 254.

  2. Àwọn olórí ọ̀dọ́, iyejú àti àwọn àjọ ààrẹ kílásì, àti àwọn olórí Ìjọ míràn pín ojúṣe yí.

  3. Bíṣọ́ọ̀pù ni ààrẹ iyejú àwọn àlùfáà. Olùdámọ̀ràn ìkínní rẹ̀ ní ojúṣe fún àwọn iyejú olùkọ́ni, àti pé olùdámọ̀ràn èkejì ní ojúṣe fún iyejú àwọn díákónì. (Wo Ìwé-ìléwọ́ Gbogbogbò: Sísìn nínú Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn ọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, 10.3, ChurchofJesusChrist.org.)

  4. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 68:25–28.

  5. Wo Quentin L. Cook, “Àtúnṣe sí Fífún àwọn Ọ̀dọ́ Lókun,” Liahona, Nov. 2019, 40–43.

  6. Lílo ọ̀rọ náà bíṣọ́ọ̀pù wúlò pẹ̀lú irú ipa dídọ́gba sí òdodo àwọn ààrẹ ẹ̀ka.

  7. 1 Pétérù 2:25.

  8. Wo Ìwé-ìléwọ́ Gbogbogbò, 6.1.1.

  9. Wo Ìwé-ìléwọ́ Gbogbogbò, 6.1.2.

  10. Wo Ìwé-ìléwọ́ Gbogbogbò, 6.1.3.

  11. Wo Ìwé-ìléwọ́ Gbogbogbò, 6.1.4.

  12. Wo Ìwé-ìléwọ́ Gbogbogbò, 6.1.5.

  13. Ìwé-ìléwọ́ Gbogbogbò, 6.1.1; bákannáà wo Ìwé-ìléwọ́ Gbogbogbò, 6.1.1.1–6.1.1.4.

  14. Ìwé-ìléwọ́ Gbogbogbò, 6.1.1.

  15. Ìwé-ìléwọ́ Gbogbogbò, 6.1.4.

  16. Wo Ìwé-ìléwọ́ Gbogbogbò, 21.2; 23.5; 25.2.

  17. Wo Ìwé-ìléwọ́ Gbogbogbk, 6.1; 14.3.3.1; bákannáà wo Quentin L. Cook, “Àtunṣe sí Okun Àwọn Ọ̀dọ́,” 40-43. Bíṣọ́ọ̀pù bákannáà ti gba ìyànjú láti lo àkokò si pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ àti ẹbí. Irú ìdojúkọ ni a mú ṣeéṣe bí olùdámọ̀ràn alágbára àwọn àgbà àti ọ̀jọ̀gbọ́n ni a pè láti ti àwọn àjọ ààrẹ iyejú Oyèàlùfáà Árọ́nì àti bìṣọ́ọ̀príkì lẹ́hìn nínú ojúṣe wọn.

  18. Russell M. Nelson, “Àwọn Ẹlẹri, Àwọn Iyejú Oyèàlùfáà Áárọ́nì, àti Kíláásì àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin,” Liahona, Nov. 2019, 39.

  19. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 107:87–88.

  20. “Olúwa nretí ọ̀dọ́mọkùnrin alágbára kọ̀ọ̀kan láti múrasílẹ̀ láti sìn [miṣọ̀n kan] (wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 36:1, 4–7). Àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin àti àgbà ọmọ ìjọ tí wọ́n nfẹ́ láti sìn níláti múrasílẹ̀ bákannáà. Apákan pàtàkì nípa ìmúrasílẹ̀ ni ìtiraka láti di olùyípadà ọkàn sí Jésù Krístì àti ìmúpadàbọ̀sípò Rẹ̀. Àwọn tí wọ́n fẹ́ láti sìn bákannáà múrasílẹ̀ níti-ara, ọpọplọ, ẹ̀dùn-ọkàn, àti ìṣúná” (Ìwé-ìléwọ́ Gbogbogbò, 24.0).

  21. A ṣètò wọ́ọ̀dù náà ní Ọjọ́ Kẹtàdínlógún Oṣù Kejìlá, 1980 Alàgbà John H. Groberg ti Iyejú Ìkínní ti Àádọ́rin ṣèrànwọ́ láti ṣètò wọ́ọ̀dù ÈdèTongan yí. (Wo Gordon Ashby, alága, àti Donna Osgood, ed., Àkọọ́lẹ̀-ìtàn ti èèkàn San Francisco California, 1927–87 [1987], 49–52.)

  22. Bíṣọ́ọ̀pù Mahe ti gòkè sí ipò ìṣàkóso pẹ̀lú American Airlines ní San Francisco, Ojúkọ́-òfúrufú Káríayé, San Francisco.

  23. Wo Àkọọ́lẹ̀ ti Èèkàn San Francisco California, 49.

  24. Bákannáà wọ́n lè ṣọ̀tẹ̀ ní ìlòdì sí àwọn ohun tí ó jẹ́ pàtàkì ti ayérayé.

  25. Wo Ìwé-ìléwọ́ Gbogbogbò, 21.2.1.

  26. Bíṣọ́ọ̀pù pẹ̀lú yíò fètòsí àwọn alàgbà iyejú àti àjọ ààrẹ Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ pẹ̀lú ọ̀wọ̀ sí ẹni tí a ó yàn àti bí a ṣe lè ṣe àṣeyege títẹ̀lé ìtọ́jú àti ìfẹ́ni.

  27. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 64:33.

  28. Wo Russell M. Nelson “Ìrètí Ísráẹ́lì” (worldwide youth devotional, June 3, 2018), HopeofIsrael.ChurchofJesusChrist.org.

  29. Ní Ọjọ́ Kọkàndínlógún Oṣù Kejì, 2021 àwọn bíṣọ́ọ̀pù ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógún ó lé marundinlọgbọn àti ààrẹ ẹ̀ka tí wọ́n nsìn káàkiri ayé.

  30. A pè mí bí bíṣọ́ọ̀pù ti wọ́ọ̀dù Burlingame ní California ní 1974 láti ọwọ́ Ààrẹ David B. Barlow a sì yà mí sọ́tọ̀ ní Ọjọ́ marundínlógún Oṣù Kẹsan, 1974, láti ọwọ́ Alàgbà Neal A. Maxwell, ẹnití a pè bí olùrànlọ́wọ́ kan sí Iyejú àwọn Àpóstélì Méjìlá.