Jésù Krístì Ni Okun Àwọn Ọ̀dọ́
Ẹ fi ìgbẹ́kẹ̀lé yín sínú Jésù Krístì. Òun yío darí yín sí ọ̀nà tí ó tọ́. Òun ni agbára yín.19
Ní gbígbaradi fún ọrọ yi lóni, mo ti ní imọlára awọn iṣílétí líle láti bá awọn ọdọ́mọbìnrin ati awọn ọdọ́mọkùnrin sọrọ.
Bákannáa mo nbá awọn ti wọ́n ti jẹ́ ọdọ́ nígbakanrí sọrọ, àní sí awọn wọnni tí wọn ko tilẹ le rántí rẹ mọ́.
Mo si nsọrọ sí gbogbo awọn tí wọ́n fẹ́ran awọn ọdọ́ wa tí wọ́n si fẹ́ kí wọn ó ṣe rere nínú ayé.
Fún awọn ìran tí ó ndìde, mo ní ọrọ kan ní pataki fún ọ láti ọdọ Olugbala wa, Jésù Krístì.
Ọrọ Olugbala sí Yín
Ẹyin ọrẹ́ mi ọwọ́n, bí Olugbala bá wa níhin nísisiyí, kíni Oun yío sọ fún yín?
Mo gbàgbọ́ pé Oun ó bẹrẹ nípa ṣíṣe afihan ifẹ́ ijinlẹ Rẹ fún yín. O le sọ ọ́ pẹlu awọn ọrọ, ṣugbọ́n bákannáa yío ṣan ní líle tóbẹ́ẹ—láti ọdọ Rẹ wá—tí a ko ni le ṣe aṣiṣe rẹ, ní lílọ jinlẹ sínú ọkan yín, tí yío kún gbogbo ẹmí yín!
Ati síbẹ, nítorípé gbogbo wa jẹ́ aláilera ati aláipé, awọn aníyan kan le rákoro sí inú yín. Ẹ le rántí awọn aṣiṣe tí ẹ ti ṣe, awọn akóko tí ẹ ti jọwọ́ sílẹ fún adánwo, awọn ohun tí ibá wu yín pé ẹ ko tíi ṣe—tabí wu yín pé ẹ bá ti ṣe dáradára síi.
Olùgbàlà yío woye eyí, mo si gbagbọ́ pé Oun yío fi dáa yín lójú pẹlú awọn ọrọ tí O ti sọ nínú awọn iwé mímọ́ pé: “Ẹ máṣe bẹru.”1
Má bẹ̀rù.5
“Ẹ máṣe ṣiyèméjì.”2
“Ẹ tújúka.”3
“Ẹ máṣe jẹ́ kí ọkàn yín kí ó dàmú”4.
Emi ko ro pé Oun yío ṣe awọn awáwí fún awọn aṣiṣe yín. Oun ko ni dín wọn ku. Rárá, Oun yío sọ fún yín láti ronúpìwàdà—láti fi awọn ẹṣẹ yín sílẹ lẹ́hin, láti yípada, kí Oun ó le dáríjì yín. Oun ó rán yín létí pé ní ẹgbẹrún ọdún méji sẹ́hin, Ó gba awọn ẹṣẹ wọnni sí orí ara Rẹ kí ẹyin ó le ronúpìwàdà. Eyí jẹ́ apákan eto idunnú tí a fifún wa lati ọdọ olufẹ́ni Baba Ọ̀run.
Jésù le tọ́ka rẹ jáde pé awọn májẹmú yín pẹlú Rẹ—tí ẹ ṣe nígbatí ẹ ṣe iribọmi ati tí ẹ nsọ dọtun ní akóko kọọkan tí ẹ bá nkópa nínú ounjẹ Olúwa—nfún yín ní asopọ pataki kan pẹlú Rẹ̀. Iru asopọ tí awọn iwé mímọ́ júwe bíi dída papọ pé, pẹlú iranlọ́wọ́ Rẹ̀, ẹ le gbé eyíkeyí ẹrù.5
Mo gbagbọ́ pé Olùgbàlà Jésù Krístì yío fẹ́ kí ẹyin ó rí, kí ẹ ní imọlára, kí ẹ si mọ pé Oun ni okun yín. Pé pẹlú iranlọ́wọ́ Rẹ, ko sí opin sí ohun tí ẹ le ṣe ní aṣeyọrí. Pé agbára ileṣe yín ko ní opin. Oun yío fẹ́ kí ẹ rí ara yín ní ọ̀nà bí Oun ti rí yín. Èyí sì yàtọ̀ gan sí ọ̀nà tí ayé ti rí yín.
Olùgbàlà yío kéde, kií ṣe ní awọn ọrọ tí ko dájú, pé iwọ jẹ́ ọmọbinrin tabí ọmọkunrin Ọlọ́run Alágbára Jùlọ. Baba yín Ọ̀run ni ẹda ológo julọ ní gbogbo agbáyé, tí ó kún fún ifẹ́, ayọ̀, ailéerí, jíjẹ́ mímọ́, imọ́lẹ, oore ọ̀fẹ́, ati otitọ́. Ati pé ní ọjọ́ kan Ó fẹ́ kí ẹ jogún gbogbo ohun tí Òun ní.6
Ó jẹ́ idí tí ẹ fi wa lórí ilẹ ayé níhĩn—láti kọ́ ẹkọ́, láti dagba, ati lati tẹsíwájú kí ẹ si da ohun gbogbo tí Baba yín ní Ọ̀run ti dá yín fún.
Lati mú kí eyí ṣeéṣe, Ó rán Jésù Krístì láti jẹ́ Olùgbàlà yín. Ó jẹ́ eredí fún eto idunnú Rẹ nlá, Ijọ Rẹ, oyè-àlùfáà Rẹ, awọn iwé mímọ́—gbogbo rẹ.
Èyíni ni ayanmọ́ yín. Èyí ni ọjọ́ ọla yín. Eyí ni yíyàn yín!
Otítọ́ ati Awọn Yíyan
Ní ibi ọkàn eto Ọlọ́run fún idunnú ni agbára yín wa láti yan.7 Bẹ́ẹ̀ni, Baba yín Ọ̀run fẹ́ kí ẹ yan ayọ̀ ayérayé pẹlú Rẹ, Oun yío si ran yín lọwọ láti ṣe aṣeyọrí rẹ, ṣugbọ́n Òun ko ní fi ipá mú un lée yín lórí.
Nítorínáa Òun fi aaye gba yín láti yan: Imọ́lẹ tabí òkùnkùn? Rere tabí ibi? Ayọ̀ tabí ìbànújẹ́? Iye ayérayé tabí ikú ti ẹ̀mí?8
O dún bíi yíyàn tó rọrùn, àbí bẹ́ẹ̀kọ́? Ṣugbọ́n ní ọna kan, nihĩn lórí ilẹ ayé, ó dabí pé ó dojúrú ju bí o ti yẹ.
Iṣoro ibẹ ni pé a kií fi igba gbogbo rí awọn nkan ní kedere tó bí a ṣe fẹ́. Paulu Apostéli fi wé wíwo “yíka inú gíláasi kan, pẹlú oju ṣíṣú.”9 Idarúdapọ púpọ wa nínú ayé nipa ohun tí ó tọ́ ati àṣìṣe. Otitọ́ ndi lílọ́ láti mú ibi dabí rere ati rere dabí ibi.10
Ṣugbọ́n nígbatí ẹ bá lépa otítọ́ pẹlú itara—otítọ́ ayérayé, tí kií yípada—awọn yíyan yín yío di kedere púpọ síi. Bẹ́ẹni, ẹ nní adánwo ati awọn idojukọ síbẹ. Awọn ohun búburú nṣẹlẹ síbẹ. Awọn ohun rúdurùdu. Awọn ohun burúkú. Ṣugbọ́n ẹ le kápá rẹ nigbati ẹ bá mọ ẹnití ẹ jẹ́, idí tí ẹ fi wa níhĩn, ati nigbati ẹ bá gbẹ́kẹlé Ọlọ́run.
Nítorínáà níbo ni ẹ ó ti rí otítọ́?
Ó wa nínú ìhìnrere ti Jésù Krístì. Àti pé ẹkúnrẹ́rẹ́ ihinrere náa ni a nkọ́ni nínú Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ikẹhìn.
Jésù Krístì wí pé, “èmi ni ọ̀nà, òtítọ́, ati ìyè: kò sí ẹnikẹ́ni tí ó le wá sí ọ̀dọ̀ Bàbá, bíkòṣe nípasẹ̀ mi.”11
Nígbatí ẹ bá ní awọn yíyan pataki lati ṣe, Jésù Krístì àti ìhìnrere Rẹ̀ tí a múpadàbọ̀sípò ni yíyan tí ó dárajulọ. Nígbatí ẹ bá ní awọn ibéere, Jésù Krístì àti ìhìnrere Rẹ̀ tí a múpadàbọ̀sípò ni awọn idáhun tí ó dára julọ. Nígbatí ẹ bá ní imọlára àìlera, Jésù Krístì ni okun yín.
Ó nfi agbára fún awọn tó ti rẹ̀; ati fún awọn tó ní imọlára ailágbára, Ó nmú okun wọn pọ síi.
Awọn tí wọ́n dúró de Olúwa yío di sísọ dọtun nípa agbára Rẹ̀.12
Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́
Láti ran yín lọ́wọ́ wá Ọna náa ati láti ràn yín lọ́wọ́ fi ẹkọ́ ti Krístì ṣe ipá itọ́ni nínú ayé yín, Ijọ Jésù Krístì ti Awọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ikẹhìn ti múra ohun elo titun kan sílẹ̀, atúnṣe ẹda ti Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́
Ó lé ní aádọ́ta ọdún, Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́ ti jẹ́ itọ́ni kan fún irandíran awọn ọdọ́ ti Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ikẹhìn. Mo máa nfi ẹda rẹ kan sí inú apo mi nígba gbogbo, mo si máa npín in pẹlú awọn eniyan tí wọ́n bá ní ibéere nípa awọn iṣe wa. A ti mú un bá igba mu a si ti ṣe atúnṣe rẹ láti dára síi ní dídojúkọ awọn ipeníja ati awọn idánwo ti akóko wa. Ẹdà titun ti Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́ wà ní arọ́wọ́tó lórí fánrán ìlà ní àádọ́ta oríṣiríṣi awọn ede yío si wà ní títẹ̀ bákannáà. Yío jẹ́ iranlọ́wọ́ kan pataki fún ṣíṣe awọn aṣayan ní igbésí ayé yín. Ẹ jọwọ ẹ gbáá bíi tiyín kí ẹ sì ṣe àbápín rẹ̀ pẹ̀lú awọn ọrẹ yín.
Ẹda titun yi ti Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́ ni a fún ní alayé akorí Itọni Kan fún Ṣíṣe Awọn Aṣayan.
Láti ṣe kedere gidi, itọ́ni tí ó dára julọ tí ó ṣeéṣe kí ẹ ní láti ṣe awọn aṣayan ni Jésù Krístì. Jésù Krístì ni okun awọn ọdọ́.
Nítorináa eredi Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́ ni láti tọ́ka yín sí I. Ó nkọ́ yín ní awọn otítọ́ ayérayé ti ìhìnrere Rẹ̀ tí a múpadàbọ̀sípò—awọn otítọ́ nípa ẹnití ẹ jẹ́, ẹnití Oun jẹ́, ati ohun tí ẹ le gbé ṣe pẹlú agbára Rẹ. Ó nkọ́ yín bí a ti nṣe awọn aṣayan ododo tí ó dá lóri awọn otítọ́ ayérayé wọnni.13
Ó ṣe pataki fún yín bákannáa láti mọ ohun tí Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́ kií ṣe. Kií ṣe awọn ipinnu fún yín. Kií fún yín ni “bẹ́ẹni” tabí “bẹ́ẹkọ́” nipa gbogbo yíyan tí ẹ le dojúkọ. Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́ nfi oju sun lorí ipilẹ awọn yíyan yín. Ó nfi ojú sùn lóri awọn iyi, awọn ìpìlẹ̀ ẹkọ́, ati ẹkọ́ dípo olukúlùkù ìhùwàsí ní pàtó.
Olúwa, nípasẹ̀ àwọn wòlíì Rẹ̀, ti nfi ìgbà gbogbo tọ́ wa ní ihà náà. Ó nbẹ̀ wá láti “fi kún agbára [wa] ní ti ẹ̀mí láti gba ìfihàn.”14 Ó npè wá láti “gbọ́ Tirẹ̀.”15 Ó npè wá láti tẹ̀lé Òun ní àwọn ọ̀nà tí ó ga jùlọ àti tí ó mọ́ jùlọ.16 A sì nkọ́ ẹ̀kọ́ ní ọ̀nà tí ó jọra ní ọ̀sẹ̀-ọ̀sẹ̀ nínú Wá, Tẹ̀lé Mi.
Mo lérò pé ìtọ́ni náà le fún yín ní awọn àkójọ gígùn ní ti àwọn aṣọ ti ẹ kò gbọdọ̀ wọ̀, àwọn ọ̀rọ̀ tí ẹ kò gbọdọ̀ sọ, àti àwọn eré ìdárayá tí ẹ kò gbọdọ̀ wò. Ṣùgbọ́n njẹ́ èyí yío ṣe ìrànlọ́wọ́ nínú ìjọ àgbáyé bí? Njẹ́ irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ yío múra yín sílẹ̀ nítòótọ́ fún ìgbé ayé Ìwà-bíi-Krístì fún gbogbo ọjọ́ ayé bí?
Joseph Smith sọ pé, “mo kọ́ wọn ní àwọn ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ pípé, wọ́n sì nṣe àkóso ara wọn.”17
Ọba Bẹ́njámínì sì sọ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì pé, “Emi kò lè sọ ohun gbogbo fún yín nínú eyí tí ẹ le dá ẹ̀ṣẹ̀; nítorípé onírurú ọ̀nà àti ipá ni ó wà, àní púpọ̀ tóbẹ̃, tí èmi kò lè kà wọ́n.”17
Ọba Bẹ́njámínì tẹ̀síwájú láti sọ pé, “Ṣùgbọ́n ìwọnba èyí ni mo lè sọ fún yín, … ẹ kíyèsí ara yínàti àwọn èrò ọkàn yín, àti àwọn ọ̀rọ̀ yín, àti àwọn iṣẹ́ yín, kí ẹ sì pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́, kí ẹ sì tẹ̀síwájú nínú ìgbàgbọ́ … Olúwa wa, àní títí dé òpin ayé yín.”18
Njẹ́ ó jẹ́ àṣìṣe láti ní àwọn ìlànà? Dájúdájú bẹ́ẹ̀kọ́. Gbogbo wa nílò wọn lójojúmọ́. Ṣùgbọ́n ó jẹ́ àṣìṣe láti fi ojú sùn sórí àwọn ìlànà nìkan dípò fífojúsùn sórí Olùgbàlà. Ẹ nílati mọ àwọn ìdí àti àwọn báwo, àti nígbànáà kí ẹ ronú sí àwọn àbájáde awọn yíyàn yín. Ẹ níláti fi ìgbẹ́kẹ̀lé yín sínú Jésù Krístì. Òun yío darí yín sí ọ̀nà tí ó tọ́. Òun ni agbára yín.19
Agbára Ẹkọ́ Òtítọ́
Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́ ní ìgboyà ní kíkéde ẹ̀kọ́ Jésù Krístì. Ó ní ìgboyà ní pípè yín láti ṣe àwọn yíyàn tí ó dá lórí ẹ̀kọ̀ Krístì. Ó sì ní ìgboyà ní síṣe àpèjúwe àwọn ìbùkún tí Jésù Krístì ṣe ìlérí fún àwọn tí wọ́n bá tẹ̀lé Ọnà Rẹ̀.20
Aarẹ Russel M. Nelson kọ́ni pé: “Nígbàtí ìfẹ́ inú yín títóbi jùlọ bá jẹ́ láti jẹ́kí Ọlọ́run borí [nínú ayé yín], ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìpinnu á di ìrọrùn síi. Ọpọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀ràn a di àìsí-ọ̀ràn! Ẹ ó mọ̀ bí ẹ ṣe lè tún ara yín ṣe dáradára jùlọ̀. Ẹ ó mọ ohun tí ẹ ó wò àti tí ẹ ó kà, ibi tí ẹ ó ti lo àkokò yín, àti pẹ̀lú ẹnití ẹ ó darapọ̀ mọ́. Ẹ ó mọ ohun tí ẹ fẹ́ ṣe ní àṣeyege. Ẹ ó mọ irú ẹni tí ẹ fẹ́ láti dà.”21
Osùnwọ̀n Gígajù Kan
Jésù Krístì ní àwọn òsùnwọ̀n tí ó ga gidi fún àwọn àtẹ̀lé Rẹ̀. Ati pé ìfipè láti lépa ìfẹ́ Rẹ̀ pẹ̀lú ìtara ati láti gbé nípa àwọn òtítọ́ Rẹ̀ ni òsùnwọ̀n tí ó ga jùlọ tí ó ṣeéṣe!
Àwọn yíyàn pàtàkì ní ti ara àti ti ẹ̀mí kò níláti dá lórí fífẹ́ ti ara ẹni nìkan, tàbí ohun tí ó rọrùn tàbí tí ó wọ́pọ̀.22 Olúwa kò máa sọ pé, “Ṣe ohunkóhun tí o fẹ́.”
Ó nsọ pé, “Jẹ́kí Ọlọ́run borí.”
Ó nsọ pé “Wá, tẹ̀lé mi.”23
Ó nsọ pé, “Ẹ gbé ní ọ̀nà tí ó mọ́ síi, tí ó ga síi, àti tí ó dàgbà síi.”
Ó nwípé, “Pa àwọn òfin mi mọ́.”
Jésù Krístì ni àpẹrẹ wa pípé, a sì ntiraka pẹ̀lú gbogbo agbára ẹ̀mí wa láti tẹ̀lé E.
Ẹyin ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, ẹ jẹ́kí nṣe àtúnsọ pé, bí Olùgbàlà bá ndúró níhĩn lóni, Òun yío sọ nípa ìfẹ́ Rẹ̀ àìlópin fún yín, ìgbẹ́kẹ̀lé pípé Rẹ̀ nínú yín. Òun yío sọ fún yín pé ẹ lè ṣe èyí. Ẹ le ṣe ìgbé ayé aláyọ̀, onídùnnú nítorípé Jésù Krístì ni agbára yín. Ẹ le rí ìgbẹ́kẹ̀lé, àlàáfíà, ààbò, ìdùnnú, àti ìfaramọ́ nísisìyí àti ní ayérayé, nítorípé ẹ ó rí gbogbo rẹ̀ nínú Jésù Krístì, nínú ìhìnrere Rẹ̀, nínú Ìjọ Rẹ̀.
Nípa èyí ni mo jẹ́ ẹ̀rí mi pẹ̀lú ọ̀wọ̀ bíi Apóstélì Olúwa Jésù Krístì mo sì fi ìbùkún àtọkànwá mi sílẹ̀ fún yín nínú ìjìnlẹ̀ ìmoore àti ìfẹ́ fún yín, ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.