Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Rírí Jésù Krístì Síi nínú Àwọn Ìgbésí Ayé Wa
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2022


Rírí Jésù Krístì Síi nínú Àwọn Ìgbésí Ayé Wa

Olùgbàlà pè wá láti rí ìgbé ayé wa nípasẹ̀ Rẹ̀ ní èrò láti rí púpọ̀ sí i nípa Rẹ̀ nínú ìgbésí ayé wa.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, bí ìrẹ̀lẹ̀ mi ti pọ̀ tó lati wà pẹ̀lú yín ní òwúrọ̀ yí. Mo so ọkàn mi pọ̀ pẹ̀lú tìyín ní ọpẹ́ láti péjọ, nibikibi ti ẹ bá wà ní gbogbo àgbáyé, láti gbọ́ ọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn wòlíì, àpóstélì, aríran, olùfihàn, àti olùdarí nínú ìjọba ti Ọlọ́run. A dàbí àwọn ènìyàn ìgbà ayé Ọba Bẹ́ńjámínì ní ìṣàpẹẹrẹ, pípa àgọ́ wa, a sì njẹ́ kí àwọn ilẹ̀kùn wa ṣí sílẹ̀, a sì ndarí wa sọ́dọ̀ wòlíì Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé,1 Ààrẹ Russell M. Nelson.

Mo ti ní ojú tí kò dára níwọ̀n ìgbà tí mo lè rántí àti nígbàgbogbo ní ìnílò ìrànlọ́wọ́ ti àwọn ìjúwe awo-ojú láti ṣe àtúnṣe ìran mi. Nígbàtí mo bá la oju mi ​​​​ni gbogbo owurọ, ìlà-ọjọ́ yoo han bàìbàì. Ohun gbogbo kò ní ìdojúkọ, wínníwíní, ati dídàrú. Kódà ọkọ mi ọ̀wọ́n tún máa nrántí àwòrán aláwọ̀ mèremère ju ti onífẹ-jùlọ tó ntuni nínú gan-an tí òun jẹ́! Àìní ìsọdọ̀tun mi, ṣáájú kí ntó ṣe ohunkóhun míràn ní ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ mi, ni láti dé ọ̀dọ̀ awo-ojú mi láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún mi láti ní òye ti agbègbè mi àti láti gbádùn ìrírí alárinrin díẹ̀ síi bí wọ́n ṣe nṣe ìrànlọ́wọ́ lílọ kiri fún mi ní gbogbo ọjọ́ mi.

Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́hìn, Mo ti mọ̀ pé ìhùwàsí yíi ṣe àfihàn ìgbẹ́kẹ̀lé mi lójoojúmọ́ lórí àwọn nkan méjì: àkọ́kọ́, ohun èlò tó ṣe ìrànlọ́wọ́ fún mi láti hàn kedere, dojúkọ, àti láti ṣe àkóso ilẹ̀ ayé tó yí mi ká; àti èkejì, ìwúlò fún ìtọ́sọ́nà ojúlówó láti tọ́ka mi sí ìdarí títọ́ nígbàgbogbo. Ìrọ̀rùn, ìṣe déédé yí nfi mi hàn sí àkíyèsí pàtàkì nípa ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú Olùgbàlà wa, Jésù Krístì.

Nínú àwọn ìgbésí ayé wa tí ó kún fún àwọn ìbéèrè, ìdàmú, wàhálà, àti ànfàní nígbàkugbà, ìfẹ́ Olùgbàlà wa fún olúkúlukú wa àti gẹ́gẹ́bi àwọn ọmọ májẹ̀mú Rẹ̀, papọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹ̀kọ́ àti òfin Rẹ̀ jẹ́ àwọn àwọn ohun èlò ojoojúmọ́ tí a lè gbáralé lati jẹ “imọlẹ èyí tí ó ntan ìmọ́lẹ̀, … ntàn sí [wa] lójú [ó sì] nmú kí òye [wa] di ààyè.”2 Bí a ṣe nwá àwọn ìbùkún ti Ẹ̀mí nínú ìgbésí ayé wa, a ò ní ànfàní láti, gẹ́gẹ́bí Jákọ́bù ti kọ́ni, wo “àwọn nkàn bí wọ́n ti rí nítòótọ́, àti … bí wọn yóò ti rí nítòótọ́.”3

Gẹ́gẹ́bí àwọn ọmọ májẹ̀mú ti Ọlọ́run, a ti bùkún wa lọ́nà àìláfiwé lọ̀pọ̀lọpọ̀ níti pípèsè tí ọ̀run yàn àwọn ohun èlò láti gbèrú ìríran ti ẹ̀mí wa. Àwọn ọ̀rọ̀ àti àwọn ẹ̀kọ́ Jésù Krístì gẹ́gẹ́bí a ṣe kọ ọ́ sínú ìwé mímọ́ àti àwọn ọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn wòlíì Rẹ̀ tí a yàn àti Ẹ̀mí Rẹ̀ tí a gbà nípasẹ̀ àdúrà ojoojúmọ́, wíwá sí tẹ́mpìlì déédéé, àti nípasẹ̀ ìlànà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ti oúnjẹ Olúwa lè ṣèrànwọ́ láti mú àlàáfíà padà bọ̀ sípò àti láti pèsè ẹ̀bùn ìfòyemọ̀ tí ó yẹ tí ó nmú ìmọ́lẹ̀ Krístì àti òye Rẹ̀ wá sí àwọn igun ìgbé ayé wa àti nínú ayé tí ó lè jẹ́ ìkukù. Olùgbàlà tún lè jẹ́ atọ́nà wa àti awakọ̀ wa bí a ṣe nrìn larín méjèjì ìdákẹ́jẹ́ àti àwọn omi rúdurùdu ti ìgbésí ayé. Ó lè ṣe ọ̀nà ìrọ̀rùn tó tọ́ tí ó ndarí wa sí òpin ìrìnàjò ayérayé. Nítorínà kíni Òun yíò jẹ́ kí a rí, àti níbo ni Òun yíò jẹ́ kí a lọ?

Wòlíì wa ọ̀wọ́n ti kọ́ni pé “a gbọ́dọ̀ gbé àfojúsùn wa sórí Olùgbàlà àti ihinrere Rẹ̀” àti pé a gbọ́dọ̀ “tiraka láti bojúwo Ó nínú gbogbo èrò.”4 Ààrẹ Nelson tún ti ṣèlérí pé “kò sí ohun tí ó npe Ẹ̀mí ju fífi àfojúsùn yín sórí Jésù Krístì. … Òun yíò dárí yíò sì tọ́ yín sọ́nà nínú ìgbé ayé ti araẹni yín bí ẹ bá fi ààyè sílẹ̀ fún Un nínú ayé yín—ní ọ̀kọ̀ọ̀kan àti ní gbogbo ọjọ́.5 Ẹ̀yin ọ̀rẹ́, Jésù Krístì jẹ́ èrèdí àfojúsùn wa àti èrò ibi tí a nlọ ní òpin ìrìnàjò. Láti ràn wá lọ́wọ́ láti dúró ṣinṣin àti láti lọ sí ọ̀nà tó tọ́, Olùgbàlà pè wá láti rí ìgbé ayé wa nípasẹ̀ Rẹ̀ ni èrò láti rí púpọ̀ sí i nípa Rẹ̀ nínú ìgbésí ayé wa. Mo ‘ti wá láti kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa kókó ìpè yìí nípasẹ̀ ẹ̀kọ́ mi ti Májẹ̀mú Láéláé.

Òfin Mósè ni a fi fún àwọn ọmọ Ísráẹ́lì ìṣáájú gẹ́gẹ́bí ìhìnrere ìmúrasílẹ̀, tí a ṣètò láti múra àwọn ènìyàn sílẹ̀ fún ìbáṣepọ̀ gígajù májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Kristi.6 Òfin náà, tí ó kún fún ìṣàpẹẹrẹ tí ntọ́ka àwọn onígbàgbọ́ láti “máa fojú sọ́nà fún bíbọ̀” àti Ètùtù ti Jésù Krístì,7 ni ó túmọ̀ sí láti ran àwọn ọmọ Ísráẹ́lì lọ́wọ́ láti dojúkọ Olùgbàlà nípa lílo ìgbàgbọ́ nínú Rẹ̀, ìrúbọ Rẹ̀, àti àwọn òfin àti àṣẹ Rẹ̀ nínú ìgbésí ayé wọn8—ó jẹ́ èrò-inú láti mú wọn wá sí òye títóbi nípa Olùràpadà wọn.

Gẹ́gẹ́bí àwa ti wà lóni, àwọn ènìyàn Ọlọ́run àtijọ́ ni a pè láti wo ìgbésí ayé wọn nípasẹ̀ Rẹ̀ ní èrò láti rí púpọ̀ sii npa Rẹ nínú ìgbésí ayé wọn. Ṣùgbọ́n ní àkókò iṣẹ́ ìránsṣ´ Olùgbàlà, àwọn ọmọ Ísráẹ́lì ti pàdánù ojú ìwòye Kristi nínú àwọn ayẹyẹ wọn, wọ́n gbé E sí ẹ̀gbẹ́ tí wọ́n sì nfikún àwọn ìṣe áítọ́ tí kò ní ìṣàpẹẹrẹ ẹ̀kọ́ tí ó ntọ́ka sí òtítọ́ àti orísun kanṣoṣo ti ìgbàlà àti ìràpadà wọn—Jésù Kristi. .9

Ayé ojoojúmọ́ ti àwọn ọmọ Ísráẹ́lì ti di dídàrú, ó sì ti ṣókùnkùn. Àwọn ọmọ Ísráẹ́lì, ní ipò yí, gbà pé àwọn ìwà àti àwọn ìlànà ìsìn níti òfin ni ọ̀nà sí ìgbàlà ti araẹni àti ní apákan dín Òfin Mósè kù sí ètò àwọn ìlànà tí a ṣe láti ṣàkóso ìgbésí ayé alágbádá.10 Èyí nílò Olùgbàlà láti mú ìdojúkọ àti mímọ̀híhàn kedere padà sí ìhìnrere Rẹ̀.

Nígbẹ̀hìn, apá kan púpọ̀ lára ​​àwọn ọmọ Ísráẹ́lì kọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ sílẹ̀, àní tí wọ́n lọ jìnnà débi tí wọ́n fi fẹ̀sùn kan Olùgbàlà—Òun tó fúnni ní òfin tó sì kéde pé òun jẹ́ “òfin, àti ìmọ́lẹ̀ náà”11—ní kíkọ̀ ọ. Síbẹ̀ Jésù nínú Ìwàásù Rẹ̀ Lórí Òkè, ní sísọ̀rọ̀ lórí Òfin Mósè, sọ pé: “Ẹ má ṣe rò pé mo wá láti pa Òfin tàbí àwọn wòlíì run: Èmi kò wá láti parun, bíkòṣe láti mú un ṣẹ.”12 Lẹ́hìnnáà Olùgbàlà, nípasẹ̀ Ètùtù ayérayé Rẹ̀, parí àwọn ìlànà, àwọn ìṣe, àti àwọn àṣà ayẹyẹ tí àwọn ọmọ Ísráẹ́lì ṣe ní àkókò náà. Ìrúbọ ìgbẹ̀yìn rẹ̀ darí ìyípadà láti inú àwọn ìrúbọ sísun sí ìmújáde ti “ìrora àyà àti ìròbìnújẹ́ ọkàn,”13 kúrò nínú ìlànà ìrúbọ sí ìlànà ounjẹ-olúwa.

Ààrẹ M. Russell Ballard, ní kíkọ́ni lórí ẹ̀kọ́ náà, wípé, “Nínú ọgbọ́n kan, ìrúbọ nyípadà látinú ẹbọ ọrẹolùrúbọ.”14 Nígbàtí, a bá mú ẹbọ ọrẹ wa wá sọ́dọ̀ Olùgbàlà, à npè wá láti rí nípa Jésù Krístì síi nínú ayé wa, bí a ti nfi ìrẹ̀lẹ̀ fi ìfẹ́ wa sí I ní ìdámọ̀ àti níní òyè ìtẹríba pípé Rẹ̀ sí ìfẹ́ Baba. Nígbàtí a bá fi ìwò wa sórí Jésù Krístì, a damọ̀ a sì ní òye pé Òun ni orísun àti ọ̀nà nìkan láti gba ìdáríjì àti ìràpadà, àní sí ìyè ayérayé àti ìgbéga.

Gẹ́gẹ́bí ọmọlẹ́hìn ihinrere àkọ́kọ́, mo pàdé ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n ṣàkíyèsí tí wọ́n sì rí àwọn ìyípadà nínú àwọn ìhùwàsí, ìṣe, àti àwọn yíyàn mi lẹ́hìn tí mo darapọ̀ mọ́ Ìjọ. Wọ́n ní ìtara nípa “kínìdí” ohun tí wọ́n nrí—ìdí tí mo fi yàn láti ṣe ìrìbọmi kí nsì darapọ̀ mọ́ èyí ìjọ àwọn onígbàgbọ́, àní Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn; ìdí tí mo fi yẹra fún àwọn ìṣe kan pàtó ní ọjọ́ Ìsinmi, ìdí tí mo fi jẹ́ olóotọ́ ní pípa Àwọn Ọ̀rọ̀ Ọgbọ́n mọ́; ìdí tí mo fi nka Ìwé ti Mọ́mọ́nì, ìdí tí mo fi gbàgbọ́ nínú tí mo sì nṣàkópọ̀ àwọn ẹ̀kọ́ wòlíì àti àpósítélì óde-òní sínú ìgbésí ayé mi; ìdí tí mo fi nlọ sí àwọn ìpàdé Ìjọ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀; ìdí ti mo fi npe àwọn elòmíràn láti “wá wò, wá ṣèrànwọ́,wá dúró,”15 kí ẹ sì “wá wà pẹ̀lú.”16

Ni akoko náà, awọn ibeere wọ̀nnì dàbí pé ó bonimọ́lẹ̀ àti, mímọ́gaara nígbàmíràn, bí ìfisùn. Ṣùgbọ́n bí mo ṣe nṣe àyẹ̀wò pẹ̀lú ènìyàn, mo wá láti mọ̀ pé ṣíṣèwádii lóotọ́ jẹ́, ìpè mi àkọ́kọ́ láti gbé àti láti wọ awò-ojú méjì ti ẹmi láti ṣàlàyé, ìdojúkọ, àti ìmúlárale ohun tó ṣe ìmóríyá ìfaramọ́ mi sí àwọn ìṣe ìhìnrere àti àwọn ọ̀ṣùwọ̀n. Kíni orísun ẹ̀rí mi? Njẹ́ mo nṣe “àwọn ìṣe ìta nìkan” láìsí gbígba àwọn ìṣe wọ̀nnì tó sopọ̀ mọ́ àwọn òfin Ọlọ́run láti “fi okun fún ìgbàgbọ́ [mi] nínú Krístì”16 tàbí ṣàfihàn òye pé Jesu Kristi nìkanṣoṣo ni orísun agbára nìkan nínú àwọn àkíyèsíi mi?

Nípa ìtiraka líle láti wo sí àti fún Jésù Krístì nínú gbogbo ìrònú àti ìṣe mi, a ṣí mi lójú, àti pé òye mi sì yára kánkán láti mọ̀ pé Jésù Krístì npè mí láti “wá sọ́dọ̀” Rẹ̀.18 Láti ìgbà ìbẹ̀rẹ̀ àkokò jíjẹ́ ọmọ ẹ̀yìn ní ìgbà èwe mi, mo lè rántí ìpè tí àwọn ìránṣẹ́ ìhínrere ṣe sí mi láti dara pọ̀ mọ́ wọn bí wọ́n ṣe nkọ́ àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin kan lẹ́kọ ìhìnrere níwọ̀n ọjọ́ orí mi. Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, ní ìjóko nínú ilé ọ̀kan lára ​​àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin wọ̀nyí, ìbéèrè jẹ́jẹ́ wọn ti kíni ìdí tí mo fi gbàgbọ́ gún mi lọ́kàn ó sì jẹ́ kí njẹ́ri fún wọn pẹ̀lú òye jíjinlẹ̀ nípa ìran Olúwa nípa àwọn ìmúnniṣe ti ẹ̀mí ti jíjẹ́ ọmọlẹ́hìn mi, ó sì ti tún ẹ̀rí mi ṣe ní lílọ síwájú.

Mo kẹ́kọ nígbànáà, gẹ́gẹ́bí mo ti mọ̀ nísisìyí, pé Olùgbàlà wa, Jésù Krístì, máa ndarí ẹsẹ̀ wa sí àwọn ilé ìjọsìn lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti jẹ nínú oúnjẹ Olúwa, sí ilé Olúwa láti dá májẹ̀mú pẹ̀lú Rẹ̀, sí àwọn ìwé mímọ́ àti àwọn ẹ̀kọ́ àwọn wòlíì láti kẹ́kọ àwọn ọrọ Rẹ̀. Ó ndarí ẹnu wa láti jẹ́ri nípa Rẹ̀, ọwọ́ wa láti gbésókè àti láti sìn gẹ́gẹ́bí Òun yíò ti gbésókè àti láti sìn, ojú wa láti rí ayé àti ara wa bí Òun ti ṣe—“gẹ́gẹ́bí wọ́n ti rí nítòótọ́, àti … bí wọ́n yóò ti rí.”17 Àti pé bí a ṣe njẹ́ kí Ó darí wa nínú ohun gbogbo, a gba ẹ̀rí pé “ohun gbogbo tọ́ka sí pé Ọlọ́run wà,”18 nítorí pé ibi tí a bá ti wá a, a ó rí I21—ní ọ̀kọ̀ọ̀kan àti gbogbo ọjọ́. Èyí ni mo jẹrí ni orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.

Tẹ̀