Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ìwà Rere ti Ọ̀rọ̀ náà
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2022


10:16

Ìwà Rere ti Ọ̀rọ̀ náà

Nípa báyìí a kẹ́kọ̀ọ́ pé ìwà rere wà nínú ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì ìgbàanì àti ti òde òní ní pàtónítorí pé àwọn ọ̀rọ̀ wọn jẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa.19

Nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì, a kà nípa ìpinnu pàtàkì kan tí wòlíì Álmà ṣe nínú ààyò ẹsẹ ti Ìwé Mímọ́. Ṣaájú kí a tó ṣe àtúnyẹ̀wò àwọn ọ̀rọ̀ wọnnì tí ó farajọ, ẹ jọ̀wọ́ ẹ ronú pẹ̀lú mi nípa àwọn ipò tí ó nira lábẹ́ èyítí a ti ṣe ìpinnu náà.

Àwọn ènìyàn kan, tí wọ́n npe ara wọn ní ará Sórámù, ti yapa kúrò lọ́dọ̀ àwọn ará Néfì1 tí wọ́n sì kórajọ sí ààlà ilẹ̀ náà nítòsí àwọn ará Lámánì.2 Àwọn ará Néfì ti ṣẹ́gun àwọn ará Lámánì ní àìpẹ́ púpọ̀ sẹ́hìn nínú ogun tí a kò rí irú rẹ̀ rí nínú èyí tí wọ́n pa ọ̀pọ̀ ẹgbẹẹgbẹ̀rún,3 ó sì jẹ́ “ẹ̀rù nlà pé àwọn ará Sórámù yíò wọ inú ìbaraṣe pẹ̀lú àwọn ará Lámánì, àti pé yíò jẹ́ ọ̀nà sí àdánù nlá.”4 Tayọ àwọn àníyàn ogun, Álmà ti gbọ́ pé àwọn ara Sórámù, tí wọ́n “ti ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní wíwàásù fún wọn,”5 ti nyípadà sí ìbọ̀rìṣà wọ́n sì “nyí àwọn ọ̀nà Olúwa po.”6 Gbogbo èyí wúwo púpọ̀ lórí Álmà ó sì jẹ́ “okùnfà ìbànújẹ́ nlá.”7

Ní rírí ara rẹ̀ nínú àwọn ipò dídíjú àti pípeniníjà wọ̀nyí, Álmà ronú nípa ohun tí ó yẹ ní ṣíṣe. Nínú ìpinnu rẹ̀, a ka àwọn ọ̀rọ̀ tí a pa mọ́ láti fún wa nímísí àti ìtọ́ni bí a ṣe nlọ kiri nínú àwọn ipò dídíjú àti pípeniníjà ti ọjọ́ wa.8

“Àti nísisìyí, bí ìwãsù ọ̀rọ̀ nã sì ṣe ní ipa nlá láti darí àwọn ènìyàn nã sí ipa ṣíṣe èyítí ó tọ́---bẹ̃ni, ó ti ní agbára tí ó tóbi jùlọ lórí ọkàn àwọn ènìyàn nã ju idà, tàbí ohun míràn tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí wọn rí---nítorínã Álmà rõ pé ó jẹ́ ohun tí ó tọ̀nà pé kí àwọn kí ó gbìyànjú ìwà rere ti ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.”9

Lára ọ̀pọ̀lọpọ̀ ojútùú tí ó ṣeé ṣe, ìgbàgbọ́ Álmà mú wọn gbé ara lé agbára ọ̀rọ̀ náà. Kìí ṣe àìròtẹ́lẹ̀ pé díẹ̀ nínú àwọn ìwàásù alágbára jùlọ tí a rí níbikíbi nínú ìwé mímọ́ ni a wàásù lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ lẹ́hìn ìpinnu náà. Nínú àwọn orí 32 ati 33 ti Álmà a ka ọ̀rọ̀ àsọyé rẹ̀ dángájíá lórí ìgbàgbọ́ nínú Olúwa Jésù Krístì, àti ní orí a rí àwọn ìkọ́ni pàtàkì ti Amulẹ́kì lórí Ètùtù ti Jésù Krístì.

Àwọn àpèjúwe Ìwà Rere ti Ọ̀rọ̀ náà

Nítòótọ́, jákèjádò ìwé mímọ́ a kà nípa àwọn ìbùkún ìyanu tí a tú jáde sórí àwọn wọnnì tí wọ́n ti yàn láti gbìyànjú ìwà rere ti ọ̀rọ̀ Ọlọrun nínú ìgbésí ayé wọn.10 Mo pè yín láti ronú lórí àwọn àpẹẹrẹ mẹ́ta pẹ̀lú mi bí a ṣe nyí ìfojúsùn wa sí Ìwé ti Mọ́mọ́nì—ìwé kan tí Ààrẹ Russell M. Nelson júwe bí “ìtọ́sọ́nà ìwàláàyè ọjọ́-ìkẹhìn wa.”11

Lákọ̀ọ́kọ́, ní rírán àwọn ènìyàn rẹ̀ létí bí Olúwa ṣe gba àwọn baba wọn là, Álmà kọ́ni: “Kíyèsĩ, ó yí ọkàn wọn padà; bẹ̃ni, ó ta wọ́n jí kúrò nínú õrun àsùnwọra, wọn sì tají sí ìpè Ọlọ́run. Kiyesi i, wọn wà ni ãrin òkunkun; bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀, ọkàn wọn ní ìmọ́lẹ̀ ọ̀rọ̀ ayérayé náà tàn.”12 Bóyá ẹ nímọ̀lára bí ẹnipé ẹ wà láarín òkùnkùn. Njẹ́ ọkàn yín ní ìrora fún ìtànná? Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, jọ̀wọ́ gbìyànjú ìwà-rere ti ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

Èkejì, ní ríronú lórí bí Olúwa ti yí àwọn ará Lámánì padà, èyí tí ó jẹ́rìí gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́-ìhìnrere kan, Ámọ́nì wí pé, “Kíyèsĩ, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn arákùnrin wa méloó ni ó ti tú kúrò nínú ìrora ọ̀run àpáàdì; a sì mú wọn wá láti kọrin ìfẹ́ ìràpadà, àti èyí nítorí agbára ọ̀rọ̀ rẹ̀tí ó wà nínú wa.13 Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló wà nínú wa tí wọ́n npòùngbẹ fún ẹnìkan tí a fẹ́ràn láti mú wá láti kọrin ìfẹ́ ìràpadà. Nínú gbogbo ìsapá wa, ẹ jẹ́ ká rántí láti dán ìwà rere ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wò, èyí tó wà nínú wa.

Ìkẹ́ta, nínú Ìwé ti Hẹ́lámánì a kà pe, “Bẹ́ẹ̀ni, a ríi pé ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ lè di ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú, èyítí ó yára tí ó sì lágbára, tí yíò sì pín gbogbo ẹ̀tàn àti ìkẹ́kùn àti ọgbọ́n àrékérekè èṣù nnì,tí yíò sì darí ọkùnrin [àti obìnrin] ẹnití ó gba Krístì gbọ́ ní ipa ọ̀nà èyítí ó há tí ó sì ṣe tóóró lórí ọ̀gbun ìbànújẹ́ ayérayé … láti gbé ẹ̀mí wọn sí … ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run ní ìjọba ọ̀run.”14 Njẹ́ ẹ nwá láti gé gbogbo ẹ̀tàn àti àwọn ìdẹkùn àti àwọn àrekérekè èṣù lulẹ̀ ní àwọn ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ ti ọjọ́ wa bí? Njẹ́ ẹ fẹ́ láti tú àwọn ìdàrúdàpọ̀ àwọ̀sánmà ká tí ó wá nípasẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàyé láti lè dojúkọ díẹ̀ síi ní ọ̀kan sí ipa ọ̀nà májẹ̀mú? Jọ̀wọ́ gbìyànjú ìwà rere ti ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

Gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a ti yí padà nípasẹ̀ agbára ọ̀rọ̀ náà, èmi fúnra mi jẹ́rìí sí òtítọ́ yìí bí a ti kọ́ni dáradára to bẹ́ẹ̀ láti ọwọ́ wòlíì wa olùfẹ́, Ààrẹ Russell M. Nelson pé: “Fún èmi, agbára Ìwé ti Mọ́mọ́nì fara hàn jù lọ nínú ìyípadà nlá tó nwá sínú ìgbésí ayé àwọn tó nkà á ‘pẹ̀lú ọkàn tòótọ́, pẹ̀lú èrò inú tòótọ́, níní ìgbàgbọ́ nínú Kristi’. Ọ̀pọ̀ àwọn tí a ti yí lọ́kàn padà ṣe ìkọsílẹ̀ ohun púpọ̀ tí wọ́n fi ìgbà kan rí yàn láàyò kí wọ́n ó lè ṣègbọràn sí àwọn ìlànà inú ìwé náà. … Yìó jẹ́ ohun èlò tí ó dára jù lọ fún yín ní mímú àwọn ẹ̀mí wá sọ́dọ̀ Jésù Krístì.”15

Orísun Ìwà rere

Nínú ìwọ̀nyí àti àwọn àpèjúwe mìíràn, a jẹ́rìí sí ìwà rere ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nínú ìgbésí ayé àwọn ọmọ Rẹ̀. A lè béèrè, kíni orísun ìwà rere tàbí agbára náà?

Bí a ṣe ngbé ìbéèrè yí yẹ̀wo, ó ṣe pàtàkì láti rántí pé gbólóhùn “ọ̀rọ̀ náà,” bí a ṣe lò ó nínú ẹsẹ ìwé mímọ́, ní ìtumọ̀ méjì, ó kéré tán. Alàgbà David A. Bednar kọ́ni láìpẹ́ pé “ọ̀kan lára ​​orúkọ Jésù Kristi ni ‘Ọ̀rọ̀ náà,’” àti pé “àwọn ẹ̀kọ́ Olùgbàlà, gẹ́gẹ́bí a ti kọ ọ́ sínú àwọn ìwé mímọ́, pẹ̀lú ni ‘ọ̀rọ̀ náà.’”17

Wòlíì Néfì ṣe àpèjúwe ìbáṣepọ̀ tó wà ní àárín àwọn ìtumọ̀ méjèèjì yìí nígbà tí ó kọ̀wé pé: “Ẹ fetí sí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí kí ẹ sì gba Kristi gbọ́; bí ẹ kò bá sì gba ọ̀rọ̀ wọ̀nyí gbọ́, ẹ gba Kristi gbọ́. Bí ẹ̀yin bá sì gbàgbọ́ nínú Krístì ẹ̀yin yíò gbàgbọ́ nínú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, nítorí wọ́n jẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ Krístì, ó sì ti fi wọ́n fún mi.”18 Nípa báyìí a kẹ́kọ̀ọ́ pé ìwà rere wà nínú ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì ìgbàanì àti ti òde òní ní pàtó nítorí pé àwọn ọ̀rọ̀ wọn jẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa.19 Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, gbígbà òtítọ́ ayérayé yìí ṣe kókó fún ìwàláàyè wa nípa ti ẹ̀mí ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn20 nígbàtí, bí a ti sọtẹ́lẹ̀, “ìyàn kan wà ní ilẹ̀ náà, kì í ṣe ìyàn oúnjẹ, tàbí òùngbẹ omi, bí kò ṣe ti gbígbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ Ọlọrun.”21

Nígbẹ̀hìn, iwa rere ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Jésù Krístì Olúwa.22 Bí a ṣe nní òye èyí ní kíkún, a lè ṣe ìsopọ̀ tó ṣe pàtàkì títí ayérayé láàrín ipa ti àwọn wòlíì Rẹ̀ àti Olùràpadà fúnra Rẹ̀. Ìfẹ́ wa fún Un, ìfẹ́ inú wa láti sún mọ́ Ọ síi àti láti dúró nínú ìfẹ́ Rẹ̀,23 yíò fi ipá mú wa láti dán ìwà rere ti ọ̀rọ̀ náà wò nínú ayé wa—àti ìwà rere tí nṣàn láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ bí Olùgbàlà àti Olùràpadà ara ẹni wa24 àti ìwà rere tí nṣàn láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ nípasẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ ti “àwọn àṣàyàn ohun èlò ti Olúwa.”25 A ó wá mọ̀ pé, bí àwọn orísun míràn ṣe lè jẹ́ ìrànwọ́ tó nínú síṣe àṣàrò wa nípa Olùgbàlà àti àwọn ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì Rẹ̀, wọn kò gbọ́dọ̀ di arọ́pò fún wọn láé. A gbọ́dọ̀ máa mu jinlẹ̀ àti nígbàgbogbo,26 tààrà láti orísun náà.27

Mo fi ìfẹ́ mi hàn sí olúkúlùkù yín, ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi. Nínú ìfẹ́ náà, mo bẹ̀ yín láti ní ìrírí ìwà rere ti ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ní pàtàkì nípasẹ̀ Ìwé ti Mọ́mọ́nì, ní gbogbo ọjọ́ ayé yín. Bí ẹ ti nṣe bẹ́ẹ̀, ẹ ó ní ìrírí ìlérí ti wòlíì yí láti ẹnu Ààrẹ Russell M. Nelson pé: “Mo ṣèlérí pé bí ẹ ti nfi pẹ̀lú àdúrà ṣe àṣarò Ìwé ti Mọ́mọ́nì lójoojúmọ́, ẹ ó ṣe àwọn ìpinnu dídára si—lójoojúmọ́. Mo ṣe ìlérí pé bí ẹ ṣe njíròrò ohun tí ẹ ṣe àṣàrò rẹ̀, àwọn fèrèsé ọ̀run yíò ṣí sílẹ̀, ẹ ó sì gba àwọn ìdáhùn sí àwọn ìbèèrè ti ara yín àti ìdarí fún ìgbé ayé ti ara yín. Mo ṣe ìlérí pé bí ẹ ṣe nri ara yín sínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì lójoojúmọ́, ẹ ó lè ní àjẹsára ní ìdojúkọ àwọn ibi ọjọ́ òní.”28

Mo jẹ́rìí pé Baba wa Ọ̀run ti fún wa ní ọ̀rọ̀ náà nítorí pé Ó nífẹ̀ẹ́ wa ní pípé ó sì fẹ́ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa padà sílé láti gbé pẹ̀lú Rẹ̀ títí láé. Mo jẹ́rìí nípa “Ọ̀rọ̀ náà… tí ó di ẹran ara,”29 àní Jésù Krístì, àti ti agbára Rẹ̀ láti gbà wá là àti láti rà wá padà. Mo mọ̀ pé ìwà rere Rẹ̀ nṣàn nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì Rẹ̀, ti àtijọ́ àti ti óde òní.

Ó jẹ́ àdúrà ọkàn mi pé kí a lè ní ọgbọ́n àti ìrẹ̀lẹ̀ láti di ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú ṣinṣin30 kí a sì dúró ní ọ̀nà májẹ̀mú tí ndarí sí ìgbéga àti ìyè ayérayé.31 Njẹ́ kí á le ni ìrírí ìyípadà nla tí ó wà fún ẹnikọ̀ọ̀kan wa nípasẹ̀ ìwà rere Ọrọ̀ náà.32 Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Wo Álmà 30:59.

  2. Wo Álmà 31:3.

  3. Wo Álmà 28:2.

  4. Álmà 31:4. Jọ̀wọ́ ṣe àkíyèsí pé Álmà àti àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ìrírí irú “ìbáramu” tẹ́lẹ̀ láàrín àwọn ará Ámlísì àti àwọn ará Lámánì, èyítí ó yọrísí ìbànújẹ́ nlá àti àdánù (wo Álmà 2:21–38and Álmà 3:1–3

  5. Álmà 31:38.

  6. Álmà 31:1.

  7. Álmà 31:2.

  8. Wo Mọ́mọ́nì 8:34–35.

  9. Álmà 31:5; àfikùn àtẹnumọ́.

  10. Wo, fún àpẹrẹ, 1 Néfì 15:24; Álmà 32:41–43; 36:26; 37:8, 44–45.

  11. Russell M. Nelson, ““Ẹ Gba Ọjọ́ iwájù Mọ́ra pẹ̀lú Ìgbàgbọ́,” Làìhónà, Oṣù Kọkànla 2020, 75.

  12. Álmà 5:7; àfikùn àtẹnumọ́.

  13. Álmà 26:13; àfikùn àtẹnumọ́.

  14. Hẹ́lámánì 3:29–30; àfikún àtẹnumọ́.

  15. Russell M. Nelson, “Ìwé ti Mọ́mọ́nì: A Miraculous Miracle” (ọ̀rọ̀ tí a fifúnni ní ibi ìdanilẹkọ fún àwọn ààrẹ tuntun míṣọ̀n, June 23, 2016), títọ́ka ní apákan Mórónì 10:4

  16. David A. Bednar, “Ṣùgbọ́n Àwa Kò Kíyèsí Sí Wọn,” Liahona, May 2022, 16.

  17. 2 Néfì 33:10àfikùn àtẹnumọ́.

  18. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 1:38

  19. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 1:14-18

  20. Ámọ́sì 8:11

  21. Wo Álmà 34:6

  22. Wo Jòhánù 15:10

  23. Wo Markù 5:25–34

  24. Mórónì 10:32

  25. “Ọ̀nà tí ó dára jùlọ wà láti múra sílẹ̀, nítorí ìgbàgbọ́ nlá ní ìgbésí ayé kúkurú. A lè pinnu láti tẹra mọ́ ṣíṣàṣàrò àwọn ọ̀rọ̀ Kristi nínú àwọn ìwé mímọ́ àti ẹ̀kọ́ àwọn wòlíì alààyè. Èyí ni ohun tí èmi ó ṣe. Èmi yíò padà sí Ìwé ti Mọ́mọ́nì láti mu jìnlẹ̀ àti nígbàgbogbo” (Henry B. Eyring, “Ìmúrasílẹ̀ Ẹ̀mí: Bẹ̀rẹ̀ ní kùtùkùtù kí o Dúróṣinṣin,” LàìhónàOṣù Kọkànlá 2005, 39).

  26. “Fún mi, kíkà àwọn ìwé mímọ́ kìí ṣe ìwé mímọ́ ní ìlépa síkọ́lásìpù. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìfẹ́ ni ọ̀rọ̀ Olúwa àti ti àwọn wòlíì rẹ̀. …

    Èmi ko ṣe àníyàn ara mi púpọ̀ pẹ̀lú kíkà àwọn ìwé àsọyé gígùn tí a ṣe ọnà fún láti gbòòrò ní gígùn lórí èyítí ó wà nínú àwọn ìwé mímọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, mo fẹ́ràn láti máa gbé pẹ̀lú orísun náà, kí ntọ́ omi àìlábàwọ́n ti ìpìlẹ̀ òtítọ́ wò—ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ó ti fi fúnni àti gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sínú àwọn ìwé tí a gbà gẹ́gẹ́ bí ẹsẹ Ìwé Mímọ́. … Nípa kíka àwọn ìwé mímọ́, a lè jèrè ìdánilójú ti Ẹ̀mí pé ohun tí a kà ti wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run fún ìmọ́lẹ̀, ìbùkún, àti ayọ̀ àwọn ọmọ rẹ̀” (Gordon B. Hinckley, “Ṣíṣe Àpèjẹ Lórí Àwọn Ìwé Mímọ́,” Tambuli, June 1986, 2, 4).

  27. Wo Russell M. Nelson, “Ìwé ti Mọ́mọ́nì: Kíni Ìgbé Ayé Rẹ̀ Yíò Jẹ́ Láìsí Rẹ̀?,” Liahona, Nov. 2017, 60.

  28. John 16:33

  29. Wo 1 Néfì 8:30

  30. Ipá ọ̀nà májẹ̀mú ni ipá ọ̀nà kanṣoṣo tí ó ndarí sí ìgbéga àti ìye ayérayé” (Russell M. Nelson, “Agbára Ipa ti Ẹ̀mí,” Làìhónà, Oṣù Karun 2022, 98).

  31. Wo Álmà 5:11–13