Jẹ́ Olõtọ sí Ọlọ́run àti Iṣẹ̀ Rẹ̀
Gbogbo wa nílò láti wá ẹ̀rí ti ara wa nípa Jésù Krístì, kó ara wa níjánu, ronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, kí a sì jẹ́ olotitọ sí Ọlọ́run àti Iṣẹ̀ Rẹ̀
Ní Oṣù kẹwá tó kọjá, a fún mi níṣẹ́, lẹgbẹ pẹ̀lú Ààrẹ M. Russell Ballard àti Alàgbà Jeffrey R, Holland, láti bẹ United Kingdom wo, níbití gbogbo àwa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ti sìn bí ọ̀dọ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere. A ní ànfàní kíkọ́ni àti jijẹri, bákannáà bí a sì ṣèrántí àkọ́ọ̀lẹ̀ ìtàn ìṣáájú Ìjọ ní Erékùṣù British níbití baba-baba-baba Heber C. Kimball àti àwọn ẹlẹ́gbẹ́ rẹ̀ ti jẹ́ ìránṣẹ ìhìnrere àkọ́kọ́.1
Ààrẹ Russell M. Nelson, nfi wá ṣe yẹ̀yẹ́ nípa iṣẹ́ yí, ó ṣe akíyèsí pé ó rí bákan láti yan Àpóstélì mẹta láti bẹ agbègbè tí wọ́n ti sìn bí àwọn ọ̀dọ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere. Ó jẹ́wọ́ pé gbogbo ènìyàn ní ìfẹ́ láti di yíyàn lọ ṣèbẹ̀wò míṣọ̀n àtètèkọ́ṣe wọn. Pẹ̀lú ẹ̀rín nlá ní ojú rẹ̀, ní ṣókí ó ṣàlàyé ohun tí ó ti sọ sẹ́hìn pé bí ẹgbẹ́ àwọn Àpóstélì mẹ́ta míràn bá wà tí wọ́n ti sìn ní míṣọ̀n kannáà ní bíi ó lé ní ọ́gọ́tá ọdún sẹ́hìn, nígbànáà wọ́n lè gbà irú iṣẹ́ yíyànfúnni bẹ́ẹ̀ bákannáà .
Ní ìmúrasílẹ̀ fún iṣẹ́ náà, mo tún Ìgbé ayé Heber C. Kimballtí a kọ láti ọwọ́ ọmọ-ọmọ kan kà, Orson F. Whitney, ẹnití a pè sí ipò àpóstélì. Àkópọ̀ yí ni a fún mi láti ọwọ́ ìyá mi iyebíye nígbàtí mo fẹ́rẹ̀ tó ọmọ ọdún méje. A ṣẹ̀ṣẹ̀ nmúrasílẹ̀ láti lọ sí ìyàsímímọ́ ti Èyí Ni Ibi Ìrántí Náà ní Ọjọ́ Kẹrìnlélógún Oṣù Kéje, 1947 nípasẹ̀ Ààrẹ George Albert Smith.2 Ó nfẹ́ kí èmi mọ̀ síi nípa babanla mi, Heber C. Kimball.
Ìwé náà ní ẹ̀là-ọ̀rọ̀ jíjinlẹ̀ tí a fi fún Ààrẹ Kímball nínú tí ó ṣe pàtàkì fún ọjọ́ wa. Ṣíwájú kí a tó pín ẹ̀là-ọ̀rọ̀ náà, ẹ jẹ́ kí npèsè àtilẹ̀bá díẹ̀.
Nígbàtí a ti Wòlíì Joseph Smith mọ́lé ní Liberty Jail, àwọn Àpóstélì Brigham Young àti Heber C. Kimball ní ojúṣe, lábẹ́ àwọn ipò búburú líle, ti bíbojútó kíkólọ àwọn Ènìyàn Mímọ́ kúrò ní Missouri. Kíkólọ náà ni a nílò ní ipa títóbi nítorí ti àṣẹ lílénikúrò tí a gbà láti ọ̀wọ́ Gómìnà Lilburn W. Boggs.3
Ó fẹ́rẹ̀ tó bí ọgbọn ọdún lẹ́hìnnáà Heber C. Kimball, tí ó wà nínú Àjọ Ààrẹ Ìkínní nígbànáà, ní ríronú lórí àkọọ́lẹ̀ ìtàn yí pẹ̀lú ìran titun, kọ́ni pé, “Ẹ jẹ́ kí èmi sọ fún yín, pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ lára yín yíò rí ìgbà tí ẹ ó ní gbogbo wàhàlà, àdánwò àti inúnibíni tí ẹ lè dojúkọ, àti àwọn ànfàní púpọ̀ láti fi hàn pé ẹ jẹ́ olõtọ́ sí Ọlọ́run àti iṣẹ́ Rẹ̀.”4
Heber tẹ̀síwájú: “Láti pàdé àwọn ìṣòro tí ó nbọ̀, ó máa pọndandan fún yín láti ní ìmọ̀ òtítọ́ ti iṣẹ́ yí fún arayín. Àwọn ìṣòro nà yíò jẹ́ irú ìwà tí ọkùnrin tàbí obìnrin tí kò bá ní ìmọ̀ araẹni yí tàbí jẹri rẹ̀ yíò ṣubú. Bí ẹ kò bá tíi ní ẹ̀rí, ẹ gbé ìgbé ayé títọ́, kí ẹ sì ké pe Olúwa kí ẹ máṣe dáwọ́dúró títí ẹ ó fi gbà á. Bí ẹ kò bá ṣe bẹ́ẹ̀ ẹ kò ní dúró. … Àkokò yíò dé nígbàtí ọkùnrin tàbí obìnrin kò lè dúró lórí ìmọ́lẹ̀ yíyá. Ẹnìkọ̀ọ̀kan yíò níláti jẹ́ títọ́sọ́nà nípa ìmọ́lẹ̀ nínú ararẹ̀. … Bí ẹ kò bá ní i ẹ kò ní dúró; nítorínáà ẹ wá ẹ̀rí Jésù kí ẹ sì dìí mú, nítorí ìgbà tí àkokò ìgbìyànjú bá dé ẹ kò ní tàgbọ̀ngbọ̀n kí ẹ sì ṣubú.”5
Ẹnìkọ̀ọ̀kan wa nílò ẹ̀rí araẹni nípa iṣẹ́ Ọlọ́run6 àti ipa pàtàkì ti Jésù Krístì. Ìpin 76th ti Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú tọ́ka sí ipò ológo mẹ́ta ó sì fi ògo Sẹ̀lẹ́stíà wé òòrùn. Nígbànáà ó fi ìjọba tẹ̀rrẹ́stíà wé òṣùpá.7
Ó dùnmọ́ni pé òòrùn ní ìmọ́lẹ̀ ti ararẹ̀, ṣùgbọ́n òṣùpá ni ó nfi ìmọ́lẹ̀ hàn tàbí “ìmọ́lẹ̀ yíyá.” Sísọ̀rọ̀ ìjọba tẹ̀rẹ́stríà, ẹsẹ 79 wí pé, “Ìwọ̀nyí ni àwọn ẹnití wọn kò ní ìgboyà nínú ẹ̀rí ti Jésù.” A kò lè gba ìjọba Sẹ̀lẹ́stíà àti gbígbé pẹ̀lú Ọlọ́run Baba lórí ìmọ́lẹ̀ yíyá; a nílò ẹ̀rí arawa nípa Jésù àti ìhìnrere Rẹ̀.
À ngbé nínú ayé nibití ẹ̀ṣẹ̀ ti wà níbigbogbo8 tí ọkàn sì nyí kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run nítorí ìlànà ènìyàn.9 Ọ̀kan lára àwọn àpẹrẹ líle nínú ìwé mímọ́ ti àwọn àníyàn Heber C. Kimball nípa wíwá ẹ̀rí iṣẹ́ Ọlọ́run àti Jésù Krístì ni a gbékalẹ̀ nínú ìmọ̀ràn Alma sí àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta—Hẹ́lámánì, Ṣííblónì, àti Kọ́ríántónì.10 Méjì lára àwọn ọmọ rẹ̀ jẹ́ olõtọ́ sí Ọlọ́run àti iṣẹ́ Rẹ̀. Ṣùgbọ́n ọmọ kan ṣe àwọn ìpinnu búburú. Sí mi, pàtàkì àmọ̀ràn tìtóbi jùlọ ti Álmà ni pé ó nfi fúnni bíi baba fún èrè ti àwọn ọmọ ararẹ̀.
Àníyàn rẹ̀ àkọ́kọ́, bíiti Heber C. Kimball, ni pé ẹnìkọ̀ọ̀kan ní ẹ̀rí Jésù Krístì áti láti jẹ́ olotitọ sí Ọlọ́run àti iṣẹ̀ Rẹ̀.
Nínú ìkọ́ni olókìkí Álmà sí ọmọ rẹ̀ Hẹ́lámánì, ó ṣe ìlérí ìjìnlẹ̀ pé àwọn tí wọ́n “fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sínú Ọlọ́run yíò gba àtìlẹhìn nínú àwọn àdánwò wọn, àti wàhálà wọn, àti ìpọ́njú wọn, a ó sì gbé wọn ga ní ọjọ́ ìkẹhìn.”11
Nígbàtí Álmà ti gba ìfihàn níbití ó ti rí àngẹ́lì, èyí ṣọ̀wọ́n. Ìtẹ̀mọ́ra tí a ṣe nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ jẹ jíjọra síi. Ìtẹ̀mọ́ra wọ̀nyí lè dọ́gba bí àwọn ìfihànni ti ángẹ́lì pàtàkì. Ààrẹ Joseph Fielding Smith kọ́ni: “Ìtẹ̀mọ́ra lórí ẹ̀mí tí ó nwá látinú Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe pàtàkì púpọ̀ ju ìran lọ. Nígbàtí Ẹ̀mí nsọ̀rọ̀ sí ẹ̀mí, ìtẹ̀mọ́ lórí ẹ̀mí ṣóro gan ju nínù kúrò.”12
Èyí ndarí wa sí àmọ̀ràn Álmà sí ọmọ rẹ̀ kejì, Ṣíbúlónì. Ṣíbúlónì jẹ́ olódodo bíiti arákùnrin rẹ̀ Hẹ́lámánì. Àmọ̀ràn tí mo fẹ́ láti tẹnumọ́ ni Álmà 38:12èyí tí ó kà ní apákan pé, “Ri pé ó kó ara rẹ̀ níjánu, kí ìwọ ba lè kún fún ìfẹ́.“
Ìjánu ni ọ̀rọ̀ dídùnmọ́ni kan. Nígbàtí a bá gùn ẹṣìn, à nlo ìjánú láti tọ́ọ sọ́nà. Ìjọra rere lè jẹ́ tààrà, ìdarí, tàbí ìdádúró. Májẹ̀mú Láéláé wí fún wa pé a kígbe fún ayọ̀ nígbàtí a kọ́ pé a ó ní ẹran ara.13 Ara kìí ṣe ibi—ó lẹ́wà ó sì jẹ́ pàtàkì—ṣùgbọ́n àwọn ìnúfùfù, bí a kò bá lòó dáadáa kí a sì nijanu títọ́, ó lè yà wá kúrò ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run àti iṣẹ́ Rẹ̀ kí ó sì ní ìpa lára fún ẹ̀rí wa.
Ẹ jẹ́ kí a sọ̀rọ̀ nípa ìnúfùfù méjì ní pàtàkì—àkọ́kọ́, ìbínú àti èkejì, ìfẹ́kúfẹ́.14 O jẹ́ ìdùnmọ́ pé bí méjèèjì kò bá ní ìjánu tàbí ìdarí ó lè fa ẹ̀fọ́rí nlá, dínkù ní agbára Ẹ̀mí, kí ó sì yà wá sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run àti iṣẹ́ Rẹ̀. Ọ̀tá nlo gbogbo ànfàní láti kún inú ayé wa pẹ̀lú àwọn àwòrán ìjà àti ìwà àìmọ́.
Nínú àwọn ẹbí kan, ó jẹ́ àìwọpọ̀ fún onínúfùfù ọkọ̀ tàbí ìyàwó láti gbá lọ́kọláyà tàbí ọmọ kan. Ní Oṣù Kéje mo kópa nínú Gbogbo Ẹgbẹ́ Òṣèlú Ìjọba ní London.15 Ìjà ní àtakò sí àwọn obìnrin àti ọ̀dọ́ ni a fi àmì sí bí wàhálà pàtàkì àgbáyé. Ní àfikún sí ìjà, àwọn míràn ti wà nínú ìlòkulò ìsọ̀rọ̀. Ìkéde lórí ẹbí wí fún wa pé “àwọn tí wọ́n lo lọ́kọláya tàbí irú-ọmọ nílòkulò yíò dúró ní ìjinyìn níwájú Ọlọ́run nijọ́kan.”16
Ààrẹ Nelson tẹnumọ́ eléyi kíkankíkan ní òwúrọ̀ àná.17 Ẹ jọ̀wọ́ ẹ sé ọkàn yín le ní ìkàsí ti bóyá àwọn òbí yín lò yín nílòkulò tàbí wọn kò lò yín, ẹ kò ní lo lọ́kọláya tàbí àwọn ọmọ yín nílòkulò níti ara tàbí níti ọ̀rọ̀.
Ní ọjọ́ wa ọ̀kan lára àwọn ìpènijà pàtàkì jùlọ ni ìjà àti ìlòkulò ọ̀rọ̀ tì o bá àwọn ọ̀ràn ti àwùjọ mu. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀ràn ìbínú àti èdè ìlòkulò ti rọ́pò èrèdí, ìbárasọ̀rọ̀, àti ọ̀làjú. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti pa ìkìlọ̀ Àpóstélì àgbà Olùgbàlà, Pétérù, láti wá àwọn ìwà bíiti Krístì bí irú ìpamọ́ra, sùúrù, ìwà-bí-Ọlọ́run, inúrere arákùnrin, àti ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́.17 Bákannáà wọ́n ti pa ìwà ìrẹ̀lẹ̀ bíiti Krístì tì.
Ní àfikún láti darí ìbínú àti kíkó àwọn ìnúfùfù wa míràn níjánu, a nílò láti darí ìgbé ayé ìwà mímọ́ nípa dídarí àwọn èrò, èdè, àti ìṣe wa. A nílò láti yẹra fún ponógíráfì, yẹ títọ́ ohun tí à nwò nínú ilé wa wò kí a sì yẹra fún gbogbo ìṣe ti ẹ̀ṣẹ̀.
Èyí mú wa wá sí àmọ̀ràn Álmà sí ọmọ rẹ̀ Kòríántónì Yàtọ̀ sí arákùnrin rẹ̀, Hẹ́lámánì àti Ṣ̣íblónì, Kòríántónì wà nínú ìwà ìrékọjá.
Nítorí Kòríántónì ti wà nínú ìwà àìmọ́, ó ṣe kókó fún Álmà láti kọ nípa ìrònúpìwàdà. Òun níláti kọ́ ọ ní lílekoko ẹ̀ṣẹ̀ áti bí yíò ti ronúpìwàdà lẹ́hìnnáà .18
Nítorínáà, ìmọ̀ràn ìdáàbòbò ti Álmà ni láti kó ìjánu àwọn ìfẹ́ inú, ṣùgbọ́n ìmọ̀ràn rẹ̀ fún àwọn tí wọn ti rékọjá ni láti ronúpìwàdà. Ààrẹ Nelson fún àwọn ọmọ ìjọ ní àmọ̀ràn jíjinlẹ̀ lórí ìrònúpìwàdà ní ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin 2019. Ó mu hàn kedere pé ìrònúpìwàdà ojojúmọ́ ni pàtàkì ara ìgbé ayé wa. “Ìronúpìwàdà kìí ṣe ìṣẹ̀lẹ̀ kan; ètò kan ni. Ó ṣe kókó sí ìdùnnú àti àláfíà ọkàn,” ni ó kọ́ni. “Ìronúpìwàdà ojoojúmọ́ ni ipá ọ̀nà sí ìwẹ̀mọ́, àti pé ìwẹ̀mọ́ nmú agbára wá.”19 Bí Kòríántónì bá ti ṣe ohun tí Ààrẹ Nelson gbàmọ̀ràn, òun yíò ti ronúpìwàdà ní àìpẹ́ bí ó ti bẹ̀rẹ̀ láti fi ààyè gba àwọn èrò àìmọ́. Àwọn kókó ìrékọjá kò ní níláti ṣẹlẹ̀.
Píparí àmọ̀ràn tí Álmà fún àwọn ọmọ rẹ̀ ni àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì jùlọ nínú gbogbo ìwé mímọ́. Ó bá Ètùtù tí a ṣe nípasẹ̀ Jésù Krístì mu.
Álmà jẹri pé Krístì yíò mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò.20 Láìsí Ètùtù Olùgbàlà, ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ayérayé ti ìdáláre yíò gba ìjìyà.21 Nítorí Ètùtù Olùgbàlà, àánú lè borí fún àwọn tí wọ́n ti ronúpìwàdà, ó sì le fi ààyè gbà wọ́n láti padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. A ó ṣe dáadáa láti jíròrò ẹ̀kọ́ pàtàkì yì.
Kò sí ẹnìkankan tí ó lè padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nípa iṣẹ́ rere ti ara rẹ lọ́kùnrin àti lóbìnrin nìkan; gbogbo wa nílò èrè ìrúbọ Olùgbàlà. Gbogbo wa ti ṣẹ, nípasẹ̀ Ètùtù Jésù Krístì nìkan ni a lè rí àánú gbà kí a sì gbé pẹ̀lú Ọlọ́run.22
Álmà bákannáà fi àmọ̀ràn ìyanu fún Kòríántónì fún gbogbo àwa tí a ti làá kọja tàbí a ó la ètò ìrònúpìwàdà kọjá láìka, bóyá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ náà kéré tàbí ó jẹ́ líle bíi àwọn wọnnì tí Kòríántónì dá. Ẹsẹ 29 ti orí 42 kà pé, “Àti nísisìyí, ọmọ mi, mo fẹ́ kí o máṣe jẹ́ kí àwọn ohun wọ̀nyí da ọkàn rẹ lãmu mọ́, jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ nìkan da ọkàn rẹ̀ lãmu, pẹ̀lú ìdãmú nnì èyítí yíò mú ọ bọ́ sí ipò ìrònúpìwàdà.”
Kòríántónì gbọ́ àmọ̀ràn Álmà àti pé àwọn méjèèjì ronúpìwàdà wọ́n sìn sìn pẹ̀lú ọlánlá. Nítorí Ètùtù Olùgbàlà, ìwòsàn wà fún gbogbo ènìyàn.
Ní ọjọ́ Álmà, ní ọjọ́ Heber, àti dájúdájú ní ọjọ́ wa gbogbo wa nílò láti wá ẹ̀rí ti ara wa nípa Jésù Krístì, kó ara wa níjánu, ronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, àti kí a sì rí àláfíà nípasẹ̀ Ètùtù Jésù Krístì kí a sì jẹ́ olotitọ sí Ọlọ́run àti Iṣẹ̀ Rẹ̀
Nínú ọ̀rọ̀ àìpẹ́ àti ìbákẹ́gbẹ́ ìròhìn tí Ààrẹ Russell M. Nelson lẹ̀ ó sọ ọ́ ní ọ̀nà yí pé: “Mo bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú yín láti gba àkóso ẹ̀rí yín nípa Jésù Krístì. Ṣiṣẹ́ fún un. Gbà á. Ṣe ìtọ́jú fún un. Ṣíkẹ́ rẹ̀ kí ó lè dagbà. Nígbànáà ẹ wo àwọn iṣẹ́ ìyanu láti ṣẹlẹ̀ nínú ayé yín.”23
Mo fi ìmoore hàn pé a ó gbọ́ ní ẹnu Ààrẹ Nelson nisisìyí. Mo jẹri pé Ààrẹ Russell M. Nelson ni wòlíì fún ọjọ́ wa. Mo nifẹ ìmísí àti ìtọ́nisọ́nà oníyanu tí à ngbà nípasẹ̀ rẹ̀.
Gẹ́gẹ́bí Àpóstélì Olúwa Jésù Krístì, mo jẹ́ ẹ`ẹ̀rí dídájú mi nípa àtọ̀runwá Olùgbàlà àti òdodo Ètùtù Rẹ̀ ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.