Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Tẹ̀lé Jésù Krístì pẹ̀lú Àwọn Ìṣísẹ̀ Ìgbàgbọ́
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2022


13:21

Tẹ̀lé Jésù Krístì pẹ̀lú Àwọn Ìṣísẹ̀ Ìgbàgbọ́

Ó le gbé wa lóni la àwọn àkókò ìṣoro já. Ó ṣe é fún àwọn aṣaájú àkọ́kọ́, ayé, Ó sì nṣeé nísisìyí fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wa.

Ẹ ṣeun, ẹ̀yin akọrin, fún kíkọrin “Ìgbàgbọ́ nínú Gbogbo Ìṣísẹ̀.” Dídún àti àwọn ọ̀rọ̀ orin náà ni a kọ ní 1996 láti ọwọ́ Arákùnrin Newell Dayley1 ní ìmúrasílẹ̀ fún àyẹyẹ àádọ́jọ ọdún ti dídé àwọn aṣaájú àkọ́kọ́ sí Àfonífojì Salt Lake ní 1847.

Bíótilẹ̀jẹ́pé a kọ orin yí ní ìmúrasílẹ̀ fún àyẹyẹ náà, àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ wúlò fún gbogbo aráyé.

Ìgbà gbogbo ni mo nfẹ́ràn ègbè rẹ̀:

Pẹ̀lú ìgbàgbọ́ ní gbogbo ìṣísẹ̀, a ntẹ̀lé Krístì, Olúwa;

Àti ní kíkún fún ìrètí nípasẹ̀ ìfẹ́ àìlábàwọ́n rẹ̀, a nkọrin pẹ̀lú ìfìmọ̀ṣọkan.2

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, mo jẹ́ ẹ̀rí pé bí a ti ntẹ̀lé Jésù Krístì pẹ̀lú àwọn ìṣísẹ̀ ìgbàgbọ́, ìrètí wà. Ìrètí wà nínú Olúwa Jésù Krístì. Ìrètí wà fún ẹni gbogbo nínú ayé yí. Ìrètí wà láti borí àwọn àṣìṣe wa, ìbànújẹ́ wa, ìtiraka wa, àti àwọn àdánwò àti ìdààmú wa. Ìrètí wà nínú ìrònúpìwàdà àti gbígba ìdáríjì àti nínú dídáríji àwọn ẹlòmíràn. Mo jẹri pé ìrètí àti àlàáfíà wà nínú Krístì. Ó le gbé wa lóni la àwọn àkókò ìṣoro já. Ó ṣe é fún àwọn aṣaájú àkọ́kọ́, ayé, Ó sì nṣeé nísisìyí fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wa.

Ọdún yí ṣe àmì ayẹyẹ ìkarũn lé ní àádọ́sãn 175th ọdún ti dídé àwọn aṣaájú àkọ́kọ́ sí àfonífojì Salt Lake, èyítí ó ti mú mi ronú lórí àwọn ará ìṣaájú mi, tí díẹ̀ nínú wọn rìn láti Nauvoo dé Àfonífojì Salt Lake. Mo ní àwọn òbí ti àwọn òbí mi àgbà tí wọ́n rìn ní orí pápá náà ní ìgbà ọ̀dọ́ wọn. Henry Ballard jẹ́ ẹni ogun ọdún;3 Margaret McNeil jẹ́ ọdún mẹ́tàlá;4 àti Joseph F. Smith, ẹnití ó di Ààrẹ kẹfà ti Ìjọ lẹ́hìnwá, jẹ́ ọdún mẹ́sãn péré nígbàtí ó dé sí Àfonífojì Salt Lake.5

Wọ́n dojúkọ àwọn àìní onírúurú ní ipa ọ̀nà náà, bí irú àwọn àkókò òtútù líle, àìsàn, àti àìní ànító aṣọ wíwọ̀ àti oúnjẹ. Fún àpẹrẹ, nígbàtí Henry Ballard wọ Àfonífojì Salt Lake, ó láyọ̀ ní rírí “Ilẹ̀ Ìlérí” ṣùgbọ́n ó gbé nínú ẹ̀rù pé ẹnìkan le rí òun nítorípé aṣọ tí ó wọ̀ ti gbó tóbẹ́ẹ̀ tí kò bo ara rẹ̀ tán. Ó fi ara rẹ̀ pamọ́ lẹ́hìn àwọn igbó ní gbogbo ọjọ́ títí tí ilẹ̀ fi ṣú. Nígbànáà ó lọ sí ilé kan ó sì tọrọ aṣọ kí ó le tẹ̀síwájú nínú ìrìnàjò rẹ̀ kí ó sì rí àwọn òbí rẹ̀. Ó kún fún ọpẹ́ sí Ọlọ́run pé ó dé ilé rẹ̀ ọjọ́ iwájú nínú ààbò.6

Àwọn òbí ti àwọn òbí mi àgbà tẹ̀lé Jésù Krístì pẹ̀lú àwọn ìṣísẹ̀ ìgbàgbọ́ ní gbogbo ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àdánwò wọn. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn fún àìrẹ̀wẹ̀sì wọn. Àwọn ìṣísẹ̀ ìgbàgbọ́ wọn ti bùkún èmi àti àwọn ìran tó nbọ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn ìṣísẹ̀ ìgbàgbọ́ yín lónĩ yío ṣe bùkún àwọn àtẹ̀lé yín.

Ọ̀rọ̀ náà aṣaájú jẹ́ ọ̀rọ̀ orúkọ àti ọ̀rọ̀ iṣe. Bíi ọ̀rọ̀ orúkọ ó le túmọ̀ sí ẹnìkan tí ó wà láàrin àwọn ẹni àkọ́kọ́ láti ṣe ìwádĩ tàbí tẹ̀dó sí ibi titun kan. Bíi ọ̀rọ̀ ìṣe, ó le túmọ̀ sí láti ṣí tàbí láti pésé ọ̀nà fún àwọn ẹlòmíràn láti tẹ̀lé.6

Bí mo ti nronú nípa àwọn aṣaájú tí wọ́n ti pèsè ọ̀nà fún àwọn ẹlòmíràn, mo kọ́kọ́ ronú nípa Wòlíì Joseph Smith. Joseph jẹ́ aṣaájú kan nítorípé àwọn ìṣísẹ̀ ìgbàgbọ́ rẹ̀ darí rẹ̀ sí ibi igbó ṣúúrú ti àwọn igi, níbití ó ti kúnlẹ̀ nínú àdúrà tí ó sì ṣí ọ̀nà fún wa láti ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere ti Jésù Krístì. Ìgbàgbọ́ Jósẹ́fù láti “béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run”7 ní òwúrọ̀ ìgbà ìrúwé náà ní 1820 ṣí ọ̀nà fún Ìmúpadàbọ̀sípò ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere ti Jésù Krístì, tí ó ní àwọn wòlíì áti áwọn àpóstélì nínú tí a pè láti sìn lórí ilẹ̀ ayé lẹ́ẹ̀kansíi.8 Mo jẹ́ri wípé mo mọ̀ pé Joseph Smith jẹ́ wòlíì Ọlọ́run. Mo mọ̀ pé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ tó kún fún ìgbàgbọ́ ló darí rẹ̀ láti kúnlẹ̀ níwájú Ọlọ́run Bàbá àti Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀ Jésù Krístì.

Àwọn ìṣísẹ̀ ìgbàgbọ́ ti Wòlíì Joseph fún un ní agbára láti jẹ́ ohun èlò Olúwa ní mímú Ìwé ti Mọ́mọ́nì jáde wá, èyítí í ṣe ẹ̀rí míràn ti Jésù àti oore ọ̀fẹ́ ètùtù Rẹ̀.

Mo jẹ́rí pé nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ àti ìfaradà Joseph Smith ní ìdojúkọ ìṣòro àti àtakò tí kò ṣeé fẹnu sọ, ó ṣeéṣe fún un láti jẹ́ ohun èlò ní ọwọ́ Olúwa ní síṣe àgbékalẹ̀Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn lẹ́ẹ̀kansíi sí aráyé.

Ní ìgbà ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò tí ó kẹ́hìn, mo sọ nípa bí íṣẹ́ ìránṣẹ́ ní kíkún mi ti bùkún mi. Mo di alábùkún fún bí mo ti nkọ́ni nípa ètò ìgbàlà ológo ti Baba Ọ̀run, Ìran Àkọ́kọ́ ti Joseph Smith, àti bí ó ti ṣe ìyírọ̀padà Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Àwọn ìkọ́ni àti ẹ̀kọ́ tí a mú padà sípò wọ̀nyí tọ́ àwọn ìṣísẹ̀ ìgbàgbọ́ mi ní kíkọ́ àwọn tí wọ́n fẹ́ láti fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ Ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere.

Àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere wa lóni jẹ́ àwọn aṣaájú ti òde òní nítorípé wọ́n npín ọ̀rọ̀ ológo yí pẹ̀lú àwọn ènìyàn ní àyíká ayé, nípa bẹ́ẹ̀ nṣí ọ̀nà fún àwọn ọmọ Baba Ọ̀run láti mọ̀ Òun àti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì. Títẹ́wọ́gba ìhìnrere Jésù Krístì nṣí ọ̀nà fún ẹni gbogbo láti múrasílẹ̀ fún àti láti gba àwọn ìlànà àti àwọn ìbùkún ti Ìjọ àti ti tẹ́mpìlì.

Ní ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò tí ó kẹ́hìn, Ààrẹ Russell M. Nelson tún ìdí rẹ̀ fi múlẹ̀ “pé Olúwa ti sọ fún gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó yẹ àti tí ó ní agbára láti múra fún kí wọn ó sì sìn ní míṣọ̀n kan” àti pé “míṣọ̀n jẹ́ ànfàní alágbára kan bákannáà, ṣùgbọ́n bí wọ́n bá fẹ́,” fún “ọ̀dọ́ àti akíkanjú àwọn arábìnrin.”9

Ẹyin ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin, àwọn ìṣísẹ̀ ìgbàgbọ́ yín yío ràn yín lọ́wọ́ láti tẹ̀lé ìpè Olúwa láti sìn ní àwọn míṣọ̀n—láti jẹ́ àwọn aṣaájú ti òde-òní—nípa ṣíṣí ọ̀nà fún àwọn ọmọ Ọlọ́run láti wá àti láti dúró ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú tó ndarí padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ tó lógo.

Ààrẹ Nelson ti jẹ́ aṣaájú nínú Ìjọ. Bí Àpóstélì ó ti rin ìrìnàjò sí ó sì ti ṣí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ilẹ̀ fún wíwàásù ìhìnrere. Bí ẹ ṣe ngbé ìgbé ayé làti yẹ fún ìbákẹ́gbẹ́ ti Ẹ̀mí Mímọ́, ní òtítọ́ ẹ̀yin “mú kí agbára ẹ̀mí yín pọ si lati gba ìfihàn.”10 Ó tẹ̀síwájú láti kọ́ wa bí a ó ṣe fún àwọn ẹ̀rí wa lókun. Nínú ìjọ́sìn kan fún àwọn ọ̀dọ́ ànìkanwà, ó sọ pé:

“Mo bẹ̀ yín láti wà ní ìkáwọ́ ẹ̀rí yín. Ẹ ṣiṣẹ́ fún un. Ẹ rí i bí tiyín Ẹ ṣe ìtọ́jú rẹ̀. Ẹ bọ́ ọ ki ó le dàgbà. …

“[Lẹ́hìnnáà] ẹ máa ṣọ́nà fún àwọn ìyanu nínú ayé yín.”11

Ó nkọ́ wa bí a ti le ní ìgbẹ́kẹ̀lé ara ẹni síi ní ti ẹ̀mí. Ó ti sọ pé, “Ní àwọn ọjọ́ tí ó nbọ̀, kò ní ṣeéṣe láti yè níti ẹ̀mí láìsí títọ́nisọ́nà, dídarí, titùnínú, àti agbára Ẹ̀mí Mímọ́ ní léraléra.”12

Mo jẹ́ri pé Ààrẹ Russell M. Nelson ni wòlíì Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé loni.

Olùgbàlà wa, Jésù Krístì, ni aṣaájú ìgbẹ̀hìn ní pípèsè ọ̀nà náà sílẹ̀. Nítòótọ́, Òun ni ọ̀nà”13 ún ètò ìgbàlà láti di mímúṣẹ kí a le ronúpìwàdà àti, nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Rẹ̀, kí a le padà sí ọ̀dọ̀ Baba wa Ọ̀run.

Jésù wípé, “èmi ni ọ̀nà, ati òtítọ́, ati ìyè: kò sí ẹnikẹ́ni tí ó le wá sí ọ̀dọ̀ Bàbá, bíkòṣe nípasẹ̀ mi.”14 Ó ti ṣèlérí láti máṣe fiwá sílẹ̀ láìsí olùtùnú; Òun yío tọ̀wá wá nínú àwọn àdánwò wa.15 Ó ti pè wá láti “wá sí ọ̀dọ̀ [Rẹ̀] pẹ̀lú gbogbo èrò ọkàn, [Òun] ó sì wò [wá] sàn.”16

Mo jẹ́ri pé Jésù Krístì ni Olùgbàlà àti Olùràpadà wa, Alágbàwí wa pẹ̀lú Bàbá. Baba wa Ọ̀run ti ṣí ọ̀nà fúnwa láti padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ nípa títẹ̀lé Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú gbogbo ìṣísẹ̀.

Àwọn òbí ti àwọn òbí mi àgbà àti àwọn aṣaájú àkọ́kọ́ mĩràn dojúkọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìdènà bí wọ́n ti wá nípasẹ̀ àwọn wágọ́nù, àwọn kẹ̀kẹ́ ọwọ́, àti rírìn sí Àfonífojì Salt Lake. Àwa náà yío dojúkọ àwọn ìpèníjà bíi ẹnikọ̀ọ̀kan nínú àwọn ìrìnàjò wa ní ìgbé ayé wa. Àwa ò ti kẹ̀kẹ́ ọwọ́ tàbí wa àwọn wágọ̀nù tí a bò lórí àwọn òkè títẹ̀ àti nínú yìnyín jíjìn; a ngbìyànjú bí wọ́n ti ṣe láti borí àwọn ìdánwò àti ìpèníjà ti ọjọ́ wa nípa ti ẹ̀mí. A ní àwọn ipasẹ̀ ọ̀nà láti rìn; a ní àwọn okè kékèké—àti nígbàmíràn àwọn òkè nlá—láti gùn. Bíótilẹ̀jẹ́pé àwọn àdánwò ti òní yàtọ̀ sí ti àwọn aṣíwájú àkọ́kọ́, wọn kò dín ní jíjẹ́ ìpèníjà fúnwa.

Ó ṣe pàtàkì láti tẹ̀lé wòlíì kí a sì fi àwọn ẹsẹ̀ wa múlẹ̀ ṣinṣin ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú àti ìṣòdodo bí ó ti rí fún àwọn aṣaájú àkọ́kọ́.

Ẹ jẹ́kí a tẹ̀lé Jésù Krístì pẹ̀lú ìgbàgbọ́ ní gbogbo ìṣísẹ̀. A nílò láti sin Olúwa kí a sì sìn àwọn ara wa. A nílò láti fún ara wa lókun ní ti ẹ̀mí nípa síṣe ìpamọ́ àti bíbu ọlá fún àwọn májẹ̀mú wa. A ko gbọdọ̀ gbàgbé bí ó ti jẹ́ kíákíá tó láti pa àwọn òfin mọ́. Sátánì ngbìyànjú láti fa ìfọkànsìn àti ifẹ́ wa fún Ọlọ́run àti Olúwa Jésù Krístì sẹ́hìn. Ẹ jọ̀wọ́ rántí pé bí ẹnikẹ́ni bá sọ ọ̀nà wọn nù, a kò le sọnù sí Olùgbàlà wa láé. Pẹ̀lú ìbùkún ìrònúpìwàdà, a le yípadà sí Òun. Òun yío rànwá lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́, láti dàgbà, àti láti yípadà bí a ti ntiraka láti dúró ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú.

Njẹ́ kí a le tẹ̀lé àwọn ìṣísẹ̀ Jésù Krístì títí láé àti, pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú gbogbo ìṣísẹ̀ wa, kí a le dojúkọ Ọ́, ní fífi àwọn ẹsẹ̀ wa múlẹ̀ ṣinṣin ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Wo K. Newell Dayley, “Ìgbàgbọ́ nínú Gbogbo Ìṣísẹ̀,” EnsignJan. 1997, 15.

  2. Dayley, “Ìgbàgbọ́ nínú Gbogbo Ìṣísẹ̀,” Ensign, Jan. 1997, 15; Liahona, Feb. 1997, 23.

  3. Wo Henry Ballard diary; 19th Century Western and Mormon Manuscripts; L. Tom Perry Special Collections, Harold B. Lee Library, Brigham Young University, archives.lib.byu.edu/repositories/ltpsc/resources/upb_msssc998.

  4. Wo “Ìwo ‘Kékeré kan’ sínú Àwọn Ìrírí Olùlànà,” Àwọn Ìròhìn I`jọ, June 15, 1996, thechurchnews.com.

  5. Wo Ìdánilẹ́kọ́ ti Àwọn Ààrẹ Ìjọ: Joseph F. Smith (1998), 400.

  6. See Douglas O. Crookston, ed., Henry Ballard: The Story of a Courageous Pioneer, 1832–1908 (1994), 14–15.

  7. Wo Merriam-Webster.com Dictionary, “pioneer.”

  8. Jákọ́bù 1:5.

  9. Wo Joseph Smith—History 1:5–20

  10. Russell M. Nelson, “Wíwàásù Ìhìnrere Àlàáfíà,” Liahona, May 2022, 6; original emphasis removed.

  11. Russell M. Nelson, “Revelation for the Church, Revelation for Our LivesLiahonaMay 2018, 96.

  12. Russell M. Nelson, “Àwọn Yíyàn fún Ayérayé” (àpéjọ ìfọkànsìn àgbáyé fún àwọn ọ̀dọ̀ ànìkanwà, Oṣù Karũn 15, 2022), broadcasts.ChurchofJesusChrist.org.

  13. Russell M. Nelson, “Ìfihàn fún Ìjọ, Ìfihàn fún Ayé Wa96.

  14. Jòhánnù14:6

  15. Jòhánnù14:6

  16. Wo Jòhánnù 14:16–18

  17. 3 Néfì 18:32