Ìlànà Kan fún Ìfihàn Araẹni
A nílò láti ní ìmọ̀ ìlànà nínú èyí tí Ẹ̀mí Mímọ́ nṣiṣẹ́. Nígbàtí a bá ṣiṣẹ́ nínú ìlànà, Ẹmí Mímọ́ lè fi òye yíyanilẹ́nu fúnni.
Bíiti ọ̀pọ̀lọpọ̀ lára yín, mo ti ní okun títóbi jùlọ nípasẹ̀ Alàgbà Dieter F. Uchtdorf ní àwọn ọdún sẹ́hìn. Èyí ṣe àlàyé, ní apákan ó kéréju, ohun tí èmi fẹ́ láti sọ.1 Nítorínáà, pẹ̀lú ẹ̀bẹ̀ sí i …
Àwọn awakọ̀ òfúrufú tí a dálẹ́kọ-dáadáa nfò nínú agbára ti ọkọ̀-òfúrufú wọn wọ́n sì ntẹ̀lé àwọn ìdarí láti ọ̀dọ̀ àwọn adarí ọkọ̀-òfúrufu nípa lílo ọ̀nà-ìkọjá àti ipa-ọ̀nà fífò. Sísọ ní ìrọ̀rùn, àwọn awakọ̀ nṣiṣẹ́ nínú ìlànà kan. Bíótiwù kí wọ́n ní ẹ̀bùn tàbí òye tó, nípa fífò nìkan nínú ìlànà ni àwọn awakọ̀-òfúrufú fi lè fi agbára nlá ọkọ̀-òfúrufú kan lélẹ̀ láti mú àwọn àfojúsùn oníyanu rẹ̀ ṣẹ.
Nínú irú ọ̀nà kannáà, a ngbà ìfihàn araẹni nínú ìlànà kan. Lẹ́hìn ìribọmi, a fún wa ní ẹ̀bùn àfojúrí àní ọlọ́lá kan, ẹ̀bùn Ẹmí Mímọ́.2 Bí a ti ntiraka láti dúró ní ipa-ọ̀nà májẹ̀mú,3 “Ẹ̀mí Mímọ́ … [ni] yíò fi ohun gbogbo hàn [wá] [tí a] níláti ṣe.”4 Nígbàtí kò bá dá wa lójú tàbí tí kò rọrùn, a lè bèèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ìrànlọ́wọ́.5 Ìlérí Olùgbàlà kò lè hàn kedere jù èyí: “Bèèrè, a ó sì fi fún yín; … nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá bèèrè yíò rí gbà.”6 Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ a lè yí ìwà-ẹ̀dá àtọ̀runwá wa padà sí àyànmọ́ ayérayé wa.7
Ìlérí ti araẹni nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ jẹ́ ìmísí-ọ̀wọ̀, púpọ̀ bíiti ọkọ̀-òfúrufú ní fífò. Àti bíi àwọn awakọ òfúrufú, a nílò láti ní ìmọ̀ ìlànà nínú èyí tí Ẹ̀mí Mímọ́ nṣiṣẹ́ láti pèsè ìfihàn araẹni. Nígbàtí a bá ṣiṣẹ́ nínú ìlànà, Ẹmí Mímọ́ lè fi òye, ìdarí, àti ìtùnú yíyanilẹ́nu fúnni. Ní òde ìlànà yí, bí ó ti wù kí ọgbọ́n wa tàbí ẹ̀bùn tó, a lè gba ẹ̀tàn kí a sì wólulẹ kí a jóná.
Àwọn ìwé mímọ́ dá ohun-èlò àkọ́kọ́ ti ìlànà yí fún ìfihàn araẹni.8 Ṣíṣe àṣàrò lórí àwọn ọ̀rọ̀ Krístì, bí a ti ri nínú àwọn ìwé mímọ́, nrú ìfihàn araẹni síta. Alàgbà Robert D. Hales wípé: “Nígbàtí a bá fẹ́ sọ̀rọ̀ sí Ọlọ́run, à ngbàdúrà. Àti nígbà tí a bá fẹ́ kí Òun sọ̀rọ̀ sí wa, a nṣe ìwákiri àwọn ìwé mímọ́.”9
Àwọn ìwé mímọ́ bákannáà kọ́ wa bí a ṣe lè gba ìfihàn araẹni.10 A nbèèrè fún ohun tí ó yẹ tí ó sì dára11 kìí ṣe fún ohun tí ó lòdì sí ìfẹ́ Ọlọ́run.12 A kò “bèère ní àìtọ́,” pẹ̀lú àwọn èrò àìbójúmu láti gbé ètò-àwòṣe arawa ga tàbí láti mú ìgbádùn arawa ṣẹ.13 Ju gbogbo rẹ̀ lọ, a ní láti bèèrè lọ́wọ́ Baba Ọ̀run ní orúkọ Jésù Krístì,14 ní gbígbàgbọ́ pé a ó gbà.15
Ohun-èlò kejì ti ìlànà ni pé a ngba ìfihàn araẹni nìkan nínú ìpèse-sílẹ̀ wa, kìí sì ṣe nínú ànfàní ti àwọn ẹlòmíràn. Ní àwọn ọ̀rọ̀ míràn, a ngbéra a sì nbalẹ̀ nínú ọ̀nà-ìkọjá tí a yàn fún wa. Pàtàkì ìlàsílẹ̀-dáadáa ti àwọn ọ̀nà-ìkọjá ni a kọ́ ní ìṣáájú àkọọ́lẹ̀-ìtàn Ìmúpadàbọ̀sípò. Hiram Page, ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹri Mẹ́jọ sí Ìwé ti Mọ́mọ́nì, ní òun ngba àwọn ìfihàn fún gbogbo Ìjọ. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ-ìjọ ni a tàn tí wọ́n sì fàyè gba àṣìṣe.
Ní ìdáhùn, Olúwa fihàn pé “kò sí ẹnìkan tí a yàn láti gba àwọn òfin àti ìfihàn nínú ìjọ yàtọ̀ sí ìránṣẹ́ mi Joseph Smith, Jun., … títí tí èmi yíò fi yan … òmíràn ní ipò rẹ̀.”16 Ẹ̀kọ́, àwọn òfin, àti àwọn ìfihàn fún Ìjọ jẹ́ ànfàní ti wólíì, tí ó ngbà wọ́n láti ọ̀dọ̀ Olúwa Jésù Krístì.17 Èyí ni ọ̀nà-ìkọjá ti wòlíì.
Àwọn ọdún sẹ́hìn, mo gba ìpè fóònù kan láti ọ̀dọ̀ ẹnìkan tí a mú fún ìrékọjá. Ó wí fún mi pé wọ́n fihan òun pé àfikún ìwé-mímọ́ ni a ri mọ́lẹ̀ lábẹ́ ògiri ilẹ̀ ilé kan tí òun ngbìyànjú láti wọ̀. Ó wí pé òun ti gba iwé-mímọ́ nígbàkan, òun mọ̀ pé òun yíò gba ẹ̀bùn ìtumọ̀-èdè, mú ìwé-mímọ́ titun jáde wá, àti kí òun sì tún ẹ̀kọ́ àti ìdarí Ìjọ ṣe. Mo wí fún un pé ó nṣe àṣiṣe, ó sì ní kí ngbàdúrà nípa rẹ̀. Mo wí fún un pé èmi kò ni ṣee. Ó di bibú èébú ó sì parí ìpè fóònù.18
Èmi kò nílò láti gbàdúrà nípa ìbèèrè yí fún èrèdí kan rírọ́rùn ṣùgbọ́n jíjinlẹ̀: wòlíì nìkan ni ó ngba ìfihàn fún Ìjọ. Yíò jẹ́ “ìlòdì sí ìṣe ti Ọlọ́run”19 fún àwọn ẹlòmíràn láti gba irú ìfihàn bẹ́ẹ̀, èyí tí ó wà lórí ọ̀nà-ìkọjá ti wòlíì.
Ìfihàn ti-ara wà fún olúkúlùkù nínú ẹ̀tọ́. Ẹ lè gba ìfihàn, fún àpẹrẹ, ibi láti gbé, irú ipá-ọ̀nà iṣẹ́ láti tẹ̀lé, tàbí ẹni láti fẹ́.20 Àwọn olórí Ìjọ lè kọ́ ẹ̀kọ́ kí a sì pín àmọ̀ràn ìmísí, ṣùgbọ́n ojúṣe fún àwọn ìpinnu wọ̀nyí wà pẹ̀lú yín. Èyí ni ìfihàn yín láti gbà; èyí ni ọ̀nà-ìkọjá yín.
Ohun-èlò kẹ́ta ti ìlànà ni pé ìfihàn araẹni yíò wà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn òfin Ọlọ́run àti àwọn májẹ̀mú tí a ti dá pẹ̀lú Rẹ̀. Ronú àdúrà kan tí ó lọ bí ohunkan bayi: “Baba Ọ̀run, ìjọ́sìn Ìjọ nwọ́lẹ̀. Njẹ́ kí njọ́sìn Yín ní Ọjọ́-ìsinmi ní orí-òkè tàbí lórí òkun? Njẹ́ kí ngbàyè kúrò ní lílọ sí Ilé-ìjọsìn kí nsì ṣe àbápín oúnjẹ-Olúwa ṣùgbọ́n síbẹ̀síbẹ̀ kí nní ìlérí àwọn ìbùkún ti pípa ọjọ́ Ìsinmi ní mímọ́ mọ́?”21 Ní èsì sí irú àdúrà bẹ́ẹ̀, a lè gbèrò èsì Ọlọ́run: “Ọmọ mi, èmi ti fi ìfẹ́ mi hàn tẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ Ìsinmi.”
Nígbàtí a bá bèèrè fún ìfihàn nípa ohunkan tí Ọlọ́run ti fúnni ní ìdarí kedere, à nṣí arawa sílẹ̀ láti ṣi ìmọ̀lára wa gbọ́ àti gbígbọ́ ohun tí a fẹ́ láti gbọ́. Ọkùnrin kan wí fún mi nípa àwọn ìlàkàkà rẹ̀ nígbàkàn láti mú ipò ìṣúna-owó ẹbí dúró. Òun ní èrò láti jí owó bí ojútú, ó gbàdúrà nípa rẹ̀, ó sì ní ìmọ̀lára pé òun ti gba ìfihàn àsọyé láti ṣe bẹ́ẹ̀. Mo mọ̀ pé ó ti gba ẹ̀tàn nítorí ó nwá ìfihàn ní ìlòdì sí òfin Ọlọ́run. Wòlíì Joseph Smith kìlọ̀, “Kò sí ọgbẹ́ tí ó tóbíjù sí àwọn ọmọ ènìyàn ju láti wà ní abẹ́ okun ẹ̀mí irọ́, nígbàtí wọ́n nronú pé wọ́n ní Ẹ̀mí Ọlọ́run.”22
Àwọn kan lè fi hàn pé Néfì rú òfin kan nígbàtí ó pa Lábánì. Bákannáà, àyọkúrò yí kò mú òfin náà lòdì—òfin náà pé ìfihàn araẹni yíò wà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn òfin Ọlọ́run. Kò sí àlàyé ìrọ̀rùn ìran yí tó jẹ́ ìtẹ́lọ́run ní pípé, ṣùgbọ́n èmi ó tẹnumọ́ àwọn kókó díẹ̀. Ìṣẹ̀lẹ̀ náà kò bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lù Néfì tí ó nbèèrè bóyá òun lè pa Lábánì. Kìí ṣe ohunkan tí ó fẹ́ láti ṣe. Pípa Lábánì kìí ṣe fún èrè araẹni ti Néfì ṣùgbọ́n láti pèsè àwọn ìwé-mímọ́ fún orílẹ̀-èdè ọjọ́-ọ̀là àti àwọn ènìyàn májẹ̀mú kan. Àti pé ó dá Néfì lójú pé ó jẹ́ ìfihàn—nítoótọ́, ni ọ̀ràn yí, ó jẹ́ òfin láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.23
Ohun-èlò kẹ́rin ti ìlànà ni láti da ohun tí Ọlọ́run ti fíhàn tẹ́lẹ̀ sí yín níti-araẹni mọ̀, nígbàtí ẹ̀ nṣí ọkàn sí ìfihàn síwájú si láti ọ̀dọ̀ Rẹ. Bí Ọlọ́run bá ti dáhùn ìbèèrè kan tí àwọn ipò kò sì yípadà, kínidí tí àwa ó fi retí kí ìdáhùn náà ó yàtọ̀? Joseph Smith ṣubú sínú ìran ti-wàhálà yí ní 1828. Apákan àkọ́kọ́ Ìwé ti Mọ́mọ́nì ni a ti túmọ̀, nígbàti Martin Harris, olóore kan àti akọ̀wé ìṣaájú, bèèrè lọ́wọ́ Joseph fún ààyè láti mú àwọn ojú-ewé tí a ti túmọ̀ lọ láti fi wọn han ìyàwó rẹ̀. Ní àìní-ìdálójú ohun to níláti ṣe, Joseph gbàdúrà fún ìtọ́sọ́nà. Olúwa wi fún kí ó maṣe jẹ́ kí Martin mu àwọn ojú-ewé náà lọ.
Martin ní kí Joseph bèèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run lẹ́ẹ̀kansi. Joseph ṣe bẹ́ẹ̀, kò yanilẹ́nu pé, ìdáhùn náà ni, ọ̀kannáà. Ṣùgbọ́n Martin bẹ Joseph láti bèèrè ní ìgbà kẹ́ta, Joseph sì ṣe bẹ́ẹ̀. Ní ìgbà yí Ọlọ́run kò wípé rárá. Dípò bẹ́ẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó dàbí Ọlọ́run wípé, “Joseph, ìwọ mọ̀ bí mo ṣe ní ìmọ̀lára nípa èyí, ṣùgbọ́n o ní agbára òmìnira rẹ̀ láti yàn. Ní ìrọ̀rùn kúrò nínú ìdíwọ́, Joseph pinnu láti jẹ́ kí Martin mú ìwé ojú-ewe mẹrindinlọgọfa lọ ó sì fi wọn han àwọn ọmọ ẹbí díẹ. Àwọn ojú-ewé tí a túmọ̀ sọnù a kò si ri pada láéláé. Olúwa bá Joseph wí gidigidi.24
Joseph kọ́, bí wòlíì Ìwé ti Mọ́mọ́nì Jákọ́bù ti kọ́ni: “Máṣe wá láti gba Olúwa ní àmọ̀ràn, ṣùgbọ́n gba àmọ̀ràn láti ọwọ́ rẹ̀. Nítorí … òun ndámọ̀ràn nínú ọgbọ́n.”25 Jákọ́bù kílọ̀ pé àwọn ohun àìdáa nṣẹlẹ̀ nígbàtí a bá bèèrè fún àwọn ohun tí ko yẹ. Ó sọtẹ́lẹ̀ pé àwọn ènìyàn ní Jérúsálẹ́mù yíò wá “àwọn ohun tí wọn kò [lè] ní ìmọ̀,” láti wò “kọjá àmì,” kí wọ́n sì fojúdi Olùgbàla aráyé.26 Wọ́n ṣubú nítorí wọ́n bééré fún àwọn ohun tí kò yẹ àti tí wọn kò lè ní ìmọ̀.
Bí a bá ti gba ìfihàn araẹni fún ipò wa tí àwọn nkan kò sì yípadà, Ọlọ́run ti dáhùn ìbèèrè wa.27 Fún àpẹrẹ, à nfi ìgbàmíràn bèèrè léraléra fún ìdánilójú si pé a ti gba ìdáríjì. Bí a bá ronúpìwàdà, tí a kún fún ayọ̀ àti àláfíà ẹ̀rí ọkàn, tí a sì gba ìwẹ̀nùmọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, a kò ní láti bèèrè lẹ́ẹ̀kansi ṣùgbọ́n a lè gbẹ́kẹ̀lé ìdáhùn tí Ọlọ́run ti fún wa.28
Àní bí a ti gbẹ̀kẹ̀lé àwọn ìdáhùn ìṣíwájú, tí a nílò láti ṣí ìfihàn araẹni síwájú si. Lẹ́hìn gbogbo rẹ̀, díẹ̀ ti òpin ìgbé ayé ni à ndé nípasẹ̀ fífò kan tí kò dáwọ́dúró. A níláti damọ̀ pé ìfihàn araẹni ni a lè gbà “lẹ́sẹ lẹ́sẹ àti ìlànà lé ìlànà,”28 tí ó nfi ìdarí hàn lè jẹ́ àti pé loorekore ni àníkún.30
Àwọn ohun-èlò ti ìlànà fún ìfihàn araẹni jẹ́ ìfibò àti alabapin ìfúnnilókun. Ṣùgbọ́n nínú ìlànà náà, Ẹmí Mímọ́ lè ó sì lè fi ohungbogbo tí a nílò hàn láti gòkè kí a sì mú ìyára lórí ipá ọ̀nà májẹ̀mú dúró. Bayi a lè di alábùkún nípa agbára Jésù Krístì láti di ohun tí Baba Ọ̀run nfẹ́ kí a dà. Mo pè yín láti ní ìgbẹ́kẹ̀lé láti gba ìfihàn araẹni fún arayín, níní ìmọ̀ ohun tí Ọlọ́run ti fihàn, lóòrèkórè pẹ̀lú àwọn ìwé mímọ́ àti àwọn òfin tí Ó ti fúnni nípasẹ̀ àwọn wòlíì Rẹ̀ tí a yàn àti nínú ìpèsè-sílẹ̀ àti agbára òmìnira ti ara yín. Mo mọ̀ pé Ẹ̀mí Mímọ́ lè yíò sì fi ohun gbogbo tí ẹ níláti ṣe hàn yín.31 Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.