Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Jíjẹ́ Ọmọ-ẹ̀hìn Títíláé
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2022


Jíjẹ́ Ọmọ-ẹ̀hìn Títíláé

A lè rí ìgbẹ́kẹ̀lé àti àlàáfíà ti ẹ̀mí bí a ṣe nṣìkẹ́ àwọn ìwà mímọ́ àti àwọn ìṣiṣẹ́ òdodo tí ó lè mú ni dúró kí ó sì fi epo sí àwọn iná ìgbàgbọ́ wa.

Láàrin ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn tí ó kọjá yìí, ó lé ní 200,000 àwọn ọ̀dọ́ wa jákèjádò àgbáyé tí wọ́n dàgbà nínú ìgbàgbọ́ nínú ọ̀kan lára ​​ọgọgọ́rũn àwọn abala ọlọ́sẹ̀kan ti Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́, tàbí àwọn ìpàdé àpapọ̀ FSY. Jíjáde kúrò nínú ìpinyà àjàkálẹ̀-àrùn, fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ó jẹ́ ìṣe ìgbàgbọ́ nínú Olúwa pàápàá láti wá síbẹ̀. Púpọ̀ nínú àwọn ọ̀dọ́ olùkópa dàbí ẹnipé ó tẹ̀lé irú áàkì tó nlọ sókè sí ọna ìyípadà jíjinlẹ̀. Ní ìparí ọ̀sẹ̀ wọn, mo fẹ́ láti bèèrè, “Báwo ní ó ṣe nlọ?”

Nígbà míràn wọ́n sọ irú nkan bí èyí: “Ó dára, lọ́jọ́ Ajé, inú bí mi gan-an sí ìyá mi torí pé ó jẹ́ kí nwá. Èmi ò sì mọ ẹnìkẹ́ni. Àti pé èmi ò rò pé ó wà fun mi. Èmi kò sì ní ní ọ̀rẹ́ kankan. … Ṣugbọ́n bayi Ọjọ́ Jímọ̀ ni, mo sì fẹ́ láti dúró nihin. Mo fẹ́ láti ní ìmọ̀lára Ẹ̀mí nínú ayé mi. Mo fẹ́ láti gbé bí èyí.”

Olúkúlùkù wọn ní àwọn ìtàn tiwọn láti sọ nípa àwọn àkokò níní òye síi àti ti àwọn ẹ̀bùn ti ẹ̀mí ti nfọ̀ wọ́n ti ó sì ngbé wọn lọ sí ipa áàkì ìdàgbàsókè náà. Èmi náà di yiyípadà pẹ̀lú nípasẹ̀ FSY ti ìgbà ooru yí bí mo ti rí ẹ̀mí Ọlọ́run tí ndáhùn ní ìdúróṣinṣin sí àwọn ìfẹ́-inú òdodo ọkàn kọ̀ọ̀kan ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀dọ́ wọ̀nyí tí olúkúlùkù wọn rí ìgboyà láti gbẹ́kẹ̀lé E pẹ̀lú ọ̀sẹ̀ kan nínú ìtọ́jú Rẹ.

Bí àwọn ọkọ̀ ojú omi onírin tí máa ntàn nínú òkun, a ngbé nínú àyíká oníbàjẹ́ nípa ti ẹ̀mí níbi tí àwọn ìdánilójú dídán mọ́rán jùlọ gbọ́dọ̀ wà pẹ̀lú ìrọ́nú tàbí tí wọ́n lè fọ́, kí ó sì bàjẹ́, lẹ́hìnnáà kí wọ́n sì wó dànù.

Irú Àwọn Ohun Wo Ni A Lè Ṣe Láti Mú Iná Àwọn Ìdánilójú Wa Dúró?

Àwọn ìrírí bí àwọn ìpàdé àpapọ̀ FSY, àwọn ìpàgọ́, àwọn ìpàdé oúnjẹ Olúwa, àti àwọn iṣẹ́ ìránṣẹ́ lè ṣe ìrànlọ́wọ́ láti mú àwọn ẹ̀rí wa dán, ní mímú wa la àwọn áàkì ìdàgbàsókè àti ìṣàwárí ti ẹ̀mí já, sí àwọn ibi àlàáfíà. Ṣùgbọ́n kí la gbọ́dọ̀ ṣe láti lè dúró síbẹ̀ kí á sì máa bá a lọ láti “tẹ̀ síwájú pẹ̀lú ìdúróṣinṣin nínú Krístì”(2 Néfì 31:20) dípò yíyọ̀ sẹ́hìn? A gbọ́dọ̀ tẹ̀síwájú láti máa ṣe àwọn ohun tí ó mú wa wá síbẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, bí gbígbàdúrà déédéé, ríri ara wa bọ inú Ìwé mímọ́, àti sísìn tọkàntọkàn.

Fún àwọn kan nínú wa, ó lè nílò gbígbẹ́kẹ̀lé Olúwa àní láti lọ sí ìpàdé oúnjẹ Olúwa pàápàá . Ṣùgbọ́n bí ó bá ti wà níbẹ̀ rí, ipa ìwòsàn ti oúnjẹ Olúwa, àwọn ìdàpọ̀ ti àwọn ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ ìhìnrere, àti ìtọ́jú ti ìletò Ìjọ lè rán wa sílé lórí ilẹ̀ gíga.

Níbo Ni Agbára nínú Pípéjọ Papọ̀ nínú Ènìyàn Ti Wá?

Ni FSY, 200,000 àti jù bẹ́ẹ̀ lọ àwọn ọ̀dọ́ wá láti mọ Olùgbàlà dáradára nípa lílo ìlànà tí ó rọrùn tí wíwá papọ̀ níbití méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ti péjọ ní orúkọ Rẹ̀ (wo Máttéù 18:20) ti ṣíṣe àmúlò ìhìnrere àti àwọn ìwé-mímọ́, kíkọrin papọ̀, gbígbàdúrà papọ̀, àti wíwá àlááfìà nínú Krístì. Èyí jẹ́ ìṣètó alágbára fún ìjídìde ti ẹ̀mí.

Ìtànkálẹ̀ ẹgbẹ́ àwọn arákùnrin àti arábìnrin yí ti lọ sílé báyìí láti pinnu ohun tí ó túmọ̀ sí láti “gbẹ́kẹ̀ lé Olúwa” síbẹ̀ (Proverbs 3:5; 2022 àkórí àwọn ọ̀dọ́) nígbà tí wọ́n bá di gbígbá sókè nínú àìgbọ́raẹniyé ti ayé tó kún fún ẹ̀mí gíga. Ó jẹ́ ohun kan láti “gbọ́ Tirẹ̀” (Àkọọ́lẹ̀ Ìtàn—Joseph Smith 1:17) ní ibi tí ó dákẹ́ jẹ́ẹ́ tí a ti nronú jinlẹ̀ pẹ̀lú àwọn Ìwé Mímọ́ ní ṣíṣí sílẹ̀. Ṣùgbọ́n ó jẹ́ ohun míràn gan-an láti gbé jíjẹ́-ọmọẹ̀hìn wa sínú ìdàrúdàpọ̀ ayé ikú yí ti àwọn ìpínyà níbi tí a ti gbọ́dọ̀ tiraka láti “gbọ́ Tirẹ̀,” àní nínú àníyàn ara-ẹni tí kò ṣe kedere àti ìgbẹ́kẹ̀lé láìní ìpinnu. Ẹ máṣe ṣiyèméjì: ó jẹ́ nkan àwọn akíkanjú tí àwọn ọ̀dọ́ wa gbé ọkàn àti inú wọn lé nígbàtí wọ́n dúró déédé ní ìlòdì sí àwọn ìwà-ọnà yíyípadà ti àkokò wa.

Kíni àwọn Ẹbí Lè Ṣe Ní Ilé láti Gbé Lé Orí Ipasẹ̀ tí a ti Dásílẹ̀ níbi àwọn Ṣíṣe Ìjọ?

Mo sìn nígbà kan rí bí ọkọ fún ààrẹ Àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin ti èèkàn . Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, wọ́n ní kí nmáa ṣètò àwọn kúkì níibi ìgbàlejò nígbà tí ìyàwó mi ndarí ìjọsìn-alẹ́ nínú ìjọ fún àwọn òbí àti àwọn ọmọbìnrin wọn láti múra fún lílọ sí ìpàgọ́ àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin ní ọ̀sẹ̀ tó nbọ̀. Lẹ́hìn ṣíṣe àlàyé ibi tí a ó wà àti ohun tí a ó mú wá, ó wí pé, “Ní báyìí, ní òwúrọ̀ ọjọ́ Ìṣẹ́gun nígbàtí ẹ bá já àwọn ọmọbìnrin aládùn yín síibi ọkọ̀, ẹ gbá wọ́n mọ́ra díẹ̀. Ẹ̀ sì fi ẹnu kò wọ́n lẹ́nu pé ó dìgbà—nítorí wọn kò ní padà wá.”

Mo gbọ́ tí ẹnìkan mí sókè, lẹ́hìnnáà a ri pé èmi ni. “Kò ní padà wá?”

Ṣùgbọ́n lẹ́hìnnáà ó tẹ̀síwájú: “Nígbàtí ó bá já àwọn ọmọbìrin ti òwúrọ̀ ọjọ́ Ìṣẹ́gun wọ̀nnì sílẹ̀, wọ́n yíò fi àwọn ìdàláàmú ti àwọn nkan kékèké sílẹ̀ wọn yío sì lo ọ̀sẹ̀ kan papọ̀ ní kíkọ́ ẹ̀kọ́ àti ní dídàgbà àti ní gbígbẹ́kẹ̀lé Olúwa. A ó gbàdúrà papọ̀ a ó sì kọrin a ó sì se àsè a ó sì sìn papọ̀ a ó sì pìn àwọn ẹ̀rí papọ̀ a ó sì ṣe àwọn ohun tí ó gbà wá láàyè láti ní ìmọ̀lára Ẹ̀mí Baba Ọ̀run, ní gbogbo ọ̀sẹ̀, títí tí yío fi wọ gbogbo inú egungun wa. Àti ní ọjọ́ Sátidé, àwọn ọmọbìnrin tí ẹ rí tí wọ́n bọ́ sílẹ̀ láti inú ọkọ̀ náà kìí yíò jẹ́ àwọn tí ẹ já sílẹ̀ ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun. Wọn yìó jẹ́ ẹ̀dá titun. Àti pé bí ẹ bá rànwọ́n lọ́wọ́ láti tẹ̀síwájú láti ibi ọkọ̀ òfúrufú gígajù náà, wọn yìó yàyínlẹ́nu. Wọn yíò tẹ̀síwájú láti yípadà àti láti dàgbà. Bẹ́ẹ̀ sì ni ẹbí yín.”

Ní ọjọ́ Sátidé náà, ó rí gẹ́gẹ́bí ó ti sọtẹ́lẹ̀. Bí mo ṣe nto àwọn àgọ́, mo gbọ́ ohùn ìyàwó mi nínú gbọ̀ngàn onígi kékeré kan tí àwọn ọmọbìnrin náà ti péjọ kí wọ́n tó máa lọ sílé. Mo gbọ́ tí ó wípé, “Ah, níbẹ̀ ni ẹ wà. A ti nwọ̀nà fún yín ní gbogbo ọ̀sẹ̀. Ẹyin ọmọbirin Sátidé wa.”

Àwọn ọ̀dọ́ akíkanjú ti Síónì nrìnrìn àjò ní àwọn àkókò àgbàyanu. Rírí ayọ̀ nínú ayé ìdádúró tí a ti sọtẹ́lẹ̀ yí láì di apákan ti ayé náà, pẹ̀lú fífọ́jú rẹ̀ sí ìwà mímọ́, ni ojúṣe wọn ní pàtó. G. K Chesterton sọ̀rọ̀ ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ bí ẹni pé ó rí ìwádìí yìí bí jíjẹ́ ti ààrin gbùngbùn ilé àti tí ìjọ tìlẹ́hìn nígbàtí ó wípé, “A ní láti ní ìmọ̀lára àgbáyé lẹ́ẹ̀kan náà bí ilé olódi ti ogre kan, láti fi ìjì jà, àti síbẹ̀ bí ilé kékeré tiwa, sí èyí tí a lè padà ní alẹ́” (Orthodoxy [1909], 130).

Pẹ̀lú ọpẹ́, wọn kò ní láti jáde lọ sínú ogun nìkan. Wọ́n ní ara wọn. Àti pé wọ́n níi yín. Wọ́n sì ntẹ̀lé wòlíì alààyè kan, Ààrẹ Russell M. Nelson, ẹni tí ó ndarí pẹ̀lú ìtara mímọ̀ ti aríran kan ní kíkéde pé akitiyan nlá ti àwọn àkókò wọ̀nyí—ìkójọpọ̀ Ísráẹ́lì—yíò jẹ́ mímúlẹ̀ àti ọlá nlá (Wo “Ìrètí Ísráẹ́lì” [ìfọkànsìn a`wọn ọ̀dọ́ káríayé, June 3, 2018],

Ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn yìí, ìyàwó mi, Kalleen, àti èmi npààrọ̀ ọkọ̀ òfúrufú ní Amsterdam níbi tí, ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́hìn, mo jẹ́ ìránṣẹ́ ìhinrere titun. Lẹ́hìn ọ̀pọ̀ oṣù ní títiraka láti kọ́ èdè Dutch, ọkọ̀ òfúrufú KLM wa nbálẹ̀, ọ̀gágun náà sì ṣe ìkéde aláìbáradé kan lórí ẹrọ PA. Lẹ́hìn ìdákẹ́jẹ́ẹ́ díẹ̀, ojúgbà mi sọ jẹ́jẹ́ pé, “Mo rò pé Dutch ni yẹn.” A wo òkè, ní kíka àwọn èrò ọkàn ara wa: Gbogbo rẹ̀ ti sọnù.

Ṣùgbọ́n gbogbo rẹ̀ kò sọnu. Bí mo ṣe nní ìyàlẹ́nu lórí àwọn fífò ìgbàgbọ́ tí a ti gbà nígbànáà bí a ṣe rìn nínú pápákọ̀ òfúrufú yìí ní ojú ọ̀nà wa lọ síbi àwọn iṣẹ́ ìyanu tí yíò rọ̀ sílẹ̀ sórí wa bí ìránṣẹ́ ìhìnrere, a mú mi padà lójijì sí lọ́wọ́lọ́wọ́ láti ipasẹ̀ ìránṣẹ́ ìhìnrere alààyè, tí ó ṣì nmí kan tí o nwọ inú ọkọ̀ òfúrufú lọ sí ilé. Ó fi ara rẹ̀ hàn ó sì béèrè pé, “Ààrẹ Lund, kí ni kí nṣe nísisìyí? Kíni kí nṣe láti dúró gbọingbọin?”

Ó dará, èyí ni ìbéèrè kannáà tí ó wà ní ọkàn àwọn ọ̀dọ́ wa nígbàtí wọ́n bá kúrò ní àwọn ìpàdé àpapọ̀ FSY, àwọn ìpàgọ́ ọ̀dọ́, àwọn ìrìn àjò tẹ́mpìlì àti nígbàkugbà tí wọ́n bá ní ìmọ̀lára àwọn agbára ọ̀run: “Báwo ni olùfẹ́ni Ọlọ́run fi lè yípadà sínú jíjẹ́ Ọmọ-ẹ̀hìn títíláé?”

Mo ní ìmọ̀lára ìdàgbàsókè ìfẹ́ fún ìránṣẹ́ ìhìnrere olójú-mímọ́ yí tí ó nsìn ní àwọn wákàtí ìkẹhìn iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀, àti ní i`yára dídákẹ́jẹ́ẹ́ ti Ẹ̀mí, mo gbọ́ ohùn fífẹ̀ mi tí o´ dún bí mo ṣe sọ jẹ́jẹ́ pé, “Ìwọ kò ní láti wọ báàjì náà láti jẹ́ orúkọ Rẹ̀. ”

Mo fẹ́ gbé ọwọ́ mi lé èjìká rẹ̀ kí nsì sọ pé, “Èyí ni ohun tí ìwọ o ṣe. Ìwọ lọ sí ilé kí o sì jẹ́ èyí. O dára púpọ̀ o fẹ́rẹ̀ dán nínú òkùnkùn. Ìkóraẹni ní ìjánu àti àwọn ìrúbọ ti iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti sọ ẹ́ di ọmọkùnrin ológo ti Ọlọ́run. Tẹ̀ramọ́ ṣíṣe ohun tí ó ti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú rẹ gidi pẹ̀lú agbára nihin nílé. O ti kẹ́kọ̀ọ́ láti gbàdúrà àti ẹnití o ngbàdúrà sí àti èdè àdúrà. O ti kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀ o sì wá láti fẹ́ràn Olùgbàlà nípa gbígbìyànjú láti dàbí Rẹ̀. O ti fẹ́ràn Baba Ọ̀run gẹ́gẹ́bí Òun ti nífẹ̀ẹ́ Baba Ọ̀run, sin àwọn ẹlòmíràn gẹ́gẹ́bí Òun ti sìn àwọn ẹlòmíràn, kí o sì gbé àwọn òfin bí Òun ti gbé wọn—àti nígbàtí ìwọ kò ṣe bẹ́ẹ̀, kí o ti ronúpìwàdà. Jíjẹ́-Ọmọlẹhin rẹ kìí ṣe ọ̀rọ̀ kan lásán lórí ẹ̀wù kan—ó ti di ara ìgbé ayé rẹ ní èrò gbígbé fún àwọn míràn. Nítorínáà lọ sí ilé, kí o ṣè èyínì. Jẹ́ èyínì. Gbé ipasẹ̀ ti ẹ̀mí yí sí inú ìyókù ìgbésí ayé rẹ.”

Mo mọ̀ pé nípasẹ̀ gbígbẹ́kẹ̀lé Olúwa Jésù Krístì àti ipa ọ̀nà májẹ̀mú Rẹ̀, a lè rí ìgbọ́kànlé àti àlàáfíà ti ẹ̀mí bí a ṣe nbọ́ àwọn àṣà mímọ́ àti àwọn ìṣiṣẹ́ òdodo tí ó lè mú ni dúró kí ó sì fi epo sí àwọn iná ìgbàgbọ́ wa. Njẹ́ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa le súnmọ́ àwọn iná tí nmóoru wọ̀nnì, àti, ohunkóhun tí ó lè wá, kí a dúró. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Tẹ̀