A Gbé e Sókè lórí Àgbélèbú
Láti jẹ́ àtẹ̀lé Jésù Krístì a níláti gbé ẹrù kan ní àwọn ìgbàmíràn—ti ara yín tàbí ti ẹlòmíràn—kí ẹ sì lọ sí ibi tí ìrúbọ ti jẹ́ dandan àti tí ìjìyà kò ṣeé yẹra fún.
Ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́hìn, lẹ́hìn ọ̀rọ̀ àjọsọ ti ilé ìwé gíga kan lórí àọọ́lẹ̀-ìtàn ẹ̀sìn àwọn ará Amẹ́ríkà, akẹgbẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ kan bi mí pé, “Kíní ṣe tí Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ikẹhìn kò gba àgbélèbú tí àwọn Krístẹ́nì míràn nlò bíi àmì ìgbàgbọ́ wọn?”
Níwọ̀n bí irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀ nípa àgbélèbú ti máa nfi ìgbà gbogbo jẹ́ ìbéèrè nípa ìfọkànsìn wa sí Krístì, lójúkannáà mo sọ fún un pé Ìjọ Jésù Krístì ti awọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ka ètùtù ẹbọ ọrẹ ti Jésù Krístì sí ààrin gbùngbùn òtítọ́, kókó ìpìlẹ̀, ẹ̀kọ́ pàtàkì, àti ìfihàn ìgbẹ̀hìn ti ìfihàn ìfẹ́ àtọ̀runwá nínú ètò títóbi ti Ọlọ́run fún ìgbàlà àwọn ọmọ Rẹ̀.1 Mo ṣàlàyé pé oore ọ̀fẹ́ tí ó ngbàlà tí ó wà nínú iṣe náà jẹ́ pàtàkì, a sì fúnni bíi ẹ̀bùn àgbáyé sí gbogbo ìran ènìyàn láti Ádámù àti Éfà dé òpin ayé.2 Mo ṣe àtúnsọ ọ̀rọ̀ Wòlíì Joseph Smith, ẹnití ó wí pé, “Gbogbo … àwọn ohun tí ó ní í ṣe sí ẹ̀sìn wa kan jẹ́ àfikún” sí Ètùtù ti Jésù Krístì ni.3
Lẹ́hinnáà mo kà ohun tí Néfì ti kọ ní ọdún 600 ṣaájú ìbí Krístì fún un: “Ángẹ́lì … ná à sì wí fún mi … , wípé: Wò ó! Mo sì wò mo sì kíyèsí Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run, … [ẹnití] a gbé sókè sórí àgbélèbú tí a sì pa fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ aráyé.”4
Pẹ̀lú ìtara “fẹ́ràn, pín, sì pè” mi ní ibi gíga, mo tẹ̀síwájú ní kíkà! Sí àwọn ará Néfì ní Ayé Titun Krístì tó jíìnde wípé, “Bàbá mi ti rán mi kí a lè gbé mi sókè sí orí àgbélèbú; … kí èmi ó lè fa gbogbo ènìyàn wá sí ọ̀dọ̀ mi, … ati nítọrínã ni a fi gbé mi sókè.”5
Mo ti fẹ́ ṣe àtúnsọ ọ̀rọ̀ Páùlù Àpóstélì nígbàtí mo fura pé ojú ọ̀rẹ́ mi ti bẹ̀rẹ̀ sí padé. Sísáré wo oju aago ọwọ́ rẹ̀ dàbí ẹnipé ó rán an létí pé ó nílò láti wà níbikan, níbikíbi—ó sì kánjú jáde lọ sí ibi àdéhùn irọ́ rẹ̀. Báyí ni ìbáraẹnisọ̀rọ̀ wa parí.
Ní òwúrọ̀ yí, àádọ́ta ọdún díẹ̀ lẹ́hìnáà, mo ní ìpinnu láti parí àlàyé náà—àní bí gbogbo ẹnìkọ̀ọ̀kan yín tilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ síí wo ojú ààgo yín. Bí mo ṣe ngbìyànjú láti ṣàlàyé ìdí tí a kò fi nlo àwòrán àgbélèbú, mo fẹ́ kí ìjìnlẹ̀ ìtẹríba àti ìwúrí wa ó hàn kedere pùpọ̀ fún ìdí tí ó kún fún ìgbàgbọ́ àti ìgbé ayé ìfọkànsìn tí àwọn tí wọ́n nṣe bẹ́ẹ̀.
Ìdí kan tí a kò fi tẹnumọ́ àgbélèbú bíi àmì kan jáde láti inú àwọn gbòngbò Bíbélì wa. Nítorípé ìkànmọ́ àgbélèbú jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọ̀nà ìrora jùlọ tí Ìjọba Roman fi npani, púpọ̀ àwọn atẹ̀lé Jésù àkọ́kọ́ yàn láti má fiyèsí ohun èlò burúkú ti ìjìyà náà. Ìtumọ̀ ikú Jésù dájúdájú wà ní ààrin gbùngbùn ìgbàgbọ́ wọn, ṣùgbọ́n fún ọgọ́rũn mẹ́ta ọdún wọ́n maa nlépa láti gbé ìdánimọ̀ ìhìnrere wọn nípasẹ̀ àwọn ọ̀nà míràn.6
Ní bíi sẹ́ntíúrì kẹrin àti ìkarũn, àgbélèbú di fífihàn bíi àmì kan fún ẹ̀sìn Krístẹ́nì gbogbogbò, ṣùgbọ́n tiwa kìí ṣe èsìn “Krístẹ́nì gbogbogbò” kan. Ní àìṣe Kátólíkì tàbí Pròtẹ́stantì, àwa jẹ́ ìjọ tí a mú padàbọ̀sípò, ijọ Májẹ̀mú Titun tí a mú padàbọ̀sípò Nípa báyí, àwọn ìṣẹ̀dálẹ̀ àti àṣẹ wa lọ padà ṣaájú àkókò àwọn ìgbìmọ̀, àwọn kókó ìgbàgbọ́, àti àpẹrẹ àwòrán.7 Ní èrò yí, àìsí àmì kan tí ó pẹ́ dé sí lílò wíwọ́pọ̀ jẹ́ ẹ̀rí míràn pé Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn jẹ́ ìmúpadàbọ̀sípò àwọn ìbẹ̀rẹ̀ Krístẹ̀nì tòótọ́.
Ìdí míràn fún àìlo àwọn àgbélèbú alámì ni àtẹnumọ́ wa lórí ìyanu pípé ti iṣẹ́ ìránṣẹ́ Krístì—Àjínde ológo Rẹ̀ áti ìjìyà ìrúbọ àti ikú Rẹ̀. Ní fífa ìlà sí abẹ́ ìbáṣepọ̀ náà, mo kíyèsí àwọn iṣẹ́ ọnà méjì8 tí ó nṣiṣẹ́ bíi àwọn àyíká fún Àjọ Ààrẹ Ìkínní àti Iyejú àwọn Àpóstélì Méjìlá nínú ìpàdé mímọ́ ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ wọn ní tẹ́mpìlì ní ọjọọjọ́bọ̀ ní Salt Lake City. Àwọn àwòrán wọ̀nyí nṣiṣẹ́ bíi àwọn ìránnilétí sí wa nípa iye tí ó jẹ́ sísan àti ìṣẹ́gun tí a borí nípasẹ̀ ẹni tí àwa í ṣe ìránṣẹ́ Rẹ̀.9
Àgbékalẹ̀ ti gbogbo ìlú kan nípa ìṣẹ́gun alábala méjì ti Krístì ni bí a ṣe nlo àwòrán kékeré ti Thorvaldsen yí ti Krístì tó jínde tí ó nfarahàn nínú ògo láti ibojì pẹ̀lú àwọn àpá ti Ìkànmọ́ àgbélèbú Rẹ̀ tí ó sì hàn síbẹ̀.9
Ní ìparí, a nrán ara wa letí pé Ààrẹ Gordon B. Hinckley ti kọ́ni nígbàkanrí pé, “Ìgbé ayé àwọn ènìyàn wa gbọdọ̀ [jẹ́] … àpẹrẹ [ìgbàgbọ́] wa.”10 Àwọn àgbéyẹ̀wò wọ̀nyí—pàápàá èyí tó kẹ́hìn—mú mi wá sí ohun tí ó le jẹ́ pàtàkì jùlọ nínú gbogbo àwọn àtọ́ka ti ìwé mímọ́ sí àgbélèbú. Kò ní ohun kan ṣe pẹ̀lú àwọn pẹ́ndántì tàbí ohun ọ̀ṣọ́, pẹ̀lú àwọn ilé ìṣọ́ tàbí àwọn àmì-ìjúwe. Ó ní í ṣe, dípò rẹ̀, pẹ̀lú ìṣòtítọ́ tí ó ní ìhà-òkúta àti ìwà tó ní ẹ̀hìn líle tí ó yẹ kí àwọn Krístẹ́nì mú wá sí ìpè tí Jésù ti fi fún gbogbo àwọn ọmọlẹ́hìn Rẹ̀. Ní gbogbo ilẹ̀ àti ọjọ́ orí, Ó ti sọ fún gbogbo wa pé: “Bí ọkùnrin [tàbí obìnrin] kankan bá nfẹ́ láti tọ̀ mí lẹ́hìn, kí ó sẹ́ ara rẹ̀, kí o sì gbé àgbélèbú rẹ, kí o sì máa tọ̀ mí lẹ́hìn.”10
Èyí sọ nípa àwọn àgbélèbú tí a ngbé dípò àwọn èyí tí a nwọ̀. Láti jẹ́ àtẹ̀lé Jésù Krístì a níláti gbé ẹrù kan ní àwọn ìgbàmíràn—ti ara yín tàbí ti ẹlòmíràn—kí ẹ sì lọ sí ibi tí ìrúbọ ti jẹ́ dandan àti tí ìjìyà kò ṣeé yẹra fún. Krístẹ́nì tòótọ́ kan kò le tẹ̀lé Olùkọ́ni nínú àwọn ọ̀ràn wọnnì tí wọ́n bá fọwọ́sí nìkan, lọ́kùnrin lóbìnrin. Rárá. A ó tẹ̀lé E níbigbogbo, pẹ̀lú, bí ó bá ṣe dandan, sí àwọn ibi tí ó kún fún omijé àti ìdààmú, níbi tí, nígbàmíràn, a le ní ìdúró ní àwa nìkan gan an.
Mo mọ àwọn ènìyàn, nínú àti ní òde Ìjọ, tí wọ́n ntẹ̀lé Krístì pẹ̀lú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́. Mo mọ àwọn ọmọdé tí wọ́n ní àwọn àfojúrí àìpé ara tó le gan, mo sì mọ àwọn òbí tí ó nṣe ìtọ́jú fún wọn. Mo rí tí gbogbo wọn nṣiṣẹ́ nígbàmíràn dé ojú rírẹ̀ pátápátá, ní lílépa okun, ààbò, àti àwọn àkókò ayọ̀ tí kìí wá ní ọ̀nà míràn. Mo mọ àwọn ànìkàngbé tí wọn npòngbẹ fún, àti tí wọ́n yẹ láti ní, olùfẹ́ni ojúgbà, ìgbeyàwó dáradára, àti ilé tí ó kún fún àwọn ọmọ tí ara wọn. Kò sí ìfẹ́ inú tí ó le jẹ́ ti òdodo jù èyí, ṣùgbọ́n ọdún lẹ́hìn ọdún síbẹ̀ irú oríire bẹ́ẹ̀ kò tíi wá. Mo mọ àwọn tí wọ́n njà pẹ̀lú àrùn ọpọlọ onírúurú, tí wọ́n nbẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ bí wọ́n ṣe ngbàdúrà tí wọ́n sì nretí fún ilẹ̀ ilérí ti jíjẹ́ wíwòsàn. Mo mọ àwọn tí wọ́n ngbé pẹ̀lú àìní líle koko ṣùgbọ́n, ní títako àìnírètí, nbèèrè fún ààyè láti mú ìgbé ayé dídára síi bá àwọn olólùfẹ́ wọn àti àwọn ẹlòmíràn nínú àìní ní ayíká wọn. Mo mọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí wọ́n wà ní ìjàkadì pẹ̀lú àwọn ìrora ọ̀rọ̀ ìdánimọ̀, ẹ̀yà lákọ-lábo, àti ti ìbálòpọ̀. Mo sunkún fún wọn, mo sì sunkún pẹ̀lú wọn, ní mímọ̀ bí àwọn àyọrísí àwọn yíyàn wọn yío ti ṣe pàtàkì tó.
Ìwọ̀nyí ni díẹ̀ lára ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ipò ìdánniwò tí a le dojúkọ ní ìgbé ayé, àwọn ìránnilétí pẹ̀lú ọ̀wọ̀ pé ìdíyelé kan wà sí jíjẹ́ ọmọ ẹ̀hìn tòótọ́. Bí Ọba Dáfídì ti sọ fún Áráúnà, ẹnití ó gbíyànjú láti fún ọba ní akọ màlúù àti igi lọ́fẹ̀ẹ́ fún ẹbọ-ọrẹ sísun rẹ̀, “Rárá; ṣùgbọ́n dájúdájú èmi yío rà á ní ọwọ́ rẹ fún iye kan: … [nítorí èmi] kò [ní] fi … fún Olúwa Ọlọ́run mi … èyíinì tí kò ná mi ní iye kankan.”12 Bẹ́ẹ̀, bákannáà, ni gbogbo wa sọ.
Bí a ti ngbé àwọn àgbélèbú wa sókè tí a sì ntẹ̀lé E, yío jẹ́ ohun búburú ní tòótọ́ bi ìwúwo àwọn ìpèníjà wa kò bá mú kí a máa ṣàánú síi fún àti kí a sì máa fétísí àwọn ẹrù tí àwọn ẹlòmíràn ngbé. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àìbáramu ti Ìkànmọ́ àgbélèbú pé àwọn apá Olùgbàlà wà ní nínà gbalaja àti ní fífi ìṣó kàn síbẹ̀, ní àìmọ̀ ṣùgbọ́n ní pípé nfihàn pé olukúlùkù ọkùnrin, obìnrin, àti ọmọdé ní gbogbo ìran ènìyàn kìí ṣe pé wọ́n káàbọ̀ nìkan ṣùgbọ́n a pè wọ́n bákannáà sínú ìgbàmọ́ra ìràpadà, ìgbéga Rẹ̀.14
Bí Àjínde ológo ti tẹ̀lé Ìkànmọ́ àgbélèbú onírora, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìbùkún onírúurú ndi títú jáde sórí àwọn tí wọ́n bá fẹ́, bí wòlíì Jákọ́bù inú Ìwé ti Mọ́mọ́nì ti sọ, láti “gbàgbọ́ nínú Krístì, kí a sì wo ikú rẹ̀, kí a sì jìyà àgbélèbú rẹ̀.”14 Nígbàmíràn àwọn ìbùkún wọ̀nyí nwá kíákíá àti nígbàmíràn wọ́n le wá lẹ́hìnwá, ṣùgbọ́n ìparí yíyanilẹ́nu sí ipa ọ̀nà ṣíṣòro pẹ̀lú ìrora ti ara ẹni wa14 ni ìlérí láti ọ̀dọ̀ Olùkọ́ni fúnra Rẹ̀ pé wọn wá. Láti gba irú ọ̀pọ̀ bẹ́ẹ̀, mo gbàdúrà pé a ó tẹ̀lé E—láìkùnà, láìkáàrẹ̀ tàbí sá lọ, láìtijú sí iṣẹ́ náà, kìí ṣe nígbàtí àwọn àgbélèbú náà bá wúwo kìí sì í ṣe nígbàtí ipa ọ̀nà náà bá dúdú, fún ìgbà díẹ̀, ní orúkọ Jésù Krístì, àmín. Fún okun yín, ìfọkàntán yín, àti ìfẹ́ yín, mo fi ìjìnlẹ̀ ìmoore ti ara ẹni hàn. Lóni yí mo jẹ́ ẹ̀ri bíi àpóstélì nípa Rẹ̀ ẹnití a “gbé sókè”15 àti nípa àwọn ìbùkún ayérayé tí Ó nfífún àwọn wọnnì tí a “gbé sókè” pẹ̀lú Rẹ̀, àní Olúwa Jésù Krístì, àmín