Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ṣíṣìkẹ́ àti Jíjẹ́ Ẹ̀rí Yín
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2022


Ṣíṣìkẹ́ àti Jíjẹ́ Ẹ̀rí Yín

Mo pè yín láti wá àwọn ànfàní láti jẹ́ ẹ̀rí yín ní ọ̀rọ̀ àti ní iṣẹ.

Ọ̀rọ̀-ìṣíwájú

Àwọn àkokò onítumọ̀ nínú ayé nwá léraléra àti ní àìròtẹ́lẹ̀, àní nígbàtí ẹ ṣì wà ní ọ̀dọ́. Ẹ fi ààyè gbà mí láti pín ìtàn kan nípa akẹkọ ilé ìwé gíga kan, Kevin, ó yàn láti rin ìrìnàjo jáde ní ìpínlẹ̀ fún ìṣẹ̀lẹ̀ olórí akẹkọ, bí a ti sọ nínú ọ̀rọ ararẹ̀.

“Àkokò mi lórí ìlà dé, akọ̀wé ìforúkọsílẹ̀ pẹ̀lú ìwò ibi-iṣẹ́ sì bèèrè fún orúkọ mi. Ó wo àkójọ rẹ̀ ó sì wípé, ‘Bẹ́ẹ̀ni ìwọ ni ọ̀dọ́mọkùnrin láti Utah.’

“‘Àbí ìwọ wípé èmi nìkanṣoṣo ni ?’ Mo bèèrè.

“‘Bẹ́ẹ̀ni, ìwọ nìkanṣoṣo ni.’ Ó fún mi ní orúkọ àlẹ̀mọ́ pẹ̀lú ‘Utah’ tí a tẹ̀ sí abẹ́ orúkọ mi. Bí mo ti fi kọ́ ara, mo nímọ̀ bí ẹnipè a sàmi sími.

“Mo bá àwọn èrò wọnú ẹ̀rọ-àtẹ̀gùn ilé ìtura pẹ̀lú àwọn akẹkọ marun ilé ìwé gíga míràn pẹ̀lú àlẹ̀mọ́ orúkọ bíi ti èmi. ‘Héè, ìwọ wá láti Utah. Ṣé Mọ́mọ́nì ni ìwọ?’ ni akẹkọ kan bèèrè.

“Mo ní ìmọ̀lára àìrẹnifojújọ pẹ̀lú gbogbo àwọn olórí akẹkọ wọ̀nyí láti gbogbo orílẹ̀-èdè káàkiri. ‘Bẹ́ẹ̀ni,’ mo fi ìlọ́ra gbà á.

“‘Ẹ̀yin ni àwọn tí wọ́n gbàgbọ́ nínu Joseph Smith, ẹni tí ó wípé òun rí àwọn ángẹ́lì. Ìwọ kò gbà èyí gbọ́ lódodo, àbí o gbà á?’

“Èmi ko mọ ohun tí èmi ó sọ. Gbogbo àwọn akẹkọ nínú ẹ̀rọ-àtẹ̀gùn náà nwò mí. Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ dé, gbogbo ènìyàn sì rò pé mo yàtọ̀. Mo di olùgbèjà díẹ̀ kan ṣùgbọ́n lẹ́hìnnáà ó wípé, ‘mo mọ̀ pé Joseph Smith ni wòlíì Ọlọ́run.’

“Níbo ni ìyẹn ti wá? Mo ròó. Èmi kò mọ̀ pé mo ni nínú mi. Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀rọ̀ náà dàbí òtítọ́.

“‘Bẹ́ẹ̀ni, a wí fún mi pé gbogbo yín kàn jẹ́ ẹlẹ́sìn kóró ni,’ ó wí.

“Pẹ̀lú èyí, ìdádúró àìnítùnú kan wà bí a ti ṣí ilẹ̀kùn ẹ̀rọ-àtẹ̀gun náà. Bí a ti kó àwọn ẹrù wa jọ, ó rìn lọ sísàlẹ̀ gbàgede ó nrẹrin.

“Nígbànáà, ohùn kan ní ẹ̀hìn mi bèèrè, ‘Héè, njẹ́ àwọn Mọ́mọ́nì kò ní Bíbélì míràn bí?’

“Ah rárá. Kìí ṣe lẹ́ẹ̀kansi. Mo yí padà sí akẹkọ míràn tí ó ti wà nínú ẹ̀rọ̀-àtẹ̀gùn pẹ̀lú mi, Christopher.”

“‘A pè é ní Ìwé ti Mọ́mọ́nì,’ ni mo wí, ní ìfẹ́ láti fi ọ̀rọ̀ náà sílẹ̀. Mo gbé àwọn àpò mi mo sì bẹ̀rẹ̀ sí rìn sísàlẹ̀ gbàgede.

“‘Ṣé ìwé tí Joseph Smith túmọ̀ ni?’ ó bèèrè.

“‘Bẹ́ẹ̀ni, òun ni,’ ni mo dáhùn. Mo tẹramọ́ rínrìn, ní ìrètí láti yẹra fún dídi alágọ̀.

“‘Ó dára, ṣe ìwọ mọ bí mo ti lè gba ọ̀kan?’

“Ìwé mímọ́ kan tí mo kọ́ nínú ìdánilẹ́kọ́ wá sí mi lọ́gán. ‘Èmi kò tijú ìhìnrere ti Jésù Krístì.’1 Bí èyí ti wọ iyè-inú mi, mo nímọ̀lára ìtìjú pé mo ti di alágọ gidi.

“Fún ìyókù ọ̀sẹ̀ náà ìwé mímọ́ kò fi mí sílẹ̀. Mo dáhùn àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbèèrè nípa Ìjọ bí mo ti lè ṣe, mo sì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀rẹ́.

“Mo ṣe àwárí pé mo nígbéraga nípa ẹ̀sìn mi.

“Mo fún Christopher ní Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Ó kọ̀wé sí mi lẹ́hìnnáà, ó wí fún mi pé òun ti pe àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere sí ilé rẹ̀.

“Mo kọ́ láti máṣe di alágọ̀ láti pín ẹ̀rí mi.”2

Mo ní ìmísí nípa ìgboyà Kevin ní pípín ẹ̀rí rẹ̀. Ó jẹ́ ìgboyà léraléra ní ojojúmọ́ nípasẹ̀ àwọn ọmọ Ìjọ káàkiri ayé. Bí mo ti npín èrò mi, mo pè yín láti ronú lórí àwọn ìbèèrè mẹ́rin wọ̀nyí:

  1. Ṣé mo mọ̀ tí mo sì ní ìmọ̀ ohun tí ẹ̀rí kan jẹ́?

  2. Ṣé mo mọ bí èmi ó ti jẹ́ ẹ̀rí mi?

  3. Kíni àwọn ìdíwọ́ ní pípín ẹ̀rí mi?

  4. Báwo ni èmi ó ti pa ẹ̀rí mi mọ́?

Ṣé Mo Mọ̀ tí Mo sì ní ìmọ̀ Ohun tí Ẹ̀rí kan Jẹ́?

Ẹ̀rí yín ni ìní iyebíye jùlọ, tí ó rọ̀mọ́ ìyárí ìmọ̀lára ti ẹ̀mí nígbàkugbà. Ìmọ̀lára wọ̀nyí wọ́pọ̀ ní ìwífúnni kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ tí a sì júwe bí “ohùn jẹ́jẹ́ kékeré.”3 Ìgbàgbọ́ yín tàbí ìmọ̀ òtítọ́ tí a fúnni bí ẹ̀rí ti ẹ̀mí nípasẹ̀ agbára Ẹmí Mímọ́ ni. Gbígba ẹ̀rí yí yíò yí ohun tí ẹ wí àti ohun tí ẹ ṣe. Kókó ohun èlò ẹ̀rí yín, tí a fi ẹsẹ̀ rẹ̀ múlẹ̀ nípasẹ̀ Ẹmí Mímọ́, pẹ̀lú:

  • Ọlọ́run ni Baba yín Òrun, ẹ̀yin ni ọmọ Rẹ̀. Ó fẹ́ràn yín.

  • Jésù Krístì wà láàyè. Òun ni Ọmọ Ọlọ́run alààyè àti Olùgbàlà àti Olùràpadà yín.

  • Joseph Smith ni wòlíì Ọlọ́run tí a pè láti mú Ìjọ ti Jésù Krístì padàsípò.

  • Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn jẹ́ Ìjọ Ọlọ́run tí a múpadà sí orí ilẹ̀ ayé.

  • Ìjọ Jésù Krístì tí a múpadàbọ̀sípò ni à ndarí nípasẹ̀ wòlíì alàyè ní òní.

Ṣé Mo Mọ Bí Èmi ó ti Jẹ́ Ẹ̀rí Mi?

Ẹ̀ njẹ́ ẹ̀rí yín nígbà tí ẹ bá pín ìmọ̀lára ti ẹ̀mí pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Bí ọmọ Ìjọ, àwọn ànfàní láti jẹ́ ẹ̀rí àìsọjáde yín nwá nínú àwọn ìpàdé Ìjọ ti ìṣe tàbí nínú ìdínkù ti ìṣe, ọ̀kan sí ọ̀kan àwọn ìbárasọ̀rọ̀ pẹ̀lú ẹbí, ọ̀rẹ́, àti àwọn ẹlòmíràn.

Ọ̀nà míràn tí ẹ fi npín ẹ̀rí yín ni nípasẹ̀ ìwà òdodo. Ẹ̀rí yín nínú Jésù Krístì kìí ṣe ohun tí ẹ̀ nsọ lásán—ẹni tí ẹ jẹ́ ni.

Ìgbà kọ̀ọ̀kan tí ẹ bá jẹ́ ẹ̀rí sísọ tàbí júwe nípasẹ̀ àwọn ìṣe ìfarasìn yín láti tẹ̀lé Jésù Krístì, ẹ npè àwọn ẹlòmíràn láti “wá sọ̀dọ̀ Krístìtì.”2

Àwọn ọmọ Ìjọ dúró bi àwọn ẹlẹri Ọlọ́run ni ìgbà gbogbo, nínú ohun gbogbo, àti ni ibi gbogbo.5 Àwọn ànfàní láti ṣe èyí nínú ohun ìgbàlóde gbogbo ayé ní lílo ìmísí ohun ti ara wa tàbí pípín ohun ìgbéga tí a múrasílẹ̀ nípasẹ̀ àwọn ẹlòmíràn tí kò lónkà. A jẹ́ ẹ̀rí nígbàtí a ba nifẹ, tí a pín, tí a sì pè lórí ayélujára. Àwọn ìfiránṣẹ́ yín, ọ̀rọ̀ tàarà, àti àlẹ̀mọ́ yíò gba èrò gígaju, mímọ́ jù nígbàtí ẹ bá lo ìròhìn àwùjọ látifi bí ìhìnrere Jésù Krístì ti tún ayé yín ṣe hàn.

Kíni Àwọn Ìdíwọ́ Ní Pípín Ẹ̀rí Mi?

Àwọn ìdíwọ́ sí pínpín ẹ̀rí yín lè pẹ̀lú àìní-ìdánilójú nípa ohun tí a ó sọ. Matthew Cowley, Àpóstélì ìṣíwájú, pín ìrírí rẹ̀ bí ó ti lọ ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ ọdún marun ní ọmọ ọjọ́ orí mẹ́tàdínlógún lọ sí New Zealand:

“Èmì kò ní gbàgbé àwọn àdúrà baba mi ní ọjọ́ náà tí mo kúrò. … Èmi kò tíì gbọ́ irú ìbùkún dídára bẹ́ẹ̀ rí ní gbogbo ayé mi. Nígbà náà ọ̀rọ̀ ìkẹ́hìn rẹ̀ sí mi ni … , ‘Ọmọkùnrin mi, ìwọ ó lọ ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ … àti nígbàmíràn nígbà tí a bá pè ọ, ìwọ ó rò pé a múra rẹ sílẹ̀ pẹ̀lú ìyanu, ṣùgbọ́n nígbàtí o bá dúró sókè, iyè-inú rẹ yíò ṣófo gbalau.’ … Mo ti ní ìrírí náà ju ìgbà kan lọ

“Mo wípé, ‘Kíni ìwọ ó ṣe nígbàtí iyè-inú rẹ bá ṣófo gbalau?’

“Ó wípé, ‘Ìwọ ó dìde níbẹ̀ àti pẹ̀lú gbogbo ìtiraka ẹ̀mí rẹ̀, jẹ́ ẹ̀rí pé Joseph Smith ni wòlíì Ọlọ́run alààyè, àti pé àwọn èrò yíò ṣàn sí iyè-inú rẹ àti àwọn ọ̀rọ̀ sí ẹnu rẹ … sí ọkàn gbogbo ẹni tí ó fetísílẹ̀.’ Nítorínáà inú mi, wà ní ṣíṣòfo gbalau ni ọ̀pọ̀ ìgbà jùlọ nínú … míṣọ́n mi … , ó fún mi ní ànfàní láti jẹ́ ẹ̀rí sí ìṣẹ̀lẹ̀ nínú àkọọ́lẹ̀ ìtàn ayé látigbà ìkànmọ́-àgbélèbú Olùkọ́ni. Ẹ gbìyànjú rẹ̀ nígbàmíràn, ẹ̀yin akẹ́gbẹ́ àti obìnrin. Bí o kò bá ní ohunkóhun míràn láti sọ, jẹri pé Joseph Smith ni wòlíì Ọlọ́run, àti pé gbogbo àkọọ̀lẹ̀ ìtàn Ìjọ yíò ṣàn lọ sí iyè inú rẹ̀.”4

Bákannáà, Ààrẹ Dallin H. Oaks pín pé, “Àwọn ẹ̀rí ni à njèrè dáradára ní ẹsẹ̀ tí ó ngbé wọn ju orí eékún tí ó ngbàdúrà fún wọn lọ.”7 Ẹ̀mí njẹ́ ẹ̀rí sí olùsọ̀rọ̀ àti olùfetísílẹ̀ bákannáà.

Ìdíwọ́ míràn, bí ìtàn Kevin ti tẹnumọ, ni ìbẹ̀rù. Bí Páùlù ti kọwé sí Tímótéù:

“Nítorí Ọlọ́run kò fún wa ní ẹ̀mí ìbẹ̀rù, ṣùgbọ́n ti agbára, àti ìfẹ́. …

“Nítorínáà ẹ máṣe tijú ẹ̀rí Olúwa wa.”6

Ìmọ̀lára ẹ̀rù kìí wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa ṣùgbọ́n ọ̀tá. Níní ìgbàgbọ́, bí Kevin ti ṣe, yíò fi ààyè gbà wá láti borí àwọn ìmọ̀lára wọ̀nyí àti pípín ohun tí ó wà ní ọkàn wa ní ọ̀fẹ́.

Báwo Ni Èmi Ó Ti Pa Ẹ̀rí Mi Mọ́?

Mo gbàgbọ́ pé ẹ̀rí wa wà nínú wa, síbẹ̀, nínú èrò láti tẹramọ àti láti mú u dàgbà, Alma kọ́ni pé a gbọ́dọ̀ ṣìkẹ́ ẹ̀rí wa pẹ̀lú ìtọ́jú púpọ̀.9 Bí a ti nṣe bẹ́ẹ̀, “yíò ní gbòngbò, yíò sì dàgbà sókè, yíò sì mú èso jáde.”7 Láìsí èyí “yíò gbẹ dànù.”8

Àyànfẹ́ ọmọ ìjọ kọ̀ọ̀kan ti Àjọ Ààrẹ Ìkínní ti pèsè wa pẹ̀lú ìdarí lórí bí a ti lè pa ẹ̀rí kan mọ́.

Ààrẹ Henry B. Eyring fi tìfẹ́tìfẹ́ kọ́ wa pé “ṣíṣe àpèjẹ lórí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àdúrà àtinúwá, àti ìgbọràn sí àwọn o`fin Olúwa gbọ́dọ̀ lo ẹ̀rí yín déédé àti léraléra kí ó lè dàgbà kí ó sì yege.”12

Ààrẹ Dallin H. Oaks rán wa létí pé láti mú ẹ̀rí wa dúró, “a nílò láti ṣe àbápín oújẹ Olúwa ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ (wo D&C 59:9) láti yege fún ìlérí oníyebíye pé a ó ní ‘Èmí Rẹ̀ pẹ̀lú [wa] nígbàgbogbo’ (D&C 20:77).”13

Ààrẹ Russell M. Nelson sì fi inúrere gbàwálámọ̀ràn láìpẹ́:

“Ẹ bọ́ [ẹ̀rí òtítọ́] yín. …

“… Ẹ ṣìkẹ́ arayín nínú ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì àtijọ́ àti ti òde òní. Ẹ ní kí Olúwa kọ́ yín bí ẹ ó ti gbọ́ Ọ dáradára. Ẹ lo àkokò síi nínú tẹ́mpìlì àti nínú iṣẹ́ àkọọ́lẹ̀ ìtàn.

“… Ẹ mú ẹ̀rí yín jẹ́ ìṣíwájú gígajùlọ.”14

Ìparí.

Ẹ̀yin olólùfẹ́ arákùnrin àti arábìnrin, mo ṣe ìlérí pé bí ẹ ti nní ìmọ́ níkíkún ohun tí ẹ̀rí jẹ́, tí ẹ sì npin in, ẹ yíò borí àwọn ìdíwọ́ ti àìnírètí àti ẹ̀rù, ìlèṣe yín láti ṣìkẹ́ àti láti pa ìní iyebíye jùlọ yí, ẹ̀rí yín mọ́.

A di alábùkún láti ní àìlónkà àwọn àpẹrẹ àwọn wòlíì àtijọ́ àti ti òde òní tí wọ́n nfi ìgboyà jẹ́ ẹ̀rí wọn.

Títẹ̀lé ikú Krístì, Pétérù dúró ó sì jẹri:

“Kí èyí kí ó ye gbogbo yín … pé ní orúkọ Jésù Krístì ti Nazareth, tí ẹ̀yin kàn mọ́ àgbélèbú, tí Ọlọ́run gbé dìde kúrò nínú òkú, … nípa rẹ̀ ni ọkùnrin yí fi dúró níwájú yín. …

“…Nítorí kò sí orúkọ míràn lábẹ́ ọ̀run tí a fifúnni nínú ènìyàn, nípa èyí tí a lè fi gbà wá là.”10

Ní Títẹ̀lé ìwàásù Álmà lórí ìgbàgbọ́, Ámúlẹ́kì sọ̀rọ̀, pẹ̀lú agbára pé: “Èmi ó jẹ́ẹ̀rí fúnrami pé òtítọ́ ni àwọn ohun wọ̀nyí íṣe. Ẹ kíyèsĩ, èmi wí fún nyín, pé èmi mọ̀ pé Krístì nbọ̀wá sí ãrin àwọn ọmọ ènìyàn, … àti pé òun yíò sì ṣe ètùtù fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àráyé; nítorítí Olúwa Ọlọ́run ni ó ti wí i.”11

Joseph Smith àti Sidney Rigdon, lóri jíjẹ́ẹ̀rí ìran ológo Olùjínde Olùgbàlà, jẹri pé:

“Àti nísisìyí, lẹ́hìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀rí tí a ti fúnni nípa rẹ̀, ìpari gbogbo rẹ̀, èyí tí a fúnni nípa rẹ̀ ni: Pé ó wà láàyè!

“Nítorí a ri i, àní ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run; a sì gbọ́ ohùn rẹ̀ tí ó njẹ́ ẹ̀rí pé òun ni Ọmọ Bíbí Kanṣoṣo ti Baba.”12

Ẹ̀yin arakùnrin àti arábìnrin, mo pè yín láti wá àwọn ànfàní láti jẹ́ ẹ̀rí yín ní ọ̀rọ̀ àti ní iṣẹ. Irú ànfàní kan wá sọ́dọ̀ mi láìpẹ́, ní òpin ìpàdé kan pẹ̀lú Máyọ̀ ti olú ìlú-nlá ní Gúsù Amẹ́ríká, nínú ìyẹ̀wù rẹ̀ pẹ̀lú iye àwọn òṣìṣẹ́ tí ó nbá gbìmọ̀. Bí a ti parí pẹ̀lú àwọn ìmọ̀lára bíbárẹ́ gan, mo fi ìlọ́ra ronú pé èmi níláti pín ẹ̀rí mi. Títẹ̀lé ìṣílétí náà, mo fi ẹ̀rí kan fúnni pé Jésù Krístì ni Ọmọ Ọlọ́run alààyè àti Olùgbàlà ayé. Gbogbo nkan yípadà ní àkokò náà. Ẹ̀mí náà nínú yàrá ni a kò lè sẹ́. Ó dàbí gbogbo ènìyàn ní ó ní ìfọwọ́tọ́. “Olútúnú náà … ṣe àkọsílẹ̀ nípa Baba àti Ọmọ.”18 Mo dúpẹ́ gidi mo sì wá ìgboyà láti jẹ́ ẹ̀rí mi.

Nígbàtí àkokò kan bíiti èyí bá wá, ẹ dìí mú kí ẹ sì gbà á mọ́ra. Ẹ lè ní ìmọ̀lára ìyárí ti Olùtùnú nínú yín nígbàtí ẹ bá ṣe é.

Mo fi ẹ̀rí àti ijẹri mi fún yín, Ọlọ́run ni Baba Ọ̀run, Jésù Krístì wà láàyè, àti Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ni Ìjọ Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé ní òní tí a ndarí nípasẹ̀ wòlíì wa ọ`wọ́n, Ààrẹ Russell M. Nelson. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Tẹ̀