Jẹ́ Pípé Nínú Rẹ̀
Pípé wa ṣeéṣe nìkan nípasẹ̀ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.
Baba wa Ọ̀run àti Olùgbàlà wa, Jésù Krístì ní agbára láti gbàwá là, kí wọ́n sì yíwa padà. Wọ́n lè rànwá lọ́wọ́ láti dà bíi Tiwọn.
Ní ọdún díẹ̀ sẹ́hìn, ọ̀kan lára àwọn ọmọ-ọmọ wa ọkùnrin, Aárọ́nì, bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìṣòro àìlera. Ó rẹ̀ ẹ́, ó ní ọgbẹ́ díẹ̀, kò sì ní ìlera. Lẹ́hìn tí wọ́n ti ṣe àyẹ̀wò ìṣègùn, wọ́n ṣàwárí rẹ̀ pé ó ní àìlera tó le gan-an, àìsàn kan níbi tí ọ̀rá inú egungun rẹ̀ ti dáwọ́ mímú àwọn sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀ pupa, sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀ funfun àti àwọn pílátélétì jáde. Láìsí ìtọ́jú àti ìwòsàn kan nígbẹ̀hìn, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ kò lè di dídì dáadáa tàbí kó gbógun ti àwọn àrùn ìkóràn, àní àwọn ìṣubú kékèké, ọgbẹ́, tàbí àìsàn lè yára di ewu-ìyè.
Fún àkokò kan, ó gba pílátélétì déédé àti fífúnni lẹ́jẹ̀ láti pa á mọ́ kúrò nínú ewu. Àwọn dókítà ṣàlàyé pé òògùn kanṣoṣo fún títọ́jú àrùn náà yíò jẹ́ pípàrọ̀ ọ̀rá inú egungun, àti pé àyè tí ó dára jùlọ fún àṣeyọrí ni láti ní arákùnrin kan gẹ́gẹ́bí olùtọrẹ. Bí ọ̀kan nínú àwọn arákùnrin rẹ̀ bá jẹ́ ìbámu pípé, àbájáde ti pípàrọ̀ lè jẹ́ ìgbàlà ẹ̀mí. Àwọn arákùnrin àbúrò rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ni a dánwò, àti ọ̀kan, Maxwell, ni a rò pé ó báamu pípé.
Pàápàá pẹ̀lú ìbáramu olùtọrẹ pípé, pípa`rọ̀ ọ̀rá inú egungun tún jẹ́ ewu nlá ti àwọn ìdíjú. Ìlànà náà nílò pé a`wọn sẹ́ẹ̀lì Aárọ́nì ti ara rẹ̀ a`ìsàn ọ̀rá inú egungun rẹ̀ ni a parun nípasẹ̀ a`papọ̀ kẹmotẹ́rápì a`ti rediáṣọ̀n ṣaájú gbígba a`wọn sẹ́ẹ̀lì láti ọ̀rá inú egungun arákùnrin Maxwell. Lẹ́hìnnáà nítorí ètò àjẹsára ti Aárọ́nì ti bàjẹ́, ó nílò kí a yà á sọ́tọ̀ ní ilé ìwòsàn fún àwọn ọ̀sẹ̀ púpọ̀ àti lẹ́hìnnáà ní ilé fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn oṣù pẹ̀lú àwọn ìlànà pàtàkì, àwọn ìhámọ́, àti àwọn òògùn.
Àbájáde tí a nretí láti ibi ìpàrọ̀ ni pé ara Aárọ́nì kò ní kọ àwọn sẹ́ẹ̀lì olùtọrẹ sílẹ̀ àti pé àwọn sẹ́ẹ̀lì Maxwell yíò mú àwọn sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀ pupa àti funfun tí a nílò jáde díẹ̀díẹ̀ àti àwọn pílátélétì nínú ara Áárónì. Àṣeyọri olùtọrẹ ìpàrọ̀ fa ìyípadà ti ìṣe-ara gidi kan. Ó yani lẹ́nu pé dókítà kan ṣàlàyé pé bí Aárọ́nì bá ṣẹ̀, tí ó sì fi ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ ní ibi tí ìwà ọ̀daràn náà ti wáyé, àwọn ọlọ́pàá lè mú arákùnrin rẹ̀ Maxwell. Èyí jẹ́ nítorí pé ẹ̀jẹ̀ Aárọ́nì yíò wa láti inú àwọn sẹ́ẹ̀lì Maxwell tí a pàrọ̀ àti pé ó ní DNA Maxwell, àti pé èyí yíò jẹ́ ọ̀ràn fún ìyókù ìgbésí ayé rẹ̀.
Níwọ̀n ìgbà tí a ti gba Áárónì là nípa ẹ̀jẹ̀ arákùnrin rẹ̀ ti ru ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrònú nípa ètùtù ẹ̀jẹ̀ Jésù Krístì àti ipa Ètùtù Rẹ̀ lórí wa sókè. Èmi yíò fẹ́ láti dojúkọ ìyípadà ayérayé lónìí, tí ó nfúnni ní ìgbé àyé tí ó wáyé bí a ṣe ngba Olúwa láàyè láti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu nínú wa.1
Aárọ́nì kò ní agbára nínú ara rẹ̀ láti borí àrùn náà. Ara rẹ̀ kò lè ṣe àwọn sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀ tí ó nílò láti ṣètọ́jú ìgbésí ayé rẹ̀. Ohun yòówù kí òun fúnra rẹ̀ ṣe, kò lè wo ọ̀rá inú egungun rẹ̀ sàn. Gẹ́gẹ́bí Aárọ́nì kò ṣe lè wo ara rẹ̀, a kò lè gba ara wa là. Bí ó ti wù kí a jẹ́ alágbára tó, tí a kàwé, tí a ní òye, tàbí lágbára to,a kò lè wẹ ara wa mọ́ nínú ẹ̀ṣẹ̀, yí ara wa padà sí ipò àìkú, tàbí gbé ara wa ga. Ó ṣeéṣe nìkan nípasẹ̀ Olùgbàlà Jésù Krístì àti Ètùtù Rẹ̀ tí àìlópin. “Kò sì sí ọ̀nà míràn tàbí orúkọ tí a fi fún ni lábẹ́ ọ̀run nípa èyí tí a lè fi gba ènìyàn là ní ìjọba Ọlọ́run.”2 Ètùtù ẹ̀jẹ̀ Rẹ̀ ni ó wẹ̀ wá tí ó sì sọ wá di mímọ́.3
Bíótilẹ̀jẹ́pé Aaron kò lè wo ararẹ̀ sàn, ní èrò kí gbígbìn náà lè ṣiṣẹ́ òun nílò láti ní ìfẹ́ láti ṣe ohun tí dókítà bèèrè—àní àwọn oun ìpènijà, tí ó ṣòrò gan. Bíótilẹ̀ jẹ́ pé a kò lè gba ara wa là, nígbà tí a bá tẹrí ba fún ìfẹ́ Olúwa tí a sì pa àwọn májẹ̀mú wa mọ́, ọ̀nà náà ṣí sílẹ̀ fún ìràpadà wa.4 Gẹ́gẹ́bí ètò ìyàlẹ́nu ti DNA tí àwọn sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀ Aárọ́nì ti nyípadà, ọkàn wa lè di yíyípadà,5 kí a ní àwòrán Rẹ̀ ní ojú wa,6 kí a sì di ẹ̀dá titun nínú Krístì.7
Álmà rán àwọn ènìyàn Zarahemla létí ti ìran ìṣáájú tí a ti yípadà. Ní sísọ̀rọ̀ nípa baba rẹ̀, Álmà ṣe àlàyé pé “gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ rẹ̀ ìyípadà nlá kan wà tí a ṣe nínú ọkàn rẹ̀.”8 Ó sì bèèrè, “Njẹ́ ẹ̀yin ti ní ìrírí ìyípadà nlá yìi ní ọkàn yín bí?”9 Kìí ṣe àwọn ènìyàn ni ó yí ọkàn ara wọn padà. Olúwa ló ṣe ìyípadà gangan. Álmà ṣe àlàyé púpọ̀ nípa èyí. Ó wípé, “Kíyèsi, ó yí ọkàn wọn padà.”10 Wọ́n “rẹ ara wọn sílẹ̀, wọ́n sì gbẹ́kẹ̀ wọn lé Ọlọ́run tòótọ́ àti alààyè … [wọ́n sì] jẹ́ olóòótọ́ títí dé òpin … [a sì] gbà wọ́n la.”11 Àwọn ènìyàn náà ṣe tán láti ṣí ọkàn wọn sílẹ̀ kí wọ́n sì lo ìgbàgbọ́, nígbà náà Olúwa yí ọkàn wọn padà. Ìyípadà nlá ni ó sì jẹ́! Ronú nípa ìyàtọ̀ nínú ìgbésí ayé àwọn ọkùnrin méjì wọ̀nyí tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ Álmà ṣáájú àti lẹ́hìn tí ọkàn wọn yí padà.12
A jẹ́ àwọn ọmọ Ọlọ́run pẹ̀lú àyànmọ́ ọlọ́lá kan. A lè yípadà láti dà bíi Rẹ̀ àti láti ní “ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ayọ̀.”13 Sátánì, ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, yíò fẹ́ kí a ní ìdààmú bí tirẹ̀.14 A ní agbára láti yàn ẹni tí a ó tẹ̀lẹ́.15 Nígbàtí a bá tẹ̀lé Sàtánì a fi agba´ra fun.16 Nígbàtí a bá tẹ̀lé Ọlọ́run, Ó fún wa ní agbára.
Olùgbàlà kọ́ wa pé “kí a jẹ́ pípé.”21 Èyí lè dàbí ìdẹ́rùbà gidi. Mo lè rí àwọn àìlera araẹni mi kedere kí n sì ní ìfura jíjìn pẹ̀lú ìrora ní àárín mi àti jíjẹ́ pípé. A lè ní ìtẹ̀sí láti ronú pé a ní láti jẹ́ pípé, ṣùgbọ́n ìyẹn kò ṣeéṣe. Títẹ̀lé gbogbo àbá nínú gbogbo ìwé ìrànwọ́ ara ẹni ní ayé kò ní mú un ṣẹ. Ọ̀nà kan ló wà àti orúkọ kan nípa èyítí pípé má nwa. A “sọ wá di pípé nípasẹ̀ Jésù alárinà májẹ̀mú titun, ẹni tí ó ṣe ètùtù pípé yìí nípasẹ̀ ìtasílẹ̀ ẹ̀jẹ̀ ti ara rẹ̀.”22 Pípé wa ṣeéṣe nìkan nípasẹ̀ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.
Njẹ́ o lè fojú inú wo bí yíò ti wúni lórí tó fún Áárónì ọmọ ọmọ wa ọ̀dọ́kùnrin láti rò pé òun gbọ́dọ̀ lóye, kí ó sì ṣe gbogbo ìlànà ìṣègùn tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìpàrọ̀ rẹ̀ fúnra rẹ̀? A níláti rò wípé a nílò láti ṣe ohun tí Olùgbàlà lè ṣe nínú ètò ìyanu ti jíjẹ́ pípé wa.
Bí Mórónì ṣe parí àkọsílẹ̀ rẹ̀, ó kọ́ni: “Bẹ́ẹ̀ni, ẹ wá sọ́dọ̀ Krístì, kí ẹ sì jẹ́ pípé nínú rẹ̀, … bí ẹ̀yin bá sì sẹ́ ara yín ní gbogbo àìwà-bí-Ọlọ́run, tí ẹ sì fẹ́ràn Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo agbára, inú àti okun, nígbà náà oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ ti tó fún yín, kí ẹ lè jẹ́ pípé nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ nínú Kristi”24 Òtítọ́ onítura àti alágbára kan ni! Õre-ọ̀fẹ́ Rẹ̀ tó fún mi Õre-ọ̀fẹ́ Rẹ̀ tó fún yín. Õre-ọ̀fẹ́ Rẹ̀ to fún gbogbo àwon tí “wọ́n sì di ẹrù wúwo lé lórí.”25
Pẹ̀lú a`wọn ìtọ́jú ìṣòògùn bíi ti Áárónì, a`ìdánilójú díẹ̀ wà nínú a`bájáde nígbàgbogbo. Kódà, Áárónì nílò ìpàrọ̀ kejì nígbà tí àkọ́kọ́ ní ìṣòro. A dúpẹ́, pẹ̀lú ìyípadà ọkàn ti ẹ̀mí, kò ní láti yàwá lẹ́nu bóyá yìó ṣẹlẹ̀. Nígbàtí a bá ngbé ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Rẹ̀, “ní gbígbẹ́kẹ̀lé pátápátá lórí àwọn ẹ̀tọ́ ẹni tí ó lágbára láti gbalà,”21 àti gbígba àti pípa àwọn májẹ̀mú ìgbàlà Rẹ̀ mọ́, ìdánilójú ní ọgọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún wà fún ìwẹ̀nùmọ́ nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ Olùgbàlà àti níkẹhìn pípé nínú Rẹ̀. Òun ni “Ọlọ́run òtítọ́, [kò sì] lè purọ́.”22
Kò sí ìbéèrè pé ìlànà ìyípadà yí gba àkokò àti pé kì yíò parí títí lẹ́hìn ayé yí, ṣùgbọ́n ìléríl náà dájú. Nígbà tí ìmúṣẹ àwọn ìlérí Ọlọ́run bá jìnnà, a ṣì ntẹ́wọ́ gba àwọn ìlérí yẹn, ní mímọ̀ pé wọ́n máa di mímú ṣẹ.23
Ìyípadà a`gbàyanu ti ìlera Áárónì ti mú ayọ̀ nlá wá sí ẹbí wa. Fojúinú wo ayọ̀ nlá ní ọ̀run bí àwọn ìyípadà nlá ṣe ṣẹlẹ̀ nínú ọkàn wa.
Bàbá wa Ọ̀run àti Olùgbàlà wa, Jésù Krístì, nífẹ̀ẹ́ wa ó sì ti fi oore-ọ̀fẹ́ fún wa láti yíwa padà àti láti ṣe wá ní pípé. Wọ́n fẹ́ láti ṣe èyí. Ó jẹ́ àáríngbùngbùn sí iṣẹ́ àti ògo wọn.24 Mo jẹ́ríì Wọn ní agbára láti ṣe èyí bí a ti wá sọ́dọ̀ wọn ní ìgbàgbọ́. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.