Gbé agbára rẹ wọ̀, Áà Síónì
Ọ̀kọ̀ọ̀kan wa níláti ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn àfọkànsí wa ní ti ara àti ti ẹ̀mí ní tòótọ́ àti pẹ̀lú àdúrà.
Àwọn òwe ni ẹ̀yà títúmọ̀ ọ̀nà ọgbọ́n-kíkún sí ìkọ́ni Olúwa Jésù Krístì. Títúmọ̀ ní ìrọ̀rùn, àwọn òwé Olùgbàlà jẹ́ ìtàn tí a lò láti ṣe àfiwé òtítọ́ ti ẹ̀mí pẹ̀lú àwọn ohun èlò àti ìrírí ara ikú. Fún àpẹrẹ, ìhìnrere Májẹ̀mú Titun wà ní àtúnsọ pẹ̀lú àwọn ìkọ́ni tí ó nṣe àfiwé ìjọba Ọ̀run sí wóró mústádì kan,1sí píálì olówó iyebíye,2sí onílé àti òṣìṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà rẹ̀,3sí wúndíá mẹwa,4àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn míràn. Ní ìgbà iṣẹ́ iṣẹ́ ìránṣẹ́ Olúwa ní Gálílì, àwọn ìwé mímọ́ fihàn pé “kò bá wọn sọ̀rọ̀ láìsí òwe.”5
Ìgbìrò títúmọ̀ tàbí ọ̀rọ̀ òwe ni a kò fihàn láti yeni déédé. Dípò bẹ́ẹ̀, ìtàn náà gbé òtítọ́ tọ̀run nìkan jáde sí olùgbà ní ìwọ̀n sí ìgbàgbọ́ ẹni náà lọ́kùnrin tàbí lóbìnrin nínú Ọlọ́run, ìmúrasílẹ̀ araẹni ti ẹ̀mí, àti níní ifẹ́ láti kẹkọ. Bayi, ẹnìkan gbọ́dọ̀ lo ìwa agbára láti yàn àti fífi aápọn “bèèrè, wá, àti kànkù”6 láti ṣe àwárí òtítọ́ tí ó wà nínú òwe kan.
Mo gbàdúrà pẹ̀lú ìtara pé Ẹ̀mí Mímọ́ yíò fi ọ̀ye fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wa bí a ti nṣe àyẹwò pàtàkì òwe àpèjẹ ìgbeyàwó ọlọ́ba.
Àpèjẹ Ìgbeyàwó Ọlọ́ba
“Jésù sì … pa òwe fún wọn lẹ́ẹ̀kansi, ò wípe,
“Ìjọba ọ̀run dàbí ọba kan, èyítí ó ṣe ìgbeyàwó fún ọmọ rẹ̀,
“Ó sì rán àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ lọ ípè àwọn tí a pè tẹ́lẹ̀ sí ibi ìyàwó: Ṣùgbọ́n wọn kò fẹ́ wá.
“Ó sì tún rán àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ míràn, wípé, Ẹ wí fún àwọn tí a pè pé, Wòó, mo ṣe oúnjẹ mi tán: a pa màálù àti gbogbo ẹ̀ran àbọ́pa mi, a sì ṣe ohun gbogbo tán: ẹ wá sí ibi ìyàwó.
“Ṣùgbọ́n wọn kò fi pe nkan, wọ́n bá tiwọn lọ, ọ̀kan sí ọ̀nà oko rẹ̀, òmíràn sí ọ̀nà òwò rẹ̀.”7
Ní ìgbà àtijọ́, ayẹyẹ aláyọ̀ jùlọ nínú ayé àwọn júù ni àjọyọ̀ ìgbeyàwó—ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí ó ngba gbogbo ọ̀sẹ̀ kan tàbí méjì. Irú ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó gba ìṣètò púpọ̀, àti àwọn àlejò tí a níláti wìfún ṣíwájú gan, pẹ̀lú fífi ìránniléti ránṣẹ́ ní ọjọ́ ṣíṣí àwọn àjọ̀dún. Ìfipè láti ọ̀dọ̀ ọba sí àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ sí ibi ìyàwó bí irú èyí ni a kàsí àṣẹ pàtàkì. Síbẹ̀síbẹ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àlejò tí a pé nínú òwe yí kò wá. 8
“Kíkọ̀ láti wá sí àpèjẹ ọba jẹ́ [ìṣe] ìmọ̀ọ̀mọ́ ṣọ̀tẹ̀ ní àtakò sí … àṣẹ ọlọ́ba àti ìdójútì araẹni ní àtàkò sí alakoso ijọba lọ́wọ́lọ́wọ́ àti ọmọ rẹ̀. … Yíyípadà kúrò nípa ẹnìkan lọ sí oko rẹ̀ àti nípa òmíràn sí [ibi òwò] rẹ̀”9fi àwọn ààyò àìtọnà àti àìkàsí pátápátá sí àṣẹ ọba hàn.10
Òwe náà tẹ̀síwájú:
“Nígbànáà ni ó wí fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, A se àsè ìyàwó tán, ṣùgbọ́n àwọn tí a ti pè kò yẹ.
“Nítorínáà ẹ lọ sí ọ̀nà òpópó, iyekíye ẹnití ẹ bá rí, ẹ pè wọ́n wá sí ibi ìyàwó.
“Bẹ́ẹ̀ni àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ wọnnì sì jáde lọ sí ọ̀nà òpópó, àwọn sì kó gbogbo àwọn ẹni tí wọ́n rí jọ, àti búburú àti rere: ibi àsè ìyàwó sì kún fún àwọn tí ó wá jẹun.”11
Àwọn àṣà ní ọjọ́ wọnnì wà fún agbàlejò àpèjẹ ìyàwó—nínú òwe yí, ọba—níláti pèsè ẹ̀wù fún àwọn àlejò ìyàwó. Irú ẹ̀wù ìyàwó bẹ́ẹ̀ rọrùn, àwọn aṣọ àìlèjúwe tí gbogbo ẹni tó wá wọ̀. Ní ọ̀nà yí, ipò àti ibùjókòó ni a múkúrò, gbogbo àwọn tí ó wà ní àpèjẹ sì lè báraṣe bí ìbádọ́gba.12
Àwọn ènìyàn tí a pè ní òpópó láti wá síbi ìyàwó kò lè ní àkokò tàbí ọ̀nà déédé láti ra aṣọ ní mímúrasílẹ̀ fún ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Ní àbájáde, ọba lè ti fún àwọn àlejò ní ẹ̀wù látinú àpótí-aṣọ ti ararẹ̀. Gbogbo ènìyàn ni a fún ní ànfàní láti wọṣọ fúnrawọn nínú ẹ̀wù ti ọlọ́ba.12
Bí ọba ṣe wọnú gbàgede ìyàwó, ó yẹ àwọn èrò wò ó sì ṣe àkíyèsí lọ́gán pé ó hàn gidi pé àlejò kan kò wọ ẹ̀wù ìyàwó. Ọkùnrin náà ni a mú wà síwájú, ọba sì biì léèrè: “Ọ̀rẹ́, ìwọ ti ṣe wọ ihin wá láìní aṣọ ìyàwó? Kò sì lè fọhùn.”13 Ní àkójá, ọba bèèrè, “Kínìdí tí ìwọ kò fi wọ aṣọ ìyàwó, àní bíótilẹ̀jẹ́pé a pèsè ọ̀kan fún ọ?”15
Ó hàn gbangba pé ọkùnrin náà kó múra dáadáa fún ayẹyẹ pàtàkì yí, àti pé ní gbólóhùn ọ̀rọ̀ “Kò sì lè fọhùn,” fihàn pé ọkùnrin náà kò ní àwáwí.16
Alàgbà James E. Talmage pèsè àsọyé ikẹkọ yí nípa pàtàkì àwọn ìṣe ọkùnrin náà.“Pé àlejò aláìwọṣọ jẹ̀bi ìpatì, ìmọ̀ọ́mọ̀ṣe àìbọ̀wọ̀, tàbí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ líle díẹ̀ síi, ni ó hàn kedere láti inú àtẹ̀kọ náà. Ọba náà ní àkọ́kọ́ ní inúrere yíyẹ, ní ìbèerè bí ọkùnrin náà ti lè wọlé láìní aṣọ ìyàwó. Bí ọkùnrin náà bá ti ṣe àlàyé ìwò yíyàtọ̀ rẹ̀, tàbí kí ó ní àwáwí èrèdí dídára láti fúnni, òun ìbáti sọ̀rọ̀ dájúdájú; ṣùgbọ́n a gbọ́ pè ó dúró láìfọhùn. Ìpè ọba náà ni a fi fún gbogbo ẹni tí àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ rí lọfẹ; ṣùgbọ́n ọ̀kọ̀ọ̀kan lára wọn ní láti wọnú àgbàlá ọba láti ẹnu ọ̀nà; àti ṣíwájú dídé yàrá àpèjẹ, nínú èyí tí ọba yíò farahàn níti ara, ọ̀kọ̀ọ̀kan yíò wọ aṣọ dáradára; ṣùgbọ́n àwọn tó ní àbùkù, nípa àwọn ọ̀nà kan ti wọlé láti ibì míràn; tí wọn kò sì lè kọjá àwọn olùdúró adènà ní ẹnu-ọ̀nà kékeré, ó jẹ́ afínràn.”14
Olùkọ̀wé krístíẹ́nì kan, John O. Reid, kíyèsi pé kíkọ̀ ọkùnrin náà láti wọ aṣọ ìyàwó fi àpẹrẹ “àìníọ̀wọ̀ kankan fún ọba àti ọmọ rẹ̀ hàn pẹ̀lú.” Kìí ṣe pé kò ní aṣọ ìyàwó nìkan; dípò bẹ́ẹ̀, ó yàn láti máṣe wọ ọ̀kan. Ó fi oríkunkun kọ̀ jálẹ̀ láti wọ aṣọ tó yẹ fún àjọyọ̀ náà. Ìfèsì ọbá ṣe kánkán àti níní ìpinnu: “Ẹ dìí tọwọ́ tẹsẹ̀ , ẹ gbé e kúrò. Kí ẹ sì sọọ́ sínú òkùnkùn lóde; níbẹ̀ ni ẹkún àti ìpahínkeke.”15
Ìdájọ́ ọba nípa ọkùnrin náà kò dálé kókó àìní aṣọ ìyàwó nìkan—ṣùgbọ́n pé “òun, nitootọ́, pinnu láti máṣe wọ̀ ọ̀kan, Ọkùnrin náà … nfẹ́ ọlá wíwá síbi àpèjẹ ìyàwó, ṣùgbọ́n … kò fẹ́ láti tẹ̀lé àṣà ọba. Ó fẹ́ láti ṣe àwọn nkan ní ọ̀nà ti ararẹ̀. Àìní aṣọ dídára fi oríkunukun inú rẹ̀ ní àtakò sí ọba àti àwọn àṣẹ rẹ̀ hàn.”19
Ọ̀pọ̀ Ni A Pè, ṣùgbọ́n Díẹ̀ Ni A Yàn
Òwe náà parí pẹ̀lú ìwé mímọ́ tí ó wọnilára yí: “Nítorí ọ̀pọ̀ ni a pè, ṣùgbọ́n díẹ̀ ni a yàn.”16
Ní Dídára, Joseph Smith ṣe àtúnṣe ìwọ̀nyí sí ẹsẹ yí látinú ìwé Máttéù nínú ìtumọ̀ onímísí ti Bíbélì rẹ̀: “Nítorí ọ̀pọ̀ ni a pè, ṣùgbọ́n díẹ̀ ni ayàn; nítorínáà gbogbo ènìyàn kò ní ẹ̀wù ìyàwó.”21
Ìfipè láti wásí àpèjẹ ìyàwó àti yíyàn láti ṣe àbápín nínú àpèjẹ báramu ṣùgbọ́n ó yàtọ̀. Ìfipè náà wà fún gbogbo ọkùnrin àti obìnrin. Àní ẹnìkọ̀ọ̀kan lè tẹ́wọ́gba ìfipè kí wọ́n sì joko sílẹ̀ níbi àpejẹ—síbẹ̀ kí a má yàn láti ṣe àbápín nítorí ọkùnrin tàbí obìnrin kò lè ní ẹ̀wù ìyàwó yíyẹ ti yíyípadà ìgbàgbọ́ nínú Olúwa Jésù àti oore ọ̀fẹ́ tọ̀run Rẹ̀. Bayi, a ní ìpè Ọlọ́run àti ìdáhùn olúkúlùkù wa sí ìpè náà pẹ̀lú, àti pé ọpọ̀ ni a pè ṣùgbọ́n díẹ̀ ni a yàn.18
Láti jẹ́ tàbí láti di yíyàn kìí ṣe ipò tí a fi lé wa lórí pátápátá. Dípò bẹ́ẹ̀, èmi àti ẹ̀yin nígbẹ̀hìn lè yàn láti jẹ́ yíyàn nípasẹ̀ lílo ìwà òdodo agbára láti yàn wa.
Ẹ jọ̀wọ́ ẹ kíyèsí ọ̀rọ̀ náà yíyàn nínú àwọn ẹsẹ dídámọ̀ wọ̀nyí láti inú Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú:
“Kíyèsi, ọ̀pọ̀ ni a pè, ṣùgbọ́n díẹ̀ ni a yàn. Àti ìdí tí a kò fi yànwọ́n?
“Nítorípé wọ́n gbé ọkàn wọn lé àwọn ohun ayé yí púpọ̀, wọ́n sì nlépa ọlá ti àwọn ènìyàn.”23
Mo gbàgbọ́ pé àyọrísí àwọn ẹsẹ wọ̀nyí wà tààrà gan. Ọlọ́run kò ní àkójọ àyànfẹ́ sí èyí tí a gbọ́dọ̀ ní ìrètí pé a ó fi orúkọ wa kún níjọ́kan. Òun ko dẹ́kun “yíyàn” sí àwọn díẹ̀ tí a hámọ́. Dípò bẹ́ẹ̀, ọkàn wa, ìfẹ́ wa, búbu-ọlá wa fún àwọn májẹ̀mú àti ìlànà mímọ́ ìhìnrere, gbígbọ́ran wa sí àwọn òfin, àti, nípàtàkì jùlọ, oore ọ̀fẹ́ ríràpadà Olùgbàlà npinnu bóyá a kà wá bí ọ̀kan nínú àwọn tí Ọlọ́run yàn.24
“Nítorí a ṣiṣẹ́ láìsinmi láti kọ̀wé, láti yí àwọn ọmọ wa lọkàn padà, àti àwọn arákùnrin wa pẹ̀lú, láti gbàgbọ́ nínú Krístì, àti láti ṣe ìlàjà sí Ọlọ́run; nítorí a mọ̀ pé nípa õre-ọ̀fẹ́ ni a gbà wá là, lẹ́hìn gbogbo ohun tí a lè ṣe.”25
Nínú iṣẹ́ làálàá ojojúmọ́ ìgbé ayé wa àti ní rúdurùdu ayé tó ndíje nínú èyí tí á ngbe, a lè ní ìdàmú kúrò nínú àwọn ohun ayérayé tí ó pọndandan jùlọ nípa mímú ìgbádùn, ìṣerere, òkìkí, àti ìyọrísí jẹ́ kókó ààyò wa. Ohun kúkúrú tí ó fi àyè gbà wá pẹ̀lú “àwọn ohun ayé” àti “bíbu-ọlá fún ènìyàn” lè darí wa láti pàdánù ẹ̀tọ́-ìbí ti ẹ̀mí wa ní dídínkù ju àbàṣà àṣáró lọ.26
Ìlérí àti Ẹ̀rí
Mo tún ìkìlọ̀ Olúwa sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ tí ó fúnni nípasẹ̀ wolíì Májẹ̀mú Láéláé Hággáì: “Njẹ́ bayi ni Olúwa ọmọ ogun wípé; Ẹ kíyèsí ọ̀nà yín.”23
Ẹnìkọ̀ọ̀kan wa níláti fi òdodo àti gbígbàdúrà yẹ ààyò ti ẹ̀mí àti ti ara wa wò láti mọ àwọn ohun inú ayé wa tí ó lè dí àwọn ìbùkún púpọ̀ tí Baba Ọ̀run àti Olùgbàlà nfẹ́ láti fi lé wa lórí. Àti pé dájúdájú Ẹ̀mí Mímọ́ yíò ràn wá lọ́wọ́ láti rí arawa bí a ti wa gan.28
Bí a ti nwá ẹ̀bùn ojú ti ẹ̀mí láti rí àti láti gbọ́ lọ́nà títọ́,25 Mo ṣe ìlérí pé a ó di alábùkúnfún pẹ̀lú okun àti ìdájọ́ láti fún ìsopọ̀ májẹ̀mú wa pẹ̀lú Olúwa alààyè lókun. Bákannáà a ó gba agbára Ìwà-bí-Ọlọ́run nínú ayé wa26—àti nígbẹ̀hìn kí a lè pè wá sí àti yàn wá fún àpèjẹ Olúwa pẹ̀lú.
“Jí, jí, gbé agbára rẹ wọ̀, Ah Síónì.”27
“Nítorí Síónì gbọ́dọ̀ pọ̀ si ní ẹwà, àti ní ìwà mímọ́; àwọn ààlà rẹ̀ gbọ́dọ̀ tóbi si; a gbọ́dọ̀ fún àwọn èèkàn rẹ̀ ní okun; bẹ́ẹ̀ni, lootọ ni mo wí fún yín, Síónì gbọ́dọ̀ dìde kí ó sì gbé àwọn aṣọ rẹ̀ tí ó rẹwà wọ̀.”28
Mo fi tayọ̀tayà kéde ẹ̀rí mi nípa àtọ̀runwá àti wíwàláàyè òdodo ti Ọlọ́run, Baba wa Ayérayé àti Olólùfẹ́ Ọmọ Rẹ, Jésù Krístì. Mo jẹ́ ẹ̀rí pé Jésù Krístì ni Olùgbàlà àti Olùràpadà wa, Ó sì wà láàyè. Bákannáà mo sì jẹri pé Baba àti Ọmọ farahàn sí ọ̀dọ́mọdékùnrin Joseph Smith, bayi ó sì mú ìpadàbọ̀sípò ìhìnrere Olùgbàlà wá ní Ọjọ́-ìkẹhìn. Njẹ́ kí ọ̀kọ̀ọ̀kan lára wa wá kí a sì di alábùnkúnfún pẹ̀lú ojú láti rí àti etí láti gbọ́, ni mo gbàdúrà ní orúkọ mímọ́ Olúwa Jésù Krístì, àmín.