Kíni Ó Jẹ́ Òtítọ́?
Ọlọ́run ni orísun gbogbo òtítọ́. Ìjọ Jésù Krístì ti awọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn gba gbogbo òtítọ́ tí Ọlọ́run nfi fún àwọn ọmọ Rẹ̀ mọ́ra.
Ẹ̀yin àyànfẹ́ arákùnrin àti arábìnrin mi, mo dúpẹ́ fún gbogbo yín fún abala onímísí yí. Látìgbà ìpàdé àpapọ̀ Oṣù Kẹ́rin tí ó kọjá, a ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ayé, láti ìrora ọkàn sí ọlọ́lá jùlọ.
Inú wa dùn pẹ̀lú àwọn ìròhìn ìpàdé àpapọ̀ títóbí tí àwọn ọ̀dọ́ nṣe káàkiri àgbáyé.1 Ní àwọn ìpàdé àpapọ̀ wọ̀nyí, àwọn akọni ọ̀dọ́ wa nkẹkọ pé ohun èyíówù kí ó ṣẹlẹ̀ nínú ayé wọn, okun wọn tí ó gajùlọ nwá látọ̀dọ̀ Olúwa.2
A láyọ̀ pé à nkọ́ àwọn tẹ́mpìlì púpọ̀ si káàkiri àgbáyé. Pẹ̀lú ìyàsímímọ tẹ́mpìlì titun kọ̀ọ̀kan, àníkún agbára ti ọ̀run nwá sínú ayé láti fún wa lókun kí a sì takò ìtẹramọ́ ìtiraka ti ọ̀tá.
Ìlòkulò jẹ́ agbára ọ̀tá. Ẹ̀ṣẹ̀ búburú jùlọ ni.3 Bí Ààrẹ Ìjọ, mo tẹnumọ́ àwọn ìkọ́ni Olúwa Jésù Krístì lórí ọ̀ràn yí. Ẹ jẹ́ kí nfi hàn kedere: irú eyikeyi ìlòkulo ti àwọn obìnrin, ọmọ, tàbí ẹnikẹ́ni jẹ́ ìríra sí Olúwa. Ó nṣọ̀fọ̀ èmi náà sì nṣọ̀fọ̀ nígbàkugbà tí ẹnìkẹ́ni bá nípalára. Ó nkẹ́dùn, gbogbo wa sì nkẹ́dùn fún ẹnìkọ̀ọ̀kan tí ó ti ṣubú sínú ìpalára ìlòkulò eyikeyi. Àwọn ẹni tí wọ́n ti ṣe àwọn ìṣe àṣepamọ́ wọ̀nyí kìí yío jihin sí àwọn òfin ènìyàn nìkan ṣùgbọ́n wọn yíò dojúkọ ìrunú ti Ọlọ́run bákannáà.
Fún àwọn dẹ́kéèdì nísisìyí, Ìjọ ti ngbé ìgbésẹ̀ òṣùwọn kíkún láti dá ààbò bo—àwọn ọmọ kúrò nínú ìlòkulò—nípàtàkì. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìrànlọ́wọ́ ni ó wà lórí ayélujára Ìjọ. A pè yín láti ṣe àṣàrò wọn.4 Àwọn ìtọ́nisọ́nà wọ̀nyí wà nípò láti dá ààbò bo aláìmọ̀kan. Mo rọ ẹnìkọ̀ọ̀kan wa láti kára mọ́ ẹnìkẹ́ni tí ó lè wà nínú ewu wíwà nínú ìlòkulò kí a sì gbésẹ̀ kíákíá láti dá ààbò bò wọ́n. Olùgbàlà kò ní fàyè gba ìlòkulò, àti àwa bí ọmọ-ẹ̀hìn Rẹ̀, bẹ́ẹ̀ni a kò lè ṣeé pẹ̀lú.
Ọ̀tá ní àwọn ètè yíyọnilẹ́nu míràn. Nínú wọn ni ìtiraka rẹ̀ láti bo ìlà tí ó wà ní àárín ohun tí ó jẹ́ òtítọ́ àti ohun tí kìí ṣe òtítọ́ mọ́lẹ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àlàyé tí ó wà ní àrọ́wọ́tó wa, ní àfiwé, nmú kí ó le púpọ̀ si láti mọ ohun tí ó jẹ́ òtítọ́.
Ìpènijà yí rán mi létí ìrírí kan tí Arábìnrin Nelson àti èmi ní nígbàtí a bẹ gbajúmọ̀ kan wò ní orílẹ̀-èdè níbití àwọn ènìyàn díẹ̀ gan an ti gbọ́ nípa Jésù Krístì. Ọ̀rẹ ọ̀wọ́n ogbó yí ti nṣàìsàn gan láìpẹ́ yi. Ó wí fún wa pé nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọjọ́ rẹ̀ ní orí bùsùn, òun máa nwo òrùlé léraléra ó sì máa nbèèrè, “Kíni Ó Jẹ́ Òtítọ́?”
Ọ̀pọ̀ ní ilẹ̀ ayé ní òní “nìkan ni a pamọ́ kúrò nínú òtítọ́ nítorí wọn kò mọ ibi tí wọn ó ti rí i.”5 Àwọn kan fẹ́ kí a gbàgbọ́ pé òtítọ́ níbámu—pé ẹnìkọ̀ọ̀kan níláti pinnu fúnrarẹ lákọ tàbí lábo ohun tí ó jẹ́ òtítọ́. Irú ìgbàgbọ́ náà jẹ́ rírònú ìfẹràn fún àwọn ẹnití ó fi àṣìṣe rò pé wọn kò ní jihin sí Ọlọ́run.
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin ọ̀wọ́n, Ọlọ́run ni orísun gbogbo òtítọ́. Ìjọ Jésù Krístì ti awọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn rọ̀mọ́ gbogbo òtítọ́ tí Ọlọ́run fi fún àwọn ọmọ Rẹ̀, bóyá kíkọ́ nínú ilé-àyẹ̀wò sáyẹ́nsì tàbí gbígba ìfihàn tààrà láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀.
Láti orí pẹpẹ yí ní òní àti ní ọ̀la, ẹ ó tẹ̀síwájú láti gbọ́ òtítọ́. Ẹ jọ̀wọ́ ẹ ṣe àkọsílẹ̀ àwọn èrò tì ó gba ìfọkànsí yín àti àwọn tí ó nwá sínú yín tí ó sì dúró nínú ọkàn yín. Ẹ fi àdúrà bèèrè lọ́wọ́ Olúwa láti fẹsẹ̀ rẹ̀ múlẹ̀ pé ohun tí ẹ gbọ́ jẹ́ òtítọ́.
Mo fẹ́ràn yín, ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n. Mo gbàdúrà pé ìpàdé àpapọ̀ yí yíò pèsè àpèjẹ ti ẹ̀mí tí ẹ̀ nwá. Ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.