Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ẹ̀kọ Ìpìlẹ̀ Ayérayé ti Ìfẹ́
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2022


Ẹ̀kọ Ìpìlẹ̀ Ayérayé ti Ìfẹ́

Ìfẹ́ Baba wa Ọ̀run fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ Rẹ̀ jẹ́ òdodo. Ó wà níbẹ̀ fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wa.

Ẹ̀kọ ìpìlẹ̀ ayérayé ti ìfẹ́ jẹ́ fífihàn nípa gbígbé àwọn òfin nlá méjì: Fẹ́ Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo ọkàn, ẹ̀mí, inú, àti okun rẹ kí o sì fẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.1

Mo rántí ìgbà òtútù mi àkọ́kọ́ ní gbígbé nihin ní Utah—òjò dídì nibigbogbo. Ní bíbọ̀wá láti aṣálẹ̀ Sonoran, mò ngbádùn rẹ̀ ní àwọn ọjọ́ àkọ́kọ́, ṣùgbọ́n lẹ́hìn àwọn ọjọ́ díẹ̀, mo ri pé mo ní láti dìde ní kùtùkùtù láti gbá òjò dídì kúrò ní òpópónà.

Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kan, ní àárín ìjì líle kan, mo nlàágùn, mo ngbọ́n òjò dídì, mo sì rí aládùúgbò mi tí ó ṣí ibi ìgbéọkọ̀si rẹ̀ ní ní òdìkejì òpópónà. Ó dàgbà ju èmi, nítorínáà mo lérò pé tí mo bá ṣetán kíákíá, mo lè ràn án lọ́wọ́. Nítorínáà ní gbígbé ohùn sókè, mo bií léèrè, “Arákùnrin, ṣe ìwọ nílò ìrànlọ́wọ́?”

O rẹ́ẹ̀rín músẹ́ ó sì wípé, “O ṣeun, Alàgbà Montoya.” Nígbànnáà ó ti ẹrọ̀ gbígbá òjò dídì jáde kúrò nínú ibùgbé-ọkọ̀, ó ṣáná sí ẹ̀rọ-ọkọ̀, àti pé ní ìṣẹ́jú díẹ̀ ó gbá gbogbo òjò dídì kúrò ní iwájú ilé rẹ̀. Lẹ́hìnnáà ó sọdá pópónà pẹ̀lú ẹ̀rọ rẹ̀ ó sì bèèrè lọ́wọ́ mi pé, “Alàgbà, ṣe ẹ nílò ìrànlọ́wọ́?”

Pẹ̀lú ẹ̀rín músẹ́ mo wípé, “Bẹ́ẹ̀ni, o ṣeun.”

A nfẹ́ láti ran ara wa lọ́wọ́ nítorí pé a fẹ́ràn ara wa, àwọn àìní arákùnrin mi sì di àìní mi, tèmi sì di tirẹ̀. Èdè yòówù kí arákùnrin mi sọ tàbí orílẹ̀-èdè tí ó ti wá, a fẹ́ràn ara wa nítorí arákùnrin, ọmọ Baba kan náà ni wá.

Nígbàtí a kéde iṣẹ́ ìránṣẹ́, Ààrẹ Nelson wípé, “A ó ṣe ìmúlò ọ̀nà titun, mímọ́ jùlọ kan sí títọ́jú àti ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún àwọn ẹlòmíràn.”2 Fún mi, mímọ́ si túmọ̀ sí díẹ̀ síi níti ara, jíjinlẹ̀, díẹ̀ síi bíiti ọ̀nà Olùgbàlà: “Ẹ ní ìfẹ́ sí ara yín,”3 ní ọ́kọ̀ọ̀kan.

Kò tó láti yẹra fún jíjẹ́ ohun ìkọ̀sẹ̀ fún àwọn ẹlòmíràn; kò tó láti ṣe àkíyèsí àwọn aláìnì ní òpópónà kí a sì kọjá lọ. Ẹ jẹ́ kí a lo ànfààní gbogbo láti ran aládùúgbò wa lọ́wọ́, àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ àti ìgbà kan ṣoṣo tí a bá pàdé rẹ̀ ní ayé yìí.

Kí nìdí tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run fi jẹ́ àṣẹ nlá àkọ́kọ́?

Mo rò pé nítorí ohun tí Ó túmọ̀ sí fún wa ni. Ọmọ Rẹ̀ la jẹ, Ó nbojútó ire wa, a gbẹ́kẹ̀le E, ìfẹ́ Rẹ̀ sì ndáàbò bò wá. Ètò Rẹ̀ ní agbára láti yàn nínú; nítorínáà, ó ṣeése kí á ṣe àwọn àṣìṣe.

Ó tún jẹ́ kí a bẹ̀wa wò kí a sì dánwa wò. Ṣùgbọ́n yálà a nṣe àwọn àṣìṣe kan tàbí a nṣubú sínú ìdẹwò, ètò náà pèsè Olùgbàlà kí a baà lè ràwá padà kí a sì padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.

Ìpọ́njú nínú ìgbésí ayé wa lè fa iyèméjì nípa ìmúṣẹ àwọn ìlérí tí a ti ṣe fún wa. Jọ̀wọ́ gbẹ́kèlé Baba wa. Ó máa npa àwọn ìlérí Rẹ̀ mọ́, a sì lè kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí Ó fẹ́ kọ́ wa.

Àní ní ṣíṣe ohun tí ó tọ́, àwọn ipò nínú ayé wa lè yípadà láti rere sí búburú, láti inú ayọ̀ sí ìbànújẹ́. Ọlọ́run ndáhùn àwọn àdúrà wa ní ìbámu sí àánú, ìfẹ́ rẹ̀ àìlópin, àti ní àkokò Tirẹ̀.

  • Odò tí Èlíjàh ti mú omi ti gbẹ.4

  • Ọrun irin tó dára ti Néfì ti ṣẹ́.5

  • Wọ́n ṣe ẹ̀tanú sí ọdọmọ́kùnrin kan wọ́n sì lé e kúrò nílé ìwé.

  • Ọmọ tí a ti nretí tipẹ́tipẹ́ ti kú láarín àwọn ọjọ́ tí a bi.

Àwọn ipò yípadà.

Nígbà tí àwọn ipò bá yípadà láti rere àti dáadáa sí búburú àti òdì, a ṣì lè láyọ̀ nítorí pé ayọ̀ kò gbára lórí àwọn ipò bí kò ṣe ìwà wa sí àwọn ipò náà. Ààrẹ Nelson wípé, “Ayọ̀ tí à ní ìmọ̀lára rẹ̀ ní díẹ̀ íṣe pẹ̀lú àwọn ipò ti ìgbé ayé wa àti pé ohungbogbo ní íṣe pẹ̀lú ìfojúsùn àwọn ìgbé ayé wa.”6

A lè jókòó kí á dúró de àwọn ipò láti yípadà fúnrarẹ̀, tàbi a lè wa láti mú àwọn ipò titun jáde.

  • Èlíjàh rìn ní Sáréfátì, níbití opó kan sì fún un ní oúnjẹ àti mímú.7

  • Néfì ṣe ọrun igi ó sì dọdẹ ẹran láti jẹ.8

  • Ọ̀dọ́mọkùnrin náà jókòó láti fetísí àti láti ṣe àkọsílẹ̀ lẹ́bàá fèrèsé, àti lónìí ó jẹ́ olùkọ́ ilé-ìwé alákọ̀bẹ̀rẹ̀.

  • Tọkọtaya náà ti mú ìgbàgbọ́ nlá nínú Olùgbàlà Jésù Krístì àti ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ètò ìgbàlà dàgbàsókè. Ìfẹ́ wọn fún ọmọ tí a ti nretí tipẹ́tipẹ́ tí ó kú lójijì ju ìbànújẹ́ wọn lọ.

Nígbàtí mo gbọ́ àwọn ìbéèrè náà “Baba Ọ̀run, ṣe O wà níbẹ̀ lõtọ́? Njẹ́ ẹ̀ ngbọ́ tí ẹ sì ndáhùn [gbogbo] àdúrà ti ọmọ?,”9 mo fẹ́ láti dáhùn pé: “Ó ti jẹ́ bẹ́ẹ̀, Ó nṣe é, Òun yíò sì wà níbẹ̀ fún ẹ̀yin àti èmi nígbàgbogbo. Ọmọ Rẹ̀ ni mí, Òun ni Baba mí, mo sì nkọ́ láti jẹ́ baba rere, bí Òun ti jẹ́.

Èmi àti ìyàwó mi máa ngbìyànjú láti wà níbẹ̀ fún àwọn ọmọ wa nígbàkugbà, lábẹ́ ipòkípò, àti lọ́nàkọnà. Ọmọ kọ̀ọ̀kan jẹ́ aìláfiwé; iye wọn sí Ọlọ́run tóbi, àti pé láìka ìpèníjà kankan, ẹ̀ṣẹ̀, àti àìlera tí wọ́n ní sí, Ọlọ́run fẹ́ràn wọn, àwa náà sì fẹ́ràn wọn.

Nígbàtí mo gba ìpè yìí gẹ́gẹ́ bí Aláṣẹ Gbogbogbò, ní ọjọ́ tí ó kẹ́hìn kí a tó rin ìrìnàjò lọ sí Salt Lake, gbogbo àwọn ọmọ mi àti àwọn ẹbí wọn wà papọ̀ nínú ilé wa fún ìrọ̀lẹ́ ilé ẹbí, níbi tí a ti fi ìfẹ́ àti ìmoore hàn. Lẹ́hìn ẹ̀kọ́ náà, mo fi ìbùkún oyèàlùfáà fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ mi. Gbogbo ènìyàn wà nínú omijé. Lẹ́hìn àwọn ìbùkún, ọmọkùnrin mi àgbà sọ àwọn ọ̀rọ̀ ìdúpẹ́ lórúkọ gbogbo ènìyàn fún ìfẹ́ nlá tí a ti fún wọn láti ọjọ́ tí wọ́n ti bí wọn títí di ìgbà náà.

Súre fún àwọn ọmọ rẹ, bóyá wọ́n jẹ́ ẹni ọdún márùn tàbí àádọ́ta ọdún. Wà pẹ̀lú wọn; wà fún wọn. Bíótilẹ̀jẹ́pé pípèsè jẹ́ ojúṣe tí a fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ nípasẹ̀ ìṣètò àtọ̀runwá, a kò gbọ́dọ̀ gbàgbé láti ṣe àjọpín àkokò aláyọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ wa.

Ìfẹ́ Baba wa Ọ̀run fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ Rẹ̀ jẹ́ òdodo. Ó wà níbẹ̀ fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wa. Èmi kò mọ bí Ó ti nṣe é, ṣùgbọ́n Ó nṣe. Òun àti Àkọ́bí Rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan nínú ṣíṣe iṣẹ́ àti ògo Baba, “láti mú àìkú àti ìyè àìnípẹ̀kun ènìyàn ṣẹ.”10 Wọ́n ti rán Ẹ̀mí Mímọ́ sí wa láti tọ́ wa sọ́nà, láti kìlọ̀ fún wa, àti láti tù wá nínú bí ó bá yẹ.

Ó kọ́ Ọmọ Rẹ̀ àyànfẹ́ láti dá ilẹ̀ ayé ẹlẹ́wà yìí. Ó kọ́ Ádámù àti Éfà ó sì fún wọn ní agbára láti yàn. Ó ti nrán àwọn òjíṣẹ́ fún àwọn ọdún àti àwọn ọdún kí a lè gba ìfẹ́ Rẹ̀ àti àwọn òfin Rẹ̀.

Ó ti wà ní Igbó-Ṣúúrú Mímọ́ ní dídáhùn ìbéèrè àtọkànwa ti ọ̀dọ́mọkùnrin Joseph nípa pípè é ní orúkọ rẹ̀. Ó wípé: “Èyí ni Àyànfẹ́ Ọmọ Mi. Gbọ́ Tirẹ̀!11

Mo gbàgbọ́ pé ìfihàn tí ó ga jùlọ ti ìfẹ́ Ọlọ́run sí wa ṣẹlẹ̀ ní Getsemane, níbití Ọmọ Ọlọ́run alààyè ti gbàdúrà pé, “Ah Baba mi, bí ó bá ṣeé ṣe, jẹ́ kí ago yí kọjá mi: ṣùgbọ́n kìí ṣe bí èmi ti fẹ́, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́bí ìwọ ti fẹ́.”12

Mo ti ṣe àkíyèsí pé apá kékeré tí mo lè lóye nípa Ètùtù Jésù Krístì nṣe àlékún ìfẹ́ mi fún Baba àti Ọmọ Rẹ̀, ó ndín ìfẹ́-ọkàn mi láti dẹ́ṣẹ̀ àti láti jẹ́ aláìgbọràn kù, ó sì nṣe àlékún ìfẹ́ mi láti di dáradára síi kí nsì máa ṣe dáradára síi.

Jésù rìn láìsí ìbẹ̀rù àti láìsí iyèméjì sí Getsemane, ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Baba Rẹ̀, ní mímọ pé Òun gbọ́dọ̀ nìkan tẹ ibi ìfúntí. Ó fara da gbogbo ìrora àti gbogbo ẹ̀gàn. Ó di fífi ẹ̀sùn kàn, dídá lẹ́jọ́, àti kíkàn mọ́gi. Lákokò ìrora àti ìjìyà Rẹ̀ lórí àgbélèbú, Jésù fojúsùn sí àwọn àìní ìyá Rẹ̀ àti àwọn àyànfẹ́ ọmọ-ẹ̀hìn Rẹ̀. Ó fi ẹ̀mí Rẹ̀ rúbọ.

Ní ọjọ́ kẹ́ta Ó jí dìde. Ibojì náà ṣófo; Ò dùrò ní ọwọ́ ọ̀tún Baba Rẹ̀. Wọ́n ní ìrètí pé a ó yàn láti pa àwọn májẹ̀mú wa mọ́ kí a sì padà sí ọ̀dọ̀ Wọn. Ayé kejì kìí ṣe ayé ìkẹhìn wa; a kìí ṣe ti ilé ayé yí, ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀ a jẹ́ ẹ̀dá ayérayé tí ngbé àwọn ìrírí ìgbà díẹ̀.

Jésù ni Krístì, Ọmọ Ọlọ́run alãyè. Ó wà láàyè, àti pé nítorí Ó wà láàyè, gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run yíò gbé títíláé. Ọpẹ́ fún ìrúbọ ètùtù Rẹ̀, a lè gbé papọ̀ pẹ̀lú Wọn. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Tẹ̀