Jẹ́kí Ṣíṣe Rere Jẹ́ Títọ́ Wa
Bí a bá dúró ṣinṣin àti àìyẹsẹ̀ ní ṣíṣe ohun rere, àwọn ìṣẹ̀dálẹ̀ wa yíò rànwá lọ́wọ́ láti dúró lórí ipa ọ̀nà májẹ̀mú.
Èmi yìó máa dúpẹ́ nígbàgbogbo fún àwọn iṣẹ́ ìyànsílẹ̀ mi nínú Ìjọ tí ó ti mú mi gbé ní àwọn oríṣiríṣi orílẹ̀-èdè. A rí ní ọ̀kọọkan àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí onírúurú nlá àti àwọn ènìyàn àràọ̀tọ̀ pẹ̀lú àwọn ìṣẹ̀dálẹ̀ àti àṣà oríṣiríṣi.
Gbogbo wa ní àwọn ìṣẹ̀dálẹ̀ àti àṣà tí ó jẹ́ ti araẹni, látinú ẹbí wa, tàbí tí ó wá láti ìletò nínú èyí tí à ngbé, àti pé a nírètí láti tọ́jú gbogbo àwọn tí ó ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà ìhìnrere. Ìgbésókè ìṣẹ̀dálẹ̀ àti àṣà jẹ́ ìpìlẹ̀ sí àwọn ìgbìyànjú wa láti dúró ní ọ̀nà májẹ̀mú, àti pé àwọn tí ó jẹ́ ìdíwọ́, ni ó yẹ kí á kọ̀.
Ìṣẹ̀dálẹ̀ kan jẹ́ ìṣe tàbí ọ̀nà ìrònú léraléra àti ìgbàgbogbo fún ẹnì kan, ọ̀làjú, tàbí àṣà. Lóòrékòòrè, àwọn ohun tí a ronú rẹ̀ tí a sì ṣe ní ọ̀nà ìṣesí ni a mọ̀ bíi “títọ́.”
Ẹ jẹ́ kí nṣe àkàwé èyí: Patricia, ìyàwó mi ọ̀wọ́n, fẹ́ràn láti mu omi àgbọn àti láti jẹ àgbọn. Nígbà ìbẹ̀wò àkọ́kọ́ wa sí Puebla, Mexico, a lọ sí ibì kan tí a ti ra àgbọn. Lẹ́hìn mímu omi náà, ìyàwó mi ní kí wọ́n gé àgbọn náà kí wọ́n sì mú ẹran rẹ̀ wá fún òun láti jẹ. Nígbàtí ó dé, ó pupa. Wọ́n ti wọ́n ata sí i! Àgbọn tí ó dùn pẹ̀lú ata! Èyí ṣe àjèjì sí wa. Ṣùgbọ́n lẹ́hìnwá a gbọ́ pé àwọn àjèjì náà ni ìyàwó mi àti èmi, tí a kì í jẹ àgbọn pẹ̀lú ata. Ní Mexico, síbẹ̀síbẹ̀, kò ṣọ̀wọ́n; ó jẹ́ títọ́ gan an.
Ní àkokò míràn a njẹun ní Brazil pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ wa, wọ́n sì fún wa ní píà. Bí a ṣe fẹ́ wọ́n iyọ̀ sí i, àwọn ọ̀rẹ́ wa sọ fún wa pé, “Kí lo nṣe!? A ti fi súgà sórí afokádò náà!” Afokádò pẹ̀lú ṣúgà! Ìyẹn dàbí ẹnipé ó ṣàjèjì sí wa. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó yá, a gbọ́ pé èmi àti ìyàwó mi ni àwọn tí ó jẹ́ àjèjì, tí a kì í jẹ afokádò pẹ̀lú ṣúgà. Ṣùgbọ́n ní Brazil, píà tí a fi ṣúgà lé lórí jẹ́ títọ́.
Ohun tí ó tọ́ fún àwọn kan lè jẹ́ àjèjì fún àwọn míràn, ó dá lórí ìṣẹ̀dálẹ̀ àti àṣà wọn.
Àwọn ìṣẹ̀dálẹ̀ àti àṣà wo ni ó jẹ́ títọ́ ni ìgbésí ayé wa?
Ààrẹ Nelson ti sọ pé: “Ní òní à nfi ìgbà gbogbo gbọ́ ‘títọ́ titun kan.’ Bí ẹ bá fẹ́ gba títọ́ titun kan mọ́ra, mo pè yín láti yí ọkàn, inú, àti ẹ̀mí yín padà púpọ̀ síi sí Baba wa Ọrun àti Ọmọ Rẹ, Jésù Krístì. Ẹ jẹ ki èyí jẹ títọ́ yín títọ́ titun” (“Títọ́ Titun Kan,” Liahona, Nov. 2020, 118).
Ìfipè yí jẹ́ fún gbogbo ènìyàn. Kò já mọ́ nkanbóyá a jẹ́ òtòṣì tàbí olówó, ọ̀mọ̀wé tàbí aláìkàwé, àgbà tàbí ọ̀dọ́, aláìsàn tàbí abarapá. Ó pè wá láti jẹ́ kí àwọn ohun títọ́ inú ìgbésí ayé wa jẹ́ àwọn tí ó nṣèrànwọ́ láti pa wá mọ́ ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú.
Kò sí orílẹ̀-èdè kan tí ó ní àpapọ̀ ohun tí ó dára tàbí wúnilórí. Nítorínáà, bí Páùlù àti Wòlíì Joseph Smith ti kọ́ni:
“Bí ohunkóhun bá jẹ́ ìwà rere, yẹ ní fífẹ́, tàbí ti ìhìn rere, tàbí yẹ fún yíyìn, àwa nlépaàwọn ohun wọ̀nyí” (Àwọn Nkan Ìgbàgbọ́ 1:13).
“Bí ìyìn kan bá wà, ẹ máa ronú sí àwọn ohun wọ̀nyí” (Philippians 4:8).
Ẹ ṣe àkíyèsí pé èyí jẹ́ ìyanju, kìí ṣe àsọyé kan lásán.
Èmi yío fẹ́ kí gbogbo wa lo àkokò díẹ̀ láti ṣe àròjinlẹ̀ lórí àwọn àṣà wa àti ọ̀nà tí wọ́n gbà nní ipa lórí àwọn ẹbí wa.
Lára àwọn ìṣesí ìyàlẹ́nu tí ó yẹ kí ó jẹ́ títọ́ fún àwọn ọmọ Ìjọ ni àwọn mẹ́rin wọ̀nyí:
-
Àṣàrò àwọn ìwé-mímọ́ ti araẹni àti ti ẹbí. Láti di yíyípadà sí Olúwa Jésù Krístì, ẹni kọọkan ní ojúse fún kíkọ́ ẹ̀kọ́ ihinrere. Àwọn òbí ní ojúṣe láti kọ́ àwọn ọmọ wọn ní ìhìnrere (wo 3 Néfì 23:1; Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 68:25
-
Àdúrà ti araẹni àti ẹbí. Olùgbàlà pàṣẹ fún wa láti gbàdúrà nígbàgbogbo (wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 19:38). Àdúrà gbàwá láàyè láti bá Baba wa Ọ̀run sọ̀rọ̀ tìkalárawa ní orúkọ Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì.
-
Wà níbi ìpàdé oúnjẹ Olúwa ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ (wo 3 Néfì 18:1–12; Mórónì 6:5–6). A nṣe bẹ́ẹ̀ láti rántí Jésù Krístì bí a ti ngba ounjẹ Olúwa. Nínú ìlànà yìí, àwọn ọmọ Ìjọ tún májẹ̀mú wọn dá ní gbígbé orúkọ Olùgbàlà lé ara wọn, ní rírántí Rẹ̀ nígbà gbogbo, àti ní pípa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́ (wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 20:77, 79).
-
Kíkópa lóòrèkórè nínú tẹ́mpìlì àti iṣẹ́ àkọọ́lẹ̀ ìtàn ẹbí. Iṣẹ́ yìí jẹ́ ọ̀nà ìṣọ̀kan àti fífi èdìdi di àwọn ẹbí fún ayérayé (wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 128:15).
Irú ìmọ̀lára wo ni a nní nígbàtí a bá gbọ́ àwọn nkan mẹ́rin wọ̀nyí? Njẹ́ wọ́n jẹ́ apákan ìgbésí ayé– wa títọ́?
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àṣà míràn wà tí ó lè jẹ́ apákan ti ìṣe títọ́ tí a ti gbà, nípa bẹ́ẹ̀ jíjẹ́kí Ọlọ́run borí nínú ayé wa.
Báwo ni a ṣe lè pinnu ohun tí ó máa jẹ́ àwọn ohun títọ́ nínú ayè wa àti ẹbí wa? Nínú àwọn ìwé-mímọ́, a rí àwòṣe nlá kan; nínú Mòsíàh 5:15 ó wípé: “Èmi ìbá fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó dúró ṣinṣin àti ní àìyẹsẹ̀, kí ẹ máa pọ̀ sí i nínú àwọn iṣẹ́ rere nígbàgbogbo.”
Mo fẹ́ràn àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, nítorí a mọ̀ pé àwọn nkan tí ó di títọ́ nínú ayè wa ni àwọn tí a tún sọ lẹ́ẹ̀kansi àti lẹ́ẹ̀kansi. Bí a bá dúró ṣinṣin àti àìyẹsẹ̀ nínú ṣíṣe rere, àwọn ìṣẹ̀dálẹ̀ wa yíò wà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ìhìnrere, wọn yíò sì rànwá lọ́wọ́ láti dúró lórí ipa ọ̀nà májẹ̀mú.
Ààrẹ Nelson ti dáni nímọ̀ràn pé: “Ẹ gba títọ́ titun yín mọ́ra nípa ríronúpìwàdà lójojúmọ́. Ẹ lépa láti jẹ́ mímọ́ púpọ̀si nínú èrò, ọ̀rọ̀, àti ìṣe. Ẹ ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn ẹlòmíràn. Ẹ teramọ́ ìwoye ayérayé. Ẹ gbé ìpè yín ga. Àti pé ohunkóhun tí àwọn ìpènijà yín bá jẹ́, ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, ẹ gbé ọjọ́ kọ̀ọ̀kan kí ẹ lè wà ní ìmúrasílẹ̀ síi láti pàdé Ẹlẹ́dã yín” (“Títọ́ Titun Kan,” 118).
Nísisìyí kò ṣe àjèjì fún ìyàwó mi, Patricia, tàbí fún èmi láti jẹ àgbọn pẹ̀lú ata—ní tòótọ́, a fẹ́ràn rẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, ìgbéga jẹ́ nkan tí ó kọjá púpọ̀ ju ìtọ́wò lọ; ó jẹ́ kókó tí ó bá ayérayé tan.
Mo gbàdúrà pé kí ìṣe títọ́ wa lè gbàwá láàyè láti ní ìrírí ipò “ayọ̀ tí kò lópin” (Mòsíàh 2:41) tí a ṣèlérí fún àwọn wọnnì tí wọ́n pa òfin Ọlọ́run mọ́ àti pé, nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, a lè ní ànfàní láti wípé, “Ó sì ṣe tí a sì gbé ní ọ̀nà ìdùnnú” (2 Néfì 5:27).
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi, mo jẹ́rìí nípa àwọn ọkùnrin marundínlógún tí a mú dúró gẹ́gẹ́ bí wòlíì, aríran, àti àwọn olùfihàn, pẹ̀lú Ààrẹ Russell M. Nelson. Mo jẹ́rìí pé Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn jẹ́ òtítọ́. Mo jẹ́rìí pàápàá nípa Jésù Krístì, Olugbàlà àti Olùràpadà wa, ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.