Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Kí Wọ́n Lè Mọ̀ Yín
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2022


Kí Wọ́n Lè Mọ̀ Yín

(Jòhánnù17:3)

Ìfẹ́ àtọkànwà mi ni pé ẹ̀yin yíò wá láti mọ Jésù nípa àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ orúkọ Rẹ̀ àti pé ẹ̀yin yíò dà bíi Rẹ̀.

Ní ọdún díẹ̀ sẹ́hìn, mo nì ìrírí ìyípadà-igbé ayé nínú ìpàdé oúnjẹ Olúwa ní wọ́ọ̀dù ilé wa ní Arizona. Bí àdúrà oúnjẹ́ Olúwa ti tọ́kasí síṣetán wa làti “gbé orúkọ [Jésù Krístì] lé orí [ara wa],”1 Ẹ̀mí Mímọ́ rán mi létí pé Jésù ní àwọn orúkọ púpọ̀. Nígbànáà ìbèèrè yí wá sí ọkàn mi: “Àwọn orúkọ Jésù èwo ní kí ngbé lé orí arami ní ọ̀sẹ̀ yí?”

Mẹ́ta lára orúkọ Jésù wá sí inú mi, mo sì kọ wọ́n sílẹ̀. Ọ̀kọ̀ọ̀kan lára àwọn mẹta wọnnì ní àwọn ìhùwasí bíiti Krístì nínú tí mo fẹ́ láti mú dàgbà si ní kíkún. Ní ọ̀sẹ̀ tí ó tẹ̀le èyí, mo dojúkọ àwọn orúkọ mẹta mo sì gbìyànjú láti rọ̀mọ́ àwọn ìhùwàsí àti ìwa tí ó fara pẹ́ wọn. Láti ìgbà náà, mo ti tẹ̀síwájú láti bèèrè ìbèèrè náà bí ara ìjọ́sìn araẹni mi: “Àwọn orúkọ Jésù èwo ní kí ngbé lé orí arami ní ọ̀sẹ̀ yí?” Dídáhùn ìbèèrè náà àti títiraka láti mú àwọn ìhùwàsí bíiti Krístì dàgbà ní ìbámu ti bùkún ayé mi.

Nínú Àdúrà Ẹ̀bẹ̀ nlá Rẹ̀, Jésù fi òtítọ́ pàtàkì yí hàn: “Ìyè àìnípẹ̀kun náà sì ni éyí, kí wọ́n kí ó lè mọ̀ ọ́ ìwọ nìkan Ọlọ́run òtítọ́, àti Jésù Krístì ẹnití ìwọ ti rán.”2 Ní òní mo fẹ́ láti pín àwọn ìbùkún àti agbára tí ó nwá ní mímọ Jésù Krístì nípasẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orúkọ Rẹ̀.

Ọ̀nà ìrọ̀rùn kan tí a lè fi mọ ẹnìkan ni nípa kíkọ́ orúkọ wọn. A ti sọ́ tẹ́lẹ̀ pé “orúkọ ẹnìkan wà fún ẹni náà bí ìró pàtàkì àti dídùn jùlọ nínú èdè eyikeyi.”3 Njẹ́ ẹ ti ní ìrírí pípe ẹnìkan nípa àṣìṣe orúkọ tàbí gbàgbé orúkọ wọn rí bí? Ìyàwó mi, Alexis, àti èmi ni, ìgbà kan, pe ọ̀kan lára àwọn ọmọ wa ní “Lola.” Ní àìdára, bí ẹ ti lè ròó sọ, Lola ni ajá wa! Fún dídárasi tàbí bíburúsi, gbígbàgbé orúkọ ti ẹnìkan nwífún ẹni náà pé bóyá ẹ kò mọ̀ wọ́n dáradára gan.

Jésù mọ̀ ó sì pe àwọn ènìyàn pẹ̀lú orúkọ. Sí Ísráẹ́lì àtijọ́ Olúwa wípé “Má bẹ̀rù: nítorí mo ti rà ọ́ padà, mo ti pè ọ́ ní orúkọ rẹ; ti èmi ni ìwọ.”4 Ní òwúrọ̀ Àjínde, ijẹri Màríà nípa Krístì olùjínde ni a filélẹ̀ nígbàtí Jésù pè é nípa orúkọ.5 Bákannáà, Ọlọ́run pe Joseph Smith nípa orúkọ ní ìdáhùn sí ìgbàgbọ́ rẹ̀.6

Ní àwọn ọ̀ràn kan, Jésù fún àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Rẹ̀ ní orúkọ titun tí ó jẹ́ àfihàn ìwà-ẹ̀dá, okun, àti ìlèṣe wọn. Jèhófà fún Jákọ́bù ní orúkọ titun Ísráẹ́lì, èyí tí ó túmọ̀sí “Ẹnití ó borí pẹ̀lú Ọlọ́run” tàbí“ Ẹ jẹ́ kí Ọlọ́run borí.”7 Jésù fún Jákọ́bù àti Jòhánnù ní orúkọ àwọn Boanerge, èyí tí ó túmọ̀sí “ọmọ àrá.”8 Rírí jíjẹ́ olórí ọjọ́ ọ̀là nínú rẹ̀, Jésù fún Símónì ní orúkọ Cephas tàbí Pétérù, èyí tí ó túmọ̀ sí àpáta.9

Gẹ́gẹ́bí Jésù ti mọ ọ̀kọ̀ọ̀kan lára wa nípa orúkọ, ọ̀nà kan tí a fi lè wá láti mọ Jésù ni nípa kíkọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orúkọ Rẹ̀. Bíiti àwọn orúkọ Ísráẹ́lì àti Pétérù, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orúkọ Jésù ni àkọlé tí ó nràn wá lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ iṣẹ́ ìránṣẹ́, èrò, ìwà, àti ìhùwàsí Rẹ̀. Bí a ti nwá láti mọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orúkọ Jésù, a ó wá láti ní ìmọ iṣẹ́ ìránṣẹ́ tọ̀run Rẹ̀ àti ìwà àìmọtaraẹninìkan. Mímọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orúkọ Rẹ̀ bákannáà nmísí wa láti dà bíi Rẹ̀—láti mú àwọn ìhùwàsí bíiti Krístì tí ó nmú ayọ̀ àti èrèdí wá sínú ayé wa dàgbà.

Ọdún díẹ̀ sẹ́hìn, Ààrẹ Russell M. Nelson ṣe àṣàrò gbogbo ìwé mímọ́ nípa Jésù Krístì nínú Ìtọ́nisọ́nà Orí-ọ̀rọ̀.10 Nígbànáà ó pe àwọn ọ̀dọ́ àgbà láti ṣe àṣàrò àwọn ìwé mímọ́ wọ̀nyí kannáà. Nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orùkọ Jésù, Ààrẹ Nelson wípé, “Ẹ kọ́ gbogbo ohun tí Krístì jẹ́ nípa fífi àdúrà àti taguntagun wá láti ní ìmọ̀ ohun tí ọ̀kọ̀ọ̀kan onírurú àkọlé àti orúkọ túmọ̀sí fún ara yín.”11

Ní títẹ̀lé ìfipè Ààrẹ Nelson, mo bẹ̀rẹ̀ sí nto àkójọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orúkọ Jésù fúnara mi. Àkójọ ti ara mi nísisìnyí ti ní ju ọgọrun mẹta lọ, ó sì dá mi lójú pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ wà tí èmi kò tíì wárí síbẹ̀síbẹ̀.

Nígbàtí àwọn orúkọ Jésù kan wà tí a fipamọ́ fún Un nìkan,12 mo fẹ́ láti ṣe àbápín àwọn orúkọ marun àti àkọlé tí ó wúlò sí ọ̀kọ̀ọ̀kan wa. Mo pè yín láti mú àkójọ ti ara yín dàgbà bí ẹ ti nwá láti mọ Jésù nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orúkọ Rẹ̀. Ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ẹ ó ri pé àwọn orúkọ míràn—lẹgbẹ pẹ̀lú ìbámu àwọn ìhùwàsí bíiti Krístì—pé ẹ ó fẹ́ láti gbé lé orí ara yín bí ọmọ-ẹ̀hìn májẹ̀mú Jésù.13

Àkọ́kọ́, Jésù ni Olùṣọ́-àgùtàn Rere.14 Nítorínáà, Jésù mọ àwọn àgùtàn Rẹ̀,15 “ó sì pe àwọn àgùtàn rẹ̀ ní orúkọ,”16 àti, bí Ọ̀dọ́ àgùtàn Ọlọ́run, ó fi ayé Rẹ̀ fún àwọn àgùtàn Rẹ̀.17 Bákannáà, Jésù nfẹ́ kí a jẹ́ olùṣọ́-àgùtàn rere, nípàtàkì nínú àwọn ẹbí wa àti bí òjíṣẹ́ ìránṣẹ́ fún àwọn arákùnrin àti arábìnrin. Ọ̀nà kan ti a fi lè júwe ifẹ́ wa fún Jésù ni nípa bíbọ́ àwọn àgùtàn Rẹ̀.18 Fún àwọn àgùtàn tí wọ́n lè máa ṣákolọ, olùṣọ́ àgùtàn rere nlọ sínú aginjù láti wá àwọn àgùtàn tí ó sọnù, lẹ́hìnnáà ó ndúró pẹ̀lú wọn títí tí wọ́n fi padà síbi ààbò.19 Bí olùṣọ́-àgùtàn rere, àti bí àwọn ipò bá ti fàyè gbàá, a níláti wá láti lo àkokò síi láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn ènìyàn ní ilé wọn. Ní ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́, títẹ̀wé ránṣẹ́ àti ẹ̀rọ ìgbàlódé ni a níláti lo láti mu gbòòrò, kìí ṣe kí a rọ́pò, ìṣọwọ́sí araẹni.20

Èkejì, Jésù ni Àlùfáà Gíga ti àwọn Ohun Rere tó Nbọ̀.21 Ní mímọ̀ pé ìkànmọ́ àgbélèbú Rẹ̀ ko ju wákàtí díẹ̀ lọ mọ́, Jésù wípé: “Nkan wọ̀nyí ni mo ti sọ fún yín tẹ́lẹ̀, kí ẹ̀yin kí ó lè ní àláfíà nínú mi. Nínú ayé ẹ̀yin ó ní ìpọ́njú: ṣùgbọ́n ẹ tújúká; mo ti ṣẹ́gun ayé.”1 Ní òní, bí ayé wa ti ndi àríyànjiyàn àti pípínká, ìnílò nlá wà fún wa láti wàásù àti láti ṣe ìṣe dídára, ìgbàgbọ́ ohun rere, àti ìrètí, Bíótilẹ̀jẹ́pé àwọn ìpènijà kankan tilẹ̀ wà ní àtẹ̀hìnwá wa, ìgbàgbọ́ máa nnawọ́ sí ọjọ́ ọ̀la nígbàgbogbo,23 ní kíkún inú wa pẹ̀lú ìrètí, ó fi ààyè gbà wá láti mú ìpè Jésù láti tújúká ṣẹ.24 Fífi ayọ̀ gbé ìgbé ayé ìhìnrere nràn wá lọ́wọ́ láti di àwọn ọmọ ẹ̀hìn ohun rere tó nbọ̀.

Àkọlé Jésù míràn ni pé Ó jẹ́ Irúkannáà, ní Àná, ní Òní, àti Títíláé.25 Ìtẹramọ́ ni ìhùwàsí bíiti Krístì. Jésù máa nṣe ìfẹ́ Baba Rẹ̀ nígbàgbogbo,26 àtí pé ó na ọwọ́ Rẹ̀ síta láti gbàlà, ṣèrànwọ́, ó sì wò wá sàn.27 Bí a ti ntẹ̀ramọ́ gbígbé ìgbé ayé ìhìnrere, a ó dà bíiti Jésù.28 Bíótilẹ̀jẹ́pé ayé yíò ní ìrírí ìyíká nlá nínú àwọn ìsorọ̀ olókìkí bí àwọn ènìyàn tí nyí sọtun sósì tí ó sì ngbé wa kiri nínú gbogbo ìjì ẹ̀kọ́,29 ìtẹramọ́ gbígbé ìgbé ayé ìhìnrere yíò ràn wá lọ́wọ́ láti dúró ṣinṣin áti làìyẹsẹ̀ ní ìgbà ìjì ayé.30 Bákannáà a lè júwe ìtẹramọ́ nípa títẹ́wọ́gba ìpè Ààrẹ Nelson láti “fi àkokò fún Olúwa.”31 Okun nlá ti ẹ̀mí nwá látinú àwọn ohun kékeré àti ìrọ̀rùn32 bíi ṣíṣe “àwọn ìwà mímọ́ àti òdodo”33 ti àdúrà ojojúmọ́, ìrònúpìwàdà, àṣàrò ìwé mímọ́, àti iṣẹ́-ìsìn sí àwọn ẹlòmíràn.

Ẹ̀kẹ́rin, Jésù ni Ẹni Mímọ́ Ísráẹ́lì.34 Ìgbé ayé Jésù ni àwòṣe ìwàmímọ́. Bí a ti ntẹ̀lé Jésù, a lè di ẹni mímọ́ Ísráẹ́lì.35 A npọ̀si nínú ìwàmímọ́ bí a ti nbẹ tẹ́mpìlì wò déédé, nibití a ti gbẹ́ “Ìwàmímọ́ sí Olúwa sí òkè gbogbo ẹnu ọ̀nà. Gbogbo ìgbà tí a bá jọ́sìn nínú tẹ́mpìlì, a nkúrò pẹ̀lú ẹ̀bùn agbára láti mú ilé wa jẹ́ ibi mímọ́.36 Fún ẹnìkẹ́ni tí kò bá ní ìwé ìkaniyẹ láti wọ inú tẹ́mpìlì mímọ́ lọ́wọ́lọ́wọ́, mo pè yín láti lọ bá bíṣọ́pù yín àti kí ẹ mura arayín sílẹ̀ láti wọnú tàbí padà lọ sí ibi mímọ́ náà. Àkokò nínú tẹ́mpìlì yíò mú ìwàmímọ́ nínú ayé wa pọ̀ si.

Orúkọ tó kẹ́hìn ti Jésù kan ni pé Òun ni Olódodo àti Olotitọ.37 Gẹ́gẹ́bí Jésù ti jẹ́ olódodo títíláé àti olotitọ nígbàgbogbo, ìfẹ́ àtinúwá Rẹ̀ ni pé kí a fi àwọn ìwà wọ̀nyí hàn nínú ayé wa. Nígbàtí ìgbàgbọ́ bá tàsé, a lè sọkún jáde sí Jésù, “Olúwa, gbà mí là,” gẹ́gẹ́bí Pétérù bí òun ti bẹ̀rẹ̀ sí rì sínú ìjì òkun Gálílì.38 Ní ọjọ́ náà, Jésù nawọ́ sílẹ̀ láti gba àwọn ọmọ-ẹ̀hìn tí ó nrì là. Òun ti ṣe irúkannáà fún mi, Òun yíò sì ṣe irúkannáà fún yín. Ẹ máṣe juwọlẹ̀ lórí Jésù—Òun kò ní juwọ́lẹ̀ lórí yín!

Nígbàtí a bá jẹ́ olódodo àti olotitọ, à ntẹ̀lé ìpè Jésù láti, “Bá mi gbé,” èyí bákannáà lè túmọ̀sí “dúró ti mí.”39 Nígbàtí a bá dojúkọ àwọn ìbèèrè, nígbàtí a bá di fífi ṣẹ̀sín fún ìgbàgbọ́ wa, nígbàtí àwọn ìka ẹ̀gàn bá nàwọ́ sí wa láti ọ̀dọ̀ àwọn wọnnì nínú ilé ayé títóbi àti gbígbòòrò, a ndúró lódodo a sì ndúró lotitọ. Ní àwọn àkokò wọ̀nyí, a rántí ẹ̀bẹ̀ Jésù, “Wò mi nínú gbogbo èrò, máṣe ṣiyèméjì, máṣe bẹ̀rù.”40 Bí a ti nṣe bẹ́ẹ̀, Ó nfún wa ní ìgbàgbọ́, ìrètí, àti okun tí a nílò láti dúró tì Í.

Ẹ̀yin arákùnrin àti àrábìnrin ọ̀wọ́n, Jésù nfẹ́ kí a mọ Òun nítorí Òun wà nínú orúkọ kanṣoṣo lábẹ́ ọ̀run níbití a ti lè ní ìgbàlà.42 Jésù ni ọ̀nà, àti òtítọ́, ati ìyè—kò sí ẹnikẹ́ni tí ó le wá sí ọ̀dọ̀ Baba, bíkòṣe nípasẹ̀ mi.43 Jésù ni ọ̀nà kanṣoṣo! Fún èrèdí náà, Jésù npè, “wá sọ́dọ̀ mi,”44 “Tẹ̀lé mi,”45 “Rìn pẹ̀lú mi,”46 àti “Kọ́ nípa mi.”47

Pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi, mo jẹ́ ẹ̀rí nípa Jésù Krístì—Pé Ó wà láàyè, pé Ó nifẹ yín, àti pé Ó mọ̀ yín nípa orúkọ yín. Òun ni Ọmọ Ọlọ́run,48 Ọmọ Bíbí Kanṣoṣo Baba.49 Òun ni Àpáta wa, Odi wa, Àsà wa, Ààbò wa, àti Olùgbàlà wa.50 Òun ni ìmọ́lẹ̀ èyí tí ó Ntàn nínú Òkùnkùn.51 Òun ni Olùgbàlà wa52 àti Olùràpadà wa.53 Òun ni Àjínde àti Ìyè.54 Ìfẹ́ àtọkànwà mi ni pé ẹ̀yin yíò wá láti mọ Jésù nípa àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ orúkọ Rẹ̀ àti pé ẹ̀yin yíò dà bíiti Rẹ̀ bí ẹ ti nfi àpẹrẹ àwọn ìhùwàsí tọ̀run Rẹ̀ hàn nínú ayé yín ní orúkọ Jésù Krístì, àmín. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Tẹ̀