Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Idùnnú àti Títíláé
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2022


Idùnnú àti Títíláé

Nítòótọ́, ayọ̀ ìforítì àti àìlópin pẹ̀lú àwọn wọnnì tí a fẹ́ràn ni àkója ètò ìdùnnú Ọlọ́run gan an.

Ẹ̀yin ọ̀rẹ́, arákùnrin, àti arábìnrin ọ̀wọ́n, ṣe ẹ rántí gbígbàgbọ́, tàbí fífẹ́ láti gbàgbọ́, ní ìdùnnú títí lẹ́hìnnáa?

Nígbànáà ìgbé ayé ṣẹlẹ̀ A “dàgbà sókè.” Àwọn ìbáṣepọ̀ di líle. Ayé yí ní aruwo, ọ̀pọ̀ èrò, ìtari, pẹ̀lú ẹ̀tàn àti dídúró. Síbẹ̀síbẹ̀, ní inú “kókó ìjìnlẹ̀ ọkàn wa,”1 a gbàgbọ́, tàbí a fẹ́ gbàgbọ́, níbìkan, bákan, ìdùnnú àti títíláé jẹ́ òdodo ó sì ṣeéṣe.

“Ìdùnnú àti títíláé” kìí ṣe ohun ríro ti ìtàn kúrékùré. Nítòótọ́, ayọ̀ ìforítì àti àìlópin pẹ̀lú àwọn wọnnì tí a fẹ́ràn ni àkója ètò ìdùnnú Ọlọ́run gan an. Ọ̀nà ìmúrasílẹ̀ pẹ̀lú ìfẹ́ lè mú ìrìnàjò ayérayé wa ní ìdùnnú àti títíláé.

A ní ayẹyẹ púpọ̀ láti ṣe àti fún èyí tí à nní ìmoore. Síbẹ̀síbẹ̀, kò sí ẹnìkankan lára wa tí ó pé, tàbí ẹbí kankan. Àwọn ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú ìfẹ́, ọ̀làjú, àti ìrínisí ṣùgbọ̀n nígbàkugbà bákannáà ìkọlura, ìpalára, nígbàmíràn ìrora jíjinlẹ̀.

“Nítorí bí gbogbo ènìyàn ṣe kú nínú Ádámù, àní bẹ́ẹ̀ni a ó sọ gbogbo ènìyàn di alààyè nínú Krístì.”2 Wíwà láàyè nínú Jésù Krístì pẹ̀lú ara àìkú—ẹ̀bùn Rẹ̀ ti àjínde ti ara wa. Bí a ti ngbé pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti ìgbọràn, wíwà láàyè nínú Krístì bákannáà wà pẹ̀lú fífi ọ̀pọ̀ ayọ̀ ìyè ayérayé wà pẹ̀lú Ọlọ́run àti àwọn tí a fẹ́ràn.

Nínú ọ̀nà olókìkí kan, wòlíì Olúwa nfà wá súnmọ́ Olùgbàlà wa, pẹ̀lú ipasẹ̀ àwọn ìlànà tẹ́mpìlì mímọ́ àti àwọn májẹ̀mú tí ó nfà súnmọ́ wa ní àwọn ibi púpọ̀ síi. A ní ànfàní jíjinlẹ̀ àti ẹ̀bùn láti lóye ìwárí ti ẹ̀mí titun, ìfẹ́, ìrònúpìwàdà, àti ìdáríjì pẹ̀lú ara wa àti àwọn ẹbí wa, ní àkokò àti àìlópin.

Nípa gbígbàyè, mò npín àwọn ìrìrí mímọ́ méjì tí a sọ láti ẹnu àwọn ọ̀rẹ́ méjì nípa Jésù Krístì tí ó nmú àwọn ẹbí ní ìrẹ́pọ̀ nípa ìwòsàn àní ìjà nínú-ìrandíràn.4 “Àìlópin àti ayérayé,”4 “ó ní agbára ju okùnfà ikú,”5 Ètùtù Jésù Krístì lè ràn wá lọ́wọ́ láti mú àláfíà sí àtẹ̀hìnwá wa àti ìrètí sí ọjọ́ ọ̀là wa.

Nígbàtí wọ́n darapọ̀ mọ́ Ìjọ Jésù Krístì ti awọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, ọ̀rẹ́ mi àti ọkọ rẹ̀ fi tayọ̀tayọ̀ kọ́ pé àwọn ìbáṣepọ̀ ẹbí kò níláti jẹ́ “títí tí ikú bá pín wa níyà.” Ní ilé Olúwa, àwọn ẹbí lè ní ìrẹ́pọ̀ ti (èdidì) ayérayé.

Ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ mi kò fẹ́ láti ṣe èdidì sí baba rẹ̀. “Òun kìí ṣe ọkọ rere sí ìyá mi. Òun kìí ṣe baba rere sí àwọn ọmọ rẹ̀,” ni ó wí. “Baba mi yíò ní láti dúró. Èmi kò ní ìfẹ́ kankan láti ṣe iṣẹ́ tẹ́mpìlì àti jẹ́ ṣíṣe èdidì pẹ̀lú rẹ̀ ní àìlópin.”

Fún ọdún kan, ó gbàwẹ̀, ó gbàdúrà, ó sọ̀rọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ pẹ̀lú Olúwa nípa baba rẹ̀. Nígbẹ̀hìn, ó ti ṣetàn. Ó parí iṣẹ́ tẹ́mpìlì baba rẹ̀. Lẹ́hìnnáà, ó wípé, “Nínú oorun mi baba mi farahàn mi nínú àlá, gbogbo wọn wọṣọ funfun. Ó ti yípadà. Ó wípé, ‘Ẹ wò mí. Mo jẹ́ àìléèrí pátápátá. O ṣé fún ṣíṣe iṣẹ́ fún mi nínú tẹ́mpìlì.’” Baba rẹ̀ fikun pe, “Dìde sókè kí ó sì padà sí tẹ́mpìlì; arákùnrin rẹ̀ ndúró láti ṣe ìribọmi.”

Ọ̀rẹ́ mi wípè, “Àwọn babanla mi àti àwọn wọnnì tí wọ́n ti kọjá lọ ndúró taratara fún iṣẹ́ wọn láti di ṣíṣe.”

Ó wípé, “fún mi,” “tẹ́mpìlì jẹ́ ibi ìwòsàn, ìkọ́ni, àti jíjẹ́wọ́ Ètùtù Jésù Krístì.”

Ìrírí kejì Ọ̀rẹ́ míràn fi aápọn ṣe ìwákiri àkọọ́lẹ̀-ìtàn ẹbí rẹ̀. Ó nfẹ́ láti yẹ baba-baba-baba rẹ̀ wò.

Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kan, ọ̀rẹ́ mi wípé òun ní ìmọ̀lára wíwà ti ẹ̀mí ọkùnrin kan nínú yàrá rẹ̀. Ọkùnrin náà fẹ́ kí a wá òun kí a sì mọ òun nínú ẹbí rẹ̀. Ọkùnrin náà nímọ̀lára àbámọ̀ fún àṣìṣe kan fún èyí tí ó ti ronúpìwàdà. Ọkùnrin náà ran ọ̀rẹ́ mi lọ́wọ́ láti damọ̀ pé ọ̀rẹ́ mi kò ní ìsopọ̀ ìbátan pẹ̀lú ẹnití ọ̀rẹ́ mi rò pé ó jẹ́ baba-baba-baba rẹ̀. “Ní ọ̀rọ̀ míràn,” ọ̀rẹ́ mi wípé, “mo ti ṣe àwárí baba-baba-baba mi mo sì ti kọ́ pé òun kìí ṣe ẹnití àkọsílẹ̀ ẹbí wa wípé ó jẹ́ baba-baba-baba wa.”

Àwọn ìbáṣepọ̀ ẹbí rẹ̀ fi ohun tí, ọ̀rẹ́ mi wípé “mo ní ìmọ̀ òmìnira, ní àláfíà hàn. Ó ṣe gbogbo ìyàtọ̀ láti mọ ẹnití ẹbí mi jẹ́.” Ọ̀rẹ́ mi ronú pé, “Ẹ̀ká tí ó tẹ̀ kò túmọ̀sí pé igi burúkú ni. Bí a ti wá sínú ayé yí kò ṣe pàtàkì ju ẹni tí a jẹ́ nígbàtí a ó fi sílẹ̀.”

Àwọn ìwé mímọ́ àti ìrírí mímọ́ ti wíwòsàn àti àláfíà araẹni, wà pẹ̀lú àwọn wọnnì tí wọ̀n wà láàyè nínú ayé ẹ̀mí, ó fi àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ marun sábẹ́ rẹ̀.

Àkọ́kọ́: Gbùngbun nínú ètò ìràpadà àti ìdùnnú Ọlọ́run, Jésù Krístì, nípasẹ̀ Ètùtù Rẹ̀, ṣe ìlérí láti sọ ẹ̀mí àti ara di ọ̀kan, “láéláé kí a máṣe pínyà, kí a lè gba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ayọ̀.”7

Èkejì: Ètùtù—ní-sísopọ̀-kan nínú Krístì—nwá bí a ti nlo ìgbàgbọ́ tí a sì nmú àwọn èso jáde wá sí ìrònúpìwàdà.8 Bíi ti ara ikú, bẹ́ẹ̀ ni nínú ara àìkú. Àwọn ìlànà tẹ́mpìlì kìí fúnra wọn yí wa padà tàbí àwọn wọnnì nínú ayé ẹ̀mí. Ṣùgbọ́n àwọn ìlànà tọ̀run wọ̀nyí nfi ààyè gba yíyàsímímọ́ àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Olúwa, èyí tí ó lè mú ìbámu pẹ̀lú Rẹ̀ àti arawa wá.

Ayọ̀ wa ndi kíkún bí a ti nní ìmọ̀lára oore ọ̀fẹ́ Jésù Krístì àti ìdáríjì fún wa. Àti, bí a ti nfúnni ní iṣẹ́ ìyanu oore ọ̀fẹ́ Rẹ̀ àti ìdáríjì sí ara wa, ìyọ́nú tí a gba àti àánú tí a fúnni lè ràn wá lọ́wọ́ láti mú kí àwọn àìní-ìdáláre di dídáláre.9

Ẹ̀kẹ́ta: Ọlọ́run mọ̀ wá ní pípé. “A kò lè fi Ọlọ́run ṣe ẹlẹ́yà,”9 tàbí kí a tàn Án. Pẹ̀lú àánú pípé àti ìdáláre, Òun nyí onírẹ̀lẹ̀ àti onísùúrù ká nínú apá ààbò Rẹ̀.

Ní Tẹ́mpìlì Kirtland, Wòlíì Joseph Smith rí arákùnrin rẹ Alvin nínú ìran tí a gbàá là nínú ìjọba Sẹ̀lẹ́stíà. Ó ya wòlíì Joseph lẹ́nu, nítorí Alvin ti kú ṣíwájú gbígba ìlànà ìgbàlà ìribọmi.10 Ní tituninínú, Olúwa ṣe àlàyé ìdí tí: Olúwa “yíò fi dájọ́ [wa] gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ [wa], gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ọkàn [wa].”11 Ẹ̀mí wa njẹ́ri iṣẹ́ àti ìfẹ́ wa.

Pẹ̀lú ìmoore, a mọ̀ pé alààyè àti “òkú tí wọ́n ronúpìwàdà ni a ó ràpàdà, nípasẹ̀ ìgbọràn sí àwọn ílànà ilé Ọlọ́run”12 àti Ètùtù Krístì. Nínú ayé ẹ̀mí, àní àwọn wọnnì nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti ìrékọjá ti ní ànfàní láti ronúpìwàdà.13

Ní ìlòdì, àwọn wọnnì tí wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ yan ìwà búburú, tí wọ́n fi ìmọra fi ìrònúpìwàdà wọn falẹ̀, tàbí nínú ìrotẹ́lẹ̀ kankan tàbí ní mímọ ọ̀nà rírú àwọn òfin ní ṣíṣe ètò fún ìrọ̀rùn ìrònúpìwàdà yíò gba ìdájọ́ ní ọwọ́ Ọlọ́run àti “rírántí gbogbo ẹ̀bí [wọn] dáadáa.”15 A kò ní mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀ ní Sátidé, nígbànáà kí a retí ìdáríjì bẹ́ẹ̀ nípa ṣíṣe àbápín oúnjẹ Olúwa ní ọjọ́ Ìsinmi. Sí àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere tàbí àwọn míràn tí wọ́n wípé títẹ̀lé Ẹ̀mí túmọ̀sí àìníláti gbọ́ran sí àwọn òṣùwọ̀n míṣọ̀n tàbí àwọn òfin, ẹ jọ̀wọ́ ẹ rántí pé gbígbọ́ran sí àwọn òṣùwọ̀n míṣọ̀n àti àwọn òfin npe Ẹ̀mí. Kò yẹ kí ẹnikẹ́ni nínú wa jáwọ́ nínú ìrònúpìwàdà. Àwọn ìbùkún nbẹ̀rẹ̀ bí a ti nronúpìwàdà.

Ẹ̀kẹ́rin: Olúwa nfún wa ní ànfàní tọ̀run láti dà bíi Tirẹ̀ bí a ti nfi ìrọ́pò àwọn ìlànà ìgbàlà tẹ́mpìlì fún àwọn míràn nínú àìní ṣùgbọ́n tí wọ́n kò lè ṣe é fúnrawọn. A lè di aláṣeparí àti pípé15 bí a ti ndà bí “olùgbàlà … ní Òkè Síónì.”16 Bí a ti nsin àwọn ẹlòmíràn, Ẹ̀mí Mímọ́ ti Ìlérí lè ṣe àtúnṣe àwọn ìlànà kí ó sì ya olùgbà àti olùfúnni sí mímọ́. Àwọn olùfúnni àti olùgbà lè ṣe àti mú àwọn májẹ̀mú ìyípadà jinlẹ̀, ní àkókò púpọ̀ gbígba àwọn ìbùkún ìlérí Ábráhámù, Ísáákì, àti Jákọ́bù.

Lákotán, Ikarun: Gẹ́gẹ́bí òfin Wúra17 ṣe kọ́ni, àkópọ̀ ìwà mímọ́ nínú ìrònúpìwàdà àti ìdáríjì npe ẹnì kọ̀ọ̀kan láti fún àwọn ẹlòmíràn ní ohun tí àwa fúnra wa nílò àti nìfẹ́ sí.

Nígbàmíràn ìfẹ́ wa láti dáríji ẹlòmíràn nmú àwọn pẹ̀lú àti àwa gbàgbọ́ pé a lè ronúpìwàdà kí a sì gba ìdáríjì. Nígbàmíràn ìfẹ́ láti ronúpìwàdà àti okun láti dáríjì nwá ní ìgbà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Olùgbàlà wa ni Olùlàjà pẹ̀lú Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ó nrànwálọ́wọ́ láti mú arawa wá bá arawa àti àwọn míràn bí a ti nwá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Nípàtàkì nígbàtí ìpalára àti ìrora bá jinlẹ̀, títún ìbáṣepọ̀ wa ṣe àti wíwo ọkàn wa sàn le, bóyá àìṣeéṣe fún wa ní arawa. Ṣùgbọ́n ọ̀run lè fún wa ní okun àti ọgbọ́n kọjá arawa láti mọ ìgbàtí a ó dáwọ́dúró, àti láti jẹ́ kó lọ.

À ndínkù ní dídáwà nígbàtí a bá damọ̀ pé a kò dá wà. Olùgbàlà wa nní ìmọ̀ nígbàgbogbo.19 Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Olùgbàlà, a lè fi ìgbéraga, ìpalára, ẹ̀ṣẹ̀ wa sílẹ̀ fún Ọlọ́run. Bákannáà a lè ní ìmọ̀lára bí a ti nbẹ̀rẹ̀, a ndà pípé síi bí a ti ngbẹ́kẹ̀lé E láti mú àwọn ìbáṣepọ̀ wa di pípé.

Olúwa, ẹnití ó rí tí ó sì ní ìmọ̀ ní pípé, ndáríji ẹnití Òun yíò daríjì; àwa (ní jíjẹ àìpé) níláti dáríji gbogbo ènìyàn. Bí a ti nwá sọ́dọ̀ Olùgbàlà wa, à ndínkù ní ìdojúkọ ara wa. À ṣe ídájọ́ kéré sí àti dáríjì díẹ̀ síi. Gbígbẹ́kẹ̀lé èrè Rẹ̀, àánú, àti oore ọ̀fẹ́20 lè sọ wá di òmìnira kúrò nínú ìjà, ìbínú, ìlòkulò, ìpatì, àìdára, àti àwọn ìpènijà ti ara àti ọpọlọ tí ó nwá nígbàmíràn pẹ̀lú ti-ara nínú ayé ikú. Ìdùnnú àti títíláé kó túmọ̀sí pé ìbáṣepọ̀ yíò jẹ́ ìdùnnú àti títíláé. Ṣùgbọ́n ẹgbẹ̀rún ọdún mílléníà kan nígbàtí a bá de Sátánì21 lè fún wa ní àkokò àti àwọn ọ̀nà yíyanilẹ́nu láti ní ìfẹ́, ìmọ̀, àti láti ṣe àwọn ohun láti múrasílẹ̀ fún ayérayé.

À nrí àwùjọ tọ̀run nínú ara wa.22 Iṣẹ́ Ọlọ́run àti ògo wà pẹ̀lú mímú ìdùnnú àti títíláé wá sí ìmúṣẹ.23 Ìyè ayérayé àti ìgbéga ni láti mọ Ọlọ́run àti Jésù Krístì bẹ́ẹ̀, nípasẹ̀ agbára ti ọ̀run, níbití Wọ́n wà ni a ó wà.24

Ẹyin arákùnrin àti arábìnrin ọ̀wọ́n, Ọlọ́run Baba wa Ọ̀run àti Olùfẹ́ Ọmọ Rẹ wà láàyè. Wọ́n nfi, àláfíà, ayọ̀, àti ìwosàn fún gbogbo ìbátan àti èdè, fún gbogbo ẹbí, fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wa. Wòlíì Olúwa ni ó ndarí ọ̀nà náà. Ìfihàn Ọjọ́-ìkẹhìn ntẹ̀síwájú. Njẹ́ kí a fà súnmọ́ Olùgbàlà wa nínú ilé mímọ́ Rẹ̀, àti pé kí Òun lè fá wá súnmọ́ Ọlọ́run àti sí ara wa, bí a ti nso ọkàn wa papọ ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ìyọ́nú, òtítọ́, àti àánú bíiti Krístì ní gbogbo ìran wa—ní àkokò àti àìlópin, ìdùnnú àti títíláé. Nínú Jésù Krístì, ó ti ṣeéṣe; nínú Jésù Krístì, ó jẹ́ òtítọ́. Ní mo jẹ́ ẹ̀rí ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín

Tẹ̀