Ẹ Fi Àkókò Sílẹ̀ fún Olúwa
Mo bẹ̀ yín lóni láti tako ẹ̀tàn ti ayé nípa fífi àkókò sílẹ̀ fún Olúwa nínú ìgbé ayé yín—ní ọ̀kọ̀ọ̀kan àti ní gbogbo ọjọ́.
Ẹyin arákùnrin àti arábìnrin mi, fún ọjọ́ méjì a ti kọ́ ẹ̀kọ́ dáradára nípasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ Olúwa àwọn tí wọ́n ti fi pẹ̀lú aápọn wá láti mọ ohun tí Ó fẹ́ kí wọn ó sọ.
A ti fúnwa ní àṣẹ wa fún oṣù mẹ́fà tí ó tẹ̀lé. Nísisìyí ìbéèrè náà ni pé, báwo ni a ó ṣe yàtọ̀ nítorí ohun tí a ti gbọ́ àti tí a ti ní ìmọ̀lára rẹ̀?
Àjàkálẹ̀-àrùn náà ti ṣe ìjúwe bí ìgbé ayé ṣe le yípadà kíákíá, nígbà míràn láti inú àwọn ipò tí ó tayọ àkóso wa. Bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀, àwọn nkan púpọ̀ ní ó wà tí a le ṣe àkóso. A nṣe àwọn ètò tiwa bí wọ́n ti ṣe kókó sí a sì npinnu bí a ó ṣe lo agbára, àkókò àti àwọn ìní wa. A npinnu bí a ó ti ran ara wa lọ́wọ́. A nyàn àwọn wọnnì tí a le kọjú sí fún òtítọ́ àti ìtọ́ni.
Àwọn ohùn àti àwọn ìwúwo ti ayé le fani síṣẹ́ wọ́n sì jẹ́ àìníye. Ṣùgbọ́n púpọ̀jù àwọn ohùn jẹ́ ìtànjẹ, ìbanijẹ́, wọ́n sì le fà wá kúrò ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú. Láti yẹra fún ìrora ọkàn tí kò le yẹ̀ tí ó máa ntẹ̀lé, mo bẹ̀ yín lóni láti tako ẹ̀tàn ti ayé nípa fífi àkókò sílẹ̀ fún Olúwa nínú ìgbé ayé yín—ní ọ̀kọ̀ọ̀kan àti ní gbogbo ọjọ́.
Bí púpọ̀ jùlọ àwọn ìwífúnni tí ẹ ngbà bá nwá láti inú ìbákẹ́gbẹ́ àwùjọ tàbí irú rẹ̀ míràn, agbára yín láti gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ ti Ẹmí yío jẹ́ dídínkù. Bákannáà bí ẹ kò bá máa wá Olúwa nípasẹ̀ àdúrà àti àṣàrò ìhìnrere ojojúmọ́, ẹ nfi ara yín sílẹ̀ láìlágbára sí àwọn ẹ̀kọ́ tí ó le wuni ṣùgbọ́n tí kìí ṣe òtítọ́. Àní Àwọn Ènìyàn Mímọ́ tí wọ́n jẹ́ olõtọ́ le jẹ́ mímú yẹ̀sẹ̀ nípa ìdúróṣinṣin ti ìlù Bábílónì.
Ẹ̀yin arákùnrin àti aràbìnrin, mo rọ̀ yín láti fi àkókò sílẹ̀ fún Olúwa. Ẹ mú kí ìpìlẹ̀ tiyín ní ti ẹ̀mí dúró ṣinṣin kí ó sì le kojú ìdánwò àkókò nípa síṣe àwọn nkan wọnnì tí yío fi ààyè gba Ẹmí Mímọ́ lati wà pẹ̀lú yín nígbà gbogbo.
Ẹ máṣe fojú kéré òtítọ́ ìjìnlẹ̀ pé, “Ẹmí nsọ̀rọ̀ … nípa ohun gbogbo bí wọ́n ṣe rí gan an , àti nípa ohun gbogbo bí wọ́n yíò ṣe rí gan an .”1 “Òun yíò “fi hàn síi yín gbogbo àwọn ohun èyí tí ó yẹ kí ẹ ṣe.”2
Kò sí ohun tí ó npe Ẹmí ju fífi ìfojúsùn yín sí ọ̀dọ̀ Jésù Krístì lọ. Ẹ sọ̀rọ̀ nípa Krístì, ẹ yọ̀ nínú Krístì, ẹ ṣe àpèjẹ lórí àwọn ọ̀rọ̀ Krístì, kí ẹ sì tẹ̀ síwájú pẹ̀lú ìdúróṣinṣin nínú Krístì.3 Ẹ ṣe Ọjọ́ Ìsinmi yín ní aláyọ̀ bí ẹ ti njọ́sìn fún Un, tí ẹ nkópa nínú ounjẹ Olúwa, tí ẹ sì nṣe ọjọ́ Rẹ̀ ní mímọ́.4
Bí mo ṣe tẹnumọ́ọ ní òwúrọ̀ yí, ẹ jọ̀wọ́ ẹ fi àkókò sílẹ̀ fún Olúwa nínú ilé mímọ́ Rẹ̀. Kò aí ohun tí ó le fún ìpìlẹ̀ yín níti ẹ̀mí lókun bíi iṣẹ́ ìsìn ní tẹ́mpìlì àti ìjọ́sìn ní tẹ́mpìlì.
A dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn tí wọ́n nṣiṣẹ́ lórí àwọn tẹ́mpìlì wa titun. A nkọ́ wọn káàkiri gbogbo àgbáyé. Ní òní inú mi dùn láti kéde àwọn ètò wa láti kọ́ àwọn tẹ́mpìlì síi ní tàbí nítorí àwọn ibi wọ̀nyí: Kaohsiung, Taiwan; Tacloban, Philippines; Monrovia, Liberia; Kananga, Democratic Republic of the Congo; Antananarivo, Madagascar; Culiacán, Mexico; Vitória, Brazil; La Paz, Bolivia; Santiago West, Chile; Fort Worth, Texas; Cody, Wyoming; Rexburg North, Idaho; Heber Valley, Utah; àti títúnṣe Tẹ́mpìlì Provo Utah lẹ́hìn tí a bá ti ya Tẹ́mpìlì Orem Utah Tsí mímọ́.
Mo féràn yín, ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin ọ̀wọ́n. Olúwa mọ̀ yín ó sì féràn yín. Òun ni Olùgbàlà yín àti Olùràpadà yín. Ó ndarí ó sì ntọ́ Ìjọ Rẹ̀. Òun yío dárí yío sì tọ́ yín nínú ìgbé ayé ti ara ẹni yín bí ẹ bá fi ààyè sílẹ̀ fún Un nínú ayé yín—ní ọ̀kọ̀ọ̀kan àti ní gbogbo ọjọ́.
Njẹ́ kí Ọlọ́run wà pẹ̀lú yín títí a ó tún pàdé, mo gbàdúrà ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.