Mímú Ìyípadà Wa sí Jésù Krístì Jinlẹ̀ Síi
Àwọn ìwé-mímọ́ àti ìmọ̀ Ọlọ́run jẹ́ ẹ̀bùn—àwọn ẹ̀bùn tí a máa nmú yẹpẹrẹ nígbàkugbà. Ẹ jẹ́ kí a mọyì àwọn ìbùkún wọ̀nyí.
O ṣe gan an, Alàgbà Nielson, fún ọ̀rọ̀ dídára rẹ. A nílò ìyẹn.
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, Ààrẹ Russell M. Nelson ti kọ́ wa láìpẹ́: “Láti ṣe ohunkóhun dáradára ní ìlò ìyànjú. Dída ọmọẹ̀hìn tòótọ́ ti Jésù Krístì kìí ṣe yíyọ sílẹ̀ rárá. Mímú ìgbàgbọ́àti ìgbẹ́kẹ̀lé yín nínu Rẹ̀ pọ síì gba ìyànjú.” Lára àwọn àbá tí ó fún wa láti mú ìgbàgbọ́ wa pọ̀ si nínú Jésù Krístì ni pé kí a di akẹ́kọ tí nṣiṣẹ́ lọ́wọ́, pé kí a ri ara wa bọ inú àwọn ìwé-mímọ́ láti ní òye dídárajù nípa iṣẹ́-pàtàkì àti iṣẹ́-ìránṣẹ́ Krístì. (Wo “Krístì Jínde; Ìgbàgbọ́ nínú Rẹ̀ Yíò Ṣí àwọn Òkè,” Liahona, May 2021, 103.)
A kọ́ nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì pé àwọn ìwé-mímọ́ jẹ́ pàtàkì ara ẹbí Léhì—stóbẹ́ẹ̀ tí Nefi àti àwọn arákùnrin rẹ̀ fi padà sí Jerusalem láti gba àwọn àwo idẹ (wo 1 Nefi 3–4).
Àwọn ìwé-mímọ́ ṣàfihàn ìfẹ́ Ọlọ́run fún wa, bí Lìàhónà ti ṣe fún Néfì àti baba rẹ̀. Lẹ́hìn tí ó fọ́ ọrun rẹ̀, Néfì nílò láti mọ ibití ó yẹ kí ó lọ láti wá oúnjẹ. Baba rẹ̀, Léhì, wo àyíká ó sì rí àwọn nkan tí a kọ. Néfì rí i pé àwọn ọ̀pá tí ó wà lórí àyíká náà nṣiṣẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú ìgbàgbọ́, aápọn, àti àfiyèsí tí a fifún wọn. Ó tún rí ìwé-kíkọ èyítí ó rọrùn láti ka ati eyiti o fun wọn ni oye nipa awọn ipa ọna Oluwa. O di mímọ̀ fún un pé Olúwa nmú àwọn ohun nlá wá nípasẹ̀ àwọn ọ̀nà kékeré. Ó jẹ́ onígbọràn nípa àwọn ìtọ́sọ́nà tí a fúnni nípasẹ̀ atọ́nà náà. Ó gun orí òkè lọ ó sì rí oúnjẹ fún ìdílé rẹ̀, tí wọ́n ti jìyà púpọ̀ nítorí àìní ibẹ̀. Wo 3 Néfì 16:23–30.)
Sí mi ó dàbí ẹnipé Néfì jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ tí a yàsọtọ̀ sí àwọn ìwé-mímọ́. A kà pé Néfì ní inú dídùn sí àwọn ìwé mímọ́, ó ronú lórí wọn nínú ọkàn rẹ̀, ó sì kọ wọ́n fún ẹ̀kọ́ àti èrè àwọn ọmọ rẹ̀ (wo 2 Néfì 4:15–16).
Ààrẹ Russell M. Nelson wípé:
“Bí àwa ‘bá tẹ̀síwájú, ní síṣe àpéjẹ lórí ọ̀rọ̀ Krístì, tí a sì forítì dé òpin, … [àwa] yíò ní ìyè ayérayé’ [2 Néfì 31:20].
“Láti jẹ àpèjẹ ní ìtúmọ̀ ju títọ́wò lọ. Láti jẹ àpèjẹ túmọ̀ sí láti gbádùn. A ngbádùn àwọn ìwé-mímọ́ nípa síṣe àṣàrò wọn nínú ẹ̀mí àwárí dídùn àti ìgbọràn tòótọ́. Nígbàtí a bá ṣe àpèjẹ lórí àwọn ọ̀rọ̀ Krístì, wọ́n nwà lórí ‘àwọn tábìlì tó lẹ́ran ti ọkàn wa’ [2 Corinthians 3:3]. Wọ́n di apákan pàtàkì ti àdánidá wa (“Gbígbé Nípa Ìtọ́ni Ìwé Mímọ́,” Liahona, Jan. 2001, 21).
Kíni Díẹ̀ Nínú àwọn Ohun Tí Àwa Yíò Ṣe Bí Ẹ̀mí Wa Bá Ní Inúdídùn Nínú àwọn Ìwé-mímọ́?
Ìfẹ́-inú wa láti jẹ́ apákan ti kíkójọ Ísráẹ́lì ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ìbòjú yíò pọ̀ síi. Yíò jẹ́ ohun tí ó ṣe déédé àti àdánidá fún wa láti pe ẹbí àti àwọn ọ̀rẹ́ wa láti tẹ́tísílẹ̀ sí àwọn ìránṣẹ́-ìhìnrere. Àwa yíò yẹ, a ó sì ní ìwé ìkaniyẹ tẹ́mpìlì lọ́wọ́lọ́wọ́ láti le lọ sí tẹ́mpìlì nígbàgbogbo bí o ti ṣeéṣe. Àwa yíò ṣiṣẹ́ láti wá-rí, pèsè, àti fi àwọn orúkọ àwọn baba nlá wa sílẹ̀ sí tẹ́mpìlì. Àwa yíò jẹ́ olótitọ́ ní pípa Ọjọ́ Ìsimi mọ́, wíwàní ilé ìjọsìn ní gbogbo Ọjọ́ Ìsinmi láti tún àwọn májẹ̀mú wa ṣe pẹ̀lú Olúwa bí a ṣe nkópa ní pípé ní gbígba oúnjẹ Olúwa náà. A ó pinnu láti dúró lórí ipa-ọ̀nà májẹ̀mú, gbígbé nípa gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó jáde wá látẹnu Ọlọ́run (wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 84:44).
Kíni Ó Túmọ̀sí Fún Yín Láti Ní Ìdùnnú Nínú àwọn Ohun ti Olúwa?
Níní inú dídùn nínú àwọn ìwé-mímọ́ ṣe kókó ju ebi pípa àti pípòngbẹ fún ìmọ̀ lọ. Néfì ní ìrírí ayọ̀ ńlá nígbà ayé rẹ̀. Sùgbọ́n, bákannáà ó dojúko àwọn ìṣòro àti ìbànújẹ́ (wo 2 Néfì 4:12–13). “Síbẹ̀síbẹ̀,” ó sọ pé, “Mo mọ ẹnití èmi ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ̀” (2 Néfì 4:19). Bí a ti nṣe àṣàrò àwọn ìwé-mímọ́, àwa yíò ní òye dáradára síi nípa ètò ìgbàlà àti ìgbéga ti Ọlọ́run, àti pé àwa yíò ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àwọn ìlérí tí Ó ti ṣe fún wa nínú àwọn ìwé-mímọ́, àti bákannáà nínú àwọn ìlérí àti àwọn ìbùkún ti àwọn wòliì òde òní.
Ní ọ̀sán kan, a pe ìyàwó mi àti èmi sí ilé ọ̀rẹ́ kan. Ọmọkùnrin wọn ẹniọdún-méje, Dáfídì, kò tíì gbọ́ ìtàn Bíbélì ti Dáfídì àti Gòlíátì rí, ó sì fẹ́ láti gbọ́ ọ. Bí mo ti bẹ̀rẹ̀ sísọ ìtàn náà, ó ní ìfọwọ́kàn nípa ọ̀nà tí Dáfídì, pẹ̀lú ìgbàgbọ́ rẹ̀ àti ní orúkọ Ọlọ́run Ísráẹ́lì, tí ṣe é léṣe tí ó sì pa Filístínì náà pẹ̀lú kànnàkànnà àti òkúta kan, láìsí idà lọ́wọ́ rẹ̀ (wo 1 Sámúẹ́lì 17).
Ní wíwò mí pẹ̀lú àwọn ojú rẹ̀ tó dúdú púpọ̀, ó bèèrè lọ́wọ́ mi ní ìdúróṣinṣin, “Tani Ọlọ́run?” Mo ṣàlàyé fún un pé Ọlọ́run ni Bàbá wa Ọ̀run àti pé a kọ́ nípa Rẹ̀ nínú àwọn ìwé mímọ́.
Lẹ́hìnnáà ó bèèrè lọ́wọ́ mi, “Kíni àwọn ìwé-mímọ́?” Mo sọ fún un pé àwọn ìwé-mímọ́ jẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti pé nínú wọn òun yíò rí àwọn ìtàn rírẹwà tí yíò ṣe ìrànlọ́wọ́ fún un láti mọ Ọlọrún dáradára síi. Mo bèèrè lọ́wọ́ ìyá rẹ̀ láti lo Bíbélì tí ó ní nínú ilé rẹ̀ àti pé kò jẹ́ kí Dáfídì lọ sùn láìsí kíka gbogbo ìtàn fún un. Inú rẹ̀ dùn bí ó ti ńfetí sí i. Àwọn ìwé-mímọ́ àti ìmọ̀ Ọlọ́run jẹ́ ẹ̀bùn—àwọn ẹ̀bùn tí a máa nmú yẹpẹrẹ nígbàkugbà. Ẹ jẹ́ kí a mọyì àwọn ìbùkún wọ̀nyí.
Lákoko ṣíṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́-ìránṣẹ́ gẹ́gẹ́bí ọ̀dọ́, mo ṣe àkíyèsí pé nípa kíkọ́ni pẹ̀lú àwọn ìwé-mímọ́, ìgbésí ayé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn di yíyípadà. Mo ní ìmọ ágbara tí ó wà nínú wọn àti bí wọ́n ṣe lè yí ìgbésí ayé wa padà. Ènì kọ̀ọ̀kan tí a kọ́ ní ìhìnrere tí a mú padàbọ̀sípò jẹ́ ẹni àrà ọ̀tọ̀ olúkúlùkù pẹ̀lú oríṣiríṣi.àwọn àìní Àwọn ìwé-mímọ́—bẹ́ẹ̀ni, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí a ti ọwọ́ àwọn wòlíì mímọ́ kọ—mú wọn wá sí ìgbàgbọ́ nínú Olúwa àti sí ìrònúpíwàdà ó sì yí ọkàn wọn padà.
Àwọn ìwé-mímọ́ kún wọn pẹ̀lú ayọ̀ bí wọ́n ti gba ìmísí, ìdarí, ìtùnú, okun, àti àwọn ìdáhùn sí àwọn àìní wọn. Púpọ̀ nínú wọn pinnu láti ṣe àwọn àyípadà nínú ìgbésí ayé wọn wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́.
Néfì gbà wá níyànjú láti ní inú dídùn nínú àwọn ọ̀rọ̀ Krístì, nítorí àwọn ọ̀rọ̀ Krístì yíò sọ gbogbo ohun tí a ní láti ṣe fún wa (wo 2 Néfì 32:3).
Mo pè yín láti ní ètò tí ó wà pẹ́ títí láti ṣe àṣàrò àwọn ìwé mímọ́. Wá, Tẹ̀lẹ̀ Mi jẹ́ ohun èlò nlá tí a ní fún ìkọ́ni àti kíkọ́ ẹ̀kọ́ iihìnrere, ó nmú ìyípadà wa sí Jésù Krìstì jìnlẹ̀ síi, ó sì nrànwálọ́wọ́ láti dàbí Rẹ. Nígbàtí a bá ṣe àṣàrò ihinrere, kìí ṣe pé a nlépa ìwífúnni titun nìkan; dipo bẹ́ẹ̀, à nwá láti di “ẹ̀dá titun” (2 Kọ́rínti 5:17).
Ẹ̀mí Mímọ́ náà nṣe amọ̀nà wa sí ìhà òtítọ́ ó sì njẹ́rí sí wa nípa òtítọ́ náà(wo Jọ̀hánnù 16:13). Ó ntan ìmọ́lẹ̀ sí ọ́kàn wa ó sì nsọ òye wa dọ̀tun, ó sì nfọwọ́kan ọkàn wa nípasẹ̀ ìfihàn Ọlọ́run, orísun gbogbo òtítọ́. Ẹ̀mí Mímọ́ nsọ ọkàn wa di mímọ́. Ó nfún wa ní ìmísí láti gbé ní ìbámú sí òtítọ́ ó sì nsọ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ fún wa àwọn ọ̀nà láti ṣe bẹ́ẹ̀. “Ẹ̀mí Mímọ́ … yíò kọ́ yín ní ohun gbogbo” (Jòhánnù 14:26).
Ní sísọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀rọ̀ tí Ó fi hàn fún Wòlíì Joseph Smith, Olùgbàlà wa sọ pé:
“Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí kìí ṣe láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tàbí láti ọ̀dọ̀ ẹnìkan; ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ mi; …
“Nítorí ohùn ti èmi ni èyítí ó sọ wọ́n jáde fún yín; nítorí a fi wọ́n fúnní nípa Ẹmí mi síi yín … ;
“Nítorínáà, ẹ̀yin lè jẹ̀ ẹ̀ri pé ẹ ti gbọ́ ohùn mi, ẹ̀yin sì mọ àwọn ọ̀rọ̀ mi” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 18:34–36).
A níláti wá àjọṣepọ̀ ti Ẹ́mí Mímọ́. Ifojúsùn yi níláti ṣe àkóso àwọn ìpinnu wa kí ó sì ṣe ìtọ́ni àwọn èrò àti ìṣe wa. A gbọ́dọ̀ wá ohun gbogbo tí ó npe ipá ti Ẹ̀mí àti kí ó kọ́ ohunkohun sílẹ̀ tí ó yapa kúrò nínú ipá yi .
Mo jẹ́ri pé Jésù Krístì ni àyànfẹ́ Ọmọ Bàbá wa Ọ̀run. Mo nífẹ Olùgbàlà mi. Mo dúpẹ́ fún àwọn ìwé mímọ́ Rẹ̀ àti fún àwọn wòlíì alààyè Rẹ̀. Ààrẹ Nelson ni wòlíì Rẹ̀. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.