Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Dídojúkọ Ẹ̀fufù-líle Ti-ẹ̀mí Wa Nípa Gbígbàgbọ́ nínú Krístì
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa (Ọ̀wàwà) 2021


9:49

Dídojúkọ Ẹ̀fufù-líle Ti-ẹ̀mí Wa Nípa Gbígbàgbọ́ nínú Krístì

À ndojúkọ àwọn ẹ̀fúfù-líle ti-ẹ̀mí wa dídárajùlọ nípa gbígbàgbọ́ nínú Krístì àti pípa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́.

Fún ọdún mẹ́fà tó kọjá, ẹnibí-ọkàn mi, Ann, àti èmi gbé ní Texas nítòsí Gulf Coast, níbi tí àwọn ẹ̀fúfù-líle ti jà ní United States, ní fífi ìparun títóbí sẹ́hìn àní àti ìpàdánù ẹ̀mí. Bíbani-nínújẹ́ gidi, àwọn oṣù àìpẹ́ kò jẹ́ àjèjì sí irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìparun. A nawọ́ ìfẹ́ àti àdúrà wa sí gbogbo ẹni tí ó ti ní ìpalára ní ọ̀nà yí. Ní 2017 a ní ìrírì Èfúfù-líle Harvey fúnra wa, èyí tí ó já àkọsílẹ̀ ìrọ̀jò wálẹ̀ dí bíi ọgọ́ta ínṣì (150 cm).

Àwọn òfin àdánidá nṣàkóso dídá àwọn èfúfù-líle. Lílọ́ òkun gbọ́dọ̀ jẹ́ ipele ọgọ́rin Fárẹ́ntì (27 degrees C), nínajáde dé ìṣísẹ̀ marunlelọ́gọ́fà (50 m) nísàlẹ̀ ojú òkun. Bí afẹ́fẹ́ ṣe npàdé omi lílọ́ òkun, ó nfa kí omi rú kí ó sì lọsókè sí àyíká, níbití ó ti nṣàlọ. Ìkukù ndì nígbànáà, àwọn afẹ́fẹ́ sì nmú àwòrán yíyí wá sórí ojú òkun.

Ìjì-líle

Èfúfù-líle jẹ́ títóbi ní ìwọ̀n, dídé ẹgbẹ̀run-àádọ́ta ìṣísẹ̀ (15,240 m) tàbí púpọ̀ sínú àyíká tí ó sì kọ́já máìlì marunlelọgọfa ó kéré jù (200 km) ní ìbú. Pẹ̀lú ìwuni, bí ẹ̀fúfù-líle ṣe dé ilẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ láti di àìlera nítorí wọn kò sí ní orí omi lílọ́ tí wọ́n nílò láti tún okun wọn ṣe mọ́.2

Ẹ lè má dojúkọ bíbàjẹ́ èfúfù-líle ti-ara kan. Bákannáà, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ti kojú a ó sì kojú àwọn ẹ̀fúfù-líle tí ó nba àláfíà wa lẹ́rù tí ó sì ndán ìgbàgbọ́ wa wò. Ní ayé òde-òní, wọ́n dàbí ẹnipé ó npọ̀si ní yíyára àti títóbi. Pẹ̀lú ọpẹ́, Olúwa ti pèsè ọ̀nà tó dájú fún wa láti fi tayọ̀-tayọ̀ borí wọn. Nípa gbígbé ìhìnrere Jésù Krístì, a ní ìdánilójú pé “nígbàtí ìkukù dúdú ti wàhálà bá kọ́wa lọ́rùn tí ó sì nba àláfíà wa lẹ́rù láti parun, ìrètí wà tí ó nrẹrin ìmọ́lẹ̀ níwájú wa.”3

Alàgbà Russell M. Nelson ṣàlàyé:

“Àwọn Ènìyàn Mímọ́ lè ní ìnúdídùn lábẹ́ onírurú ipò. A lè nímọ̀lára ayọ̀ àní nígbàtí a bá nní ọjọ́ burúkú kan, ọ̀sẹ̀ burúkú kan, tàbí ọdún burúkú kan!

“… Ayọ̀ tí à nní ìmọ̀lára rẹ̀ ní díẹ̀ íṣe pẹ̀lú àwọn ipò ti ìgbé-ayé wa àti ohungbogbo nííṣe pẹ̀lú ìdojúkọ àwọn ìgbé ayé wa.

“Nígbàtí ìdojúkọ ti ìgbé-ayé wa bá wà lórí … Jésù Krístì àti ìhìnrere Rẹ, a lè ní ayọ̀ láìkà ohun tó nṣẹlẹ̀ sí—tàbí tí kò ṣẹlẹ̀—nínú ìgbé-ayé wa.”4

Gẹ́gẹ́ bí àwọn òfin ádánidá ti nṣàkóso àwọn ẹ̀fúfù-líle ti-ara, àwọn òfin tọ̀run nṣàkóso bí a ó ti nímọ̀lára ayọ̀ nìgbà àwọn ẹ̀fufù-líle ti-ẹ̀mí wa. Ayọ̀ tàbí ìbànújẹ́ tí a nímọ̀lára bí a ti nfi ìgboyà kojú àwọn ìjì ayé ni ó rọ̀mọ́ àwọn òfin tí Ọlọ́run ti gbékalẹ̀. Ààrẹ Nelson ti ṣe àbápín, “A pè wọ́n ní àwọn òfin, ṣùgbọ́n wọ́n kàn jẹ́ bí òtítọ́ bí òfin ìgbéga, òfin ìwálẹ̀, [àti pé] òfin náà tí ó nṣàkóso ímí-ọkàn.”

Ààrẹ Nelson tẹ̀síwájú pé, “Bóyá ó ti di àmì-ẹ̀là ìrọ̀rùn: Bí ẹ bá fẹ́ láti ní ìdùnnú, ẹ pa àwọn òfin mọ́.”5

Iyèméjì jẹ́ ọ̀tá fún ìgbàgbọ́ àti ayọ̀. Gẹ́gẹ́ bíi lílọ́ omi òkun ni ìbísí ilẹ̀ fún ẹ̀fúfù-líle, iyèméjì ni ìbísí ilẹ̀ fún àwọn ẹ̀fúfù-líle ti-ẹ̀mí. Gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ ti jẹ́ àṣàyàn kan, bẹ́ẹ̀náà nì iyèméjì. Nígbàtí a bá yan iyèméjì, a yàn láti gba ṣíṣe ìṣe lé lórí, agbára jíjuwọ́lẹ̀ fún ọ̀tá, ní fífi wa sílẹ̀ nínú àìlera àti pípalára bẹ́ẹ̀.6

Sátánì nwá láti darí wa lọ sí ìbísí ilẹ̀ ti iyèméjì. Ó nwá láti sé àwọn ọkàn wa le kí a má ba gbàgbọ́.7 Ìbísí ilẹ̀ iyèméjì lè farahàn ní wíwuni nítorí ó dábí ó ní àláfíà, omi lílọ kò nílò kí a gbé “nípa gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó wá láti ẹnu Ọlọ́run.”8 Ní irú omi bẹ́ẹ̀ Sátánì ndán wa wò láti baralẹ̀ ní ìfojúṣọ́rí ti-ẹ̀mí wa. Àìkíyèsí náà lè fa àìní ẹ̀rí ti-ẹ̀mí, níbití ti “kò sí bóyá tútù tàbí gbígbóná.”9 Bí a kò bá rọ̀mọ́ Krístì, iyèméjì àti àwọn ìfanimọ́ra rẹ̀ yíò darí wa kúrò sí ìtara níbití a kò ti ní rí bóyá iṣẹ́-ìyanu, ìdùnnú pípẹ́, tàbí “ìsimi fún ọkàn [wa].”10

Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀fúfù-líle ṣe ndi àláìlera lórí ilẹ̀, ìgbàgbọ́ nrọ́pò iyèméjì bí a ti ngbé ìpilẹ̀ wa lórí Krístì. Nígbànáà a lè rí àwọn ẹ̀fúfù-líle ti-ẹ̀mí nínú ìwò dídára wọn, àti pé okun wa láti borí wọn ó gbòòrò si. Nígbànáà, “ìgbàtí èṣù bá fẹ́ ẹ̀fúfù-líle rẹ̀ wá, bẹ́ẹ̀ni, àwọn ọ̀pá rẹ̀ nínú ìjì, bẹ́ẹ̀ni, nígbàtí gbogbo àwọn òkútà yìnyín rẹ̀ àti ìjì-líle bá rọ̀ lé [wa] lórí, kò lè ní agbára … láti fà [wá] sínú ọ̀gbun òṣì àti ègbé àìlópin, nítorí àpáta èyítí a kọ́ [wa] lé lórí, èyítí íṣe ìpìlẹ̀ tó dájú.”11

Ààrẹ Nelson ti kọ́ni:

“Ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì ni ìpìlẹ̀ gbogbo ìgbàgbọ́ àti ọ̀nà sí agbára tọ̀run. …

“Olúwa kò bèère fún ìgbàgbọ́ pípé fún wa láti ní àyè sí agbára pípé Rẹ̀. Ṣùgbọ́n Ó ní kí a gbàgbọ́.”12

Látìgbà ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin, ẹbí mi àti èmi ti nwá láti fún ìgbàgbọ́ wa nínú Jésù Krísti àti Ètùtù Rẹ̀ lókun láti ràn wá lọ́wọ́ “láti yí àwọn ìpènijà [wa] padà sínú ìdàgbà àti ànfàní tí kò láfiwé.”13

Ọmọ-ọmọ wa obìnrin, Ruby, ní a ti bùkún pẹ̀lú okun, agbára láti wàní àkóso. Nígbàtí wọ́n bi, ọ̀nà-ọ̀fun rẹ̀ kò lẹ̀ mọ́ ìkùn rẹ̀. Àní bí ọmọ-ọwọ́, Ruby, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn òbí rẹ̀, bá àdánwò mu pẹ̀lú ìpinnu àìwọpọ̀. Ruby ti pé ọmọ ọdún marun nisisìyí. Bíotilẹ̀jẹ́pé ó ṣì keré gan, ó jẹ́ àpẹrẹ alágbára tí kò jẹ́kí àwọn ipò rẹ̀ pinnu ìdùnnú rẹ̀. Inú rẹ̀ ndùn nígbàgbogbo.

Ní Oṣù karun tó kọjá, Ruby dojúkọ àfikún ẹ̀fúfù-líle kan nínú ayé rẹ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́. Bákannáà a bi pẹ̀lú ọwọ́ tí kò gbèrú tán tí ó nílò àtúnṣe iṣẹ́-abẹ. Ṣíwájú sí iṣẹ́-abẹ líle yí, a ṣebẹ̀wò pẹ̀lú rẹ̀ a sì fun ni ìyàwòrán kan tí ó fi ẹwà ọwọ́ ọmọdé tí ó fi ìyárí di ọwọ́ Olùgbàlà mú hàn. Nígbàtí a bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ bí ó bá ngbọ̀n, láìsí àníní, ó fèsì, “Rárá, inú mi ndùn!”

Ruby pẹ̀lú kíkun ọwọ́ Olùgbàlà

Nígbànáà a bií léèrè, “Ruby, báwo ni ìyẹn ṣe rí bẹ́ẹ̀”

Ruby fi ìgboyà tunsọ, “Nítorí mo mọ̀ pé Jésù yíò di ọwọ́ mi mú.”

Ìmúlárada Ruby ti jẹ́ iṣẹ́-ìyanu, òun sì ntẹ̀síwájú láti ní inú dídùn. Bí ìgbàgbọ́ mímọ́ ọmọdé kan ti lòdì sí píponú iyèméjì tí ó lè dán wa wò bí a ṣe ndàgbà si!14 Ṣùgbọ́n gbogbo wa lè dàbí ọmọdé kí a yàn láti gbé àìgbàgbọ́ wa sẹgbẹ́. Ó jẹ́ àṣàyàn ìrọ̀rùn kan.

Baba olùṣìkẹ́ kan fi taratara bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú Olùgbàlà, wípé, “Bí ìwọ bá lè ṣe ohunkóhun, … ràn wá lọ́wọ́.”15

Nígbànáà Jésù wí fún un;

“Bí ìwọ bá gbàgbọ́, ohun gbogbo ni ṣíṣe fún ẹnití ó bá gbàgbọ́.

“Lẹ́sẹ́kannáà baba … kígbe, ó sí wí pẹ̀lú omijé pé, Olúwa, mo gbàgbọ́; ran àìgbàgbọ́ mi lọ́wọ́.”16

Baba onírẹ̀lẹ̀ yí fi ọgbọ́n yàn láti gbẹ́kẹ̀lé ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú Krístì ju iyèméjì rẹ̀. Ààrẹ Nelson ṣe àbápín pé, “Àìgbàgbọ́ yín nìkan ni yíò pa Ọlọ́run mọ́ ní bíbùkún yín pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ ìyanu láti ṣí òkè inú ayé yín nidi.10

Bí Ọlọ́run ti jẹ́ aláàánú láti fi ìbú-igi fún wa ní ipele gbígbàgbọ́ kìí sì ṣe ní ipele mímọ̀!

Álmà kọ́ni:

“Alábùkúnfún ni ẹni náà tí ó gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbọ́.”18

“[Nítorí] aláàánú ni Ọlọ́run sí gbogbo ẹnití ó bá gbàgbọ́ nínú orúkọ rẹ̀; nítorínáà ó fẹ́ kí ẹ gbàgbọ́, níbi àkọ́kọ́.”19

Bẹ́ẹ̀ni, níbi àkọ́kọ́, Ọlọ́run fẹ́ kí a gbàgbọ́ nínú Òun.

À ndojúkọ àwọn ẹ̀fúfù-líle ti-ẹ̀mí wa dídárajùlọ nípa gbígbàgbọ́ nínú Krístì àti pípa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́. Ìgbàgbọ́ àti ìgbọràn so wá pọ̀ mọ́ agbára tí ó kọjá tiwa láti borí “[ohunkóhun] tí ó nṣẹlẹ̀—tàbí tí kò ṣẹlẹ̀—nínú ayé wa.”20 Bẹ́ẹ̀ni, Ọlọ́run “nbùkún [wa] lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀” fún gbígbàgbọ́ àti gbígbọ́ran.21 Lotitọ, ní ìgbà pípẹ́ ipò wa ní jíjẹ́ ìyípadà sí ìdùnnú, tí a sì “mú wa wà láàyè nínú Krístì” bí a ti nlo ìgbàgbọ́ wa nínú Rẹ̀ tí a sì npa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́.22

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, njẹ́ kí a yàn ní òní láti “máṣe ṣiyèméjì, ṣùgbọ́n kí a gbàgbọ́.”23 “Ọ̀nà tó tọ́ ni láti gbàgbọ́ nínú Krístì.”25 A jẹ́ “fínfín … lórí àtẹ́lẹwọ́ ọwọ́ [Rẹ̀].”26 Òun ni Olùgbàlà àti Olùràpadà ẹnití ó dúró ní ẹnu ọ̀nà gan tí ó nkan ìlẹ̀kùn.27 Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.