Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa (Ọ̀wàwà) 2021 Abala Òwúrọ̀ Sátidé Abala Òwúrọ̀ Sátidé Russell M. NelsonÒtitọ́ Mímọ́, Ẹkọ́ Mímọ́, àti Ìfihàn Mímọ́Ààrẹ Nelson kí àwọn ènìyàn káàbọ̀ sí ìpàdé àpapọ̀ ó sì pè wọ́n láti fetísílẹ̀ fún òtítọ́ mímọ́, ẹ̀kọ́ ti Krístì mímọ́, àti ìfihàn mímọ́. Jeffrey R. HollandOhun Ìní Títóbi JùlọAlàgbà Holland kọ́wa láti ní ìfẹ́ Ọlọ́run kí a sì tẹ̀lé E pátápatá. Bonnie H. CordonẸ Wá sọ́dọ̀ Krístì Ẹ Má sì Nìkan DáwáArábìnrin Cordon kọ́ni pé a jẹ́ àwọn ọmọ Ọlọ́run àti pé èrèdí ayérayé wa ni láti mú àwọn míràn wá sọ́dọ̀ Krístì. Ulisses SoaresÀánú Ìbánigbé OlùgbàlàAlàgbà Soares kọ́ wa pé a níláti tẹ̀lé àpẹrẹ Olùgbàlà ti àánú fún àwọn ẹlòmíràn nípa dídi ìdájọ́ mú kí a sì ní sùúrù D. Todd ChristoffersonÌfẹ́ ti Ọlọ́runAlàgbà Christofferson kọ́ni pé àwọn òfin nrọ́pò ìfẹ́ Ọlọ́run fún wa ó sì nfàmì sí ipa-ọ̀nà wíwòsàn, dídunnú, àláfíà, àti ayọ̀. Clark G. GilbertDidi Ọ̀kan nínú Krístì: Òwe Ibi Gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́.Alàgbà Gilbert kọ́ni pé láìka àwọn ipò wa sí, Olúwa le rànwá lọ́wọ́ lati dé ibi gíga jùlọ ti agbára wa. Patricio M. GiuffraÌwádìí Tòótọ́ Kan Gba ÈrèAlàgbà Giuffra pè wá láti gbádùn àwọn ìbùkún tí ó nwá látinú níní ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì. Dallin H. OaksÌnílò fún Ìjọ kanÀàrẹ Oaks kọ́ni ní àwọn ìbùkún ti jíjẹ́ ti Ìjọ Jésù Krístì. Abala Ọ̀sán Sátidé Abala Ọ̀sán Sátidé Henry B. Eyring Ìmúdúró àwọn Aláṣẹ Gbogbogbò, Àádọ́rin Agbègbè, àti Olóyè GbogbogbòÀàrẹ Eyring ṣè àgbékalẹ̀ àwọn Aláṣẹ Gbogbogbò, Àádọ́rin Agbègbè, àti Olóyè Gbogbogbò fún ìbò ìmúdúró. David A. BednarPẹ̀lú Agbára Ọlọ́run nínú Ògo NláAlàgbà Bednar kọ́ni pé bíbu-ọlá fún àwọn májẹ̀mú wa nrànwálọ́wọ́ láti gba agbára ìwà-mímọ́ nínú ayé wa. Ciro SchmeilÌgbàgbọ́ láti Ṣiṣẹ́ àti láti DàAlàgbà Schmeil kọ́ni pé a lè di ọmọẹ̀hìn dídárasi ti Jésù Krístì bi a ti nbèèrè, tí a sìn nṣàṣàrò. Susan H. PorterÌfẹ́ Ọlọ́run: Ayọ̀ Púpọ̀ Jùlọ sí ỌkànArábìnrin Porter kọ́ni pé Baba Ọrun àti Jésù Krístì ní ìfẹ́ àìlábáwọ́n fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wa àti pé pípín ìfẹ́ Wọn le bùkún wa. Erich W. KopischkeÌsọ̀rọ̀ Nípa Ilera ỌpọlọAlàgbà Kopischke pín àwọn àkíyèsí díẹ̀ nípa àrùn ọpọlọ, tí ó dálé àwọn ìdánwò tí ẹbí rẹ̀ ti là kọjá. Ronald A. RasbandÀwọn Ohun Ẹ̀mí MiAlàgbà Rasband pín ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ iyebíye “àwọn ohun ẹmí rẹ̀” méje—ti ó nfi èrò fún ìgbé-ayé bí ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì fúnni. Christoffel GoldenMímúrasílẹ̀ fún Ìpadàbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì ti KrístìAlàgbà Golden kọ́ni pé a nsúnmọ́ Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì náà, ọjọ́ ọ̀fọ̀ fún àwọn ẹni búburú, ṣùgbọ́n ọjọ́ àlàáfíà fún àwọn olódodo. Moisés VillanuevaRírí Ojúrere Olúwa ní Gbogbo Àwọn Ọjọ́ MiAlàgbà Villanueva lo àwọn àpẹrẹ Olùgbàlà, Néfì, àti ọ̀dọ́mọdékùnrin òjíṣẹ́-ìránṣẹ́ kan láti fihàn bí a ṣe lè kojú ìpọ́njú pẹ̀lú ayọ̀ àti àánú. Gary E. StevensonPẹ̀lú Ìrọ̀rùn Ẹwà—Pẹ̀lú Ẹwà Ìrọ̀rùnAlàgbà Stevenson lo àwọn ìtàn mẹrin látọ̀dọ̀ àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn láti júwe àwọn ọ̀nà tí a lè fi mú àwọn ojúṣe yíyàn àtọ̀runwá wa ṣẹ. Abala Ìrọ̀lẹ́ Sátidé Abala Ìrọ̀lẹ́ Sátidé M. Russell Ballard“Ìwọ Ha Fẹ́ Mi Ju Àwọn Wọ̀nyí Lọ Bí?”Ààrẹ Ballard kọ́wa bí a ṣe le fi hàn pé a fẹ́ràn Olùgbàlà tayọ gbogbo àwọn ohun tí ayé nípa gbígbàgbọ́ nínú Rẹ̀, sísìn Ín, àti sísin àwọn ẹlòmíràn. Sharon EubankMo Gbàdúrà pé Yíò Lò WáArábìnrin Eubank ròhìn lórí awọn ìgbìyànjú arannilọ́wọ́ àìpẹ́ Ìjọ. Brent H. NielsonKò ha sí ìkunra ní Gíléádì?Alàgbà Nielson kọ́ni pé Olùgbàlà ní agbára láti wo ọkàn wa sàn àti láti mú wa dúró nípasẹ̀ àwọn ìṣòro wa bákannáà láti wo ara wa sàn. Arnulfo ValenzuelaMímú Ìyípadà Wa sí Jésù Krístì Jinlẹ̀ SíiAlàgbà Valenzuela kọ́ni pé a lè mú ìyípadà-ọkàn wa jinlẹ̀ bí a ti nṣe àṣàrò àwọn ìwé-mímọ́ kí a sì kọ́ nípa Jésù Krístì síi. Bradley R. WilcoxKíkàyẹ Kìí Ṣe ÀìlábùkùArákùnrin Wilcox kọ́ni pé a kò nílò láti jẹ́ pípé láti ní oore-ọ̀fẹ́ àti agbára ètùtù Jésù Krístì nínú ayé wa. Alfred KyunguLáti Jẹ́ Ọmọlẹ̀hìn Jésù Krístì Alàgbà Kyungu kọ́ni nípa àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ mẹ́rin tí ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti di ọmọ-ẹ̀hìn Jésù Krístì tí ó dára jùlọ. Marcus B. NashẸ Di Ìmọ́lẹ̀ Yín Mú SókèAlàgbà Nash kọ́ wa láti pín ìhìnrere ní àwọn ọ̀nà déédé àti àdánidá kí àwa àti àwọn wọnni tí à npín pẹ̀lú lè ní ayọ̀ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìbùkún míràn. Henry B. EyringÌgbàgbọ́ láti Bèèrè àti Nígbànáà kí a Ṣe ÌṣeÀàrẹ Eyring kọ́ni pé a lè gba ìfihàn bí a ti nlo ìgbàgbọ́ tí a sì nfẹ́ láti ṣe ìṣe. Abala Àárọ̀ Ọjọ́ Ìsinmi Abala Àárọ̀ Ọjọ́ Ìsinmi Dieter F. UchtdorfÌmúpadàbọ̀sípò Ojojúmọ́Alàgbà Uchtdorf kọ́ni pé gbogbo wa ndárí kúrò níti-ẹ̀mí nígbàmíràn ṣùgbọ́n pé a lè padà sì ọ̀nà nípa títẹ̀lé àwọn ìlànà tí Ọlọ́run ti pèsè. Camille N. JohnsonẸ Pe Krístì láti jẹ́ Olùpilẹ̀sẹ̀ Ìtàn YínArábìnrin Johnson kọ́ wa bí a ṣe lè jẹ́ kí Olùgbàlà jẹ́ olùpilẹ̀ṣẹ̀ àti aláṣetán ti ìtàn araẹni wa nípa níní ìgbàgbọ́ si àti jíjẹ́ kí Ọlọ́run borí nínú ìgbé-ayé wa. Dale G. RenlundÀlàáfíà ti Krístì Mú Ìṣọ̀tá KúròAlàgbà Relund kọ́ni pé nípa fífi ìfẹ́ Ọlọ́run àti jíjẹ́ ọmọẹ̀hìn ti Jésù Krístì wa ṣíwájú, a lè borí àwọn ìyàtọ̀ wa kí a sì ní àláfíà. Vaiangina SikahemaIlé Elétò ti Ṣísẹ̀ntẹ̀lé KanAlàgbà Sikahema kọ́ni ní àwọn ìbùkún tí ó lè wá nígbàtí a bá gbé ìgbé-ayé ìhìnrere tí a sì nṣe àwọn ohun ní ètò títọ́. Quentin L. CookAláfíà Araẹni ní àwọn Akókò ÌpènijàAlàgbà Cook pín àwọn ìkọ́ni Jésù Krístì tí ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti dín ìjà kù àti láti rí àláfíà nínú àwọn àkokò ìpènijà òní. Russell M. NelsonTẹ́mpìlì àti Ìpilẹ̀ṣẹ̀ Ti-ẹ̀mí YínÀàrẹ Nelson tọ́ka sí iṣẹ́ lórí ìpìlẹ̀ Tẹ́mpìlì Salt Lake láti kọ́ni bí àwọn ìlànà tẹ́mpìlì àti májẹ̀mú ti nfún ìpìlẹ̀ ti-ẹ̀mí wa lókun. Abala Ọ̀sán Ọjọ́ Ìsimi Abala Ọ̀sán Ọjọ́ Ìsimi Gerrit W. GongẸ Ní Ìgbẹ́kẹ̀lé Lẹ́ẹ̀kansíi.Alàgbà Gong kọ́ni pé ìgbẹ́kẹ̀lé jẹ́ ìṣe ìgbàgbọ́ àti pé bí a ti nní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run àti ara wa, a ngba àwọn ìbùkún tọ̀run. L. Todd BudgeFífi Ìwàmímọ́ fún OlúwaBíṣọ́ọ̀pù Budge ròhìn lorí ìgbìyànjú ìràniyànlọ́wọ́ Ìjọ ó sì kọ́ni pé àwọn ẹbọ wa nínú ìwọ̀nyí àti ìgbìyànjú míràn ni ẹ̀bùn yíyàsọ́tọ̀ sí Olúwa. Anthony D. PerkinsRántí Àwọn Ènìyàn-Mímọ́ Rẹ Tí Njìyà, Áà Ọlọ́run WaAlàgbà Perkins pín àwọn ẹ̀kọ́-ìpìlẹ̀ mẹ́rin láti ran àwọn tí wọ́n njìyà rírí ìrètí àti ayọ̀ nínú Jésù Krístì. Michael A. DunnÌdá Kan Dídára SíiAlàgbà Dunn kọ́ni pé ìgbìyànjú kọ̀ọ̀kan láti ronúpìwàdà, bí ó ti wù kí ó dàbí ó kéré tó, lè mú àwọn ìbùkún nlá wá. Sean DouglasDídojúkọ Ẹ̀fufù-líle Ti-ẹ̀mí Wa Nípa Gbígbàgbọ́ nínú KrístìAlàgbà Douglas kọ́ni pé a ndojúkọ ìpọ́njú dáradárajùlọ nípa níní ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì àti pípa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́. Carlos G. Revillo Jr.Àwọn Iṣẹ́ Ìyanu ti ìhìnrere Jésù Krístì.Alàgbà Revillo kọ́ni pé gbígbọ́ran sí àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ àti ìlànà ìhìnrere nbùkún wa ó sì nrànwálọ́wọ́ láti yípadà. Alvin F. Meredith IIIWò ìsàlẹ̀ Òpópónà náàAlàgbà Meredith lo ìtàn Pétérù tí ó nrìn lórí omi láti kọ́ni pé bí a bá dojúkọ Krístì tí a ní ìfura àwọn ìdààmú. A lè di gbígbàlà. Neil L. AndersenOrúkọ Ìjọ kò Gba Ìdúnádúrà.Alàgbà Andersen kọ́ni nípa pàtàkì lílo orúkọ ìfihàn ti Ìjọ. Russell M. NelsonẸ Fi Àkókò Sílẹ̀ fún OlúwaÀàrẹ Nelson kọ́ni nípa pàtàkì fífi àkókò sílẹ̀ fún Olúwa ní ojojúmọ́ ó sì kéde àwọn tẹ́mpìlì titun.