Didi Ọ̀kan nínú Krístì: Òwe Ibi Gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́.
Ní àkókò ti Olúwa, kìí ṣe ibití a ti bẹ̀rẹ̀, ṣùgbọ́n ibití à da orí kọ ni ó ṣe pàtàkì jùlọ.
Bíí ọmọdékùnrin kan, mo ní àwọn ìrètí nlá. Ni ọjọ́ kan lẹ́hìn ilé-ìwé mo bèèrè: “Màmá, kíni ó yẹ kí njẹ́ nígbàtí mo bá dàgbà: òṣèré bọ́ọ̀lù alágbọ̀n tàbí olókìkí rọ́ọ̀kì kan?” Láìlóríre, Clark “ìyanu aláìléyín” kò fi àwọn àmí ti eléré-ìje tàbí ògo ti-orin ọjọ́ iwájú hàn. Àti láìbìkítà fún àwọn akitiyan ọ̀pọ̀lọpọ̀, a kọ̀ mí léraléra ní gbígbà sí ètò ẹ̀kọ́ ìmúgbòrò ti ilé-ìwé mi. Àwọn olùkọ́ mi níkẹhìn dába pé kí nkàn dúró lórí ojúlówó yàrá ìkàwé. Bí àkókò ti nlọ, mo ṣe ìmúdàgbà àwọn ìwà ṣíṣe àṣàrò tó nmú èrè wa. Ṣùgbọ́n kìí ṣe títí ìgbà iṣẹ́-ìránṣẹ́ mi sí Japan ni mo ní ìmọ̀lára pé àwọn ọgbọ́n mi àti àwọn agbára ìleṣe ti ẹ̀mí bẹ̀rẹ̀sí farahàn. Mo tẹ̀síwájú làti ṣiṣẹ́ kára. Ṣùgbọ́n fún ìgbà àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé mi, mo finúfẹ́dọ̀ jẹ́kí Olúwa kópa nínú ìdàgbàsokè mi, ó sì mú gbogbo ìyàtọ̀ wá.
Ẹyin arákùnrin àti arábìnrin, nínú Ìjọ yi, a gbàgbọ́ nínú agbára tọ̀run gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run àti nínú okun wa láti di ohun kan síi nínú Kristi. Ní àkókò ti Olúwa, kìí ṣe ibití a ti bẹ̀rẹ̀, ṣùgbọ́n ibití à da orí kọ ni ó ṣe pàtàkì jùlọ.1
Láti júwe ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ yi, èmi yíò mú láti inú àwọn ìṣirò ìpìlẹ̀ díẹ̀. Báyi, ẹ máṣe bẹ̀rù ní gbígbọ́ ọ̀rọ̀ náà ìṣirò nínú ìpadé àpapọ̀ gbogbogbò. Ìmọ̀ wa ní ẹ̀ka ìṣirò ti BYU-Idaho fi dámi lójú pé alákọbẹ̀rẹ̀ paapaa yíò ní òye èrò àringbùngbùn yi. Ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ètò fún ìlà kan. Ibi ìkọlù, fún èrèdí tiwa, ni ìbẹ̀rẹ̀ ìlà wa. Ìdálọ́nà náà lè ní bóyá ibi ìbẹ̀rẹ̀ gíga tàbi kékeré. Ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ ti ìlà náà le jẹ́ dáadáa tàbí ìdàkejì ní ìtẹ̀sí lẹ́hìnnáà.
Gbogbo wa la ní àwọn ìkóríta ní ìgbésí ayé—a bẹ̀rẹ̀ ní àwọn ibi yíyàtọ̀ pẹ̀lú àwọn tálẹ́ntì àti àwọn ẹ̀bùn ìgbésí ayé yíyàtọ̀. A bí àwọn kan pẹ̀lú àwọn ìkóríta gíga, tí ó kún fún ànfààní. Àwọn miran dojúkọ àwọn ipò bíbẹ̀rẹ̀ tí ó nira àti tí ó dàbí ẹnipé kò dára.2 Lẹ́hìnnáà à nni ìlọsíwájú pẹ̀lú gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ ti ìlọsíwájú araẹni. Ọjọ́ iwájú wa yíò jẹ́ pípinnu kíkéré díẹ̀ nípa ibi tí a ti bẹ̀rẹ̀ àti púpọ̀jù síi nipasẹ̀ gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ wa. Jésù Krísti rí agbára tọrun níbikíbi yówù kí a ti bẹ̀rẹ̀. Ó rí nínú alágbe, ẹlẹ́ṣẹ, àti aláìlera. Ó rí nínú apẹja, agbowó orí, àti pàápàá onítara. Ibi yówù kí a ti bẹ̀rẹ̀, Krísti yẹ ohun ti a ṣe sí pẹlu ohun ti a fifun wa.3 Nígbàtí àgbáyé fojúsùn sí orí ìkóríta wa, Ọlọ́run fojúsùn sí gẹ̀rẹ́gẹ́rẹ́ wa. Nínú ìṣirò Olúwa, Òun yíò ṣe ohun gbogbo tí O lè ṣe làti rànwá lọ́wọ láti yí àwọn gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ wa sí ìhà ọ̀run.
Ìlànà yí yẹ kí ó fi ìtùnù fún àwọn tó ntiraka àti ìdádúró fún àwọn tí ó dàbí ẹnipé wọ́n ní gbogbo ànfàní. Ẹ jẹ́kí nbẹ̀rẹ̀ nípa bíbá àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan tí wọ́n ní àwọn ipò ìbẹ̀rẹ̀ tí ó nira sọ̀rọ̀, nínú èyí tí ìṣẹ́, ọ̀nà sí ètò ẹ̀kọ́, àwọn ipò ìpèníjà ti ẹbí wà. Àwọn míràn dojúkọ àwọn ìpèníjà ti ara, àwọn ìdíwọ́ ìlera ọpọlọ, tàbí àjogúnbá ìṣaájú líle.4 Fún ẹnikẹ́ni tó nlàkàkàì pẹ̀lú àwọn ààyè ìbẹ̀rẹ̀ nínira, jọ̀wọ́ mọ̀ pé Olùgbàlà mọ àwọn ìjàkadì rẹ. Òun “[gbé] gbogbo àìlera [wa] lé ara rẹ̀, kí inú rẹ̀ [lè] kún fún ãnú, … kí òun kí ó [lè] mọ̀ … bí òun yíò ṣe ran [wa] lọ́wọ́ nínú gbogbo àìlera [wa].”5
Jẹ́ kí npín àwọn ibi ìyànjú méjì fún àwọn tó nkọjú àwọn ipò ìbẹ̀rẹ̀ nínira. Ní àkọ́kọ́, dojúkọ ibi tí ò nlọ àti kìí ṣe ibití o ti bẹ̀rẹ̀. Yíò jẹ́ àṣìṣe láti fojú ṣá àwọn ipò rẹ tì—wọ́n dáju wọ́n sì nílò yíyẹ̀wo. Ṣùgbọ́n ìdojúkọ púpọ̀jù lórí àmì ìbẹ̀rẹ̀ nínira lè mú kí o ṣàlàyé rẹ̀ àti paapaa kí ó ṣe ìdíwọ́ agbára òmìnira láti yàn rẹ.6
Ní àwọn ọdún sẹ́yìn, mo sìn pẹ̀lú ẹgbẹ́ kan tí àwọn ọ̀dọ́ inú ìlú ní Boston, Massachusetts, tí púpọ̀ nínú wọn jẹ́ tuntun sí ìhìnrere àti sí àwọn ìrètí ti Ìjọ. Ó jẹ́ ìdánwò láti rú àánu àti ìbákẹ́dùn mi fún ipò wọn pọ̀ pẹ̀lú ìfẹ́ inú láti dín àwọn odiwọ̀n ti Ọlọ́run kù.7 Ní ìgbẹ̀hìn mo rí pé ọ̀nà tí ó lágbára jùlọ láti ṣe àfihàn ìfẹ́ mi ni láti máṣe dín àwọn ìrètí mi kù láéláé. Pẹ̀lú ohungbogbo tí mo mọ̀ láti ṣe, a dojúkọ agbára wọn papọ̀, àti pé ọ̀kọ̀ọkan wọn bẹ̀rẹ̀ sí gbé àwọn gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ wọn ga. Ìdàgbà wọn nínú ìhìnrere jẹ́ díẹ̀díẹ̀ ṣùgbọ́n dídúróṣinṣin. Lóni wọ́n ti sìn ní àwọn míṣọ̀n, parí ilé-ẹ̀kọ́ kọ́lẹ̀jì, ti ṣe ìgbéyàwó nínú tẹ́mpìlì, àti pè wọ́n nṣe ìdarí àwọn ìgbésí ayé tó lápẹrẹ ti ara ẹni àti àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n.
Ẹ̀ẹ̀kejì, fi Olúwa sínú ìlànà ti gbígbé ìtẹ̀ rẹ̀ sókè. Lákoko sísìn bíi alága ti BYU–Pathway Káríayé, mo rántí jíjóko nínú ìfọkànsìn nlá kan ní Límà, Perú, níbití Alàgbà Carlos A. Godoy ti jẹ́ olùsọ̀rọ̀. Bí ó ti wo ìta lórí ìjọ náà, ó dàbí ẹni pé ó ìbòmọ́lẹ̀ ní rírí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn onígbàgbọ́ ìran-àkọ́kọ́ àwọn ọmọ ilé-ìwé gíga unifásítì. Bóyá ní ríronú lórí ipa ọ̀nà tirẹ̀ láti la irú àwọn ipò bẹ́ẹ̀ kọjá, Alàgbà Godoy sọ pẹ̀lú ẹ̀dùn-ọkàn pé: Olúwa yíò “ràn ọ́ lọ́wọ́ ju bí o ti lè ran ara rẹ lọ́wọ́ lọ. [Nítorínáà] fi Olúwa sínú ìlànà yi. ”8 Wòlíì Néfi kọ́ni “pé nípa õre-ọ̀fẹ́ ni a gbà wá là, lẹ́hìn gbogbo ohun tí a lè ṣe.9 A gbọ́dọ̀ ṣe dídárajùlọ tiwa,10 èyí tí ó pẹ̀lú ìrònúpìwàdà, ṣùgbọ́n ó jẹ́ nípasẹ̀ õre-ọ̀fẹ́ Rẹ̀ nìkan ni a lè mọ agbára wa ti ọ̀run.11
Ní ìparí, ẹ jẹ́ kí npín àwọn ibi ìmọ̀ràn méjì fún àwọn tí ó ní àwọn àmì ìbẹ̀rẹ̀ tí ó ga. Ní àkọ́kọ́, njẹ́ a lè ṣe àfihàn ìrẹ̀lẹ̀ díẹ̀ fún àwọn ipò tí a kò lè dásílẹ̀ fún arawa? Bí Ààrẹ BYU tẹ́lẹ̀rí Rex E. Lee ti ṣàtúnsọ fún àwọn akẹ́kọ́ rẹ̀, “Gbogbo wa ti mu láti inú kànga tí a kò wà a sì ti mú ara wa lọ́ nípasẹ̀ àwọn iná tí a kò dá.”12 Ààrẹ Lee lẹ́hìnnáà pe àwọn akẹ́kọ́ rẹ̀ láti fúnni padà àti láti tún àwọn kànga ètò-ẹ̀kọ́ ti àwọn aṣájú ti kọ́ ṣe. Ìkùnà láti ṣe àtúngbìn àwọn pápá tí a gbìn láti ọwọ́ àwọn míràn lè jẹ́ déédé pẹ̀lú ìdápadà tálẹ́ntì kan láìsí àlékún.
ÈKejì, dídojúkọ lórí ààyè ìbẹ̀rẹ̀ tí ó ga kan lè figbàgbogbo dẹ wá sínú níní ìmọ̀lára pé à nṣe rere, nígbàtí, gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ inú wa lè wà ní dídúró lotitọ. Ọ̀jọ̀gbọ́n Clayton M. Christensen ní Harvard kọ́ni pé àwọn ènìyàn tí wọ́n ṣàṣeyọrí jùlọ ni onírẹ̀lẹ̀ nítorí wọ́n ní ìgboyà tó láti ṣe àtúnṣe àti láti kọ́ ẹ̀kọ́ láti ọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni.12 Alàgbà D. Todd Christofferson gbà wá nímọ̀ràn láti “fi tinútinú [wá àwọn ọ̀nà] láti gbà àti láti wá àtúnṣe.”13 Paapaa nígbàtí àwọn nkàn bá hàn pé ó nlọ dáradára, a gbọ́dọ̀ wá àwọn ànfàní láti ní ìlọsíwájú nípasẹ̀ ẹ̀bẹ̀ àdúrà àti ìfẹ́ láti ronúpíwàdà.
Láìbìkítà bóyá a bẹ̀rẹ̀ nínú ọ̀pọ̀ tàbí àwọn ipò tí o nira, a ó dá agbára ìgbẹ̀hìn wa tí ó ga jùlọ mọ̀ nígbàtí a bá fi Ọlọ́run ṣe alábaṣepọ̀ wa nìkan. Láìpẹ́ mo ní ìbárasọ̀rọ̀ pẹ̀lú olùkọ́ni olókìkí ti orílẹ̀-èdè kan tí ó nbèèrè nípa àṣeyọrí àwọn akẹkọ BYU-Pathway. Ó jẹ́ dídán ìwádi rẹ̀ sì jẹ́ òtítọ́, ṣùgbọ́n ó hàn gbangba pé ó fẹ́ ìdáhùn tí ikẹkọ́. Mo pín àwọn ètò ìmúdúró àti àwọn ìgbìyànjú ìdámọ̀ràn wa pẹ̀lú rẹ̀. Ṣùgbọ́n Mo parí nípa sísọ pé, “Ìwọ̀nyí jẹ́ gbogbo àwọn ìṣe tí ó dára, àti pé a ní ìdùnnú láti pín èyíkéyi nínú wọn pẹ̀lú rẹ̀, ṣùgbọ́n ìdí gidi tí àwọn akẹkọ wa fi nlọsíwájú jẹ́ nítorí a nkọ́ wọn ní agbára tọ̀run wọn. Fi ojú inú wòó ni gbogbo ọjọ́ ayé rẹ, tí a bá nsọ fún ọ pé ìwọ kò le ṣe àṣeyọrí láéláé. Lẹ́hìnnáà ronú pé kí a kọ́ ọ pé ìwọ jẹ́ ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin ti Bàbá Ọ̀run pẹ̀lú ìleṣe tọ̀run?” Ó dúró díẹ̀, lẹ́hìnnáà ó dáhùn pé, “Ìyẹn lágbára.”
Ẹyin arakùnrin àti arábìrin, ọ̀kan nínú àwọn iṣẹ́ ìyanu èyí, Ìjọ Olúwa, ni pé olúkúlukú wa lè di ohun kan síi nínú Krístì. Èmi kò mọ ìṣètò míran tí ó fún àwọn ọmọ ìjọ rẹ̀ ní àwọn ànfàní síi láti ṣe ìránṣẹ́, fífún padà, ronúpíwàdà, àti di ènìyàn tí ó dára jùlọ. Bóyá a bẹ̀rẹ̀ ní àwọn ipò ti ẹ̀mí nínira tabi ọ̀pọ̀lọpọ̀, ẹ jẹ́kí a tọ́jú àwọn ojú wa àti àwọn gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ wa ní títọ́ka sí ọ̀run. Bí a ṣe nṣé bẹ́ẹ̀, Krístì yíò gbé wa lọ sí ibi gíga. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.