Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ẹ Ní Ìgbẹ́kẹ̀lé Lẹ́ẹ̀kansíi.
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa (Ọ̀wàwà) 2021


13:7

Ẹ Ní Ìgbẹ́kẹ̀lé Lẹ́ẹ̀kansíi.

Ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run àti ara wa nmú àwọn ìbùkún tọ̀run wá.

Nígbàkanrí, nígbàtí mo sì jẹ́ ọ̀dọ́ gan, mo yára ronú nípa sísálọ kúrò ní ilé. Ní ọ̀nà ti ọmọdékùnrin, mo ní ìmọ̀lára pé ẹnìkankan kò fẹ́ràn mi.

Ìyá mi tó ní àkíyèsí fi etí sílẹ̀ ó sì fúnmi ní ìdánilójú. Mo wà nílé láìléwu.

Njẹ́ ẹ ti ní ìmọ̀lára rí bí ẹnipé ẹ nsá kúrò nílé? Nígbàgbogbo, sísá kúrò nílé túmọ̀ sí pé ìgbẹ́kẹ̀lé ti ṣá tàbí bàjẹ́—ìgbẹ́kẹ̀lé pẹ̀lú ara wa, pẹ̀lú ẹlòmíràn, pẹ̀lú Ọlọ́run. Nígbàtí ìgbẹ́kẹ̀lé bá jẹ́ pípèníjà, a máa nro bí a ṣe le ní ìgbẹkẹ̀lé lẹ́ẹ̀kansíi.

Ọrọ̀ mi lóni ni pé, bóyá a nbọ̀ nílé tàbí nlọ sílé, Ọlọ́run nbọ̀ láti pàdé wa.1 Nínú Rẹ̀ a le rí ìgbàgbọ́ àti ìgboyà, ọgbọ́n àti ìfura, láti ní ìgbẹ́kẹ̀lé lẹ́ẹ̀kansíi. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Ó pè wá láti mú ìmọ́lẹ̀ náà dúró fún ara wa, láti jẹ́ olùdáríjì síi kí a sì dínkù ní síṣe ìdájọ́ ara wa àti ẹlòmíràn, kí Ìjọ Rẹ̀ ó le jẹ́ ibití a ó ti ní ìmọ̀lára wíwà nílé, bóyá a nbọ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́ tàbí a npadàbọ̀.

Níní ìgbẹ́kẹ̀lé jẹ́ ìṣe ti ìgbàgbọ́ Ọlọ́run pa ìgbàgbọ́ mọ́ pẹ̀lú wa. Síbẹ̀, ìgbẹ́kẹ̀lé ẹ̀dá ènìyàn le jẹ́ títẹ́nbẹ́lú tàbí bíbàjẹ́ nígbàtí:

  • Ọrẹ́ kan, olùbá-dòwòpọ̀, tàbí ẹnìkan tí a gbẹ́kẹ̀lé kò bá jẹ́ olõtọ́, ṣe ìpalára, tàbí lo ànfàní lórí wa.2

  • Ẹnìkejì kan nínú ìgbeyàwó kò jẹ́ olõtọ́.

  • Bóyá láìròtẹ́lẹ̀, ẹnìkan tí a fẹ́ràn ndojúkọ ikú, ìfarapa, tàbí àìsàn.

  • A dojúkọ ìbéèrè ìhìnrere kan tí a kò retí, bóyá ohun kan nípa ìtàn Ìjọ tàbí ìlànà Ìjọ, kí ẹnìkan sì sọ pé bákan-bàkan ìjọ wa fi pamọ́ tàbí wọn kò sọ òtítọ́.

Àwọn ipò míràn lé dínkù ní ṣíṣe pàtó ṣùgbọ́n pẹ̀lú àníyàn tí ó dọ́gba.

Bóyá a kò rí ara wa nínú Ìjọ, a kò ní ìmọ̀lára pé a yẹ, a ní ìmọ̀lára pé àwọn ẹlòmíràn ndáwa lẹ́jọ́.

Tàbí, bíótilẹ̀jẹ́pé a ti ṣe ohun gbogbo tí ó yẹ, àwọn nkan kò tíi dára síbẹ̀. Láì ka àwọn ìrírí ti ara-ẹni wa sí pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́, a le má ì tíì ní ìmọ̀lára pé a mọ̀ pé Ọlọ́run wà láàyè tàbí pé ìhìnrere jẹ́ òtítọ́.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ lóni ní ìmọ̀lára ìnílò gidigidi kan láti mú ìgbẹ́kẹ̀lé padàbọ̀sípò nínú àwọn àjọṣepọ̀ ẹ̀dá ènìyàn àti ní àwùjọ òde òní.3

Bí a ti nronú lóri ìgbẹ́kẹ̀lé, a nmọ̀ pé Ọlọ́run jẹ́ Ọlọ́run òtítọ́ “kò sì leè parọ́.”4 A mọ̀ pé òtítọ́ ni ìmọ àwọn nkan bí wọ́n ṣe wà, bí wọ́n ṣe ti wà rí, àti bí wọn yíó ṣe wá.”5 A mọ̀ pé títẹ̀síwájú ìfihàn àti ìmísí ṣe àmúyẹ òtítọ́ tí kìí yípadà sí àwọn ipò tí ó nyípadà.

A mọ̀ pé bíba àwọn májẹ̀mú jẹ́ nba ọkàn jẹ́. “Mo ṣe àwọn ohun agọ̀,” ni ó sọ. “Ṣe ó lè dáríjì mí láéláé?” Ọkọ àti aya le di àwọn ọwọ́ mú, pẹ̀lú ìrètí láti ní ìgbẹ́kẹ̀lé lẹ́ẹ̀kansíi. Nínú ètò kan tí ó yàtọ̀, ẹlẹ́wọ̀n kan ronú pé, “Kání mo ti pa Ọrọ̀ Ọgbọ́n mọ́ ni, èmi ìbá má wà níbí.”

A mọ ayọ̀ ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú ti Olúwa, àti pé àwọn ìpè láti sìn nínú Ìjọ Rẹ̀ jẹ́ ìfipè láti ní ìmọ̀lára ìgbẹ́kẹ̀lé àti ìfẹ́ Ọlọ́run fún wa àti fún ara wa. Àwọn ọmọ Ìjọ, pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́-àgbà ànìkanwà, nsìn déédé jákèjádò Ìjọ àti ní àwọn àwùjọ wa.

Nípa ìmísí, bíṣọ́pù kan pe àwọn ọ̀dọ́ tọkọ-taya kan láti sìn ní nọ́sírì ti wọ́ọ̀dù kan. Ní àkọ́kọ́, ọkọ máa njóko ní igun kan, ní títa-kété àti jìnnà. Díẹ̀díẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀sí rẹ́rĩn múṣẹ́ sí àwọn ọmọ náà. Lẹ́hìnwá, tọkọ-taya náà fi ìmoore hàn. Ṣaájú, wọ́n sọ pé, ìyàwó fẹ́ àwọn ọmọ, ọkọ kò fẹ́. Nísisìyí, sísìn ti yí wọn padà ó sì ti mú wọn wà ní ìrẹ́pọ̀. Bákannáà ó ti mú ayọ̀ ti àwọn ọmọdé wá sí ìgbeyàwó àti ilé wọn,

Ní ilú nlá míràn, ọ̀dọ́ ìyá kan pẹ̀lú àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ àti ọkọ rẹ̀ ní ìyanu àti ìrẹ̀wẹ̀sì ṣùgbọ́n ó gbà nígbàtí a pè é láti sìn bíi ààrẹ Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ ti wọ́ọ̀dù. Láìpẹ́ lẹ́hìnnáà, àwọn ìjì yìnyín já iná mọ̀nà-mọ́ná, tí ó fi àwọn ṣẹ́ẹ̀fù ilé ìtajà sílẹ̀ ní òfo tí àwọn ibùgbé sì dàbí àwọn àpótí yìnyín Nítorípé wọ́n ní iná àti ooru, ọ̀dọ́ ẹbí yi fi inúrere ṣí ilé wọn sílẹ̀ fún ọ̀pọ̀ àwọn ẹbí àti àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan láti la ìjì já’

Ìgbẹ́kẹ̀lé ndi gidi nígbàtí a bá ṣe àwọn ohun líle pẹ̀lú ìgbàgbọ́. Iṣẹ́ ìsìn àti ìrúbọ nmú agbára lékún ó sì ntún ọkàn ṣe. Ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run àti ara wa nmú àwọn ìbùkún ọ̀run wá.

Lẹ́hìn tí ó yọ nínú ewu àrun jẹjẹrẹ, ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan tún kọlù arákùnrin onígbàgbọ́ kan. Dípò níní ìmọ̀lára ìkáànú fún ara rẹ̀, ó bèèrè pẹ̀lú àdúrà, “Kíni mo le kọ́ láti inú ìrírí yí?” Nínú yàrá àkànṣe ìtọ́jú rẹ̀, ó ní ìmọ̀lára ìṣílétí láti fura sí nọ́ọ̀sì kan tí ó ní àìbalẹ̀ ọkàn fún ọkọ àti àwọn ọmọ rẹ̀. Olùgbàtọ́jú nínú ìrora rí àwọn ìdáhùn bí ó ti ngbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run tí ó sì nnawọ́ sí áwọn ẹlòmíràn.

Bí arákùnrin kan pẹ̀lú àwọn àníyàn nípa pọnógíráfì ṣe ndúró ní ìta ọ́físì rẹ̀, ààrẹ èèkàn kan gbàdúra láti mọ bí yío ti ṣèrànwọ́. Ìṣíléti kedere kan wá, “Ṣí ìlẹ̀kùn kí o sì jẹ́kí ó wọlé.” Pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run yío ṣe ìrànwọ́, olóyè àlùfáà olùdarí náà ṣí ìlẹ̀kùn ó sì gba arákùnrin náà mọ́ra. Ọkọ̀ọ̀kan ní ìmọ̀lára ìfẹ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé tó nyínipadà fún Ọlọ́run àti fún ara wọn. Ní ìgbaradì, arákùnrin náà le bẹ̀rẹ̀ láti ronúpìwàdà kí ó sì yípadà.

Nígbàtí àwọn ipò olukúlùkù wa jẹ́ ti ara ẹni, àwọn ìpìlẹ̀ ìhìnrere àti Ẹ̀mí Mímọ́ le rànwá lọ́wọ́ láti mọ̀ bóyá, báwo, àti ìgbà tí a lè ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àwọn ẹlòmíràn lẹ́ẹ̀kansíi Nígbàtí a bá ba ìgbẹ́kẹ̀lé jẹ́ tàbí dalẹ̀ rẹ̀, ìjákulẹ̀ àti ìbànújẹ́ máa njẹ́ gidi, bẹ́ẹ̀ ni ìnílò fún ìfòyemọ̀ láti mọ ìgbàtí ìgbàgbọ́ àti ìgboyà bá yẹ tó láti ní ìgbẹ́kẹ̀lé lẹ́ẹ̀kansíi nínú àwọn ìbáṣepẹ̀ ẹ̀dá ènìyàn.

Síbẹ̀, pẹ̀lú ọ̀wọ̀ sí Ọlọ́run àti ìfihàn ara ẹni, Ààrẹ Russell M. Nelson fi dánilójú pé, “Ẹ kò nílati ronú ẹnití ẹ̀yin le gbẹ́kẹ̀lé láìléwu.”6 A le gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run nígbàgbogbo. Olúwa mọ̀ wá dáradára Ó sì fẹ́ràn wa jù bí àwa ti mọ̀ tàbí fẹ́ràn ara wa. Ìfẹ́ àìlópin àti ìmọ̀ pípé Rẹ̀ nípa èyítí ó ti kọjá, ti ìsisìyí, àti ti ọjọ́ iwájú mú àwọn májẹ̀mú àti àwọn ìlérí Rẹ̀ dúróṣinṣin ó sì dájú.

Gbẹ́kẹ̀lé ohun tí àwọn ìwé mímọ́ pè ní “nínú ètò ti àkókò [náà].”7 Pẹ̀lú ìbùkún Ọlọ́run, ìlànà ti àkókò, àti títẹ̀síwájú ìgbàgbọ́ àti ìgbọràn, a le rí ìpinnu àti alàáfíà.,

Olùwa ntuninínú.

“Ẹkún le pẹ́ di alẹ́ kan, ṣùgbọ́n ayọ̀ nbọ̀ ní òwúrọ̀.”8

“Kó ẹrù rẹ [lé] Olúwa kí o sì gbẹ́kẹ̀lé ìtọ́jú rẹ̀ tí ó wà títí.”9

“Ilẹ̀ ayé kò ní ìbànújẹ́ tí ọ̀run kò le wòsàn.”10

Ẹ gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run11 àti àwọn iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀. Àwa àti àwọn àjọṣepọ̀ wa lè yípada. Nípasẹ̀ Ètùtù ti Krístì Olúwa, a le bọ́ ìmọtaraẹni ti àdánidá ẹni kúrò kí a sì di ọmọ Ọlọ́run, oníwàtútù, onírẹ̀lẹ̀,12 kíkún fún ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé tí ó dára. Nígbàtí a bá ronúpìwàdà, nígbàtí a bá jẹ́wọ́ tí a sì kọ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa sílẹ̀, Olúwa wípé Òun kì yío rántí wọn mọ́.13 Kìí ṣe pé Ó gbàgbé; dípò bẹ́ẹ̀,ní ọ̀nà tó lápẹrẹ kan, ó dàbí ẹnipé Ó yàn láti máṣe rántí wọn mọ́, bẹ́ẹ̀ni àwa náà kò nílò rẹ̀.

Ẹ Gbẹ́kẹ̀lé ìmísí Ọlọ́run kí ẹ si fi òye mọ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n. A le dárijì àwọn ẹlòmíràn ní àkókò àti ọ̀nà tí ó tọ́ bí Olúwa ti sọ pé a gbọdọ̀ ṣe.14 nígbàtí a njẹ́ “ọlọ́gbọ́n bí ejò àti oníwà tútù bí àdàbà.”15

Nígbàmíràn tí ọkàn wa bá ní ìròbínújẹ́ àti ìrora jùlọ, a ṣí sílẹ̀ jùlọ fún ìtùnú àti ìtọ́ni Ẹmí Mímọ́.16 Ìdálẹ́bi àti ìdáríjì méjèèjì nbẹ̀rẹ̀ nípa dídá àṣìṣe kan mọ̀. Nígbọa púpọ̀ ìdálẹ́bi máa nfojúsùn sórí ohun tó ti kọjá. Ìdáríjì nwò sí ọjọ́ iwájú pẹ̀lú ìtúsílẹ̀. “Nítorí Ọlọ́run kò rán Ọmọ Rẹ̀ sínú ayé láti dá ayé lẹ́bi; ṣùgbọ́n pé kí ayé nípa rẹ̀ lè ní ìgbàlà.”17

Àpóstélì Páulù bèèrè pé, “Tani ó lè yà wa kúrò nínú ìfẹ́ Krístì?” Ó dáhùn, “Bóyá ikú, tàbí ìyè, … tàbí gíga, tàbí ìbú, … ni yíò lè yà wa kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, èyí tí ó wà nínú Krístì Jésù Olúwa wa.”18 Síbẹ̀, ẹnìkan wà tí ó le yà wá kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run àti Jésù Krístì—àti pé ẹni náà ni àwa, àwa fúnrawa. Bí Isaiàh ti sọ, “Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín ti fi ojú wọn pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ yín.”19

Nípa ìfẹ́ àtọ̀runwá àti òfin àtọ̀runwá, a ní ojúṣe fún àwọn yíyàn wa àti àwọn àyọrísí wọn. Ṣùgbọ́n ètùtù ìfẹ́ Olùgbàlà wa jẹ́ “àìlópin àti ti ayèrayè.”20 Nígbàtí a bá ṣetán láti wá sílé, àní bí a tilẹ̀ wà “ní ọ̀nà jíjìn síbẹ̀,”21 Ọlọ́run ṣetán pẹ̀lú ìyọ́nú nlá láti kí wa káàbọ̀, ní fífi ohun dídára jùlọ tí Ó ní sílẹ̀ tayọ̀tayọ̀.22

Ààrẹ J. Reuben Clark sọ pé, “Mo gbàgbọ́ pé Baba wa Ọrun fẹ́ láti gba ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ rẹ̀ là, … pé nínú òdodo àti àánú rẹ̀ òun yío fúnwa ní èrè gígajù fún àwọn ìṣe wa, yío fúnwa ní gbogbo ohun tí ó le fúnni, àti ní ìdàkejì, mo gbàgbọ́ pé òun yío gbé ìjìyà tó kéréjù tí ó ṣeéṣe fún un láti gbé lé wa.”23

Ní orí àgbélébu, àní ẹ̀bẹ̀ tàánú-tàánú ti Olùgbàlà wa sí Baba Rẹ̀ kìí ṣe àìní-àjọsọ, “Baba, dáríjì wọ́n,” ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀ “Baba, dáríjì wọ́n, nítorí wọn kò mọ ohun tí wọ́n ṣe.”24 Agbára láti yàn àti òmìnira wa ní ìtumọ̀ nítorípé a ó jíyìn níwájú Ọlọ́run àti ara wa fún ẹnití a jẹ́, fún ohun tí a mọ̀ àti tí a ṣe. Pẹ̀lú ọpẹ́, a le gbẹ́kẹ̀lé òdodo pípé àti àánú pípé ti Ọlọ́run láti dá ẹjọ́ àwọn èrò inú àti àwọn ìṣe wa ní pípé.

A parí bí a ti bẹ̀rẹ̀—pẹ̀lú ìyọ́nú Ọlọ́run bí a ti wá sílé sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ àti ọ̀dọ̀ ẹnìkọ̀ọ̀kan ara wa.

Njẹ́ ẹ rántí òwe Jésù Krístì nípa ọkùnrin kan tí ó ní ọmọkùnrin méjì?25 Ọmọkùnrin kan kúrò nílé ó sì fi ogún ìní rẹ̀ ṣòfò. Nígbàtí ó rónú ara rẹ̀, ọmọkùnrin yi lépa láti wá sílé. Ọmọkùnrin kejì, nínú ìmọ̀lára pé òun ti pa àwọn òfin mọ́ “kíyèsí, ní àwọn ọdún púpọ̀ wọ̀nyí,”26 kò fẹ́ láti kí arákùnrin rẹ̀ káàbọ̀ sílé.

Ẹyin arákùnrin àti arábìnrin, njẹ́ ẹ̀yin kó ròó pé Jésù Krístì nbèèrè lọ́wọ́ wa láti ṣí ọkàn wa, òye wa, ìyọ́nú, àti ìrẹ̀lẹ̀, àti láti rí ara wa nínú àwọn ipa méjèèjì bí?

Bíi ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin àkọ́kọ́, a le rìn kiri àti lẹ́hìnwá kí a lépa láti padà sílé. Ọlọ́run ndúró láti kí wa káàbọ̀.

Àti bíi ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin kejì, Ọlọ́run rọra nbẹ̀ wá láti yọ ayọ̀ papọ̀ bí ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ti nbọ̀wá sílé sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Ó npèwá láti mú kí àwọn ìpéjọpọ̀, iyejú, kíláàsì, àti àwọn ìṣe ìdárayá wa ṣí sílẹ̀, jẹ́ ojúlówó, àìléwu—ilé fún ẹnìkọ̀ọ̀kan ara wa. Pẹ̀lú inúrere, òye, àti ìbọ̀wọ̀ fún tọ̀tún-tòsì, ọ̀kọ̀ọ̀kan wa le fi ìrẹ̀lẹ̀ wá Olúwa àti kí a gbàdúrà kí a sì tẹ́wọ́gba àwọn ìbùkún ìhìnrere Rẹ̀ tí a múpadàbọ̀sípò fún gbogbo ènìyàn.

Àwọn ìrìn àjò ìgbé ayé wa jẹ́ ti ẹnìkọ̀ọ̀kan, ṣùgbọ́n a le wá lẹ́ẹ̀kansíi sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa àti Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀ nípasẹ̀ ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run, ẹlòmíràn, àti ara wa.27 Jésù ṣẹ́wọ́, “Máṣe bẹ̀rù, ṣá gbàgbọ́ nìkan.”28 Bí Wòlíì Joseph Smíth ti ṣe, láìsínira kí a le ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìtọ́jú Baba wa Ọrun.29 Arákùnrin ọ̀wọ́n, arábìnrin ọ̀wọ́n, ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n, ẹ jọ̀wọ́ ẹ wòó fún ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé—iṣẹ́́ ìyanu kan tí Ó ṣèlérí fún yín lóni. Ní orúkọ ọlọ́wọ̀ àti mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.