Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ẹ Wá sọ́dọ̀ Krístì Ẹ Má sì Nìkan Dáwá
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa (Ọ̀wàwà) 2021


10:19

Ẹ Wá sọ́dọ̀ Krístì Ẹ Má sì Nìkan Dáwá

Ọ̀nà dídárajùlọ fún yín láti tún ayé ṣe ni láti múra aráyé sílẹ̀ fún Krístì nípa pípe ẹni-gbogbo láti tẹ̀lé E.

Láìpẹ́ mo gba lẹ́tà kan látọ̀dọ̀ ọ̀dọ́mọbìnrin onígboyà kan. Ó kọ pé, “Ọ̀na dí mọ́ mi. … Èmi kò dá ẹni tí mo jẹ́ mọ̀, ṣùgbọn mo ní ìmọ̀lára pé mo wà nihin fùn ohun nlá kan.”

Njẹ́ ẹ ti ní irú ìmọ̀lára ìwákiri bẹ́ẹ̀ rí, ní ìyàlẹ́nu bí Baba Ọrun ti mọ ẹni tí ẹ jẹ́ àti bí Òun bá nílò yín? Ẹ̀yin ọ̀dọ́ mi ọ̀wọ́n, àti sí ẹni-gbogbo, mo jẹ́rí pé ìdáhùn náà ni bẹ́ẹ̀ni Olúwa ní ètò kan fún yín. Olúwa ti múra yín sílẹ̀ fún ọjọ́ yí, nísisìyí gan, láti jẹ́ okun àti ipá fún rere nínú iṣẹ́ nlá Rẹ̀. A nílò yín! Kò kàn ní jẹ́ nlá bẹ́ẹ̀ láìsí yín!

Lábẹ́ àwọn ìpò mímọ́, olólùfẹ́ wòlíì wa. Ààrẹ Russell M. Nelson, nígbàkan rán mi létí àwọn òtítọ́ jẹ́jẹ́ méjì tí ó jẹ́ ìpilẹ̀ṣẹ̀ sí ìṣẹ́ ọlọ́lá àti ológo.

Mo rántí jijóko lórí àga pẹ̀lú ọkọ mi nígbàtí wòlíì gbé ijoko rẹ sílẹ̀, ní fífẹ́rẹ̀ jẹ́ eékún sí eékún pẹ̀lú wa, ó sì wò mí pẹ̀lú àwọn ojú ìwonitán búlúù rẹ̀. Kò dá mi lójú bí ọkàn mi bá nyí tàbí ó ti dúró pátápátá bí ó ti pè mí láti sìn bí Ààrẹ Gbogbogbò àwọn Ọ̀dọ́mọbìrin. Ó bèèrè ìbèère kan tí ó ṣì ndún nínú ọkàn mi pé, “Bonnie, kíni ohun tí ó ṣe pàtàkì jùlọ tí àwọn [ọ̀dọ́] nílò láti mọ̀?”

Mo jíròrò fún àkokò díẹ̀ mo sì wí pé, “Wọ́n nílò láti mọ ẹni tí wọ́n jẹ́.”

“BẸ́Ẹ̀NI!” ó kígbe, “wọ́n sì níláti mọ èrèdí wọn.”

Ìdánimọ̀ Àtọ̀runwá Wa

Ẹ jẹ́ oníkẹ́, olùfẹ́ ọmọ Baba Ọ̀run. Ó nifẹ́ yín ní pípe gidi tí Ó fi rán Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, láti ṣe ètùtù fún yín àti fún èmi.1 Ìfẹ́ Olùgbàlà fún wa jẹ́ àìkùnà—àní nígbàtí a bá kùnà! Kò sí ohun tí ó lè yà wá kúrò nínú ifẹ́ Ọlọ́run.2 Rírántí ìfẹ́ yí lè ràn yín lọ́wọ́ láti ti ìdàmú ayé tí ó ngbìyànjú láti mú àìlera bá ìgbẹ́kẹ̀lé yín nínú ìdánimọ̀ tọ̀run kí ó sì so yín pọ̀ mọ́ okun yín.

Ní ìpàdé àpapọ̀ kan ti FSY, mo pàdé àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin tí wọ́n ti nlàkàkà. Àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin bákannáà dárúkọ yíyípadà sí ìbùkún bàbánlá rẹ̀ láti ṣe àtúnrí ìfẹ́ Olúwa àti ìtọ́sọ́nà fún ti araẹni rẹ̀. Ẹ wá ìbùkún bàbánlá yín, kí ẹ fẹ́ eruku kúrò tí ẹ bá níláti ṣe, ṣùgbọ́n ẹ ṣe àṣàrò rẹ̀ lemọ́lemọ́. Bí ẹ kò bá ní ọ̀kan, ẹ gba ọ̀kan—láìpẹ́. Ẹ máṣe ní ìdádíró láti wadi ohun tí Olúwa nfẹ́ láti wí fún yín nísisìyí nípa ẹni tí ẹ jẹ́.

Èrèdí Ayérayé Wa

Òtítọ́ kejì tí Ààrẹ Nelson wí fún wa ní ọjọ́ náà ni láti mọ èrèdí wa. Èyí ni àṣẹ ọlọ́lá àti akọni.

Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́hìn, ọmọkùnrin mi Tanner jẹ́ ọmọ ọdún marun péré nígbàtí ó ṣe eré bọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá rẹ̀ àkọ́kọ́. Inú rẹ̀ dùn!

Nígbàtí a dé ibi eré, a damọ̀ pé ẹgbẹ́ rẹ̀ nlo ìdá-ìlànà ìfojúsùn bọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá—kìí ṣe àfojúsùn yíyọ-sókè díẹ̀ ṣùgbọ́n àwọn nlá tí ó dàbí ó tóbijùlọ fún àwọn ọmọ ọdún marun.

Eré náà gba àwọn iye àròso bí mo ti rí tí Tanner gba ibi-ipò góòlù. Ó yà mí lẹ́nu. Ṣe òun ní ìmọ̀ èrèdí rẹ̀ dájúdájú ní títọ́jú àwọ̀n?

Wọ́n fun fèrè, a sì di híhá sínú eré tí a fi gbàgbé gbogbo ohun nípa Tanner. Lọ́gán ọ̀kàn lára àwọn ọmọ ẹgbẹ́ alátakò gba bọ́ọ̀lù ó sì nyilọ síwájú rẹ̀. Mo wo ibi ìdarí Tanner láti mu dájú pé ó ṣetán láti dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ̀ kí ó sì dáàbò bo góòlù. Mo rí ohunkan tí èmi kò retí.

Ọmọdékùnrin ngbá góòlù

Ní àmì kan nínú eré, Tanner ti ní ìdènà tí ó fi bẹ̀rẹ̀sí ju ọwọ́ òsì rẹ̀ nínú àwọn ihò inú àwọ̀n. Nígbànáá ó ṣe ohun kannáà pẹ̀lú apá ọ̀tún rẹ̀. Títẹ̀le ni, ẹsẹ̀ rẹ̀ ọ̀tún. Nígbẹ̀hìn, ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀. Tanner ti yímọ́ inú àwọ̀n ní kíkún. Ó ti gbàgbé èrèdí rẹ̀ àti ohun tí ó ṣe ìlérí fún ẹgbẹ́ rẹ̀ pé òun ó ṣe.

Ọmọdékùnrin dìmọ́ inú àwọ̀n

Nígbàtí iṣẹ́ bọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá Tanner kò pẹ́ títí, ẹ̀kọ́ rẹ̀ sí mi ní ọjọ́ náà kò ní kúrò láéláé. Gbogbo wa nní ìdènà ní ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan tí a sì ndarí okun wa sí ibòmíràn. Ọ̀kan lára àwọn ohun-ìjà alágbára jùlọ Sátánì ni láti dè wá lọ́nà pẹ̀lú ìdí rere àti dídárasi èyítí, ní àkokò àìní, lè sopọ̀ àti láti so wá pọ̀ kúrò nínú iṣẹ́ náà gan tí ó pè wá wá sínú ayé.3

Èrèdí ayérayé wa ni láti wá sọ́dọ̀ Krístì àti fífi taratara darapọ̀ mọ́ Ọ nínú iṣẹ́ nlá Rẹ̀. Ó jẹ́ bí ìrọ̀rùn bí ṣíṣe ohun tí Ààrẹ Nelson kọ́ni: “Ìgbàkúgbà tí a bá ṣe ohunkan tí ó nran ẹnìkan lọ́wọ́ … tí a dá tí a sì pa àwọn májẹ̀mú wa pẹ̀lú Ọlọ́run mọ́, à nṣèrànwọ́ láti kó Ísráẹ́lì jọ.”4 Nígbàtí a bá sì ṣe iṣẹ́ Rẹ̀ papọ̀ pẹ̀lú Rẹ̀, a ó mọ̀ a ó sì nifẹ Rẹ̀ si.

Nígbànáà a ntẹ̀síwájú láti lépa láti fà súnmọ́ Olùgbàlà nínú ìgbàgbọ́, ṣìkẹ́ ìrònúpìwàdà, àti pípa àwọn òfin mọ́. Bí a ti nso arawa mọ́ Ọ nípasẹ̀ àwọn májẹ̀mú àti ìlànà, à nkún ìgbé-ayé wa pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé,5 ààbò,6 àti ìjìnlẹ̀ àti ayọ̀ pípẹ́.7

Bí á bá wá sọ́dọ̀ Rẹ̀, a nrí àwọn ẹlòmíràn nípa ojú Rẹ̀.8 Wá sí ọ̀dọ̀ Krístì Wá nísisìyí, ṣùgbọ́n máṣe dá wá!9

Ìhìnrere Jésù Krístì ko kàn dára nìkan; ó ṣe pàtàkì fún ẹni-gbogbo. “Kò sí ọ̀nà míràn tàbí ibi èyí tí [a] ti lè ní ìgbàlà, nínú àti nípasẹ̀ Krístì nìkan ni.”7 A nílò Jésù Krístì! Aráyé nílò Jésù Krístì.11

Ẹ rántí pé, ọ̀nà dídárajùlọ fún yín láti tún ayé ṣe ni láti múra aráyé sílẹ̀ fún Krístì nípa pípe ẹni-gbogbo láti tẹ̀lé E.

Ìtàn alágbára kan wà nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì nípa àjínde Olùgbàlà ní lílo àkokò pẹ̀lú àwọn Néfì. Ṣe ẹ lè ro ohun tí ìyẹn yíò dàbí?

Bí Krístì ti kéde pé Òun gbọ́dọ̀ padà sí ọ̀dọ̀ Baba, “ó wò yíká lẹ́ẹ̀kansi.”12 Wíwo omijé lójú àwọn ènìyàn, Ó mọ pé ọkàn wọn nlọ́ra fún Un láti dúró pẹ́.

Olùgbàlà npe àwọn Néfì láti wá gba ìwòsàn

Ó bèèrè: “Njẹ́ ẹ̀yin ní aláìsàn lãrín yín? Ẹ mú wọn wá sí ọ̀dọ̀ mi. Njẹ́ ẹ ní ẹnikẹ́ni tí ó yarọ, tàbí fọ́jú, … yadi, tàbí tí wọ́n ní ìpọ́njú ní ọ̀nàkọnà? Ẹ mú wọn wá síhin èmi ó sì wò wọ́n san.”9

Níní àánú nlá, Òun kò gbé òpin kankan kalẹ̀ ó sì pè fún gbogbo àwọn “tí a pọ́nlójú ní ọ̀nàkọnà.” Mo nifẹ pé kò sí ohunkóhun tí ó tóbi jùlọ tàbí kéré jùlọ fún Jésù láti wòsàn.

Ó mọ ìjìyà àti ìlàkàkà wa bákannáà ó sì npè láti mú ìtara àti ìrẹ̀wẹ̀sì, rírẹ̀, gbígbéraga àti àìní-ìmọ, àdánìkanwà, tàbí àwọn tí a “pọ́nlójú ní ọ̀nàkọnà.”

Ìwonisàn Olùgbàlà

Àti pé gbogbo wọn “jáde wá … ; ó sì wò wọ́n sàn ní ọ̀kọ̀ọ̀kan. …

“… Gbogbo wọn tí ó ti wòsàn àti àwọn tí ó wà ní pípé, ni ó wólẹ̀ sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀, tí wọ́n sì jọ́sìn fún un.”14

Gbogbo ìgbà tí mo bá ka eyí, mo máa nbi ara mi léèrè. Tani èmi yíò mú wá sọ́dọ̀ Krístì? Tani ẹ̀yin yíò mú wá?

Ṣe a lè wo yíká lẹ́ẹ̀kansi, bí Jésù ti ṣe, láti mọ̀ dájú pé kò sí ẹni tí ó sọnù kí a sì pe ẹnìkọ̀ọ̀kan láti wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀?

Ẹ jẹ́ kí nṣe àbápín àpẹrẹ nípa bí ó ti lè rọrùn tó. Ọ̀rẹ́ mi ọ̀dọ́ Peyton ọjọ́-orí mẹẹdogun ní ìfojúsùn láti ka ẹsẹ marun ìwé-mímọ́ níbi oúnjẹ òwúrọ̀ lójojúmọ́, ṣùgbọ́n kò dá ṣeé fúnra rẹ̀. Wíwò lẹ́ẹ̀kansi, Peyton pe àwọn òbí àti tẹ̀gbọ́n-tàbúrò rẹ̀, àní arákùnrin ọmọ ọdún marun láti ṣe é bákannáà. Ìṣẹ tí ó dàbí kékeré yí ni ohun tí Krístì nkọ́ni nígbàtí Ó pe, “Ẹ mú wọn wá sí ọ̀dọ̀ mi.”

Ìpè yí láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni a ṣì nà síwa loni. Ẹ̀yin ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin, ẹ bẹ̀rẹ̀ nísisìyí, nínú ilé arayin. Ẹ gbàdúrà kí ẹ sì bèèrè lọ́wọ́ Baba Ọ̀run bí ti lè ṣàtìlẹhìn àwọn òbí yín bí wọ́n ti ntẹ̀síwájú láti wá sí ọ̀dọ̀ Krístì? Wọ́n nílò yín bákannáà bí ẹ ti nílò wọn.

Nígbànáà ẹ wò àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò yín lẹ́ẹ̀kansi, àwọn ọ̀rẹ́, àti aladugbo. Tani ẹ ó mú wá sọ́dọ̀ Krístì?

Olùgbàlà kéde, “Ẹ kíyèsĩ èmi ni ìmọ́lẹ̀; èmi ti fi àpẹrẹ lélẹ̀ fún yín.”3 A ó ní ìmọ̀lára ìfẹ́ àti àláfíà Olùgbàlà bí a ti ndarapọ̀ mọ́ Ọ ní gbígba ẹbí Ọlọ́run là, nítorí Ó ti ṣèlérí pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé mi kò ni rìn nínú òkùnkùn, ṣùgbọ́n yíò ní ìmọ́lẹ̀ ayé.”16

Irú àkokò ológo láti ṣiṣẹ́ nínú èrò Krístì!

Bẹ́ẹ̀ni, ẹ wà nihin fún ohun ọlọ́lá kan. Mo darapọ̀ pẹ̀lú Ààrẹ Nelson, ẹnití ó wípé, “Olúwa nílò yín láti yí ayé padà. Bí ẹ ti ntẹ́wọ́gbà tí ẹ sì ntẹ̀lé ìfẹ́ Rẹ̀ fún yín, ẹ ó rí arayin ní ṣíṣe àṣeyọrí ohun tí kò ṣeéṣe!”14

Mo jẹ́rí pẹ̀lú ìgboyà pé Olúwa mọ ẹni tí ẹ jẹ́ Ó sì nifẹ yín! Lápapọ̀, a ó mú èrò Rẹ̀ dàgbà títí ọjọ́ nlá náà nígbàtí Krístì Fúnrarẹ̀ yíò padà sí ilẹ̀-ayé yí ti yíò sì pè wá láti wá “sí ọ̀dọ̀ rẹ̀.” A ó fi tayọ̀tayọ̀ kójọ papọ̀, nítorí àwa ni àwọn ẹnití ó wá sọ́dọ̀ Krístì, a kò sì dánìkan wá. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.